Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MARCH 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 22-23
“Ọlọ́run Dán Ábúráhámù Wò”
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Sọ Pé Kí Ábúráhámù Fi Ọmọ Rẹ̀ Rúbọ?
Wo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ábúráhámù, ó ní: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì rìnnà àjò lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:2) Kíyè sí i pé Jèhófà sọ pé Ísákì jẹ́ ọmọkùnrin tí Ábúráhámù “nífẹ̀ẹ́ gidigidi.” Jèhófà mọ̀ pé Ábúráhámù fẹ́ràn Ísákì bí ẹyinjú rẹ̀. Bákan náà, Ọlọ́run mọ bí ọ̀rọ̀ Jésù Ọmọ òun ṣe rí lára òun náà. Jèhófà fẹ́ràn Jésù gan-an débi pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ̀rọ̀ látọ̀run, tó dìídì pe Jésù ní “Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—Máàkù 1:11; 9:7.
Tún kíyè sí i pé Jèhófà lo gbólóhùn náà “jọ̀wọ́,” nígbà tó sọ fún Ábúráhámù pé kó ṣe ìrúbọ náà. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ìdí tí Ọlọ́run fi lo gbólóhùn náà ni pé “OLÚWA mọ̀ pé àdánù ńlá ló máa jẹ́ fún un tó bá fi ọmọ náà rúbọ.” Bí a bá sì fojú inú wò ó, a ó rí i pé yóò dun Ábúráhámù gan-an nígbà tí Ọlọ́run ní kó fi ọmọ rẹ̀ yẹn rúbọ. Èyí jẹ́ ká ní òye díẹ̀ nípa bó ṣe jẹ́ ìrora tó lékenkà fún Jèhófà nígbà tó ń wo Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n bó ṣe ń jìyà títí tó fi kú. Ó dájú pé ìyẹn ló máa jẹ́ ohun tó tíì dun Jèhófà jù, kò sì ní sí ohun míì tó tún máa dùn ún bẹ́ẹ̀ mọ́ láé.
Nítorí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara wa lè bù mọ́ aṣọ tá a bá ronú nípa ohun tí Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe, ó bọ́gbọ́n mu ká máa rántí pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jèhófà kò jẹ́ kí Ábúráhámù, ọkùnrin olóòótọ́ yẹn, fi ọmọ náà rúbọ. Kò jẹ́ kí àdánù tó le jù fún òbí bá Ábúráhámù, ó gba Ísákì sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Àmọ́, Jèhófà “kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n . . . ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa.” (Róòmù 8:32) Kí nìdí tí Jèhófà fi kó ara rẹ̀ sí ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà bẹ́ẹ̀? Torí kí “a lè jèrè ìyè” ló fi ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Jòhánù 4:9) Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa gidigidi! Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa ṣe ohun tó máa fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀?
Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Kí O sì Jàǹfààní Nínú Àwọn Ìlérí Tó Fi Ìbúra Ṣe
6 Jèhófà pẹ̀lú búra kí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ lè gba àwọn ìlérí tó ṣe gbọ́. Ó lo gbólóhùn bíi, “ ‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” (Ìsík. 17:16) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ju ogójì ìgbà lọ tí Jèhófà Ọlọ́run búra. Bóyá àpẹẹrẹ tá a mọ̀ jù lọ lèyí tó wáyé nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Jèhófà ti bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú bíi mélòó kan, èyí tó jẹ́ pé tá a bá pa gbogbo wọn pọ̀, ńṣe ló fi hàn pé irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà máa wá látọ̀dọ̀ Ábúráhámù nípasẹ̀ Ísákì ọmọ rẹ̀. (Jẹ́n. 12:1-3, 7; 13:14-17; 15:5, 18; 21:12) Lẹ́yìn náà, Jèhófà dán Ábúráhámù wò lọ́nà tó lágbára gan-an, ó pàṣẹ fún un pé kí ó fi ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ. Láìjáfara, Ábúráhámù ṣègbọràn sí Ọlọ́run, àmọ́ bó ṣe kù díẹ̀ kó fi Ísákì rúbọ báyìí ni áńgẹ́lì Ọlọ́run dá a dúró. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wá búra pé: “Mo fi ara mi búra . . . pé nítorí òtítọ́ náà pé o ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì fawọ́ ọmọkùnrin rẹ sẹ́yìn, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, èmi yóò bù kún ọ dájúdájú, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun; irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnubodè àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”—Jẹ́n. 22:1-3, 9-12, 15-18.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Jèhófà Pè É Ní “Ọ̀rẹ́ Mi”
13 Nígbà tí Ábúráhámù sún mọ́ ibi tó ti fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró síhìn-ín ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ṣùgbọ́n èmi àti ọmọdékùnrin náà fẹ́ tẹ̀ síwájú lọ sí ọ̀hún yẹn láti jọ́sìn kí a sì padà wá bá yín.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:5) Kí ni Ábúráhámù ní lọ́kàn? Ṣé irọ́ ló ń pa nígbà tó sọ pé òun àti Ísákì á pa dà wá, nígbà tó mọ̀ pé òun máa fi rúbọ? Rárá. Bíbélì sọ pé Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà lè jí Ísákì dìde tó bá tiẹ̀ kú. (Ka Hébérù 11:19.) Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà ló jẹ́ kí òun àti Sárà bímọ lọ́jọ́ ogbó àwọn. (Hébérù 11:11, 12, 18) Torí náà, ó mọ̀ pé kò sí ohun tí Jèhófà ò lè ṣe. Ábúráhámù ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ó nígbàgbọ́ pé bí ọmọ òun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí i dìde kí gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe lè nímùúṣẹ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”
it-1 853 ¶5-6
Mímọ ọjọ́ ọ̀la
Yíyàn láti mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ṣáájú. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí kádàrá. Tí Ọlọ́run bá lo agbára tó ní láti mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó máa ń bá ìlànà òdodo rẹ̀ mu, ó sì máa ń ṣe rẹ́gí pẹ̀lú irú ẹni tí Bíbélì fi hàn pé ó jẹ́. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ò kádàrá àwa èèyàn. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run máa ṣàyẹ̀wò ohun tó ń ṣẹlẹ̀, á sì fìyẹn pinnu ìgbésẹ̀ tó máa gbé.
Bí àpẹẹrẹ, ní Jẹ́nẹ́sísì 11:5-8, Bíbélì sọ pé nígbà tí Ọlọ́run wo ayé, ó kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Bábélì. Ó wá pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ kó lè dá iṣẹ́ àwọn èèyàn burúkú náà dúró. Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn tí ìwà ibi gbilẹ̀ ní Sódómù àti Gòmórà, Jèhófà tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì sọ ohun tó pinnu láti ṣe ní ìlú náà fún Ábúráhámù. Ó sọ pé: “Èmi yóò lọ wò ó bóyá ohun tí mò ń gbọ́ nípa wọn náà ni wọ́n ń ṣe. Tí kò bá sì rí bẹ́ẹ̀, màá lè mọ̀.” (Jẹ 18:20-22; 19:1) Bákan náà, Ọlọ́run sọ pé òun ‘ti wá mọ̀ Ábúráhámù.’ Lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi Ísákì rúbọ, Jèhófà sọ pé, “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, torí o ò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní.”—Jẹ 18:19; 22:11, 12; fi wé Ne 9:7, 8; Ga 4:9.
Bíbélì Kíkà
it-1 604 ¶5
Kà sí Olódodo
Kí ló mú kí Ọlọ́run ka Ábúráhámù sí olódodo kí Jésù tó san ìràpadà? Bákan náà, torí ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní àti iṣẹ́ tó fi tì i lẹ́yìn, Ọlọ́run “kà á sí òdodo fún un.” (Ro 4:20-22) Èyí ò túmọ̀ sí pé ẹni pípé tí kò dẹ́ṣẹ̀ kankan ni Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó wà ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run kà wọ́n sí olódodo torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀ nípa “ọmọ” kan, wọ́n sì ń sapá láti máa tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀. Èyí mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn aláìṣòdodo tí kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jẹ 3:15; Sm 119:2, 3) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní mú kó kà wọ́n sí aláìlẹ́bi torí pé wọ́n ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn tó jìnnà sí Ọlọ́run. (Sm 32:1, 2; Ef 2:12) Torí náà, Ọlọ́run bù kún àwọn ọkùnrin yìí torí pé wọ́n nígbàgbọ́ bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ṣe bẹ́ẹ̀ láìtẹ ìlànà òdodo rẹ̀ lójú. (Sm 36:10) Bákan náà àwọn èèyàn yìí gbà pé àwọn nílò ìràpadà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa pèsè ìràpadà náà.—Sm 49:7-9; Heb 9:26.
MARCH 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 24
“Bí Ísákì Ṣe Rí Ìyàwó”
“Mo Múra Tán Láti Lọ”
Ábúráhámù mú kí Élíésérì búra fún òun pé kò ní fẹ́yàwó fún Ísákì láàárín àwọn ọmọbìnrin Kénáánì. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ọmọ Kénáánì kò jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run, wọn ò sì ka Jèhófà sí. Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà máa tó fìyà jẹ àwọn èèyàn yẹn torí ìwà ibi tó kún ọwọ́ wọn. Torí náà, Ábúráhámù kò fẹ́ kí Ísákì ọmọ rẹ̀ ní àjọṣe kankan pẹ̀lú wọn. Ó tún mọ̀ pé ọmọ òun máa kópa pàtàkì láti mú kí ohun tí Ọlọ́run ti pinnu ní ìmúṣẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 15:16; 17:19; 24:2-4.
“Mo Múra Tán Láti Lọ”
Élíésérì wá sọ fún àwọn tó gbà á lálejò pé òun gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run nígbà tí òun dé ibi kànga tó wà létí ìlú Háránì. Ó bẹ Jèhófà pé kó bá òun yan ọmọbìnrin fún Ísákì láti fi ṣaya. Lọ́nà wo? Élíésérì bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí ọmọbìnrin tó fẹ́ kí Ísákì fẹ́ wá síbi kànga náà. Tí òun bá sì ní kó fún òun lómi, kí ọmọbìnrin náà gbà láti fún òun, kó sì tún fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti fún àwọn ràkúnmí òun lómi pẹ̀lú. (Jẹ́nẹ́sísì 24:12-14) Ta sì lẹ́ni tó wá tó sì ṣe àwọn nǹkan yìí? Rèbékà ni! O lè fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Rèbékà tó bá fetí kọ́ ohun tí Élíésérì ń sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀!
wp16.3 14 ¶6-7
“Mo Múra Tán Láti Lọ”
Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú àkókò yìí, Élíésérì ti béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé: “Bí obìnrin náà kò bá ní bá mi wá ńkọ́?” Ábúráhámù dáhùn pé: ‘Ìwọ yóò bọ́ lọ́wọ́ ìbúra tó o ṣe fún mi.’ (Jẹ́nẹ́sísì 24:39, 41) Nílé Bẹ́túélì pàápàá, wọ́n ka èrò ọmọbìnrin náà sí pàtàkì. Inú Élíésérì dùn gan-an pé ohun tí òun bá wá yọrí sí rere, torí náà ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, ó béèrè bóyá òun lè máa mú Rèbékà lọ sí ìlú Kénáánì lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí ṣì fẹ́ kí Rèbékà dúró fún ọjọ́ mẹ́wàá sí i. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n pinnu láti pe ọ̀dọ́bìnrin náà, kí wọ́n sì wádìí lẹ́nu rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:57.
Ọ̀rọ̀ náà wá dà bíi ti àlejò tó dé oríta mẹ́ta tí kò mọ ibi tó máa yà sí fún Rèbékà. Kí ló máa sọ? Ṣé ó máa dọ́gbọ́n yẹ ìrìn àjò náà sílẹ̀ torí ó kíyè sí i pé bàbá òun àti ẹ̀gbọ́n òun kò tíì fẹ́ kí òun lọ? Àbí ó wò ó bí àǹfààní láti kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí Jèhófà lọ́wọ́ sí? Èsì tó fún wọn jẹ́ ká mọ bí àyípadà òjijì yìí ṣe rí lára rẹ̀. Ohun tó sọ ni pé: “Mo múra tán láti lọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:58.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Mo Múra Tán Láti Lọ”
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn tó ti pọn omi kún korobá rẹ̀ tán, bàbá àgbàlagbà kan wá bá a. Bàbá náà sọ pé: “Jọ̀wọ́ fún mi ní òfèrè omi díẹ̀ láti inú ìṣà omi rẹ.” Ohun tí bàbá náà béèrè kò pọ̀ jù, ó sì béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Rèbékà rí i pé bàbá náà ti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn. Kíá ló gbé korobá omi náà sọ̀ kalẹ̀ léjìká, ó sì fún bàbá náà ní omi tútù débi tí bàbá náà fi mu ún tẹ́rùn. Rèbékà kíyè sí i pé, kò sí omi nínú ọpọ́n ìmumi tí àwọn ràkúnmí mẹ́wàá tí bàbá náà kó wá lè mu. Àánú ṣe é bó ṣe rí i tí bàbá náà ń wo òun, ó sì wù ú láti ṣoore fún bàbá náà. Torí náà, ó sọ pé: “Àwọn ràkúnmí rẹ ni èmi yóò tún fa omi fún títí tí wọn yóò fi mu tẹ́rùn.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:17-19.
Wàá rí i pé kì í ṣe pé Rèbékà kàn fẹ́ fún àwọn ràkúnmí náà lómi mu nìkan, àmọ́ ó máa fún wọn títí wọn yóò fi mu ún tẹ́rùn. Tí òùngbẹ bá gbẹ ràkúnmí dáadáa, ẹyọ kan lè mú tó gálọ̀nù omi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ ṣe gbẹ àwọn ràkúnmí mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà, á jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá ni Rèbékà fẹ́ ṣe. Àmọ́, ó jọ pé òùngbẹ kò fi bẹ́ẹ̀ gbẹ àwọn ràkúnmí náà lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́ ṣé Rèbékà mọ̀ bẹ́ẹ̀ kó tó sọ pé òun máa fún wọn lómi? Rárá o. Ńṣe ló wù ú látọkànwá pé kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti ṣaájò bàbá àgbàlagbà náà. Bàbá náà gbà pé kó fún wọn lómi. Ó sì ń wo Rèbékà bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀, tó ń pọn omi, tó sì ń dà á sínú ọpọ́n ìmumi náà.—Jẹ́nẹ́sísì 24:20, 21.
wp16.3 13, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé
“Mo Múra Tán Láti Lọ”
Ó ti di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Ìtàn náà kò sì sọ pé Rèbékà wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Kò sì jọ pé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sùn kó tó délé tàbí pé ẹnì kan wá wò ó kó lè mọ ohun tó fà á tó fi pẹ́.
“Mo Múra Tán Láti Lọ”
Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọjọ́ tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wọlé dé wẹ́rẹ́. Ilẹ̀ sì ti ń ṣú nígbà tí wọ́n fi máa dé ilẹ̀ Négébù, Rèbékà sì tajú kán rí ọkùnrin kan tó ń rìn lórí pápá. Ó jọ pé ńṣe ni ọkùnrin náà ń ronú. Bíbélì sọ nípa Rèbékà pé: “Ó sì tọ sílẹ̀ láti orí ràkúnmí.” Kò tiẹ̀ dúró kí ràkúnmí náà bẹ̀rẹ̀ tó fi bọ́ sílẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ bàbá náà pé: “Ta ni ọkùnrin yẹn tí ó wà lọ́hùn-ún, tí ń rìn nínú pápá láti pàdé wa?” Nígbà tó gbọ́ pé Ísákì ni, ńṣe ló daṣọ borí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 24:62-65) Kí nìdí? Kò sí àní-àní pé ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ẹni tó máa di ọkọ rẹ̀. Àwọn kan lè gbà pé irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ kò bóde mu mọ́. Àmọ́, tọkùnrin tobìnrin wa ló yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Rèbékà yìí, àbí èwo nínú wa ni kò nílò irú ìwà àtàtà yìí?
Bíbélì Kíkà
MARCH 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 25-26
“Ísọ̀ Ta Ogún Ìbí Rẹ̀”
it-1 1242
Jékọ́bù
Jékọ́bù yàtọ̀ sí Ísọ̀ tó jẹ́ ààyò bàbá rẹ̀. Ògbójú ọdẹ tí kì í fara balẹ̀ ni Ísọ̀, àmọ́ Bíbélì sọ pé Jékọ́bù jẹ́ ‘aláìlẹ́bi [ìyẹn tam lédè Hébérù] inú àgọ́ ló sì máa ń wà.’ Èèyàn jẹ́jẹ́ ni, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló ń ṣe, òun ló ń bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ilé torí pé ó ṣeé fọkàn tán, èyí sì mú kí ìyá rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jẹ 25:27, 28) Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà tam tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó rójú rere Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, “àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ máa ń kórìíra ẹni tó bá jẹ́ aláìlẹ́bi,” síbẹ̀ Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé “àlàáfíà ń dúró de [aláìlẹ́bi] ní ọjọ́ ọ̀la.” (Owe 29:10; Sm 37:37) Bíbélì tún sọ nípa Jóòbù tó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ pe “aláìlẹ́bi [ìyẹn tam lédè Hébérù] àti adúróṣinṣin èèyàn ni.”—Job 1:1, 8; 2:3.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?
11 Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan wà nínú Bíbélì tí wọ́n ya aláìmoore. Àpẹẹrẹ kan ni Ísọ̀, ilé ire ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, olùjọsìn Jèhófà sì làwọn òbí rẹ̀, àmọ́ kò mọyì nǹkan tẹ̀mí rárá. (Ka Hébérù 12:16.) Kí ló ṣe tó fi hàn pé kò moore àti pé kò mọyì nǹkan tẹ̀mí? Ó ta ogún ìbí rẹ̀ fún Jékọ́bù arákùnrin rẹ̀ nítorí abọ́ ọbẹ̀ kan ṣoṣo. (Jẹ́n. 25:30-34) Nígbà tó yá, ó ti ìka àbámọ̀ bọnú. Àmọ́ ìyẹn ti bọ́ sórí, ẹ̀pa ò sì bóró mọ́. Torí náà, kò yẹ kó bínú pé wọn ò fún òun ní ìbùkún tó tọ́ sí àkọ́bí.
it-1 835
Àkọ́bí
Ọjọ́ pẹ́ tí ọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí ti máa ń ní àǹfààní tó pọ̀ nínú ìdílé. Òun ló máa di olórí ìdílé tí bàbá wọn bá kú. Tí wọ́n bá sì ń pín ogún, ìlọ́po méjì ohun tó tọ́ sí àwọn ọmọ yòókù ni àkọ́bí náà máa gbà. (Di 21:17) Rúbẹ́nì ló jókòó sí ipò àkọ́bí nígbà tí àwọn ọmọ Jékọ́bù ń jẹun pẹ̀lú Jósẹ́fù ní Íjíbítì. (Jẹ 43:33) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Bíbélì máa ń to àwọn ọmọ bí wọ́n ṣe dàgbà sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó bá yọrí ọlá tàbí tó jẹ́ olóòótọ́ ló máa ń wà nípò àkọ́kọ́ dípò ẹni tó jẹ́ àkọ́bí.—Jẹ 6:10; 1Kr 1:28; fi wé Jẹ 11:26, 32; 12:4; tún wo OGÚN ÌBÍ; OGÚN.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ẹ jẹ́ ká wá pa dà sínú Hébérù 12:16 tó sọ pé kí ó má ṣe “sí àgbèrè kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀, bí Ísọ̀, ẹni tí ó fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tọrẹ ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.” Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ gan-an?
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ìlà ìdílé Mèsáyà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń jíròrò nínú ẹsẹ yìí. Nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú, ó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ‘ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ wọn,’ kí wọ́n sì sá fún àgbèrè kí wọ́n má bàa di ẹni “tí a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run dù.” (Héb. 12:12-16) Tí wọ́n bá ṣe àgbèrè, ọ̀rọ̀ wọn ò ní yàtọ̀ sí ti Ísọ̀ tí kò “mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀,” tó jẹ́ pé àwọn nǹkan tara ló jẹ ẹ́ lógún.
Ísọ̀ gbé ayé lásìkò àwọn baba ńlá tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, torí náà ó ṣeé ṣe kóun náà láǹfààní láti rú àwọn ẹbọ kan. (Jẹ́n. 8:20, 21; 12:7, 8; Jóòbù 1:4, 5) Àmọ́ torí pé Ísọ̀ kì í ṣe ẹni tẹ̀mí, ó sọ ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí nù torí abọ́ ọbẹ̀ kan ṣoṣo. Bóyá ohun tó sì mú kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kò fẹ́ ní ìpín nínú ìyà tí Ọlọ́run sọ pé àwọn ọmọ Ábúráhámù máa jẹ. (Jẹ́n. 15:13) Yàtọ̀ síyẹn, Ísọ̀ tún fi hàn pé òun ò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀ bó ṣe lọ fẹ́ àwọn obìnrin méjì tí kì í ṣe olùjọ́sìn Ọlọ́run, èyí sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn òbí rẹ̀ gan-an. (Jẹ́n. 26:34, 35) Ti Jékọ́bù ò rí bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀, torí pé olùjọ́sìn Jèhófà ló fẹ́.—Jẹ́n. 28:6, 7; 29:10-12, 18.
it-2 245 ¶6
Irọ́
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì dẹ́bi fún irọ́ pípa, síbẹ̀ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó di dandan kéèyàn sọ òótọ́ fún àwọn tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ ohun náà. Jésù Kristi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe fún àwọn ajá ní ohun tó jẹ́ mímọ́, ẹ má sì sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, kí wọ́n má bàa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kí wọ́n wá yíjú pa dà, kí wọ́n sì fà yín ya.” (Mt 7:6) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé láwọn ìgbà kan, Jésù náà ò sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tán nígbà táwọn kan bi í ní ìbéèrè, torí ó mọ̀ pé tí òun bá sọ òótọ́ fún wọn, èyí lè fa ìpalára. (Mt 15:1-6; 21:23-27; Jo 7:3-10) Ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ni Ábúráhámù, Ísákì, Ráhábù àti Èlíṣà ṣe nígbà tí wọn fi òótọ́ ọ̀rọ̀ pa mọ́ fún àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà.—Jẹ 12:10-19; orí 20; 26:1-10; Joṣ 2:1-6; Jem 2:25; 2Ọb 6:11-23.
