Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
NÍ ỌDÚN 613 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Jeremáyà wà ní Júdà, ó ń fìgboyà kéde ìparun Jerúsálẹ́mù àti ìsọdahoro ilẹ̀ Júdà tó kù sí dẹ̀dẹ̀. Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti kó ọ̀pọ̀ àwọn Júù lọ sígbèkùn lákòókò yẹn. Dáníẹ́lì tó jẹ́ ọ̀dọ́ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ààfin àwọn ará Kálídíà, wà lára àwọn tó kó nígbèkùn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù tó kó nígbèkùn yìí ló ń gbé nítòsí odò Kébárì ní “ilẹ̀ àwọn àrá Kálídíà.” (Ìsíkíẹ́lì 1:1-3) Jèhófà ò fi àwọn tó wà nígbèkùn yẹn sílẹ̀, ó ń rán ońṣẹ́ sí wọn. Ó yan Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún gẹ́gẹ́ bí wòlíì.
Ọdún 591 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ìsíkíẹ́lì kọ ìwé rẹ̀ tán. Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún méjìlélógún ló sì wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ìsíkíẹ́lì fara balẹ̀ kọ ìwé rẹ̀. Ó kọ ìgbà tó sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kódà ó mẹ́nu kan ọjọ́, oṣù, títí kan ọdún pàápàá. Apá àkọ́kọ́ ìwé Ìsíkíẹ́lì dá lórí ìṣubú àti ìparun Jerúsálẹ́mù. Ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa mú wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè tó yìí Jerúsálẹ́mù ká ló wà nínú apá kejì, nígbà tí apá tó kẹ́yìn dá lórí fífi ìdí ìjọsìn Jèhófà múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì látinú Ìsíkíẹ́lì 1:1–24:27, tó ní àwọn ìran nínú, àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀, àti fífara ṣàpèjúwe àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù.
“OLÙṢỌ́ NI MO FI Ọ́ ṢE”
Lẹ́yìn tí Jèhófà ti fi ìran tó jẹ́ àgbàyanu nípa ìtẹ́ rẹ̀ han Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà wá sọ iṣẹ́ tó máa ṣe fún un. Jèhófà sọ fún un pé: “Olùṣọ́ ni mo fi ọ́ ṣe fún ilé Ísírẹ́lì, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu mi, kí o sì kìlọ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ mi.” (Ìsíkíẹ́lì 3:17) Kí Ìsíkíẹ́lì lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa sàga ti Jerúsálẹ́mù àti ipa tíyẹn máa ní lórí ìlú náà, Jèhófà sọ fún un pé kó fara ṣàpèjúwe méjì lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ Júdà, ó tipasẹ̀ Ìsíkíẹ́lì sọ pé: “Èmi rèé! Èmi yóò mú idà wá sórí yín, èmi yóò sì pa àwọn ibi gíga yín run dájúdájú.” (Ìsíkíẹ́lì 6:3) Ó sọ fún àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà pé: “Òdòdó ẹ̀yẹ [ìyẹn àjálù] gbọ́dọ̀ wá bá ọ.”—Ìsíkíẹ́lì 7:7.
Lọ́dún 612 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ísíkíẹ́lì rí ìran kan tó ti bá ara rẹ̀ nílùú Jerúsálẹ́mù. Àwọn ohun ìríra tó rí tó ń ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run mà burú jáì o! Nígbà tí Jèhófà bá rán àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó máa mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ (ìyẹn àwọn tí “ọkùnrin mẹ́fà” ṣàpẹẹrẹ wọn) láti mú ìbínú rẹ̀ wá sórí àwọn apẹ̀yìndà, kìkì àwọn tó ti gba ‘àmì sí iwájú orí wọn’ nìkan ló máa yè bọ́. (Ìsíkíẹ́lì 9:2-6) Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ná, “ẹyín iná,” ìyẹn ìkéde ìdájọ́ ìparun mímúná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wá sórí ìlú náà. (Ìsíkíẹ́lì 10:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘Jèhófà yóò mú ọ̀nà àwọn ẹni ibi wá sórí wọn,’ ó ṣèlérí pé òun yóò padà kó àwọn tó fọ́n káàkiri lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ.—Ìsíkíẹ́lì 11:17-21.
