ORÍ 82
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Ní Pèríà
Ẹ SAPÁ LÁTI GBA ẸNU Ọ̀NÀ TÓÓRÓ WỌLÉ
JÉSÙ GBỌ́DỌ̀ KÚ SÍ JERÚSÁLÉMÙ
Ó ti tó ọjọ́ bíi mélòó kan tí Jésù ti ń kọ́ni, tó sì ń wo àwọn èèyàn sàn ní Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, ó sọdá Odò Jọ́dánì kó lè máa kọ́ni láti ìlú kan dé òmíì ní agbègbè Pèríà. Àmọ́ kò ní pẹ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
Nígbà tí Jésù wà ní Pèríà, ọkùnrin kan bi í pé: “Olúwa, ṣé díẹ̀ ni àwọn tí a máa gbà là?” Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà mọ̀ nípa àríyànjiyàn kan táwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń ṣe pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa rí ìgbàlà. Dípò kí Jésù sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn tó máa rí ìgbàlà ṣe máa pọ̀ tó, ohun tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè rí ìgbàlà ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó ní: “Ẹ sa gbogbo ipá yín láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé.” Ó gba ìsapá lóòótọ́ kéèyàn tó lè rí ìgbàlà. Kí nìdí? Jésù ṣàlàyé pé: “Mò ń sọ fún yín pé, ọ̀pọ̀ èèyàn máa fẹ́ wọlé àmọ́ wọn ò ní lè wọlé.”—Lúùkù 13:23, 24.
Jésù wá ṣàpèjúwe ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn sapá, ó ní: “Tí baálé ilé bá dìde, tó sì ti ilẹ̀kùn pa, ìta lẹ máa dúró sí, ẹ máa kan ilẹ̀kùn, ẹ sì máa sọ pé, ‘Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’ . . . Àmọ́ ó máa sọ fún yín pé, ‘Mi ò mọ ibi tí ẹ ti wá. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin aláìṣòdodo!’”—Lúùkù 13:25-27.
Àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá pẹ́, ìyẹn ẹni tó dé lásìkò tó wù ú tó wá rí i pé wọ́n ti tilẹ̀kùn pa. Ṣe ló yẹ kẹ́ni náà tètè dé, kódà tí ò bá tiẹ̀ rọ̀ ọ́ lọ́rùn. Bí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn yẹn ṣe rí nìyẹn, torí wọn ì bá ti jàǹfààní látinú ohun tí Jésù ń kọ́ wọn. Àmọ́ wọn ò lo àǹfààní tí wọ́n ní láti fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Àwọn ni Ọlọ́run dìídì rán Jésù sí, síbẹ̀ wọn ò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọn ò tiẹ̀ mọyì ètò tí Ọlọ́run ṣe láti gba aráyé là. Jésù wá sọ pé wọ́n máa ‘sunkún, wọ́n á sì payín keke’ tí wọ́n bá jù wọ́n síta. Àmọ́ àwọn èèyàn “láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá àti gúúsù,” ìyẹn àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè “máa jókòó sídìí tábìlì nínú Ìjọba Ọlọ́run.”—Lúùkù 13:28, 29.
Jésù wá ṣàlàyé pé: “Àwọn tó jẹ́ ẹni ìkẹyìn [ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù àtàwọn Júù tí wọ́n ń wò bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan] máa di ẹni àkọ́kọ́, àwọn tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ [ìyẹn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tí wọ́n ń yangàn torí pé wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù] sì máa di ẹni ìkẹyìn.” (Lúùkù 13:30) Àwọn aláìmoore yẹn máa jẹ́ ẹni “ìkẹyìn” ní ti pé wọn ò tiẹ̀ ní dé inú Ìjọba Ọlọ́run rárá.
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn Farisí kan wá sọ́dọ̀ Jésù wọ́n sì sọ fún un pé: “Jáde kúrò níbí, torí Hẹ́rọ́dù [Áńtípà] fẹ́ pa ọ́.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ọba Hẹ́rọ́dù fúnra rẹ̀ ló ní káwọn èèyàn máa sọ bẹ́ẹ̀ kí Jésù lè kúrò ní agbègbè yẹn. Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Hẹ́rọ́dù pé òun ò tún fẹ́ pa wòlíì míì bóun ṣe pa Jòhánù Arinibọmi. Àmọ́ Jésù sọ fáwọn Farisí náà pé: “Ẹ lọ sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yẹn pé, ‘Wò ó! Mò ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, mo sì ń wo àwọn èèyàn sàn lónìí àti lọ́la, màá ṣe tán ní ọjọ́ kẹta.’” (Lúùkù 13:31, 32) Nígbà tí Jésù pe Hẹ́rọ́dù ní “kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló ń dọ́gbọ́n sọ pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ bíi ti kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ni Hẹ́rọ́dù. Kò sẹ́ni tó lè dí Jésù lọ́wọ́ tàbí kán an lójú, Hẹ́rọ́dù gan-an ò tó bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé Jésù máa parí iṣẹ́ tí Baba rẹ̀ rán an lọ́nà tó fẹ́ kó gbà ṣe é, èèyàn kọ́ ló sì máa sọ ohun tó máa ṣe fún un.
Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sítòsí Jerúsálẹ́mù, torí ó ti sọ ṣáájú ìgbà yẹn pé: “Kò lè ṣẹlẹ̀ pé kí wọ́n pa wòlíì lẹ́yìn òde Jerúsálẹ́mù.” (Lúùkù 13:33) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé òun máa kú sí Jerúsálẹ́mù nígbà tó jẹ́ pé kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé wọ́n máa pa Mèsáyà níbẹ̀? Ìdí ni pé ibẹ̀ ni olú ìlú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ibẹ̀ náà ni ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní Ísírẹ́lì wà, táwọn mọ́kànléláàádọ́rin (71) tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti ń gbẹ́jọ́. Ilé ẹjọ́ yẹn sì ni wọ́n ti máa ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn tí wọ́n bá kà sí wòlíì èké. Jerúsálẹ́mù yìí kan náà ni wọ́n ti máa ń fi ẹran rúbọ. Torí náà, Jésù gbà pé kò ní bọ́gbọ́n mu tó bá jẹ́ pé ibòmíì ni wọ́n ti máa pa òun.
Jésù wá sọ pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, ìlú tó ń pa àwọn wòlíì, tó sì ń sọ àwọn tí a rán sí i lókùúta, wo bí mo ṣe máa ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ tó lọ́pọ̀ ìgbà, bí ìgbà tí àgbébọ̀ adìyẹ ń kó ọ̀wọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀! Àmọ́ ẹ ò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ẹ wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.” (Lúùkù 13:34, 35) Orílẹ̀-èdè náà ò tẹ́wọ́ gba Ọmọ Ọlọ́run, ó sì dájú pé wọn ò ní lọ láìjìyà!
Kí Jésù tó lọ sí Jerúsálẹ́mù, ọkùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú nínú àwọn Farisí ní kó wá jẹun nílé òun lọ́jọ́ Sábáàtì. Ṣe ni wọ́n ń ṣọ́ Jésù lójú méjèèjì nígbà tó débẹ̀, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa wo ọkùnrin kan sàn. Àrùn ògùdùgbẹ̀ ló ń ṣe ọkùnrin náà, ìyẹn àìsàn àpọ̀jù omi ara tó máa ń jẹ́ kí ara èèyàn wú. Jésù wá béèrè lọ́wọ́ àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin tó wà níbẹ̀, ó ní: “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì àbí kò bófin mu?”—Lúùkù 14:3.
Wọn ò dá a lóhùn. Jésù wá wo ọkùnrin náà sàn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ta ni ọmọ rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ máa já sí kànga nínú yín, tí kò ní fà á jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì?” (Lúùkù 14:5) Wọn ò tún rí ohunkóhun sọ sí ọ̀rọ̀ tó gba àròjinlẹ̀ tí Jésù sọ yẹn.