Ǹjẹ́ O Nígbàgbọ́ Bí Ti Ábúráhámù?
“Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”—LÚÙKÙ 18:8.
1. Èé ṣe tó fi ṣòro láti di ìgbàgbọ́ tó lágbára mú lónìí?
KÒ RỌRÙN rárá láti di ìgbàgbọ́ tó lágbára mú lónìí. Pákáǹleke tí ayé dojú rẹ̀ kọ àwọn Kristẹni kí wọn má bàa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí kúrò ní kèrémí. (Lúùkù 21:34; 1 Jòhánù 2:15, 16) Nítorí ogun, ìjàǹbá, ọ̀kan-ò-jọ̀kan àrùn, tàbí ebi, ekukáká ní ọ̀pọ̀ fi ń rọ́nà gbé e gbà. (Lúùkù 21:10, 11) Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn jọ wọ́n lójú gidigidi, wọ́n sì máa ń wo àwọn tó bá ń di ìgbàgbọ́ wọn mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí òpònú, kódà lójú tiwọn agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Ní àfikún sí i, ọ̀pọ̀ Kristẹni ni a ń ṣenúnibíni sí nítorí ìgbàgbọ́ wọn. (Mátíù 24:9) Dájúdájú, ìbéèrè tí Jésù béèrè ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn ṣe wẹ́kú, nígbà tó wí pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”—Lúùkù 18:8.
2. (a) Èé ṣe tí ìgbàgbọ́ lílágbára fi ṣe pàtàkì fún Kristẹni? (b) Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ ta ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
2 Kókó ibẹ̀ ni pé, ìgbàgbọ́ lílágbára ṣe pàtàkì báa bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé wa nísinsìnyí, tí a sì fẹ́ kí ìyè àìnípẹ̀kun tí a ti ṣèlérí tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní ọjọ́ iwájú. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Hábákúkù yọ, ó wí pé: “‘Olódodo mi yóò yè nítorí ìgbàgbọ́,’ àti pé, ‘bí ó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní ìdùnnú nínú rẹ̀.’ . . . Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti [wu Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 10:38–11:6; Hábákúkù 2:4) Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́.” (1 Tímótì 6:12) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo wá ni ẹnì kan ṣe lè nígbàgbọ́ tí kò lè yẹ̀? Láti gbé ìbéèrè yẹn yẹ̀ wò, yóò dára kí a kẹ́kọ̀ọ́ lára ọkùnrin kan tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn, tó sì jẹ́ pé títí dòní olónìí, a ṣì ń gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ gẹ̀gẹ̀ nínú ẹ̀sìn mẹ́ta pàtàkì—ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù, àti ẹ̀sìn Kristẹni. Ábúráhámù ni ọkùnrin náà. Èé ṣe tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ fi pabanbarì tó bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ a lè fara wé e lónìí?
Ṣíṣègbọràn sí Àṣẹ Ọlọ́run
3, 4. Èé ṣe tí Térà fi kó ìdílé rẹ̀ kúrò ní Úrì lọ sí Háránì?
3 Ìtàn inú Bíbélì kò tíì lọ jìnnà rárá tí a fi kọ́kọ́ mẹ́nu kan Ábúráhámù (tí a ń pè ní Ábúrámù tẹ́lẹ̀). Nínú Jẹ́nẹ́sísì 11:26, a kà pé: “Térà . . . bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì.” Ìlú Úrì ti àwọn ará Kálídíà, ìlú aláásìkí tó wà ní gúúsù Mesopotámíà, ni Térà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ ń gbé. Ṣùgbọ́n, wọn kò pẹ́ níbẹ̀. “Térà mú Ábúrámù ọmọkùnrin rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì, ọmọkùnrin Háránì, ọmọ ọmọ rẹ̀, àti Sáráì [Sárà] aya ọmọ rẹ̀, aya Ábúrámù ọmọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì bá a jáde kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà, láti lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé Háránì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:31) Náhórì, tó jẹ́ arákùnrin Ábúráhámù, àtòun àti ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ṣí lọ sí Háránì. (Jẹ́nẹ́sísì 24:10, 15; 28:1, 2; 29:4) Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Térà fi ṣí kúrò ní Úrì ìlú aláásìkí, tó wá kó lọ sí Háránì, ìlú tó jìnnà réré?
4 Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún lẹ́yìn àkókò Ábúráhámù, nígbà tí Sítéfánù, ọkùnrin olóòótọ́ náà, ń sọ̀rọ̀ níwájú Sànhẹ́dírìn ti àwọn Júù, ó ṣàlàyé ṣíṣí tí ìdílé Térà ṣí lọ lọ́nà yíyanilẹ́nu yìí. Ó wí pé: “Ọlọ́run ògo fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tí ó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì, ó sì wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’ Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì.” (Ìṣe 7:2-4) Ṣíṣí tí Térà àti ìdílé rẹ̀ ṣí lọ sí Háránì fi hàn pé ó fara mọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ fún Ábúráhámù.
5. Ibo ni Ábúráhámù lọ nígbà tí baba rẹ̀ kú? Èé ṣe?
5 Ìdílé Térà fìdí kalẹ̀ sí ìlú wọn tuntun. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Ábúráhámù sọ pé “ilẹ̀ mi,” àgbègbè Háránì ló ní lọ́kàn, kì í ṣe Úrì. (Jẹ́nẹ́sísì 24:4) Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe Háránì ni Ábúráhámù yóò máa gbé lọ títí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Sítéfánù, “lẹ́yìn tí baba [Ábúrámù] kú, Ọlọ́run mú kí ó yí ibùgbé rẹ̀ padà sí ilẹ̀ yìí tí ẹ ń gbé nísinsìnyí.” (Ìṣe 7:4) Láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà, Ábúráhámù, pẹ̀lú Lọ́ọ̀tì, sọdá Yúfírétì sí ilẹ̀ Kénáánì.a
6. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù?
6 Èé ṣe tí Jèhófà fi mú kí Ábúráhámù ṣí lọ sí Kénáánì? Ìdí rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ète tí Ọlọ́run ní fún ọkùnrin olóòótọ́ náà. Jèhófà ti wí fún Ábúráhámù pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́; èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì mú kí orúkọ rẹ di ńlá; kí ìwọ fúnra rẹ sì jẹ́ ìbùkún. Èmi yóò sì súre fún àwọn tí ń súre fún ọ, ẹni tí ó sì ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí rẹ ni èmi yóò fi gégùn-ún, gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ yóò sì bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ rẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3) Ábúráhámù yóò jẹ́ baba fún orílẹ̀-èdè ńlá kan tí yóò gbádùn ààbò Jèhófà, tí yóò sì ni ilẹ̀ Kénáánì. Ìlérí àgbàyanu mà ní ìyẹn jẹ́ o! Àmọ́, Ábúráhámù ní láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà pátápátá kí ó bàa lè jogún ilẹ̀ náà.
7. Àwọn ìyípadà wo ni Ábúráhámù ti gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe kí ó bàa lè jogún ìlérí Jèhófà?
7 Nígbà tí Ábúráhámù fi Úrì sílẹ̀, ó fi ìlú aláásìkí sílẹ̀, àfàìmọ̀ ni kò sì fi àwọn mọ̀lẹ́bí baba rẹ̀ sílẹ̀—àwọn nǹkan tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ gidigidi ní ayé ìgbàanì. Nígbà tó kúrò ní Háránì, ó kúrò ní sàkáání agboolé baba rẹ̀, títí kan ìdílé Náhórì, arákùnrin rẹ̀, ó sì ṣí lọ sí ilẹ̀ tí kò mọ̀. Nígbà tó dé Kénáánì, kò bẹ̀rẹ̀ sí wá ibi ààbò tí yóò fìdí kalẹ̀ sí nínú ìlú náà. Èé ṣe tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Kété lẹ́yìn tí Ábúráhámù dé ilẹ̀ náà, Jèhófà wí fún un pé: “Lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já ní gígùn rẹ̀ àti ní ìbú rẹ̀, nítorí pé ìwọ ni èmi yóò fi í fún.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:17) Ábúráhámù ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin àti Sárà, aya rẹ̀, ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin, tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí. “Nípa ìgbàgbọ́ ni ó ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí bí ní ilẹ̀ òkèèrè, ó sì gbé nínú àwọn àgọ́.”—Hébérù 11:9; Jẹ́nẹ́sísì 12:4.
Ìgbàgbọ́ Bí Ti Ábúráhámù Lónìí
8. Báa bá ronú nípa àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti àwọn ẹlẹ́rìí ìgbàanì mìíràn, kí ló yẹ ká ní?
8 A dárúkọ Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí [tó gbé ayé ṣáájú àwọn Kristẹni],” tí a mẹ́nu kàn nínú Hébérù orí kọkànlá. Lójú ìwòye ìgbàgbọ́ tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run yìí ní ìjímìjí ní, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ [àìní ìgbàgbọ́] tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Hébérù 12:1) Bẹ́ẹ̀ ni, àìní ìgbàgbọ́ lè “wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù àti ní ọjọ́ wa, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn ojúlówó Kristẹni láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tí ó jọ ti Ábúráhámù àti àwọn mìíràn ní ìgbàanì. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ àti àwọn Kristẹni mìíràn, ó wí pé: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—Hébérù 10:39.
9, 10. Ẹ̀rí wo ló wà pé ọ̀pọ̀ lónìí ní ìgbàgbọ́ bí ti Ábúráhámù?
9 Ká sòótọ́, ayé ti yàtọ̀ pátápátá sí ìgbà ti Ábúráhámù. Síbẹ̀síbẹ̀, “Ọlọ́run Ábúráhámù” ni àwa pẹ̀lú ń sìn, kì í sì í yí padà. (Ìṣe 3:13; Málákì 3:6) Bí Jèhófà ṣe yẹ lẹ́ni táàá jọ́sìn ní ìgbà ayé Ábúráhámù, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ lẹ́ni táàá jọ́sìn lónìí. (Ìṣípayá 4:11) Bí ti Ábúráhámù, ọ̀pọ̀ ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà, wọ́n ti ṣe àtúnṣe yòówù tó yẹ nínú ìgbésí ayé wọn kí wọn bàa lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́dún tó kọjá, 316,092 èèyàn ló fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn nípa ṣíṣe batisí nínú omi “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.”—Mátíù 28:19.
10 Àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn Kristẹni tuntun wọ̀nyí kò ní láti rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè kí wọ́n tó lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn ṣẹ. Ṣùgbọ́n o, lọ́nà tẹ̀mí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti rin ọ̀nà jíjìn. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Mauritius, àjẹ́ ni Elsie tẹ́lẹ̀. Kò sẹ́ni tí kì í bẹ̀rù obìnrin yìí. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọmọ Elsie, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún Elsie ‘láti ti inú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀.’ (Ìṣe 26:18) Nítorí ìfẹ́ tí ọmọ rẹ̀ ní sí ẹ̀kọ́ náà, Elsie gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Iwe Itan Bibeli Mi. Ìgbà mẹ́ta ni wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́sẹ̀ nítorí tí ó ń fẹ́ ìṣírí gidigidi. Iṣẹ́ awo rẹ̀ kò fún un láyọ̀ rárá, ó sì ti kó wọnú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti parí ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn náà láti inú ìjọsìn ẹ̀mí èṣù bọ́ sínú ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tí àwọn èèyàn bá wá aájò wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àlàyé tó ń ṣe fún wọn ni pé, Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè dáàbò boni lọ́wọ́ aburú. Elsie mà ti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí, àwọn mẹ́rìnlá láti inú ìdílé rẹ̀ àti ojúlùmọ̀ rẹ̀ ló mà sì ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́.
11. Àtúnṣe wo ni àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ṣe tán láti ṣe?
11 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run lọ́dún tó kọjá kò ní láti ṣe irú ìyípadà ńláǹlà bí ti obìnrin yẹn. Àmọ́ ṣá o, gbogbo wọn ló ti ipò jíjẹ́ òkú nípa tẹ̀mí bọ́ sí dídi ààyè nípa tẹ̀mí. (Éfésù 2:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì wà nínú ayé nípa ti ara, wọn kì í ṣe apá kan rẹ̀ mọ́. (Jòhánù 17:15, 16) Bí ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn tí “ẹ̀tọ́ [wọn] gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní ọ̀run,” wọ́n dà bí “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀.” (Fílípì 3:20; 1 Pétérù 2:11) Wọ́n mú ìgbésí ayé wọn bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run mu, ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ aládùúgbò wọn ló sì sún wọn ṣe é. (Mátíù 22:37-39) Wọn kò lépa àwọn góńgó ti ara, tó jẹ́ ti onímọtara-ẹni-nìkan tàbí kí wọn máa ronú pé ó yẹ káwọn náà dẹni ńlá nínú ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fọkàn wọn sí ìlérí ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí òdodo yóò máa gbé.’—2 Pétérù 3:13; 2 Kọ́ríńtì 4:18.
12. Ìgbòkègbodò wo ni a ròyìn ní ọdún tó kọjá tó fi ẹ̀rí hàn pé nígbà wíwàníhìn-ín Jésù, ó ti rí “ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé”?
