“Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run Rẹ”
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.”—MÁT. 22:37.
1. Kí ló mú kí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn?
JÉSÙ Kristi tí í ṣe Ọmọ Jèhófà, sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòh. 14:31) Jésù tún sọ pé: “Baba ní ìfẹ́ni fún Ọmọ.” (Jòh. 5:20) Kò yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu. Ó ṣe tán, àìmọye ọdún ni Jésù ti jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run kó tó di pé ó wá sáyé. (Òwe 8:30) Bí Jèhófà àti Jésù ṣe jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ náà túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀ tó sì túbọ̀ ń rí ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ kí òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kódà, àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín wọn mú kí wọ́n túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
2. (a) Kí ni ọ̀kan lára ohun tí ìfẹ́ wé mọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?
2 Lára ohun tí ìfẹ́ wé mọ́ ni pé kéèyàn ní ìfẹ́ni tó jinlẹ̀ fún ẹnì kan. Nínú orín tí onísáàmù náà, Dáfídì kọ, ó sọ pé: “Èmi yóò ní ìfẹ́ni fún ọ, ìwọ Jèhófà okun mi.” (Sm. 18:1) Èrò tó yẹ kí àwa náà ní nípa Ọlọ́run nìyẹn, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ó máa nífẹ̀ẹ́ wa. (Ka Diutarónómì 7:12, 13.) Àmọ́, níwọ̀n bí a kò ti lè rí Ọlọ́run, ǹjẹ́ a lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ti gidi? Kí ló túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
3, 4. Kí nìdí tá a fi lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
3 Bíbélì sọ pé, “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” ìdí nìyẹn tí a kò fi lè rí i. (Jòh. 4:24) Síbẹ̀, a lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kódà, Ìwé Mímọ́ pa á láṣẹ pé ká fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Bí àpẹẹrẹ, Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”—Diu. 6:5.
4 Kí nìdí tá a fi lè ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run? Ìdí ni pé ó da wa lọ́nà tí ohun tẹ̀mí á fi lè máa jẹ wá lọ́kàn, ó sì tún mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fìfẹ́ hàn. Tá a bá ń jẹ àjẹyó nípa tẹ̀mí, a máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn á sì mú ká láyọ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mát. 5:3) Nígbà tí ìwé kan ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń wu àwa èèyàn látọkàn wá láti sin Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ó yẹ kí ẹ̀rù bà wá, kí ẹnú yà wá, ká sì ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, nígbà tá a bá rí bí gbogbo èèyàn kárí ayé ṣe ń wá ẹnì kan tó ga ju ẹ̀dá èèyàn lọ tí wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.”—Ìwé Man Does Not Stand Alone, látọwọ́ A. C. Morrison.
5. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe àìríkan-ṣèkan ló jẹ́ láti máa wá Ọlọ́run?
5 Ṣé àìríkan-ṣèkan ló jẹ́ láti máa wá Ọlọ́run? Rárá o, ìdí ni pé Ọlọ́run fẹ́ ká wá òun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kí ìyẹn ṣe kedere nígbà tó wàásù fún àgbájọ àwọn èèyàn kan ní Áréópágù. Ìwàásù náà wáyé níbi tí kò jìnnà sí Páténónì, ìyẹn tẹ́ńpìlì kan tí wọ́n kọ́ fún Áténà tó jẹ́ yèyé òrìṣà tí wọ́n ń bọ ní ìlú Áténì ìgbàanì. Jẹ́ ká sọ pé o wà níbẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀,” lẹ́yìn náà tó wá ṣàlàyé pé Ọlọ́run yìí “kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́.” Àpọ́sítélì náà wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá, ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn, fún wọn láti máa wá Ọlọ́run, bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:24-27) Kò sírọ́ níbẹ̀, àwọn èèyàn lè wá Ọlọ́run rí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju mílíọ̀nù méje ààbọ̀ lọ ti wá ‘rí i ní ti tòótọ́,’ a sì fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
6. Èwo ni Jésù sọ pé ó jẹ́ “àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní”?
6 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn wá. Jésù mú kí ìyẹn ṣe kedere nígbà tí Farisí kan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olùkọ́, èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” Jésù dá a lóhùn pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.”—Mát. 22:34-38.
7. Kí ló túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú (a) “gbogbo ọkàn-àyà” wa? (b) “gbogbo ọkàn” wa? (d) “gbogbo èrò inú” wa?
7 Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú “gbogbo ọkàn-àyà” wa? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa, tó fi mọ́ ohun tá à ń fẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí lọ́kàn wa àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wa. A tún gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú “gbogbo ọkàn” wa, ìyẹn ìgbésí ayé tàbí ìwàláàyè wa lódindi. Síwájú sí i, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú “gbogbo èrò inú” tàbí làákàyè wa. Gbogbo èyí túmọ̀ sí pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, láìkù síbì kan.
8. Kí la máa fẹ́ láti ṣe tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá?
8 Tá a bá fi gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa àti èrò inú wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a ó máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ taápọntaápọn, a ó máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, a ó sì máa fìtara polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14; Róòmù 12:1, 2) Torí pé a ní ojúlówó ìfẹ́ fún Jèhófà a máa túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Ják. 4:8) Ohun kan ni pé, kò ṣeé ṣe láti ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára wọn.
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ
9. Kí nìdí tó fi dùn mọ́ ẹ pé Jèhófà ni Olùpèsè àti Ẹlẹ́dàá wa?
9 Jèhófà ni Olùpèsè àti Ẹlẹ́dàá wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Jèhófà fún wa ní ilẹ̀ ayé tó dára rèǹtèrente pé ká máa gbénú rẹ̀. (Sm. 115:16) Ó tún ń pèsè oúnjẹ àti àwọn nǹkan míì tá a nílò fún wa ká lè máa wà láàyè. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi lè sọ fún àwọn abọ̀rìṣà tó ń gbé ní ìlú Lísírà pé, “Ọlọ́run alààyè . . . kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:15-17) Ǹjẹ́ èyí ò tó fún wa láti nífẹ̀ẹ́ Olùpèsè àti Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá?—Oníw. 12:1.
10. Báwo ni ohun tí Ọlọ́run ṣe láti mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣe yẹ kó rí lára wa?
10 Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, èyí tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Kódà, “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Láìsí àní-àní, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀ torí pé ó ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà tá a bá ronú pìwà dà tá a sì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù.—Jòh. 3:16.
11, 12. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú ká ní ìrètí?
11 Jèhófà ń fún wa ní ìrètí tó ń mú kí inú wa dùn ká sì ní àlàáfíà ọkàn. (Róòmù 15:13) Ìrètí tí Ọlọ́run ń fúnni máa ń mú ká lè fara da àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́. Àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n bá ‘jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, máa gba adé ìyè, ní ọ̀run.’ (Ìṣí. 2:10) Àwọn tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì ń pa ìwà títọ́ mọ́ máa gbádùn ìbùkún ayérayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Lúùkù 23:43) Báwo ni irú ìlérí yìí ṣe máa ń rí lára wa? Ó dájú pé ó ń mú inú wa dùn, ó ń mú ká ní àlàáfíà ọkàn, ó sì ń mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—Ják. 1:17.
12 Ọlọ́run ṣèlérí àjíǹde, èyí tó ń múnú wa dùn. (Ìṣe 24:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń bà wá nínú jẹ́ tí èèyàn wa kan bá kú, àmọ́ torí pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé àjíǹde máa wà, a kì í “kárísọ gẹ́gẹ́ bí àwọn . . . tí kò ní ìrètí ti ń ṣe.” (1 Tẹs. 4:13) Nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní, ó wù ú pé kó jí àwọn òkú dìde, pàápàá jù lọ àwọn adúróṣinṣin bíi Jóòbù. (Jóòbù 14:15) Wo bí ìdùnnú ṣe máa ṣubú layọ̀ nígbà tá a bá ń kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀ sórí ilẹ̀ ayé níbí. A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run o nítorí ìlérí àgbàyanu tó ṣe pé àwọn òkú máa jíǹde!
13. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa ní tòótọ́?
13 Jèhófà bìkítà nípa wa ní tòótọ́. (Ka Sáàmù 34:6, 18, 19; 1 Pétérù 5:6, 7.) Nítorí pé a mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ṣe tán láti ran àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i lọ́wọ́, ọkàn wa máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ pé a wà lára “agbo ẹran pápá ìjẹko” rẹ̀. (Sm. 79:13) Síwájú sí i, ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà tún máa jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Lẹ́yìn tí Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run yàn, bá ti mú ìwà ipá, ìnilára àti ìwà ibi kúrò láyé, àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn á máa gbádùn àlàáfíà àti aásìkí títí ayé. (Sm. 72:7, 12-14, 16) Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tá a máa gbádùn yìí, ǹjẹ́ kò yẹ ká fi gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa, okun wa àti èrò inú wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa aláàánú?—Lúùkù 10:27.
14. Àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ wo ni Ọlọ́run ti fi jíǹkí wa?
14 Jèhófà fi àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ jíǹkí wa ní ti pé ó mú ká jẹ́ Ẹlẹ́rìí òun. (Aísá. 43:10-12) A nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí àǹfààní tó fún wa pé ká máa kọ́wọ́ ti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ká sì mú káwọn èèyàn ní ojúlówó ìrètí nínú ayé onílàásìgbò yìí. Síwájú sí i, a mọ̀ pé àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kì í kùnà, torí náà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú la fi ń polongo ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Jóṣúà 21:45; 23:14.) Tá a bá ní ká máa ka àwọn ìbùkún tá a máa rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà àti ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ilẹ̀ á kún. Àmọ́, báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
BÍ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
15. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń fi ẹ̀kọ́ náà sílò, báwo ló ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
15 Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run taápọntaápọn kó o sì máa fi ẹ̀kọ́ náà sílò. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé òótọ́ la fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ‘ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa.’ (Sm. 119:105) Tá a bá ní ìdààmú ọkàn, a lè rí ìtùnú gbà látinú àwọn ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, tí Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” “Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni ó ń gbé mi ró. Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sm. 51:17; 94:18, 19) Jèhófà máa ń fi àánú hàn sí àwọn tí ìyà ń jẹ, bákan náà sì ni Jésù máa ń káàánú àwọn èèyàn. (Aísá. 49:13; Mát. 15:32) Ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ lè mú kó túbọ̀ ṣe kedere sí wa pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lógún gan-an, èyí sì mú kí àwa náà fẹ́ láti fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí i.
16. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe lè jinlẹ̀ sí i tá a bá ń gbàdúrà déédéé?
16 Máa gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé. Àdúrà tá à ń gbà ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run á túbọ̀ máa jinlẹ̀ bá a ṣe ń kíyè sí i pé ó ń dáhùn àdúrà wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè ti kíyè sí i pé Ọlọ́run kì í jẹ́ ká dán wa wò kọjá ohun tá a lè fara dà. (1 Kọ́r. 10:13) Torí náà, tá a bá ń ṣàníyàn nítorí ohun kan, tá a sì fi tọkàntọkàn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà, a lè wá ní “àlàáfíà Ọlọ́run” èyí tí kò láfiwé. (Fílí. 4:6, 7) Nígbà míì, a lè gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ bíi ti Nehemáyà, ká sì wá rí i pé Ọlọ́run dáhùn àdúrà náà. (Neh. 2:1-6) Bá a ṣe ń “ní ìforítì nínú àdúrà” tá a sì mọ̀ pé Jèhófà ń fún wa ní ohun tá à ń tọrọ, bẹ́ẹ̀ ni a óò túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, á sì túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìdánwò ìgbàgbọ́ tó bá tún dojú kọ wá.—Róòmù 12:12.
17. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ojú wo la ó máa fi wo lílọ sí ìpàdé?
17 Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti àwọn àpéjọ. (Héb. 10:24, 25) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kóra jọ pọ̀ kí wọ́n lè tẹ́tí sílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà kí wọ́n lè ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un kí wọ́n sì máa pa Òfin rẹ̀ mọ́. (Diu. 31:12) Tó bá jẹ́ pé òótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kò ní nira fún wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 5:3.) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká fàyè gba ohunkóhun táá mú ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú lílọ sí ìpàdé. Ó dájú pé a kò ní fẹ́ kí ohunkóhun mú ká pàdánù ìfẹ́ tá a kọ́kọ́ ní fún Jèhófà.—Ìṣí. 2:4.
18. Bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere, kí ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ń mú ká ṣe?
18 Máa fìtara wàásù “òtítọ́ ìhìn rere” fáwọn èèyàn. (Gál. 2:5) Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Mèsáyà tó jẹ́ ti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, ẹni tó máa ‘gẹṣin nítorí òtítọ́’ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Sm. 45:4; Ìṣí. 16:14, 16) Ẹ ò rí i pé ohun ayọ̀ ńlá gbáà ló jẹ́ pé à ń kópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa àti nípa ayé tuntun tó ṣèlérí!—Mát. 28:19, 20.
19. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún bíbójútó agbo rẹ̀?
19 Fi hàn pé o mọyì ètò tí Ọlọ́run ṣe fún bíbójútó agbo rẹ̀. (Ìṣe 20:28) Jèhófà ló fún wa ní àwọn alàgbà, ire wa ni wọ́n sì máa ń wá nígbà gbogbo. Àwọn alàgbà “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísá. 32:1, 2) Ẹ sì wo bá a ṣe máa ń mọrírì rẹ̀ tá a bá rí ibi fara pa mọ́ sí nígbà tí ẹ̀fúùfù líle ń fẹ́ tàbí nígbà àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò! Bí oòrùn mímú ganrínganrín bá ń pa wá, inú wa máa dùn tá a bá rí ibi ìbòòji sá sí lábẹ́ àpáta gàǹgà kan. Àwọn àkànlò èdè yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn alàgbà máa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtura tẹ̀mí tá a nílò fún wa. Bá a ṣe ń ṣègbọràn sí àwọn tó ń múpò iwájú láàárín wa, à ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a mọyì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” yìí àti pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Kristi, tó jẹ́ Orí ìjọ.—Éfé. 4:8; 5:23; Héb. 13:17.
JẸ́ KÍ ÌFẸ́ TÓ O NÍ FÚN ỌLỌ́RUN MÁA JINLẸ̀ SÍ I
20. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí lo máa ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Jákọ́bù 1:22-25?
20 Tó o bá ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, ‘olùṣe ọ̀rọ̀ náà lo máa jẹ́, kì í ṣe olùgbọ́ nìkan.’ (Ka Jákọ́bù 1:22-25.) Ẹni tó jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” á ní ìgbàgbọ́ tó lè mú kó máa ṣe àwọn iṣẹ́ bíi fífi ìtara wàásù àti kíkópa nínú àwọn ìpàdé ìjọ. Torí pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́, wàá máa pa ‘òfin pípé’ Jèhófà mọ́. Inú òfin yìí ni gbogbo nǹkan tí Jèhófà fẹ́ kó o máa ṣe wà.—Sm. 19:7-11.
21. Kí la lè fi àdúrà àtọkànwá tó ò ń gbà wé?
21 Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà Ọlọ́run á mú kó o máa gba àdúrà àtọkànwá sí i lemọ́lemọ́. Nínú orin kan tí Dáfídì ti sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ń sun tùràrí lójoojúmọ́ ní ìbámu pẹ̀lú májẹ̀mú Òfin, ó sọ pé: “Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ [Jèhófà], àti gbígbé tí mo gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè bí ọrẹ ẹbọ ọkà ìrọ̀lẹ́.” (Sm. 141:2; Ẹ́kís. 30:7, 8) Ǹjẹ́ kí àwọn ohun tó ò ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́run, àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tó ò ń fi tọkàntọkàn ṣe àti àwọn ọ̀rọ̀ tó o fi ń yin Jèhófà tó o sì fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ látọkàn wá dà bí tùràrí olóòórùn dídùn èyí tó dúró fún àdúrà tó ṣètẹ́wọ́gbà.—Ìṣí. 5:8.
22. Irú ìfẹ́ wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
22 Jésù sọ pé ká fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-39) Bí a ó ṣe máa bá ìjíròrò nípa ìfẹ́ nìṣó nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti àwọn ìlànà rẹ̀ á mú ká lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa.