ORÍ 8
Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Ń Wàásù Ìhìn Rere
JÈHÓFÀ fún wa ní àpẹẹrẹ pípé tá ó máa tẹ̀ lé, ìyẹn Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. (1 Pét. 2:21) Tí ẹnì kan bá di ọmọlẹ́yìn Jésù, onítọ̀hún á máa wàásù ìhìn rere torí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni. Jésù fi hàn pé iṣẹ́ yìí máa fún onítọ̀hún ní ìtura tẹ̀mí, ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín.” (Mát. 11:28, 29) Gbogbo ẹni tó wá sọ́dọ̀ Jésù ló ń rí ìtura tó ṣèlérí náà gbà!
2 Torí pé Jésù ni Olórí Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run, ó pe àwọn kan pé kí wọ́n di ọmọlẹ́yìn òun. (Mát. 9:9; Jòh. 1:43) Ó kọ́ wọn ní iṣẹ́ ìwàásù, ó sì rán wọn jáde láti lọ ṣe iṣẹ́ kan náà tí òun ń ṣe. (Mát. 10:1–11:1; 20:28; Lúùkù 4:43) Nígbà tó yá, ó rán àwọn àádọ́rin (70) míì pé kí wọ́n lọ polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 10:1, 8-11) Nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí lọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fetí sí yín, fetí sí mi. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì kà yín sí, kò ka èmi náà sí. Bákan náà, ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, kò ka ẹni tó rán mi náà sí.” (Lúùkù 10:16) Nípa báyìí, Jésù jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí bí iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́ ti ṣe pàtàkì tó. Àbí ẹ ò rí nǹkan, wọ́n á máa ṣojú fún Jésù àti Ọlọ́run Gíga Jù Lọ! Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fún àwọn míì tó dáhùn sí ìkésíni Jésù lónìí pé kí wọ́n “máa tẹ̀ lé” òun. (Lúùkù 18:22; 2 Kọ́r. 2:17) Gbogbo àwọn tó bá dáhùn sí ìkésíni yìí la yàn pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 24:14; 28:19, 20.
3 Torí pé a ti dáhùn sí ìkésíni Jésù pè ká máa tẹ̀ lé òun, àǹfààní tá à ń rí ni pé a ti “wá mọ” Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (Jòh. 17:3) Jèhófà ti kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Lọ́lá ìtìlẹ́yìn rẹ̀, a ti yí èrò inú wa pa dà, a ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, a sì ti jẹ́ kí ìwà wa bá àwọn ìlànà òdodo Jèhófà mu. (Róòmù 12:1, 2; Éfé. 4:22-24; Kól. 3:9, 10) Ìmọrírì àtọkànwá tá a ní ti mú ká ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì ti ṣèrìbọmi láti fi hàn pé a ti yara wa sí mímọ́. Ìgbà tá a ṣèrìbọmi ni Jèhófà sọ wá di òjíṣẹ́.
4 Máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé ọwọ́ mímọ́ àti ọkàn mímọ́ la gbọ́dọ̀ máa fi ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Sm. 24:3, 4; Àìsá. 52:11; 2 Kọ́r. 6:14–7:1) Nítorí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jésù Kristi, a ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Héb. 10:19-23, 35, 36; Ìfi. 7:9, 10, 14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run ká má bàa mú àwọn èèyàn kọsẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé bí ìwà rere ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè àwọn aláìgbàgbọ́ sínú òtítọ́. (1 Kọ́r. 10:31, 33; 1 Pét. 3:1) Ọ̀nà wo lo máa gbà ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè kúnjú ìwọ̀n láti di òjíṣẹ́ tó ń wàásù ìhìn rere, kó sì dara pọ̀ mọ́ wa?
ÀWỌN AKÉDE TUNTUN
5 Látìgbà tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kó o ti máa rọ̀ ọ́ pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fún àwọn èèyàn. Rọ̀ ọ́ pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fún àwọn ẹbí rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn míì nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dà wọ́n pọ̀. Èyí ni ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà kọ́ àwọn ẹni tuntun láti di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi kí wọ́n sì di òjíṣẹ́ tó ń wàásù ìhìn rere. (Mát. 9:9; Lúùkù 6:40) Bí ẹni tuntun náà ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, tó sì ń jáfáfá sí i nínú ìjẹ́rìí àìjẹ́ bí àṣà, ó dájú pé á wù ú láti bá wa jáde òde ẹ̀rí.
BÉÈYÀN ṢE LÈ KÚNJÚ ÌWỌ̀N LÁTI DI AKÉDE
6 Kó o tó sọ pé kí ẹnì kan tẹ̀ lé wa jáde ìwàásù ilé-dé-ilé fúngbà àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé onítọ̀hún kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun kan. Ohun tí ẹni tó bá tẹ̀ lé wa lọ sóde ẹ̀rí ń sọ fún gbogbo èèyàn ni pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, a gbà pé ó ti ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ìlànà òdodo Jèhófà mu, ó sì lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.
7 Bó o ṣe ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó o sì ń jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ti mọ bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀. O lè ti kíyè sí i pé ó ń fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. Ṣùgbọ́n àwọn ohun kan wà nípa ìgbésí ayé akẹ́kọ̀ọ́ náà tí àwọn alàgbà máa fẹ́ bá ẹ̀yin méjèèjì jíròrò.
8 Olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ṣètò pé kí alàgbà méjì jíròrò àwọn ohun náà pẹ̀lú ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ (ọ̀kan nínú àwọn alàgbà náà máa jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ). Ní àwọn ìjọ tí kò ní alàgbà púpọ̀, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó dáńgájíá lè ṣìkejì alàgbà kan láti bójú tó ìjíròrò náà. Kí àwọn arákùnrin tá a ní kó bójú tó ìjíròrò náà sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀. Kódà, tó bá jẹ́ pé ìpàdé ni àwọn alàgbà ti gbọ́ nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà fẹ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n bá ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé. Kí ẹ ṣe é lọ́nà tí ara á fi tu akẹ́kọ̀ọ́ náà. Kí àwọn alàgbà tó lè fọwọ́ sí i pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ rèé:
(1) Ó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì.—2 Tím. 3:16.
(2) Ó mọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Ìwé Mímọ́, ó sì gbà wọ́n gbọ́ débi pé tí wọ́n bá bi í ní ìbéèrè, ìdáhùn rẹ̀ á bá Bíbélì mu, kò sì ní fi àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké tàbí èrò ara rẹ̀ dáhùn.—Mát. 7:21-23; 2 Tím. 2:15.
(3) Ó ń pa àṣẹ Bíbélì mọ̀ pé kó máa dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà ní àwọn ìpàdé ìjọ tó bá lágbára àtiṣe bẹ́ẹ̀.—Sm. 122:1; Héb. 10:24, 25.
(4) Ó mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣekúṣe, títí kan àgbèrè, ìkóbìnrinjọ, kí ọkùnrin àti ọkùnrin máa fẹ́ ara wọn tàbí kí obìnrin àti obìnrin máa fẹ́ ara wọn, ó sì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ yìí sílò nígbèésí ayé rẹ̀. Tí ẹni náà bá ń gbé pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì tí kì í ṣe ìbátan rẹ̀, àwọn méjèèjì ní láti ṣègbéyàwó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—Mát. 19:9; 1 Kọ́r. 6:9, 10; 1 Tím. 3:2, 12; Héb. 13:4.
(5) Ó ń ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì pé ká má ṣe mu àmupara, kì í sì í lo àwọn oògùn tó ń pani lọ́bọlọ̀ tí dókítà kò fọwọ́ sí, yálà wọ́n jẹ́ ewé tàbí oògùn míì.—2 Kọ́r. 7:1; Éfé. 5:18; 1 Pét. 4:3, 4.
(6) Ó mọ ìdí tí kò fi yẹ ká máa kó ẹgbẹ́ búburú.—1 Kọ́r. 15:33.
(7) Ó ti jáwọ́ pátápátá nínú gbogbo ẹ̀sìn èké tó ṣeé ṣe kó ti máa dara pọ̀ mọ́ tẹ́lẹ̀. Kò bá wọn ṣèsìn mọ́, kò sì bá wọn dá sí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.—2 Kọ́r. 6:14-18; Ìfi. 18:4.
(8) Kò bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ayé lọ́nàkọnà.—Jòh. 6:15; 15:19; Jém. 1:27.
(9) Ó gba ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, bó ṣe wà nínú Àìsáyà 2:4, ó sì ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn bẹ́ẹ̀.
(10) Òótọ́ ni pé ó fẹ́ di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Sm. 110:3.
9 Bí èrò akẹ́kọ̀ọ́ náà nípa èyíkéyìí lára ọ̀rọ̀ yìí kò bá dá àwọn alàgbà náà lójú, kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n lè lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò síwájú àwọn ìbéèrè náà láti mọ èrò rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì kó yé e pé àwọn tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ wàásù gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé tó bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tá a jíròrò náà mu. Ọ̀rọ̀ tó bá sọ ni àwọn alàgbà á fi mọ̀ bóyá ó mọ ohun tó yẹ kóun máa ṣe àti pé bóyá ó kúnjú ìwọ̀n dé ibi tó yẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá wa jáde lọ wàásù.
10 Kí àwọn alàgbà tètè sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà tó bá kúnjú ìwọ̀n. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ̀ bóyá ó kúnjú ìwọ̀n nígbà tí wọ́n bá fi máa parí ìjíròrò náà. Tó bá kúnjú ìwọ̀n, àwọn alàgbà á fi ìdùnnú sọ fún un pé o ti di akéde. (Róòmù 15:7) Kí wọ́n gbà á níyànjú pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù láìjáfara, kó sì ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ̀ ní ìparí oṣù náà. Àwọn alàgbà á ṣàlàyé fún un pé tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi tó sì ròyìn iṣẹ́ ìsìn nígbà àkọ́kọ́, wọ́n máa ṣí Àkọsílẹ̀ Akéde Ìjọ (Congregation’s Publisher Record) lórúkọ rẹ̀, wọ́n á sì fi àkọsílẹ̀ náà sínú fáìlì ìjọ. Àwọn alàgbà máa gba àwọn ìsọfúnni nípa akéde náà kí ètò Ọlọ́run lè fi bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, kí akéde náà lè kópa nínú ìjọsìn, ká sì lè ràn án lọ́wọ́ nínú ìjọsìn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà lè rán akéde tuntun náà létí pé a máa ń lo àwọn ìsọfúnni náà ní ìbámu pẹ̀lú Àdéhùn Ààbò Lórí Ìsọfúnni Ara Ẹni Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé Kárí Ayé bó ṣe wà lórí ìkànnì jw.org.
11 Tá a bá ń gbìyànjú láti mọ akéde tuntun náà sí i, tá a sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì ohun tó ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, a máa fún un níṣìírí. Ìyẹn á sì mú kó máa fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sílẹ̀ lóṣooṣù kó sì túbọ̀ tẹra mọ́ bó ṣe ń sin Jèhófà.—Fílí. 2:4; Héb. 13:2.
12 Tí àwọn alàgbà bá ti pinnu pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti kúnjú ìwọ̀n láti máa jáde òde ẹ̀rí, wọ́n á fún un ní ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn tó bá ti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ̀ sílẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́, a ó ṣe ìfilọ̀ ṣókí fún ìjọ pé ó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.
BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN ỌMỌDÉ LỌ́WỌ́
13 Àwọn ọmọdé pẹ̀lú lè di akéde ìhìn rere. Jésù kó àwọn ọmọdé mọ́ra ó sì súre fún wọn. (Mát. 19:13-15; 21:15, 16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe àwọn òbí ni láti bójú tó àwọn ọmọ wọn, àwọn míì nínú ìjọ lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ tó nífẹ̀ẹ́ láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Tó o bá jẹ́ òbí, àpẹẹrẹ rere rẹ nínú iṣẹ́ ìwàásù yóò ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti máa fi ìtara sin Ọlọ́run. Tí ọmọ kan tí ìwà rẹ̀ dáa bá sọ pé ó wu òun láti máa sọ ohun tí òun gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn, báwo la ṣe lè túbọ̀ ràn án lọ́wọ́?
14 Ohun tí òbí ọmọ náà máa ṣe ni pé kó sọ fún ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kí wọ́n lè jíròrò bóyá ọmọ náà kúnjú ìwọ̀n láti di akéde. Olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà á ṣètò pé kí alàgbà méjì jíròrò pẹ̀lú ọmọ náà àti òbí rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tàbí alágbàtọ́ rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí (kí ọ̀kan nínú alàgbà méjì náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ). Bí ọmọ náà bá ti mọ àwọn ohun tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ mọ̀ nínú Bíbélì tó sì fi hàn pé òun fẹ́ láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn fi hàn pé ó ń tẹ̀ síwájú. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò títí kan àwọn nǹkan míì tá à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà, àwọn alàgbà méjèèjì á wá pinnu bóyá ọmọ náà lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. (Lúùkù 6:45; Róòmù 10:10) Bí àwọn alàgbà bá ń jíròrò pẹ̀lú ọmọdé, wọn ò ní jíròrò àwọn kókó kan tá a sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà, tó sì ṣe kedere pé kò kan ọmọdé.
15 Nígbà ìjíròrò náà, kí àwọn alàgbà gbóríyìn fún ọmọ náà pé ò ń tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì fún un níṣìírí pé kó ní in lọ́kàn pé òun máa ṣèrìbọmi lọ́jọ́ iwájú. Kò sí àní-àní pé àwọn òbí ọmọ náà ti ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, torí náà ó yẹ kí wọ́n gbóríyìn fún àwọn òbí náà. Kí àwọn òbí lè túbọ̀ ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú, kí àwọn alàgbà ní kí wọ́n lọ wo àpilẹ̀kọ náà, “Ọ̀rọ̀ Ìyànjú fún Àwọn Òbí,” tó wà ní ojú ìwé 179 sí 181.
ÌYÀSÍMÍMỌ́ ÀTI ÌRÌBỌMI
16 Tó o bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ tó o sì ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé, èyí á jẹ́ kó o mọ Jèhófà kó o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà, ó yẹ kó o jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Lọ́nà wo? Ìyẹn ni pé kó o ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún un kó o sì fi èyí hàn nípa ìrìbọmi.—Mát. 28:19, 20.
17 Ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí kéèyàn ya nǹkan sọ́tọ̀, kó di ohun mímọ́. Téèyàn bá fẹ́ ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, á gbàdúrà sí Ọlọ́run á sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa lo gbogbo ìgbésí ayé òun láti sìn ín, òun á sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni wàá máa sìn títí láé. (Diu. 5:9) Àárín ìwọ àti Ọlọ́run nìkan ni ìpinnu yìí wà. Kò sẹ́ni tó lè bá ẹ ṣe é.
18 Àmọ́, ọ̀rọ̀ yìí kò mọ sórí pé kó o sọ fún Jèhófà pé o jẹ́ tirẹ̀. O gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Bó o sì ṣe máa ṣe é ni pé kó o ṣe ìrìbọmi nínú omi bíi ti Jésù. (1 Pét. 2:21; 3:21) Tó o bá ti pinnu pé Jèhófà lo fẹ́ sìn, tó o sì fẹ́ ṣe ìrìbọmi, kí ló yẹ kó o ṣe? Lọ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Ó máa ṣètò pé kí àwọn alàgbà mélòó kan bá ẹ sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá o kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi ṣe. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa èyí, jọ̀ọ́ ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, “Ọ̀rọ̀ Ìyànjú fún Àwọn Akéde Tí Kò Tíì Ṣèrìbọmi,” tó wà ní ojú ìwé 182 sí 184 nínú ìwé yìí àti “Ìbéèrè Tá A Máa Ń Bi Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi,” ní ojú ìwé 185 sí 207.
ÌRÒYÌN NÍPA BÍ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ṢE Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ
19 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ìròyìn nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe ń gbòòrò sí i kárí ayé máa ń fún àwa èèyàn Jèhófà níṣìírí. Látìgbà tí Jésù Kristi ti kọ́kọ́ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà kárí ayé ló ti ń wu àwọn Kristẹni tòótọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe máa ṣiṣẹ́ náà láṣeyọrí.—Mát. 28:19, 20; Máàkù 13:10; Ìṣe 1:8.
20 Inú àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù máa ń dùn láti gbọ́ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀ síwájú. (Máàkù 6:30) Ìwé Ìṣe sọ fún wa pé nǹkan bí ọgọ́fà (120) èèyàn ló wà níbẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Kò pẹ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fi di ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000), nígbà tó sì yá, wọ́n di ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000). Bíbélì ròyìn pé: “Jèhófà ń mú kí àwọn tó ń rí ìgbàlà dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́” àti pé “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ náà.” (Ìṣe 1:15; 2:5-11, 41, 47; 4:4; 6:7) Ẹ wo bí ìròyìn nípa bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i yìí ṣe máa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn níṣìírí gan-an! Ó dájú pé èyí á mú kí wọ́n máa bá iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ nìṣó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù ń ṣe inúnibíni tó rorò sí wọn!
21 Nígbà tó fi máa di ọdún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kólósè pé ìhìn rere náà ‘ń so èso, ó sì ń gbilẹ̀ ní gbogbo ayé’ àti pé wọ́n ti ‘wàásù rẹ̀ láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.’ (Kól. 1:5, 6, 23) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀mí mímọ́ sì fún wọn lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù láṣeyọrí kí ètò àwọn Júù tó dópin ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni. Ẹ ò rí i bí ìròyìn nípa bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú ṣe máa fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ yẹn níṣìírí!
Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ pé ká ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà dójú àmì kí òpin tó dé? Ṣé ò ń sa gbogbo ipá rẹ?
22 Lọ́nà kan náà, ètò Jèhófà ń ṣe àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe bí iṣẹ́ náà ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mátíù 24:14 ṣẹ, tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti ṣe. Ó sì yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sa gbogbo ipá wa ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà dójú àmì kí òpin tó dé. Jèhófà máa rí sí i pé a parí iṣẹ́ náà, tá a bá sì lọ́wọ́ nínú rẹ̀, inú Jèhófà máa dùn sí wa.—Ìsík. 3:18-21.
ÌRÒYÌN IṢẸ́ ÌSÌN RẸ
23 Àwọn nǹkan wo gan-an ló yẹ ká ròyìn? A máa rí àwọn ohun tó yẹ ká ròyìn lórí ìwé pélébé tá a pè ní Field Service Report, ìyẹn ìwé tá a fi ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá. Àmọ́, àwọn àlàyé tó tẹ̀ lé e yìí lè ràn wá lọ́wọ́.
24 Lábẹ́ àlàfo tá a pè ní “Placements (Printed and Electronic),” wàá kọ àròpọ̀ gbogbo ìtẹ̀jáde tó o fún àwọn tí kò tíì ṣèrìbọmi, yàlá èyí tá a ṣe jáde tàbí èyí tó o fi ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ. Lábẹ́ àlàfo tá a pè ní “Video Showings,” wàá kọ iye ìgbà tó o fi àwọn fídíò wa han àwọn èèyàn.
25 Iye ìgbà tó o pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni tí kò tíì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tí kò sì tíì ṣèrìbọmi láti mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lo máa kọ sábẹ́ “Return Visits,” ìyẹn ìpadàbẹ̀wò. O lè ṣe ìpadàbẹ̀wò nígbà tó o bá lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tàbí tó o kọ lẹ́tà sí i, tó o pè é lórí fóònù, tó o fi àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ránṣẹ́ sí i tàbí tó o fi ìwé sílẹ̀ fún un. Gbogbo ìgbà tá a bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnì kan la máa ka ìpadàbẹ̀wò. Òbí kan lè ka ìpadàbẹ̀wò kan lọ́sẹ̀ tó bá jẹ́ pé òun ló darí ìjọsìn ìdílé wọn, tí ọmọ rẹ̀ tí kò tíì ṣèrìbọmi sì wà níbẹ̀.
26 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la sábà máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnì kan, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣoṣo la máa ròyìn pé onítọ̀hún jẹ́ ní ìparí oṣù. Torí náà, àròpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí akéde kan bá ṣe lóṣù ló máa kọ sílẹ̀. Lára àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a lè ròyìn ni èyí tá a ṣe pẹ̀lú àwọn tí kò tíì ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Tí ẹnì kan nínú ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn bá ní kó o máa kọ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tàbí tó o bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi àmọ́ tí kò tíì parí ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn náà, o máa ròyìn wọn.
27 Rí i pé iye wákàtí tó o lò nínú iṣẹ́ ìwàásù lo kọ sínú àlàfo tá a pè ní “Hours” ìyẹn wákàtí. Ohun tí èyí ń tọ́ka sí ni iye wákàtí tó o lò nígbà tó o ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ìpadàbẹ̀wò, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí nígbà tó o wàásù láìjẹ́-bí-àṣà tàbí nígbàkigbà tó o wàásù fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Bí akéde méjì bá jọ ṣiṣẹ́, àwọn méjèèjì ló máa ròyìn àkókò tí wọ́n lò, ṣùgbọ́n ẹni tó bá ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa ròyìn rẹ̀. Òbí méjèèjì lè ròyìn ohun tí ó tó wákàtí kan lọ́sẹ̀ tó bá jẹ́ pé àwọn méjèèjì ló fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Àwọn arákùnrin lè ròyìn àkókò tí wọ́n fi sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ẹni tó ṣe ògbufọ̀ nígbà àsọyé fún gbogbo èèyàn náà lè ròyìn àkókò tó lò. Àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tá a máa ń ṣe ṣùgbọ́n tí a kì í ka àkókò tá a fi ṣe wọ́n, bí àkókò tá a fi múra iṣẹ́ ìsìn pápá sílẹ̀, èyí tá a lò níbi ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, èyí tá a fi bójú tó nǹkan ara ẹni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
28 Akéde kọ̀ọ̀kan ló máa jẹ́ kí ìlànà Ọlọ́run darí ẹ̀rí ọkàn òun nígbà tó bá ń pinnu bó ṣe máa ka àkókò tó fi wàásù, á sì ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. Àwọn akéde kan máa ń wàásù ní àwọn ibi tí èèyàn pọ̀ sí gan-an, àwọn míì sì ń wàásù níbi tí àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, tó sì gba pé kí wọ́n rìn gan-an kí wọ́n tó débẹ̀. Ìpínlẹ̀ ìwàásù yàtọ̀ síra; ojú táwọn akéde fi ń wo iṣẹ́ ìwàásù wọn sì yàtọ̀ síra. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń fẹ́ kí kálukú wa lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, a ò sì yan ẹnikẹ́ni pé kó máa ṣe àríwísí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ẹlòmíì.—Mát. 6:1; 7:1; 1 Tím. 1:5.
29 Tá a bá fẹ́ ròyìn àkókò tá a lò nínú iṣẹ́ ìwàásù, odindi wákàtí ló yẹ ká ròyìn, kì í ṣe ààbọ̀ wákàtí. Àmọ́ tí akéde kan bá jẹ́ arúgbó, tàbí tí àìsàn ò jẹ́ kó jáde nílé, tàbí tó ń gbé nílé àwọn arúgbó tàbí tí àwọn nǹkan míì mú kó ṣòro fún un láti wàásù, ó lè fi ìròyìn oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sílẹ̀. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ló fi wàásù lóṣù, kó fi ìròyìn náà sílẹ̀. A máa ka ẹni náà sí akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣe déédéé. Ètò yìí tún kan akéde tó jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára láti ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀, bóyá tí kò lè rìn káàkiri fún bí oṣù kan torí pé àìsàn tó le ń ṣe é tàbí torí pé ó fara ṣèṣe. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àwọn tí kò lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù nìkan ni ètò yìí wà fún. Ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ló sì máa pinnu bóyá ká lo ètò yìí fún akéde kan.
ÀKỌSÍLẸ̀ AKÉDE ÌJỌ
30 A máa ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ oṣooṣù sínú Àkọsílẹ̀ Akéde Ìjọ, ìyẹn Congregation’s Publisher Record. Ìjọ ló ni àkọsílẹ̀ náà. Tó o bá fẹ́ kó lọ sí ìjọ míì, rí i dájú pé o sọ fún àwọn alàgbà. Akọ̀wé ìjọ máa fi àkọsílẹ̀ rẹ ránṣẹ́ sí ìjọ tuntun tó o lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa rọrùn fún àwọn alàgbà ìjọ tó o kó lọ láti gbà ẹ́ tọwọ́tẹsẹ̀, kí wọ́n sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tó o bá lọ síbì kan, tó ò sì ní lò tó oṣù mẹ́ta níbẹ̀, jọ̀wọ́ máa fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ ránṣẹ́ sí ìjọ rẹ látibi tó o bá wà.
ÌDÍ TÁ A FI Ń RÒYÌN IṢẸ́ ÌSÌN WA
31 Ṣé o máa ń gbàgbé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn rẹ sílẹ̀? Ó dájú pé gbogbo wa la máa ń nílò kí wọ́n rán wa létí nǹkan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, tá a bá ń fi ojú tó tọ́ wo ríròyìn tá a sì mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ròyìn, àá tètè máa rántí láti fi ìròyìn wa sílẹ̀.
32 Àwọn kan ti béèrè pé: “Ṣebí Jèhófà mọ ohun tí mò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, kí nìdí tí mo fi ní láti máa fún ìjọ ní ìròyìn mi?” Òótọ́ ni pé Jèhófà mọ ohun tá à ń ṣe, ó sì mọ̀ bóyá tọkàntọkàn la fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wa tàbí ńṣe là ń ṣe iṣẹ́ gbà-má-póò-rọ́wọ́-mi. Ṣùgbọ́n rántí pé Jèhófà mú kí á ṣàkọsílẹ̀ iye ọjọ́ tí Nóà lò nínú áàkì àti iye ọdún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi rìn nínú aginjù. Ọlọ́run rí i pé a ṣàkọsílẹ̀ iye àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn tó ṣàìgbọràn. Ó rí i pé a ṣàkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe gba ilẹ̀ Kénáánì díẹ̀díẹ̀ àti ohun tí àwọn onídàájọ́ tí wọ́n fi òótọ́ inú ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì gbé ṣe. Ó tún mú ká ṣàkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ nǹkan tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe. Ó mí sí àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ká bàa lè rí i pé Ọlọ́run fi ojú pàtàkì wo kíkọ́ àkọsílẹ̀ tó péye.
33 Àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìròyìn àtàwọn àkọsílẹ̀ táwọn èèyàn Jèhófà ṣe péye gan-an. Lọ́pọ̀ ìgbà, ì bá ṣòro láti lóye bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì ṣe le tó ká ní wọn ò sọ iye àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn gan-an. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí: Jẹ́nẹ́sísì 46:27; Ẹ́kísódù 12:37; Àwọn Onídàájọ́ 7:7; 2 Àwọn Ọba 19:35; 2 Kíróníkà 14:9-13; Jòhánù 6:10; 21:11; Ìṣe 2:41; 19:19.
34 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà là ń ròyìn, síbẹ̀ àwọn nǹkan tá à ń ròyìn wúlò fún wa nínú ètò Jèhófà. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì pa dà dé látẹnu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ròyìn “gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, tí wọ́n sì fi kọ́ni” fún Jésù. (Máàkù 6:30) Nígbà míì, àwọn ìròyìn tó ń wọlé wá lè fi hàn pé àwọn apá kan lára iṣẹ́ ìwàásù wa ń fẹ́ àbójútó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àkọsílẹ̀ náà lè fi hàn pé ìtẹ̀síwájú ti bá apá kan iṣẹ́ ìwàásù wa, àmọ́ iye àwọn akéde lè má pọ̀ sí i. Ó lè jẹ́ pé àwọn ará nílò ìṣírí, ó sì lè jẹ́ pé àwọn ìṣòro kan wà tó ń fẹ́ àbójútó. Àwọn alábòójútó tó ń rí sí ìròyìn ìjọ á kíyè sí àwọn ìròyìn náà, wọ́n á sì sapá láti ṣe àtúnṣe ohunkóhun tó bá ń fa ẹnì kan tàbí ìjọ sẹ́yìn.
35 Àwọn ìròyìn tá à ń rí gbà tún máa ń ṣe ètò Ọlọ́run láǹfààní torí pé a máa ń lò wọ́n láti fi mọ àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. A fi ń mọ àwọn ibi tá a ti ṣe dáadáa gan-an. A fi ń mọ àwọn ibi tá ò fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ síwájú. A tún máa ń lo àwọn ìròyìn náà láti fi mọ àwọn ìtẹ̀jáde tá a nílò ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìròyìn tí ètò Ọlọ́run ń rí gbà la fi ń mọ iye ìwé tá a nílò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tó yàtọ̀ síra kárí ayé, ká lè máa tẹ iye ìwé tí wọ́n nílò.
36 Àwọn ìròyìn yìí máa ń fún ọ̀pọ̀ wa níṣìírí. Àbí inú wa kì í dùn nígbà tá a bá gbọ́ nípa gudugudu méje táwọn ará wa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere kárí ayé? Ìròyìn nípa ìtẹ̀síwájú tá a ní ń jẹ́ ká rí bí ètò Jèhófà ṣe ń gbòòrò sí i. Àwọn ìrírí tá à ń gbọ́ tún ń mú inú wa dùn, wọ́n ń jẹ́ ká ní ìtara, wọ́n sì ń mú ká máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣe 15:3) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká tètè máa fi ìròyìn wa sílẹ̀, ó sì ń fi hàn pé à ń gba ti àwọn ará wa rò kárí ayé. Lọ́nà kékeré yìí, à ń fi hàn pé à ń tẹrí ba fún ètò Jèhófà.—Lúùkù 16:10; Héb. 13:17.
KÍ NI ÀFOJÚSÙN RẸ?
37 Kò sí ìdí láti máa fi ohun tá a bá ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù wé ti ẹlòmíràn. (Gál. 5:26; 6:4) Ipò kálukú wa yàtọ̀. Síbẹ̀, a lè jàǹfààní tó pọ̀ tá a bá fi ohun tọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ṣe àfojúsùn wa, tá a sì ń fi ìyẹn pinnu bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú sí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí ọwọ́ wa bá ṣe ń tẹ àwọn àfojúsùn wa, inú wa á máa dùn torí ohun tá à ń gbé ṣe.
38 Ó dájú pé Jèhófà ń mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá sínú ètò rẹ̀, ìyẹn àwọn tó máa dáàbò bò nígbà “ìpọ́njú ńlá náà.” Àkókò tá a wà yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ń ṣẹ. Ó sọ pé: “Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré sì máa di orílẹ̀-èdè alágbára. Èmi fúnra mi, Jèhófà, máa mú kó yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Ìfi. 7:9, 14; Àìsá. 60:22) Àǹfààní ńlá gbáà ni pé a jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìn rere láwọn ọjọ́ ìkẹyìn táwọn nǹkan pàtàkì ń ṣẹlẹ̀ yìí!—Mát. 24:14.