Orí 38
Ẹ Yin Jáà Nítorí Ìdájọ́ Rẹ̀!
1. Kí ni Jòhánù gbọ́ tí “ohùn rara ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ní ọ̀run” sọ?
BÁBÍLÓNÌ ŃLÁ kò sí mọ́! Dájúdájú, Ìròyìn ayọ̀ ni. Abájọ tí Jòhánù fi gbọ́ ìhó ayọ̀ lọ́run! Ó ní: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo gbọ́ ohun tí ó dà bí ohùn rara ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ní ọ̀run. Wọ́n wí pé: ‘Halelúyà!a Ìgbàlà àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ọlọ́run wa, nítorí òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí pé ó ti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí aṣẹ́wó ńlá tí ó fi àgbèrè rẹ̀ sọ ilẹ̀ ayé di ìbàjẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ lára rẹ̀.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sọ ní ìgbà kejì pé: ‘Halelúyà!* Èéfín láti ara rẹ̀ sì ń bá a lọ ní gígòkè títí láé àti láéláé.’”—Ìṣípayá 19:1-3.
2. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Halelúyà” túmọ̀ sí, kí ni gbígbọ́ tí Jòhánù gbọ́ ọ lẹ́ẹ̀mejì níbí tọ́rọ̀ dé yìí nínú Ìṣípayá fi hàn? (b) Ta ló gba ògo pípa Bábílónì Ńlá run? Ṣàlàyé.
2 Halelúyà ni lóòótọ́! Ọ̀rọ̀ náà Halelúyà túmọ̀ sí “Ẹ yin Jáà,” níwọ̀n bí “Jáà” ti jẹ́ ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Èyí rán wa létí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí onísáàmù sọ pé: “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà. Ẹ yin Jáà!” (Sáàmù 150:6) Níbi tọ́rọ̀ dé yìí nínú Ìṣípayá, bí Jòhánù ṣe gbọ́ tí wọ́n fayọ̀ kọrin lọ́run lẹ́ẹ̀mejì pé “Halelúyà!” fi hàn pé ṣíṣí òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run payá ṣì ń bá a lọ. Ọlọ́run tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni Ọlọ́run kan náà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, Jèhófà sì ni orúkọ rẹ̀. Ọlọ́run tó mú kí Bábílónì ìgbàanì ṣubú ló ṣèdájọ́ Bábílónì Ńlá nísinsìnyí tó sì máa pa á run. Ọlọ́run ni ká gbé gbogbo ògo fún nítorí ohun ribiribi tó ṣe yẹn! Ti Ọlọ́run ni agbára tó mú kí Bábílónì ṣubú, agbára náà kì í ṣe tàwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run wulẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ láti fi sọ Bábílónì dahoro. Ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ìgbàlà ti wá.—Aísáyà 12:2; Ìṣípayá 4:11; 7:10, 12.
3. Kí nìdí tí ìdájọ́ tó le gan-an fi tọ́ sí aṣẹ́wó ńlá náà?
3 Kí nìdí tí ìdájọ́ tó le gan-an fi tọ́ sí aṣẹ́wó ńlá náà? Bí òfin tí Jèhófà fún Nóà tó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà fún gbogbo aráyé ṣe wí, ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn gbọ́dọ̀ kú. Ọlọ́run tún òfin yẹn sọ nínú òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 9:6; Númérì 35:20, 21) Yàtọ̀ síyẹn, lábẹ́ Òfin Mósè, ikú tọ́ sí ẹni tó bá ṣe panṣágà tara tàbí tẹ̀mí. (Léfítíkù 20:10; Diutarónómì 13:1-5) Fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún, Bábílónì Ńlá ti tàjẹ̀ sílẹ̀, ó sì jẹ́ àgbèrè paraku. Bí àpẹẹrẹ, ìlànà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó ka ìgbéyàwó léèwọ̀ fáwọn àlùfáà rẹ̀ ti mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn ṣe ìṣekúṣe tó bùáyà, kì í sì í ṣe díẹ̀ lára wọn ló ń kó àrùn éèdì lónìí. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 1 Tímótì 4:1-3) Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ńlá ‘tó wọ́ jọpọ̀ dé ọ̀run,’ ni ìwà àgbèrè rẹ̀ tẹ̀mí tó bùáyà. Ó ń hùwà àgbèrè tẹ̀mí yìí nípa kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ èké àti dídara pọ̀ mọ́ àwọn òṣèlú oníwà ìbàjẹ́. (Ìṣípayá 18:5) Nítorí pé ó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run ké Halelúyà lẹ́ẹ̀kejì.
4. Kí ni èéfín Bábílónì Ńlá tó “ń bá a lọ ní gígòkè títí láé àti láéláé” ṣàpẹẹrẹ?
4 A ti tiná bọ Bábílónì Ńlá bí ìlú tá a ṣẹ́gun, èéfín rẹ̀ “sì ń bá a lọ ní gígòkè títí láé àti láéláé.” Nígbà táwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́gun bá fi iná sun ìlú kan, èéfín yóò máa bá a lọ ní ríròkè níwọ̀n ìgbà tí eérú rẹ̀ bá ṣì gbóná. Bí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti tún àwókù ìlú náà kọ́ nígbà tó ṣì ń ṣèéfín, ńṣe ni iná tó wà níbẹ̀ á wulẹ̀ jó ẹni náà. Níwọ̀n bí èéfín Bábílónì Ńlá yóò ti máa ròkè “láé àti láéláé,” èyí tó jẹ́ àmì pé ìdájọ́ rẹ̀ ti parí, kò sẹ́ni tó máa lè mú ìlú oníwà ìbàjẹ́ yẹn padà bọ̀ sípò láé. Ìsìn èké á lọ, kò sì ní padà mọ́ láéláé. Halelúyà ni lóòótọ́!—Fi wé Aísáyà 34:5, 9, 10.
5. (a) Kí ni alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rin ń ṣe tí wọ́n sì ń sọ? (b) Kí nìdí tí orin Halelúyà náà fi dùn ju èyí tí wọ́n ń kọ láwọn ṣọ́ọ̀ṣì?
5 Nínú ìran kan tí Jòhánù rí níṣàájú, ó rí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká, àti alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn ajogún Ìjọba náà nínú ipò wọn ológo ní ọ̀run. (Ìṣípayá 4:8-11) Wàyí o, ó tún rí wọn lẹ́ẹ̀kan sí i bí wọ́n ti ń fi ohùn tó dún bí ààrá ké Halelúyà lẹ́ẹ̀kẹta, tí wọ́n ń yọ̀ pé Bábílónì Ńlá ti pa run. Ó ní: “Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà sì wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n sì wí pé: ‘Àmín! Halelúyà!’”b (Ìṣípayá 19:4) Nípa bẹ́ẹ̀, orin Halelúyà títóbilọ́lá tí wọ́n kọ yìí jẹ́ ní àfikún sí “orin tuntun” tí wọ́n fi yin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. (Ìṣípayá 5:8, 9) Wọ́n wá ń kọ orin ìṣẹ́gun tó ga lọ́lá yìí, tí wọ́n ń gbé gbogbo ògo fún Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ nítorí pé ó ṣẹ́gun aṣẹ́wó ńlá náà, Bábílónì Ńlá pátápátá. Ìró orin Halelúyà wọ̀nyí dùn ju èyí tí wọ́n máa ń kọ láwọn ṣọ́ọ̀ṣì, níbi tí wọ́n ti tàbùkù sí Jèhófà, tí wọ́n sì ti tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀. Irú orin àgàbàgebè bẹ́ẹ̀ tí ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà yóò dákẹ́ wẹ́lo títí láé!
6. “Ohùn” ta ni Jòhánù gbọ́, kí ni ohùn náà rọni láti ṣe, àwọn wo ló sì nípìn-ín nínú ṣíṣe ohun tí ohùn náà sọ?
6 Ọdún 1918 ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í san èrè fún ‘àwọn tí ń bẹ̀rù orúkọ rẹ̀, ẹni kékeré àti ẹni ńlá.’ Àkọ́kọ́ nínú àwọn wọ̀nyí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣòtítọ́ títí wọ́n fi kú. Jèhófà jí wọn dìde ó sì fi wọn sí ipò àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà lọ́run. (Ìṣípayá 11:18) Àwọn mìíràn dara pọ̀ mọ́ wọn nínú kíkọ orin Halelúyà, nítorí Jòhánù ròyìn pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan jáde wá láti orí ìtẹ́ náà, ó sì wí pé: ‘Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, gbogbo ẹ̀yin ẹrú rẹ̀, tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin ẹni kékeré àti ẹni ńlá.’” (Ìṣípayá 19:5) Èyí ni “ohùn” Agbẹnusọ fún Jèhófà, Ọmọ Jèhófà tìkára rẹ̀, Jésù Kristi, ẹni tó dúró “ní àárín ìtẹ́ náà.” (Ìṣípayá 5:6) “Gbogbo [àwọn] ẹrú rẹ̀” ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé níbí, ń nípìn-ín nínú orin náà, tí ẹgbẹ́ Jòhánù tá a fi òróró yàn sì ń mú ipò iwájú lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. Ẹ wo bí wọ́n ṣe ń fi ayọ̀ nípìn-ín nínú ṣíṣègbọràn sí àṣẹ náà pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa”!
7. Lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá ti pa run, àwọn wo ni yóò máa yin Jèhófà?
7 Bẹ́ẹ̀ ni, a ka àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá mọ́ ẹrú wọ̀nyí. Láti 1935 ni wọ́n ti ń jáde látinú Bábílónì Ńlá, ìlérí Ọlọ́run sì ti ṣẹ sí wọn lára pé: “Òun yóò bù kún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà. Àwọn ẹni kékeré àti àwọn ẹni ńlá.” (Sáàmù 115:13) Nígbà tá a bá pa Bábílónì tó dà bí aṣẹ́wó yìí run, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá pa pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Jòhánù àtàwọn ẹgbàágbèje ẹ̀dá tí ń bẹ lọ́run yóò dara pọ̀ nínú ‘yíyin Ọlọ́run wa.’ Nígbà tó bá yá, àwọn tá a jí dìde sórí ilẹ̀ ayé, yálà wọ́n ti ń múpò iwájú tẹ́lẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóò kọrin Halelúyà síwájú sí i nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé Bábílónì Ńlá ti lọ láú. (Ìṣípayá 20:12, 15) Gbogbo ìyìn á lọ sọ́dọ̀ Jèhófà nítorí ó ṣẹ́gun aṣẹ́wó àtayébáyé náà lọ́nà tó pabanbarì!
8. Nísinsìnyí, kí Jèhófà tó pa Bábílónì Ńlá run, kí ló yẹ káwọn orin ìyìn tí wọ́n kọ lọ́run níṣojú Jòhánù fún wa níṣìírí láti ṣe?
8 Ẹ ò rí i pé gbogbo èyí fún wa níṣìírí láti kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run tó wà fún àkókò yìí! Ǹjẹ́ kí gbogbo ìránṣẹ́ Jáà máa fi gbogbo ọkàn kéde ìdájọ́ Ọlọ́run àti ìrètí Ìjọba náà nísinsìnyí, kí Jèhófà tó gbé Bábílónì Ńlá ṣubú kúrò ní ipò rẹ̀ àti kó tó pa á run.—Aísáyà 61:1-3; 1 Kọ́ríńtì 15:58.
‘Halelúyà, Jèhófà Di Ọba!’
9. Kí nìdí tí Halelúyà ìkẹyìn yìí fi dún gan-an tó sì rinlẹ̀ dáadáa?
9 Ìdí púpọ̀ sí i wà fún yíyọ̀ ayọ̀, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ti ń bá a lọ láti sọ fún wa pé: “Mo sì gbọ́ ohun tí ó dà bí ohùn ogunlọ́gọ̀ ńlá àti bí ìró omi púpọ̀ àti bí ìró àwọn ààrá pípabanbarì. Wọ́n wí pé: ‘Halelúyà,c nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa, Olódùmarè, ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.’” (Ìṣípayá 19:6) Halelúyà kẹrin tó gbẹ̀yìn yìí ló mú kí ìkéde náà gún régé, tàbí tó mú kó dún yíká-yíká. Ó jẹ́ ìró alágbára ńlá lókè ọ̀run, èyí tó ga lọ́lá ju ẹgbẹ́ akọrin èèyàn èyíkéyìí lọ, tó sì ní ọlá ńlá ju omi tó ń tàkìtì wálẹ̀ látorí àpáta, tó tún jẹ́ ohun ìyanu ńláǹlà ju dídún ààrá èyíkéyìí lọ. Ẹgbàágbèje ẹ̀dá ẹ̀mí lókè ọ̀run yọ̀ nítorí pé “Jèhófà Ọlọ́run wa, Olódùmarè, ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.”
10. Lọ́nà wo la fi lè sọ pé Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá ti pa run?
10 Ṣùgbọ́n, báwo ni Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti kọjá lọ látìgbà tí onísáàmù ti polongo pé: “Ọlọ́run ni Ọba mi láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” (Sáàmù 74:12) Kódà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn tí onísáàmù ṣe ìpolongo yìí, ipò ọba Jèhófà ti wà látayébáyé. Báwo wá ni orin tó kárí ọ̀run òun ayé yìí ṣe lè sọ pé “Jèhófà . . . ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba”? Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ti pé nígbà tó bá pa Bábílónì Ńlá run, kò ní sí mọ́ láti máa fi ìwà ọ̀yájú bá Jèhófà díje, kò ní lè sọ mọ́ pé káwọn èèyàn má gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé òun ọ̀run. Kó ní ṣẹlẹ̀ mọ́ pé kí ìsìn èké ru àwọn alákòóso ayé lọ́kàn sókè láti ta ko Ọlọ́run. Nígbà tí Bábílónì ìgbàanì ṣubú kúrò ní ipò ìjẹgàba lórí ayé, Síónì gbọ́ ìkéde ìṣẹ́gun náà pé: “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!” (Aísáyà 52:7) Lẹ́yìn ìbí Ìjọba náà lọ́dún 1914, alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà pòkìkí pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, . . . nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.” (Ìṣípayá 11:17) Wàyí o, lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá ti dahoro, igbe náà tún dún jáde pé: “Jèhófà . . . ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.” Kò sí ọlọ́run táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ mọ́ láti máa ta ko ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà!
Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
11, 12. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni Jerúsálẹ́mù ayé ọjọ́un sọ sí Bábílónì ìgbàanì, kí sì nìyẹn fi hàn nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun àti Bábílónì Ńlá? (b) Nígbà tá a ṣẹ́gun Bábílónì Ńlá, kí làwọn ẹgbàágbèje ẹ̀dá tí ń bẹ lọ́run kọ lórin tí wọ́n sì kéde?
11 “Ìwọ ọ̀tá mi obìnrin”! Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jerúsálẹ́mù, níbi tí tẹ́ńpìlì ìjọsìn Jèhófà wà, sọ sí Bábílónì abọ̀rìṣà. (Míkà 7:8) Lọ́nà kan náà, ‘ìlú ńlá mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun,’ ìyẹn ìyàwó tí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] para pọ̀ jẹ́, ní ìdí pàtàkì láti pe Bábílónì Ńlá ní ọ̀tá rẹ̀. (Ìṣípayá 21:2) Ṣùgbọ́n níkẹyìn ìpọ́njú bá aṣẹ́wó ńlá náà, àjálù ibi bá a, ó sì pa run. Àwọn àṣà ìbẹ́mìílò àti àwọn awòràwọ̀ rẹ̀ kò lágbára láti gbà á là. (Fi wé Aísáyà 47:1, 11-13.) Dájúdájú, ìṣẹ́gun tó kàmàmà lèyí jẹ́ fún ìjọsìn tòótọ́!
12 Ní báyìí tí Bábílónì Ńlá, aṣẹ́wó tí ń kóni nírìíra náà ti pa run, ó ṣeé ṣe fún wa láti pọkàn wa pọ̀ sára wúńdíá aya ọ̀dọ́ àgùntàn! Fún ìdí yìí, ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run fayọ̀ kọrin ìyìn sí Jèhófà pé: “Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì láyọ̀ púpọ̀, ẹ sì jẹ́ kí a fi ògo fún un, nítorí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé, aya rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, a ti yọ̀ǹda fún un kí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títànyòyò, tí ó mọ́ ṣe é ní ọ̀ṣọ́, nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà náà dúró fún àwọn ìṣe òdodo àwọn ẹni mímọ́.”—Ìṣípayá 19:7, 8.
13. Ìmúrasílẹ̀ wo fún ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ló ti wáyé láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá?
13 Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá, Jésù ti fìfẹ́ múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó òkè ọ̀run yìí. (Mátíù 28:20; 2 Kọ́ríńtì 11:2) Ó ti ń wẹ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] Ísírẹ́lì tẹ̀mí mọ́ kó bàa lè “mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ìdángbinrin rẹ̀, láìní èérí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n pé kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.” (Éfésù 5:25-27) Kọ́wọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lè tẹ “ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè,” ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbọ́dọ̀ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, kó gbé ìwà tuntun ti Kristẹni wọ̀ bí aṣọ, kó sì máa ‘fi gbogbo ọkàn ṣe àwọn iṣẹ́ òdodo bí ẹni pé fún Jèhófà.’—Fílípì 3:8, 13, 14; Kólósè 3:9, 10, 23.
14. Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti kó èérí bá àwọn tó máa di ara ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìnwá ọ̀la?
14 Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni síwájú, Sátánì lo Bábílónì Ńlá gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ rẹ̀ láti fi kó èérí bá àwọn tó máa di ara ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìnwá ọ̀la. Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kìíní, ó ti fún àwọn irúgbìn ìsìn Bábílónì sínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 15:12; 2 Tímótì 2:18; Ìṣípayá 2:6, 14, 20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe àwọn tí ń sojú ìgbàgbọ́ dé, ó ní: “Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa ara wọn dà di àpọ́sítélì Kristi. Kò sì ṣeni ní kàyéfì, nítorí Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:13, 14) Láwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà ṣe bíi tàwọn ìsìn yòókù tó jẹ́ ara Bábílónì Ńlá, ó fi ọlà àti àǹfààní wọ ara rẹ̀ ní aṣọ “aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò . . . wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì.” (Ìṣípayá 17:4) Ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ àtàwọn póòpù rẹ̀ ti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọba ayé tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, irú bíi Kọnsitatáìnì àti Charlemagne. Kò fi “òdodo àwọn ẹni mímọ́” ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ rí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ayédèrú ìyàwó ni, ó dájú pé Sátánì ló gbé e kalẹ̀ láti máa tan àwọn èèyàn jẹ. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, á pa run, kò sì ní padà wá mọ́ láé!
Ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Ti Múra Sílẹ̀
15. Báwo ni fífi èdìdì di àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe ṣẹlẹ̀, kí sì ni a béèrè lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn?
15 Wàyí o, lẹ́yìn tí nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún ti kọjá, gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹgbẹ́ ìyàwó ti wà ní sẹpẹ́. Ṣùgbọ́n àkókò wo gan-an la lè sọ pé ‘ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti múra sílẹ̀’? Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni síwájú, àwọn onígbàgbọ́ ẹni àmì òróró ni “a fi èdìdì dì . . . pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí,” èyí jẹ́ nítorí dídé “ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.” Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ ọ́, Ọlọ́run “tún ti fi èdìdì rẹ̀ sórí wa, ó sì ti fún wa ní àmì ìdánilójú ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí náà, tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà wa.” (Éfésù 1:13; 4:30; 2 Kọ́ríńtì 1:22) Kristẹni ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan ni a ti “pè, tí a [sì ti] yàn,” tó sì ti fi hàn pé “olùṣòtítọ́” ni òun.—Ìṣípayá 17:14.
16. (a) Ìgbà wo ni fífi èdìdì di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù parí, báwo sì ni a ṣe mọ̀? (b) Ìgbà wo ni ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ti “múra sílẹ̀” lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
16 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Pọ́ọ̀lù fi dojú kọ ìdánwò, ó ṣeé ṣe fún un láti polongo pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo, yóò fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn, síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo àwọn tí ó ti nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀ pẹ̀lú.” (2 Tímótì 4:7, 8) Ó jọ pé fífi èdìdì di àpọ́sítélì náà ti parí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì wà nínú ẹran ara tó sì ń bọ̀ wá dojú kọ ikú ajẹ́rìíkú. Lọ́nà kan náà, àkókò ń bọ̀ nígbà tá a óò ti fi èdìdì di gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n jẹ́ ara ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ìyẹn a sì fi hàn pé wọ́n jẹ́ ti Jèhófà. (2 Tímótì 2:19) Èyí yóò jẹ́ nígbà tí ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ti múra sílẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ìyẹn nígbà táwọn tó pọ̀ jù lọ lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] yóò ti gba èrè wọn lọ́run tá a ó sì ti tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé níkẹyìn pé wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ tí a óò sì ti fi èdìdì dì wọ́n.
17. Ìgbà wo ni ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn yóò wáyé?
17 Lákòókò yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Jèhófà, ìyẹn nígbà tí fífi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] bá ti parí, àwọn áńgẹ́lì yóò tú ẹ̀fúùfù mẹ́rin ti ìpọ́njú ńlá náà sílẹ̀. (Ìṣípayá 7:1-3) Lákọ̀ọ́kọ́, a óò pa Bábílónì Ńlá tó dà bí aṣẹ́wó yìí run. Lẹ́yìn náà, Kristi tó jẹ́ aṣẹ́gun yóò gbéra kíákíá lọ sí Amágẹ́dọ́nì láti pa ìyókù ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé run, tí yóò sì gbé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níkẹyìn. (Ìṣípayá 19:11–20:3) Bí àwọn ẹni àmì òróró kan bá ṣì kù lórí ilẹ̀ ayé, kò sí àní-àní pé kò ní pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n á fi gba èrè wọn ti ọ̀run láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ ìyàwó. Lẹ́yìn náà, ní àkókò tí Ọlọ́run yàn, ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn yóò wáyé!
18. Báwo ni Sáàmù 45 ṣe ṣàlàyé báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra?
18 Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 45 ṣàpèjúwe báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Ọba tá a ti gbé gun orí ìtẹ́ ń gẹṣin lọ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Ẹsẹ 1-7) Lẹ́yìn náà, a ṣe ìgbéyàwó náà, tí àwọn wúńdíá alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ogunlọ́gọ̀ ńlá, wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèránṣẹ́ lórí ilẹ̀ ayé fún ìyàwó ti ọ̀run náà. (Ẹsẹ 8-15) Lẹ́yìn èyí, ìgbéyàwó náà bẹ̀rẹ̀ sí í mú èso jáde, pẹ̀lú aráyé tá a jí dìde tá a mú wọn dé ìjẹ́pípé lábẹ́ àbójútó àwọn “olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ẹsẹ 16, 17) Ẹ wo àwọn ìbùkún ológo tí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò mú wá!
Aláyọ̀ Làwọn Tí A Pè
19. Èwo ni ìkẹrin lára ayọ̀ méje inú ìwé Ìṣípayá, àwọn wo ni wọ́n sì nípìn-ín nínú ayọ̀ tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí?
19 Wàyí o, Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ ìkẹrin lára ayọ̀ méje inú ìwé Ìṣípayá, ó ní: “Ó [ìyẹn áńgẹ́lì tí ó ti ń ṣí nǹkan wọ̀nyí payá fún Jòhánù] sì sọ fún mi pé: ‘Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn tí a ké sí wá síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sọ fún mi pé: ‘Ìwọ̀nyí ni àsọjáde tòótọ́ ti Ọlọ́run.’” (Ìṣípayá 19:9)d Àwọn tá a pè wá “síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ni àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ ìyàwó. (Fi wé Mátíù 22:1-14.) Àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀ tó jẹ́ ìyàwó ló ní ayọ̀ pé a pè wọ́n. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tá a pè sì ti lọ sí ọ̀run, ìyẹn ibi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó náà. Àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé láyọ̀ pẹ̀lú pé a pe àwọn náà. Àyè wọn níbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó náà ti wà ní sẹpẹ́. (Jòhánù 14:1-3; 1 Pétérù 1:3-9) Nígbà tá a bá jí wọn dìde sí ọ̀run, ìyàwó náà lápapọ̀, yóò wà níṣọ̀kan, àwọn àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò sì ṣe ìgbéyàwó tó láyọ̀ jù lọ yẹn.
20. (a) Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Ìwọ̀nyí ni àsọjáde tòótọ́ ti Ọlọ́run”? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà mú kí Jòhánù ṣe, báwo sì ni áńgẹ́lì náà ṣe fèsì?
20 Áńgẹ́lì náà fi kún un pé “ìwọ̀nyí ni àsọjáde tòótọ́ ti Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ náà, “tòótọ́,” jẹ́ ìtumọ̀ Gíríìkì náà a·le·thi·nosʹ, ó sì túmọ̀ sí “ojúlówó” tàbí “ṣeé gbára lé.” Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti wá látọ̀dọ̀ Jèhófà lóòótọ́, wọ́n ṣeé gbíyè lé wọ́n sì ṣeé gbára lé. (Fi wé 1 Jòhánù 4:1-3; Ìṣípayá 21:5; 22:6.) Nítorí pé Jòhánù wà lára àwọn tá a pè wá síbi àsè ìgbéyàwó yẹn, inú rẹ̀ ti ní láti dùn gan-an nígbà tó gbọ́ àti nígbà tó ń wo àwọn ìbùkún tí ń bẹ níwájú fún ẹgbẹ́ ìyàwó náà. Àní sẹ́, ọ̀rọ̀ náà wọ Jòhánù lára gan-an débi tí áńgẹ́lì náà fi ní láti fún un ní ìmọ̀ràn, Jòhánù ròyìn pé: “Látàrí ìyẹn, mo wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé: ‘Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù. Jọ́sìn Ọlọ́run.’”—Ìṣípayá 19:10a.
21. (a) Kí ni ìwé Ìṣípayá sọ fún wa nípa àwọn áńgẹ́lì? (b) Báwo ló ṣe yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe sí àwọn áńgẹ́lì?
