“Ẹ Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Èrò Inú Di Ara Yín Lámùrè”
“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 PÉTÉRÙ 5:5.
1, 2. Ìwà méjì wo tó jẹ mọ́ èrò inú ló ń ní ipa tó jinlẹ̀ lórí ìwà ènìyàn?
LÁRA àwọn ìwà tó jẹ mọ́ èrò inú wa tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú wá sí àfiyèsí wa ni àwọn ìwà méjì kan, tí wọ́n yàtọ̀ síra pátápátá. Àwọn ìwà méjèèjì yìí ló ń nípa tó jinlẹ̀ lórí ìwà ènìyàn. A ṣàpèjúwe ìkan gẹ́gẹ́ bí “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.” (1 Pétérù 5:5) Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ “ìrẹ̀lẹ̀” sí “jíjẹ́ ẹni tí kò ní ìwà tàbí ẹ̀mí ìrera: yíyàgò fún ẹ̀mí ìgbéraga tí ń múni ganpá.” Níní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹni tí kò lẹ́mìí ìgbéraga, táa bá sì wo ojú tí Ọlọ́run fi wo ànímọ́ yìí, ànímọ́ tó dára gan-an ni.
2 Òdìkejì èyí ni ìgbéraga. Èyí ló túmọ̀ sí “jíjọra ẹni lójú jù,” jíjẹ́ ẹni tí ń “tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlòmíràn.” Ẹ̀mí anìkànjọpọ́n ló jẹ́, tó bá sì ń wá nǹkan ti ara, tó bá ń wá ògo tiẹ̀, àti àwọn àǹfààní mìíràn, kì í bìkítà rárá nípa ìpalára tí èyí lè ṣe fáwọn ẹlòmín-ìn. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun kan tí èyí ti yọrí sí, ó ní: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” Ó sọ nípa “bíbá ẹnì kìíní-kejì díje” pé, “lílépa ẹ̀fúùfù” ló jẹ́, nítorí pé lọ́jọ́ tíkú bá dé, “ènìyàn kò . . . lè kó nǹkan kan lọ.” Ọlọ́run ò fẹ́ ìgbéraga rárá.—Oníwàásù 4:4; 5:15; 8:9.
Ẹ̀mí Tó Gbayé Kan
3. Ẹ̀mí wo ló gbayé kan?
3 Nínú àwọn ìwà méjèèjì tó jẹ mọ́ èrò inú yìí, èwo ló wọ́pọ̀ nínú ayé lónìí? Ẹ̀mí wo ló gbayé kan? Ìwé náà, World Military and Social Expenditures 1996, sọ pé: “Kò sí ọ̀rúndún mìíràn tó wà lákọọ́lẹ̀ táa tún lè fi wé ọ̀rúndún ogún yìí tó bá kan ti ìwà ipá . . . tó kún fún òǹrorò.” Dídíje fún ipò ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ ajé—títí kan ìdíje láàárín orílẹ̀-èdè kan sí ìkejì, ìdíje láàárín ẹ̀sìn kan sí òmíràn, láàárín ẹ̀yà kan sí ìkejì, àti láàárín àwùjọ kan sí òmíràn—ti gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní ọ̀rúndún yìí. Ṣe làwọn tí ń hùwà anìkànjọpọ́n kàn ń pọ̀ sí i ṣáá. Ìwé ìròyìn, Chicago Tribune, sọ pé: “Lára àwọn àrùn tó wà láwùjọ wa ni ìwà ipá tó fi àìní làákàyè hàn, híhùwà àìdáa sáwọn ọmọdé, ìkọ̀sílẹ̀, ìmutípara, àrùn AIDS, àwọn ọ̀dọ́langba tí ń fọwọ́ ara wọn para wọn, ìjoògùnyó, àwọn ọmọọ̀ta, ìfipábánilòpọ̀, bíbí ọmọ àlè, oyún ṣíṣẹ́, ìwé àti àwòrán tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, . . . irọ́ pípa, lílu jìbìtì, ìwà ìbàjẹ́ àwọn òṣèlú . . . A ti pa ìlànà ìwà híhù nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ rẹ́ pátápátá.” Abájọ, tí ìwé ìròyìn UN Chronicle fi kìlọ̀ pé: “Àwùjọ wa mà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ run tán o.”
4, 5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ọjọ́ wa ṣe ṣàpèjúwe ẹ̀mí tó gbayé kan lọ́nà tó ṣe rẹ́gí?
