ORÍ 59
Ta Ni Ọmọ Èèyàn?
MÁTÍÙ 16:13-27 MÁÀKÙ 8:22-38 LÚÙKÙ 9:18-26
JÉSÙ LA OJÚ AFỌ́JÚ KAN
JÉSÙ FÚN PÉTÉRÙ NÍ ÀWỌN KỌ́KỌ́RỌ́ ÌJỌBA Ọ̀RUN
JÉSÙ SỌ TẸ́LẸ̀ PÉ ÒUN MÁA KÚ ÒUN SÌ MÁA JÍǸDE
Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé Bẹtisáídà, àwọn èèyàn mú ọkùnrin afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo ọkùnrin náà sàn.
Jésù di ọwọ́ ọkùnrin náà mú, ó sì mú un jáde sẹ́yìn abúlé náà. Lẹ́yìn tó tutọ́ sí ojú ẹ̀, ó bi í pé: “Ṣé o rí nǹkan kan?” Ọkùnrin náà dá a lóhùn pé: “Mo rí àwọn èèyàn, àmọ́ wọ́n dà bí igi tó ń rìn káàkiri.” (Máàkù 8:23, 24) Jésù wá gbé ọwọ́ lé ojú ọkùnrin náà, ó sì ríran. Torí náà, ó ní kó máa lọ sílé, ó sì kìlọ̀ fún un pé kó má ṣe wọ inú abúlé náà.
Nígbà tó yá, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ sí apá àríwá agbègbè Kesaríà ti Fílípì. Wọ́n rin ọ̀nà tó jìn tó nǹkan bíi máìlì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) kí wọ́n tó dé ìlú náà, òkè ni wọ́n sì gùn dé ibẹ̀. Látorí òkè tó ga gan-an yẹn, wọ́n lè rí Òkè Hámónì tí yìnyín bò tó wà lápá àríwá ìlà oòrùn, torí òkè yẹn ga ju abúlé náà lọ. Ó ṣeé ṣe kí ìrìn yẹn gbà wọ́n tó ọjọ́ mélòó kan.
Bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò lọ, Jésù yà síbì kan kó lè lọ gbàdúrà. Oṣù mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá péré ló kù tí Jésù fi máa kú, ó sì ń ṣàníyàn nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti pa á tì, nǹkan sì ti tojú sú àwọn míì. Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn máa ronú pé kí nìdí tí Jésù ò fi gbà káwọn èèyàn fi òun jọba tàbí tí kò fi fàmì kankan han àwọn èèyàn kí wọ́n lè mọ irú ẹni tó jẹ́.
Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé ibi tó ti ń gbàdúrà, Jésù bi wọ́n pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé Ọmọ èèyàn jẹ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Àwọn kan sọ pé Jòhánù Arinibọmi, àwọn míì ń sọ pé Èlíjà, àwọn míì sì ń sọ pé Jeremáyà tàbí ọ̀kan lára àwọn wòlíì.” Àwọn kan ń ronú pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wòlíì tó jíǹde. Àmọ́ kí Jésù lè mọ ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rò, ó bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ sọ pé mo jẹ́?” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Pétérù dáhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”—Mátíù 16:13-16.
Jésù sọ pé ó yẹ kínú Pétérù máa dùn bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kọ́ mọ òtítọ́ yìí, ó wá sọ fún un pé: “Mò ń sọ fún ọ pé: Ìwọ ni Pétérù, orí àpáta yìí sì ni màá kọ́ ìjọ mi sí, àwọn ibodè Isà Òkú kò sì ní borí rẹ̀.” Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé òun máa kọ́ ìjọ àti pé Isà Òkú pàápàá ò ní lágbára lórí àwọn ọmọ ìjọ òun, tí wọ́n bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́. Jésù wá ṣèlérí fún Pétérù pé: “Màá fún ọ ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run.”—Mátíù 16:18, 19.
Kì í ṣe pé Jésù gbé Pétérù ga ju àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lọ, kò sì sọ pé Pétérù ló máa jẹ́ ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni. Ó ṣe tán Jésù fúnra ẹ̀ ni Òkúta tí wọ́n kọ́ ìjọ lé. (1 Kọ́ríńtì 3:11; Éfésù 2:20) Síbẹ̀, kọ́kọ́rọ́ mẹ́ta ni Jésù máa fún Pétérù. Ó sì máa fi kọ́kọ́rọ́ yìí ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún àwọn àwùjọ kan láti jogún Ìjọba ọ̀run.
Pétérù máa lo kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., ó sì máa jẹ́ káwọn Júù tó ti ronú pìwà dà àtàwọn aláwọ̀ṣe mọ ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Ó tún máa lo kọ́kọ́rọ́ kejì láti ṣí àyè sílẹ̀ fáwọn ará Samáríà tí wọ́n gba Jésù gbọ́ láti jogún Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, lọ́dún 36 S.K., Pétérù máa lo kọ́kọ́rọ́ kẹta láti ṣí àǹfààní sílẹ̀ fáwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ bíi Kọ̀nílíù àtàwọn míì kí wọ́n lè jogún Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣe 2:37, 38; 8:14-17; 10:44-48.
Inú àwọn àpọ́sítélì ò dùn rárá nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé òun máa jìyà, wọ́n sì máa tó pa òun ní Jerúsálẹ́mù. Kò yé wọn pé Jésù ṣì máa jíǹde lọ sí ọ̀run, ni Pétérù bá mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.” Àmọ́ Jésù yíjú pa dà, ó sì sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ lo jẹ́ fún mi, torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.”—Mátíù 16:22, 23.
Jésù wá pe àwọn míì yàtọ̀ sáwọn àpọ́sítélì, ó sì ṣàlàyé fún wọn pé ojú àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa rí màbo. Ó ní: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi. Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere máa gbà á là.”—Máàkù 8:34, 35.
Káwọn ọmọlẹ́yìn tó lè rí ojúure Jésù, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìgboyà. Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran alágbèrè àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ èèyàn náà máa tijú rẹ̀ nígbà tó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.” (Máàkù 8:38) Torí náà, tí Jésù bá dé, “ó máa wá san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.”—Mátíù 16:27.