Ìgbà Tí Ìfẹ́ Ọlọ́run Yóò Ṣẹ Délẹ̀délẹ̀ Lórí Ilẹ̀ Ayé
NÍGBÀ tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé, “Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú,” èyí jẹ́ ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ ti rí nítorí pé ó ti fìgbà kan rí gbé ní ọ̀run lọ́dọ̀ Baba. (Mátíù 6:10; Jòhánù 1:18; 3:13; 8:42) Kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ó mọ ìgbà tí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Àwọn àkókò yẹn jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó ní àṣeyọrí àti ìtẹ́lọ́rùn.—Òwe 8:27-31.
Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ìyẹn àwọn ‘áńgẹ́lì rẹ̀, tí wọ́n tóbi jọjọ nínú agbára, tí wọ́n ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.’ Wọ́n jẹ́ “òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 103:20, 21) Ǹjẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn áńgẹ́lì náà ní ìfẹ́ tara wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ní in, àti pé nígbà tá a dá ilẹ̀ ayé, “àwọn ọmọ Ọlọ́run . . . bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:7) Yíyìn tí wọ́n ń yin Ọlọ́run fi hàn pé inú wọn dùn sí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì mú ìfẹ́ tiwọn bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.
Nígbà tí Ọlọ́run ti dá ilẹ̀ ayé tán, ó ṣètò rẹ̀ kó lè ṣeé gbé fún èèyàn, lẹ́yìn náà ló wá dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 1) Ṣé ìyẹn náà yẹ fún ìyìn? Nínú àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí, a kà á pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni,” bẹ́ẹ̀ ni o, kò ní àbààwọ́n kankan, ó jẹ́ pípé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:31.
Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ àti àtọmọdọ́mọ wọn? Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 1:28 ṣe sọ, ohun tó dára gan-an ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún wọn, ibẹ̀ sọ pé: “Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.’” Kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu yìí yanjú, wọ́n ní láti máa wà láàyè nìṣó, àní títí láé, bẹ́ẹ̀ sì ni àtọmọdọ́mọ wọn pẹ̀lú. Kò sí ohunkóhun tó fi hàn pé jàǹbá, àìsí-ìdájọ́-òdodo, ìrora ọkàn tàbí ikú yóò wáyé.
Ìgbà kan nìyẹn tí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ní ayọ̀ púpọ̀ fún ṣíṣe tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀. Kí lohun tó wá da ọ̀ràn náà rú?
Ẹnì kan ṣàdédé ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́, àtakò náà kò ní ṣàìyanjú o. Síbẹ̀, àtakò náà mú kí aráyé ní ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ fún àkókò gígún, ó sì ti wá mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run fún aráyé túbọ̀ dojú rú. Inú ipò burúkú náà ni gbogbo wa wà báyìí. Kí tiẹ̀ ni àtakò náà?
Ìfẹ́ Ọlọ́run Nígbà Ìṣọ̀tẹ̀ Kan
Ọ̀kan lára “àwọn ọmọ Ọlọ́run” tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí kò fẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run fún aráyé ṣẹ, ète rẹ̀ sì ni láti wá ire ara rẹ̀. Bí ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ṣe ń ronú nípa ohun tó fẹ́ ṣe yìí, bẹ́ẹ̀ ni èrò náà túbọ̀ ń jọ ohun tó máa bọ́ si, ó sì túbọ̀ ń fà á mọ́ra. (Jákọ́bù 1:14, 15) Ó ti lè máa rò ó pé tóun bá lè mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí gbọ́rọ̀ sóun lẹ́nu dípò Ọlọ́run, nígbà náà kò ní sóhun tí Ọlọ́run máa lè ṣe ju pé kó gba ọba aláṣẹ mìíràn láyè. Ó ti lè máa rò ó pé Ọlọ́run ò ní pa wọ́n, nítorí pé èyí á mú kí ète Ọlọ́run já sí pàbó. Dípò ìyẹn, kí Jèhófà Ọlọ́run ṣe àtúnṣe sí ète rẹ̀, kí ó gba ẹ̀dá ẹ̀mí yìí láyè láti máa ṣàkóso, káwọn èèyàn sì máa ṣègbọràn sí ẹ̀dá ẹ̀mí náà. Sátánì lorúkọ tá a wá ń pé ọlọ̀tẹ̀ yìí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tó túmọ̀ sí “alátakò,” orúkọ náà sì bá a mu.—Jóòbù 1:6.
Kí Sátánì lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ó tọ obìnrin náà lọ. Ó rọ obìnrin náà pé kó pa ìfẹ́ Ọlọ́run tì, kó sì lómìnira láti ṣe ohun tó bá wù ú, ó sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. . . . Ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Lójú obìnrin náà, ohun tí Sátánì sọ yẹn jọ nǹkan tó máa mú kó lómìnira, torí náà ó gbà pé ìgbésí ayé òun yóò dára tóun bá gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. Lẹ́yìn náà, ó pàrọwà fún ọkọ rẹ̀ láti dára pọ̀ mọ́ òun.—Jẹ́nẹ́sísì 3:6.
Ìfẹ́ Ọlọ́run fún tọkọtaya yìí kọ́ nìyẹn. Ìfẹ́ inú wọn ni wọ́n ṣe yẹn. Èyí yóò sì mú kí wọ́n kàgbákò. Ọlọ́run ti sọ fún wọn ṣáájú pé tí wọ́n bá tọ ipa ọ̀nà yẹn ikú ló máa yọrí sí fún wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:3) Ọlọ́run ò dá wọn láti ṣàṣeyọrí sí rere láìsí ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ rẹ̀. (Jeremáyà 10:23) Láfikún sí i, wọn yóò di aláìpé, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn yóò sì jogún àìpé àti ikú. (Róòmù 5:12) Sátánì kò lè yí àtúbọ̀tán yìí padà.
Ṣé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wá yí ète Ọlọ́run tàbí ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀ ayé padà kó má ṣẹ láé ni? Rárá o. (Aísáyà 55:9-11) Àmọ́, ìyẹn mú ká máa béèrè àwọn ìbéèrè kan tó yẹ ká mọ ìdáhùn rẹ̀: Ṣé èèyàn lè “dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú,” gẹ́gẹ́ bí Sátánì ṣe sọ? Lédè mìíràn, ká sọ pé wọ́n fún àwa èèyàn ní àkókò tí ó tó, ǹjẹ́ a lè dá nìkan mọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, èyí tó ṣàǹfààní àtèyí tó lè pani lára nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe? Ǹjẹ́ Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tá a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí délẹ̀délẹ̀, torí pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dára jù lọ? Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tó bá ní ká ṣe? Báwo ni wàá ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn?
Ọ̀nà kan ṣoṣo ló wà tá a lè gbà yanjú ọ̀rọ̀ yìí níṣojú gbogbo ẹ̀dà onílàákàyè, ọ̀nà náà ni pé: Kí á fún àwọn tí kò fẹ́ sí lábẹ́ Ọlọ́run láyè láti gbìyànjú rẹ̀ wò bóyá wọ́n á lè ṣàṣeyọrí. Bá a bá kàn pa wọ́n, ìyẹn ò ní yanjú ọ̀ràn náà. Fífún aráyé lómìnira fún àkókò tó pọ̀ tó láti wà láyè ara wọn láìsí ọwọ́ Ọlọ́run ni yóò yanjú ọ̀ràn náà, nítorí pé nígbà yẹn yóò hàn kedere pé èèyàn kò lè dá wà láìsí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ọ̀ràn wọn. Ọlọ́run fi hàn pé ọ̀nà tóun yóò gbà yanjú ọ̀ràn ọ̀hún nìyẹn nígbà tó sọ fún obìnrin náà pé yóò bí àwọn ọmọ. Ìdílé ìran ènìyàn yóò tipa báyìí bẹ̀rẹ̀. A mà dúpẹ́ o, ìyẹn ló mú ká wà láàyè lọ́jọ́ òní!—Jẹ́nẹ́sísì 3:16, 20.
Àmọ́ ṣá o, èyí kò wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run yóò gba àwọn èèyàn àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ọlọ̀tẹ̀ yìí láyè láti máa ṣe gbogbo ohun tó bá sáà ti wù wọ́n. Ọlọ́run kò sọ pé òun kì í ṣe ọba aláṣẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò pa ète rẹ̀ tì. (Sáàmù 83:18) Ó mú kí èyí ṣe kedere nípa sísọ tẹ́lẹ̀ pé, nígbà tó bá yá ọlọ̀tẹ̀ náà yóò di ẹni ìparun àti pé gbogbo ohun búburú tí ọ̀tẹ̀ náà fà yóò kásẹ̀ nílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Nítorí náà, látìbẹ̀rẹ̀ ni ìlérí ti wà fún aráyé pé wọn yóò rí ìtura.
Ní báyìí ná, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti mú ara wọn àti àtọmọdọ́mọ wọn kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Tí Ọlọ́run bá wá ń yọ wọn nínú gbogbo ìṣòro tí ìpinnu wọn kó wọn sí, á jẹ́ pé ńṣe ló ń mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí wọn tipátipá nìyẹn. Bí ìgbà tí Ọlọ́run ò fún wọn lómìnira láti wà láyè ara wọn láìsí ọwọ́ rẹ̀ lára wọn lọ̀rọ̀ náà yóò wá rí.
Lóòótọ́, olúkúlùkù lè yàn láti wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Wọ́n lè mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún èèyàn ní àkókò yìí kí wọ́n sì mú ara wọn bá ìfẹ́ rẹ̀ mú bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó. (Sáàmù 143:10) Àmọ́, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀ràn nípa òmìnira aráyé kò bá tíì yanjú, wọn ò tíì lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro.
Kò pẹ́ rárá tí àbájáde ìpinnu téèyàn ń dá ṣe fi bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Kéènì tí í ṣe àkọ́bí ìdílé ìràn ènìyàn pa Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀ nítorí pé “àwọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣùgbọ́n àwọn ti arákùnrin rẹ̀ jẹ́ òdodo.” (1 Jòhánù 3:12) Èyí kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún Kéènì tẹ́lẹ̀, ó sì fìyà jẹ ẹ́ níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-12) Kéènì yan ọ̀nà ìgbésí ayé olómìnira tí Sátánì fún un, nípa bẹ́ẹ̀ o “pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.” Àwọn mìíràn ṣe bíi tirẹ̀.
Lẹ́yìn téèyàn ti gbé lórí ilẹ̀ ayé fún ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún [1,500], “ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Ó gba pé kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ ní kánmọ́ kí ilẹ̀ ayé má bàa bá jẹ́ tán. Ọlọ́run sì ṣe nǹkan kan nípa mímú kí omi bo ayé, ó sì dáàbò bo ìdílé kan ṣoṣo tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà náà, ìyẹn Nóà àti aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 7:1) Gbogbo wa pátá jẹ́ àtọmọdọ́mọ wọn.
Látìgbà náà wá títí di ìsinsìnyí ni Ọlọ́run ti ń fún àwọn tó ti ọkàn wọn wá láti mọ ìfẹ́ rẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà. Ó mí sí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń fẹ́ ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ rẹ̀. Inú Bíbélì ni wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà sí. (2 Tímótì 3:16) Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi jẹ́ káwọn olóòótọ́ èèyàn ní àjọṣe pẹ̀lú òun, àní wọ́n lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀ pàápàá. (Aísáyà 41:8) Ó sì tún fún wọn lókun tí wọ́n nílò láti lè fara da ìṣòro lílekoko tí aráyé wà nínú rẹ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n fi wà lómìnira yìí. (Sáàmù 46:1; Fílípì 4:13) A mà dúpẹ́ o fún gbogbo ìtìlẹ́yìn yìí!
‘Kí Ìfẹ́ Rẹ Ṣẹ’ Délẹ̀délẹ̀
Kì í ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe títí di àkókò yìí ni gbogbo ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé. Kristẹni àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ọ̀rọ̀ ìṣàpẹẹrẹ yìí ń tọ́ka sí ìjọba tuntun tí yóò ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé àti àwùjọ èèyàn tuntun tí yóò wà lábẹ́ ìjọba náà.
Wòlìí Dáníélì lo ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere láti kọ ọ́ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ ohun tó máa gbẹ̀yìn ètò àwọn nǹkan tí kò wúlò tó wà lónìí, ó sọ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò rọ́pò rẹ̀. Ìròyìn ayọ̀ gbáà lèyí mà jẹ́ o! Ìforígbárí àti ìmọtara-ẹni-nìkan tó mú kí ìwà ipá kúnnú ayé lónìí tó sì tún fẹ́ mú kí ayé yìí bà jẹ́ yóò pòórá lọ́jọ́ kan.
Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bi í pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Lára ìdáhùn tí Jésù fún wọn ni pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:3, 14.
Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé jákèjádò ayé la ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ́ náà ti rí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ yìí ládùúgbò rẹ. Nínú ìwé náà These Also Believe tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles S. Braden kọ, ó sọ pé: “Ní ti gidi, iṣẹ́ ìjẹ́rìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kárí ilẹ̀ ayé. . . . Kò tíì sí ẹ̀sìn èyíkéyìí láyé tó tíì tẹra mọ́ iṣẹ́ sísọ ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn èèyàn bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi ìtara wàásù ìhìn rere náà ní èyí tó lé ní ọgbọ̀nlérúgba [230] orílẹ̀-èdè ní èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó irínwó [400] èdè. A ò tíì ṣe iṣẹ́ tá a sọ tẹ́lẹ̀ yìí tó báyìí rí ní gbogbo ayé. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé àkókò náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tí Ìjọba Ọlọ́run yóò rọ́pò ìjọba èèyàn.
Ìjọba tí Jésù sọ fún wa pé ká máa wàásù rẹ̀ náà ni ó kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún nínú àdúrà àwòṣe tó gbà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìjọba náà ni ohun tí Ọlọ́run yóò lò láti mú ète rẹ̀, ìyẹn ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀ ayé ṣẹ.
Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Jẹ́ kí Ìṣípayá 21:3, 4 dáhùn, o sọ pé: “Mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’” Nígbà yẹn, ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ṣẹ délẹ̀délẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti lókè ọ̀run.a Ǹjẹ́ o ò ní fẹ́ láti wà níbẹ̀?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ púpọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run, jọ̀wọ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí ọ̀kan lára àdírẹ́sì tá a tò sí ojú ìwé 2 ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti kó wa sínú ìyọnu ńlá