ORÍ 13
‘Lẹ́yìn Tí Wọ́n Jiyàn Díẹ̀’
Wọ́n gbé ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ lọ síwájú ìgbìmọ̀ olùdarí
Ó dá lórí Ìṣe 15:1-12
1-3. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni tó fẹ́ fa ìpínyà? (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ìwé Ìṣe sọ lórí ọ̀rọ̀ náà?
INÚ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń dùn gan-an! Kò pẹ́ tí wọ́n dé sílùú Áńtíókù ti Síríà lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ. Ohun tó sì mú kí wọ́n láyọ̀ ni pé Jèhófà “ti ṣí ilẹ̀kùn fún àwọn orílẹ̀-èdè láti di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 14:26, 27) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará Áńtíókù ń fìdùnnú tẹ́wọ́ gba ìhìn rere, “ọ̀pọ̀ èèyàn” lára àwọn Kèfèrí sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà níbẹ̀.—Ìṣe 11:20-26.
2 Kò pẹ́ tí ìròyìn ayọ̀ nípa báwọn onígbàgbọ́ ṣe ń pọ̀ sí i yìí fi dé Jùdíà. Àmọ́, ìròyìn yìí ò múnú gbogbo àwọn ará dùn. Torí àwọn kan gbà pé ó yẹ káwọn Kristẹni máa dádọ̀dọ́, nígbà táwọn míì sì gbà pé kò pọn dandan. Àmọ́, báwo ló ṣe yẹ kí nǹkan rí láàárín àwọn Júù àtàwọn onígbàgbọ́ tí kì í ṣe Júù. Bákan náà, ṣé ó pọn dandan káwọn onígbàgbọ́ tí kì í ṣe Júù máa pa Òfin Mósè mọ́? Ọ̀rọ̀ yìí dá wàhálà sílẹ̀, ó sì le débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fa ìpínyà nínú ìjọ Kristẹni. Báwo ni wọ́n ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ yìí?
3 Bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò nínú ìwé Ìṣe, a máa rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye kọ́. Àwọn ẹ̀kọ́ náà lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn nǹkan tó lè fa ìpínyà bá wáyé lónìí.
“Láìjẹ́ Pé Ẹ Dádọ̀dọ́” (Ìṣe 15:1)
4. Èrò tí kò tọ́ wo làwọn Kristẹni kan ní, ìbéèrè wo nìyẹn sì lè gbé wá síni lọ́kàn?
4 Ọmọ ẹ̀yìn náà, Lúùkù, sọ pé: “Àwọn ọkùnrin kan wá [sí Áńtíókù] láti Jùdíà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ará pé: ‘Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà tí Mósè fi lélẹ̀, ẹ ò lè rí ìgbàlà.’ ” (Ìṣe 15:1) A ò mọ̀ bóyá Farisí làwọn ‘ọkùnrin tó wá láti Jùdíà’ yìí kí wọ́n tó di Kristẹni. Àmọ́, ó jọ pé èrò àwọn Farisí tó máa ń rin kinkin mọ́ òfin ti fẹ́ máa nípa lórí wọn. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ pé ńṣe làwọn ń gbẹnu sọ fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 15:23, 24) Àmọ́, kí wá nìdí táwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù yẹn ṣì fi ń tẹnu mọ́ ọn pé èèyàn gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́, lẹ́yìn odindi ọdún mẹ́tàlá tí Ọlọ́run ti darí àpọ́sítélì Pétérù láti gba àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ sínú ìjọ Kristẹni?a—Ìṣe 10:24-29, 44-48.
5, 6. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó mú káwọn kan lára àwọn Júù tó di Kristẹni máa rin kinkin mọ́ ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́? (b) Ṣé májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́ wà lára májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá? Ṣàlàyé. (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
5 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló fà á. Ohun kan ni pé, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló pàṣẹ pé kí wọ́n máa dádọ̀dọ́ fáwọn ọmọkùnrin, ó sì jẹ́ àmì pé wọ́n ní àjọṣe pàtàkì pẹ̀lú rẹ̀. Jèhófà ti kọ́kọ́ sọ fún Ábúráhámù pé kí òun àti agbo ilé rẹ̀ dádọ̀dọ́, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Jèhófà wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin pé kí wọ́n máa dádọ̀dọ́.b (Léf. 12:2, 3) Kódà, Òfin Mósè sọ pé ó pọn dandan pé káwọn àjèjì dádọ̀dọ́ kí wọ́n tó lè ní àwọn àǹfààní kan, irú bíi jíjẹ oúnjẹ Ìrékọjá. (Ẹ́kís. 12:43, 44, 48, 49) Torí náà, aláìmọ́ tàbí ẹlẹ́gbin làwọn Júù máa ń ka ẹni tí kò bá dádọ̀dọ́ sí.—Àìsá. 52:1.
