Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
JUNE 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN| JEREMÁYÀ 51-52
“Gbogbo Ọ̀rọ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ Láìkù Síbì Kan”
it-2 360 ¶2-3
Àwọn ará Mídíà, Mídíà
Àwọn ará Páṣíà máa ṣẹ́gun Bábílónì. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa gbéjà ko Bábílónì nípasẹ̀ àwọn “àwọn ará Mídíà, tí kò ka fàdákà pàápàá sí nǹkan kan, àwọn tí ó sì jẹ́ pé, ní ti wúrà, wọn kò ní inú dídùn sí i. Ọrun wọn yóò sì fọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin túútúú.” (Ais 13:17-19; 21:2) Tí wọ́n bá lo gbólóhùn náà “àwọn ará Mídíà,” ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Páṣíà náà wà lára wọn. Torí náà, kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ àwọn àsọtàn ilẹ̀ Gíríìkì máa ń lo ọ̀rò náà àwọn ará Mídíà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa Mídíà àti Páṣíà. Bí àwọn ará Médíà àti Páṣíà kò ṣe ka fàdákà àti wúrà sí fi hàn pé bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì ló jẹ wọ́n lógún ju lọ, kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn. Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí iye tí wọ́n fún wọn tó máa jọ wọ́n lójú débi tí wọn kò fi ní pa ìlú náà run. Bíi ti àwọn ará Mídíà, ọfà ni olórí ohun ìjà àwọn ará Páṣíà. Igi ni wọ́n fi ń ṣe ọrun wọn, àmọ́ wọ́n tún máa ń fi idẹ tàbí bàbà ṣe òkè àti ìsàlẹ̀ rẹ̀ (fi wé Sm 18:34). Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí olúkúlùkù àwọn ọmọ ogun náà ṣe dán àwọn ọfà wọn tó mú ṣóróṣóró ló mú kó túbọ̀ wọni lára. Bí wọ́n ṣe rọ̀jọ̀ àwọn ọfà náà lẹ́ẹ̀kan náà mú kí wọ́n “fọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin Bábílónì túútúú.”—Jer 51:11.
A tún rí i pé Jeremáyà (51:11, 28) sọ pé “àwọn ọba Mídíà” wà lára àwọn tó wá gbógun ja ìlú Bábílónì. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà àwọn ọba fi hàn pé nígbà tí Kírúsì ṣì ń ṣàkóso, ọba tàbí àwọn ọba Mídíà kan wà tó ń ṣàkósò lákòókò náà, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì wọ́pọ̀ nígbà àtijọ́. (Fi wé Jer 25:25.) Torí náà, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Mídíà, Páṣíà, Élámù, àtàwọn ẹ̀yà míì pawọ́pọ̀ ṣẹ́gun Bábílónì, Dáríúsì tó jẹ́ ará Mídíà ni ó “jẹ ọba lórí ìjọba àwọn ará Kálídíà,” tó fi hàn pé òun ni Ọba Kírúsì ilẹ̀ Páṣíà yàn.—Da 5:31; 9:1; wo DARIUS No. 1.
it-2 459 ¶4
Nábónídọ́sì
Ìwé Nabonidus Chronicle sọ nípa alẹ́ ọjọ́ tí Bábílónì pa run pé: “Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kírúsì wọnú Bábílónì láìsí ìjà ogun.” Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé wọ́n ṣẹ́gun ìlú náà láì la wàhálà ogun púpọ̀ lọ, èyí sì tún bá àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà mu pé ‘àwọn alágbára ńlá Bábílónì ti ṣíwọ́ ìjà.’—Jer 51:30.
