Bọla fun Oriṣi Eniyan Gbogbo
“Bọla fun oriṣi eniyan gbogbo, . . . bẹru Ọlọrun, ni ọla fun ọba.” —1 PETERU 2:17, NW.
1. (a) Tani yatọ si Ọlọrun ati Kristi ni a le bọla fun lọna titọ? (b) Ni awọn agbegbe wo ni a ti le fi ọla han fun awọn eniyan ni ibamu pẹlu 1 Peteru 2:17?
AWA ti rii pe a wa labẹ aigbọdọmaṣe lati fi ọla fun Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi. Iyẹn jẹ ohun ti o tọ, lọgbọn ninu, ti o si jẹ onifẹẹ lati ṣe. Sibẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tun fihan wa pe awa nilati bọla fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa. “Bọla fun oriṣi eniyan gbogbo,” ni a sọ fun wa. (1 Peteru 2:17) Niwọnbi ẹsẹ iwe yii ti pari pẹlu aṣẹ naa pe, “ni ọla fun ọba,” itumọ ti o mulọwọ ni pe ọla ni a nilati fi fun awọn wọnni ti wọn lẹtọọ sii lati gbà á nitori ipò wọn. Nigba naa, awọn wo ni a nilati bu ọla fun lọna titọ? Iye awọn ti o lẹtọọ si ọla le ni ọpọlọpọ sii ninu ju bi awọn kan ti lè rò lọ. Awa le wipe apa iha mẹrin ni o wà nibi ti awa nilati fi ọla hàn fun awọn eniyan miiran.
Bọla Fun Awọn Oluṣakoso Oloṣelu
2. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe “ọba” ti a mẹnukan ni 1 Peteru 2:17 tọkasi ọba ẹda eniyan tabi oluṣakoso oloṣelu eyikeyii?
2 Akọkọ ninu awọn apa iha wọnyi tanmọ awọn ijọba aye. Awa nilati bu ọla fun awọn oluṣakoso oloṣelu. Nigba ti Peteru gbaninimọran pe: “Ni ọla fun ọba,” eeṣe ti a fi wipe Peteru ni awọn oluṣakoso oloṣelu lọkan? Nitori pe oun nsọrọ nipa ipo ti o wa lẹhin ode ijọ Kristian. Oun ṣẹṣẹ pari sisọ pe: “Ẹ mu araayin tẹriba fun olukuluku iṣẹda eniyan: boya fun ọba gẹgẹ bi onipo gigaju tabi awọn gomina gẹgẹbi ẹni ti a ran lati ọdọ rẹ̀.” Ṣakiyesi, pẹlu, pe Peteru gbe Ọlọrun kalẹ ni ifiwera pẹlu “ọba,” ni wiwipe: “Bẹru Ọlọrun, ni ọla fun ọba.” (1 Peteru 2:13, 14) Nitori naa “ọba” ẹni ti Peteru rọni lati ni ọla fun tọkasi awọn ọba ẹda eniyan ati awọn oluṣakoso oloṣelu.
3. Awọn wo ni “alaṣẹ onipo gigaju,” naa, kinni o sì yẹ fun wọn?
3 Apọsteli Pọọlu paṣẹ lọna ti o farajọra pe: “Foribalẹ [“wa ni itẹriba,” NW] fun awọn alaṣẹ ti o wà ní ipo giga.” “Awọn alaṣẹ ti o wà ní ipo giga” wọnyi kii ṣe Jehofa Ọlọrun tabi Jesu Kristi, ṣugbọn wọn jẹ awọn oluṣakoso oloṣelu, awọn oṣiṣẹ olóyè ijọba. Pẹlu iwọnyi lọkan Pọọlu nbaa lọ lati wipe: “Nitori naa ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: . . . ọla fun ẹni ti ọla nṣe tirẹ̀.” Bẹẹni, iru awọn ẹni bẹẹ ti Ọlọrun ti yọnda fun lati ṣakoso lọna oṣelu ni wọn lẹtọọ si ọla.—Roomu 13:1, 7.
4. (a) Bawo ni a ṣe lè fi ọla hàn fun awọn oluṣakoso oloṣelu? (b) Apẹẹrẹ wo ni aposteli Pọọlu filelẹ ninu fifi ọla hàn fun awọn oluṣakoso?
4 Bawo ni awa yoo ṣe bọla fun awọn alakoso oloṣelu? Ọna kan ni nipa biba wọn lò pẹlu ọ̀wọ̀ jijinlẹ. (Fiwera pẹlu 1 Peteru 3:15.) Ati nitori ipo wọn, iru ọ̀wọ̀ bẹẹ tọ si wọn ani bi o tilẹ jẹ pe wọn le jẹ ẹni buburu paapaa. Opitan ara Roomu Tacitus ṣapejuwe Gomina Fẹliisi gẹgẹ bi ọkunrin kan ti o “ronu pe oun le ṣe iṣẹ ibi eyikeyii ní àṣegbé.” Sibẹ Pọọlu bẹrẹ ìgbèjà ọrọ rẹ̀ niwaju Fẹliisi ni ọna ti o kun fun ọ̀wọ̀. Lọna ti o farajọra, Pọọlu fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fun ọba Hẹrodu Agiripa Keji, “inu emi tikaraami dùn nitori ti emi yoo wi ti ẹnu mi lonii niwaju rẹ,” ani bi o tilẹ jẹ pe Pọọlu mọ pe Agiripa ngbe igbesi-aye onibaalopọ takọtabo laaarin ibatan ti o sunmọra. Bakan naa bẹẹ gẹgẹ, Pọọlu fi ọla han fun Gomina Fẹsitọsi, ni fifi ọrọ naa “ọlọla julọ,” pè é ani bi o tilẹ jẹ pe Fẹsitọsi jẹ olujọsin awọn oriṣa.—Iṣe 24:10; 26:2, 3, 24, 25.
5. Ọna wo siwaju sii ni a lè gbà fi ọla hàn fun awọn alaṣẹ ijọba, bawo sì ni awọn Ẹlẹrii Jehofa ṣe fi apẹẹrẹ rere lelẹ ninu ṣiṣe eyi?
5 Ọna miiran ti awa fi ọla han fun awọn oṣiṣẹ oloye ijọba ni a fihan lati ọwọ apọsteli Pọọlu nigba ti o kọwe nipa fifun awọn alaṣẹ ijọba ni ohun ti o tọ́ si wọn. Oun sọ pe ki a san “owó òde fun ẹni ti owó òde nṣe tirẹ̀: owó bodè fun ẹni ti owó bodè nṣe tirẹ̀.” (Roomu 13:7) Awọn Ẹlẹrii Jehofa nfi iru awọn ohun ti o tọ bẹẹ funni laika orilẹ-ede naa ni aye nibi ti wọn ngbe si. Ni Italy iwe-irohin La Stampa ṣakiyesi pe: “Awọn ni eniyan ilu ti wọn duro ṣinṣin julọ ti ẹnikan le daniyan fun: wọn kii yẹ owo ori tabi wa ọna lati sa fun awọn ofin ti ko rọgbọ fun ere tiwọn.” Iwe-irohin The Post ti Palm Beach, Florida, U.S.A., si ṣakiyesi nipa awọn Ẹlẹrii Jehofa pe: “Wọn nsan owo ori wọn. Wọn jẹ diẹ lara awọn ara ilu aláìlábòsí julọ ninu Ijọba-ibilẹ.”
Fi Ọla Han fun Awọn Agbanisiṣẹ
6. Fun awọn wo tun ni awọn aposteli Pọọlu ati Peteru sọ pe a nilati fi ọla fun?
6 Agbegbe keji nibi ti ọla ti yẹ ni awọn ibi ti a ti gba wa siṣẹ. Apọsteli Pọọlu ati Peteru tẹnumọ ijẹpataki ti ki awọn Kristian maa bọla fun awọn wọnni ti wọn fi ṣe olori wọn ninu ajọṣepọ iṣẹ kan. Pọọlu kọwe pe: “Ki gbogbo ẹni ti nṣe ẹrú labẹ ìrú [“àjàgà,” NW] maa ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a ma baa sọrọ odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ rẹ̀. Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ, ki wọn maṣe gan wọn nitori arakunrin ni wọn; ṣugbọn ki wọn tubọ maa sìn wọn.” Peteru si wipe: “Ẹyin ọmọ ọdọ, ẹ maa tẹriba fun awọn oluwa yin pẹlu ibẹru gbogbo; kii ṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onroro pẹlu.”—1 Timoti 6:1, 2; 1 Peteru 2:18; Efesu 6:5; Kolose 3:22, 23.
7. (a) Bawo ni imọran Bibeli fun “awọn ẹru” lati fi ọla hàn fun “awọn oluwa” ṣe ṣeefisilo lọna titọ lonii? (b) Kinni awọn Kristian ẹni ti a gbasiṣẹ ti wọn ni Kristian agbanisiṣẹ nilati ṣọra lati kiyesi?
7 Dajudaju nitootọ, isinru ko tankalẹ lonii. Ṣugbọn awọn ilana ti nṣakoso awọn Kristian ninu ipo ibatan ẹru si olówó ni o ṣeefisilo fun ipo ibatan ẹni ti a gbasiṣẹ si agbanisiṣẹ. Nipa bayii, awọn ẹni ti a gbasiṣẹ ti wọn jẹ Kristian ní ẹru iṣẹ fifi ọla han ani fun awọn agbanisiṣẹ ti wọn ṣoro lati tẹlọrun paapaa. Ki si ni bi o ba ṣẹlẹ pe agbanisiṣẹ naa pẹlu jẹ onigbagbọ ẹlẹgbẹ kan? Dipo fifojusọna fun ikanisi tabi iyanni ṣaaju lọna akanṣe nitori ipo ibatan yẹn, ẹni ti a gbasiṣẹ naa nilati ṣiṣẹsin Kristian agbanisiṣẹ rẹ̀ ani pẹlu imuratan pupọ sii paapaa, lai ko o nífà ni ọna eyikeyii.
Ọla ninu Agbo Idile
8, 9. (a) Awọn wo ni a beere lọwọ awọn ọmọ lati bọla fun? (b) Eeṣe ti awọn ọmọ fi nilati fi ọla yii hàn, bawo sì ni wọn ṣe lè fihan?
8 Agbegbe kẹta ti ọla ti yẹ ni laaarin agbo idile. Fun apẹẹrẹ, awọn ọmọ wa labẹ aigbọdọmaṣe lati bọla fun awọn òbí wọn. Eyi kii ṣe kiki ohun ti Òfin ti a fifun Mose beere fun nikan ṣugbọn o tun jẹ aigbọdọmaṣe fun awọn Kristian. Apọsteli Pọọlu kọwe pe: “Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ ti awọn òbí yin ninu Oluwa: nitori pe eyi ni o tọ. Bọwọ fun baba ati iya rẹ.”—Efesu 6:1, 2; Ẹksodu 20:12.
9 Eeṣe ti awọn ọmọ fi nilati bọwọ fun awọn òbí wọn? Wọn nilati bọwọ fun wọn nitori aṣẹ ti Ọlọrun fifun awọn òbí wọn ati nitori ohun ti awọn òbí ti ṣe pẹlu, ni mimu ki a bí wọn ki a sì bọ́ wọn, ti wọn sì ṣetọju wọn dagba lati igba ọmọde titilọ. Bawo ni awọn ọmọ ṣe nilati bọla fun awọn òbí wọn? Wọn nilati ṣe eyi paapaa nipa jijẹ onigbọran ki wọn sì tẹriba fun wọn. (Owe 23:22, 25, 26; Kolose 3:20) Fifunni ni iru ọla bẹẹ le beere pe ki awọn ọmọ ti wọn ti dagba ṣe afikun itilẹhin, nipa ti ara ati tẹmi, fun awọn òbí tabi òbí àgbà wọn ọlọjọlori. Eyi ni o yẹ ki a mu wà deedee lọna ọgbọ́n pẹlu awọn ẹrù iṣẹ miiran, iru bii bibojuto ọmọ ẹni funra ẹni ati ṣiṣajọpin ni kikun ninu ibakẹgbẹpọ Kristian ati iṣẹ-ojiṣẹ pápá.—Efesu 5:15-17; 1 Timoti 5:8; 1 Johanu 3:17.
10. Si tani awọn aya wa labẹ aigbọdọmaṣe lati fi ọla hàn fun, ni awọn ọna wo sì ni wọn lè gba ṣe eyi?
10 Sibẹ kii ṣe awọn ọmọ nikan laaarin idile ni wọn ní aigbọdọmaṣe lati fi ọla fun awọn ẹlomiran. Awọn aya nilati fi ọla fun awọn ọkọ wọn. Aposteli Pọọlu tun wipe “aya nilati ni ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun ọkọ rẹ̀.” (Efesu 5:33, NW; 1 Peteru 3:1, 2) Fifi “ọ̀wọ̀ jijinlẹ” han fun awọn ọkọ dajudaju ni fifun wọn ni ọla ninu. Sera bọla fun ọkọ rẹ, Abrahamu, nigba ti o tọka si i gẹgẹbi “oluwa.” (1 Peteru 3:6) Nitori naa, ẹyin aya, ẹ ṣafarawe Sera. Ẹ fi ọla fun awọn ọkọ yin nipa titẹwọgba awọn ipinnu wọn ati ṣiṣẹ lati jẹ ki wọn ni aṣeyọrisirere. Nipa ṣiṣe gbogbo ohun ti ẹ le ṣe lati ba awọn ọkọ yin gbe ẹru inira wọn, dipo fifikun iwọnyi, ẹyin nfi ọla fun wọn.
11. Nipa fifi ọla hàn, aigbọdọmaṣe wo ni awọn ọkọ ni, eesitiṣe?
11 Kinni niti awọn ọkọ? A fun wọn ni itọni ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pe: “Ẹyin ọkọ, ẹ maa fi òye ba awọn aya yin gbe, ẹ maa fi ọla fun aya, bi ohun eelo ti ko lagbara, ati pẹlu bi ajumọ jogun oore ọfẹ iye; ki adura yin ki o ma baa ni idena.” (1 Peteru 3:7) Iyẹn ni dajudaju nilati mu ki olukuluku ọkọ ronu. Nṣe ni o dabii pe aya kan ni ami akiyesi naa “Aṣeyebiye. Ẹlẹgẹ. Ṣe é jẹ́jẹ́! Fi ọla fun un!” Nitori naa ẹ jẹ ki awọn ọkọ ranti pe ayafi bi wọn ba fi ọla fun awọn aya wọn nipa fifi ikanisi ti o yẹ hàn si wọn, wọn yoo ba ipo ibatan wọn pẹlu Jehofa Ọlọrun jẹ, nitori awọn adura wọn yoo ni idena. Nitootọ, o lere tọtuntosi fun awọn mẹmba idile lati fi ọla fun araawọn ẹnikinni ẹnikeji.
Ninu Ijọ
12. (a) Tani o ni ẹru iṣẹ lati fi ọla han ninu ijọ? (b) Bawo ni Jesu ṣe fihan pe o tọna lati gba ọla?
12 Ẹru iṣẹ ti olukuluku ni lati fi ọla han laaarin ijọ Kristian tun wà. A gba wa nimọran pe: “Niti ọla, ẹ maa fi ẹnikeji yin ṣaaju.” (Roomu 12:10) Jesu fihan ninu ọkan lara awọn àkàwé rẹ̀ pe o tọna lati tẹwọgba ọla. Oun sọ pe nigba ti a ba kesi wa si ase, awa nilati mu ibi rirẹlẹ julọ, nitori nigba naa ni olugbalejo wa yoo sọ fun wa lati mu ijokoo nibi giga, awa yoo si ní ọla niwaju gbogbo awọn alejo ẹlẹgbẹ wa. (Luuku 14:10) Nisinsinyi, niwọn bi gbogbo wa ti mọriri jijẹ ẹni ti a fi ọla fun, ko ha yẹ ki a ní ẹmi ìfọ̀ràn rora ẹni ki a si bọla fun ẹnikinni ẹnikeji? Bawo ni awa ṣe le ṣe eyi?
13. Kinni awọn ọna diẹ ti awa le gba fi ọla hàn fun awọn ẹlomiran ninu ijọ?
13 Awọn ọrọ imọriri fun iṣẹ ti a ṣe daradara baradọgba pẹlu fifunni ni ọla. Nitori naa awa le bọla fun araawa nipa fifunni ni ọrọ ìwúrí, boya fun asọye kan tabi ọrọ ilohunsi ti ẹnikan funni ninu ijọ. Ni afikun, awa le bọla fun araawa nipa fifi irẹlẹ ọkan di araawa ni amure si awọn Kristian arakunrin ati arabinrin wa, nipa biba wọn lo pẹlu ọ̀wọ̀ jijinlẹ. (1 Peteru 5:5) Nipa bayii awa fihan pe a ka wọn si iṣura gẹgẹbi alájùmọ̀jẹ́ iranṣẹ Jehofa Ọlọrun ti wọn yẹ fun ọla.
14. (a) Bawo ni awọn arakunrin ninu ijọ ṣe le bọla ti o yẹ fun awọn arabinrin? (b) Kinni o fihan pe fifunni ni awọn ẹ̀bùn jẹ ọna kan lati bọla funni?
14 Apọsteli Pọọlu gba Timoti ọ̀dọ́ nimọran lati ba awọn Kristian arabinrin àgbà lò gẹgẹ bi iya ati awọn ọ̀dọ́ gẹgẹ bi arabinrin nipa ti ara, “ninu ìwà àìlábàwọ́n.” Bẹẹni, nigba ti awọn arakunrin ba kun fun iṣọra lati maṣe ṣi ominira lò lọdọ awọn Kristian arabinrin, iru bii ṣiṣe timọtimọ lọna àṣerégèé, wọn nbu ọla fun wọn. Pọọlu nbaa lọ lati kọwe pe: “Bọwọ fun awọn opó ti nṣe opó nitootọ.” Ọna kan ti a lè gba bọla fun opó kan ti o ṣe alaini ni nipa itilẹhin ohun ti ara. Ṣugbọn lati yẹ fun eyi, a ti gbọdọ “jẹrii rẹ fun iṣẹ rere.” (1 Timoti 5:2-10) Ni isopọ pẹlu awọn ẹbun ohun ti ara, Luuku kọwe nipa awọn eniyan ni erekuṣu Malta: “Wọn si bọla fun wa pẹlu ọpọ ẹbun ati, nigba ti a ṣikọ, wọn di ẹrù awọn nnkan fun aini wa. (Iṣe 28:10, NW) Nipa bayii ọla ni a le fihan fun ẹlomiran nipa pipese awọn ẹbun ohun ti ara.
15. (a) Siha awọn wo ni awa ní akanṣe iṣẹ aigbọdọmaṣe lati fi ọla hàn? (b) Kinni ọna kan ti awa lè gbà fi ọla han fun awọn wọnni ti wọn mu ipo iwaju?
15 Ni biba lẹta rẹ si Timoti lọ, Pọọlu kọwe pe: “Awọn alagba ti o ṣe akoso daradara ni ki a ka yẹ̀ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe làálàá ní ọ̀rọ̀ ati ni kikọni.” (1 Timoti 5:17) Ni awọn ọna wo ni awa le gba bọla fun awọn alagba, tabi alaboojuto? Pọọlu wipe: “Ẹ maa ṣe afarawe mi, gẹgẹ bi emi ti nṣe afarawe Kristi.” (1 Kọrinti 11:1) Nigba ti a ba kọbiara si awọn ọ̀rọ̀ Pọọlu lati di alafarawe rẹ̀, awa bọla fun un. Eyi yoo ṣee fisilo fun awọn wọnni ti wọn mu ipo iwaju laaarin wa lonii. De àyè ṣiṣafarawe wọn, nipa titẹle apẹẹrẹ wọn, awa yoo maa bọla fun wọn.
16. Kinni awọn ọna siwaju sii ti a le gba fi ọla hàn fun awọn wọnni ti wọn mu ipo iwaju?
16 Ọna miiran ti a ngba fi ọla han fun awọn alaboojuto ni nipa kikọbiara si igbaniniyanju naa: “Ẹ maa ṣegbọran si awọn wọnni ti wọn nmu ipo iwaju laaarin yin ki ẹ si tẹriba, nitori wọn nṣọ ẹ̀ṣọ́ lori ọkan yin gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn yoo ṣe iṣiro.” (Heberu 13:17, NW) Ni ọna kan naa ti awọn ọmọ ngba bọla fun awọn òbì wọn nipa jijẹ onigbọran si wọn, bẹẹ ni awa nbọla fun awọn wọnni ti wọn mu ipo iwaju laaarin wa nipa jijẹ onigbọran ati atẹriba fun wọn. Ati, gẹgẹ bi a ti bọla fun Pọọlu ati awọn alabaakẹgbẹ rẹ̀ pẹlu awọn ẹbun ohun ti ara lati ọwọ́ awọn oninurere olugbe Malta, ọpọlọpọ awọn aṣoju arinrin-ajo ti Society ni a ti bọla fun bakan naa ni ọna yii lọpọlọpọ ìgbà. Ṣugbọn, nitootọ wọn ko nilati tọrọ iru awọn ẹbun bẹẹ tabi ki wọn yàn an leti awọn ẹlomiran pe wọn yoo mọriri rẹ̀ tabi pe wọn nilo wọn.
17. Aigbọdọmaṣe wo ni awọn wọnni ti wọn ni anfaani iṣẹ abojuto ní niti fifi ọla hàn?
17 Ni idakeji ẹ̀wẹ̀, gbogbo awọn wọnni ti wọn wa ninu ipo abojuto ninu eto ajọ ti iṣakoso Ọlọrun—boya ninu ijọ adugbo, ni ayika tabi agbegbe gẹgẹ bi alaboojuto arinrin ajo, ni ọkan lara awọn ẹka Watch Tower Society tabi laaarin agbo idile—ní aigbọdọmaṣe naa lati bọla fun awọn wọnni ti wọn wa ni ikawọ wọn. Eyi beere pe ki wọn ni ẹmi ifọran rora ẹni ati imọlara fun ẹnikeji. Wọn nilati jẹ aṣeesunmọ ni gbogbo igba, ki wọn jẹ ọlọkan tutupẹlẹ ati onirẹlẹ ni ero-inu ati ọkan-aya, gẹgẹ bi Jesu ti sọ pe oun jẹ.—Matiu 11:29, 30.
Ṣiṣẹ Lori Bibọla Fun Ẹnikinni Ẹnikeji
18. (a) Kinni o lè di wa lọwọ kuro ninu fifi ọla hàn fun awọn wọnni ti wọn yẹ fun un? (b) Eeṣe ti ko fi si idalare kankan fun ipo ero-inu odi ti o si lekoko?
18 Gbogbo wa nilo lati ṣiṣẹ kara ni bibọla fun araawa, nitori idilọwọ alagbara wa si ṣiṣe bẹẹ wa. Idilọwọ yẹn, tabi ohun idina, ni ọkan-aya alaipe wa. Bibeli wipe, “Ìrò ọkan eniyan ibi ni lati ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹnẹsisi 8:21) Ọkan lara awọn itẹsi ọkan ẹda eniyan ti o le ṣedilọwọ fun fifi ọla ti o yẹ hàn fun awọn ẹlomiran ni nini ipò ero-inu odi, ti o lekoko. Gbogbo wa jẹ eniyan alaipe, alailera, ti o nilo aanu ati inurere ailẹtọọsi Jehofa. Ni imọriri eyi, ẹ jẹ ki a ṣọra ki a ma maa rinkinkin mọ́ ailera awọn arakunrin wa tabi ki a maa ka awọn isunniṣe agbebeere dide sọrun awọn arakunrin wa.
19. Kinni yoo ran wa lọwọ lati gbejako ẹmi ironu odi eyikeyii?
19 Oògùn ẹ̀rọ̀ fun iru itẹsi ero òdì eyikeyii ni ifẹ ati ikora-ẹni-ni-ijanu. Awa nilati ni ẹmi ironu abanikẹdun, aduroṣinṣin, ati ọlọkan rere nipa awọn arakunrin wa, ni ṣiṣakiyesi awọn animọ rere wọn. Bi ohun kan ba wà ti awa ko loye, ẹ jẹ ki a muratan nigbagbogbo lati gbagbọ pe ọrun awọn arakunrin wa mọ bi ko ba si ẹri fun iwa aitọ ki a si kọbiarasi imọran Peteru: “Ju gbogbo rẹ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbona laaarin araayin: nitori ifẹ ni nbo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọlẹ.” (1 Peteru 4:8) Awa gbọdọ ni iru ifẹ bẹẹ bi awa yoo ba bọla ti o yẹ fun awọn arakunrin wa.
20, 21. (a) Kinni itẹsi miiran ti o ṣeeṣe ki o ṣedilọwọ fun fifi ọla han fun araawa? (b) Kinni yoo ran wa lọwọ lati gbejako itẹsi yii?
20 Iwa animọ miiran ti o ṣeeṣe ki o ṣedilọwọ fun fifi ọla ti o yẹ han fun awọn ẹlomiran ni itẹsi naa lati jẹ atetebinu, tabi ẹni ti nyara fi imọlara han laiyẹ. Yiyara fi imọlara han ni aye tirẹ. Awọn oniṣẹ ọnà nilati yara fi imọlara han si awọn ìró ati àwọ̀ gẹgẹ bi apakan iṣẹ wọn. Ṣugbọn jijẹ ẹni ti nyara fi imọlara han laiyẹ, tabi atetebinu, ninu awọn ibaṣepọ wa pẹlu awọn ẹlomiran jẹ iru imọtara-ẹni-nikan ti o le jà wa lole alaafia wa ki o si di wa lọwọ lati maa fi ọla fun awọn ẹlomiran.
21 Ohun ti nfunni ni amọran rere ni isopọ pẹlu eyi ni awọn ọrọ ti o wà ni Oniwaasu 7:9: “Maṣe yara ni ọkan rẹ lati binu, nitori pe ibinu sinmi ni àyà aṣiwere.” Nitori naa o fi aini ọgbọ́n, lakaaye rere, ati aini ifẹ han, lati jẹ ẹni ti nyara fi imọlara han laiyẹ tabi lati jẹ ẹni ti a tètè ńṣẹ̀. A gbọdọ ṣọra ki awọn itẹsi ọkan wa ti o kun fun ẹ̀ṣẹ̀, iru bii jijẹ onironu odi, alekoko ju, tabi ẹni ti nyara fi imọlara han laiyẹ, di wa lọwọ ninu bibọla fun gbogbo awọn wọnni ti ọlá yẹ.
22. Bawo ni a ṣe lè ṣakopọ iṣẹ aigbọdọmaṣe wa lati fi ọla hàn?
22 Nitootọ, awa ni ọpọlọpọ idi fun fifi ọla han fun awọn ẹlomiran. Ati, gẹgẹ bi awa ti rii, ọpọlọpọ ọna ni o wà, ti awa le gbà fi iru ọla bẹẹ hàn. Ni igba gbogbo awa gbọdọ ṣọra ki ẹmi ironu òdì tabi onimọtara-ẹni-nikan eyikeyii ma baa ṣedilọwọ fun fifi ọla han niha ọ̀dọ̀ wa. Ni pataki, awa nilati ṣọra lati fi ọla hàn fun awọn wọnni ninu agbo idile wa, awọn ọkọ ati aya si araawọn ati awọn ọmọ si awọn òbí wọn. Ati ninu ijọ, awa wa labẹ aigbọdọmaṣe naa lati fi ọla hàn fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ati, ni pataki, fun awọn wọnni ti wọn nṣiṣẹ kara laaarin wa ninu ipo abojuto. Ni gbogbo awọn agbegbe wọnyi, o jẹ fun ere wa lati bọla titọna fun awọn wọnni ti a mẹnukan loke, niwọnbi, gẹgẹbi Jesu ti wipe: “Ayọ pupọ nbẹ ninu fifunni ju eyi ti o wà ninu rírígbà lọ.”—Iṣe 20:35, NW.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Eeṣe ati bawo ni awa ṣe nilati bọla fun awọn alaṣẹ ijọba?
◻ Imọran Bibeli wo ni a le fisilo fun ipo ibatan ẹni ti a gbasiṣẹ ati agbanisiṣẹ?
◻ Bawo ni a ṣe nilati fi ọla hàn laaarin agbo idile?
◻ Ọla akanṣe wo ni a le fihan ninu ijọ, eesitiṣe?
◻ Bawo ni a ṣe lè bori awọn ailera eniyan ti kikuna lati bọla fun awọn ẹlomiran?