6 Àwọn Júù tó di Kristẹni yẹn gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára kí wọ́n tó lè yí èrò wọn pa dà lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́. Ó ṣe tán, májẹ̀mú tuntun ti rọ́pò májẹ̀mú Òfin. Torí náà, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ jẹ́ Júù, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ẹni náà wà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó di Kristẹni yẹn ló jẹ́ pé àárín àwọn Júù bíi tiwọn ni wọ́n ṣì ń gbé. Torí náà, wọ́n ní láti jẹ́ onígboyà kí wọ́n tó lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí wọ́n sì máa jọ́sìn pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́ táwọn náà ti di Kristẹni.—Jer. 31:31-33; Lúùkù 22:20.
7. Kí ni kò tíì yé àwọn ‘ọkùnrin tó wá láti Jùdíà’ yẹn?
7 Àmọ́ o, ìlànà Ọlọ́run ò tíì yí pa dà. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé díẹ̀ lára ohun tí Òfin Mósè dá lé wà nínú májẹ̀mú tuntun. (Mát. 22:36-40) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìdádọ̀dọ́, ó kọ̀wé pé: “Ẹni tó jẹ́ Júù ní inú ni Júù, ìdádọ̀dọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn nípa ẹ̀mí, kì í ṣe nípa àkọsílẹ̀ òfin.” (Róòmù 2:29; Diu. 10:16) Àwọn ‘ọkùnrin tó wá láti Jùdíà’ yẹn ò lóye àwọn nǹkan yìí, ńṣe ni wọ́n ń rin kinkin mọ́ ọn pé Ọlọ́run ò tíì mú òfin ìdádọ̀dọ́ kúrò. Ṣé wọ́n máa fẹ́ yí èrò wọn pa dà?
‘Wọ́n Jiyàn, Wọ́n sì Jọ Ṣe Awuyewuye’ (Ìṣe 15:2)
8. Kí nìdí tí wọ́n fi fọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ lọ ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù?
8 Lúùkù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ti bá [àwọn ọkùnrin tó “wá láti Jùdíà”] jiyàn díẹ̀, tí wọ́n sì jọ ṣe awuyewuye, àwọn ará ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pẹ̀lú àwọn míì lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù lórí ọ̀rọ̀ yìí.”c (Ìṣe 15:2) Bíbélì sọ pé ‘wọ́n jiyàn, wọ́n sì jọ ṣe awuyewuye,’ èyí fi hàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn fi ohùn tó le sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń fi ìdánilójú ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe yé wọn sí. Ọ̀rọ̀ yẹn kọjá ohun tí ìjọ tó wà ní Áńtíókù lè yanjú. Torí náà, ìjọ ṣètò pé kí wọ́n fọ̀rọ̀ náà lọ “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù,” tí wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà yẹn, kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà. Kí la lè rí kọ́ lára àwọn alàgbà tó wà ní Áńtíókù?
9, 10. Àpẹẹrẹ rere wo ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àtàwọn ará tó wà ní Áńtíókù fi lélẹ̀ fún wa lónìí?
9 Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tá a rí kọ́ nínú èyí ni pé a gbọ́dọ̀ máa fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan rèé: Àwọn ará Áńtíókù mọ̀ pé àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù nìkan ló wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí. Síbẹ̀, wọ́n fọkàn tán ìgbìmọ̀ náà pé wọ́n máa yanjú ìbéèrè tó wáyé lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Kí nìdí? Ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ àti Jésù Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Mát. 28:18, 20; Éfé. 1:22, 23) Táwọn ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ bá wáyé lónìí, ẹ jẹ́ ká ṣe bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Áńtíókù, ká fọkàn tán ètò Ọlọ́run àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ó ṣe tán, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí.
10 A tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù ti ṣe pàtàkì tó. Ẹ̀mí mímọ́ ló yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà láti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ wọn ò lo àṣẹ tí wọ́n ní láti yanjú ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ láàárín ara wọn nílùú Áńtíókù níbẹ̀. (Ìṣe 13:2, 3) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo lọ [sí Jerúsálẹ́mù] nítorí ìfihàn kan,” èyí tó fi hàn pé ọwọ́ Ọlọ́run wà nínú ọ̀rọ̀ náà. (Gál. 2:2) Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà máa ń gbìyànjú láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọ́n sì máa ń ní sùúrù nígbà táwọn ọ̀rọ̀ tó lè fa ìyapa bá ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ. Dípò kí wọ́n rin kinkin mọ́ èrò wọn, wọ́n máa ń wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nípa wíwo inú Ìwé Mímọ́ àti nípa títẹ̀ lé ìtọ́ni tí ẹrú olóòótọ́ bá fún wọn.—Fílí. 2:2, 3.
11, 12. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa dúró de àkókò Jèhófà?
11 Àwọn ìgbà míì wà tó lè gba pé ká ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa mú kí nǹkan túbọ̀ ṣe kedere. Rántí pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé, àwọn ará ní láti dúró títí di nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13) lẹ́yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan Kọ̀nílíù lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni, kí Jèhófà tó jẹ́ kí wọ́n rí ojútùú sí ọ̀rọ̀ bóyá káwọn Kèfèrí dádọ̀dọ́ tàbí kí wọ́n má ṣe dádọ̀dọ́. Kí nìdí tó fi pẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Ó lè jẹ́ pé ṣe ni Ọlọ́run fẹ́ yọ̀ǹda àkókò tó pọ̀ tó fáwọn Júù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn láti yí ojú tí wọ́n fi ń wo ọ̀rọ̀ náà pa dà pátápátá. Ó ṣe tán, kì í ṣe ọ̀rọ̀ kékeré pé Ọlọ́run fòpin sí májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́ tó bá baba ńlá wọn Ábúráhámù dá ní ẹgbẹ̀rún méjì ó dín ọgọ́rùn-ún (1,900) ọdún sẹ́yìn!—Jòhánù 16:12.
12 Àǹfààní ńlá ni pé Baba wa ọ̀run tó jẹ́ onísùúrù àti onínúure ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń fẹ́ ká fìwà jọ òun! Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ire ló máa já sí fún wa. (Àìsá. 48:17, 18; 64:8) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká máa rin kinkin mọ́ èrò tiwa, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ ká máa fara mọ́ àwọn àyípadà tó bá ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run tàbí àlàyé lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. (Oníw. 7:8) Tó o bá rí i pé ó ṣòro fún ẹ láti máa fara mọ́ ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, á dáa kó o ronú lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Ìṣe orí 15, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi wọ́n sílò.d
13. Báwo la ṣe lè ní sùúrù bíi ti Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
13 Ó tún yẹ ká ní sùúrù bíi ti Jèhófà tá a bá rí i pé ó ṣòro fún ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ èké tàbí àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè gba pé ká máa fi sùúrù ran ẹni náà lọ́wọ́, ká sì fara balẹ̀ wò ó bóyá ó máa jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ tọ́ òun sọ́nà kó lè yí èrò ẹ̀ pa dà. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Bákan náà, ó máa dáa ká gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí àkókò bá sì tó lójú Ọlọ́run, ó máa jẹ́ ká mọ ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe.—1 Jòhánù 5:14.
Wọ́n Sọ Àwọn Ìrírí Tó Ń Gbéni Ró “ní Kúlẹ̀kúlẹ̀” (Ìṣe 15:3-5)
14, 15. Báwo làwọn ará ìjọ Áńtíókù ṣe ṣàpọ́nlé Pọ́ọ̀lù, Bánábà àtàwọn míì tó bá wọn rìnrìn àjò, báwo sì ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn níṣìírí?
14 Lúùkù ń bá àlàyé ẹ̀ lọ, ó ní: “Lẹ́yìn tí ìjọ ti sin àwọn ọkùnrin yìí síwájú díẹ̀, wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n gba Foníṣíà àti Samáríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe ń yí pa dà, wọ́n sì ń mú inú gbogbo àwọn ará dùn gidigidi.” (Ìṣe 15:3) Àwọn ará ìjọ sin Pọ́ọ̀lù, Bánábà àtàwọn míì tó bá wọn rìnrìn àjò dé ojú ọ̀nà. Èyí fi hàn pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n pọ́n wọn lé, wọ́n sì fẹ́ kí Ọlọ́run bù kún wọn. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere míì làwọn ará Áńtíókù fi lélẹ̀ fún wa yìí! Ṣéwọ náà máa ń ṣàpọ́nlé àwọn arákùnrin àti arábìnrin ẹ, “pàápàá àwọn [alàgbà] tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni”?—1 Tím. 5:17.
15 Nínú ìrìn àjò wọn, wọ́n gba Foníṣíà àti Samáríà kọjá, wọ́n sì fún àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ níṣìírí gan-an, torí wọ́n ń sọ “kúlẹ̀kúlẹ̀” ìrírí nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń lọ sí lọ́dọ̀ àwọn Kèfèrí fáwọn ará náà. Ó ṣeé ṣe káwọn Júù tó jẹ́ onígbàgbọ́ àmọ́ tí wọ́n sá lọ sáwọn agbègbè yẹn lẹ́yìn ikú Sítéfánù wà lára àwọn tó gbọ́ wọn. Bákan náà lónìí, a máa ń gbọ́ ìròyìn nípa bí Jèhófà ṣe ń bù kún iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn sì máa ń fún àwọn ará níṣìírí, pàápàá àwọn tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí. Ṣé ìwọ náà máa ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti agbègbè kó o lè máa gbọ́ irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀? Ṣé o sì máa ń ka àwọn ìrírí tó ń jáde nínú àwọn ìwé wa tàbí lórí jw.org?
16. Kí ló fi hàn pé ìdádọ̀dọ́ ti di ọ̀rọ̀ pàtàkì tó ń fẹ́ àbójútó?
16 Lẹ́yìn táwọn ará tí ìjọ Áńtíókù rán níṣẹ́ yìí ti rìnrìn àjò lọ sí apá gúúsù, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) kìlómítà, wọ́n débi tí wọ́n ń lọ. Lúùkù kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, ìjọ àti àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú àwọn alàgbà gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì ròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.” (Ìṣe 15:4) Àmọ́, ńṣe ni “àwọn kan tó wá látinú ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisí, àmọ́ tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ dìde lórí ìjókòó wọn, wọ́n sì sọ pé: ‘Ó pọn dandan kí a dádọ̀dọ́ wọn, kí a sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa pa Òfin Mósè mọ́.’ ” (Ìṣe 15:5) Ní báyìí, ó ti wá hàn kedere pé ọ̀rọ̀ dídádọ̀dọ́ fáwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù ti di ọ̀rọ̀ pàtàkì tó ń fẹ́ àbójútó.
“Àwọn Àpọ́sítélì àti Àwọn Alàgbà Kóra Jọ” (Ìṣe 15:6-12)
17. Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù, kí sì nìdí tí “àwọn alàgbà” fi ń bá wọn ṣiṣẹ́?
17 Ìwé Òwe 13:10 sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.” Torí náà, “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà kóra jọ láti gbé ọ̀rọ̀ [ìdádọ̀dọ́] yẹ̀ wò.” (Ìṣe 15:6) Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń ṣe lóde òní, ńṣe ni “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà” yẹn ṣojú fún gbogbo ìjọ Kristẹni pátá. Kí nìdí tí “àwọn alàgbà” àtàwọn àpọ́sítélì fi ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀? Ẹ rántí pé wọ́n pa àpọ́sítélì Jémíìsì, wọ́n sì ti àpọ́sítélì Pétérù mọ́lé láwọn àkókò kan. Bírú ẹ̀ bá tún lọ ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì tó kù ńkọ́? Ìdí nìyẹn táwọn alàgbà míì táwọn náà jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n fi ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì, kí iṣẹ́ àbójútó lè máa bá a nìṣó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
18, 19. Ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn wo ni Pétérù sọ, kí ló sì yẹ káwọn tó gbọ́rọ̀ ẹ̀ fi sọ́kàn?
18 Lúùkù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu, Pétérù dìde, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ mọ̀ dáadáa pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti yàn mí láàárín yín pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere látẹnu mi, kí wọ́n sì gbà gbọ́. Ọlọ́run tí ó mọ ọkàn sì jẹ́rìí sí i ní ti pé ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́, bó ṣe fún àwa náà. Kò sì fi ìyàtọ̀ kankan sáàárín àwa àti àwọn, àmọ́ ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.’ ” (Ìṣe 15:7-9) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu” ní ẹsẹ 7 tún lè túmọ̀ sí “wíwádìí; bíbéèrè nípa ohun kan.” Ó jọ pé àwọn arákùnrin yẹn ní èrò tó yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀.
19 Ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Pétérù sọ yẹn rán gbogbo wọn létí pé òun fúnra ẹ̀ wà níbẹ̀ lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan Kọ̀nílíù àti agbo ilé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ àkọ́kọ́. Torí náà, tí Jèhófà bá sọ pé òun ò fìyàtọ̀ sáàárín àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù mọ́, ta ló jẹ́ sọ pé òun ò fara mọ́ ọn? Síwájú sí i, ìgbàgbọ́ nínú Kristi ló ń sọ ọkàn onígbàgbọ́ di mímọ́, kì í ṣe Òfin Mósè.—Gál. 2:16.
20. Ọ̀nà wo làwọn tó ń gbé ìdádọ̀dọ́ lárugẹ gbà “ń dán Ọlọ́run wò”?