it-1 237 ¶1
Bábílónì
Ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn Bábílónì, torí pé ọdún yẹn ni ògo orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí í wọmi. Ẹ̀ẹ̀mejì ni Bábílónì ṣọ̀tẹ̀ sí olú ọba Páṣíà, ìyẹn Dáríúsì Kìíní (Hystaspis), nígbà kejì wọ́n pa Bábílónì run. Àwọn kan tún apá kan lára ìlú náà kọ́, wọ́n bá tún ṣọ̀tẹ̀ sí Sásítà Kìíní, ìyẹn tún jẹ wọ́n run. Alẹkisáńdà Ńlá fẹ́ sọ Bábílónì di olú ìlú rẹ̀, àmọ́ ṣàdédé ló kú ní ọdún 323 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọ̀gágun Nicator náà tún ṣẹ́gun ìlú yẹn lọ́dún 312 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì kó ọ̀pọ̀ nǹkan láti ibẹ̀ wá sí etíkun Tígírísì kó lè fi kọ́ Sìlúṣíà tó fẹ́ fi ṣe olú ìlú rẹ̀ tuntun. Ṣùgbọ́n apá díẹ̀ ṣì ṣẹ́ kù lára ìlú náà àwọn Júù kan sì ń gbé ibẹ̀ títí di àkókò tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ìdí sì nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi lọ sí Bábílónì bá a ṣe rí i nínú lẹ́tà tó kọ. (1Pe 5:13) Àwọn àkọlé tá a rí níbẹ̀ fi hàn pé wọ́n ti kọ́ tẹ́ńpìlì Bélì tó wà ní Bábílónì láti nǹkan bí ọdún 75 Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni, ìlú náà ti di ahoro, kò sì sí mọ́. Ńṣe ló di ibi “ìtòjọpelemọ òkúta.”—Jer 51:37.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 444 ¶9
Òkè, Òkè ńlá
Ó dúró fún ìjọba. Nínú Bíbélì, òkè tàbí òkè ńlá sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ìjọba tàbí ìṣakóso. (Da 2:35, 44, 45; Ais 41:15; Iṣi 17:9-11, 18.) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pe Bábílónì ní “òkè ńlá tí ń fa ìparun” torí pé ó ṣẹ́gun àwọn ìlú tó pọ̀, ó sì pa wọ́n run. (Jer 51:24, 25) Àpẹẹrẹ míì wà nínú Sáàmù kan tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jèhófà fojú àwọn jagunjagun alágbára ńlá rí, ó ní: “Ìmọ́lẹ̀ ni ó bò ọ́ yí ká, ìwọ jẹ́ ọlọ́lá ńlá ju àwọn òkè ńlá tí ó ní ẹran ọdẹ.” (Sm 76:4) Gbólóhùn náà, “àwọn òkè ńlá tí ó ní ẹran ọdẹ” dúró fún àwọn ìjọba tó jẹ́ àkòtagìrì. (Fi wé Na 2:11-13.) Àmọ́ Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ti mú kí òkè ńlá mi dúró tokuntokun,” tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé Jèhófà ti gbé ìjọba Dáfídì lékè, ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọin. (Sm 30:7; fi wé 2Sa 5:12.) Bí a ṣe wá mò pé òkè lè túmọ̀ sí ìjọba jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú Ìṣípayá 8:8 tó sọ pé: “Ohun kan bí òkè ńlá títóbi tí iná ń jó.” Àfiwé tí ẹsẹ yìí sọ pé òkè ńlá ń jó bí iná jẹ́ ká mọ̀ pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tó ń jẹ nǹkan run bí iná.
it-2 882 ¶3
Òkun
Àwọn ọmọ ogun tó pọ̀. Jeremáyà sọ pé ńṣe ni ìró àwọn tó máa wá gbógun ti Bábílónì máa dún bí “òkun tí í ṣe aláriwo líle.” (Jer 50:42) Torí náà, nígbà tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé “òkun” máa ya bo Bábílónì, ó dájú pé ohun tó ń sọ ni bí àwọn ọmọ ogun Mídíà àti Páṣíà tó pọ̀ bí omi òkun ṣe máa ya bo Bábílónì tí wọ́n á sì ṣẹ́gun rẹ̀.—Jer 51:42; fi wé Da 9:26.
JUNE 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌDÁRÒ 1-5
“Ẹ̀mí Ìdúródeni Ń Jẹ́ Ká Ní Ìfaradà”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìdárò
3:21-26, 28-33. Báwo la ṣe lè fara da ìnira tó tiẹ̀ gàgaàrá? Jeremáyà sọ fún wa. A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé Jèhófà pọ̀ ní ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti pé ọ̀pọ̀ ni àánú rẹ̀. Ó tún yẹ ká máa rántí pé wíwà tá a tiẹ̀ wà láàyè tó fún wa láti má ṣe sọ̀rètínù, àti pé ó yẹ ká ní sùúrù ká sì dúró de Jèhófà fún ìgbàlà, ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti láìráhùn. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún yẹ ká “fi ẹnu [wa] sínú ekuru,” ìyẹn ni pé tí ìdààmú bá dé, ká fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, ní mímọ̀ pé bí Ọlọ́run bá fàyè gba ohun kan láti ṣẹlẹ̀, fún ìdí rere kan ni.
3:27. Kíkojú àwọn ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò nígbà tá a wà lọ́dọ̀ọ́ lè gba pé ká fara da ìnira àti ìfiṣẹ̀sín. Àmọ́, ó “dára kí abarapá ọkùnrin ru àjàgà ní ìgbà èwe rẹ̀.” Kí nìdí? Nítorí pé kíkọ́ láti fara da ìnira nígbà téèyàn wà lọ́dọ̀ọ́ máa ń jẹ́ kéèyàn wà ní ìmúrasílẹ̀ láti lè kojú ìṣòro nígbà tó bá dàgbà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìdárò
2:17—“Àsọjáde” wo ní pàtàkì ni Jèhófà mú ṣẹ sórí Jerúsálẹ́mù? Kò sí àní-àní pé ohun tó wà nínú Léfítíkù 26:17 ni ẹsẹ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èyí tó sọ pé: “Èmi yóò sì dojú kọ yín, a ó sì ṣẹ́gun yín dájúdájú níwájú àwọn ọ̀tá yín; àwọn tí ó kórìíra yín yóò sì wulẹ̀ tẹ̀ yín mọ́lẹ̀, ẹ ó sì sá lọ ní ti tòótọ́ nígbà tí ẹnì kankan kò lépa yín.”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìdárò
5:7—Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń mú káwọn èèyàn jìyà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn baba ńlá wọn ṣẹ̀? Rárá o, Jèhófà kì í fìyà jẹ àwọn èèyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Àmọ́ o, àwọn ohun tó ń tìdí ẹ̀ṣẹ̀ yọ lè máà tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀, káwọn ìran tó ń bọ̀ sì máa jìyà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nítorí pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un yà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ tí wọ́n lọ ń bọ̀rìṣà, èyí mú kó ṣòro fáwọn tó tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ lẹ́yìn ìgbà náà láti rọ̀ mọ́ ọ̀nà òdodo.—Ẹ́kísódù 20:5.
JUNE 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 1-5
“Inú Ìsíkíẹ́lì Dùn Láti Kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
Bá A Ṣe Lè Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù Ilé-dé-Ilé
6 Ìwé Ìsíkíẹ́lì jẹ́ ká mọ nǹkan míì tó tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fìgboyà wàásù. Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà fún un ní àkájọ ìwé kan tí a kọ̀wé sí tojú-tẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú “orin arò àti ìkédàárò àti ìpohùnréré ẹkún.” Jèhófà wá ní kó jẹ ìwé náà, ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn, mú kí ikùn rẹ jẹ ẹ́, kí o lè fi àkájọ ìwé yìí tí mo ń fi fún ọ kún ìfun rẹ.” Kí ni ìran yìí túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ìsíkíẹ́lì gbọ́dọ̀ mọ iṣẹ́ tó fẹ́ lọ jẹ́ fáwọn èèyàn ní àmọ̀dunjú. Ọ̀rọ̀ yẹn sì gbọ́dọ̀ di ara rẹ̀, ìyẹn ni pé kó wà nínú ọkàn rẹ̀. Wòlíì náà ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́, ó sì wá dà bí oyin ní ẹnu mi ní dídùn.” Ohun ìdùnnú ni kíkéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbangba jẹ́ fún Ìsíkíẹ́lì, ńṣe ló dùn bí oyin lẹ́nu rẹ̀. Àǹfààní ńlá ni Ìsíkíẹ́lì kà á sí láti máa ṣojú fún Jèhófà àti láti máa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tí kò ní fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀ ló fẹ́ jẹ́ iṣẹ́ tó lágbára yìí fún.—Ka Ìsíkíẹ́lì 2:8–3:4, 7-9.
7 Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní lè kẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí. Àwa pẹ̀lú ní iṣẹ́ tó lágbára kan láti jẹ́ fáwọn èèyàn, àwọn táwa náà sì ń jíṣẹ́ ọ̀hún fún kì í sábà mọyì àwọn ìsapá tá à ń ṣe. Tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti máa wo iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ńlá tí Ọlọ́run fún wa, a gbọ́dọ̀ máa gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú. Ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ lóréfèé tàbí ní ìdákúrekú kò tó rárá tá a bá fẹ́ kí ìmọ̀ wa jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o lè ṣe láti mú kí Bíbélì kíkà rẹ àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ túbọ̀ máa ṣe déédéé kó sì nítumọ̀? Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ máa ṣàṣàrò sí i lórí àwọn ohun tó ò ń kà?—Ps. 1:2, 3.
it-1 1214
Ìfun
Tí oúnjẹ bá dà nínú wa, inú ìfun wa ló ń lọ. Àfiwé tó bá a mu wẹ́kù yìí ni Bíbélì lo láti ṣàpèjúwe bá a ṣe ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí sì fara hàn nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó jẹ àkájọ ìwé kan kí ó sì fi kún ìfun (Heb., me·ʽimʹ) rẹ̀. Ìsíkíẹ́lì á wá tipa bẹ́ẹ̀ rí okun tẹ̀mí bó ṣe ń fi ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé náà sọ́kàn tó sì ń ṣàṣàrò lé e lórí. Èyí mú kí ara rè jí pépé nípa tẹ̀mí kó sì jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an.—Isk 3:1-6; fi wé Re 10:8-10.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
2:9–3:3—Kí nìdí tí àkájọ ìwé tí wọ́n kọ orin arò àti ìkédàárò sí ṣe dùn mọ́ Ísíkíẹ́lì lẹ́nu? Ohun tó mú kí àkájọ ìwé náà dùn mọ́ Ísíkíẹ́lì lẹ́nu ni ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Inú Ísíkíẹ́lì dùn gan-an láti jẹ́ wòlíì Jèhófà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
1:4-28—Kí ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? Kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ṣàpẹẹrẹ apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ olóòótọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni orísun agbára ètò rẹ̀ yìí. Ẹni tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà, tó ṣàpẹẹrẹ Jèhófà, ní ògo lọ́nà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Ìparọ́rọ́ rẹ̀ la sì fi wé òṣùmàrè kan tó fani mọ́ra.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
4:1-17—Ṣé lóòótọ́ ni Ísíkíẹ́lì ṣe àṣefihàn bí àwọn ọ̀tá ṣe máa sàga ti Jerúsálẹ́mù? Bí Ísíkíẹ́lì ṣe bẹ̀bẹ̀ láti yí ohun tí Ọlọ́run ní kó fi dáná padà tí Jèhófà sì gbà fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ fi hàn pé lóòótọ́ ni wòlíì náà ṣe àṣefihàn ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Bí Ísíkíẹ́lì ṣe fi ẹgbẹ́ òsì dùbúlẹ̀ dúró fún àṣìṣe tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ṣe fún irínwó ó dín mẹ́wàá [390] ọdún, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí dìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó sì ṣe fi ẹgbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ dúró fún ogójì ọdún tí Júdà fi dẹ́ṣẹ̀, èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti àkókò tí Ọlọ́run yan Jeremáyà sípò wòlíì lọ́dún 647 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Oúnjẹ díẹ̀ ni Ísíkíẹ́lì jẹ ní gbogbo irínwó ó lé ọgbọ̀n [430] ọjọ́ yẹn ìwọ̀nba omi díẹ̀ ló sì mu, èyí sì fi hàn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé ìyàn máa mú nígbà táwọn ọ̀tá bá sàga ti Jerúsálẹ́mù.
JUNE 26–JULY 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 6-10
“Ṣé O Máa Wà Lára Àwọn Tá A Máa Sàmì Sí Láti Là Á Já?”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ohun Tó Mú Kí Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ Wa Ta Yọ
10 Jèhófà nìkan lẹni tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la nítorí ó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ó mọ bí ọjọ́ ọ̀la aráyé ṣe máa rí. (Aísá. 46:9, 10) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” (Sef. 1:14) Ọ̀rọ̀ tó wà ní Òwe 11:4 yóò ṣẹ lọ́jọ́ yẹn, ó sọ pé: “Àwọn ohun tí ó níye lórí kì yóò ṣàǹfààní rárá ní ọjọ́ ìbínú kíkan, ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.” Ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run lohun tó máa ṣe pàtàkì jù nígbà tí àkókò Jèhófà bá tó láti ṣèdájọ́ ayé Sátánì yìí. Owó kò ní já mọ́ nǹkan kan nígbà yẹn. Bó ṣe rí gan-an ni Ìsíkíẹ́lì 7:19 ṣe sọ ọ́, pé: “Wọn yóò sọ fàdákà wọn pàápàá sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn.” Ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nísinsìnyí.