“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
“Ọmọ ènìyàn, . . . fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ohun tí èmi yóò fi hàn ọ́ . . . Sọ gbogbo ohun tí ìwọ yóò rí fún ilé Ísírẹ́lì.”—ÌSÍKÍẸ́LÌ 40:4.
1. Ipò wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run bá ara wọn ní ọdún 593 ṣááju Sànmánì Tiwa?
ỌDÚN 593 ṣááju Sànmánì Tiwa ni, ọdún kẹrìnlá tí Ísírẹ́lì ti wà nígbèkùn. Lójú àwọn Júù tí ń gbé ní Bábílónì, ìlú wọn tí ń dá wọn lọ́rùn, ti ní láti dà bí ibi tó jìnnà réré. Nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú wọn rí Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn, iná ló ń jó lala nínú rẹ̀, tí ògiri rẹ̀ gìrìwògiriwo wó palẹ̀, tí àwọn ilé àwòyanu tí ń bẹ nínú rẹ̀ sì di òkìtì àlàpà. Tẹ́ńpìlì Jèhófà—tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ adé ògo ìlú ńlá náà, ibi ìkóríjọ kan ṣoṣo tó wà fún ìjọsìn mímọ́ gaara ní gbogbo ilẹ̀ ayé—ti wó palẹ̀ bẹẹrẹbẹ. Wàyí o, èyí tí ó pọ̀ jù nínú ọdún tí Ísírẹ́lì yóò lò nígbèkùn ṣì wà níwájú. Ó ṣì ku ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta kí ìlérí nípa ìdáǹdè tó lè ṣẹ.—Jeremáyà 29:10.
2. Èé ṣe tí rírántí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù ti lè ba Ìsíkíẹ́lì lọ́kàn jẹ́?
2 Ó dájú pé ríronú kan tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tó wà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà sí ibi tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì olóòótọ́ wà báyìí, pé ó ti di àlàpà, tí ó sì ti di ahoro níbi tí àwọn ẹranko ẹhànnà ti ń jẹ̀, ti ní láti bà á lọ́kàn jẹ́. (Jeremáyà 9:11) Búúsì, baba tó bí i lọ́mọ, ti sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà níbẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 1:3) Ìsíkíẹ́lì pẹ̀lú ì bá ti gbádùn àǹfààní kan náà, ṣùgbọ́n a ti mú un nígbèkùn pẹ̀lú àwọn ọ̀tọ̀kùlú Jerúsálẹ́mù ní ọdún 617 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́. Ó ṣeé ṣe kí Ìsíkíẹ́lì tí ó tó ẹni nǹkan bí àádọ́ta ọdún báyìí mọ̀ pé òun kò tún ní fojú kan Jerúsálẹ́mù mọ́, ká má tilẹ̀ wá sọ pé kí òun wá kópa èyíkéyìí nínú títún tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́. Wá fojú inú wo bí ìmọ̀lára Ìsíkíẹ́lì yóò ti rí láti rí ìran nípa tẹ́ńpìlì ológo kan!
3. (a) Kí ni ète tí a fi fi ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí hàn án? (b) Apá pàtàkì mẹ́rin wo ni ìran náà ní?
3 Ìran gbígbòòrò yìí, tí ó kún orí mẹ́sàn-án nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, pèsè ìlérí afúngbàgbọ́-lókun fún àwọn ará Jùdíà tó wà nígbèkùn. Dájúdájú, a ó mú ìjọsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò! Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún láti ìgbà náà wá, àní títí di òní olónìí pàápàá, ìran yìí ti jẹ́ orísun ìṣírí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí ìran alásọtẹ́lẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn. Ìran náà ní apá mẹ́rin pàtàkì: tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà, ìjòyè, àti ilẹ̀ náà.
A Mú Tẹ́ńpìlì Náà Padà Bọ̀ Sípò
4. Ibo ni a mú Ìsíkíẹ́lì lọ nígbà tí ìran náà bẹ̀rẹ̀, kí ló sì rí níbẹ̀, ta ló sì mú un rìn yíká?
4 Lákọ̀ọ́kọ́, a mú Ìsíkíẹ́lì lọ sí “òkè ńlá kan tí ó ga gan-an.” Tẹ́ńpìlì jìmọ̀wò kan tó dà bí ìlú olódi wà níhà gúúsù òkè ńlá náà. Áńgẹ́lì kan tí “ìrísí rẹ̀ dà bí ìrísí bàbà” mú wòlíì náà lọ yí ká gbogbo àgbègbè ilé náà. (Ìsíkíẹ́lì 40:2, 3) Bí ìran náà ti ń tẹ̀ síwájú, Ìsíkíẹ́lì rí áńgẹ́lì náà tí ń fara balẹ̀ wọn ẹnubodè mẹ́ta dídọ́gba ti tẹ́ńpìlì náà pẹ̀lú ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ wọn, àgbàlá òde, àgbàlá inú, àwọn yàrá ìjẹun, pẹpẹ, ibùjọsìn tẹ́ńpìlì pẹ̀lú àwọn Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ rẹ̀.
5. (a) Ìdánilójú wo ni Jèhófà fún Ìsíkíẹ́lì? (b) Kí ni “òkú àwọn ọba” tí a ní láti gbé kúrò nínú tẹ́ńpìlì, èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì?
5 Lẹ́yìn náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ fara hàn nínú ìran náà. Ó wọnú tẹ́ńpìlì náà, ó sì mú un dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé ibẹ̀ ni Òun yóò máa gbé. Ṣùgbọ́n Ó ní kí a sọ ilé òun di mímọ́, ó sọ pé: “Kí wọ́n mú àgbèrè wọn àti òkú àwọn ọba wọn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nísinsìnyí, dájúdájú, èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Ìsíkíẹ́lì 43:2-4, 7, 9) Ẹ̀rí fi hàn pé “òkú àwọn ọba wọn” wọ̀nyí ń tọ́ka sí àwọn òrìṣà. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ alákòóso Jerúsálẹ́mù àti àwọn ará ìlú ọ̀hún ti fi òrìṣà sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run di ẹlẹ́gbin, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ àwọn òrìṣà di ọba wọn. (Fi wé Ámósì 5:26.) Ó dájú pé àwọn òrìṣà wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run tí ó wà láàyè, òkú ọlọ́run ni wọ́n, nǹkan ẹ̀gbin lójú Jèhófà. A gbọ́dọ̀ mú wọn kúrò.—Léfítíkù 26:30; Jeremáyà 16:18.
6. Kí ni wíwọn tẹ́ńpìlì náà dúró fún?
6 Kí ni kókó ohun tó wà nínú apá yìí nínú ìran náà? Ó mú un dá àwọn tó wà nígbèkùn lójú pé, a óò mú ìjọsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run. Síwájú sí i, wíwọn tẹ́ńpìlì náà fúnni ní ìdánilójú àtọ̀runwá pé dájúdájú ìran náà yóò ní ìmúṣẹ. (Fi wé Jeremáyà 31:39, 40; Sekaráyà 2:2-8.) Gbogbo ìbọ̀rìṣà pátá ni a óò mú kúrò. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà yóò bù kún ilé rẹ̀.
Àwọn Àlùfáà àti Ìjòyè
7. Ìsọfúnni wo ni a pèsè nípa àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà?
7 Àwọn àlùfáà pẹ̀lú ni a óò sọ di mímọ́, tàbí kí a yọ́ wọn mọ́. A óò bá àwọn ọmọ Léfì wí fún lílọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, ṣùgbọ́n a óò gbóríyìn fún àwọn ọmọ Sádókù tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, a óò sì san èrè fún wọn fún bíbá a nìṣó láti wà ní mímọ́.a Síbẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yóò ní ipò iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run tí a ti mú padà bọ̀ sípò—àmọ́ ṣá o, èyí yóò sinmi lórí ìṣòtítọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Síwájú sí i, Jèhófà pàṣẹ pé: “Kí wọ́n . . . fún àwọn ènìyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ láàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́; kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tí ó mọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 44:10-16, 23) Nítorí náà, a óò mú àwọn àlùfáà padà bọ̀ sípò, a óò sì san èrè fífaradà tí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ fara dà á fún wọn.
8. (a) Àwọn wo ni ìjòyè ní Ísírẹ́lì ìgbàanì? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni ìjòyè inú ìràn tí Ìsíkíẹ́lì rí fi gbà jẹ́ ẹni tó kógìírí mọ́ ọ̀ràn ìjọsìn mímọ́ gaara?
8 Ìran náà tún sọ nípa ẹnì kan tí a pè ní ìjòyè. Láti ìgbà ayé Mósè ni orílẹ̀-èdè náà ti máa ń ní ìjòyè. Ọ̀rọ̀ Hébérù fún ìjòyè, na·siʼʹ, lè tọ́ka sí olórí ilé baba, olórí ẹ̀yà, tàbí ti orílẹ̀-èdè pàápàá. Nínú ìran Ìsíkíẹ́lì, a bá àwọn olùṣàkóso Ísírẹ́lì wí fún níni àwọn ènìyàn lára, a sì ṣí wọn létí pé kí wọ́n jẹ́ aláìṣègbè àti onídàájọ́ òdodo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjòyè náà kò sí nínú ẹgbẹ́ àlùfáà, ó jẹ́ ẹni tó kógìírí mọ́ ọ̀ràn ìjọsìn mímọ́ gaara. Ó ń bá àwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe àlùfáà wọnú àgbàlá òde, ó sì ń bá wọn jáde, ó máa ń jókòó sí gọ̀bì Ẹnubodè Ìlà-Oòrùn, ó sì ń pèsè díẹ̀ lára àwọn ọrẹ ẹbọ tí àwọn èèyàn yóò rú. (Ìsíkíẹ́lì 44:2, 3; 45:8-12, 17) Nípa bẹ́ẹ̀, ìran náà mú un dá àwọn ènìyàn Ìsíkíẹ́lì lójú pé orílẹ̀-èdè tí a ti mú padà bọ̀ sípò náà ni a óò fi àwọn aṣáájú tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ bù kún, àwọn ọkùnrin tí yóò ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àlùfáà nípa ṣíṣètò àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí wọn yóò sì jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí.
Ilẹ̀ Náà
9. (a) Báwo ni wọn yóò ṣe pín ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ta ni kò ní gba ogún? (b) Kí ni ọrẹ mímọ́, kí ló sì wà nínú rẹ̀?
9 Níkẹyìn, ìran Ìsíkíẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì lápapọ̀ nínú. A óò pín in, ìpín kan fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìjòyè pẹ̀lú yóò ní ogún. Ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà kì yóò ní, nítorí tí Jèhófà sọ pé, “Èmi ni ogún wọn.” (Ìsíkíẹ́lì 44:10, 28; Númérì 18:20) Ìran náà fi hàn pé ilẹ̀ tí a óò pín fún àwọn ìjòyè yóò wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì àgbègbè àkànṣe kan tí a pè ní ọrẹ mímọ́. Èyí jẹ́ ilẹ̀ kan tí ó dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí a pín sí ilẹ̀ tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ mẹ́ta—apá òkè wà fún àwọn ọmọ Léfì tí ó ronú pìwà dà, ti àárín wà fún àwọn àlùfáà, apá ìsàlẹ̀ wà fún ìlú ńlá náà àti ilẹ̀ rẹ̀ tí ń méso jáde. Tẹ́ńpìlì Jèhófà yóò wà nínú ilẹ̀ tẹ́ẹ́rẹ́ ti àwọn àlùfáà, ní àárín gbùngbùn ọrẹ tí ó dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.—Ìsíkíẹ́lì 45:1-7.
10. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ náà nípa pípín ilẹ̀ náà túmọ̀ sí fún àwọn ará Jùdíà tó wà nígbèkùn?
10 Ẹ wo bí gbogbo èyí yóò ti mú inú àwọn tí ó wà nígbèkùn dùn tó! A mú un dá ìdílé kọ̀ọ̀kan lójú pé yóò ní ogún ní ilẹ̀ náà. (Fi wé Míkà 4:4.) Ìjọsìn mímọ́ gaara yóò wà ní ibi gíga, tó wà ní àárín gbùngbùn. Sì kíyè sí i pé nínú ìran Ìsíkíẹ́lì àwọn ìjòyè náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà, yóò máa gbé lórí ilẹ̀ tí àwọn ènìyàn náà fi tọrẹ. (Ìsíkíẹ́lì 45:16) Nítorí náà, nínú ilẹ̀ tí a ti mú padà bọ̀ sípò yìí, àwọn ènìyàn yóò máa ṣèrànwọ́ fún iṣẹ́ àwọn tí Jèhófà ti yàn láti mú ipò iwájú, wọ́n yóò máa kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà wọn. Látòkè délẹ̀, ilẹ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣètò, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àti ààbò tí ó ga lọ́lá.
11, 12. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe lo àsọtẹ́lẹ̀ láti fi mú un dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú pé òun yóò bù kún ìlú ìbílẹ̀ wọn tí a mú padà bọ̀ sípò? (b) Kí ni àwọn igi tó wà ní bèbè odò náà ṣàpẹẹrẹ?
11 Jèhófà yóò ha bù kún ilẹ̀ wọn bí? Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi àpèjúwe amọ́kànyọ̀ dáhùn ìbéèrè yìí. Omi kan ń ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì, bí ó ti ń ṣàn lọ, bẹ́ẹ̀ ló ń gbòòrò sí i, ó sì ti di ọ̀gbàrá nígbà tó fi máa wọnú Òkun Òkú. Nígbà tí ó ṣàn débẹ̀, ó mú kí omi tí kò sí ohun alààyè kankan nínú rẹ̀ sọ jí, iṣẹ́ òwò ẹja sì gbèrú lẹ́bàá èbúté gbígbòòrò náà. Ọ̀pọ̀ igi tí ń so èso yípo ọdún, tí èso rẹ̀ ń ṣara lóore, tí ó sì ń woni sàn, wà lẹ́bàá odò náà.—Ìsíkíẹ́lì 47:1-12.
12 Fún àwọn ìgbèkùn náà, ìlérí yìí ṣàtúnsọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò tí wọ́n ṣìkẹ́, tí a ti sọ ṣáájú, ó sì fìdí àwọn ìlérí náà múlẹ̀. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí àwọn wòlíì Jèhófà tí a mí sí ti fi àwọn ipò bí ti Párádísè ṣàpèjúwe Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀ sípò, tí àwọn ènìyàn tún ti ń gbé inú rẹ̀. Àwọn àgbègbè tó ti dahoro tẹ́lẹ̀ tó sì tún ti bẹ̀rẹ̀ sí kún fún ìgbòkègbodò ti jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a ń sọ léraléra. (Aísáyà 35:1, 6, 7; 51:3; Ìsíkíẹ́lì 36:35; 37:1-14) Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà lè retí pé àwọn ìbùkún Jèhófà tí ń fúnni ní ìyè yóò máa ṣàn wá gẹ́gẹ́ bí odò láti inú tẹ́ńpìlì tí a ti mú padà bọ̀ sípò. Nítorí èyí, orílẹ̀-èdè tí ó ti kú nípa tẹ̀mí yóò sọ jí. A óò fi àwọn ọkùnrin tẹ̀mí tí ó tayọ bù kún àwọn ènìyàn tí a ti mú padà bọ̀ sípò—àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olódodo tí wọ́n sì dúró ṣinṣin bí àwọn igi tí ó wà lẹ́bàá odò inú ìran yẹn, àwọn ọkùnrin tí yóò mú ipò iwájú nínú títún ilẹ̀ tí ó ti di ahoro kọ́. Aísáyà pẹ̀lú ti kọ̀wé nípa àwọn “igi ńlá òdodo” tí yóò “tún àwọn ibi ìparundahoro tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ kọ́.”—Aísáyà 61:3, 4.
Nígbà Wo Ni Ìran Náà Nímùúṣẹ?
13. (a) Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà lo àwọn “igi ńlá òdodo” láti bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a mú padà bọ̀ sípò? (b) Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Òkun Òkú ṣẹ?
13 A ha já àwọn òǹdè tí ó padà wá kulẹ̀ bí? Rárá o! Ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn àṣẹ́kù tí a mú bọ̀ sípò, padà sí ilẹ̀ wọn tí ń dá wọn lọ́rùn. Bí àkókò ti ń lọ, lábẹ́ ìdarí àwọn “igi ńlá òdodo” wọ̀nyí—àwọn bí Ẹ́sírà akọ̀wé òfin, wòlíì Hágáì àti Sekaráyà, àti Jóṣúà Àlùfáà Àgbà—a tún àwọn ibi tí a ti sọ dahoro tipẹ́tipẹ́ kọ́. Àwọn ìjòyè, bí àpẹẹrẹ Nehemáyà àti Serubábélì, fi ẹ̀tọ́ àti òdodo ṣàkóso ní ilẹ̀ náà. A mú tẹ́ńpìlì Jèhófà padà bọ̀ sípò, àwọn ìpèsè tí ó ṣe fún ìyè—àwọn ìbùkún gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú májẹ̀mú rẹ̀—sì tún ṣàn jáde lẹ́ẹ̀kan sí i. (Diutarónómì 30:19; Aísáyà 48:17-20) Ìmọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ìbùkún náà. A dá àwọn àlùfáà padà sẹ́nu iṣẹ́, àwọn àlùfáà sì fi Òfin kọ́ àwọn ènìyàn. (Málákì 2:7) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn ènìyàn náà sọ jí nípa tẹ̀mí, wọ́n sì tún di ìránṣẹ́ Jèhófà tí ń méso jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti fi Òkun Òkú tí a wò sàn, tí ó sì di ibi iṣẹ́ òwò ẹja tí ń gbèrú, ṣàpẹẹrẹ rẹ̀.
14. Èé ṣe tí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì yóò fi ní ìmúṣẹ lọ́nà tó ju ti ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn Júù padà láti ìgbèkùn Bábílónì?
14 Ṣé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni kìkì ìmúṣẹ ìran Ìsíkíẹ́lì ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́; ó tún ń tọ́ka sí ohun tí ó tóbi ju èyí lọ. Gbé èyí yẹ̀ wò: Kò ṣeé ṣe láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀. Lóòótọ́, àwọn Júù fọwọ́ pàtàkì mú ìran yẹn, àní wọ́n tilẹ̀ lo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí gan-an nínú ìran náà.b Ṣùgbọ́n, tẹ́ńpìlì inú ìran náà tóbi débi pé Òkè Ńlá Mòráyà, ibi tí tẹ́ńpìlì ti tẹ́lẹ̀ wà, kò tilẹ̀ lè gbà á. Ní àfikún sí i, tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí kò sí nínú ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n ó wà lókèèrè lórí abá ilẹ̀ ọ̀tọ̀, nígbà tí ó sì jẹ́ pé orí ilẹ̀ tí tẹ́ńpìlì àkọ́kọ́ wà gan-an ní ìlú Jerúsálẹ́mù ni a kọ́ tẹ́ńpìlì ti èkejì sí. (Ẹ́sírà 1:1, 2) Síwájú sí i, kò sí odò gidi kan tí ó ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, kìkì díẹ̀ táṣẹ́rẹ́ ni Ísírẹ́lì ìgbàanì rí nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì. Èyí túmọ̀ sí pé ìmúṣẹ ìran yìí lọ́nà títóbi jù, tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, ní láti wà.
15. (a) Nígbà wo ni tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́? (b) Kí ló fi hàn pé ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí kò nímùúṣẹ nígbà tí Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé?
15 Ní kedere, a ní láti yíjú sí ìmúṣẹ pàtàkì ìran Ìsíkíẹ́lì tó dá lórí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi jù ti Jèhófà, èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jíròrò ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nínú ìwé Hébérù. Tẹ́ńpìlì yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà tí a fòróró yan Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà tẹ́ńpìlì náà ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, ìran Ìsíkíẹ́lì ha ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ Jésù bí? Ó hàn kedere pé kò rí bẹ́ẹ̀. Jésù, gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà mú ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ọjọ́ Ètùtù ṣẹ nípasẹ̀ batisí rẹ̀, ikú ìrúbọ tí ó kú, àti wíwọ̀ tí ó wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ, tí í ṣe ọ̀run gan-an lọ. (Hébérù 9:24) Ṣùgbọ́n, lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, ìran Ìsíkíẹ́lì kò mẹ́nu kan yálà àlùfáà àgbà tàbí Ọjọ́ Ètùtù rárá. Nítorí náà, kò jọ pé ìran yìí ń tọ́ka sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Bó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, àkókò wo ni ó ń tọ́ka sí?
16. Àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn wo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí rán wa létí rẹ̀, báwo sì ni èyí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ ìgbà tí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nímùúṣẹ ní ti gidi?
16 Láti rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ kí a padà lọ sínú ìran náà fúnra rẹ̀. Ìsíkíẹ́lì kọ̀wé pé: “Nínú àwọn ìran ti Ọlọ́run, ó mú mi wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbé mi kalẹ̀ sórí òkè ńlá kan tí ó ga gan-an, lórí èyí tí ohun kan wà tí ó ní ìrísí ìlú ńlá níhà gúúsù.” (Ìsíkíẹ́lì 40:2) Orí “òkè ńlá kan tí ó ga gan-an,” tí a ti rí ìran yìí, rán wa létí ohun tí ó wà nínú Míkà 4:1, tí ó sọ pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀.” Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ? Míkà 4:5 fi hàn pé èyí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. Ní tòótọ́, ní àkókò tiwa ni, ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ni a gbé ìjọsìn mímọ́ gaara ga, tí a dá a padà sí àyè tí ó yẹ ẹ́ nínú ìgbésí ayé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
17. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Málákì 3:1-5 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ìgbà tí tẹ́ńpìlì tó wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yóò di èyí tí a fọ̀ mọ́?
17 Kí ni ó mú ìmúpadàbọ̀sípò yìí ṣeé ṣe? Rántí, nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì, ó sì fi dandan lé e pé kí a mú ìbọ̀rìṣà kúrò nínú ilé òun. Ìgbà wo ni a sọ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Ọlọ́run di mímọ́? Nínú Málákì 3:1-5, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí òun yóò “wá sí tẹ́ńpìlì [Òun],” tí Jésù Kristi “ońṣẹ́ májẹ̀mú” rẹ̀ yóò sì bá a wá. Fún ète wo? “Òun yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ọṣẹ ìfọṣọ alágbàfọ̀.” Ìyọ́mọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Kí ni àbájáde rẹ̀? Jèhófà ti ń gbé inú ilé rẹ̀, láti ọdún 1919 síwájú ló sì ti ń bù kún ilẹ̀ tẹ̀mí tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn rẹ̀. (Aísáyà 66:8) Nígbà náà, a lè parí èrò sí pé àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa tẹ́ńpìlì ní ìmúṣẹ pàtàkì ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.
18. Ìgbà wo ni ìran tẹ́ńpìlì náà yóò ní ìmúṣẹ ìkẹyìn rẹ̀?
18 Gẹ́gẹ́ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò yòókù, ìran Ìsíkíẹ́lì yóò tún ní ìmúṣẹ síwájú sí i, ìmúṣẹ tí ó kẹ́yìn, nínú Párádísè. Ìgbà yẹn nìkan ni ìran ènìyàn ọlọ́kàn títọ́ yóò tó jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní ìṣètò tẹ́ńpìlì Ọlọ́run. Kristi yóò wá lo ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ ọ̀run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Gbogbo ènìyàn onígbọràn tí wọ́n jẹ́ ọmọ abẹ́ ìṣàkóso Kristi ni a óò wá sọ di ẹni pípé. (Ìṣípayá 20:5, 6) Àmọ́ ṣá o, kò lè jẹ́ inú Párádísè ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ìran Ìsíkíẹ́lì yóò ní ìmúṣẹ. Èé ṣe tí kò fi rí bẹ́ẹ̀?
Ìran Náà Darí Àfiyèsí sí Ọjọ́ Tiwa Gan-an
19, 20. Èé ṣe tí ìmúṣẹ pàtàkì ìran náà fi gbọ́dọ̀ wáyé lónìí, tí kò fi ní jẹ́ nínú Párádísè?
19 Ìsíkíẹ́lì rí tẹ́ńpìlì kan tí ó yẹ kí a mú ìbọ̀rìṣà àti àgbèrè nípa tẹ̀mí kúrò níbẹ̀ pátápátá. (Ìsíkíẹ́lì 43:7-9) Dájúdájú èyí kò lè ní ìmúṣẹ sí ìjọsìn Jèhófà nínú Párádísè. Síwájú sí i, àwọn àlùfáà inú ìran yìí ń ṣàpẹẹrẹ ẹgbẹ́ àlùfáà tí a fòróró yàn nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe lẹ́yìn àjíǹde wọn sí ọ̀run tàbí nígbà Ẹgbẹ̀rúndún. Èé ṣe? Ṣàkíyèsí pé a ṣàpèjúwe àwọn àlùfáà náà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń sìn nínú àgbàlá inú. Àwọn àpilẹ̀kọ tó jáde nínú àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ tó ti kọjá ti fi hàn pé àgbàlá yìí ṣàpẹẹrẹ ìdúró aláìlẹ́gbẹ́ nípa tẹ̀mí ti àwọn àlùfáà ọmọ abẹ́ Kristi nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé.c Kíyè sí i pẹ̀lú pé ìran yìí tẹnu mọ́ ọn pé àwọn àlùfáà náà jẹ́ aláìpé. A sọ fún wọn pé kí wọ́n rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn. A kìlọ̀ fún wọn nípa ewu tí ó wà nínú dídi aláìmọ́—nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà híhù. Nítorí náà, wọn kò ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró tí a ti jí dìde, àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa wọn pé: “Kàkàkí yóò dún, a ó sì gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:52; Ìsíkíẹ́lì 44:21, 22, 25, 27) Àwọn àlùfáà inú ìran Ìsíkíẹ́lì dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń sìn wọ́n ní tààrà. Èyí kò ní rí bẹ́ẹ̀ nínú Párádísè, nígbà tí ẹgbẹ́ àlùfáà náà yóò ti wà ní ọ̀run. Nítorí náà, lọ́nà tí ó tayọ, ìran yìí ṣàpẹẹrẹ bí àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lórí ilẹ̀ ayé lónìí.—Ìṣípayá 7:9; Ìsíkíẹ́lì 42:14.
20 Nípa báyìí, ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ń tọ́ka sí ìyọrísí gbígbámúṣé ní ti ìwẹ̀nùmọ́ nípa tẹ̀mí tí ń lọ lọ́wọ́ lónìí. Ṣùgbọ́n, kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún ọ? Èyí kì í kàn-án ṣe àdììtú ẹ̀kọ́ ìsìn tí kò gbin èrò kan pàtó síni lọ́kàn. Ìran yìí ní í ṣe gan-an pẹ̀lú bí o ti ń jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà, lójoojúmọ́. A óò rí i bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí ti lè jẹ́ ìwúrí fún Ìsíkíẹ́lì alára, nítorí a sọ pé òun fúnra rẹ̀ jẹ́ ìdílé àlùfáà Sádókù.
b Bí àpẹẹrẹ, ìwé Mishnah ìgbàanì sọ pé a kọ́ pẹpẹ, àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì ti tẹ́ńpìlì, àti àgbègbè tí a ti ń dáná sí inú tẹ́ńpìlì tí a mú padà bọ̀ sípò náà lọ́nà tó bá ìran Ìsíkíẹ́lì mu.
c Wo Ilé-Ìṣọ́nà, July 1, 1996, ojú ìwé 16; August 15, 1973, ojú ìwé 494 sí 495.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ti ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí àti ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀?
◻ Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa bí wọ́n ṣe pín ilẹ̀ náà ṣe ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́?
◻ Nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn wo ló ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjòyè olóòótọ́, àwọn wo ló sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn “igi ńlá ti òdodo”?
◻ Èé ṣe tí ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fi ní ìmúṣẹ pàtàkì ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?