Àwa Kristẹni Ń gbé Ògo Jèhófà Yọ
“Aláyọ̀ ni ojú yín nítorí pé wọ́n rí, àti etí yín nítorí pé wọ́n gbọ́.”—MÁTÍÙ 13:16.
1. Ìbéèrè wo la lè béèrè nítorí bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe sá sẹ́yìn fún Mósè níwájú Òkè Sínáì?
DÁJÚDÁJÚ, ó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pé jọ síbi Òkè Sínáì sún mọ́ Jèhófà. Òun ló sáà fi ọwọ́ agbára ńlá gbà wọ́n sílẹ̀ lóko ẹrú ní Íjíbítì. Ó tọ́jú wọn, ó pèsè oúnjẹ àti omi fún wọn ní aginjù. Ó tún mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ámálékì tó gbéjà kò wọ́n. (Ẹ́kísódù 14:26-31; 16:2–17:13) Nígbà tí ààrá ń sán tí mànàmáná ń kọ yẹ̀rì, ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì débi pé ara wọn ń gbọ̀n níbi tí wọ́n pàgọ́ sí níwájú Òkè Sínáì ní aginjù. Lẹ́yìn èyí, wọ́n rí i pé bí Mósè ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí òkè náà, ìtànṣán ògo Jèhófà ń yọ lójú rẹ̀. Dípò kí orí wọ́n wú, kí wọ́n fìyẹn yin Ọlọ́run lógo, ńṣe ni wọ́n sá sẹ́yìn. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n . . . fòyà láti sún mọ́ [Mósè].” (Ẹ́kísódù 19:10-19; 34:30) Kí nìdí tí ẹ̀rù ìtànṣán ògo Jèhófà, ẹni tó ti ṣe ọ̀pọ̀ ohun ribiribi fún wọn, fi wá ń bà wọ́n?
2. Kí ló lè jẹ́ ìdí tí ẹ̀rù fi ń ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí i tí ìtànṣán ògo Ọlọ́run ń yọ lójú Mósè?
2 Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìgbà náà jẹ́ ara ohun tó mú kẹ́rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà bí wọ́n ṣe lọ ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà, Jèhófà sì bá wọn wí. (Ẹ́kísódù 32:4, 35) Ǹjẹ́ wọ́n mọyì ìbáwí yẹn kí wọ́n sì fi kọ́gbọ́n? Rárá o. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kò fi kọ́gbọ́n. Nígbà tí Mósè darúgbó, ó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí ère ọmọ màlúù oníwúrà tí wọ́n ṣe yẹn àtàwọn ìgbà míì tí wọ́n ṣàìgbọràn. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹ kò sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fetí sí ohùn rẹ̀. Ẹ ti fi ara yín hàn ní ọlọ̀tẹ̀ nínú ìwà híhù sí Jèhófà, láti ọjọ́ tí mo ti mọ̀ yín.”—Diutarónómì 9:15-24.
3. Báwo ni Mósè ṣe ń lo ìbòjú rẹ̀?
3 Wo ohun tí Mósè ṣe nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bẹ̀rù. Ìtàn náà sọ pé: “Nígbà tí Mósè bá parí bíbá wọn sọ̀rọ̀, òun a fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Mósè bá wọlé [lọ sínú àgọ́ ibùjọsìn] síwájú Jèhófà láti bá a sọ̀rọ̀, òun a mú ìbòjú kúrò títí yóò fi jáde kúrò. Òun a sì jáde lọ, a sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ohun tí a pa láṣẹ fún un. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí ojú Mósè, pé awọ ojú Mósè mú ìtànṣán jáde; Mósè sì fi ìbòjú náà bo ojú rẹ̀ padà títí ó fi wọlé lọ bá [Jèhófà] sọ̀rọ̀.” (Ẹ́kísódù 34:33-35) Kí nìdí tí Mósè fi ń fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ nígbà míì? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí lè mú ká tún àjọṣe tiwa pẹ̀lú Jèhófà gbé yẹ̀ wò.
Wọ́n Sọ Àwọn Àǹfààní Tí Wọ́n Ní Nù
4. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ nípa fífi tí Mósè ń fi ìbòjú bo ojú rẹ̀?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló fà á tí Mósè fi ń fi ìbòjú bo ojú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè fi tọkàntara tẹjú mọ́ ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀ . . . A mú agbára èrò orí wọn pòkúdu.” (2 Kọ́ríńtì 3:7, 14) Áà, ó mà ṣe o! Àyànfẹ́ Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fẹ́ kí wọ́n sún mọ́ òun. (Ẹ́kísódù 19:4-6) Wọ́n wá ń bẹ̀rù láti fi tọkàntara tẹjú mọ́ ìtànṣán ògo rẹ̀. Èyí fi hàn pé dípò kí wọ́n máa sin Jèhófà tọkàntọkàn àti tìfẹ́tìfẹ́, wọ́n ti ń kẹ̀yìn sí i.
