À Ń Gbèjà Ìhìn Rere Níwájú Àwọn Aláṣẹ
NÍGBÀ tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Júù tá a wá pa dà mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba.”—Ìṣe 9:15.
Ọ̀kan lára àwọn “ọba” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ níwájú rẹ̀ ni Nérò Olú Ọba Róòmù. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó bá jẹ́ pé ìwọ lo fẹ́ gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ níwájú irú aláṣẹ tí ipò rẹ̀ ga tó bẹ́ẹ̀? Bó ti wù kó rí, Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́r. 11:1) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ronú lórí bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ níwájú àwọn aláṣẹ nígbà ayé rẹ̀.
Òfin Mósè ni wọ́n ń tẹ̀ lé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, òun náà sì làwọn Júù níbi gbogbo ń tẹ̀ lé. Àmọ́ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́. (Ìṣe 15:28, 29; Gál. 4:9-11) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni tó kù ò bẹnu àtẹ́ lu Òfin Mósè, torí náà wọ́n láǹfààní láti wàásù láwọn àgbègbè táwọn Júù ń gbé láìsí èdèkòyédè kankan. (1 Kọ́r. 9:20) Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń lọ sínú àwọn sínágọ́gù kó lè wàásù fáwọn tó gba Ọlọ́run Ábúráhámù gbọ́. Ó tún máa ń wàásù fáwọn tó gba Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù gbọ́.—Ìṣe 9:19, 20; 13:5, 14-16; 14:1; 17:1, 2.
Ìlú Jerúsálẹ́mù làwọn àpọ́sítélì ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní pẹrẹu. Gbogbo ìgbà ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì. (Ìṣe 1:4; 2:46; 5:20) Nígbà kan, Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú un níbẹ̀. Ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́jọ́ rẹ̀ títí wọ́n fi gbẹ́jọ́ náà lọ sí Róòmù.
PỌ́Ọ̀LÙ GBÈJÀ ARA RẸ̀ LÁBẸ́ ÒFIN RÓÒMÙ
Ojú wo lẹ rò pé àwọn aláṣẹ ìlú Róòmù á fi wo ohun tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ojú tí ìjọba Róòmù fi ń wo ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Wọn kì í fipá mú àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba wọn pé kí wọ́n fi ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ àyàfi tí wọ́n bá rí i pé ó fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìlú.
Ìjọba Róòmù fàyè gba àwọn Júù gan-an. Ìwé kan tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni sọ pé: ‘Ìjọba ìlú Róòmù ò fi dandan mú àwọn Júù pé kí wọ́n máa jọ́sìn àwọn òrìṣà ìlú Róòmù. Wọ́n láǹfààní láti ṣe àwọn ìyípadà kan lágbègbè ibi tí wọ́n ń gbé.’ Bákan náà, wọn ò fipá mú wọn láti wọṣẹ́ ológun.a Òmìnira tí ìjọba Róòmù fáwọn ẹlẹ́sìn Júù ni Pọ́ọ̀lù fi gbèjà ara rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìlú náà.
Kò sí ohun táwọn alátakò Pọ́ọ̀lù ò ṣe tán káwọn èèyàn àtàwọn aláṣẹ lè kórìíra rẹ̀. (Ìṣe 13:50; 14:2, 19; 18:12, 13) Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan. Àwọn alàgbà tó wà ní ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ àhesọ láàárín àwọn Júù pé Pọ́ọ̀lù ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó yàtọ̀ sí Òfin Mósè. Ohun tí wọ́n ń sọ kiri yìí lè mú káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Pọ́ọ̀lù ò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ìyẹn lè mú káwọn Sànhẹ́dírìn bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni pé wọ́n ti ya pa kúrò nínú ìsìn àwọn Júù. Tí ìyẹn bá sì ṣẹlẹ̀, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni. Wọ́n á ní káwọn èèyàn má ṣe bá wọn da nǹkan pọ̀ mọ́, wọn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n wọ tẹ́ńpìlì tàbí sínágọ́gù láti wàásù mọ́. Torí náà, àwọn alàgbà ìjọ sọ pé kí Pọ́ọ̀lù lọ sí tẹ́ńpìlì, kó sì ṣe ohun tó máa fi hàn pé irọ́ ni àhesọ náà. Ohun tí wọ́n ní kó ṣe yìí ò pọn dandan fún Kristẹni, àmọ́ nǹkan ọ̀hún ò ta ko Ìwé Mímọ́.—Ìṣe 21:18-27.
Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn sì fún un láǹfààní láti gbèjà ìhìn rere, kí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin. (Fílí. 1:7) Kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í fa wàhálà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n ní àfi káwọn pa Pọ́ọ̀lù. Torí náà, ọ̀gágun Róòmù kan wá mú Pọ́ọ̀lù, ó sì mú un lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun. Nígbà tí wọ́n fẹ́ na Pọ́ọ̀lù lẹ́gba níbẹ̀, ó sọ fún wọn pé ọmọ ìlú Róòmù ni òun. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi mú un lọ sí ìlú Kesaréà, torí àtibẹ̀ ni ìjọba ìlú Róòmù ti ń ṣàkóso ilẹ̀ Jùdíà. Pọ́ọ̀lù máa láǹfààní láti wàásù níwájú àwọn aláṣẹ tó bá débẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe kíyẹn mú káwọn tí ò tíì gbọ́ nípa ẹ̀sìn Kristẹni tẹ́lẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀.
Ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì orí 24 sọ nípa bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbèjà ara rẹ̀ níwájú Fẹ́líìsì tó jẹ́ gómìnà ará Róòmù tó ń ṣàkóso ilẹ̀ Jùdíà. Fẹ́líìsì ti gbọ́ nípa ohun táwọn Kristẹni gbà gbọ́. Àmọ́ ní báyìí, àwọn Júù fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù pé ó ti rú mẹ́ta lára àwọn òfin Róòmù. Àkọ́kọ́, wọ́n ní Pọ́ọ̀lù àtàwọn Júù kan ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Ìkejì, wọ́n ní Pọ́ọ̀lù dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀, ẹgbẹ́ ọ̀hún sì lè da ìlú rú. Ìkẹta, wọ́n tún ní Pọ́ọ̀lù fẹ́ sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, abẹ́ ìjọba Róòmù ni tẹ́ńpìlì ọ̀hún wà. (Ìṣe 24:5, 6) Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù yẹn lágbára gan-an, ó sì lè yọrí sí ikú.
Àwa Kristẹni òde òní máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbèjà ara rẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án. Kò bẹ̀rù, síbẹ̀ ó bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń bá a ṣẹjọ́. Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì sọ, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti sin ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá òun.’ Ó ṣe tán, gbogbo àwọn Júù ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sin Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn lábẹ́ òfin Róòmù. (Ìṣe 24:14) Lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù wá sọ ohun tó gbà gbọ́ níwájú gómìnà Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti níwájú Hẹ́rọ́dù Àgírípà Ọba.
Lẹ́yìn gbogbo atótónu, Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n gba tòun rò, ló bá ní: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” Nígbà yẹn, Késárì ni aláṣẹ tó ga jù lọ.—Ìṣe 25:11.
PỌ́Ọ̀LÙ GBÈJÀ ARA RẸ̀ LỌ́DỌ̀ KÉSÁRÌ
Áńgẹ́lì kan sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ dúró níwájú Késárì.” (Ìṣe 27:24) Nérò ni Késárì tó wà lórí oyè nígbà yẹn. Nígbà tó dórí oyè, ó sọ pé kì í ṣe gbogbo ẹjọ lòun á máa dá sí. Láàárín ọdún mẹ́jọ àkọ́kọ́ tó lò lórí oyè, kò dá ẹjọ́ kankan, àwọn míì ló ní kí wọ́n máa bá òun dá a. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìyẹn The Life and Epistles of Saint Paul sọ pé nígbà tí Nérò gbà láti gbọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù, ààfin rẹ̀ ló ti gbọ́ ọ, àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tó mọ òfin gan-an ló sì kó tira.
Bíbélì ò sọ bóyá Nérò fúnra rẹ̀ ló gbọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù, àbí ó ní kí ẹlòmíì bá òun gbọ́ ọ, kónítọ̀hún sì wá jábọ̀ fún òun. Bó ti wù kó rí, ó dájú pé Pọ́ọ̀lù á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run àwọn Júù lòun ń sìn, òun sì máa ń rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n san owó orí fún ìjọba. (Róòmù 13:1-7; Títù 3:1, 2) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbèjà ara rẹ̀ níwájú àwọn aláṣẹ onípò gíga yìí mú kí wọ́n dá a láre torí pé wọ́n dá Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ láàfin Késárì.—Fílí. 2:24; Fílém. 22.
ÀWA NÁÀ GBỌ́DỌ̀ GBÈJÀ ÌHÌN RERE
Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 10:18) Ó dáa tá a bá jẹ́rìí nípa Jésù níwájú àwọn aláṣẹ. Tá a bá sapá láti gbèjà ìhìn rere, ìjọba lè fún wa lómìnira tá a fẹ́. Àmọ́ ó yẹ ká rántí pé ìwọ̀nba làwọn èèyàn aláìpé tó ń dá ẹjọ́ lè ṣe láti fìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìdájọ́ òdodo wá, táá sì fòpin sí gbogbo ìnilára.—Oníw. 8:9; Jer. 10:23.
Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni lè gbé orúkọ Jèhófà ga nígbà tí wọ́n bá ń gbèjà ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ ká fara balẹ̀, ká sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, ká sì jẹ́ kí ohun tá à ń sọ dá wa lójú. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn ò ní láti ṣe ìdánrawò bí wọ́n á ṣe gbèjà ara wọn, torí pé òun máa fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, òun á sì fún wọn ní ọgbọ́n, débi pé àwọn alátakò wọn kò ní lè borí wọn.—Lúùkù 21:14, 15; 2 Tím. 3:12; 1 Pét. 3:15.
Nígbà táwọn Kristẹni bá ń gbèjà ìgbàgbọ́ wọn níwájú àwọn ọba, àwọn gómìnà tàbí àwọn aláṣẹ míì, ṣe ni wọ́n ń lo àǹfààní yẹn láti jẹ́rìí fún wọn torí pé kì í rọrùn láti wàásù dé ọ̀dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Wọ́n ti dá àwọn ẹjọ́ kan tó gbè wá, ìyẹn sì ti fún wa lómìnira láti wàásù, ká sì ṣe ìjọsìn wa. Àmọ́, ibi yòówù kí àwọn ẹjọ́ náà já sí, ìgboyà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń lò láti jẹ́rìí níwájú àwọn aláṣẹ ń múnú Ọlọ́run dùn.
a Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ James Parkes sọ pé: ‘Àwọn Júù lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tiwọn. Kò sí yani lẹ́nu torí pé ìjọba Róòmù máa ń fàyè gba àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìjọba wọn láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n.’