Aásìkí Lè Dán Igbagbọ Rẹ Wò
AÁSÌKÍ lè dán igbagbọ aduroṣinṣin kan wò. Lilakaka lati di aláásìkí nipa ti ara lè sinni lọ sinu sisọ igbagbọ nù. (1 Timoteu 6:9, 10) Ṣugbọn aásìkí tun lè dán igbagbọ wò ni ọ̀nà miiran. Nigba ti olódodo bá ṣakiyesi pe awọn alaiṣododo pupọ ń láásìkí nipa ti ara nigba ti oun ń jìyà, a lè dán an wò lati lé ipa-ọna alaiwa-bi-Ọlọrun kan. Koda, eyi tilẹ ti sun awọn iranṣẹ Jehofa kan lati ṣiyemeji nipa iniyelori lilepa igbesi-aye aduroṣinṣin!
Eyi ṣẹlẹ si olórin ọmọ Lefi naa Asafu nigba iṣakoso Dafidi ọba Israeli. Asafu ṣakojọ awọn orin ti a lò ninu ijọsin itagbangba. Pẹlu Hemani ati Jedutuni, oun tun sọtẹlẹ pẹlu, ni lilo ohun eelo orin lati fi iyin ati ọpẹ́ fun Jehofa Ọlọrun. (1 Kronika 25:1; 2 Kronika 29:30) Bi o tilẹ jẹ pe Asafu ní anfaani, iwe Orin Dafidi 73 fihàn pe aásìkí nipa ti ara ti awọn eniyan buburu jẹ́ idanwo nla fun igbagbọ rẹ̀.
Awọn Iṣarasihuwa Eléwu ti Asafu
“Nitootọ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti i ṣe aláyà mímọ́. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹẹ yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹrẹẹ yọ̀ tán.” (Orin Dafidi 73:1, 2) Nipasẹ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi, Asafu jẹwọ pe Jehofa ṣe rere fun orilẹ-ede Israeli. Iyẹn ri bẹẹ ni pataki si awọn “ti i ṣe aláyà mímọ́,” nitori pe o jẹ́ ìfẹ́-ọkàn wọn lati fun Ọlọrun ni ijọsin ti a yà sọ́tọ̀ gédégbé ki wọn sì kọwọti iyasimimọ orukọ mímọ́ rẹ̀. Bi a bá ni iṣarasihuwa yẹn, awa yoo yin Jehofa nipa sisọrọ rẹ̀ ni rere àní bi a bá tilẹ dán wa wò nipa aásìkí awọn ẹni buburu pẹlu ẹ̀dùn tabi nipa ipo-ọran eyikeyii miiran.—Orin Dafidi 145:1, 2.
Bi o tilẹ jẹ pe Asafu mọ̀ nipa iṣeun Jehofa, ẹsẹ rẹ̀ fẹrẹẹ yẹ̀ tán kuro ni ipa-ọna òdodo. Ńṣe ni o dabi ẹni pe wọn ń yọ̀ lori ilẹ oníyìnyín nigba eré-ìje ẹlẹ́mì-ẹṣin kan. Eeṣe ti igbagbọ rẹ̀ fi di alailera tobẹẹ? Ó ṣalaye pe: “Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣeféfé, nigba ti mo rí alaafia awọn eniyan buburu. Nitori ti kò si irora ninu iku wọn: agbara wọn sì pọ̀. Wọn kò ni ipin ninu ìyọnu eniyan; bẹẹ ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.”—Orin Dafidi 73:3-5.
Aásìkí nipa ti ara ti awọn alaiṣododo mú ki Asafu ṣe ilara wọn. Ó dabi ẹni pe wọn gbadun igbesi-aye alalaafia, bi o tilẹ jẹ pe wọn kó ọrọ̀ jọ nipasẹ jibiti. (Fiwe Orin Dafidi 37:1.) Laika awọn iṣẹ ibi wọn si, lati inu ìrísí òde wọn ní aabo. Họwu, iwalaaye wọn dabi eyi ti ń dopin laisi awọn ìrora bibanilẹru! Nigba miiran wọn ń ku lalaafia ati pẹlu idara-ẹni loju, laisi ironu kankan fun aini nipa tẹmi. (Matteu 5:3) Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awọn kan ninu awọn iranṣẹ Ọlọrun jiya aisan aronilara ati iku, ṣugbọn oun ń ṣe itilẹhin fun wọn, wọn si ni ireti agbayanu ajinde.—Orin Dafidi 43:1-3; Johannu 5:28, 29.
Ọpọ awọn eniyan buburu kò ni awọn iṣoro ilera ti ń dí wọn lọwọ lati gbadun ipese ounjẹ wọn pupọ yanturu. “Agbara wọn pọ̀,” ikùn wọn ń yọ. Siwaju sii, wọn kò sì “ní ipin ninu ìyọnu eniyan,” nitori laidabi awọn eniyan gbáàtúù, wọn kò nilati sagbara lati rí awọn kòṣeémánìí igbesi-aye. Asafu pari ero nipa awọn eniyan buburu pe “a ko si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.” Ni pataki ni wọn yèbọ́ lọwọ awọn idanwo ti awọn eniyan oniwa-bi-Ọlọrun ń ni iriri rẹ̀ nitori pe awọn ti a mẹnukan gbẹhin yii dìrọ̀ mọ́ awọn ọpa-idiwọn òdodo Jehofa ninu ayé Satani buburu yii.—1 Johannu 5:19.
Nitori pe awọn eniyan buburu ń láásìkì, Asafu ń baa lọ ni sisọ nipa wọn: “Nitori naa ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọ̀n ọ̀ṣọ́; ìwà-ipá bò wọn mọ́lẹ̀ bi aṣọ. Oju wọn yọ jade fun ìsanra: wọn ni ju bi ọkàn wọn ti ń fẹ́ lọ. Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀ buburu niti inilara: wọn ń sọ̀rọ̀ lati ibi giga. Wọn gbé ẹnu wọn lé ọ̀run, ahọn wọn sì ń rin ilẹ̀ já.”—Orin Dafidi 73:6-9.
Awọn oluṣe buburu wọ igberaga bi “ẹ̀wọ̀n,” awọn iṣẹ oniwa-ipa wọn si pọ̀ jọjọ debi pe ‘a fi wọ̀ wọn bi aṣọ.’ Bi wọn ti pinnu lati rìn ní ọ̀nà tiwọn, wọn mọ́ awọn ẹlomiran lójú. Oju awọn eniyan buburu ko kowọnu nitori airi ounjẹ jẹ ṣugbọn ‘ó yọ kòǹgbà nitori ìsanra,’ ti o hàn gbangba nitori ìsanra ti o jẹ́ iyọrisi ounjẹ àjẹkì. (Owe 23:20) Awọn èrò wọn jẹ́ alaṣeyọrisirere debi pe wọn tilẹ “ní ju awọn ìwòye ọkàn-àyà wọn.” Wọn sọrọ nipa jibiti wọn ni ọ̀nà igbeeraga, “lati ibi giga.” Họwu, “wọn gbé ẹnu wọn lé ọ̀run, ahọ́n wọn si ń rin ilẹ já”! Laini ọ̀wọ̀ fun ẹnikẹni ni ọ̀run tabi lori ilẹ̀-ayé, wọn sọrọ buburu si Ọlọrun wọn sì ṣáátá awọn eniyan.
Lọna ti o hàn gbangba, Asafu kò dá wà ninu didi ẹni ti ohun ti o rí ní ipa òdì lori rẹ̀. Ó wi pe: “Nitori naa ni awọn eniyan rẹ̀ ṣe yipada sí ìhín: ọpọlọpọ omi ni a si ń pọn jade fun wọn. Wọn si wi pe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? Ìmọ̀ ha wà ninu Ọga-ogo?” (Orin Dafidi 73:10, 11) Ọ̀rọ̀ Heberu naa lè tumọsi pe nitori pe o dabi ẹni pe awọn eniyan buburu ń láásìkí, awọn kan lara awọn eniyan Ọlọrun tẹwọgba oju-iwoye ti o kuna a sì mu wọn wá si ipo kan-naa gẹgẹ bi awọn alailofin, ni wiwi pe: ‘Ọlọrun kò mọ ohun ti ń ṣẹlẹ oun kì yoo sì huwapada si iwa ailofin.’ Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, riri awọn eniyan buburu ti wọn ń huwa ailofin bi ẹni pe lọna àṣegbé dabi mímu iwọ kikoro kan, eyi ti ń sún aduroṣanṣan lati beere pe: ‘Bawo ni Ọlọrun ṣe faayegba awọn nǹkan wọnyi? Oun kò ha ri ohun ti ń ṣẹlẹ ni bi?
Ní fifi awọn ipo-ọran rẹ̀ wera pẹlu ti awọn eniyan buburu, Asafu sọ pe: “Kiyesi i, awọn wọnyi ni alaiwa-bi-Ọlọrun, ẹni ti ayé ń san, wọn ń pọ̀ ni ọrọ̀. Nitootọ ní asán ni mo wẹ àyà mi mọ́, ti mo si wẹ ọwọ́ mi ni ailẹṣẹ. Nitori pe ni gbogbo ọjọ ni a ń yọ mi lẹnu, a sì ń nà mi ni oroowurọ.” (Orin Dafidi 73:12-14) Asafu nimọlara pe kò wulo lati gbe igbesi-aye iduroṣanṣan. Awọn eniyan buburu ń láásìkí, o ṣeeṣe ‘ki wọn maa pọ̀ ni ọrọ̀’ nipasẹ jibiti. Ó dabi ẹni pe wọn bọ́ lọwọ ifiyajẹni fun iwa ibi tí ó buru julọ, ṣugbọn Asafu ń ni ìyọnu “ní gbogbo ọjọ”—lati ìgbà ti ó bá ti jí titi di ìgbà ti o bá lọ sùn ni alẹ́. Ó nimọlara pe Jehofa ń tọ́ oun sọna ni òròòwúrọ̀. Niwọn bi eyi ti dabi ohun ti kò dara, ó dán igbagbọ Asafu wò.
Atunṣebọsipo kan Ninu Ironu
Nikẹhin ni mímọ̀ pe ironu oun kò tọna, Asafu sọ pe: “Bi emi bá pe, emi o fọ̀ bayii: kiyesi i, emi o ṣẹ̀ si iran awọn ọmọ rẹ. Nigba ti mo rò lati mọ eyi, ó ṣoro ni oju mi, titi mo fi lọ sinu ibi-mímọ́ Ọlọrun; nigba naa ni mo mọ igbẹhin wọn. Nitootọ iwọ gbé wọn ka ibi yíyọ̀: iwọ tì wọn ṣubu sinu iparun. Bawo ni a ti mu wọn lọ sinu idahoro yii, bi ẹni pe ni iṣẹju kan! Ibẹru ni a fi ń run wọn patapata. Bi ìgbà ti ẹnikan bá jí ni oju àlá; bẹẹni Oluwa, nigba ti iwọ bá jí, iwọ ó ṣe abuku aworan wọn.”—Orin Dafidi 73:15-20.
O dara pe Asafu kò ṣaroye, nitori sisọ ni gbangba pe kò wúlò lati ṣiṣẹsin Jehofa ti lè kó irẹwẹsi bá awọn mẹmba idile rẹ̀ olujọsin tabi o ti lè jin igbagbọ wọn lẹsẹ. Ẹ wo bi o ti dara ju tó lati dakẹ ki a sì ṣe ohun ti Asafu ṣe! Lati ri idi tí ó fi dabi ẹni pe awọn eniyan buburu ń mú iwa ibi jẹ ti awọn aduroṣanṣan sì ń jiya, o lọ si ibi mímọ́ Ọlọrun. Ipo ayika yẹn gba Asafu laaye lati farabalẹ ronu laaarin awọn olujọsin Jehofa, ironu rẹ̀ ni a sì tunṣebọsipo. Nitori naa lonii, bi ohun ti a rí bá dà wa láàmú, ẹ jẹ ki awa bakan naa wá awọn idahun si awọn ibeere wa nipa pipejọpọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun dipo yiya araawa láṣo.—Owe 18:1.
Asafu wá mọ̀ pe Ọlọrun gbé awọn eniyan buburu ka “ibi yíyọ̀.” Nitori pe iwalaaye wọn yika awọn ohun ti ara, wọn wà ninu ewu rírí iṣubu ojiji. Ni igbẹhin, iku yoo lé wọn bá ni ọjọ ogbó, ti ọrọ̀ wọn ti wọn fi èrú kojọ kì yoo mu iwalaaye gigun wá fun wọn. (Orin Dafidi 49:6-12) Aásìkí wọn yoo dabi àlà kan ti ń yara kọja lọ. Idajọ òdodo tilẹ lè mú ifaṣẹ-ọba muni wá bá wọn ki ọjọ ogbó wọn tó dé bi wọn ti ń ká ohun ti wọn funrugbin. (Galatia 6:7) Niwọn bi wọn ti mọọmọ dagunla si Ẹni kanṣoṣo naa ti o lè ràn wọn lọwọ, a fi wọn silẹ lailoluranlọwọ, laisi ireti. Nigba ti Jehofa bá huwa lodi si wọn, oun yoo bojuwo “aworan” wọn—ògo ati ipo wọn—pẹlu ẹ̀gàn.
Ṣọ Ihuwapada Rẹ
Bi kò ti huwapada daadaa si ohun ti ó rí, Asafu gba pe: “Bayii ni inu mi bajẹ, ẹ̀gún si gun mi ni ọkàn mi. Bẹẹ ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ nǹkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ. Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigba gbogbo: iwọ ni o ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Iwọ ó fi imọ rẹ tọ́ mi ni ọ̀nà, ati nigbẹhin iwọ ó gbà mi sinu ògo.”—Orin Dafidi 73:21-24.
Rironu nipa aásìkí nipa ti ara ti awọn eniyan buburu ati lori ijiya awọn aduroṣanṣan lè sọ ọkan-aya ẹnikan di kíkan tabi ki o mu ọkan-aya rẹ̀ korò. Ni inu lọ́hùnún—ninu kíndìnrín rẹ̀—agara ti o dá Asafu nipa ipo yii mú irora nla wa bá a. Lati oju iwoye Jehofa, o wá dabi ẹranko alainironu ti ń huwapada nitori iwoye ara ìyára lasan. Sibẹ, Asafu ‘wà pẹlu Ọlọrun nigba gbogbo, ẹni ti o ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú.’ Bi a bá ṣaṣiṣe ninu ironu wa ṣugbọn ti a wá imọran Jehofa bi Asafu ti ṣe, Ọlọrun yoo dì wá ni ọwọ́ mú, lati ti wa lẹhin ki o sì ṣamọna wa. (Fiwe Jeremiah 10:23.) Kiki nipa fifi imọran rẹ̀ silo ni a fi lè ṣamọna wa wọnu ọjọ iwaju alayọ kan. A lè jiya irẹsilẹ fun akoko kan, ṣugbọn Jehofa yoo mu iyipada wá, ‘ni gbígbà wá sinu ògo,’ tabi ọlá.
Bi o ti mọriri aini naa fun igbẹkẹle ninu Jehofa, Asafu fikun un pe: “Ta ni mo ní ní ọ̀run bikoṣe iwọ? Ko sì sí ohun ti mo fẹ́ ni ayé pẹlu rẹ. Ẹran-ara mi ati àyà mi di àárẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata àyà mi, ati ipin mi laelae. Sa wò ó, awọn ti o jìnnà si ọ yoo ṣègbé: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti ń ṣe agbere kirikiri kuro lọdọ rẹ. Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi lé Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o lè maa sọrọ iṣẹ rẹ̀ gbogbo.”—Orin Dafidi 73:25-28.
Gẹgẹ bi Asafu, awa kò ni ẹnikankan bikoṣe Jehofa ẹni ti a nilati gbẹkẹle fun aabo ati itunu tootọ. (2 Korinti 1:3, 4) Nitori naa dipo ṣiṣe ojukokoro awọn ọrọ̀ ori ilẹ̀-ayé ti ẹnikan ni, ẹ jẹ ki a ṣiṣẹsin Ọlọrun ki a sì to awọn iṣura jọ si ọ̀run. (Matteu 6:19, 20) Nini iduro ti o ṣe itẹwọgba pẹlu Jehofa gbọdọ jẹ́ idunnu wa ti o ga julọ. Ani bi eto ara wa ati ọkàn-àyà wa bá nilati kuna, oun óò fun wa lokun yoo si fun ọkàn-àyà wa ni idurodeedee ki a ma baa sọ ireti ati igboya nù ninu ipọnju pupọ. Iwatimọtimọ pẹlu Jehofa jẹ́ ohun-ìní kan ti kò ṣeediyele. Kikọ ọ silẹ yoo yọrisi ijamba fun wa papọ pẹlu gbogbo awọn ti wọn bá kọ̀ ọ́ silẹ. Nitori naa, gẹgẹ bi Asafu, ẹ jẹ́ ki a fà sunmọ Ọlọrun pẹkipẹki ki a sì kó gbogbo aniyan wa lé e. (1 Peteru 5:6, 7) Eyi ń gbe ire ti ẹmi wa larugẹ o si ń sun wa lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa awọn iṣẹ agbayanu Jehofa.
Maa Baa Lọ Pẹlu Iduroṣinṣin si Jehofa
Asafu daamu nitori pe o rí awọn ẹni buburu ti wọn ń láásìkí ni Israeli, ilẹ ibilẹ rẹ̀. Ni aaarin awọn aduroṣinṣin iranṣẹ Jehofa, awọn “eniyan buburu” wà ti wọn jẹ̀bi ìyangàn, igberaga, iwa-ipa, ìkẹ́gàn, ati jibiti, awọn ẹni ti wọn sẹ́ pe Ọlọrun mọ ohun ti wọn ń ṣe. (Orin Dafidi 73:1-11) Ẹ wo iru ikilọ ti eyi jẹ́! Lati tẹ́ Jehofa Ọlọrun lọ́rùn, a nilati yàgò fun fífi ìwà bi igberaga, iwa-ipa, ìkẹ́gàn, ati àìṣòtítọ́ hàn. Bi Asafu, ẹ jẹ́ ki gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa ‘wá sinu ibi-mimọ Ọlọrun titobilọla’ nipa pipejọpọ deedee pẹlu awọn aduroṣanṣan olujọsin Rẹ̀. Niti tootọ, ẹ jẹ́ ki gbogbo awọn ti wọn nifẹẹ Jehofa ‘sunmọtosi Ọlọrun,’ ni gbigbẹkẹle e lati ràn wọn lọwọ ninu awọn ijiya, laika ohun ti awọn miiran lè sọ tabi ṣe si.—Orin Dafidi 73:12-28; 3 Johannu 1-10.
Lotiitọ, aásìkí nipa ti ara ti awọn oluṣe buburu lè dán igbagbọ wa wò, gẹgẹ bi o ti ṣe ti Asafu. Sibẹ, awa lè foriti àdánwò yii bi a bá gbé iwalaaye wa kari iṣẹ-isin Jehofa. A o san èrè fun wa fun ṣiṣe eyi nitori pe ‘Ọlọrun kìí ṣe alaiṣododo ti yoo fi gbagbe iṣẹ wa ati ifẹ ti a fihàn fun orukọ rẹ̀.’ (Heberu 6:10) Awọn àdánwò wa yoo jẹ́ ‘fun igba kukuru yoo sì fúyẹ́’ ni ifiwera pẹlu èrè wa. (2 Korinti 4:17) Àní 70 tabi 80 ọdun ijiya wulẹ dabi kiki afẹfẹ ti ń gba ètè wa kọja ti a bá súfèé bi a bá fiwera pẹlu igbesi-aye ayeraye alayọ ti Jehofa ṣeleri fun awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin.—Orin Dafidi 90:9, 10.
Ǹjẹ́ ki awa maṣe faayegba aásìkí nipa ti ara ti awọn oluṣebuburu ni ifiwera pẹlu awọn ijiya wa nitori ti òdodo lati ṣediwọ fun wa lati ṣaṣefihan igbagbọ naa ti o jẹ́ eso ti ẹmi mimọ Ọlọrun. (Galatia 5:22, 23; 1 Peteru 3:13, 14) Inu Satani yoo dùn bi a bá ṣafarawe awọn ẹni buburu, ti wọn sábà maa ń láásìkí nitori pe wọn jẹ́ alaini iwarere. Kaka bẹẹ, ẹ jẹ́ ki a bọla fun orukọ Jehofa nipa gbigbejako awọn adanwo lati pa awọn ilana òdodo rẹ̀ tì. (Sefaniah 2:3) Ẹ maṣe jẹ ki aṣeyọrisirere awọn oluṣebuburu mu wa rẹwẹsi, nitori pe, pátá-pinrá, wọn lè jere kiki ohun-ìní ti ara nikan. Iniyelori wo sì ni iyẹn ní? Ko tilẹ ni afiwe pẹlu aásìkí tẹmi tí awọn tí wọn ń fi igbagbọ hàn ninu Oluwa Ọba-Alaṣẹ naa Jehofa ní.