5, 6. (a) Báwo làwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní ṣe dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Mósè? (b) Ọ̀nà wo làwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ Jésù gbà yàtọ̀ sáwọn tí kò fetí sí i?
5 Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa di Kristẹni, májẹ̀mú tuntun tí Jésù Kristi, Mósè Ńlá, ṣe alárinà rẹ̀ ti rọ́pò májẹ̀mú òfin. Jésù sì gbé ògo Jèhófà yọ lọ́nà pípé nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe. Ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa Jésù lẹ́yìn tó ti lọ sọ́run ni pé: “Òun ni àgbéyọ ògo [Ọlọ́run] àti àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà rẹ̀ gan-an.” (Hébérù 1:3) Àǹfààní táwọn Júù ní mà ga lọ́lá o! Wọn ì bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun látẹnu Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gan-an! Ó dunni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí Jésù wàásù fún ni kò fetí sílẹ̀. Jésù sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ ṣẹ sí wọn lára, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé: “Ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí láé, kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́, kí òye rẹ̀ sì yé wọn nínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má sì yí padà, kí n má sì mú wọn lára dá.”—Mátíù 13:15; Aísáyà 6:9, 10.
6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ṣe bíi tàwọn Júù yòókù rárá. Jésù sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni ojú yín nítorí pé wọ́n rí, àti etí yín nítorí pé wọ́n gbọ́.” (Mátíù 13:16) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fẹ́ láti mọ Jèhófà àti láti sìn ín. Inú wọn sì máa ń dùn láti ṣe ohun tó fẹ́ gẹ́lẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì. Ìdí nìyí táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi ń fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ ti májẹ̀mú tuntun gbé ògo Jèhófà yọ, táwọn àgùntàn mìíràn náà sì ń gbé e yọ bíi tiwọn pẹ̀lú.—2 Kọ́ríńtì 3:6, 18.
Ìdí Tí Ìhìn Rere Fi Wà Lábẹ́ Ìbòjú
7. Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kì í fẹ́ gbọ́ ìhìn rere?
7 A ti wá rí i pé nígbà ayé Jésù àti ti Mósè, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kọ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní. Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tá à ń wàásù. Ìyẹn ò sì yà wá lẹ́nu. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wàyí o, bí ìhìn rere tí àwa ń polongo bá wà lábẹ́ ìbòjú, ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn tí ń ṣègbé, láàárín àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.” (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Láfikún sí ipá tí Sátánì ń sà káwọn èèyàn má bàa gbọ́ ìhìn rere, ọ̀pọ̀ èèyàn ló tún ń fúnra wọn fi ìbòjú bo ara wọn lójú kí wọ́n má bàa ríran nípa tẹ̀mí.
8. Ọ̀nà wo ní ọ̀pọ̀ èèyàn gbà fọ́jú nítorí àìmọ̀kan, kí la sì lè ṣe kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ má ṣẹlẹ̀ sí wa?
8 Ojú inú ọ̀pọ̀ èèyàn ti fọ́ nítorí àìmọ̀kan wọn nípa Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè “wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan tí ń bẹ nínú wọn.” (Éfésù 4:18) Kí Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ amòfin tó di Kristẹni, àìmọ̀kan fọ́ ọ lójú débi pé ó ń ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 15:9) Síbẹ̀síbẹ̀ Jèhófà jẹ́ kó mọ òtítọ́. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ìdí tí a fi fi àánú hàn sí mi ni pé nípasẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àkọ́kọ́, kí Kristi Jésù lè fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan lára àwọn tí yóò gbé ìgbàgbọ́ wọn lé e fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (1 Tímótì 1:16) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ta ko òtítọ́ Ọlọ́run nígbà kan rí ti dẹni tó ń sin Ọlọ́run báyìí, gẹ́gẹ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù. Ìdí nìyẹn tó fi dára pé ká máa wàásù nìṣó àní fáwọn tó ń ta kò wá pàápàá. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé tá a sì ń jẹ́ kí òye rẹ̀ yé wa, a ò ní fi àìmọ̀kan hùwà tó máa jẹ́ kí Jèhófà bínú sí wa.
9, 10. (a) Báwo làwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ṣe fi hàn pé àwọn ò fẹ́ gba ẹ̀kọ́ àti pé àwọn ò ṣe tán láti yí èrò ọkàn wọn padà? (b) Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lóde òní? Ṣàlàyé.
9 Ohun tí kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ríran nípa tẹ̀mí ni pé wọn ò fẹ́ gba ẹ̀kọ́, wọn ò sì ṣe tán láti yí èrò ọkàn wọn padà. Ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù ò fi tẹ́wọ́ gba Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni ni pé wọ́n wonkoko mọ́ Òfin Mósè. Kì í ṣe gbogbo wọn ló ṣe bẹ́ẹ̀ ṣá o. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, “ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà . . . bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.” (Ìṣe 6:7) Ṣùgbọ́n ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ni pé: “Títí di òní, nígbàkigbà tí wọ́n bá ń ka òfin Mósè, ìbòjú a bo ọkàn-àyà wọn.” (2 Kọ́ríńtì 3:15) Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù mọ ohun tí Jésù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn Júù nígbà kan rí, ìyẹn ni pé: “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ̀nyí gan-an sì ni ó ń jẹ́rìí nípa mi.” (Jòhánù 5:39) Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń wá fínnífínní ni ì bá mú kí wọ́n róye pé Jésù ni Mèsáyà. Ṣùgbọ́n àwọn Júù yìí ní èrò tí wọ́n ti gbìn sọ́kàn, tó fi jẹ́ pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọmọ Ọlọ́run ṣe pàápàá kò yí wọn lọ́kàn padà.
10 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì òde òní náà nìyẹn. Wọn ò yàtọ̀ sí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní nítorí pé “wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Òmíràn lára wọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì o, àmọ́ wọn ò fẹ́ gba ohun tó wí gbọ́. Wọn ò gbà pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni Jèhófà ń lò láti kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. (Mátíù 24:45) Àmọ́, ní tiwa, a mọ̀ pé Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, a sì mọ̀ pé òye òtítọ́ ń yé àwọn èèyàn Ọlọ́run síwájú àti síwájú sí i. (Òwe 4:18) Nítorí pé a jẹ́ kí Jèhófà kọ́ wa, a mọ ohun tó ní ká ṣe àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe.
11. Báwo ni òtítọ́ ṣe fara sin fáwọn kan nítorí pé ohun tó bá ìfẹ́ ọkàn wọn mu nìkan ni wọ́n gbà gbọ́?
11 Ohun tó fọ́ àwọn mìíràn lójú ni pé nǹkan tó bá bá ìfẹ́ ọkàn wọn mú nìkan ni wọ́n máa ń gbà gbọ́. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan yóò máa fi àwọn èèyàn Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa wíwà níhìn-ín Jésù ṣẹ̀sín. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn,” ìyẹn ni pé Ọlọ́run fi ìkún omi pa ayé ìgbà Nóà rẹ́. (2 Pétérù 3:3-6) Lónìí bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn máa ń gbà láìjanpata pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, onínú-rere onífẹ̀ẹ́ àti olùdáríjì; àmọ́ wọn ò gbà, wọn ò sì fẹ́ mọ̀ pé kì í dáni sí láìjẹni-níyà. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Ńṣe làwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ máa ń sa gbogbo ipá wọn láti lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an.
12. Báwo ni òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe fọ́ àwọn èèyàn lójú?
12 Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ló fọ́ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lójú. Jésù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.” (Mátíù 15:6) Àwọn Júù tó dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì fi ìtara mú ìjọsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò, àmọ́ àwọn àlùfáà wọn di agbéraga àti olódodo àṣelékè. Àwọn àjọyọ̀ ìsìn wọn wá di èyí tí wọ́n ń fara ṣe láìfọkàn ṣe é, wọn ò sì fi bọlá fún Ọlọ́run rárá. (Málákì 1:6-8) Nígbà tó fi máa dìgbà ayé Jésù, àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ti fi àìmọye òfin àtọwọ́dọ́wọ́ kún Òfin Mósè. Jésù jẹ́ kó hàn pé alágàbàgebè ni wọ́n, nítorí pé ìlànà òdodo tí Ọlọ́run gbé Òfin Mósè kà ti pa rẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn. (Mátíù 23:23, 24) Àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a ò jẹ́ kí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ nínú ẹ̀sìn mú wa kúrò nínú ìjọsìn mímọ́.
“Ẹni Tí Ń Rí Ẹni Tí A Kò Lè Rí”
13. Ọ̀nà méjì wo ni Mósè gbà rí díẹ̀ lára ògo Ọlọ́run?
13 Mósè sọ fún Ọlọ́run lórí òkè pé òun fẹ́ rí ògo rẹ̀, ó sì rí fìrífìrí ìmọ́lẹ̀ ògo Jèhófà lẹ́yìn tí ògo yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lọ tán. Nígbà tí Mósè bá lọ sínú àgọ́ ìjọsìn, kì í fi ìbòjú bo ojú. Ó jẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ jinlẹ̀ àti ẹni tó ń fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lóòótọ́ ó rí díẹ̀ lára ògo Jèhófà lójú ìran, àmọ́ ó ti kọ́kọ́ fi ojú ìgbàgbọ́ rí Ọlọ́run láwọn ọ̀nà kan tẹ́lẹ̀. Bíbélì sọ pé Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27; Ẹ́kísódù 34:5-7) Kì í ṣe yíyọ tí ìmọ́lẹ̀ ògo Ọlọ́run ń yọ lójú rẹ̀ fúngbà díẹ̀ nìkan ló fi gbógo Ọlọ́run yọ, ó tún fi àwọn nǹkan tó ṣe káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì máa sìn ín gbé e yọ pẹ̀lú.
14. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà rí ògo Ọlọ́run, kí ló sì ń dùn mọ́ ọn láti ṣe?
14 Ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún ni Jésù ti ń rí ògo Ọlọ́run ní tààràtà ní ọ̀run, àní ṣáájú kí ọ̀run òun ayé tó wà. (Òwe 8:22, 30) Láàárín àsìkò yìí, òun àti Ọlọ́run sún mọ́ra gan-an, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn gidigidi. Ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó jinlẹ̀ jù lọ ni Jèhófà Ọlọ́run fi ń ṣìkẹ́ àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá yìí. Jésù náà sì fẹ́ràn Ọlọ́run tó dá a yìí jinlẹ̀jinlẹ̀. (Jòhánù 14:31; 17:24) Ojúlówó ìfẹ́ Bàbá àti Ọmọ ló ń bẹ láàárín wọn. Bó ṣe dùn mọ́ Mósè náà ló ṣe dùn mọ́ Jésù láti máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ni gbé ògo Jèhófà yọ.
15. Ọ̀nà wo làwa Kristẹni gbà ń tẹjú mọ́ ògo Ọlọ́run?
15 Bó ṣe wu Mósè àti Jésù láti tẹjú mọ́ ògo Jèhófà náà ló ṣe ń wu àwa Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run lóde òní. A ò kọ ìhìn rere ológo náà rárá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n bá yíjú sí Jèhófà [láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀], ìbòjú náà a ká kúrò.” (2 Kọ́ríńtì 3:16) Ìdí tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ni pé a fẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ògo tó ń hàn lójú Jésù Kristi Ọmọ Jèhófà, ẹni tó fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba máa ń wù wá gan-an, a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Bí Ọlọ́run ṣe gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ lé Mósè àti Jésù lọ́wọ́ náà ló ṣe gbé e lé àwa náà lọ́wọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà sì ni pé ká máa kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run ológo tá à ń sìn.
16. Àǹfààní wo là ń rí nítorí mímọ̀ tá a mọ òtítọ́?
16 Jésù gbàdúrà pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, . . . nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Mátíù 11:25) Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn tí kì í tan ara wọn jẹ ni Jèhófà máa ń mú kó lóye àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe. (1 Kọ́ríńtì 1:26-28) Abẹ́ ààbò Ọlọ́run la wà báyìí, ó sì ń kọ́ wa lọ́nà tá a ó gbà ṣe ara wa níre, ìyẹn ni pé ó ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ. Nítorí náà, á dára ká sa gbogbo ipá wa láti sún mọ́ Jèhófà, ká sì mọyì gbogbo ohun tó ń pèsè fún wa ká lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa.
17. Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà ní kíkún?
17 Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó sọ pé: “A ń fi ojú tí a kò fi ìbòjú bò ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí, gbogbo wa ni a sì ń pa lára dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo.” (2 Kọ́ríńtì 3:18) Ì báà jẹ́ ọ̀run là ń retí pé à ń lọ tàbí ayé là ń retí pé a ó jogún, bá a bá ṣe mọ Jèhófà tó, ìyẹn bá a ṣe mọ ìwà rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé rẹ̀ tó, la ó ṣe dà bíi tirẹ̀ tó. Bí a bá ronú jinlẹ̀ nípa ìgbé ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi àtàwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ni tá a sì mọrírì wọn, a óò túbọ̀ máa gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ ní kíkún. Ẹ ò rí i pé ìdùnnú ńláǹlà ló jẹ́ láti mọ̀ pé à ń bọlá fún Ọlọ́run wa tá a fẹ́ máa gbé ògo rẹ̀ yọ!
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń bẹ̀rù láti wo ìtànṣán ògo Ọlọ́run tó ń yọ lójú Mósè?
• Àwọn ọ̀nà wo ni ìhìn rere gbà wà “lábẹ́ ìbòjú” ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní?
• Àwọn ọ̀nà wo la gbà ń gbógo Ọlọ́run yọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè tẹjú mọ́ ojú Mósè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ta ko òtítọ́ Ọlọ́run nígbà kan rí ti dẹni tó ń sin Ọlọ́run báyìí, gẹ́gẹ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Inú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń dùn láti gbé ògo Ọlọ́run yọ