12 Nígbà tí Ábúráhámù ṣí lọ sí Kénáánì, òun àti ìdílé rẹ̀ nìkan ṣoṣo gíro ló wà níbẹ̀, àfi Jèhófà nìkan tó wà pẹ̀lú wọn, tó ń pèsè fún wọn, tó sì ń dáàbò bò wọ́n. Ṣùgbọ́n, àwọn 316,092 Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìbatisí wọ̀nyí kò dá wà. Ní tòótọ́, Jèhófà ń tì wọ́n lẹ́yìn nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ń dáàbò bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún Ábúráhámù. (Òwe 18:10) Ní àfikún sí i, ó tún ń tì wọ́n lẹ́yìn nípasẹ̀ “orílẹ̀-èdè” kan tó lágbára, tó kárí ayé, tí àwọn olùgbé rẹ̀ sì pọ̀ ju ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè mìíràn nínú ayé lónìí. (Aísáyà 66:8) Lọ́dún tó kọjá, góńgó 5,888,650 àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yẹn fẹ̀rí hàn pé ìgbàgbọ́ àwọn ṣì ń ṣiṣẹ́ nípa bíbá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọ́run. (Máàkù 13:10) Wọ́n lo àkókó tó gadabú nínú iṣẹ́ yìí, àròpọ̀ wákàtí tí iye rẹ̀ jẹ́ 1,186,666,708, ni wọ́n fi wá àwọn olùfìfẹ́hàn kiri. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọ́n darí 4,302,852 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fẹ́ ní ìgbàgbọ́. Láti túbọ̀ fi ìtara wọn hàn, 698,781 nínú “orílẹ̀-èdè” yìí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, yálà ní àkókò kíkún tàbí fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún tó kọjá wà ní ojú ìwé 12 sí 15.) Àkójọ pípẹtẹrí yìí jẹ́ ìdáhùn tààrà, tó sì hàn gbangba sí ìbéèrè Jésù náà pé, “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”
Wọ́n Ṣolóòótọ́ Láìfi Àdánwò Pè
13, 14. Ṣàpèjúwe díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ dojú kọ ní Kénáánì?
13 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni nǹkan kò rọgbọ fún Ábúráhámù àti agboolé rẹ̀ ní Kénáánì. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan, ìyàn ńlá kan mú, ó sì lé e wá sí Íjíbítì láti ilẹ̀ Kénáánì. Ìyẹn nìkan kọ́, kódà ọba Íjíbítì àti ọba Gérárì (nítòsí Gásà) gbìyànjú láti gba Sárà, ìyàwó Ábúráhámù, mọ́ ọn lọ́wọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 12:10-20; 20:1-18) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni aáwọ̀ tún wà láàárín àwọn darandaran Ábúráhámù àti darandaran Lọ́ọ̀tì, èyí sì mú kí ìdílé méjèèjì pínyà. Láìro ti ara rẹ̀ nìkan, Ábúráhámù jẹ́ kí Lọ́ọ̀tì kọ́kọ́ yan ibi tó wù ú nínú ilẹ̀ náà, Lọ́ọ̀tì sì yàn láti gbé ní Àgbègbè Jọ́dánì, ibi tó dà bí Édẹ́nì, ní ti bó ṣe lọ́ràá tó àti bó ṣe lẹ́wà tó.—Jẹ́nẹ́sísì 13:5-13.
14 Lẹ́yìn èyí, Lọ́ọ̀tì fara gbá nínú ogun tí ọba Élámù tó wà lọ́nà jíjìn réré pẹ̀lú àwọn onígbèjà rẹ̀ bá àwọn ọba ìlú márùn-ún tó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Sídímù jà. Àwọn ọba ilẹ̀ òkèèrè náà ṣẹ́gun àwọn ọba àdúgbò, wọ́n kó wọn lẹ́rú, wọ́n sì kó wọn lẹ́rù, títí kan Lọ́ọ̀tì àti ohun ìní rẹ̀. Nígbà tí Ábúráhámù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó fi ìgboyà lépa àwọn ọba ilẹ̀ òkèèrè náà, ó sì gba Lọ́ọ̀tì àti agboolé rẹ̀ padà, àti ẹrù àwọn ọba àdúgbò náà. (Jẹ́nẹ́sísì 14:1-16) Àmọ́, kékeré nìyẹn lára ohun tí ojú Lọ́ọ̀tì rí nílẹ̀ Kénáánì. Fún ìdí kan, ó lọ wálé sí Sódómù, láìbìkítà nípa ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa ìwà pálapàla ìlú náà.b (2 Pétérù 2:6-8) Nígbà tí àwọn áńgẹ́lì méjì kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì pé, a óò pa ìlú náà run, ó sá kúrò ní ìlú náà tòun ti aya àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n o, aya Lọ́ọ̀tì kò ka ìtọ́ni pàtó tí àwọn áńgẹ́lì náà fún wọn sí, iyọ̀ sì bò ó látòkè délẹ̀. Fún sáà kan, Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì di ẹni tí ń gbé nínú hòrò ní Sóárì. (Jẹ́nẹ́sísì 19:1-30) Kò sí àní-àní pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yóò ti kó ìrònú bá Ábúráhámù gidigidi, ní pàtàkì, nígbà tò jẹ́ pé Lọ́ọ̀tì wá sí ilẹ̀ Kénáánì gẹ́gẹ́ bí apá kan agboolé Ábúráhámù.
15. Láìfi àwọn ìṣòro tí Ábúráhámù dojú kọ nígbà tó ń gbé nínú àgọ́ ní ilẹ̀ àjèjì pè, èrò òdì wo ló dájú pé ó yẹra fún?
15 Ǹjẹ́ Ábúráhámù ha fìgbà kan ronú pé òun àti Lọ́ọ̀tì ì bá mọ̀ kí wọ́n ti jókòó wọn jẹ́jẹ́ sí Úrì lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí baba wọn tàbí ní Háránì lọ́dọ̀ Náhórì, arákùnrin òun? Ǹjẹ́ ó fìgbà kan ronú pé òun ì bá ti fìdí kalẹ̀ sínú ìlú kan dípò tí òun fi ń gbé inú àgọ́ káàkiri? Ǹjẹ́ ó ha tilẹ̀ fìgbà kan kọminú nípa ọgbọ́n tó wà nínú fífi tó fi ara rẹ̀ rúbọ láti jẹ́ alárìnkiri ní ilẹ̀ àjèjì? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀, ó sọ pé: “Bí wọ́n bá ti ń bá a nìṣó ní tòótọ́ ní rírántí ibi tí wọ́n ti jáde lọ, àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti padà.” (Hébérù 11:15) Síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò kúkú padà sílé. Láìfi àwọn ìṣòro náà pè, ibi tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n dúró sí ni wọ́n dúró sí.
Lílo Ìfaradà Lónìí
16, 17. (a) Àwọn ìṣòro wo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni dojú kọ lónìí? (b) Ẹ̀mí rere wo ni àwọn Kristẹni ní? Èé sì ti ṣe?
16 Irú ìfaradà kan náà ni àwọn Kristẹni ń fi hàn lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sísin Ọlọ́run jẹ́ orísun ayọ̀ ńláǹlà fún wọn, ìgbésí ayé kò rọgbọ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Bí wọ́n tilẹ̀ ń gbé nínú párádísè tẹ̀mí, ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ tó ń bá àwọn aládùúgbò wọn fínra, ń bá àwọn pẹ̀lú fínra. (Aísáyà 11:6-9) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló ti fara gbọgbẹ́ nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ń bá ara wọn jagun, wọ́n tilẹ̀ pa àwọn mìíràn, àwọn kan sì ti di ẹdun arinlẹ̀ pátápátá, tí kì í sì í ṣe ẹ̀bi wọn. Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n tún fara da ìṣòro jíjẹ́ àwùjọ kéréje tí àwọn èèyàn ń fojú burúkú wò. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, wọ́n ń wàásù ìhìn rere náà láìka ẹ̀mí ìdágunlá sí. Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, àwọn “tí ń fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n” tí wọ́n sì ń “pe ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ pàápàá ní ohun burúkú” ń dọ́gbọ́n fínná mọ́ wọn. (Sáàmù 94:20, 21) Àní ní àwọn ilẹ̀ tí wọn kò ti gbógun ti àwọn Kristẹni pàápàá, tó jẹ́ pé ṣe ni àwọn èèyàn ń gbóṣùbà fún wọn nítorí ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí wọ́n ń tẹ̀ lé, wọn kò gbàgbé pé wọ́n ní láti dá yàtọ̀ láàárín àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn—ọ̀ràn tiwọn kò dà bí ti Ábúráhámù, ẹni tó jẹ́ pé inú àgọ́ ló ń gbé, tí àwọn tó yí i ká sì ń gbé nínú ìlú ńlá. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò rọrùn láti gbé nínú ayé, kí a ‘má sì jẹ́ apá kan’ rẹ̀.—Jòhánù 17:14.
17 Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ṣé à ń kábàámọ̀ ìyàsímímọ́ tí a ṣe sí Ọlọ́run ni? A ha ń ronú pé à bá kúkú ti mọ̀ ká ti jẹ́ apá kan ayé, káwa náà lè dà bí ti àwọn ojúgbà wa? A há ń jẹ̀ka àbámọ̀ nítorí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí a ti fi hàn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Àgbẹdọ̀! Kàkà tí ọkàn wa yóò fi máa fà sí ohun táa ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, a mọ̀ pé ohunkóhun yòówù tí a ti lè fi rúbọ kò níye lórí tó ìbùkún yàbùgà-yabuga tí a ń gbádùn nísinsìnyí, àti ọ̀pọ̀ tí a óò gbádùn ní ọjọ́ ọ̀la. (Lúùkù 9:62; Fílípì 3:8) Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, ṣé àwọn tó wà nínú ayé láyọ̀ ni? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló jẹ́ pé ojútùú táa ti mọ̀ ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá kiri. Wọ́n ń jìyà nítorí pé wọn kò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí àwa ń tẹ̀ lé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn ojú ìwé Bíbélì. (Sáàmù 119:105) Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì ń fẹ́ gbádùn irú ìkẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni àti ìfararora lílárinrin tí a ń gbádùn pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—Sáàmù 133:1; Kólósè 3:14.
18. Kí ló máa ń jẹ́ àbárèbábọ̀ rẹ̀ nígbà tí àwọn Kristẹni bá fi ìgboyà bí ti Ábúráhámù hàn?
18 Lóòótọ́, nígbà mìíràn, a ní láti jẹ́ onígboyà bí ti Ábúráhámù nígbà tó gbá tẹ̀ lé àwọn tó kó Lọ́ọ̀tì ní ìkógun. Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá fi ìgboyà hàn, Jèhófà máa ń bù kún iṣẹ́ ọwọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Northern Ireland, rúkèrúdò tí àwọn ẹlẹ́sìn dá sílẹ̀ ti fa ìkórìíra tó pọ̀ débi gẹ́ẹ́, ó sì gba ìgboyà gidigidi láti wà láìdá sí tọ̀tún tòsí. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni olóòótọ́ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó sọ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” (Jóṣúà 1:9; Sáàmù 27:14) Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, ìwà àìṣojo wọn tí sọ wọ́n di ẹni tí à ń bọ̀wọ̀ fún láwùjọ, lónìí, wọ́n lè wàásù fàlàlà ní gbogbo ìlú tó wà ní ilẹ̀ náà.
19. Ibo ni àwọn Kristẹni láyọ̀ láti wà, kí ni wọ́n sì ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé retí pé yóò jẹ́ àbárèbábọ̀ rẹ̀ bí wọ́n bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà?
19 Kò yẹ kí a ṣiyèméjì rárá pé ipòkípò táa lè wà, báa bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, àbárèbábọ̀ rẹ̀ yóò mú ògo wá fún un, yóò sì ṣe wá láǹfààní pípẹ́ títí. Láìfi àwọn ìṣòro tí a ti dojú kọ àti ìrúbọ tí a ti ṣe pè, kò sí ibòmíràn táa tún lè wà tó sàn ju inú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kò sí ibòmíràn tó lè tù wá lára tó ibi táa ti ń gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa, tí a sì ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọ̀nà fún ọjọ́ ọ̀la ayérayé tí Ọlọ́run ti ṣèlérí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ábúráhámù gba Lọ́ọ̀tì, ọmọ àbúrò rẹ̀ ṣọmọ, nígbà tí baba Lọ́ọ̀tì, tó jẹ́ arákùnrin Ábúráhámù, kú.—Jẹ́nẹ́sísì 11:27, 28; 12:5.
b Àwọn kan sọ pé kíkó tí àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà kó Lọ́ọ̀tì ní ìkógun ló jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sì gbé inú ìlú, kí ọkàn rẹ̀ lè balẹ̀.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èé ṣe tí ìgbàgbọ́ lílágbára fi ṣe pàtàkì?
◻ Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó lágbára?
◻ Báwo ni ìyípadà nínú ìgbésí ayé ẹni ṣe ń bá ìyàsímímọ́ rìn?
◻ Èé ṣe tí a fi ń láyọ̀ láti sin Ọlọ́run láìfi ìṣòro èyíkéyìí tí a lè dojú kọ pè?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ábúráhámù ṣe tán láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà pátápátá kó bàa lè jogún ìlérí náà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù ti rí “ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé” nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