Mímọrírì Àwọn Ìpéjọpọ̀ Kristẹni
“Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.”—HÉBÉRÙ 10:24, 25.
1, 2. (a) Èé ṣe tí ó fi jẹ́ àǹfààní láti lọ sí ìpéjọpọ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́? (b) Ọ̀nà wo ni Jésù ń gbà wà nínú ìpéjọpọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
ẸWO irú àǹfààní tí ó jẹ́ láti pésẹ̀ sí ìpéjọpọ̀ Kristẹni, yálà àwọn olùjọsìn Jèhófà tí ó kóra jọ síbẹ̀ kò tó mẹ́wàá tàbí wọ́n tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún, nítorí Jésù sọ pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọpọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn”! (Mátíù 18:20) Òtítọ́ ni pé nígbà tí ó ń ṣèlérí yẹn, ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn ìdájọ́, tí àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ gbọ́dọ̀ bójú tó lọ́nà yíyẹ, ni Jésù ń jíròrò. (Mátíù 18:15-19) Ṣùgbọ́n, a ha lè lo ìlànà inú ọ̀rọ̀ Jésù náà fún gbogbo ìpéjọpọ̀ Kristẹni, tí a bẹ̀rẹ̀ tí a sì parí pẹ̀lú àdúrà lórúkọ rẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Rántí pé nígbà tí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó ṣèlérí pé: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:20.
2 Kò lè sí iyè méjì pé Orí ìjọ Kristẹni náà, Jésù Kristi Olúwa, ní ìfẹ́ gidigidi nínú gbogbo ìpéjọpọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́. Síwájú sí i, a lè ní ìdánilójú pé òun wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Ìṣe 2:33; Ìṣípayá 5:6) Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú lọ́kàn ìfẹ́ nínú pípéjọ tí a ń pé jọ pọ̀. Ète pàtàkì irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀ jẹ́ láti mú ìyìn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ‘nínú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.’ (Sáàmù 26:12) Lílọ tí a ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ tí a ní fún un.
3. Àwọn ìdí pàtàkì wo ni ó mú kí a mọrírì àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni?
3 Àwọn ìdí rere mìíràn wà tí a fi ń mọrírì àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni. Kí Jésù Kristi tó fi ayé sílẹ̀, ó yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ tí a fòróró yàn láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí yóò máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí ó ṣe kòńgẹ́ àkókò fún agboolé ìgbàgbọ́. (Mátíù 24:45) Ọ̀nà pàtàkì kan tí a ń gbà fi oúnjẹ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ bọ́ wa ni nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ àti àwọn ìpéjọpọ̀ ńlá—àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀. Jésù Kristi Olúwa ń darí ẹrú olóòótọ́ yìí láti pèsè ìsọfúnni ṣíṣe kókó ní irú ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ la òpin ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí já, kí wọ́n sì jèrè ìyè nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.
4. “Àṣà” líléwu wo ni Bíbélì mẹ́nu kàn, kí ni yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún un?
4 Nítorí náà, kò yẹ kí Kristẹni kankan dáwọ́ lé àṣà eléwu tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kíyè sí, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Ṣíṣàṣàrò lórí àǹfààní àti èrè lílọ sí àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìdúróṣinṣin àti gbogbo ọkàn ti irú ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn.
Àwọn Ìpàdé Tí Ń Gbéni Ró
5. (a) Ipa wo ni ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa ní nínú àwọn ìpàdé? (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a jáfara ní kíkésí àwọn olùfìfẹ́hàn wá sí àwọn ìpàdé?
5 Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ti ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà láti wà pẹ̀lú wa nínú ìpàdé Kristẹni, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó wá ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí náà, kí ó sì “má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.” (Éfésù 4:30) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ onímìísí yẹn, ọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè lo ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ́nà tí ó yẹ ni ó ń jíròrò. Ohun tí a bá ń sọ nígbà gbogbo yẹ kí ó jẹ́ “fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” (Éfésù 4:29) Èyí ṣe pàtàkì gan-an nínú àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ kí àwọn ìpàdé gbéni ró, kí wọ́n kún fún ìsọfúnni, kí wọ́n sì fúnni níṣìírí. (1 Kọ́ríńtì 14:5, 12, 19, 26, 31) Gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ máa ń jàǹfààní láti inú irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀, títí kan àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìpàdé, tí ó lè parí èrò sí pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.” (1 Kọ́ríńtì 14:25) Fún ìdí yìí, a kò gbọ́dọ̀ jáfara ní kíké sí àwọn ẹni tuntun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn láti pé jọ pẹ̀lú wa, nítorí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí yára kánkán.
6. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn kókó tí ó ń ṣèrànwọ́ ní mímú kí ìpàdé gbéni ró?
6 Gbogbo àwọn tí a bá yan àsọyé, ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò, tàbí àṣefihàn fún ní ìpàdé Kristẹni yóò fẹ́ láti ri dájú pé ọ̀rọ̀ ẹnu wọ́n gbéni ró, ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Ní àfikún sí sísọ ọ̀rọ̀ tí ó péye jáde lẹ́nu, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀lára tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ti Kristi hàn. Bí gbígbé ‘èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run,’ irú bí ìdùnnú, ìpamọ́ra, àti ìgbàgbọ́, yọ, bá jẹ gbogbo àwọn tí ó nípa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé lọ́kàn, dájúdájú wọn yóò gbé gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ ró.—Gálátíà 5:22, 23.
7. Báwo ni gbogbo àwọn tí ó wá sí ìpàdé ṣe lè fi kún ìpéjọpọ̀ tí ó gbéni ró?
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kéréje ní ń nípa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ nínú àwọn ìpàdé ìjọ, gbogbo àwùjọ lè fi kún ìpéjọpọ̀ tí ń gbéni ró. Lọ́pọ̀ ìgbà, àǹfààní máa ń wà fún àwùjọ láti dáhùn ìbéèrè. Ìwọ̀nyí jẹ́ àkókò fún pípolongo ìgbàgbọ́ wa ní gbangba. (Róòmù 10:9) A kò gbọ́dọ̀ lò wọ́n láé gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti gbé èrò ara wa lárugẹ, láti fi àṣeyọrí wa yangàn, tàbí láti ṣe lámèyítọ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ìyẹn kò ha ní kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run bí? Ó dára jù láti fi ìfẹ́ yanjú aáwọ̀ tí ó bá wà láàárín àwa àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa láàárín ara wa. Bíbélì sọ pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfésù 4:32) Ẹ wo irú àǹfààní gígalọ́lá tí ìpéjọpọ̀ Kristẹni ṣí sílẹ̀ fún wa láti fi ìmọ̀ràn àtàtà yìí sílò! Láti lè ṣe èyí, ọ̀pọ̀ ń tètè dé sí ìpàdé, wọ́n sì ń dẹsẹ̀ dúró díẹ̀ lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Èyí ń ran àwọn ẹni tuntun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn lọ́wọ́ pẹ̀lú, tí ó ṣe pàtàkì fún wọn láti nímọ̀lára pé a gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Nípa báyìí, gbogbo Kristẹni tí ó ti ṣèyàsímímọ́ ní ipa láti kó ní mímú kí ìpàdé gbéni ró nípa ‘gbígba ti ara wọn rò lẹ́nì kìíní-kejì, kí wọ́n sì máa ru ara wọn sókè lẹ́nì kìíní-kejì sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’
Múra Sílẹ̀ Dáradára
8. (a) Àwọn ìrúbọ tí ó yẹ fún oríyìn wo ni àwọn kan ń ṣe láti lè wá sí ìpàdé? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn?
8 Nígbà tí ó lè rọrùn ní ìfiwéra fún àwọn kan láti pésẹ̀ sí àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni, fún àwọn mìíràn, ó ń béèrè ìrúbọ tí ń bá a lọ títí. Fún àpẹẹrẹ, ó sábà máa ń rẹ Kristẹni ìyá kan, tí ó ní láti ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láti ṣèrànwọ́ ní pípèsè fún àìní agboolé rẹ̀, nígbà tí ó bá darí sílé lẹ́nu iṣẹ́. Lẹ́yìn náà, ó lè ní láti se oúnjẹ, kí ó sì ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti múra ìpàdé sílẹ̀. Àwọn Kristẹni mìíràn lè ní láti rin ọ̀nà jínjìn láti lọ sí àwọn ìpàdé, tàbí kí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó dín ohun tí wọ́n lè ṣe kù. Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run lóye ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń fi òtítọ́ wá sí ìpàdé, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ ṣe lóye àìní àrà ọ̀tọ̀ àgùntàn kọ̀ọ̀kan inú agbo rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí olùṣọ́ àgùntàn ni [Jèhófà] yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí. Àwọn tí ń fọ́mọ lọ́mú ni yóò máa rọra dà.”—Aísáyà 40:11.
9, 10. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní jù lọ láti inú àwọn ìpàdé?
9 Àkókò tí àwọn tí ó ní láti ṣe ìrúbọ ńlá láti wà ní ìpàdé déédéé lè lò láti fi múra àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a óò gbé yẹ̀ wò sílẹ̀ lè má pọ̀. Bíbá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ ń mú kí wíwà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run túbọ̀ ṣeni láǹfààní. Bákan náà, mímúrasílẹ̀ fún àwọn ìpàdé mìíràn, irú bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, ń mú kí ìwọ̀nyí túbọ̀ ṣeni láǹfààní. Nípa kíka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a óò kẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú, àti nípa fífún, ó kéré tán, díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí ní àfiyèsí, àwọn tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ìdílé tí ń gbani lákòókò yóò nítẹ̀sí láti nípìn-ín tí ó jọjú nínú àwọn ìjíròrò Bíbélì ṣíṣe pàtàkì wọ̀nyí.
10 Àwọn yòókù, tí ipò wọn túbọ̀ fún wọn láyè, lè lo àkókò púpọ̀ sí i ní mímúra ìpàdé sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lè ṣèwádìí lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, ṣùgbọ́n tí a kò ṣàyọlò wọn. Gbogbo àwùjọ lè tipa báyìí múra láti jàǹfààní tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìpàdé, kí wọ́n sì ṣàjọpín lọ́nà tí ó dára ní gbígbé ìjọ ró nípasẹ̀ àsọyé àti ìdáhùn wọn. Nípa mímúrasílẹ̀ dáradára, àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú mímú kí ìdáhùn wọ́n ṣe ṣókí, kí ó sì sọ ojú abẹ níkòó. Nítorí ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún àwọn ìpèsè Jèhófà, àwọn tí ó pésẹ̀ yóò yẹra fún àwọn àṣà tí ń fa ìpínyà ọkàn nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.—1 Pétérù 5:3.
11. Èé ṣe tí a fi nílò ìsẹ́ra-ẹni láti lè múra àwọn ìpàdé sílẹ̀?
11 Àwọn ìgbòkègbodò àti àwọn eré ìnàjú tí kò ṣe kókó fún ìlera wa tẹ̀mí lè máa gba ọ̀pọ̀ nínú àkókò wa. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a ṣàyẹ̀wò ara wa fínnífínní, kí a sì “ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú” nínú ọ̀nà tí a gbà ń lo àkókò wa. (Éfésù 5:17) Góńgó wa gbọ́dọ̀ jẹ́ láti ‘ra àkókò padà’ láti inú àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, kí a baà lè lo àkókò púpọ̀ sí i nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti mímúra ìpàdé sílẹ̀, àti nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba. (Éfésù 5:16) A gbà pé èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn, ó sì ń béèrè sísẹ́-ara-ẹni. Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fún èyí ní àfiyèsí ń fi ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú ọjọ́ ọ̀la. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, ọ̀dọ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí [ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sí Tímótì]; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tímótì 4:15.
Àwọn Àpẹẹrẹ Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
12. Àpẹẹrẹ títayọlọ́lá wo ni ìdílé Sámúẹ́lì fi lélẹ̀?
