ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36
Ìròyìn Ayọ̀ Ni Amágẹ́dọ́nì!
“Wọ́n sì kó wọn jọ sí . . . Amágẹ́dọ́nì.”—ÌFI. 16:16.
ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. (a) Kí nìdí tí Amágẹ́dọ́nì fi jẹ́ ìròyìn ayọ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ǸJẸ́ o ti gbọ́ ọ rí káwọn èèyàn pe “Amágẹ́dọ́nì” ní ogun runlérùnnà tàbí ìjábá ńlá kan tó máa pa ayé run? Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ ni Bíbélì pe Amágẹ́dọ́nì, kódà ìròyìn tó ń múnú ẹni dùn ni! (Ìfi. 1:3) Ogun Amágẹ́dọ́nì kò ní pa ayé run, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa tún ayé ṣe! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
2 Bíbélì fi hàn pé ogun Amágẹ́dọ́nì máa fòpin sí ìṣàkóso èèyàn, á sì tipa bẹ́ẹ̀ dá aráyé nídè. Ogun yìí máa pa àwọn ẹni ibi run, á sì dá àwọn olódodo sí. Ó tún máa gba aráyé là torí pé kò ní jẹ́ kí ayé yìí pa run. (Ìfi. 11:18) Káwọn nǹkan tá a sọ yìí lè túbọ̀ yé wa, a máa dáhùn ìbéèrè mẹ́rin yìí: Kí ni Amágẹ́dọ́nì? Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ogun Amágẹ́dọ́nì? Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká wà lára àwọn tó máa la ogun yẹn já? Kí lá jẹ́ ká di ìgbàgbọ́ wa mú bí Amágẹ́dọ́nì ṣe ń sún mọ́lé?
KÍ NI AMÁGẸ́DỌ́NÌ?
3. (a) Kí ni “Amágẹ́dọ́nì” túmọ̀ sí? (b) Bó ṣe wà nínú Ìfihàn 16:14, 16, kí nìdí tá a fi sọ pé Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ibì kan pàtó?
3 Ka Ìfihàn 16:14, 16. Ẹ̀ẹ̀kan péré ni ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, ó sì wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò.” (Ìfi. 16:16; àlàyé ìsàlẹ̀) Ìlú kan ló ń jẹ́ Mẹ́gídò ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. (Jóṣ. 17:11) Àmọ́, Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ibì kan pàtó lórí ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí bí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” ṣe máa kóra jọ lòdì sí Jèhófà. (Ìfi. 16:14) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” tún ń tọ́ka sí ogun tó máa wáyé kété lẹ́yìn tí gbogbo ọba ilẹ̀ ayé bá kóra jọ. Báwo la ṣe mọ̀ pé ibi ìṣàpẹẹrẹ ni Amágẹ́dọ́nì? Àkọ́kọ́, kò sí òkè kankan láyé yìí tó ń jẹ́ Òkè Mẹ́gídò. Ìkejì, agbègbè Mẹ́gídò kò fẹ̀ débi tó máa gba “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” títí kan àwọn ọmọ ogun wọn àtàwọn ohun ìjà ogun tí wọ́n kó jọ. Ìkẹta, bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ogun Amágẹ́dọ́nì máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí “àwọn ọba” ayé bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run tó wà káàkiri ayé.
4. Kí nìdí tí Jèhófà fi mẹ́nu kan Mẹ́gídò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ogun ọjọ́ ńlá rẹ̀?
4 Kí nìdí tí Jèhófà fi mẹ́nu kan Mẹ́gídò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ogun ọjọ́ ńlá rẹ̀? Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ ogun làwọn èèyàn jà ní Mẹ́gídò àti Àfonífojì Jésírẹ́lì tó wà nítòsí Mẹ́gídò. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jèhófà dìídì ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mú kí Bárákì ṣẹ́gun Sísérà, ìyẹn olórí àwọn ọmọ ogun Kénáánì “létí omi Mẹ́gídò.” Bárákì àti Dèbórà tó jẹ́ wòlíì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe mú kí wọ́n ṣẹ́gun lọ́nà ìyanu. Lára ohun tí wọ́n kọ lórin ni pé: “Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run; wọ́n bá Sísérà jà. . . . Ọ̀gbàrá Kíṣónì gbá wọn lọ.”—Oníd. 5:19-21.
5. Ìyàtọ̀ pàtàkì wo ló wà nínú ogun Amágẹ́dọ́nì àtèyí tí Bárákì jà?
5 Bárákì àti Dèbórà fi ọ̀rọ̀ yìí parí orin wọn, pé: “Jẹ́ kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé, Jèhófà, àmọ́ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ dà bí oòrùn tó ń yọ nínú ògo rẹ̀.” (Oníd. 5:31) Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run pátápátá, á sì dá ẹ̀mí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí. Àmọ́, ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà nínú ogun Amágẹ́dọ́nì àtèyí tí Bárákì jà. Àwọn èèyàn Ọlọ́run kò ní jà nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Kódà, wọn ò ní ní ohun ìjà kankan débi tí wọ́n á dira ogun! Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ‘máa lágbára tí wọ́n bá fara balẹ̀, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé’ Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ tó wà lọ́run.—Àìsá. 30:15; Ìfi. 19:11-15.
6. Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kí Jèhófà fi pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì?
6 Báwo ni Jèhófà ṣe máa pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì? Onírúurú nǹkan ló ṣeé ṣe kó lò. Bí àpẹẹrẹ, ó lè lo ìmìtìtì ilẹ̀, òkúta yìnyín, ó sì lè mú kí àrá àti mànàmáná pa wọ́n run. (Jóòbù 38:22, 23; Ìsík. 38:19-22) Ó tún lè mú káwọn ọ̀tá rẹ̀ kọjú ìjà síra wọn. (2 Kíró. 20:17, 22, 23) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti pa àwọn ẹni ibi run. (Àìsá. 37:36) Èyí ó wù ó jẹ́, Jèhófà ló máa ṣẹ́gun, á sì run àwọn ọ̀tá rẹ̀ wómúwómú. Kò sẹ́nì kankan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó máa yè bọ́, àmọ́ gbogbo àwọn olódodo ló máa là á já.—Òwe 3:25, 26.
ÀWỌN NǸKAN WO LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ ṢÁÁJÚ OGUN AMÁGẸ́DỌ́NÌ?
7-8. (a) Bó ṣe wà nínú 1 Tẹsalóníkà 5:1-6, ìkéde àrà ọ̀tọ̀ wo làwọn alákòóso ayé máa ṣe? (b) Kí nìdí tí ìkéde yẹn fi léwu gan-an?
7 Ìkéde “àlàáfíà àti ààbò” ló máa ṣáájú “ọjọ́ Jèhófà.” (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:1-6.) “Ọjọ́ Jèhófà” tí 1 Tẹsalóníkà 5:2 sọ̀rọ̀ ẹ̀ ni “ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:14) Kí lá jẹ́ ká mọ ìgbà tí ìpọ́njú ńlá náà máa bẹ̀rẹ̀? Bíbélì sọ pé wọ́n máa ṣe ìkéde kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìkéde yẹn lá jẹ́ ká mọ̀ pé ìpọ́njú ńlá máa tó bẹ̀rẹ̀.
8 Ìkéde yẹn ló máa mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ tó sọ pé àwọn alákòóso ayé máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” Kí nìdí tí wọ́n á fi sọ bẹ́ẹ̀? Ṣé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa dara pọ̀ mọ́ wọn? Ó ṣeé ṣe. Àmọ́, ọ̀kan lára ìtànjẹ àwọn ẹ̀mí èṣù ló máa jẹ́. Irọ́ burúkú ni ìkéde náà, ó sì léwu gan-an torí pé á mú káwọn èèyàn gbà pé àlàáfíà àti ààbò ti dé tó sì jẹ́ pé ìpọ́njú ńlá tírú ẹ̀ ò tíì ṣẹlẹ̀ rí ló rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí aráyé. Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ náà ló máa rí, pé “ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn, bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí.” Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwa ìránṣẹ́ Jèhófà? Ó lè yà wá lẹ́nu pé wẹ́rẹ́ lọjọ́ Jèhófà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ kò ní bá wa lábo.
9. Ṣé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Jèhófà máa pa ayé èṣù yìí run? Ṣàlàyé.
9 Jèhófà ò ní pa ayé Sátánì run lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo bó ṣe ṣe nígbà ayé Nóà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa kọ́kọ́ pa apá kan run, lẹ́yìn náà á pa apá tó ṣẹ́ kù run. Bábílónì Ńlá ló máa kọ́kọ́ pa run, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké. Níkẹyìn, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì ó máa pa èyí tó kù lára ètò Sátánì run, títí kan ètò òṣèlú, àwọn ológun àti ètò ìṣòwò. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí.
10. Bó ṣe wà nínú Ìfihàn 17:1, 6 àti 18:24, kí nìdí tí Jèhófà fi máa pa Bábílónì Ńlá run?
10 “Ìdájọ́ aṣẹ́wó ńlá” náà. (Ka Ìfihàn 17:1, 6; 18:24.) Bábílónì Ńlá ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Jèhófà gan-an. Ó tún ń pa irọ́ fáwọn èèyàn nípa Ọlọ́run. Aṣẹ́wó ni torí pé àwọn alákòóso ayé ló ń tì lẹ́yìn dípò Ìjọba Ọlọ́run. Ó ń mú àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ sìn, ó sì ń fipá gba tọwọ́ wọn. Ó ti ṣekú pa ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Ìfi. 19:2) Báwo wá ni Jèhófà ṣe máa pa Bábílónì Ńlá run?
11. Kí ni “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà ṣàpẹẹrẹ, báwo sì ni Jèhófà ṣe máa lò ó láti pa Bábílónì Ńlá run?
11 Jèhófà máa lo “ìwo mẹ́wàá” tó wà lórí “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” kan láti pa “aṣẹ́wó ńlá” náà run. Ẹranko ẹhànnà yìí ṣàpẹẹrẹ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀ sì dúró fún àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso báyìí tí wọ́n ń ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn. Tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, á mú kí àwọn alákòóso yẹn gbéjà ko Bábílónì Ńlá. Wọ́n “máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò” ní ti pé wọ́n á gba gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀, wọ́n á sì tú àṣírí ìwà ìkà tó ń hù. (Ìfi. 17:3, 16) Òjijì ni ìparun yẹn máa ṣẹlẹ̀, bíi pé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, kódà ó máa ya àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lẹ́nu. Ó ṣe tán, ọjọ́ pẹ́ tó ti ń fọ́nnu pé: “Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í ṣe opó, mi ò sì ní ṣọ̀fọ̀ láé.”—Ìfi. 18:7, 8.
12. Kí ni Jèhófà kò ní fàyè gbà, kí sì nìdí?
12 Jèhófà kò ní jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè pa àwa èèyàn rẹ̀ run. Kí nìdí? Àwa là ń jẹ́ kí aráyé mọ orúkọ Jèhófà, a sì ti pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ pé ká jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá. (Ìṣe 15:16, 17; Ìfi. 18:4) Yàtọ̀ síyẹn, à ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti kúrò nínú rẹ̀. Torí náà, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní “gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.” Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan kan ṣì máa dán ìgbàgbọ́ wa wò.
13. (a) Ta ni Gọ́ọ̀gù? (b) Bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 38:2, 8, 9, kí lá mú kí Gọ́ọ̀gù gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run?
13 Gọ́ọ̀gù máa gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:2, 8, 9.) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa gbogbo ẹ̀sìn èké run, àwa èèyàn Jèhófà máa dà bí igi tó dá dúró lẹ́yìn tí ìjì ti ya gbogbo igi inú igbó lulẹ̀. Ìyẹn máa bí Sátánì nínú gan-an, ṣe lá tu itọ́ sókè, táá sì fojú gbà á. Á wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ‘àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́ tó ní ìmísí,’ ìyẹn àwọn ìpolongo ẹ̀tàn láti mú káwọn orílẹ̀-èdè gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n sì gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ìfi. 16:13, 14) Ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” Tí àwọn orílẹ̀-èdè bá ti kọjú ìjà sáwa èèyàn Jèhófà, ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.—Ìfi. 16:16.
14. Kí ni Gọ́ọ̀gù máa wá mọ̀ níkẹyìn?
14 Gọ́ọ̀gù máa gbára lé “agbára èèyàn,” ìyẹn àwọn ọmọ ogun rẹ̀. (2 Kíró. 32:8) Àmọ́ ní tiwa, Jèhófà Ọlọ́run wa la máa gbẹ́kẹ̀ lé, ìyẹn sì máa dà bí ìwà òmùgọ̀ lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n á ronú pé bí ọlọ́run àwọn ẹ̀sìn Bábílónì Ńlá kò bá lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ “ẹranko náà” àti “ìwo mẹ́wàá” rẹ̀, mélòómélòó àwa! (Ìfi. 17:16) Torí náà, Gọ́ọ̀gù máa ronú pé wẹ́rẹ́ báyìí lòun máa pa wá run. Nípa bẹ́ẹ̀, á gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà “bí ìgbà tí ìkùukùu bo ilẹ̀.” (Ìsík. 38:16) Àmọ́ ńṣe ni Gọ́ọ̀gù máa kàgbákò. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ á dà bíi ti Fáráò nínú Òkun Pupa tó gbà níkẹyìn pé Jèhófà lòun ń bá jà.—Ẹ́kís. 14:1-4; Ìsík. 38:3, 4, 18, 21-23.
15. Kí ni Jésù Kristi máa ṣe fáwọn ọ̀tá Jèhófà?
15 Kristi àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run máa gbèjà àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n á sì pa Gọ́ọ̀gù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run pátápátá. (Ìfi. 19:11, 14, 15) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí olórí ọ̀tá Jèhófà, ìyẹn Sátánì tó lo ìpolongo ẹ̀tàn láti mú káwọn orílẹ̀-èdè bá Ọlọ́run jà ní Amágẹ́dọ́nì? Jésù máa ju òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, ibẹ̀ sì ni wọ́n máa wà fún odindi ẹgbẹ̀rún ọdún kan.—Ìfi. 20:1-3.
KÍ LA LÈ ṢE TÁÁ JẸ́ KÁ LA OGUN AMÁGẸ́DỌ́NÌ JÁ?
16. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a “mọ Ọlọ́run”? (b) Àǹfààní wo ni mímọ̀ tá a mọ Jèhófà máa ṣe wá nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì?
16 Yálà ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà nínú òtítọ́ tàbí kò pẹ́, tá a bá máa la ogun Amágẹ́dọ́nì já, ó ṣe pàtàkì ká “mọ Ọlọ́run,” ká sì máa “ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹs. 1:7-9) A lè fi hàn pé a “mọ Ọlọ́run” tá a bá mọ ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, tá a sì tún mọ àwọn ìlànà rẹ̀. A tún lè fi hàn pé a mọ Ọlọ́run tá a bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tá a sì ń jọ́sìn òun nìkan. (1 Jòh. 2:3-5; 5:3) Tá a bá mọ Ọlọ́run, tá a sì ń fi hàn bẹ́ẹ̀, Jèhófà náà máa mọ̀ wá, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká la Amágẹ́dọ́nì já! (1 Kọ́r. 8:3) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn tí Jèhófà mọ̀ ló máa fojúure hàn sí.
17. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn “ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa”?
17 Gbogbo òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Jésù fi kọ́ni ni Bíbélì pè ní “ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” À ń ṣègbọràn sí ìhìn rere tá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí wa. Lédè míì, ká máa fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa, ká máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run, ká sì máa fìtara kéde Ìjọba rẹ̀. (Mát. 6:33; 24:14) Ó tún yẹ ká máa ti àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Jésù lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń bójú tó ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ní nínú ètò Ọlọ́run.—Mát. 25:31-40.
18. Báwo làwọn ẹni àmì òróró ṣe máa fi hàn pé àwọn mọrírì ìtìlẹ́yìn tí wọ́n rí gbà?
18 Láìpẹ́ àwọn ẹni àmì òróró máa fi hàn pé àwọn mọrírì ìtìlẹ́yìn tí “àwọn àgùntàn mìíràn” fún wọn. (Jòh. 10:16) Báwo ni wọ́n á ṣe fi hàn pé àwọn mọrírì wọn? Kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ti máa wà lọ́run, wọ́n á sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́. Wọ́n máa wà lára ẹgbẹ́ ogun ọ̀run táá pa Gọ́ọ̀gù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run, wọ́n á sì dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìfi. 2:26, 27; 7:9, 10) Ó dájú pé inú ogunlọ́gọ̀ èèyàn yìí máa dùn gan-an pé àwọn ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró nígbà tí wọ́n wà láyé!
KÍ LÁ JẸ́ KÁ DI ÌGBÀGBỌ́ WA MÚ BÍ AMÁGẸ́DỌ́NÌ ṢE Ń SÚN MỌ́LÉ?
19-20. Kí lá jẹ́ ká di ìgbàgbọ́ wa mú láìka àdánwò tá à ń kojú sí?
19 Onírúurú àdánwò làwa èèyàn Jèhófà ń kojú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó nira yìí. Bó ti wù kó rí, a lè máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. (Jém. 1:2-4) Ohun kan tó máa mú ká lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà látọkàn wá. (Lúùkù 21:36) Ó tún yẹ ká fiṣẹ́ ti àdúrà wa, ìyẹn ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà. (Sm. 77:12) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, tá a sì ń wàásù déédéé, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára, ìrètí wa á sì máa dán gbinrin.
20 Wo bí inú rẹ ṣe máa dùn tó nígbà tí Bábílónì Ńlá ò bá sí mọ́ tí ogun Amágẹ́dọ́nì sì ti parí! Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wo bó ṣe máa rí lára rẹ nígbà tí Jèhófà bá dá orúkọ rẹ̀ láre tó sì jẹ́ kí aráyé mọ̀ pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé àti Ọ̀run! (Ìsík. 38:23) Ó ṣe kedere pé ìròyìn ayọ̀ ni Amágẹ́dọ́nì jẹ́ fún àwa tá a mọ Jèhófà, tá à ń ṣègbọràn sí Jésù, tá a sì fara dà á dópin.—Mát. 24:13.
ORIN 143 Tẹpá Mọ́ṣẹ́, Wà Lójúfò, Kó O sì Máa Retí
a Ọjọ́ pẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ti ń retí Amágẹ́dọ́nì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàlàyé ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́, àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú Amágẹ́dọ́nì àtohun táá jẹ́ ká di ìgbàgbọ́ wa mú bí òpin ti ń sún mọ́lé.
b ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Àwọn nǹkan àgbàyanu tó ṣì máa ṣẹlẹ̀. (1) Àá máa wàásù bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, (2) àá máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, (3) àá sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bò wá.
c ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Àwọn ọlọ́pàá fẹ́ já wọ inú ilé àwọn ará, àmọ́ ó dá àwọn ará yẹn lójú pé Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n á sì dáàbò bo àwọn.