Bíbélì Kíkà
MARCH 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 27-28
“Jékọ́bù Gba Ìbùkún Tó Tọ́ Sí I”
Rèbékà—Akíkanjú Obìnrin Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run
Bíbélì ò sọ bóyá Ísákì mọ̀ pé Ísọ̀ yóò ṣe ìránṣẹ́ fún Jékọ́bù. Bó ti wù kó rí, Rèbékà àti Jékọ́bù mọ̀ pé Jékọ́bù ni yóò gba ìbùkún náà. Nígbà tí Rèbékà gbọ́ pé Ísákì fẹ́ súre fún Ísọ̀ tó bá ti gbé oúnjẹ ẹran ìgbẹ́ lọ fún bàbá rẹ̀, kíá ló káràmáásìkí ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀mí ṣíṣe nǹkan ní kánmọ́ àti ẹ̀mí ìtara tó ní nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ ṣì wà lára rẹ̀. Ó ‘pàṣẹ’ fún Jékọ́bù pé kó lọ mú ọmọ ewúrẹ́ méjì wá fóun. Ó fẹ́ fi se oúnjẹ tí ọkọ rẹ̀ fẹ́ràn gan-an. Jékọ́bù gbọ́dọ̀ dọ́gbọ́n ṣe bíi pé òun ni Ísọ̀ láti lè rí ìbùkún náà gbà. Àmọ́, Jékọ́bù sọ pé òun kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó di dandan kí àṣírí ìwà arúmọjẹ yìí tú sí bàbá rẹ̀ lọ́wọ́, yóò sì fi í ré! Rèbékà sọ pé àfi dandan kó ṣe ohun tóun sọ. Ó ní, “orí mi ni kí ìfiré tí ó wà fún ọ wá, ọmọkùnrin mi.” Ó wá se oúnjẹ náà, ó sì dọ́gbọ́n kan tí ara Jékọ́bù fi dà bíi ti Ísọ̀, ó wá ní kó lọ bá ọkọ òun.—Jẹ́nẹ́sísì 27:1-17.
Wọn ò sọ ìdí tí Rèbékà fi hùwà lọ́nà yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé ohun tó ṣe yẹn kò dára, ṣùgbọ́n Bíbélì ò sọ bẹ́ẹ̀, àní Ísákì pàápàá kò sọ pé ohun tó ṣe burú lẹ́yìn tó mọ̀ pé Jékọ́bù ti gba ìbùkún náà. Dípò ìyẹn ńṣe ni Ísákì tún fi kún ìbùkún náà. (Jẹ́nẹ́sísì 27:29; 28:3, 4) Rèbékà mọ ohun tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọmọ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe nǹkan kan láti lè rí i dájú pé Jékọ́bù ló gbà ìbùkún náà, torí pé òun ló tọ́ sí. Ó ṣe kedere pé èyí bá ìfẹ́ Jèhófà mu.—Róòmù 9:6-13.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú kí Rèbékà àti Jékọ́bù ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí, síbẹ̀ ó jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ yìí ṣàdédé wáyé ni láìjẹ́ pé wọ́n ti jọ rò ó tẹ́lẹ̀. Ó yẹ ká mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ pé ohun tí Rèbékà àti Jékọ́bù ṣe yìí dára tàbí ó burú. Nítorí náà, èèyàn ò lè tìtorí ohun tí wọ́n ṣe yìí sọ pé irọ́ pípa àti ẹ̀tàn dára. Àmọ́ Bíbélì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà yé wa yékéyéké.
Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ìtàn yẹn jẹ́ ká rí i kedere pé Jékọ́bù lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìre lẹ́nu bàbá rẹ̀, àmọ́ Ísọ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jékọ́bù ti fi ẹ̀tọ́ ra ipò àkọ́bí lọ́wọ́ ẹní tí wọ́n jọ jẹ́ ìbejì, ìyẹn Ísọ̀ tí kò mọrírì ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tó sì tà á nítorí oúnjẹ nígbà tébi ń pa á. Ísọ̀ “tẹ́ńbẹ́lú ogún ìbí náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:29-34) Nítorí náà, nígbà tí Jékọ́bù lọ bá bàbá rẹ̀, ńṣe ló fẹ́ gba ìre tó tọ́ sí i.
it-1 341 ¶6
Ìbùkún
Láyé àtijọ́, àwọn bàbá sábà máa ń bù kún àwọn ọmọkùnrin wọn kí wọ́n tó kú. Èyí ṣe pàtàkì gan-an nígbà yẹn, àwọn èèyàn ò sì fojú kéré ẹ̀ rárá. Ìdí nìyẹn tí Ísákì fi bù kún Jékọ́bù torí ó rò pé Ísọ̀ ní. Ísákì sọ pé Jékọ́bù máa yọrí ọlá ju Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì bẹ Jèhófà pé kó mú ìlérí náà ṣẹ, ó ṣe tán Ísákì ò ríran mọ́, ó sì ti darúgbó nígbà yẹn. (Jẹ 27:1-4, 23-29; 28:1, 6; Heb 11:20; 12:16, 17) Nígbà tó yá, Ísákì mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì fi kún ìbùkún Jékọ́bù. (Jẹ 28:1-4) Kí Jékọ́bù náà tó kú, ó kọ́kọ́ bù kún àwọn ọmọkùnrin méjì tí Jósẹ́fù bí, lẹ́yìn náà ó wá bù kún àwọn ọmọ tiẹ̀. (Jẹ 48:9, 20; 49:1-28; Heb 11:21) Bákan náà, kí Mósè tó kú ó bù kún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Di 33:1) Ṣe làwọn ìbùkún tá a mẹ́nu kàn yìí jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ torí pé gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó ń bù kún èèyàn máa ń gbé ọwọ́ lé orí ẹni tí wọ́n ń bù kún.—Jẹ 48:13, 14.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Máa Lọ Déédéé Láàárín Tọkọtaya
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Ísákì àti Rèbékà máa ń yéra wọn? Lẹ́yìn tí Ísọ̀ ọmọ wọn lọ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Hétì méjì, ìṣòro ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ nínú ìdílé wọn. Rèbékà “ń wí ṣáá fún” Ísákì pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì. Bí Jékọ́bù [tó jẹ́ àbúrò] bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì . . . , ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?” (Jẹ́nẹ́sísì 26:34; 27:46) Kò sí àní-àní pé, bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ gan-an ló sọ fún ọkọ rẹ̀.
Ísákì baba wọn sọ fún Jákọ́bù tí òun pẹ̀lú Ísọ̀ jọ jẹ́ ìbejì pé kò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 28:1, 2) Èyí fi hàn pé ọ̀rọ̀ Rèbékà yé Ísákì. Àwọn méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ yìí, wọ́n sì gbọ́ ara wọn yé, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lónìí. Àmọ́ o, tí èdèkòyédè bá wà láàárín tọkọtaya ńkọ́? Kí ni wọ́n lè ṣe?
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kejì
28:12, 13—Kí ni ìjẹ́pàtàkì àlá tí Jékọ́bù lá nípa “àkàsọ̀ kan”? “Àkàsọ̀” yìí tó ṣeé ṣe kó rí bí àtẹ̀gùn òkúta fi hàn pé àwọn tó ń bẹ lọ́run àtàwọn tí ń bẹ láyé máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Báwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣe ń gòkè tí wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn yìí fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń jíṣẹ́ láwọn ọ̀nà pàtàkì kan láàárín Jèhófà àtàwọn èèyàn tínú rẹ̀ dùn sí.—Jòhánù 1:51.
Bíbélì Kíkà
MARCH 30–APRIL 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 29-30
“Jékọ́bù Fẹ́ Ìyàwó”
Jékọ́bù Mọyì Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
Kíá ló ti wọnú àdéhùn ìgbéyàwó nípa sísan owó orí ìyàwó fún ìdílé ìyàwó. Lẹ́yìn-ò-rẹyìn ni Òfin Mósè wá sọ pé àádọ́ta ṣékélì owó fàdákà la ó máa san lórí wúńdíá tí a bá ti fi ẹ̀tàn bá lòpọ̀. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Scholar Gordon Wenham gbà pé èyí ni “owó orí ìyàwó tó pọ̀ jù lọ” nítorí ọ̀pọ̀ ló “kéré sí èyí.” (Diutarónómì 22:28, 29) Jékọ́bù ò lè san irú owó bẹ́ẹ̀. Ó yáa gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje. Wenham ń báa lọ pé: “Níwọ̀n ìgbà to jẹ́ pé ní Bábílónì àtijọ́, òṣìṣẹ́ kàn kì í gbà ju ààbọ̀ ṣékélì sí ṣékélì kan lọ lóṣù (tá a bá ṣírò ìyẹn lọ́dún méje, yóò wà láàárín ṣékélì méjìlélógójì sí ṣékélì mẹ́rìnlélọ́gọ́rin) a jẹ́ pe owó orí tó pọ̀ ni Jékọ́bù fẹ́ san kó bàa lè fẹ́ Réṣẹ́lì.” Kíá ni Lábánì gbà láì janpata.—Jẹ́nẹ́sísì 29:19.
Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
Ṣé Léà àti bàbá rẹ̀ jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti tan Jékọ́bù jẹ ni? Àbí ńṣe ló di dandan kí Léà ṣègbọràn sí bàbá rẹ̀? Ibo ni Réṣẹ́lì wà lákòókò yẹn? Ǹjẹ́ ó mọ ohun tó ń lọ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀? Ṣé apàṣẹwàá ni bàbá rẹ̀ tó fi jẹ́ pé ohun tó bá sọ pé kó ṣe ló gbọ́dọ̀ ṣe? Bíbélì ò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ohun yòówù kí Réṣẹ́lì àti Léà rò nípa ọ̀ràn náà, ohun tá a mọ̀ ni pé ọ̀rọ̀ náà bí Jékọ́bù nínú gan-an. Jékọ́bù ò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí, Lábánì ló lọ bá tó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kì í ha ṣe nítorí Réṣẹ́lì ni mo fi sìn ọ́? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi ṣe àgálámàṣà sí mi?” Báwo ni Lábánì ṣe dá a lóhùn? O ní: “Kì í ṣe àṣà . . . láti fi obìnrin tí ó jẹ́ àbúrò fúnni ṣáájú àkọ́bí. Ṣe ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ obìnrin yìí pé. Lẹ́yìn ìyẹn, a ó sì fi obìnrin kejì yìí fún ọ pẹ̀lú fún iṣẹ́ ìsìn tí ìwọ bá lè ṣe fún mi fún ọdún méje sí i.” (Jẹ́nẹ́sísì 29:25-27) Bí wọ́n ṣe jẹ́ kí Jékọ́bù di oníyàwó méjì nìyẹn, èyí sì fa owú burúkú.
it-2 341 ¶3
Ìgbéyàwó
Ayẹyẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ètò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà ìgbéyàwó, síbẹ̀ ohun ayọ̀ ni ìgbéyàwó jẹ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ ìgbéyàwó, ìyàwó máa ń ṣe onírúurú nǹkan láti múra sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, á wẹ̀, á sì fi òróró olóòórùn dídùn para. (Fi wé Rut 3:3; Isk 23:40.) Nígbà míì, àwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ obìnrin máa ń múra fún ìyàwó, wọ́n á sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ọ̀já ìgbàyà àti aṣọ funfun tí a hun dáadáa bí obìnrin náà bá ṣe lówó tó. (Jer 2:32; Ifi 19:7, 8; Sm 45:13, 14) Ó máa ń lo onírúurú ohun ọ̀ṣọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó (Ais 49:18; 61:10; Ifi 21:2), á sì fi aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó gùn láti orí dé ẹsẹ̀ bó ara rẹ̀. (Ais 3:19, 23) Èyí jẹ́ ká rí ìdí tó fi rọrùn fún Lábánì láti tan Jékọ́bù, tó fi fún un ní Líà dípò Réṣẹ́lì. (Jẹ 29:23, 25) Rèbékà fi ìborùn bo orí rẹ̀ nígbà tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ Ísákì. (Jẹ 24:65) Bó ṣe borí jẹ́ àmì pé ó tẹrí ba fún ipò orí ọkọ́ rẹ̀.—1Kọ 11:5, 10.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 50
Ìsọdọmọ
Réṣẹ́lì àti Líà ka ọmọ táwọn ìránṣẹ́ wọn bí fún Jékọ́bù sí ọmọ tí a bí ‘lórí orúnkún wọn.’ (Jẹ 30:3-8, 12, 13, 24) Àwọn ọmọ náà gba ogún bíi ti àwọn ọmọ yòókù tí Réṣẹ́lì àti Líà bí. Jékọ́bù kúkú ni bàbá wọn. Réṣẹ́lì àti Líà lè ka àwọn ọmọ ẹrú yìí sí ọmọ wọn, ó ṣe tán ẹni tó lẹrú ló lẹrù.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kejì
30:14, 15—Kí nìdí tí Réṣẹ́lì fi torí èso máńdírékì yááfì àǹfààní tó ní láti sùn ti ọkọ rẹ̀ kó lè lóyún? Ní ayé ìgbàanì, wọ́n máa ń fi èso máńdírékì ṣe oògùn apàrora àti oògùn tó máa ń mú kí iṣan dẹ̀. Wọ́n tún gbà pé èso náà lè mú kí ìbálòpọ̀ máa wu èèyàn àti pé ó lè jẹ́ kéèyàn lóyún tàbí kó rí ọmọ bí. (Orin Sólómọ́nì 7:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ohun tó mú kí Réṣẹ́lì ṣe pàṣípààrọ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Réṣẹ́lì rò ni pé èso máńdírékì á mú kóun lóyún, kí ẹ̀gàn yíyà tó yàgàn lè kúrò. Bó ti wú kó rí, ó ṣì tó ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà kí Jèhófà tó “ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 30:22-24.
Bíbélì Kíkà