12 Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àtàtà tí ìdílé Sámúẹ́lì, tí ń lọ́wọ́ déédéé nínú ètò pípéjọpọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn, nígbà tí àgọ́ àjọ Ọlọ́run wà ní Ṣílò. Àwọn ọkùnrin nìkan ni a béèrè pé kí wọ́n ṣèbẹ̀wò ọdọọdún síbi ayẹyẹ àjọyọ̀. Ṣùgbọ́n, Ẹlikénà, bàbá Sámúẹ́lì, kó gbogbo ìdílé rẹ̀ dání, bí ó ti “máa ń gòkè lọ láti ìlú ńlá rẹ̀ láti ọdún dé ọdún láti wólẹ̀, kí ó sì rúbọ sí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Ṣílò.” (1 Sámúẹ́lì 1:3-5) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìtòsí etíkun, ní Rentis òde òní, ní ẹsẹ̀ òkè “ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,” ni ìlú Sámúẹ́lì, Ramataimu-sófíímù, wà. (1 Sámúẹ́lì 1:1) Nípa báyìí, ìrìn àjò sí Ṣílò yóò ti gba rírin nǹkan bí 30 kìlómítà, ìrìn tí ń tánni lókun ní ayé ọjọ́un. Èyí ni ohun tí ìdílé Ẹlikénà fi ìdúróṣinṣin ṣe “lọ́dọọdún, nígbàkúùgbà tí [wọ́n] bá gòkè lọ sí ilé Jèhófà.”—1 Sámúẹ́lì 1:7.
13. Àpẹẹrẹ wo ni àwọn Júù olùṣòtítọ́ fi lélẹ̀ nígbà tí Jésù wá lórí ilẹ̀ ayé?
13 Jésù pẹ̀lú dàgbà nínú agbo ilé ńlá kan. Lọ́dọọdún, ìdílé náà máa ń rìnrìn àjò láti Násárétì lọ sí nǹkan bí 100 kìlómítà sí gúúsù láti ṣàjọyọ̀ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù. Ọ̀nà méjì ni wọ́n lè ti gbà. Ọ̀nà tí ó ṣe tààràtà jù béèrè pé kí wọ́n gba Àfonífojì Mẹ́gídò sọ̀ kalẹ̀, kí wọ́n sì tún gùnkè tí ó ga tó 600 mìlímítà la àgbègbè Samáríà kọjá sí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀nà kejì tí ó gbajúmọ̀ ni èyí tí Jésù gbà nígbà ìrìn àjò rẹ̀ tí ó kẹ́yìn sí Jerúsálẹ́mù ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Èyí béèrè pé kí ó gba Àfonífojì Jọ́dánì sọ̀ kalẹ̀ dé ìtẹ́jú òkun, títí tí ó fi dé “ààlà ilẹ̀ Jùdíà . . . sí òdì-kejì Jọ́dánì.” (Máàkù 10:1) Láti ibí yìí, “ojú ọ̀nà gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù” jìn tó 30 kìlómítà, tí ó sì gba gígùnkè tí ó ga tó 1,100 mítà. (Máàkù 10:32) Àwọn èrò tí wọ́n jẹ́ olùfòtítọ́-ṣayẹyẹ-àjọyọ̀ máa ń rìnrìn àjò aláápọn náà láti Gálílì sí Jerúsálẹ́mù déédéé. (Lúùkù 2:44) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àtàtà tí èyí jẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn tí ó lè lọ sí àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni tìrọ̀rùntìrọ̀rùn ní ìfiwéra, a dúpẹ́ fún àwọn ohun ìrìnnà òde òní!
14, 15. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Ánà fi lélẹ̀? (b) Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìṣarasíhùwà àtàtà tí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sí ìpàdé fi hàn?
14 Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Ánà, opó ẹni ọdún 84. Bíbélì sọ pé, “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ.” (Lúùkù 2:37) Síwájú sí i, Ánà fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn fún àwọn ẹlòmíràn. Ní títajúkán rí Jésù ọmọ ọwọ́ náà, tí ó sì gbọ́ pé òun ni Mèsáyà tí a ṣèlérí, kí ni ohun tí ó ṣe? Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí “sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.” (Lúùkù 2:38) Ẹ wo irú ìṣarasíhùwà àtàtà tí èyí jẹ́, àwòkọ́ṣe fún àwọn Kristẹni lónìí!
15 Bẹ́ẹ̀ ni, wíwá sì àwọn ìpàdé wa àti kíkópa nínú wọn yẹ kí ó dùn mọ́ wa débi pé, bí Ánà, a kì yóò fẹ́ láti pa á jẹ. Kò sí kí ọ̀pọ̀ ẹni tuntun máà ní irú ìmọ̀lára yìí. Níwọ̀n bí wọ́n ti ti inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu Ọlọ́run, wọ́n fẹ́ kọ́ gbogbo ohun tí wọ́n lè kọ́, ọ̀pọ̀ sì ń fi ìtara gígalọ́lá hàn fún àwọn ìpàdé Kristẹni. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tí ó ti pẹ́ nínú òtítọ́ gbọ́dọ̀ yẹra fún ‘fífi ìfẹ́ tí wọ́n ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.’ (Ìṣípayá 2:4) Àwọn àìlera burúkú tàbí àwọn kókó mìíràn, tí ó kọjá agbára ẹnì kan, lè mú kí wíwá sí ìpàdé rẹ̀ ṣe ségesège ní àwọn ìgbà kan. Ṣùgbọ́n, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, eré ìnàjú, tàbí àìnífẹ̀ẹ́ mú kí a má múra sílẹ̀, kí a má lọ́kàn ìfẹ́, tàbí kí wíwá sí ìpàdé wá máa ṣe ségesège, láé.—Lúùkù 8:14.
Àpẹẹrẹ Dídára Jù Lọ
16, 17. (a) Kí ni ìṣarasíhùwà Jésù sí àwọn ìpéjọpọ̀ tẹ̀mí? (b) Àṣà dáradára wo ni ó yẹ kí gbogbo Kristẹni gbìyànjú láti tẹ̀ lé?
16 Jésù fi àpẹẹrẹ títayọlọ́lá lélẹ̀ nínú fífi ìmọrírì hàn fún ìpéjọpọ̀ tẹ̀mí. Nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 12, ó fi ìfẹ́ tí ó ní fún ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù hàn. Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ ibi tí ó wà, ṣùgbọ́n, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rí i níbi tí ó ti ń jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn olùkọ́ nínú tẹ́ńpìlì. Ní dídáhùnpadà sí àníyàn àwọn òbí rẹ̀, Jésù béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” (Lúùkù 2:49) Pẹ̀lú ìtẹríba, Jésù ọ̀dọ́ náà bá àwọn òbí rẹ̀ padà sí Násárétì. Níbẹ̀, ó ń bá a lọ láti fi ìfẹ́ tí ó ní fún àwọn ìpàdé ìjọsìn hàn, nípa lílọ sí sínágọ́gù déédéé. Nípa báyìí, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Bíbélì ròyìn pé: “Ó . . . wá sí Násárétì, níbi tí a ti tọ́ ọ dàgbà; àti pé, gẹ́gẹ́ bí àṣà rẹ̀ ní ọjọ́ sábáàtì, ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì dìde dúró láti kàwé.” Lẹ́yìn tí Jésù ka Aísáyà 61:1, 2, tí ó sì ṣàlàyé rẹ̀, “ẹnu” bẹ̀rẹ̀ sí “ya [àwùjọ náà] nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.”—Lúùkù 4:16, 22.
17 Àwọn ìpàdé Kristẹni tí a ń ṣe lónìí ń tẹ̀ lé àwòṣe kan náà bí èyí. Lẹ́yìn tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé pẹ̀lú orin ìyìn àti àdúrà, a óò ka àwọn ẹsẹ láti inú Bíbélì (tàbí àwọn ẹsẹ tí a ṣàyọlò nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì), a óò sì ṣàlàyé wọn. Ó pọndandan fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti fara wé àṣà rere Jésù Kristi. Dé ibi tí ipò wọ́n yọ̀ǹda, inú wọ́n máa ń dùn láti wà ní àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni déédéé.
Àwọn Àpẹẹrẹ Òde Òní
18, 19. Àwọn àpẹẹrẹ títayọlọ́lá wo ni àwọn ará tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù fún fi lélẹ̀ ní ti ìpàdé, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ lílọ?
18 Ní àwọn apá ibi tí nǹkan kò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ń fi àpẹẹrẹ àtàtà ti ìmọrírì fún àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni lélẹ̀. Ní Mòsáńbíìkì, ó gba alábòójútó àgbègbè kan, Orlando, àti aya rẹ̀, Amélia, ní wákàtí 45 láti rin 90 kìlómítà kọjá lórí òkè ńlá kan láti sìn ní àpéjọ kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní láti rin irú ìrìn kan náà padà láti sìn ní àpéjọ tí ó tẹ̀ lé e. Orlando ròyìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “A nímọ̀lára pé a kò ṣe ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí àwọn ará tí ó wá láti Ìjọ Bawa ṣe. Láti wá sí àpéjọ náà, kí wọ́n sì padà sí ilé, ó gbà wọ́n ní ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́fà, ní fífẹsẹ̀rin 400 kìlómítà, arákùnrin ẹni 60 ọdún sì wà lára wọn!”
19 Ìmọrírì fún àwọn ìpàdé ìjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ńkọ́? Kashwashwa Njamba jẹ́ arábìnrin tí ara rẹ̀ kò le mọ́, tí ó ti lé ní 70 ọdún. Ó ń gbé ní Kaisososi, abúlé kékeré kan, tí ó wà ní nǹkan bí kìlómítà márùn-ún sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Rundu, Namibia. Láti lọ sí àwọn ìpàdé, ó ń rin kìlómítà mẹ́wàá, ní àlọ àti àbọ̀, la inú igbó kọjá. A ti dá àwọn ènìyàn lọ́nà lójú ọ̀nà yìí, ṣùgbọ́n, Kashwashwa kò yéé wá. Èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn ìpàdé náà ni a ń darí ní àwọn èdè tí kò gbọ́. Nítorí náà, báwo ni wíwá tí ó ń wá ṣe ń se é láǹfààní? Kashwashwa sọ pé: “Nípa fífojú bá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí lọ, mo máa ń gbìyànjú láti mọ ohun tí àsọyé náà dá lé lórí.” Ṣùgbọ́n, kò mọ̀ ọ́n kọ kò mọ̀ ọ́n kà, nítorí náà, báwo ni ó ṣe ń fojú bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ? Ó dáhùn pé: “Mo máa ń tẹ́tí sílẹ̀ láti gbọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo mọ̀ sórí.” Bí ọdún sì ti ń gorí ọdún, ó ti kọ́ ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí. Láti mú agbára ìlò Bíbélì rẹ̀ sunwọ̀n si, ó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí ìjọ ṣètò. Ó sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ láti máa lọ sí àwọn ìpàdé. Kò sígbà tí kò sí àwọn ohun tuntun láti kọ́. Mo nífẹ̀ẹ́ láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin. Bí n kò tilẹ̀ lè bá gbogbo wọn sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń wá kí mi ṣáá ni. Èyí tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, mo mọ̀ pé nípa lílọ sí àwọn ìpàdé, mo ń múnú Jèhófà dùn.”
20. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ kọ ìpéjọpọ̀ Kristẹni wa sílẹ̀?
20 Bí Kashwashwa, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ olùjọsìn Jèhófà jákèjádò ayé ń fi ìmọrírì tí ó yẹ fún oríyìn hàn fún àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni. Bí ayé Sátánì ti ń forí lé ìparun rẹ̀, a kò jẹ́ kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí a sì fi ìmọrírì tí ó jinlẹ̀ hàn fún ìpàdé, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀. Kì í ṣe pé ìyẹn yóò mú inú Jèhófà dùn nìkan ni, ṣùgbọ́n, yóò ṣe wá láǹfààní jìngbìnnì pẹ̀lú, bí a ti ń nípìn-ín nínú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, tí ń sinni lọ sí ìyè ayérayé.—Òwe 27:11; Aísáyà 48:17, 18; Máàkù 13:35-37.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Èé ṣe tí ó fi jẹ́ àǹfààní láti lọ sí àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni?
◻ Báwo ni gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ ṣe lè fi kún ìpàdé tí ó gbéni ró?
◻ Àpẹẹrẹ títayọlọ́lá wo ni Jésù Kristi fi lélẹ̀?
◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù fún?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Wọ́n Mọrírì Àwọn Ìpàdé Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń gbé ní àwọn ìlú tí ipò òṣì àti ìwà ọ̀daràn ń pọ́n lójú. Láìka irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ sí, àwọn Kristẹni tòótọ́ láàárín wọn ń fi ìmọrírì tí ó yẹ fún oríyìn hàn fún àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni. Alàgbà kan tí ń sìn nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ Soweto ti Gauteng, ní Gúúsù Áfíríkà, ròyìn pé: “Nínú ìjọ tí ó ní 60 Ẹlẹ́rìí àti àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, nígbà mìíràn, a máa ń ní tó 70 sí 80 ènìyàn, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ń wá sí àwọn ìpàdé wa. Bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin kò tilẹ̀ ń rin ọ̀nà jíjìn láti wá, ipò nǹkan ní àgbègbè Soweto yìí kò fara rọ rárá. A gún arákùnrin kan lẹ́yìn nígbà tí ó ń rìn lọ sí ìpàdé. Ó kéré tán, a dá àwọn arábìnrin méjì lọ́nà. Ṣùgbọ́n, èyí kò ní kí wọ́n má lọ. Ní àwọn ọjọ́ Sunday, a máa ń kọ́ orin fún ìṣẹ́jú bí mélòó kan lẹ́yìn tí a bá ti fi àdúrà parí ìpàdé. Ó kéré tán, nǹkan bí ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún ni ó máa ń dúró ní gbogbo ìgbà láti kọ gbogbo orin tí a óò lò ní àwọn ìpàdé lọ́sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Èyí ń ran àwọn olùfìfẹ́hàn, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sì dara pọ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn orin náà, kí wọ́n sì dara pọ̀ ní kíkọ́ wọ́n.”
Ìdènà mìíràn ń dojú kọ àwọn tí ń gbé ní ìgbèríko, irú bí rínrin ọ̀nà jíjìn láti lè pésẹ̀ sí ìpàdé lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀. Tọkọtaya olùfìfẹ́hàn kan ń gbé ní kìlómítà 15 sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Lobatse, Botswana. Ní gbogbo ọdún tí ó kọjá, wọ́n wá sí ìpàdé déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn méjèèjì. Iṣẹ́ sobàtà ni ọkọ ń ṣe láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Aya ń ta àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti fi kún owó tí ń wọlé wá fún ìdílé, kí wọ́n lè rí owó ọkọ̀ san wá sí ìpàdé àti padà lọ sílé.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, láìpẹ́ yìí, lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú alábòójútó àyíká, ìdílé yìí tàn sí ibùdókọ̀ ní agogo mẹ́sàn-án alẹ́. Àwọn ọlọ́kọ̀ ti tètè ṣíwọ́ iṣẹ́, nítorí ojú ọjọ́ tí kò dára. Ọ̀gá ọlọ́pàá kan, tí ń wa ọkọ̀ lọ dúró, ó sì béèrè ohun tí wọ́n ń ṣe. Nígbà tí ó gbọ́ ìṣòro tí wọ́n ní, àánú wọn ṣe é, ó sì gbé wọn rìnrìn àjò kìlómítà 15 náà délé. Aya náà, tí ó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Oò rí, bí a bá fi àwọn ìpàdé ṣàkọ́kọ́, Jèhófà máa ń pèsè ṣáá ni.” Ní báyìí, ọkọ ti sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ jáde láti di oníwàásù ìhìn rere náà pẹ̀lú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Ẹlẹ́rìí bí ìwọ̀nyí ní Romania, fi àpẹẹrẹ àtàtà ti mímọrírì àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni lélẹ̀