Ẹ̀mí Ọlọ́run mú Ísíkíẹ́lì padà wá sí Kálídíà. Àṣefihàn kan fi bí Sedekáyà Ọba àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣe máa sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù hàn. Àwọn wòlíì èké lọ́kùnrin lóbìnrin di ẹni ìfibú. Àwọn abọ̀rìṣà di ẹni ìtanù. Ó fi ilẹ̀ Júdà wé àjàrà tí kò ní láárí. Àlọ́ tó sọ nípa ẹyẹ idì àti àjàrà fi hàn pé ohun búburú jáì ló máa tẹ̀yìn ìrànlọ́wọ́ tí Jerúsálẹ́mù wá lọ sí Íjíbítì jáde. Ìlérí náà pé ‘Jèhófà yóò tún ọ̀jẹ̀lẹ́ ẹ̀ka igi kan gbìn sórí òkè ńlá kan’ ló parí àlọ́ náà. (Ìsíkíẹ́lì 17:22) Àmọ́, kò ní “sí ọ̀pá aládé fún ṣíṣàkóso mọ́” ní Júdà.—Ìsíkíẹ́lì 19:14.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:4-28—Kí ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? Kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ṣàpẹẹrẹ apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ olóòótọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni orísun agbára ètò rẹ̀ yìí. Ẹni tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà, tó ṣàpẹẹrẹ Jèhófà, ní ògo lọ́nà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Ìparọ́rọ́ rẹ̀ la sì fi wé òṣùmàrè kan tó fani mọ́ra.
1:5-11—Àwọn wo ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà? Nínú ìran kejì tí Ísíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run, ó sọ pé àwọn kérúbù làwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà. (Ìsíkíẹ́lì 10:1-11; 11:22) Nínú àpèjúwe tó ṣe lẹ́yìn ìyẹn, ó pe ojú akọ màlúù ní “ojú kérúbù.” (Ìsíkíẹ́lì 10:14) Èyí bá a mú wẹ́kú nítorí pé akọ màlúù ṣàpẹẹrẹ agbára àti okun, àwọn kérúbù sì jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tó lágbára gan-an.
2:6—Kí nìdí tó fi jẹ́ pé léraléra ni Bíbélì pe Ísíkíẹ́lì ní “ọmọ ènìyàn”? Jèhófà pe Ísíkíẹ́lì bẹ́ẹ̀ kó lè rán wòlíì náà létí pé ẹlẹ́ran ara ni, kíyẹn sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ ńlá tó wà láàárín ońṣẹ́ tó jẹ́ èèyàn àti Ọlọ́run tó fún un ní iṣẹ́ náà. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ni wọ́n lò fún Jésù Kristi ní nǹkan bí ọgọ́rin ìgbà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, tó fi hàn gbangba pé Ọmọ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí èèyàn, kì í ṣe bí áńgẹ́lì kan tó gbé ara èèyàn wọ̀.
2:9–3:3—Kí nìdí tí àkájọ ìwé tí wọ́n kọ orin arò àti ìkédàárò sí ṣe dùn mọ́ Ísíkíẹ́lì lẹ́nu? Ohun tó mú kí àkájọ ìwé náà dùn mọ́ Ísíkíẹ́lì lẹ́nu ni ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Inú Ísíkíẹ́lì dùn gan-an láti jẹ́ wòlíì Jèhófà.
4:1-17—Ṣé lóòótọ́ ni Ísíkíẹ́lì ṣe àṣefihàn bí àwọn ọ̀tá ṣe máa sàga ti Jerúsálẹ́mù? Bí Ísíkíẹ́lì ṣe bẹ̀bẹ̀ láti yí ohun tí Ọlọ́run ní kó fi dáná padà tí Jèhófà sì gbà fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ fi hàn pé lóòótọ́ ni wòlíì náà ṣe àṣefihàn ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Bí Ísíkíẹ́lì ṣe fi ẹgbẹ́ òsì dùbúlẹ̀ dúró fún àṣìṣe tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ṣe fún irínwó ó dín mẹ́wàá [390] ọdún, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí dìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó sì ṣe fi ẹgbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ dúró fún ogójì ọdún tí Júdà fi dẹ́ṣẹ̀, èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti àkókò tí Ọlọ́run yan Jeremáyà sípò wòlíì lọ́dún 647 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Oúnjẹ díẹ̀ ni Ísíkíẹ́lì jẹ ní gbogbo irínwó ó lé ọgbọ̀n [430] ọjọ́ yẹn ìwọ̀nba omi díẹ̀ ló sì mu, èyí sì fi hàn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé ìyàn máa mú nígbà táwọn ọ̀tá bá sàga ti Jerúsálẹ́mù.
5:1-3—Kí ni ìtúmọ̀ mímú tí Ísíkíẹ́lì mú díẹ̀ lára irun tí wọ́n ní kó tú ká sínú ẹ̀fúùfù tó sì dì wọ́n sínú ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀? Èyí jẹ́ láti fi hàn pé àwọn kan yóò ṣẹ́ kù tí wọ́n á padà sí ilẹ̀ Júdà tí wọ́n á sì máa ṣe ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn àádọ́rin ọdún ìsọdahoro náà.—Ìsíkíẹ́lì 11:17-20.
17:1-24—Àwọn wo ni idì ńlá méjì, báwo la ṣe já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí ẹ̀ka igi kédárì kúrò, ta sì ni “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́” tí Jèhófà tún gbìn? Àwọn idì ńlá méjì yẹn dúró fún àwọn alákòóso Bábílónì àti Íjíbítì. Idì àkọ́kọ́ wá sórí téńté igi kédárì, ìyẹn ni pé ó wá sọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣàkóso nínú ìran Dáfídì ọba. Idì yìí wá já àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ orí igi náà kúrò nípa fífi Sedekáyà rọ́pò Jèhóákínì Ọba Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sedekáyà búra pé òun ò ní dalẹ̀, síbẹ̀ ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ idì mìíràn, ìyẹn alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ pàbó ló já sí. Ńṣe ni wọ́n máa mú un nígbèkùn, Bábílónì ló sì máa kú sí. Jèhófà tún já “èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́,” ìyẹn Mèsáyà Ọba. Ó wá tún èyí gbìn “sórí òkè ńlá gíga tí ó lọ sókè fíofío,” ìyẹn lórí Òkè Síónì, níbi tó ti máa di “kédárì ọlọ́lá ọba,” ìyẹn orísun ìbùkún àgbàyanu fún ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 14:1.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
2:6-8; 3:8, 9, 18-21. A ò gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù àwọn ẹni ibi tàbí ká máa lọ́ tìkọ̀ láti kéde ọrọ̀ Ọlọ́run, kíkìlọ̀ fún wọn sì wà lára ìkéde náà. Nígbà tá a bá bá àwọn tó ń dágunlá tàbí àwọn tó ń ṣàtakò pàdé, a ní láti rí i pé a le koránkorán bíi dáyámọ́ǹdì. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ di aláyà líle, ká má dẹni tí kì í gba ti ẹlòmíràn rò, tàbí aláìláàánú. Àánú àwọn tí Jésù wàásù fún máa ń ṣe é gan-an, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àánú máa sún wa láti wàásù fáwọn èèyàn.—Mátíù 9:36.
3:15. Lẹ́yìn tí Ísíkíẹ́lì gba iṣẹ́ ti Ọlọ́run rán an, ó lọ ń gbé Tẹli-Àbíbù, ‘ọjọ́ méje gbáko ló fi wà níbẹ̀ tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu,’ tó ń ronú lórí iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kó kéde. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa wá àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa ká sì máa ṣàṣàrò ká lè lóye àwọn òtítọ́ tẹ̀mí tó jinlẹ̀ gan-an?
4:1–5:4. Ísíkíẹ́lì ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ gan-an kó sì nígboyà kó tó lè ṣe àwọn àṣefihàn méjì tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì nígboyà bá a ti ń ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ọlọ́run gbé fún wa.
7:4, 9; 8:18; 9:5, 10. A ò ní láti máa ṣàánú àwọn tí Ọlọ́run bá dá lẹ́jọ́ tàbí ká máa bá wọn dárò.
7:19. Nígbà tí Jèhófà bá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, owó kò ní wúlò rárá.
8:5-18. Ìpẹ̀yìndà máa ń bá àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. “Ẹnu ara rẹ̀ ni apẹ̀yìndà fi ń run ọmọnìkejì rẹ̀.” (Òwe 11:9) Ọlọgbọ́n la jẹ́ tá a bá yẹra fáwọn apẹ̀yìndà, ká má tiẹ̀ jẹ́ kí èrò pé a fẹ́ tẹ́tí sí wọn wá sọ́kàn wa rárá.
9:3-6. Gbígba àmì náà, ìyẹn ẹ̀rí tó fi hàn pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣèrìbọmi ni wá, àti pé a ní àwọn ànímọ́ Kristẹni jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó lè la “ìpọ́njú ńlá” já. (Mátíù 24:21) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ wọn, ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ fífúnni ní àmì náà, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Tá a bá fẹ́ kí àmì wa máa wà títí lọ, a gbọ́dọ̀ máa fi tọkàntọkàn ran àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí.
12:26-28. Ní ti àwọn tó tiẹ̀ ń fi iṣẹ́ tí Ísíkíẹ́lì ń jẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pàápàá, ó ní láti sọ fún wọn pé: “Kì yóò sí ìsúnsíwájú mọ́ rárá nípa èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ [Jèhófà].” A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó tó di pé ó mú ètò nǹkan ìsinsìnyí wá sópin.
14:12-23. Kálukú wa ló máa ṣiṣẹ́ tó máa fi rí ìgbàlà. Ẹlòmíràn kò lè bá wa ṣe é.—Róòmù 14:12.
18:1-29. Àwa fúnra wa la máa kórè ohunkóhun tá a bá ṣe.
“RÍRUN, RÍRUN, RÍRUN NI ÈMI YÓÒ RUN ÚN”
(Ezekiel 20:1–24:27)
Lẹ́yìn ọdún méje táwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ti wà nígbèkùn, ìyẹn ní ọdún 611 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n wá sọ́dọ̀ Ísíkíẹ́lì “láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.” Wọ́n gbọ́ ìtàn tó gùn gan-an nípa ọ̀tẹ̀ Ísírẹ́lì àti ìkìlọ̀ pé ‘Jèhófà yóò mú idà rẹ̀ wá’ sórí wọn. (Ìsíkíẹ́lì 20:1; 21:3) Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa olórí Ísírẹ́lì (ìyẹn Sedekáyà), Jèhófà sọ pé: “Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé kúrò. Èyí kì yóò rí bákan náà. Gbé ohun tí ó rẹlẹ̀ pàápàá ga, kí o sì rẹ ẹni gíga pàápàá wálẹ̀. Rírun, rírun, rírun ni èmi yóò run ún. Ní ti èyí pẹ̀lú, dájúdájú, kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin [ìyẹn Jésù Kristi] yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.”—Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27.
Wọ́n fi ẹ̀sùn ìwà àìtọ́ kan Jerúsálẹ́mù. Jèhófà fi ẹ̀ṣẹ̀ Òhólà (ìyẹn Ísírẹ́lì) àti ti Òhólíbà (ìyẹn Júdà) hàn. Jèhófà ti fi Òhólà “lé ọwọ́ àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìgbónára, lé ọwọ́ àwọn ọmọ Ásíríà.” (Ìsíkíẹ́lì 23:9) Ìparun Òhólíbà ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Ọdún kan ààbọ̀ tí wọ́n fi sàga ti Jerúsálẹ́mù bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 609 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí ìlú náà bá ṣubú níkẹyìn, ìbànújẹ́ àwọn Júù yóò pọ̀ débi pé wọn ò ní lè sọ ohunkóhun. Ísíkíẹ́lì kò gbọ́dọ̀ sọ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an fún àwọn tó wà nígbèkùn yìí títí dìgbà tó bá gbọ́ ìròyìn látẹnu àwọn “olùsálà” pé ìlú náà ti pa rẹ́.—Ìsíkíẹ́lì 24:26, 27.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
21:3—Kí ni “idà” tí Jèhófà mú jáde kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀? Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni “idà” tí Jèhófà lò láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Jerúsálẹ́mù àti Júdà. Apá tó jẹ́ ti òkè ọ̀run lára ètò Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ alágbára, tún lè wà lára ohun tí “ìdà” náà dúró fún.
24:6-14—Kí ni ìpẹtà ìkòkò ìse-oúnjẹ dúró fún? Ipò tí Jerúsálẹ́mù wà lákòókò tí wọ́n sàga tì í ni Bíbélì fi wé ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀. Ìpẹtà rẹ̀ dúró fún ìwà ìbàjẹ́ ìlú náà, ìyẹn ìwà àìmọ́, ìwàkíwà, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó ń lọ níbẹ̀. Ìwà àìmọ́ rẹ̀ pọ̀ débi pé gbígbé ìkòkò náà sórí ẹyín iná ní òfìfo kí wọ́n sì jẹ́ kó gbóná gan-an kò mú ìpẹtà náà kúrò.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
20:1, 49. Ohun táwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fi hàn pé wọn ò fi gbogbo ara gba ọ̀rọ̀ Ísíkíẹ́lì gbọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣiyèméjì láé nípa ìkìlọ̀ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
21:18-22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nebukadinésárì woṣẹ́, síbẹ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀ lẹni tó mú kí alákòóso tó jẹ́ abọ̀rìṣà yẹn lọ gbógun ti Jerúsálẹ́mù. Èyí fi hàn pé kódà àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá kò lè dá àwọn tó máa mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ dúró pé kí wọ́n má mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
22:6-16. Jèhófà kórìíra ìbanilórúkọjẹ́, ìwàkiwà, kéèyàn máa lo agbára nílòkulò, àti kéèyàn máa gba rìbá. A ò ní jẹ́ kí ìpinnu tá a ṣe pé a ò ní lọ́wọ́ sí ìwà àìtọ́ yẹ̀ láé.
23:5-49. Lílẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Júdà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ló mú kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké wọn. Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra fún níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé tí wọ́n lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.—Jákọ́bù 4:4.
Ọ̀rọ̀ Tó Yè Tó Sì Ń Sa Agbára
Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ tó dáa gan-an la rí kọ́ látinú orí mẹ́rìnlélógún àkọ́kọ́ nínú ìwé Ísíkíẹ́lì! Àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tó lè mú kéèyàn pàdánù ojú rere Ọlọ́run, ó jẹ́ ká mọ ọ̀nà tá a fi lè rí àánú rẹ̀ gbà, àti ìdí tó fi yẹ ká kìlọ̀ fáwọn ẹni ibi. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù jẹ́ ká rí i kedere pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń ‘jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀ nípa àwọn ohun tuntun kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀.’—Aísáyà 42:9.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bí irú èyí tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì 17:22-24 àti 21:26, 27 tọ́ka sí fífi ìdí Ìjọba Mèsáyà múlẹ̀ ní ọ̀run. Láìpẹ́, ìṣàkóso yẹn yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó lágbára àti ìdánilójú, a lè máa retí àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá. Láìsí àní-àní, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kí ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Fífi gbogbo ara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí “àmì” wa máa wà títí lọ