4 Ipò wọ̀nyí wà káàkiri àgbáyé. Gẹ́lẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò rí ní àkókò wa ló ṣe rí, ó wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.”—2 Tímótì 3:1-4.
5 Rẹ́gí ni àpèjúwe yẹn ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí tó gbayé yìí kan. Ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, ẹ̀mí tèmi-làkọ́kọ́ ló gbayé kan. Ẹ̀mí ìdíje tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè náà là ń rí láàárín àwọn èèyàn. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìdíje eré ìdárayá, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń kópa ló ṣáà fẹ́ ṣepò kìíní láìkọ ohun tí èyí lè dà, bóyá ó lè mú ẹ̀dùn-ọkàn bá àwọn ẹlòmíràn tàbí kó tilẹ̀ ṣe wọ́n léṣe, ìyẹn ò kàn wọ́n. Wọ́n ti gbé ẹ̀mí anìkànjọpọ́n yìí lárugẹ láàárín àwọn ọmọdé, wọ́n sì tún ń bá a nìṣó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi tí ẹ̀mí náà ti wọnú ìgbésí ayé àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú. Ó ti yọrí sí “ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà.”—Gálátíà 5:19-21.
6. Ta ní ń gbé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan lárugẹ, ojú wo sì ni Jèhófà fi ń wo irú ìrònú yìí?
6 Bíbélì fi hàn pé ẹ̀mí anìkànjọpọ́n tó wà nínú ayé yìí fi ẹ̀mí tó wà nínú “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì” hàn, “ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Nígbà tí Bíbélì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ipa tí Sátánì yóò ní lórí àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí ó le koko wọ̀nyí, ó wí pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:9-12) Nítorí náà, òun pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù, tí wọ́n jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ti fi kún ìsapá wọn láti gbé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan lárugẹ láàárín ìdílé ẹ̀dá ènìyàn. Ojú wo sì ni Jèhófà fi ń wo irú ìwà bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Owe 16:5.
Ọ̀dọ́ Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà Wà
7. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn onírẹ̀lẹ̀, kí sì ni èyí kọ́ wọn?
7 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà ń bù kún àwọn tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú. Nínú orin tí Dáfídì Ọba kọ sí Jèhófà, ó wí pé: “Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ìwọ yóò sì gbà là; ṣùgbọ́n ojú rẹ lòdì sí àwọn onírera, kí o lè rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 22:1, 28) Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Sefanáyà 2:3) Jèhófà ń kọ́ àwọn tí wọ́n bá fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wá a, ó ń kọ́ wọn pé kí wọ́n ní ẹ̀mí tó yàtọ̀ pátápátá sí ti ayé yìí. “Yóò . . . kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.” (Sáàmù 25:9; Aísáyà 54:13) Ọ̀nà yẹn ni ọ̀nà ìfẹ́. A gbé e ka ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, ìfẹ́ tí a gbé ka ìlànà yìí “kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:1-8) Ó tún ń fi ara rẹ̀ hàn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.
8, 9. (a) Níbo ni ìfẹ́ táa gbé ka ìlànà ti pilẹ̀? (b) Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó láti fara wé ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi hàn?
8 Pọ́ọ̀lù àti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kọ́ irú ìfẹ́ yìí nínú ẹ̀kọ́ Jésù. Jésù pẹ̀lú kọ́ ọ lọ́dọ̀ Jèhófà, Baba rẹ̀, ẹni tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Jésù mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún òun ni pé kí òun gbé ìgbésí ayé tó bá òfin ìfẹ́ mu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 6:38) Ìdí nìyẹn tó fi ní ìyọ́nú sí àwọn táa ni lára, àwọn òtòṣì, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Mátíù 9:36) Ó wí fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi.”—Mátíù 11:28, 29.
9 Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ ìjẹ́pàtàkì fífarawé ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, nígbà tó sọ fún wọn pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Wọn yóò dá yàtọ̀ gédégbé nínú ayé tí ìwà anìkànjọpọ́n ti wọ̀ lẹ́wù yìí. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14) Rárá o, wọn kì í fara wé ẹ̀mí ayé Sátánì, ẹ̀mí ìgbéraga, tó jẹ́ tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fara wé ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn tí Jésù fi hàn.
10. Kí ni Jèhófà ń ṣe pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọjọ́ wa?
10 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, a óò kó àwọn onírẹ̀lẹ̀ jọ sínú àwùjọ kan tó wà káàkiri àgbáyé, àwùjọ táa gbé ka ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé, nínú ayé tí ìgbéraga ń pa kú lọ yìí, àwọn ènìyàn Jèhófà ń fi ìwà tó yàtọ̀ pátápátá hàn—ìyẹn ni ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú. Ohun tí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ń sọ ni pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà [ìjọsìn rẹ̀ tòótọ́ tí a gbé ga], . . . òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” (Aísáyà 2:2, 3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ àwùjọ tó wà káàkiri àgbáyé yìí, àwùjọ àwọn tí ń rìn ní ipa ọ̀nà Ọlọ́run. Nínú wọn la ti rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí nísinsìnyí. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wọn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Ní Ìrẹ̀lẹ̀ Èrò Inú
11, 12. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú hàn?
11 Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tó ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ bí wọn yóò ṣe borí ẹ̀mí burúkú ti ayé yìí, kí wọ́n sì wá fi èso ẹ̀mí ti Ọlọ́run hàn. Èso yìí ń fi ara rẹ̀ hàn nínú “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn dàgbà, a ń fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe di ‘ẹni tí ń gbé ara wọn lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Gálátíà 5:26) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.”—Róòmù 12:3.
12 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti má ṣe “ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn [àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run] lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:3, 4) “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Bẹ́ẹ̀ ni, “ìfẹ́ a máa gbé [àwọn ẹlòmíràn] ró,” nígbà tí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa bá fi hàn pé a kò lẹ́mìí tara wa nìkan. (1 Kọ́ríńtì 8:1) Ó ń gbé ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lárugẹ, kì í ṣe ẹ̀mí ìbánidíje. Kò sáyè fún ẹ̀mí tèmi-làkọ́kọ́ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.
13. Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, báwo ni ẹnì kan sì ṣe lè kọ́ ọ?
13 Ṣùgbọ́n, nítorí àìpé táa ti jogún, a kò bí ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú mọ́ wa. (Sáàmù 51:5) A gbọ́dọ̀ kọ́ ànímọ́ yìí ni. Èyí sì lè ṣòro fáwọn tó jẹ́ pé a kò fi ọ̀nà Jèhófà kọ́ wọn láti kékeré, tó jẹ́ pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn la ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fi kọ́ wọn. Ṣáájú ìgbà yìí, ìṣarasíhùwà ayé ògbólógbòó yìí ti mú kí wọ́n ní àwọn ànímọ́ kan. Nítorí náà, wọ́n ní láti kọ́ bí wọn yóò ṣe “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà [wọn] àtijọ́ ṣe déédéé,” lẹ́yìn náà, ni wọn yóò wá kọ́ bí wọn yóò ṣe “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22, 24) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, àwọn olóòótọ́ ọkàn lè ṣe ohun tó béèrè lọ́wọ́ wọn, pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:12.
14. Báwo ni Jésù ṣe kìlọ̀ nípa kí ẹnì kan fẹ́ máa gbé ara rẹ̀ ga?
14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní láti kọ́ ìwà yẹn. Wọ́n ti dàgbà kí wọ́n tó di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, bó sì ṣe wù kó mọ, ẹ̀mí ayé, ẹ̀mí ìbánidíje ti wà nínú wọn. Nígbà tí ìyá àwọn méjì lára wọn wá fẹ́ gba ipò ọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀, Jésù wí pé: “Àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn [Jésù] ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:20-28) Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe lo orúkọ oyè, kó má bàa di pé wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ara wọn ga, ó fi kún un pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín.”—Mátíù 23:8.
15. Ẹ̀mí wo làwọn tó bá fẹ́ dé ipò alábòójútó gbọ́dọ̀ ní?
