ORÍ 101
Wọ́n Lọ Jẹun Nílé Símónì Ní Bẹ́tánì
MÁTÍÙ 26:6-13 MÁÀKÙ 14:3-9 JÒHÁNÙ 11:55–12:11
JÉSÙ PA DÀ SÍ BẸ́TÁNÌ, NÍTÒSÍ JERÚSÁLẸ́MÙ
MÀRÍÀ DA ÒRÓRÓ ONÍLỌ́FÍNŃDÀ SÍ ORÍ JÉSÙ
Bí Jésù ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, ó lọ sí Bẹ́tánì. Ìrìn máìlì méjìlá (12) ni wọ́n máa rìn, ọ̀nà yẹn ò sì dáa. Wọ́n tún máa ní láti gun òkè bí wọ́n ṣe ń lọ torí pé ilẹ̀ olókè ni Bẹ́tánì, àwọn òkè yẹn sì máa ń ga gan-an. Àmọ́ ibi tí Jẹ́ríkò wà dagun sísàlẹ̀. Abúlé kékeré ni Bẹ́tánì, ibẹ̀ sì ni Lásárù àtàwọn arábìnrin rẹ̀ ń gbé. Nǹkan bíi máìlì méjì ni Bẹ́tánì wà sí Jerúsálẹ́mù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Ólífì lápá ìlà oòrùn.
Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ti dé sí Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. Wọ́n ti tètè dé síbẹ̀ “kí wọ́n lè wẹ ara wọn mọ́ bí Òfin ṣe sọ,” torí wọ́n lè ti fara kan òkú tàbí kí wọ́n ti ṣe nǹkan kan tó lè sọ wọ́n di aláìmọ́. (Jòhánù 11:55; Nọ́ńbà 9:6-10) Àwọn kan lára àwọn tó tètè dé yìí kóra jọ sí tẹ́ńpìlì. Wọ́n ń rò ó bóyá Jésù máa wá síbi Ìrékọjá àbí kò ní wá.—Jòhánù 11:56.
Àwọn èèyàn ń bára wọn jiyàn gan-an lórí ọ̀rọ̀ Jésù. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan fẹ́ mú un kí wọ́n lè pa á. Kódà, wọ́n ti pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá mọ ibi tí Jésù wà, kó wá sọ fáwọn “kí wọ́n lè mú un.” (Jòhánù 11:57) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ti gbìyànjú láti pa Jésù tẹ́lẹ̀, lẹ́yìn tó jí Lásárù dìde. (Jòhánù 11:49-53) Torí náà, kò yani lẹ́nu táwọn kan bá ń rò ó pé Jésù lè má wá síbi táwọn èèyàn á ti rí i.
Jésù dé sí Bẹ́tánì lọ́jọ́ Friday, “nígbà tí Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà.” (Jòhánù 12:1) Wọ́n máa mú ọjọ́ tuntun nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn (ìyẹn Nísàn 8 tó jẹ́ ọjọ́ Sábáàtì). Torí náà, Jésù ti débi tó ń lọ kó tó di ọjọ́ Sábáàtì yẹn. Kò ní lè rin ìrìn yẹn láti Jẹ́ríkò lọ́jọ́ Sábáàtì, ìyẹn láti ìrọ̀lẹ́ Friday sí ìrọ̀lẹ́ Saturday, torí òfin àwọn Júù ò fàyè gba irú ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ilé Lásárù ni Jésù dé sí, bó ṣe máa ń ṣe.
Bẹ́tánì ni Símónì náà ń gbé. Ó pe Jésù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀, ó tún pe Lásárù náà, pé kí wọ́n wá jẹun nílé òun nírọ̀lẹ́ Saturday. Wọ́n máa ń pe Símónì ní “adẹ́tẹ̀,” bóyá torí pé adẹ́tẹ̀ ni tẹ́lẹ̀ kí Jésù tó wò ó sàn. Òṣìṣẹ́ kára ni Màtá, torí náà òun ló ń lọ sókè sódò láti tọ́jú àwọn àlejò. Àmọ́ Màríà ní tiẹ̀ ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí Jésù débi pé ohun tó ṣe yẹn dá àríyànjiyàn sílẹ̀.
Màríà ṣí ìgò òróró kékeré kan, òróró inú ẹ̀ tó “ìwọ̀n pọ́n-ùn kan òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì”. (Jòhánù 12:3) Òróró yìí ṣeyebíye gan-an, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) dínárì ni wọ́n ń tà á, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó owó iṣẹ́ ọdún kan! Màríà da òróró náà sí orí Jésù àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wá fi irun rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jésù. Ṣe ni gbogbo inú ilé náà bẹ̀rẹ̀ sí í ta sánsán.
Ni inú bá bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n béèrè pé: “Kí ló dé tó ń fi òróró onílọ́fínńdà yìí ṣòfò báyìí?” (Máàkù 14:4) Júdásì Ìsìkáríọ́tù náà fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí dun òun, ó sọ pé: “Kí ló dé tí a ò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì, ká sì fún àwọn aláìní?” (Jòhánù 12:5) Kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní ló ká Júdásì lára tó bẹ́ẹ̀. Torí ṣe ló máa ń jí owó nínú àpótí owó tí wọ́n tọ́jú sí i lọ́wọ́.
Jésù gbèjà Màríà, ó ní: “Kí ló dé tí ẹ fẹ́ máa yọ obìnrin yìí lẹ́nu? Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi. Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín, àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín. Nígbà tí obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà yìí sí ara mi, ó ṣe é kó lè múra mi sílẹ̀ fún ìsìnkú. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, wọ́n á máa sọ ohun tí obìnrin yìí ṣe láti fi rántí rẹ̀.”—Mátíù 26:10-13.
Ó ti lé lọ́jọ́ kan báyìí tí Jésù ti wà ní Bẹ́tánì, ìròyìn sì ti kàn káàkiri pé Jésù ti dé. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù wá sílé Símónì kí wọ́n lè rí Jésù, àmọ́ kì í ṣe òun nìkan ni wọ́n wá rí, wọ́n tún fẹ́ rí Lásárù, “ẹni tí Jésù jí dìde.” (Jòhánù 12:9) Làwọn olórí àlùfáà bá gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù àti Lásárù. Ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí ń rò ni pé Lásárù tó jíǹde ló fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gba Jésù gbọ́. Àbẹ́ ò rí i pé ìkà làwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí!