Ta Ni Yoo Yèbọ́ Ni “Akoko Idaamu”?
“Olukuluku ẹni tí ó bá képe orukọ Jehofa yoo móríbọ́ laisewu.” —JOẸLI 2:32, NW.
1. Gẹgẹ bi Daniẹli ati Malaki ti wi, ki ni ami idanimọyatọ fun awọn wọnni ti wọn wà ni oju ìlà fun igbala nigba “akoko idaamu” tí ń bọ̀?
NÍ WÍWO iwaju fun ọjọ wa, wolii Daniẹli kọwe pe: “Akoko idaamu yoo ṣẹlẹ dajudaju iru eyi ti a kò tíì mú ki o ṣẹlẹ rí lati ìgbà ti orilẹ-ede kan ti wà titi di ìgbà yẹn. Ati ni akoko yẹn awọn eniyan rẹ yoo yèbọ́, olukuluku ẹni ti a rí ti a kọ silẹ ninu iwe naa.” (Daniẹli 12:1, NW) Awọn ọrọ atuninínú nitootọ! Awọn eniyan Jehofa ti a tẹwọgba ni oun yoo ranti, gan-an gẹgẹ bi Malaki 3:16 tún ti polongo pe: “Nigba naa ni awọn ti ó bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ń bá araawọn sọrọ nigbakugba; Oluwa [“Jehofa,” NW] sì tẹti si i, ó sì gbọ́, a sì kọ iwe iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], ti wọn sì ń ṣe aṣaro [“ń ronu lori,” NW] orukọ rẹ̀.”
2. Ki ni rironu lori orukọ Jehofa yọrisi?
2 Rironu lori orukọ Jehofa a maa yọrisi ìmọ̀ pipeye nipa rẹ̀, Kristi rẹ̀, ati gbogbo awọn ète titobilọla Ijọba rẹ̀. Nipa bayii, awọn eniyan rẹ̀ kẹkọọ lati bu ọ̀wọ̀-ńlá fun un, lati wọnu ipo ibatan iyasimimọ timọtimọ pẹlu rẹ̀, ati lati fẹran rẹ̀ ‘pẹlu gbogbo ọkan-aya wọn ati pẹlu gbogbo òye ati pẹlu gbogbo okun wọn.’ (Maaku 12:33, NW; Iṣipaya 4:11) Jehofa ti ṣe ipese alaaanu, nipasẹ irubọ Jesu Kristi, fun awọn ọlọkantutu ori ilẹ̀-ayé lati rí ìyè ainipẹkun. Fun idi yii, awọn wọnyi lè ṣe gbohungbohun awọn ọrọ ogun ọ̀run naa tí ó yin Ọlọrun ni akoko ìbí Jesu pẹlu igbọkanle, ni wiwi pe: “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọ̀run, ati ni ayé alaafia, ifẹ inurere si eniyan.”—Luuku 2:14.
3. Kí alaafia tó lè dé si ilẹ̀-ayé yii, igbegbeesẹ wo lati ọ̀dọ̀ Jehofa wo ni ó gbọdọ wáyé?
3 Alaafia yẹn ti sunmọ tosi ju bi ọpọ eniyan ti ro lọ. Ṣugbọn ìmúdàájọ́ Jehofa ṣẹ lori ayé oniwa-ibajẹ gbọdọ kọ́kọ́ wá. Wolii rẹ̀ Sefanaya polongo pe: “Ọjọ ńlá Oluwa [“Jehofa,” NW] kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń yara kánkán.” Iru ọjọ wo niyẹn? Asọtẹlẹ naa ń ba a lọ pe: “Ohùn ọjọ Oluwa [“Jehofa,” NW]: alagbara ọkunrin yoo sọkun kikoro nibẹ. Ọjọ naa ọjọ ibinu ni, ọjọ ìyọnu, ati ipọnju [“idaamu,” NW], ọjọ òfò ati idahoro, ọjọ okunkun ati okudu, ọjọ kuukuu ati okunkun biribiri, ọjọ ìpè ati idagiri si ilu olodi wọnni ati sí ìṣọ́ giga wọnni. Emi yoo sì mú ipọnju [“idaamu,” NW] wá bá eniyan, ti wọn yoo maa rin bi afọju, nitori wọn ti dẹṣẹ si Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Sefanaya 1:14-17; tun wo Habakuku 2:3; 3:1-6, 16-19.
4. Awọn wo lonii ni wọn ń dahun pada si ikesini naa lati mọ̀ ki wọn sì ṣiṣẹsin Ọlọrun?
4 Lọna ti ó muni layọ, araadọta-ọkẹ lonii ń dahun si ikesini naa lati mọ̀ ki wọn sì ṣiṣẹsin Ọlọrun. Nipa awọn Kristẹni ẹni ami ororo, ti a mú wọnu majẹmu titun, a sọtẹlẹ pe: “Gbogbo wọn ni yoo mọ̀ mi, lati ẹni kekere wọn dé ẹni ńlá wọn, ni Oluwa [“Jehofa,” NW] wí.” (Jeremaya 31:34) Awọn wọnyi ti ṣe òléwájú iṣẹ ijẹrii ode-oni. Ati nisinsinyi bi pupọ pupọ sii ninu awọn aṣẹku ẹni ami ororo ti ń pari ipa-ọna ti ilẹ̀-ayé wọn, “awọn ogunlọgọ” ti “agutan miiran” ti wá siwaju lati ‘ṣe iṣẹ-isin mimọ si Ọlọrun lọsan ati loru’ ninu iṣeto bii ti tẹmpili rẹ̀. (Iṣipaya 7:9, 15, NW; Johanu 10:16) Iwọ ha jẹ́ ẹnikan ti ń gbadun anfaani alaiṣeediyele yii bi?
Bi “Awọn Ohun Fifanilọkanmọra” Ṣe Wọle
5, 6. Ṣaaju ki a tó fi mimi jìgìjìgì pa gbogbo awọn orilẹ-ede run, iṣẹ igbala wo ni ó ń ṣẹlẹ?
5 Nisinsinyi ẹ jẹ ki a sí Hagai 2:7 (NW), nibi ti Jehofa ti sọ asọtẹlẹ nipa ile ijọsin rẹ̀ tẹmi. Ó wi pe: “Emi yoo sì mi gbogbo orilẹ-ede jìgìjìgì, awọn ohun fifanilọkanmọra gbogbo orilẹ-ede sì gbọdọ wọle wá, emi yoo sì fi ogo kún ile yii.” Awọn asọtẹlẹ Bibeli fihan pe ‘mími awọn orilẹ-ede jìgìjìgì’ tọka si imuṣẹ idajọ Jehofa lori awọn orilẹ-ede. (Nahumu 1:5, 6; Iṣipaya 6:12-17) Fun idi eyi, igbésẹ̀ Jehofa ti a sọtẹlẹ ni Hagai 2:7 (NW) yoo dé òtéńté pẹlu mímì ti a o mi awọn orilẹ-ede jìgìjìgì di alaisi mọ́—a pa wọn run ráúráú. Ṣugbọn ki ni nipa “awọn ohun fifanilọkanmọra gbogbo awọn orilẹ-ede”? Wọn ha nilati duro de mímì jìgìjìgì aṣèparun yẹn lati mú wọn wọle bi? Àgbẹdọ̀.
6 Joẹli 2:32 sọ pe “olukuluku ẹni ti ó bá képe orukọ Jehofa yoo móríbọ́ laisewu; nitori ni Oke Sioni ati ni Jerusalẹmu ni ẹ̀rí yoo fihan pe awọn ti o yèbọ́ wà, gan-an gẹgẹ bi Jehofa ti sọ, ati laaarin awọn olulaaja, awọn ẹni ti Jehofa ń pè.” Jehofa fà wọn jade, wọn sì képe orukọ rẹ̀ pẹlu igbagbọ ninu irubọ Jesu ṣaaju mímì ogogoro opin ti ipọnju ńlá naa. (Fiwe Johanu 6:44; Iṣe 2:38, 39.) Lọna ti ó muni layọ, awọn ogunlọgọ ńlá ti wọn ṣeyebiye, ti iye wọn pọ̀ ju million mẹrin lọ nisinsinyi, ‘wá sinu’ ile ijọsin Jehofa ni ifojusọna fun ‘mímì ti yoo mi gbogbo awọn orilẹ-ede jìgìjìgì’ rẹ̀ ni Amagẹdọni.—Iṣipaya 7:9, 10, 14.
7. Ki ni ‘kíképe orukọ Jehofa’ ní ninu?
7 Bawo ni awọn olulaaja wọnyi ṣe képe orukọ Jehofa? Jakọbu 4:8 fun wa ni ìtọ́ka kan, ni wiwi pe: “Ẹ sunmọ Ọlọrun, oun yoo sì sunmọ yin, ẹ wẹ ọwọ́ yin mọ́, ẹyin ẹlẹṣẹ; ẹ sì ṣe ọkàn yin ni mímọ́, ẹyin oniyemeji.” Gẹgẹ bi o ti rí pẹlu awọn aṣẹku ẹni ami ororo naa ti wọn ṣaaju ọ̀nà, awọn wọnni ti wọn nireti lati jẹ́ ọ̀kan lara awọn ogunlọgọ ńlá olula Amagẹdọni já gbọdọ gbegbeesẹ pẹlu ipinnu. Bi iwọ bá nireti lati la a já, iwọ gbọdọ mu lọpọlọpọ lati inu Ọrọ Jehofa tí ń sọni di mimọgaara ki o sì fi awọn ọ̀pá idiwọn ododo rẹ̀ silo ninu igbesi-aye rẹ. Iwọ nilati jẹ́ onipinnu ni yiya igbesi-aye rẹ si mimọ fun Jehofa, ni ṣiṣapẹẹrẹ eyi nipasẹ iribọmi ninu omi. Kíké ti wọn ń ké pe orukọ Jehofa ninu igbagbọ tun ní jijẹrii fun un ninu. Nipa bayii, ni Roomu ori 10, ẹsẹ 9 ati 10 (NW), Pọọlu kọwe pe: “Bi iwọ bá kede nigbangba ‘ọrọ naa ti ó wà ni ẹnu araarẹ,’ pe Jesu ni Oluwa, ti iwọ sì lo igbagbọ ninu ọkan-aya rẹ pe Ọlọrun jí i dide kuro ninu òkú, a o gbà ọ́ là. Nitori ọkan-aya ni a fi ń lo igbagbọ fun ododo, ṣugbọn ẹnu ni a fi ń ṣe ikede nigbangba fun igbala.” Lẹhin naa, ni ẹsẹ 13 (NW), apọsiteli naa ṣayọlo asọtẹlẹ Joẹli, ni titẹnumọ ọn pe “olukuluku ẹni ti ó bá képe orukọ Jehofa ni a o gbala.”
‘Wá, Wá, Wá
8. (a) Gẹgẹ bi wolii Sefanaya ti wi, ki ni Jehofa beerefun fún igbala? (b) Ikilọ wo ni ọrọ naa “bóyá” ni Sefanaya 2:3 gbeyọ sí wa lọkan?
8 Ní ṣiṣi i sí iwe Bibeli ti Sefanaya, ori 2, ẹsẹ 2 ati 3, a ka ohun ti Jehofa beerefun fun igbala pe: “Ki gbigbona ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW] tó dé ba yin, ki ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW] ki o tó dé ba yin. Ẹ wa Oluwa [“Jehofa,” NW], gbogbo ẹyin ọlọkantutu ayé tí ń ṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá iwapẹlẹ: boya a o pa yin mọ ni ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW].” Ṣakiyesi ọrọ naa “boya.” Kì í ṣe ọ̀ràn igbala lẹẹkan, igbala gbogbo ìgbà. Pipa wá mọ́ nikọkọ ni ọjọ yẹn sinmi lori biba a lọ wa lati ṣe awọn nǹkan mẹta wọnyẹn. A gbọdọ wá Jehofa, wá ododo, ki á sì wá iwapẹlẹ.
9. Bawo ni a ṣe bukun awọn wọnni ti wọn wá iwapẹlẹ?
9 Agbayanu ni èrè naa, nitootọ, fun wíwá iwapẹlẹ! Ni Saamu 37, ẹsẹ 9 titi dé 11, a kà pe: “Awọn ti o duro de Oluwa [“Jehofa,” NW] ni yoo jogun ayé. Nitori pe nigba diẹ, awọn eniyan buburu kì yoo sí . . . Ṣugbọn awọn ọlọkantutu ni yoo jogun ayé; wọn yoo sì maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.” Kí sì ni nipa wíwá ododo? Ẹsẹ 29 sọ pe: “Olododo ni yoo jogun ayé, yoo sì maa gbé inú rẹ̀ laelae.” Niti wiwa Jehofa. Ẹsẹ 39 ati 40 sọ fun wa pe: “Lati ọwọ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá ni igbala awọn olododo; oun ni aabo wọn ni ìgbà ipọnju. Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo sì ràn wọn lọwọ, yoo sì gbà wọn, yoo sì gbà wọn lọwọ eniyan buburu, yoo sì gbà wọn là, nitori ti wọn gbẹkẹle e.”
10. Awọn wo ni a ti mọ̀ daradara ninu kíkọ̀ wọn lati wá Jehofa ati lati wá iwapẹlẹ?
10 Awọn ẹ̀yà isin Kristẹndọmu ti kuna lati wá Jehofa. Awujọ alufaa rẹ̀ paapaa ti kọ orukọ ṣiṣeyebiye rẹ̀ silẹ, ni fifi ìwà ọ̀yájú yọ ọ́ kuro ninu itumọ Bibeli wọn. Wọn yan lati jọsin Oluwa tabi Ọlọrun alailorukọ kan, ki wọn sì bọwọ gidigidi fun Mẹtalọkan oloriṣa kan. Ju bẹẹ lọ Kristẹndọmu, kò wá ododo. Ọpọlọpọ ninu awọn alatilẹhin rẹ̀ tẹwọgba tabi ṣetilẹhin fun ọ̀nà igbesi-aye onígbọ̀jẹ̀gẹ́. Dipo ti wọn ìbá fi wá iwapẹlẹ gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, wọn ṣe aṣehan aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀, fun apẹẹrẹ lori tẹlifiṣọn, nipa igbesi-aye onifaaji ati lọpọ ìgbà oniwa palapala. Awọn alufaa mú araawọn sanra ni jíjìfà lara agbo wọn. Ninu ọrọ Jakọbu 5:5, wọn ti ‘jẹ adùn ni ayé, wọn sì ti fi araawọn fun ayé jíjẹ.’ Bi ọjọ Jehofa ti ń sunmọ etile, wọn yoo mọ̀ daju pe awọn ọrọ onimiisi naa ń ba wọn wi: “Ọrọ̀ kì í ní anfaani ni ọjọ ibinu.”—Owe 11:4.
11. Ta ni ọkunrin alailofin naa, bawo ni o sì ti ṣe kó ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ jọ pelemọ?
11 Ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti rohin ninu lẹta rẹ̀ keji si awọn ará Tẹsalonika, awọn Kristẹni kan di ẹni ti a ru soke, ni rironu pe ọjọ Jehofa ti kàn wọn lara nigba yẹn. Ṣugbọn Pọọlu kilọ pe lakọọkọ ipẹhinda titobi naa nilati kọ́kọ́ dé, ti “ọkunrin alailofin naa” sì nilati di eyi ti a ṣipaya. (2 Tẹsalonika 2:1-3, NW) Nisinsinyi, ni ọrundun lọna 20 yii, a lè mọriri ìwọ̀n gígadabú ipẹhinda yẹn ati bi awujọ alufaa Kristẹndọmu ti jẹ́ alailofin tó ni oju Ọlọrun. Ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi lati ọdun 1914 wá, awujọ alufaa ti ṣàkójọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ni ọpọ rẹpẹtẹ nipa ṣiṣetilẹhin fun ‘fifi awọn ohun èèlò ìtúlẹ̀ rọ idà.’ (Joẹli 3:10) Wọn ti ń ba a lọ lati fi awọn ẹ̀kọ́ èké kọni, iru bii aileku ọkàn eniyan, pọgatori, ìdálóró ina ọrun apaadi, iribọmi ọmọ-ọwọ, Mẹtalọkan ti wọn jẹ apakan ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti kìí yipada, ati iru miiran bẹẹ bẹẹ. Nibo ni wọn yoo duro sí nigba ti Jehofa bá mú ipinnu idajọ rẹ̀ ṣẹ? Owe 19:5 sọ pe: “Ẹni ti o sì ń ṣeke ki yoo mú un jẹ.”
12. (a) Ki ni “awọn ọ̀run” ati “ilẹ̀-ayé” ti eniyan ti a o parun ráúráú laipẹ? (b) Ki ni a kẹkọọ rẹ̀ lati inu iparun ayé buburu yii ti ń bọ̀?
12 Ni 2 Peteru 3:10 (NW), a kà pe: “Ọjọ Jehofa yoo dé gẹgẹ bi olè, ninu eyi ti awọn ọ̀run yoo kọja lọ pẹlu ariwo híhóyànmù, ṣugbọn awọn ohun ipilẹ niwọn bi wọn ti gbonajanjan ni a o mú di yíyọ́ ilẹ̀-ayé ati awọn iṣẹ inu rẹ̀ ni a o sì ṣawari.” Iṣakoso oniwa ibajẹ ti o ti tẹ́ rẹrẹ bi awọn ọ̀run lé araye lori, papọ pẹlu gbogbo awọn ohun ipilẹ ti ó papọ di awujọ eniyan tí ó ti lọ silẹ niti iwarere, ni a o gbá kuro lori ilẹ̀-ayé ti Ọlọrun. Awọn oniṣowo ati awọn oluṣe ohun ìjà ọjọ àgbákò ibi, awọn oníjìbìtì, awọn onisin alagabagebe ati awujọ alufaa wọn, awọn olùṣagbátẹrù ìwà ibajẹ, ìwà ipá, ati ìwa ọdaran—gbogbo iwọnyi ni yoo pòórá. A o yọ́ wọn danu nipasẹ ibinu Jehofa. Ṣugbọn ni ẹsẹ 11 ati 12 (NW), Peteru fi ọrọ iṣọra yii kun un fun awọn Kristẹni pe: “Niwọn bi a o ti mú awọn nǹkan wọnyi di yíyọ́ bayii, iru awọn eniyan wo ni ó yẹ ki ẹyin jẹ́ ninu awọn iṣe mimọ ti ìwà ati awọn iṣẹ ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ni diduro de ati fifi wíwà nihin-in ọjọ Jehofa sọkan pẹkipẹki.”
Maikẹli Bọ́ Sẹnu Iṣẹ!
13, 14. Ta ni Olùdá agbara iṣakoso Jehofa láre titobi naa, bawo ni ó sì ti ń gbékánkán ṣiṣẹ lati 1914 wá?
13 Bawo ni ẹnikan ṣe lè yèbọ́ ni “akoko idaamu” Jehofa? Aṣoju Jehofa fun pipese asala ni olori angẹli naa Maikẹli, ẹni ti orukọ rẹ̀ tumọsi “Ta Ni Dabi Ọlọrun?” Lọna ti ó ba a mu, nigba naa, oun ni Ẹni naa ti ó dá agbara iṣakoso Jehofa lare, ni gbigbe Jehofa larugẹ gẹgẹ bi Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa ati Oluwa Ọba-Alaṣẹ gbogbo agbaye tí ẹ̀tọ́ tọ́ sí.
14 Iru awọn iṣẹlẹ pípẹtẹrí wo ni Iṣipaya ori 12, ẹsẹ 7 titi dé 17, ṣapejuwe nipa “ọjọ Oluwa” lati 1914! (Iṣipaya 1:10) Olori awọn angẹli Maikẹli fi Satani ọ̀dàlẹ̀ naa sọko kuro ni ọ̀run wá si ilẹ̀-ayé. Lẹhin naa, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ ni Iṣipaya ori 19, ẹsẹ 11 titi dé 16, ẹni ti a pe ni “Ododo ati Otitọ” “ń tẹ ifunti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare.” Jagunjagun ọ̀run alagbara yii ni a fun ni orukọ naa “Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa.” Nikẹhin, Iṣipaya ori 20, ẹsẹ 1 ati 2, sọ nipa angẹli ńlá kan ti ó fi Satani sọko sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ti ó sì há a mọ́ ibẹ̀ fun ẹgbẹrun ọdun. Ni kedere, gbogbo awọn iwe mimọ wọnyi tọka si Olùdá ipo ọba-alaṣẹ Jehofa láre kan naa, Oluwa Jesu Kristi, ẹni ti Jehofa gbé ka ori ìtẹ́ rẹ̀ ológo lọ́run ni 1914.
15. Ni ọ̀nà akanṣe wo ni Maikẹli yoo gbà “dide duro” laipẹ?
15 Maikẹli ti “ń dúró,” gẹgẹ bi a ti sọ ọ́ ni Daniẹli 12:1, nititori awọn eniyan Jehofa tipẹtipẹ lati ìgbà ti a ti fi sipo gẹgẹ bi Ọba ni 1914. Ṣugbọn laipẹ Maikẹli ni yoo “dide duro” ní èrò itumọ akanṣe gan-an—gẹgẹ bi Aṣoju Jehofa ni mímú gbogbo iwa buburu kuro ni ilẹ̀-ayé ati gẹgẹ bi Olùdáǹdè awujọ awọn eniyan Ọlọrun yika ayé. Bi “ọjọ idaamu” yẹn yoo ti kàmàmà tó ni a fihan nipasẹ awọn ọrọ Jesu ni Matiu 24:21, 22 pe: “Nigba naa ni ipọnju ńlá yoo wà, iru eyi ti kò sí lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ́ ìwà di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ ki yoo sì sí. Bi kò sì ṣe pe a ké ọjọ wọnni kuru, kò sí ẹ̀dá ti ìbá lè là á; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ ni a o fi ké ọjọ wọnni kuru.”
16. Ẹran-ara wo ni a o gbala nigba ipọnju ńlá?
16 Ó ti yẹ ki a layọ tó pe a o gba awọn ẹran-ara diẹ là ni akoko yẹn! Rárá, kì í ṣe ẹran ara bii ti awọn Juu ọlọtẹ ti a ká mọ́ Jerusalẹmu ni 70 C.E., diẹ ninu awọn ẹni ti a kó lọ gẹgẹ bi ẹrú si Roomu. Kaka bẹẹ, awọn wọnni ti wọn yèbọ́ ni “akoko opin” yoo dabii ìjọ Kristẹni ti wọn ti sá kuro ni Jerusalẹmu ṣaaju ìgbà ti ìsàgatì ti o kẹhin bẹrẹ. Wọn yoo jẹ́ eniyan Ọlọrun fúnraarẹ̀, araadọta-ọkẹ awọn ogunlọgọ ńlá papọ pẹlu awọn ẹni ami ororo eyikeyii ti wọn lè ṣẹ́kù sori ilẹ̀-ayé sibẹ. (Daniẹli 12:4) Ogunlọgọ ńlá “jade wá lati inu ipọnju ńlá.” Eeṣe? Nitori pe “wọn ti fọ aṣọ igunwa wọn wọ́n sì ti sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọdọ-agutan naa.” Wọn lo igbagbọ ninu agbara irapada ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a ta silẹ wọn sì ṣaṣefihan igbagbọ yẹn nipa fifi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Ọlọrun. Ani nisinsinyi paapaa, Jehofa, “Ẹni naa ti ó jokoo lori ìtẹ́,” ta àgọ́ adaaboboni rẹ̀ sori wọn, nigba ti Ọdọ-agutan naa, Kristi Jesu, ṣoluṣọ agutan ti o sì dari wọn lọ sibi orisun omi ìyè.—Iṣipaya 7:14, 15, NW.
17. Bawo ni a ṣe fun awọn ogunlọgọ ńlá ni pataki niṣiiri lati gbegbeesẹ ki a baa lè fi wọn pamọ nikọkọ ní ọjọ idaamu ti ń bọ̀?
17 Ni wíwá Jehofa, ododo, ati ìwàpẹ̀lẹ́, araadọta-ọkẹ awọn ogunlọgọ ńlá kò gbọdọ jẹ ki ifẹ wọn akọkọ fun otitọ di tútù! Bi iwọ bá jẹ́ ọ̀kan lara awọn ẹni bi agutan wọnyi, ki ni iwọ gbọdọ ṣe? Gẹgẹ bi a ti sọ ni Kolose ori 3, ẹsẹ 5 titi dé 14 (NW), iwọ gbọdọ “bọ́ ogbologboo akopọ animọ naa kuro pẹlu awọn àṣà rẹ̀” patapata. Bi o ti ń wá iranlọwọ atọrunwa, saakun lati ‘fi akòpọ animọ titun, ti a gbekari ìmọ̀ pipeye wọ araarẹ laṣọ.’ Pẹlu iwapẹlẹ, mú itara dagba ki o sì maa lo ìtara niṣo ninu yiyin Jehofa ati ninu sisọ awọn ète titobilọla rẹ̀ di mímọ̀ fun awọn ẹlomiran. Nipa bayii, a lè fi ọ́ pamọ nikọkọ ni “ọjọ idaamu,” ọjọ “ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW].”
18, 19. Ni ọ̀nà wo ni ifarada ti gbà di eyi ti ó ṣe kókó fun igbala?
18 Ọjọ yẹn ti sunmọle! Ó ń yara kánkán bọ̀ lọdọ wa. Ìkójọpọ̀ awọn eniyan tí wọn parapọ di ogunlọgọ ńlá naa ti ń ba a lọ bayii fun nǹkan bi ọdun 57. Ọpọlọpọ ninu awọn wọnyi ti kú ti wọn sì ń duro de ajinde wọn. Ṣugbọn a mú un dá wa loju nipasẹ asọtẹlẹ Iṣipaya pe gẹgẹ bi agbo kan awọn ogunlọgọ ńlá naa yoo jade lati inu ipọnju ńlá naa gẹgẹ bi ẹgbẹ́ awujọ kekere kan ninu “ayé titun kan.” (Iṣipaya 21:1) Iwọ yoo ha wà nibẹ bi? Iyẹn ṣeeṣe, nitori pe Jesu sọ ni Matiu 24:13 pe: “Ẹni tí ó bá foriti i titi dé opin, oun naa ni a o gbala.”
19 Pákáǹleke tí awọn eniyan Jehofa niriiri rẹ̀ ninu eto igbekalẹ ogbologboo yii lè maa peleke sii. Nigba ti ipọnju ńlá onidaamu naa bá sì bẹsilẹ, iwọ lè jiya inira. Ṣugbọn wà pẹkipẹki pẹlu Jehofa ati eto-ajọ rẹ. Wà lojufo rekete! “‘Ẹ maa pa araayin mọ́ ni ifojusọna fun mi,’ ni asọjade ọrọ Jehofa, ‘titi di ọjọ idide mi sí iyẹ́, nitori ipinnu idajọ mi ni lati kó awọn orilẹ-ede jọ, fun mi lati ṣa awọn ijọba jọ papọ, lati tú ibawi ìkannú mi jade sori wọn, gbogbo ibinu jíjófòfò mi; nitori gbogbo ilẹ̀-ayé ni a o jẹ ráúráú nipasẹ iná ìtara mi.’”—Sefanaya 3: 8, NW.
20. Bi ogogoro opin “akoko idaamu” ti ń sunmọle ju ti igbakigba ri lọ, ki ni a gbọdọ ṣe?
20 Fun aabo ati iṣiiri wa, Jehofa ti fi oore-ọ̀fẹ́ pese “èdè mimọgaara kan,” eyi ti o ní ninu ihin-iṣẹ titobilọla ti Ijọba rẹ̀ ti ń bọ̀, “ki gbogbo wọn baa lè maa képe orukọ Jehofa, lati lè maa ṣiṣẹsin in ni ifẹgbẹkẹgbẹ.” (Sefanaya 3:9, NW) Bi “akoko idaamu” ogogoro opin naa ti ń yara sunmọ pẹkipẹki ju ti igbakigba ri lọ, ǹjẹ́ ki a ṣiṣẹsin pẹlu ìtara, ni ríran awọn ọlọkantutu miiran lọwọ lati ‘képe orukọ Jehofa’ fun igbala.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Igbegbeesẹ wo lati ọ̀dọ̀ Jehofa ni yoo ṣaaju mímú alaafia wá sori ilẹ̀-ayé?
◻ Gẹgẹ bi Joẹli ti wi, ki ni ẹnikan gbọdọ ṣe ki ó baa lè di ẹni ti a gbala?
◻ Gẹgẹ bi Sefanaya ti wi, bawo ni awọn ọlọkantutu ṣe lè rí aabo kuro lọwọ ibinu jíjófòfò Jehofa?
◻ Ta ni “ọkunrin alailofin naa,” bawo sì ni o ṣe kó ẹbi ẹ̀jẹ̀ jọ pelemọ?
◻ Bawo ni ifarada ti ṣe pataki tó ninu ọ̀ràn igbala?