15 Ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ jẹ́ ìránṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni, ẹrú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ló jẹ́. (Gálátíà 5:13) Èyí rí bẹ́ẹ̀, pàápàá jù lọ fáwọn tó fẹ́ di alábòójútó nínú ìjọ. Wọn ò gbọ́dọ̀ bá ara wọn díje fún ipò tàbí agbára; wọn ò ní ‘máa ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí wọ́n di àpẹẹrẹ fún wọn.’ (1 Pétérù 5:3) Ká sọ̀rọ̀ síbi ọ̀rọ̀ wà, ẹ̀mí wíwá ire tara ẹni nìkan ń fi hàn pé ẹnì kan ò tóótun láti jẹ́ alábòójútó. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò pa ìjọ lára. Lóòótọ́, ó yẹ ká “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó,” ṣùgbọ́n ìfẹ́ láti sin àwọn Kristẹni yòókù ló yẹ kó sún wa ṣe bẹ́ẹ̀. Ipò yìí kì í ṣe ipò táa fi ń fẹlá tàbí táa fi ń lo agbára lórí ẹni, torí pé àwọn tí wọ́n wà ní ipò alábòójútó gan-an ló yẹ kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú jù lọ nínú ìjọ.—1 Tímótì 3:1, 6.
16. Èé ṣe táa fi bá Dìótíréfè wí kíkankíkan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
16 Àpọ́sítélì Jòhánù pe àfiyèsí wa sí ẹnì kan tó lérò òdì, ó sọ pé: “Mo kọ̀wé ohun kan sí ìjọ, ṣùgbọ́n Dìótíréfè, ẹni tí ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́ láàárín wọn, kò fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ wa.” Ipò gíga tó gba ọkùnrin tì à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí lọ́kàn kò jẹ́ kó bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmín-ìn rárá. Nítorí èyí, ẹ̀mí Ọlọ́run sún Jòhánù láti fi ìbáwí kíkan tí a fún Dìótíréfè nítorí ẹ̀mí tèmi-làkọ́kọ́ tó ní sí inú Bíbélì.—3 Jòhánù 9, 10.
Ẹ̀mí Tó Dáa
17. Báwo ni Pétérù, Pọ́ọ̀lù, àti Bánábà ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú hàn?
17 Àpẹẹrẹ pọ̀ rẹpẹtẹ nínú Bíbélì tó jẹ́ ti ẹ̀mí tó dáa, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú. Nígbà tí Pétérù wọnú ilé Kọ̀nílíù, ṣe ni ọkùnrin yẹn “wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ [Pétérù], [tí] ó sì wárí fún un.” Ṣùgbọ́n dípò tí Pétérù yóò fi tẹ́wọ́ gba àpọ́nlé tó pọ̀ lápọ̀jù yìí, “[ó] gbé e sókè, ó wí pé: ‘Dìde; ènìyàn ni èmi náà.’” (Ìṣe 10:25, 26) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wà ní Lísírà, Pọ́ọ̀lù mú ọkùnrin kan táa bí ní arọ lára dá. Kí la máa rí, làwọn èrò bá sọ pé ọlọ́run làwọn àpọ́sítélì wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà “fa ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn ya, wọ́n sì fò sáàárín ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n ń ké jáde, wọ́n sì wí pé: ‘Ẹ̀yin ènìyàn, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní àwọn àìlera kan náà tí ẹ̀yin ní.’” (Ìṣe 14:8-15) Àwọn Kristẹni onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kò jẹ́ gba ògo èyíkéyìí lọ́dọ̀ ènìyàn.
18. Nítorí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí áńgẹ́lì alágbára kan ní, kí ló sọ fún Jòhánù?
18 Nígbà tí a fún àpọ́sítélì Jòhánù ní “ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi,” ipasẹ̀ áńgẹ́lì kan la gbà fún un. (Ìṣípayá 1:1) Mímọ bí agbára áńgẹ́lì kan ti tó, lè jẹ́ ká lóye ìdí tí jìnnìjìnnì fi bo Jòhánù, ṣe bí áńgẹ́lì kan ló pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] ará Asíríà kú bámúbámú lóru ọjọ́ kan ṣoṣo. (2 Àwọn Ọba 19:35) Jòhánù ròyìn pé: “Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn níwájú ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tí ó ti ń fi nǹkan wọ̀nyí hàn mí. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé: ‘Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ . . . Jọ́sìn Ọlọ́run.’” (Ìṣípayá 22:8, 9) Ẹ wo bí áńgẹ́lì alágbára yìí ṣe lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó!
19, 20. Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀mí ìyangàn tí àwọn ọ̀gágun ará Róòmù, tí wọ́n ti jagun ṣẹ́gun ní àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú tí Jésù ní.
19 Jésù ṣì ni àpẹẹrẹ tó pegedé jù lọ táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú. Òun jẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run, òun ni Ọba lọ́la ti Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run. Nígbà tó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn èèyàn pé òun ni ẹni táà ń wí yìí, kò ṣe é bí àwọn ọ̀gágun, tí wọ́n ti jagun ṣẹ́gun nígbà ayé àwọn ará Róòmù, ti máa ń ṣe. Ṣe ni wọ́n máa ń ṣètò pé kí àwọn ọmọ ogún máa yan-lọ yan-bọ̀ níwájú wọn—ìyẹn ni ayẹyẹ ìtọ́wọ̀ọ́rìn—tí àwọn náà yóò wá fẹ̀ sórí kẹ̀kẹ́ tí wọ́n ti fi góòlù àti eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, tí àwọn ẹṣin funfun mélòó kan, tàbí erin, kìnnìún, tàbí ẹkùn pàápàá yóò máa fa kẹ̀kẹ́ yìí. Bí ìtọ́wọ̀ọ́rìn náà bá ṣe ń lọ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ làwọn akọrin yóò máa kọrin ìṣẹ́gun, tí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí ìkógun kún inú rẹ̀ fọ́fọ́ àti àwọn ọkọ̀ tó kẹ́rù gèlètè yóò máa wọ́ yọyọ láti ṣàkàwé ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ogun. Bí èyí ti ń lọ lọ́wọ́ ni wọn yóò mú kí àwọn ọba, àwọn ọmọ ọba, àtàwọn ọ̀gágun, pẹ̀lú àwọn ìdílé wọn tí wọn kó lẹ́rú, rìn níhòòhò ọmọlúwàbí, kí wọ́n lè fi wọ́n ṣẹ̀sín. Ẹ̀mí ìgbéraga, ẹ̀mí ìyangàn ń pọ̀ lápọ̀jù nínú ayẹyẹ yìí.
20 Ẹ wá fìyẹn wé ọ̀nà tí Jésù gbà fi ara rẹ̀ lélẹ̀. Ó ṣe tán láti fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ táa ti sọ nípa rẹ̀, tó sọ pé: “Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà; onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” Ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gun ẹran táa fi ń kẹ́rù, kò gun kẹ̀kẹ́ tí àwọn ẹran ńláǹlà, táa ń lò nígbà ayẹyẹ ìtọ́wọ̀ọ́rìn ń fà. (Sekaráyà 9:9; Mátíù 21:4, 5) Ayọ̀ ńláǹlà mà ló jẹ́ fáwọn èèyàn onírẹ̀lẹ̀ láti ní Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jèhófà yóò yàn láti ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé nínú ayé tuntun o, ẹni tó ní ojúlówó ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá, tó kún fún ìyọ́nú, tó sì jẹ́ aláàánú!—Aísáyà 9:6, 7; Fílípì 2:5-8.
21. Kí ni ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú kò jẹ́?
21 Òótọ́ náà pé Jésù, Pétérù, Pọ́ọ̀lù, àtàwọn mín-ìn lọ́kùnrin lóbìnrin, tí wọ́n jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́ ní àkókò táa kọ Bíbélì, jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ èrò inú fi hàn pé irọ́ gbáà ni èrò náà pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ìkùdíẹ̀-káàtó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi bí agbára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó hàn, nítorí àwọn wọ̀nyí jẹ́ onígboyà, wọ́n jẹ́ onítara. Pẹ̀lú ọpọlọ tó jí pépé àti ìwà rere tó kọyọyọ, ni wọ́n fi fara da àwọn àdánwò tó lékenkà. (Hébérù, orí kọkànlá) Lónìí pẹ̀lú, bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, wọn yóò ní irú agbára kan náà nítorí pé Ọlọ́run ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tí agbára rẹ̀ pọ̀ jọjọ ti àwọn onírẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn. Nípa báyìí, a rọ̀ wá pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.”—1 Pétérù 5:5, 6; 2 Kọ́ríńtì 4:7.
22. Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
22 Apá mìíràn tó dáa ṣì tún wà nínú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú yìí táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti sọ dàṣà. Ìyẹn ni èyí tí ń fi kún ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nínú ìjọ. Ní gidi, ó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú. Èyí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
Àtúnyẹ̀wò
◻ Ṣàpèjúwe ẹ̀mí tó gbayé yìí kan.
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe ń fojú rere hàn sí àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
◻ Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì nípa àwọn èèyàn kan tí wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Áńgẹ́lì náà sọ fún Jòhánù pé: “Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ”