Ta Ló Lè Dá Àwọn Tó Ń kígbe Fún Ìrànlọ́wọ́ Nídè?
“Ọlọ́run, fi àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ fún ọba . . . Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè.”—SM. 72:1, 12.
1. Kí la kọ́ nípa àánú Ọlọ́run látinú ọ̀ràn Dáfídì?
Ọ̀RỌ̀ yìí mà múni lọ́kàn yọ̀ o! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kó tó kọ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bà jẹ́ lẹ́yìn tó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Nígbà yẹn, Dáfídì bẹ Ọlọ́run pé: “Nu àwọn ìrélànàkọjá mi kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ. . . . Ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo. . . . Wò ó! Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ, nínú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi.” (Sm. 51:1-5) Ojú àánú Jèhófà máa ń mú kó wo ti ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún mọ́ wa lára.
2. Báwo ni Sáàmù Kejìléláàádọ́rin ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
2 Jèhófà mọ ipò tó ń bani nínú jẹ́ tá a wà. Àmọ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Ọba tí Ọlọ́run ti fòróró yàn “yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” (Sm. 72:12, 13) Báwo ló ṣe máa mú ìtura wá? Sáàmù Kejìléláàádọ́rin sọ fún wa. Sáàmù yìí dá lórí ìjọba Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì, ó sì jẹ́ ká mọ bí ìṣàkóso Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run ṣe máa mú ìtura bá ìran èèyàn kúrò lọ́wọ́ ìnilára.
Ó Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìjọba Kristi Ṣe Máa Rí
3. Kí ni Sólómọ́nì béèrè, kí sì ni Ọlọ́run fún un?
3 Lẹ́yìn tí Dáfídì tó ti darúgbó pàṣẹ pé kí wọ́n fi Sólómọ́nì jọba, ó wá fún un ní àwọn ìtọ́ni pàtó, èyí tí Sólómọ́nì fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ lé lórí. (1 Ọba 1:32-35; 2:1-3) Lẹ́yìn náà, Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá, ó sì sọ fún un pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò fún ọ.” Ohun kan ṣoṣo ni Sólómọ́nì béèrè, ó sọ pé: “Kí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn-àyà ìgbọràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ, láti fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú.” Nítorí ohun tí Sólómọ́nì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ béèrè yìí, Ọlọ́run fún un ní ohun tó béèrè àtàwọn nǹkan míì.—1 Ọba 3:5, 9-13.
4. Kí ni ọba kan tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Sólómọ́nì sọ nípa ìṣàkóso rẹ̀?
4 Torí pé Jèhófà bù kún Sólómọ́nì, àlàáfíà àti aásìkí gbilẹ̀ nígbà ìṣàkóso rẹ̀, èyí sì mú kó jẹ́ àkókò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ nínú ìtàn ìṣàkóso èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé. (1 Ọba 4:25) Ọbabìnrin Ṣébà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tó pọ̀ gan-an wà lára àwọn tó wá wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ó sọ fún Sólómọ́nì pé: ‘Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ tèmi já sí. A kò sọ ìdajì wọn fún mi. Ìwọ ta yọ ní ọgbọ́n àti aásìkí ré kọjá àwọn ohun tí a gbọ́.’ (1 Ọba 10:1, 6, 7) Síbẹ̀, ọgbọ́n tó ju ìyẹn lọ fíìfíì ni Jésù fi hàn, torí náà ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Wò ó! ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín.”—Mát. 12:42.
Ìtura Lábẹ́ Ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù
5. Kí ni Sáàmù Kejìléláàádọ́rin fi hàn, kí ló sì jẹ́ ká mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú?
5 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó wà nínú Sáàmù Kejìléláàádọ́rin, ká lè kọ́ nípa àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi, tó jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù. (Ka Sáàmù 72:1-4.) Sáàmù yìí sọ ojú tí Jèhófà fi wo “ìṣàkóso ọmọ aládé” tó jẹ́ ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísá. 9:6, 7) Lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, Sólómọ́nì Títóbi Jù náà yóò ‘fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, yóò sì gba àwọn ọmọ òtòṣì là.’ Àlàáfíà àti òdodo yóò sì gbilẹ̀ nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àpẹẹrẹ ohun tí òun máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀ hàn.—Ìṣí. 20:4.
6. Àwọn nǹkan wo ni Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó máa ṣe lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?
6 Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìgbòkègbodò Jésù Kristi tó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣe fún aráyé ní ìmúṣẹ ohun tó wà nínú Sáàmù Kejìléláàádọ́rin. Ìyọ́nú tó fi hàn sí àwọn tí ìyà ń jẹ wú wa lórí gan-an ni, ó sì yẹ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. (Mát. 9:35, 36; 15:29-31) Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Jésù fèsì pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Ara ọkùnrin náà sì yá! (Máàkù 1:40-42) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jésù pàdé obìnrin opó kan tí ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó ní kú. “Àánú rẹ̀ ṣe” Jésù, ó sọ pé: “Dìde!” ọmọkùnrin náà sì dìde jókòó. Ọmọ náà tún pa dà wà láàyè!—Lúùkù 7:11-15.
7, 8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jésù fi agbára tó ní láti woni sàn ṣe?
7 Jèhófà fún Jésù lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ọ̀ràn ti ‘obìnrin kan tó ti jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘ọ̀pọ̀ oníṣègùn ti mú ọ̀pọ̀ ìrora bá a, ó sì ti ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀,’ síbẹ̀ ńṣe ló ń burú sí i. Obìnrin náà wọ àárín èrò, ó sì fọwọ́ kan Jésù, èyí sì jẹ́ rírú Òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú ‘àsunjáde tó jẹ́ ẹ̀jẹ̀.’ (Léf. 15:19, 25) Jésù kíyè sí i pé agbára jáde lára òun, ó sì béèrè pé ta ló fọwọ́ kan òun. Obìnrin náà, “tí jìnnìjìnnì ti bá, tí ó sì ń wárìrì,” “wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ náà fún un.” Bí Jésù ti mọ̀ pé Jèhófà ti wo obìnrin náà sàn, kò le koko mọ́ ọn, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”—Máàkù 5:25-27, 30, 33, 34.
8 Agbára tí Ọlọ́run fún Jésù wo aláìsàn náà sàn, àmọ́ ó tún ní láti nípa gidi lórí àwọn tó ń wòran. Bí àpẹẹrẹ, kò sí iyè méjì pé orí ọ̀pọ̀ èèyàn wú nígbà tí wọ́n rí i tí Jésù ń wo àwọn èèyàn sàn kó tó bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù Orí Òkè. (Lúùkù 6:17-19) Nígbà tí Jòhánù Oníbatisí rán èèyàn méjì láti rí àrídájú bóyá Jésù ni Mèsáyà, wọ́n bá a tó ń “wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ sàn kúrò nínú àwọn àìsàn àti àwọn òkùnrùn burúkú àti àwọn ẹ̀mí burúkú, ó sì ṣe ojú rere sí ọ̀pọ̀ afọ́jú láti ríran.” Jésù wá sọ fún àwọn méjì náà pé: “Ẹ ròyìn ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a ń gbé àwọn òkú dìde, a ń sọ ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” (Lúùkù 7:19-22) Ó dájú pé iṣẹ́ tó rán sí Jòhánù yìí á fún un ní ìṣírí gan-an!
9. Kí ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ṣàpẹẹrẹ?
9 Lóòótọ́, ìtura tí Jésù pèsè fún àwọn tó ń jìyà nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kò wà pẹ́ lọ títí. Àwọn aláìsàn tó wò sàn àti àwọn tó jí dìde tún pa dà kú. Síbẹ̀, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé jẹ́ àpẹẹrẹ ìtura ayérayé tó máa mú wá fún ìran èèyàn nígbà ìṣàkóso rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.
Párádísè Tó Máa Kárí Ayé Kò Ní Pẹ́ Dé!
10, 11. (a) Báwo ni àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa pẹ́ tó, báwo sì ni ìṣàkóso Jésù ṣe máa rí? (b) Ta ló máa wà pẹ̀lú Kristi ní Párádísè, báwo ló sì ṣe lè wà láàyè títí láé?
10 Fọkàn yàwòrán bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. (Ka Sáàmù 72:5-9.) Á ṣeé ṣe fún àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà láti gbádùn ìwàláàyè nínú Párádísè, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá fi wà, àní títí láé! Ọba náà Jésù Kristi yóò mú kí ara tuni bí ‘òjò tó ń rọ̀ sórí koríko tí a gé àti bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò tí ń mú kí ilẹ̀ rin.’
11 Bó o ṣe ń fojú inú wo ìmúṣẹ ohun tó wà nínú sáàmù yìí, ǹjẹ́ ìrètí gbígbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé kì í múnú rẹ dùn? Ó dájú pé inú aṣebi tí wọ́n kàn mọ́gi pẹ̀lú Jésù dùn nígbà tí Jésù sọ fún un pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Ọkùnrin yẹn máa pa dà wà láàyè nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù. Tó bá tẹrí ba fún ìṣàkóso Kristi, á ṣeé ṣe fún un láti wà láàyè títí láé, yóò sì ní ìlera pípé àti ayọ̀.
12. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àǹfààní wo ló máa ṣí sílẹ̀ fún àwọn aláìṣòótọ́ tó bá jí dìde?
12 Lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù, ìyẹn Jésù Kristi, àwọn “olódodo yóò rú jáde” ìyẹn ni pé wọ́n á láásìkí, nǹkan á sì ṣẹnuure fún wọn. (Sm. 72:7) Jésù Kristi yóò wá láǹfààní láti fi ìfẹ́ bójú tó gbogbo èèyàn, bó ṣe rí nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Kódà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, “àwọn aláìṣòdodo” tó máa jíǹde yóò ní àǹfààní láti lè máa fi àwọn ìlànà Jèhófà ṣèwà hù, kí wọ́n lè ní ìyè. (Ìṣe 24:15) Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run kò ní gba àwọn tó kọ̀ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ láyè láti máa wà láàyè nìṣó, kí wọ́n sì ba àlàáfíà àti ìtòròmini tó wà nínú ayé tuntun náà jẹ́.
13. Báwo ni ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa gbòòrò tó, kí sì nìdí tí kò fi ní sẹ́ni tó máa ba àlàáfíà ibẹ̀ jẹ́?
13 Ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí fi bí ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù náà ṣe máa gbòòrò kárí ayé tó hàn. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Òun yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò [Yúfírétì] dé òpin ilẹ̀ ayé. Àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀, àní àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò lá ekuru.” (Sm. 72:8, 9) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù Kristi máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé. (Sek. 9:9, 10) Àwọn tó mọrírì ìṣàkóso rẹ̀ àtàwọn ìbùkún tó máa mú wá yóò fínnú fíndọ̀ “tẹrí ba” fún un. Àmọ́, a ó ké àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ “ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún.” (Aísá. 65:20) Wọn “yóò lá ekuru.”
Jésù Ń Bá Wa Kẹ́dùn
14, 15. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwa èèyàn àti pé ó máa “dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè”?
14 Àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ipò tó burú jáì, a sì nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì. Àmọ́, a ní ìrètí. (Ka Sáàmù 72:12-14.) Jésù tó jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù ń bá wa kẹ́dùn torí pé ó mọ̀ pé aláìpé ni wá. Síwájú sí i, Jésù jìyà nítorí òdodo, Ọlọ́run sì gbà á láyè láti fojú winá àdánwò. Ìdààmú ọkàn tó bá Jésù pọ̀ débi pé “òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀”! (Lúùkù 22:44) Lẹ́yìn náà, nígbà tó wà lórí òpó igi oró, ó kígbe pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?” (Mát. 27:45, 46) Pẹ̀lú gbogbo ìyà tí Jésù jẹ yìí àti bí Sátánì ṣe gbógun tì í kó lè kẹ̀yìn sí Jèhófà, kò ṣíwọ́ jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run.
15 Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jésù rí ìnira wa, ó sì máa “dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́.” Bíi ti Bàbá rẹ̀, ìfẹ́ á mú kí Jésù “fetí sí àwọn òtòṣì” yóò sì ‘mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, yóò sì di àwọn ojú ibi tó ń ro wọ́n.’ (Sm. 69:33; 147:3) Jésù lè ‘bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa,’ torí pé ‘a ti dán an wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa.’ (Héb. 4:15) Inú wa mà dùn o láti mọ̀ pé, Ọba náà Jésù Kristi ti ń ṣàkóso ní ọ̀run, ó sì ń hára gàgà láti mú ìtura bá ìràn èèyàn tó ń jìyà!
16. Kí ló mú kí Sólómọ́nì lè bá àwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ kẹ́dùn?
16 Torí pé Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀, kò sí àní-àní pé ó “káàánú ẹni rírẹlẹ̀.” Síbẹ̀, inú tirẹ̀ náà bà jẹ́, ó sì dojú kọ àwọn ìṣòro kan tó dà á lọ́kàn rú ní ìgbésí ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ámínónì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Sólómọ́nì, fipá bá Támárì tó jẹ́ àbúrò rẹ̀ tí obìnrin míì bí fún bàbá wọn, lò pọ̀, Ábúsálómù tó jẹ́ iyèkan Támárì àti ẹ̀gbọ́n fún Sólómọ́nì sì pa Ámínónì nítorí ọ̀ràn yìí. (2 Sám. 13:1, 14, 28, 29) Ábúsálómù fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ Dáfídì, àmọ́ ọ̀tẹ̀ náà kò kẹ́sẹ járí, Jóábù sì ṣekú pa Ábúsálómù. (2 Sám. 15:10, 14; 18:9, 14) Lẹ́yìn náà, Ádóníjà arákùnrin Sólómọ́nì náà gbìyànjú láti gba ìjọba. Ká sọ pé ó ṣàṣeyọrí ni, ẹ̀mí Sólómọ́nì ì bá lọ sí i. (1 Ọba 1:5) Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé Sólómọ́nì mọ bí ìyà ṣe rí lára ni ọ̀rọ̀ tó sọ nínú àdúrà tó gbà níbi ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Lórí kókó yìí, Sólómọ́nì Ọba gbàdúrà pé: “Nítorí pé olúkúlùkù wọn mọ ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀ . . . Kí [ìwọ Jèhófà] sì dárí jì, kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—2 Kíró. 6:29, 30.
17, 18. Ìnira wo ni àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ń kojú, kí ló sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí?
17 Ó lè jẹ́ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà kan rí ló fa “ìrora” fún wa. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mary,a ẹni ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀ kọ̀wé pé: “Kò sí ohun tó lè mú kí n máà láyọ̀, àmọ́ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi kọjá máa ń mú kí ojú tì mí, ó sì máa ń kó mi ní ìríra. Inú mi á wá bà jẹ́, á sì máa ṣe mí bíi pé kí n bú sẹ́kún, bíi pé àná lọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ yìí kò ṣe lọ lọ́kàn mi bọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kó ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan, ẹ̀rí ọkàn sì máa ń dà mí láàmú.”
18 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló lè máa ní irú èrò yìí, àmọ́ kí ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní okun tí wọ́n á fi lè fara dà á? Mary sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ àtàwọn ará nínú ìjọ máa ń jẹ́ kí n láyọ̀. Mo máa ń gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tí Jèhófà ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú, ó sì dá mi lójú pé igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́ máa di igbe ayọ̀.” (Sm. 126:5) A ní láti gbé ìrètí wa karí pípèsè tí Ọlọ́run pèsè Ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ Alákòóso tó yàn. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.” (Sm. 72:13, 14) Ọ̀rọ̀ yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!
Ayé Tuntun Tí Oúnjẹ Ti Máa Pọ̀ Yanturu Ń Bọ̀
19, 20. (a) Bí Sáàmù Kejìléláàádọ́rin ṣe fi hàn, ìṣòro wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú? (b) Ta lọpẹ́ yẹ fún ìṣàkóso Kristi, báwo sì ni ohun tó máa gbé ṣe ṣe rí lára rẹ?
19 Tún fọkàn yàwòrán bí ọjọ́ ọ̀la àwọn olódodo ṣe máa rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù. A ṣèlérí fún wa pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sm. 72:16) Níwọ̀n bí ọkà kì í ti í ṣàdédé lalẹ̀ hù lórí àwọn òkè ńlá, ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso jáde wọ̀ǹtìwọnti. Àwọn èso rẹ̀ “yóò rí bí ti Lẹ́bánónì,” ìyẹn àgbègbè kan tó ń méso jáde lọ́pọ̀ jaburata nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ìwọ rò ó wò ná! Kò ní sí àìtó oúnjẹ mọ́, kò sẹ́ni tí kò ní máa jẹun kánú, kò sì sẹ́ni tí kò ní máa rí oúnjẹ jẹ! Nígbà yẹn gbogbo èèyàn ló máa gbádùn “àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn.”—Aísá. 25:6-8; 35:1, 2.
20 Ta lọpẹ́ yẹ nítorí àwọn ìbùkún yìí? Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Ayérayé, tó sì tún jẹ́ Olùṣàkóso Ayé Àtọ̀run ni. Nígbà yẹn gbogbo wa pátá la máa fi ayọ̀ pa ohùn wa pọ̀ láti kọ apá tó gbẹ̀yìn orin aládùn tó ń mọ́kàn yọ̀ yìí, pé: “Kí orúkọ rẹ̀ [ìyẹn orúkọ Ọba náà Jésù Kristi] máa wà nìṣó fún àkókò tí ó lọ kánrin; kí orúkọ rẹ̀ ní ìbísí níwájú oòrùn, kí wọ́n sì máa bù kún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀; kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀. Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu. Ìbùkún sì ni fún orúkọ rẹ̀ ológo fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Àmín àti Àmín.”—Sm. 72:17-19.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni Sáàmù Kejìléláàádọ́rin jẹ́ ká mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú?
• Ta ni Sólómọ́nì Títóbi Jù, báwo sì ni ìṣàkóso rẹ̀ ṣe máa gbòòrò tó?
• Kí ló fa ìwọ fúnra rẹ mọ́ra nínú àwọn ìbùkún tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nínú Sáàmù Kejìléláàádọ́rin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kí ni aásìkí tí àwọn èèyàn gbádùn nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ṣàpẹẹrẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa ká lè jèrè ìyè nínú Párádísè lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù