ORÍ KEJE
Máa Sin Jèhófà Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Tó Fi Lélẹ̀
1. Nígbà ayé Sefanáyà, kí ni èrò àwọn èèyàn ìlú Jerúsálẹ́mù nípa àwọn ìlànà Jèhófà?
“JÈHÓFÀ kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.” Èrò àwọn ará Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Sefanáyà nìyẹn. Wọ́n ronú pé Jèhófà ò sọ pé káwọn tẹ̀ lé ìlànà kankan. Sefanáyà sọ fún wọ́n pé wọ́n ń “dì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,” ìyẹn ìdọ̀tí tó máa ń sẹ̀gẹ̀dẹ̀ sísàlẹ̀ ọtí wáìnì. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn èèyàn náà ò fẹ́ yí ọ̀nà tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn tí wọ́n gbà ń gbé ìgbé ayé wọn padà, wọn ò fẹ́ kẹ́nì kankan fi ìkéde ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún wọn dí wọn lọ́wọ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run sọ fáwọn Júù wọ̀nyẹn pé òun á “fi fìtílà wá inú Jerúsálẹ́mù lẹ́sọ̀lẹsọ̀,” òun á sì ‘fún àwọn tí kò ka ìlànà òun sí láfiyèsí.’ Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ní àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀ ó sì ń kíyè sí irú ojú táwọn èèyàn rẹ̀ fi ń wo àwọn ìlànà náà.—Sefanáyà 1:12.
2. Ojú wo làwọn èèyàn sábà máa ń fi wo títẹ̀lé ìlànà ládùúgbò rẹ?
2 Bọ́rọ̀ ṣe rí lóde òní náà nìyẹn o. Ọ̀pọ̀ ni kì í fẹ́ tẹ̀ lé ìlànà. Àwọn kan máa ń sọ pé: “Ohun tó wù ẹ́ ni kó o ṣe!” Àwọn mìíràn tún máa ń ronú pé: ‘Tí mi ò bá lówó lọ́wọ́ tàbí tọ́wọ́ mi ò bá lè tẹ ohun tí mò ń fẹ́, kò burú tí mo bá dọ́gbọ́n sí i, wọ́n sáà sọ pé Ọlọ́run ò kọ aájò.’ Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í gbé ohun tó jẹ́ èrò Ọlọ́run lórí àwọn nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ ṣe yẹ̀ wò bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í wádìí ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn. Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o nífẹ̀ẹ́ sí bí Ẹlẹ́dàá ṣe fi àwọn ìlànà lélẹ̀?
3, 4. Kí nìdí tó o fi mọyì pé kí ìlànà wà?
3 Kó o sì máa wò ó o, kì í ṣòro fún ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í fẹ́ pa ìlànà Ọlọ́run mọ́ wọ̀nyí láti pa àwọn ìlànà téèyàn ẹlẹ́ran ara fi lélẹ̀ lórí onírúurú nǹkan mọ́ o. Àpẹẹrẹ kan ni ìlànà lórí irú omi tó yẹ kí ará ìlú máa mu. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni ìjọba ti máa ń fi ìlànà lélẹ̀ nípa irú omi tí wọ́n fẹ́ kí ara ìlú máa mu. Àmọ́ kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí ìlànà tí wọ́n fi lélẹ̀ náà kò bá dára tó? Èyí lè fa ìgbẹ́ gbuuru fáwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọdé, ó sì lè fa àwọn àrùn mìíràn téèyàn máa ń kó nínú omi. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó o máa jàǹfààní nínú àwọn ìlànà tí ìjọba fi lélẹ̀ nípa irú omi tó yẹ káwọn ará ìlú máa mu. Àjọ Tó Ń Fi Ìlànà Lélẹ̀ fún Àwọn Ilé Iṣẹ́ Lágbàáyé sọ pé: “Tí kò bá sí ìlànà, ojú gbogbo wa ì bá ti já a.” Àjọ yìí tún sọ pé: “A kì í sábàá rí àǹfààní tí ìlànà máa ń mú wá. Bẹ́ẹ̀ ìlànà ló máa ń jẹ́ kí nǹkan táwọn ilé iṣẹ́ ń ṣe jáde jẹ́ ojúlówó, tí kì í wuni léwu, tó máa ń ṣeé fọkàn tẹ̀, tó máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa, téèyàn á sì lè fi èyí tí ilé iṣẹ́ mìíràn ṣe pààrọ̀ rẹ̀ tó bá bà jẹ́. Ìlànà ló sì ń jẹ́ kí wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ ojúlówó bẹ́ẹ̀ jáde ní iye owó tí kò gani lára.”
4 Tó o bá gbà pé àǹfààní wà nínú kéèyàn ní ìlànà tí yóò máa tẹ̀ lé nínú onírúurú nǹkan nígbèésí ayé, ǹjẹ́ o ò gbà pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn retí pé kí Ọlọ́run fi ìlànà lélẹ̀ fún àwọn èèyàn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn?—Ìṣe 15:14.
ǸJẸ́ ÀWỌN ÌLÀNÀ TÍ ỌLỌ́RUN FI LÉLẸ̀ LE JÙ?
5. Báwo ni Jèhófà ṣe tipasẹ̀ Ámósì fi ìjẹ́pàtàkì pípa àwọn ìlànà Rẹ̀ mọ́ hàn?
5 Ó ṣe pàtàkì pé kó o tẹ̀ lé ìlànà tó o bá ń kọ́lé, nítorí pé bí ògiri ẹ̀gbẹ́ kan ò bá dúró ṣánṣán, tó wọ́, ó lè mú kí ilé náà lódindi tẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Tí àlàfo bá sì wà láàárín ògiri ẹ̀gbẹ́ ibí àti tọ̀hún, ilé náà ò ní ṣeé gbé. Ìyẹn ni kókó tó wà nínú ìran kan tí Ámósì rí nípa ipò tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì wà, nígbà tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó rí i tí Jèhófà dúró lórí ògiri ‘pẹ̀lú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́.’ Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò ta okùn ìwọ̀n sáàárín àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi kì yóò tún fàyè gbà á síwájú sí i mọ́.” (Ámósì 7:7, 8) Okùn ìwọ̀n ni wọ́n máa ń lò láti fi mọ̀ bóyá ògiri dúró ṣánṣán, irin kan tàbí òkúta kan sì máa ń wà ní ìparí okùn náà. ‘Okùn ìwọ̀n ni wọ́n fi wọn’ ògiri ìṣàpẹẹrẹ tí Ámósì rí Jèhófà lórí rẹ̀. Ògiri yẹn dúró ṣánṣán, kò tẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò wọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan rárá. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Ámósì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò dúró ṣánṣán mọ́ nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé wọn kì í ṣe olódodo mọ́, wọ́n dà bí ògiri tó tẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tó jẹ́ pé ohun tó kàn ń dúró dè ni pé kí wọ́n dà á wó.
6. (a) Kí ni kókó pàtàkì kan tó wà nínú àwọn ìwé méjìlá náà? (b) Kí nìdí tó o fi lè sọ pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ò le jù?
6 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé táwọn wòlíì méjìlá náà kọ, lemọ́lemọ́ ni wàá máa rí kókó pàtàkì kan. Kókó pàtàkì ọ̀hún ni pé: Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Dídá àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́bi nítorí pé wọn kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kọ́ ni nǹkan kan ṣoṣo tó wà nínú àwọn ìwé wọ̀nyí o. Tí Jèhófà bá ṣàyẹ̀wò àwọn èèyàn náà nígbà mìíràn, ó máa ń rí i pé wọ́n ń pa ìlànà òun mọ́. Bó ṣe ṣeé ṣe fún wọn láti pa àwọn ìlànà náà mọ́ fi hàn pé àwọn ìlànà náà kò le jù; àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé lè pa wọ́n mọ́. Ìwọ wo àpẹẹrẹ kan ná.
7. Báwo ni Sekaráyà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ó ṣeé ṣe fún èèyàn aláìpé láti pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́?
7 Lẹ́yìn táwọn Júù tó padà dé láti ìgbèkùn fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀, iṣẹ́ náà dáwọ́ dúró. Nítorí náà, Jèhófà rán wòlíì Hágáì àti Sekaráyà láti fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n padà sẹ́nu iṣẹ́ náà. Nínú ìran kan tí Jèhófà fi han Sekaráyà, Sekaráyà rí i pé ‘okùn ìwọ̀n wà ní ọwọ́’ Serubábélì gómìnà Júdà nígbà tí gómìnà náà gbé òkúta tó máa wà ní igun tẹ́ńpìlì náà lókè pátápátá sáyè rẹ̀. Èyí fi hàn pé wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà níbàámu pẹ̀lú ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. (Sekaráyà 4:10) Àmọ́ kókó pàtàkì kan wà tó fani lọ́kàn mọ́ra nípa tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ parí náà. Ìwé Sekaráyà sọ pé: “Àwọn méje yìí ni ojú Jèhófà. Wọ́n ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ọlọ́run rí Serubábélì nígbà tí Serubábélì gbé òkúta tó máa wà ní igun tẹ́ńpìlì náà lókè pátápátá sáyè rẹ̀, níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé kò sí ibi tí ojú rẹ̀ kò tó, nígbà tó ṣàyẹ̀wò tẹ́ńpìlì náà fínnífínní, Ó rí i pé wọ́n kọ́ ọ níbàámu pẹ̀lú ìlànà tí Òun fi lélẹ̀! Ohun tí èyí fi hàn ni pé àwọn ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ kò le jù, àwa èèyàn lè pa wọ́n mọ́. Serubábélì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí Hágáì àti Sekaráyà fún wọn níṣìírí. Bíi ti Serubábélì, ìwọ náà lè ṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ rẹ. O ò rí i pé ó fini lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ bẹ́ẹ̀!
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O FARA MỌ́ ÀWỌN ÌLÀNÀ JÈHÓFÀ?
8, 9. (a) Kí nìdí tó fi bẹ́tọ̀ọ́ mu pé kí Jèhófà máa fi ìlànà lélẹ̀ fáwa ẹ̀dá èèyàn? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pa àṣẹ òun mọ́?
8 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìlànà lélẹ̀ fún àwa èèyàn kó sì retí pé ká máa pa á mọ́. (Ìṣípayá 4:11) Kò pọn dandan kí Jèhófà sọ gbogbo ohun tó dára àti gbogbo ohun tí kò dára fún wa, nítorí pé ó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn tó ń tọ́ wa sọ́nà. (Róòmù 2:14, 15) Ọlọ́run sọ fáwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ pé kí wọ́n má ṣe jẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” èyí tó dúró fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti máa fi ìlànà lélẹ̀ nípa ohun tó dára àtohun tó burú. Ìwọ náà mọ ohun táwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ wọ̀nyẹn ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:1-19) Ìpinnu burúkú tí Ádámù ṣe ni Hóséà dọ́gbọ́n mẹ́nu kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn [ọmọ Ísírẹ́lì] fúnra wọn, gẹ́gẹ́ bí ará ayé, ti tẹ májẹ̀mú lójú.” (Hóséà 6:7) Nípa bẹ́ẹ̀, Hóséà fi hàn pé ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀.
9 Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n dá? “Wọ́n tẹ májẹ̀mú [Òfin] lójú.” (Bí Bíbélì New International Version ṣe kà) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá àwọn èèyàn náà nídè kúrò ní Íjíbítì, òun ló ni wọ́n, ó sì hàn gbangba pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fi ìlànà lélẹ̀ fún wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fara mọ́ májẹ̀mú tí Jèhófà bá wọn dá, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé àwọn á máa gbé ìgbé ayé àwọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. (Ẹ́kísódù 24:3; Aísáyà 54:5) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ni kò pa Òfin náà mọ́. Wọ́n ń tàjẹ̀ sílẹ̀, wọ́n di apààyàn, wọ́n sì ń ṣàgbèrè.—Hóséà 6:8-10.
10. Kí ni Ọlọ́run ṣe láti ran àwọn tí kò pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́?
10 Jèhófà rán àwọn wòlíì tí Hóséà jẹ́ ọ̀kan lára wọn pé kí wọ́n lọ ran àwọn èèyàn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Òun lọ́wọ́. Níparí ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tí Hóséà kọ, Hóséà kéde pé: “Ta ni ó gbọ́n, kí ó lè lóye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó lóye, kí ó lè mọ̀ wọ́n? Nítorí àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán, àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn; ṣùgbọ́n àwọn olùrélànàkọjá ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.” (Hóséà 14:9) Ní ìbẹ̀rẹ̀ Hóséà orí kẹrìnlá, a rí i pé wòlíì náà tẹnu mọ́ ọn pé àwọn èèyàn náà ní láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ẹni tó bá gbọ́n á rí i pé Jèhófà ti lànà àwọn ọ̀nà dídúró ṣánṣán tó fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ máa tọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ṣèyàsímímọ́, ó dájú pé ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kó o máa bá a lọ láti jẹ́ adúróṣánṣán, kó o máa rìn láwọn ọ̀nà Jèhófà.
11. Kí nìdí tó o fi fẹ́ láti máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́?
11 Bákan náà, Hóséà 14:9 jẹ́ ká rí àwọn àǹfààní tí jíjẹ́ adúróṣánṣán máa ń mú wá. Ìbùkún yàbùgà-yabuga àti èrè ńlá lèèyàn máa ń rí téèyàn bá ń ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ. Nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá, ó mọ̀ wá láìkù síbì kan. Nítorí náà, àǹfààní ara wa làwọn nǹkan tó ń béèrè lọ́wọ́ wa wà fún. Jẹ́ ká fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ẹni tó ṣe é ṣàpèjúwe bá a ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run. Ṣé o mọ̀ pé ẹni tó ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mọ ọ̀nà tóun gbà ṣe é àti bóun ṣe to gbogbo àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ pọ̀ tó fi di odindi ọkọ̀. Ẹni tó ṣe é náà tún mọ̀ pé ẹni tó bá ń lò ó gbọ́dọ̀ máa fi ọ́ìlì, ìyẹn epo kíki sí i lóòrèkóòrè. Àmọ́ tí ìwọ bá rò pé kò pọn dandan kó o pa ìlànà yẹn mọ́ nítorí pé ọkọ̀ náà ń sáré dáadáa, tí o kò wá fi ọ́ìlì sí i, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀? Kò ní pẹ́ tí ọkọ̀ náà ò fi ní lè rìn dáadáa mọ́, tó bá sì yá, á dúró. Bí ọ̀rọ̀ àwa èèyàn ṣe rí nìyẹn. Ẹni tó dá wa ti pàṣẹ fún wa. Àǹfààní ara wa ni tá a bá ń pa àwọn àṣẹ náà mọ́. (Aísáyà 48:17, 18) Àǹfààní tá à ń rí bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run jẹ́ ìdí mìíràn tó fi yẹ ká máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.—Sáàmù 112:1.
12. Báwo ni rírìn ní orúkọ Ọlọ́run ṣe lè mú kí okùn àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ yi?
12 Èrè gíga jù lọ tí ẹni tó bá ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ á ní ni àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run. Tá a bá ń gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ rẹ̀ tá a sì rí i pé àwọn àṣẹ náà bọ́gbọ́n mu wọ́n sì tún ń ṣeni láǹfààní, a óò túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ẹni tó pa àwọn àṣẹ náà. Wòlíì Míkà ṣàpèjúwe àjọṣe yẹn lọ́nà tó wuni, ó ní: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa rìn ní orúkọ Jèhófà, láti máa gbé orúkọ rere rẹ̀ lárugẹ ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ nígbèésí ayé wa! Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ẹni bí ni là á jọ, a fẹ́ láti máa fara wé e. Ẹ jẹ́ kí kálukú wa sapá láti jẹ́ kí okùn àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ yi.—Sáàmù 9:10.
13. Kí nìdí tí ìbẹ̀rù téèyàn máa ń ní fún orúkọ Ọlọ́run kì í fi í ṣe ìbẹ̀rù tí ń múni gbọ̀n jìnnìjìnnì?
13 Bíbélì sọ pé àwọn tó ń pa ìlànà Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n sì ń rìn ní orúkọ rẹ̀ máa ń bẹ̀rù orúkọ rẹ̀. Èyí kì í ṣe ìbẹ̀rù tó ń múni gbọ̀n jìnnìjìnnì o. Jèhófà mú un dá àwọn tó ń bẹ̀rù orúkọ rẹ̀ lójú pé: “Oòrùn òdodo yóò sì ràn dájúdájú fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, pẹ̀lú ìmúniláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; ẹ ó sì jáde lọ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra.” (Málákì 4:2) Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Jésù Kristi ni “oòrùn òdodo” náà. (Ìṣípayá 1:16) Ní báyìí, ó ń ràn bí oòrùn pẹ̀lú ìmúláradá nípa tẹ̀mí, tí àkókò bá sì tó, yóò ràn bí oòrùn pẹ̀lú ìmúláradá nípa tara, ìyẹn ni pé yóò mú aráyé lára dá nípa tara. Málákì fi ayọ̀ tí àwọn tá a bá mú lára dá yóò ní wé ayọ̀ màlúù àbọ́sanra ‘tó ń fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bó ṣe ń lọ,’ inú wọn á máa dùn pé àwọn ti dòmìnira. Kódà nísinsìnyí, ǹjẹ́ o ò ti ní òmìnira tó pabanbarì?—Jòhánù 8:32.
14, 15. Àwọn ọ̀nà wo lo gbà ń jàǹfààní nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà Jèhófà?
14 Ọ̀nà kejì tó o lè gbà jàǹfààní nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run ni pé àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn yóò máa dára sí i. Hábákúkù kéde ègbé márùn-ún, èkíní sórí àwọn tó ń ṣojú kòkòrò, èkejì sórí àwọn tó ń wá èrè àbòsí, ẹ̀kẹta sórí àwọn tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀kẹrin sórí àwọn tó ń pète pèrò láti ṣèṣekúṣe, ẹ̀karùn-ún sórí àwọn tó ń bọ̀rìṣà. (Hábákúkù 2:6-19) Kíké tí Jèhófà kéde àwọn ègbé wọ̀nyí fi hàn kedere pé ó ti fi ìlànà lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa. Àmọ́ o, kíyè sí i pé: Mẹ́rin nínú àwọn ìwàkiwà márùn-ún tí Hábákúkù mẹ́nu kàn ló jẹ mọ́ bá a ṣe ń bá àwọn ẹ̀dá èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa lò. Tá a bá ní èrò tí Ọlọ́run ní, a ò ní pa àwọn aládùúgbò wa lára, ìyẹn á sì jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ jù lọ wọn dára sí i.
15 Ayọ̀ tá a máa ń ní nínú ìdílé wa ni ọ̀nà kẹta tá a gbà ń jàǹfààní nínú títẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run. Lóde òní, ìkọ̀sílẹ̀ làwọn èèyàn sábà máa ń kà sí ojútùú gbọ́nmi-si-omi-ò-to, èyí tó máa ń wáyé láàárín tọkọtaya. Àmọ́ Jèhófà gbẹnu wòlíì Málákì sọ pé: “Òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.” (Málákì 2:16) Tó bá yá, a óò gbé Málákì 2:16 yẹ̀ wò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, àmọ́ ní báyìí, o ti rí i pé ẹsẹ Bíbélì náà fi hàn pé Ọlọ́run ti fi ìlànà lélẹ̀ fún bàbá, ìyá, àtàwọn ọmọ; bí wọ́n bá sì ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà tó, bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà yóò ṣe wà nínú ilé wọn tó. (Éfésù 5:28, 33; 6:1-4) Òótọ́ ni pé aláìpé ni gbogbo wa, nítorí náà ìṣòro ò lè ṣe kó máà wáyé. Àmọ́ ‘Ẹni náà tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti ní orí ilẹ̀ ayé gba orúkọ lọ́dọ̀ rẹ̀’ fún wa ní àpẹẹrẹ tó ṣeé fojú rí nínú ìwé Hóséà láti fi hàn pé, kódà àwọn ìṣòro tó le gan-an tó máa ń wáyé láàárín tọkọtaya ṣeé yanjú. A ṣì máa gbé ìyẹn náà yẹ̀ wò ní orí kan tó ṣì wà níwájú nínú ìwé yìí. (Éfésù 3:15) Wàyí o, jẹ́ ká tún wo àwọn nǹkan mìíràn to jẹ́ ara pípa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́.
“Ẹ KÓRÌÍRA OHUN BÚBURÚ, KÍ Ẹ SÌ NÍFẸ̀Ẹ́ OHUN RERE”
16. Kí ni Ámósì 5:15 sọ fún wa nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run?
16 Ìpinnu òmùgọ̀ ni Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ ṣe nígbà tó ń yan ẹni tó gbà pé ó ní ìlànà tó dára jù lọ lórí ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ǹjẹ́ àwa máa fi ọgbọ́n yan ohun tó dára ní tiwa? Ámósì gbà wá níyànjú pé, nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún, ká ní ìkórìíra tó ga fún ohun tí kò dára, ká sì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ohun rere. Ó rọ̀ wá pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:15) Olóògbé William Rainey Harper tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àwọn èdè tí àwọn ẹ̀yà ìran Ṣémù ń sọ, tó sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì tó wà ní Chicago, kọ àkíyèsí tó ṣe nípa ẹsẹ Bíbélì yìí, pé: “Ìlànà ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ tí [Ámósì] ní lọ́kàn ni pé kéèyàn máa gbé ìgbé ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Yahweh.” Èyí jẹ́ kókó pàtàkì kan tá a rí kọ́ nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà. Ǹjẹ́ a múra tán láti fara mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? Bíbélì ló fi àwọn ìlànà ọ̀hún hàn wá, àwọn tó sì ń ṣàlàyé rẹ̀ fún wa ni àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì nírìírí, tí wọ́n para pọ̀ di “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mátíù 24:45-47.
17, 18. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kórìíra ohun tó burú? (b) Fi àpẹẹrẹ kan ṣàlàyé bá a ṣe lè máa ní ìkórìíra tó ga fún ohun tó burú.
17 Tá a bá kórìíra ohun tó burú, á ṣeé ṣe fún wa láti máa yàgò fún àwọn ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè mọ̀ pé ewu ń bẹ nínú kéèyàn máa wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sì lè máa gbìyànjú láti má ṣe wò ó. Àmọ́, ‘ní inú lọ́hùn-ún,’ báwo làwọn àwòrán oníhòòhò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe rí lọ́kàn rẹ̀? (Éfésù 3:16) Tó bá fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ọlọ́run sọ, tó wà ní Ámósì 5:15 sílò, yóò túbọ̀ rọrùn fún un láti kórìíra ohun tí kò dára. Ìyẹn á sì jẹ́ kó jagun mólú bó ṣe ń sapá láti yàgò fún àwọn ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́.
18 Àpẹẹrẹ mìíràn rèé: Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ara rẹ tó ò ń dọ̀bálẹ̀ níwájú òrìṣà ìjọsìn ìbálòpọ̀? Kéèyàn tiẹ̀ ronú nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lásán máa kóòyàn nírìíra gan-an ni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣùgbọ́n, o jẹ́ mọ̀ pé Hóséà sọ pé àwọn baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣèṣekúṣe níwájú Báálì Péórù. (Númérì 25:1-3; Hóséà 9:10) Ó ṣe kedere pé ìdí tí Hóséà fi mẹ́nu kan èyí ni pé ìjọsìn Báálì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan tí wọ́n ń dá ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. (2 Àwọn Ọba 17:16-18; Hóséà 2:8, 13) Tiẹ̀ jẹ́ ká fojú inú wo ohun tí wọ́n ń ṣe ná: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń tẹrí bá fún òrìṣà níbi àríyá tí wọ́n kanlẹ̀ ṣètò fún ìbálòpọ̀ aláìnítìjú. Mímọ bí Ọlọ́run ṣe kórìíra irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tó á ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti máa sa gbogbo ipá wa ká má bàa kó sínú okùn tí Sátánì fẹ́ dẹ mú wa nípasẹ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ àwọn òrékelẹ́wà obìnrin àtàwọn arẹwà ọkùnrin tí wọ́n máa ń lò nínú àwọn ìpolówó ọjà tó gbajúmọ̀ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Àmọ́ ní tiwa, a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìkìlọ̀ táwọn wòlíì náà ṣe nípa ìjọsìn òrìṣà.
MÁA FI Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SỌ́KÀN
19. Kí lo lè rí kọ́ nínú ohun tí Jónà ṣe nígbà tó wà nínú ikùn ẹja ńlá náà?
19 Bó o ṣe ń sapá láti pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ lákòókò ìṣòro àti ìdẹwò, nígbà mìíràn, ó lè ṣe ọ́ bíi pé o ò ní lè jagun mólú tàbí kó o má mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Tó o bá wà ní ipò kan tó le gan-an, tó sì dà bíi pé agbára rẹ ti kéré jọjọ débi pé o ò lè ronú lọ́nà tó já gaara láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, báwo lo ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú bíbójútó ipò náà? (Òwe 24:10) Ó dáa, nǹkan kan wà tó o lè kọ́ lára Jónà, tó jẹ́ aláìpé bíi tiwa tó sì ṣe àṣìṣe. Ṣé o rántí ohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ikùn ẹja ńlá náà? Ó gbàdúrà sí Jèhófà. Wo àwọn ohun tó sọ nínú àdúrà rẹ̀.
20. Báwo lo ṣe lè dẹni tó gbára dì láti ṣe ohun tí Jónà ṣe?
20 Nígbà tí Jónà gbàdúrà sí Ọlọ́run “láti inú ikùn Ṣìọ́ọ̀lù,” ó lo ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tó mọ̀, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù. (Jónà 2:2) Ìdààmú bá a gidigidi ó sì bẹ Jèhófà pé kó dákun kó ṣíjú àánú rẹ̀ wo òun, síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ló bọ́ sí Jónà lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, fi àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Jónà 2:3, 5 wé èyí tó wà ní Sáàmù 69:1, 2.a Ǹjẹ́ kò hàn gbangba pé wòlíì Jónà mọ àwọn sáàmù Dáfídì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn onímìísí tó wà nínú àwọn sáàmù wá sọ́kàn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run “ń bẹ ní ìhà inú” Jónà. (Sáàmù 40:8) Tí ìwọ náà bá wà nínú ipò tó le gan-an, ǹjẹ́ o lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run sọ tó bá ipò náà mu? Tó o bá ń gbìyànjú láti mọ ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nísinsìnyí, ìyẹn á lè ràn ọ́ lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú nígbà tó o bá fẹ́ ṣèpinnu tó o sì fẹ́ yanjú àwọn ìṣòro lọ́nà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu.
NÍ ÌBẸ̀RÙ TÓ YẸ FÚN ỌLỌ́RUN
21. Kí lo gbọ́dọ̀ ní kó o lè máa pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ láìyẹsẹ̀?
21 Ká sòótọ́, kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kàn wà ní ọkàn rẹ nìkan kọ́ ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́ láìyẹsẹ̀. Wòlíì Míkà tún jẹ́ ká mọ ohun mìíràn tó yẹ kó o ní kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, ó ní: “Ẹni tí ó ní ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ yóò sì bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Míkà 6:9) Kó o tó lè di ẹni tó ní ọgbọ́n gbígbéṣẹ́, ìyẹn ẹni tó lè fi ohun tó mọ̀ sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀, o gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù fún orúkọ Ọlọ́run.
22, 23. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi rán Hágáì sáwọn Júù tó padà dé láti ìgbèkùn? (b) Kí nìdí tó o fi lè ní ìdánilójú pé á ṣeé ṣe fún ọ láti pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́?
22 Báwo lo ṣe lè mọ bí wàá ṣe máa bẹ̀rù orúkọ Ọlọ́run? Hágáì tó sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ìgbèkùn Bábílónì dé ni yóò jẹ́ kó o mọ̀ ọ́n. Nínú ìwé rẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gùn, tó jẹ́ ẹsẹ méjìdínlógójì [38] péré, ìgbà márùndínlógójì [35] ló mẹ́nu kan orúkọ náà, Jèhófà! Ní ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni tí Jèhófà fiṣẹ́ rán Hágáì pé kó sọ tẹ́lẹ̀, ó ti lé ní ọdún mẹ́rìndínlógún táwọn èèyàn Ọlọ́run ti ti ìgbèkùn dé, àmọ́ wọn ò tíì bá iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù débì kan. Àtakò táwọn ọ̀tá wọn ń ṣe sí wọn sọ ọkàn wọn domi. (Ẹ́sírà 4:4, 5) Èrò wọn ni pé àkókò kò tíì tó láti tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Ni Jèhófà bá ṣí wọn létí pé: ‘Ẹ fi ọkàn yín sí àwọn ọ̀nà yín. Ẹ kọ́ ilé náà, kí n lè ní ìdùnnú nínú rẹ̀, kí a sì lè yìn mí lógo.’—Hágáì 1:2-8.
23 Gómìnà Serubábélì, Jóṣúà Àlùfáà Àgbà àti “gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn, . . . àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù nítorí Jèhófà.” Ni Ọlọ́run bá sọ fún wọn pé: “Èmi wà pẹ̀lú yín.” Ọ̀rọ̀ yìí mà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ ò! Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, àwọn èèyàn náà “bẹ̀rẹ̀ sí wọlé, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ilé Jèhófà.” (Hágáì 1:12-14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ń ṣàtakò sí àwọn èèyàn tí ọkàn wọn ti domi yìí, ìbẹ̀rù yíyẹ tí wọ́n ní, pé àwọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, mú kí wọ́n ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe.
24, 25. Fi àwọn àpẹẹrẹ pàtó ṣe àpèjúwe bó o ṣe lè lo àwọn ìlànà tó wà ní orí yìí.
24 Ìwọ ńkọ́? Tó o bá bá ara rẹ ní ipò kan, tó o sì mọ ohun tí àwọn ìlànà Ọlọ́run sọ nípa ipò náà, ǹjẹ́ wàá ní ìgboyà láti bẹ̀rù Jèhófà dípò èèyàn? Bí àpẹẹrẹ, ká ní o jẹ́ ọ̀dọ́bìnrin, tí ọkùnrin kan tí kò mọ ìlànà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe mọ̀ ọ́n wà ní ibi tó o ti ń ṣiṣẹ́. Ọkùnrin tá à ń wí yìí máa ń ṣaájò rẹ ó sì máa ń ṣe inúure sí ọ. Ǹjẹ́ wàá rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kankan tó máa rán ọ létí àwọn ìlànà Jèhófà àti ewu tó lè wu ọ́ tí o kò bá pa àwọn ìlànà náà mọ́? Bí àpẹẹrẹ, ṣé wàá rántí Hóséà 4:11 tó sọ pé: “Àgbèrè àti wáìnì àti wáìnì dídùn ni ohun tí ń gba ète rere kúrò”? Pẹ̀lú ẹsẹ Bíbélì yìí lọ́kàn rẹ, ǹjẹ́ ìbẹ̀rù tó o ní fún Ọlọ́run á mú kó o rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀ kó o sì kọ̀ bí ọkùnrin náà bá ní kó o wá síbi àpèjẹ kan? Tó bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọ tage, ìbẹ̀rù pé o kò fẹ́ ṣe ohun tó máa dun Ọlọ́run tó fẹ́ràn rẹ ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti “fẹsẹ̀ fẹ.”—Jẹ́nẹ́sísì 39:12; Jeremáyà 17:9.
25 Ní báyìí, jẹ́ ká padà sórí àpẹẹrẹ ọkùnrin tó ń gbìyànjú láti má ṣe wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ọkùnrin náà rántí àdúrà tó wà ní Sáàmù 119:37, tó sọ pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí”? Ǹjẹ́ yóò fọkàn rẹ̀ ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nígbà ìwàásù tó ṣe lórí òkè, pé “olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀”? (Mátíù 5:28) Ó yẹ kí ìbẹ̀rù tí Kristẹni kan ní fún Jèhófà àti fífẹ́ tó fẹ́ láti máa pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́ mú kó yẹra fún ohunkóhun tó lè ba ìwà ẹni jẹ́. Ìgbàkigbà tó bá ń ṣe ọ́ bíi pé kó o ronú lọ́nà tí kò bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu, gbìyànjú láti jẹ́ kí ìbẹ̀rù tó o ní fún Ọlọ́run pọ̀ sí i. Sì máa fi sọ́kàn pé Jèhófà sọ fún ọ nípasẹ̀ Hágáì pé: ‘Èmi wà pẹ̀lú rẹ.’
26. Kí la ṣì máa gbé yẹ̀ wò nínú ìwé yìí?
26 Dájúdájú, o lè sin Jèhófà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀ kó o sì jàǹfààní rẹ̀. Bó o ṣe ń bá àgbéyẹ̀wò àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ náà nìṣó, kedere ni wàá túbọ̀ máa rí àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, tàbí lédè mìíràn, àwọn ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ìsọ̀rí tó kàn nínú ìwé yìí yóò sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìhà pàtàkì mẹ́ta tí Jèhófà ti fi àwọn ìlànà rere lélẹ̀. Àwọn ìhà náà ni: ìwà wa, bá a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò, àti ìdílé wa.