20 Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó lágbára tó wà nílẹ̀ yìí, ìyẹn ohun tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí àti ẹ̀rí tó hàn kedere pé Ọlọ́run ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ darí wọn, Pétérù parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ báyìí pé: “Kí ló wá dé tí ẹ fi ń dán Ọlọ́run wò báyìí, tí ẹ̀ ń gbé àjàgà tí àwọn baba ńlá wa tàbí àwa fúnra wa kò lè rù kọ́ ọrùn àwọn ọmọ ẹ̀yìn? Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní ìgbàgbọ́ pé ipasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa la fi rí ìgbàlà bíi ti àwọn náà.” (Ìṣe 15:10, 11) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ńṣe làwọn tó ń gbé ìdádọ̀dọ́ lárugẹ “ń dán Ọlọ́run wò.” Ìtúmọ̀ Bíbélì míì tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni ‘wọ́n ń dán sùúrù Ọlọ́run wò.’ Wọ́n fẹ́ fipá mú àwọn Kèfèrí láti máa tẹ̀ lé òfin táwọn Júù fúnra wọn ò lè pa mọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí tí wọ́n torí ẹ̀ gba ìdálẹ́bi ikú. (Gál. 3:10) Torí náà, dípò táwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ Pétérù á fi máa gbé ìdádọ̀dọ́ lárugẹ, ńṣe ló yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ẹ̀ hàn nípasẹ̀ Jésù.
21. Kí ni Bánábà àti Pọ́ọ̀lù sọ táá mú káwọn arákùnrin náà ṣe ìpinnu tó dáa?
21 Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn, torí pé ńṣe ni ‘gbogbo wọn dákẹ́.’ Lẹ́yìn náà, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ròyìn “ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Ìṣe 15:12) Àkókò ti wá tó báyìí fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà láti gbé àwọn ẹ̀rí tó wà lọ́wọ́ yẹ̀ wò kí wọ́n sì ṣe ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́.
22-24. (a) Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti òde òní ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? (b) Báwo ni gbogbo àwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé ìlànà Ọlọ́run làwọn ń tẹ̀ lé?
22 Bákan náà lónìí, tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá pàdé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n máa ń jẹ́ kó tọ́ wọn sọ́nà, wọ́n sì máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́. (Sm. 119:105; Mát. 7:7-11) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti máa ń mọ ohun tí wọ́n máa jíròrò ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa ṣèpàdé, èyí á jẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè ronú jinlẹ̀ lórí àwọn kókó náà, kí wọ́n sì gbàdúrà nípa ẹ̀. (Òwe 15:28) Bí ìpàdé náà bá sì ń lọ lọ́wọ́, àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró yìí máa ń sọ èrò wọn jáde fàlàlà, àmọ́ lọ́nà tó fọ̀wọ̀ hàn. Wọ́n máa ń lo Bíbélì gan-an nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò.
23 Àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn táwọn alàgbà ṣèpàdé, ọ̀rọ̀ tó lágbára kan wà tí wọn ò mọ bí wọ́n á ṣe yanjú ẹ̀, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì, bí àwọn alábòójútó àyíká. Tó bá sì pọn dandan, ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lè kọ lẹ́tà sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí.
24 Ó dájú pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ọ̀nà tó fẹ́ ká máa gbà ṣe nǹkan nínú ètò ẹ̀, tí wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, adúróṣinṣin àti onísùúrù. Bá a ṣe máa rí i nínú orí tó kàn, tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní àlàáfíà tòótọ́, àwọn èèyàn á túbọ̀ wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àá sì wà níṣọ̀kan.
a Wo àpótí náà, “Ohun Táwọn Ẹlẹ́sìn Júù Fi Ń Kọ́ni.”
b Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣì wà títí dòní, àmọ́ kò sí májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́ lára ẹ̀. Ọdún 1943 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tí Ábúráhámù (tó ń jẹ́ Ábúrámù nígbà yẹn) sọdá odò Yúfírétì bó ṣe ń lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) ni nígbà yẹn. Lẹ́yìn ìyẹn, májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́ wáyé lọ́dún 1919 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ábúráhámù sì ti di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) nígbà yẹn.—Jẹ́n. 12:1-8; 17:1, 9-14; Gál. 3:17.
c Ó dà bíi pé Kristẹni kan tó ń jẹ́ Títù wà lára àwọn tí wọ́n rán. Gíríìkì ni Títù, ó bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù sì tún rán an lọ sáwọn ibì kan. (Gál. 2:1; Títù 1:4) Èèyàn dáadáa ni Títù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ ni, Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án.—Gál. 2:3.
d Wo àpótí náà, “Orí Bíbélì Ni Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Dá Lé.”