21 Gbogbo ìwé Ìṣípayá látòkèdélẹ̀ jẹ́rìí sí i pé àwọn áńgẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ àti òṣìṣẹ́ aláápọn. Wọ́n jẹ́ ara ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣí òtítọ́ payá. (Ìṣípayá 1:1) Wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú wíwàásù ìhìn rere náà àti nínu dída àwọn ìyọnu àfiṣàpẹẹrẹ náà jáde. (Ìṣípayá 14:6, 7; 16:1) Wọ́n jà tẹ̀ lé Jésù lẹ́yìn láti lé Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀run, wọn yóò sì tún jà tẹ̀ lé Jésù lẹ́yìn ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 12:7; 19:11-14) Àní sẹ́, Jèhófà fàyè gbà wọ́n láti dé ọ̀dọ̀ òun alára. (Mátíù 18:10; Ìṣípayá 15:6) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ẹrú onírẹ̀lẹ̀ fún Ọlọ́run. Nínú ìjọsìn mímọ́, kò sáyè fún jíjọ́sìn àwọn áńgẹ́lì, kódà kò sáyè fún ìjọsìn alápá kan, ìyẹn jíjọ́sìn Ọlọ́run nípasẹ̀ “ẹni mímọ́” kan tàbí áńgẹ́lì kan. (Kólósè 2:18) Jèhófà nìkan ṣoṣo làwọn Kristẹni ń jọ́sìn, wọ́n ń tọrọ ohun tí wọ́n fẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ Jésù.—Jòhánù 14:12, 13.
Ipa Tí Jésù Ń Kó Nínú Àsọtẹ́lẹ̀
22. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ fún Jòhánù, kí sì ni ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí?
22 Áńgẹ́lì náà wí lẹ́yìn náà pé: “Nítorí jíjẹ́rìí Jésù ni ohun tí ń mí sí ìsọtẹ́lẹ̀.” (Ìṣípayá 19:10b) Báwo ni ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí la sọ nítorí Jésù àti ipa tó ń kó nínú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé. Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ṣèlérí pé irú-ọmọ kan ń bọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Jésù wá ni Irú-Ọmọ náà. Àwọn ìṣípayá ẹ̀yìn ìgbà náà fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ dá lórí ìlérí àkọ́kọ́ yẹn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún Kèfèrí onígbàgbọ́ náà Kọ̀nílíù pé: “Òun [Jésù] ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sí.” (Ìṣe 10:43) Ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀ [Jésù].” (2 Kọ́ríńtì 1:20) Ní ọdún mẹ́tàlélógún [43] lẹ́yìn náà, Jòhánù fúnra rẹ̀ rán wa létí pé: “Òtítọ́ wá wà nípasẹ̀ Jésù Kristi.”—Jòhánù 1:17.
23. Kí nìdí tí ipò gíga tí Jésù wà àti àṣẹ ńlá tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ kò fi dín ìjọsìn tá à ń ṣe sí Jèhófà kù?
23 Ǹjẹ́ èyí dín ìjọsìn tá à ń ṣe sí Jèhófà kù lọ́nàkọnà? Rárá. Rántí ìkìlọ̀ tí áńgẹ́lì náà ṣe, pé: “Jọ́sìn Ọlọ́run.” Jésù kò gbìyànjú rí láti bá Jèhófà díje. (Fílípì 2:6) Òótọ́ ni pé gbogbo àwọn áńgẹ́lì la sọ fún pé kí wọ́n “wárí fún [Jésù],” tí gbogbo ẹ̀dá sì gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ipò gíga ló wà kó bàa lè jẹ́ pé “ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba,” àmọ́ kíyè sí i pé, èyí jẹ́ “fún ògo Ọlọ́run Baba” àti pé òun ló pàṣẹ rẹ̀. (Hébérù 1:6; Fílípì 2:9-11) Jèhófà ló fún Jésù ní àṣẹ ńlá tó wà níkàáwọ́ rẹ̀, bá a bá sì ń tẹ̀ lé àṣẹ yẹn, Ọlọ́run là ń fi ògo fún yẹn. Bí a kò bá fi ara wa sábẹ́ ìṣàkóso Jésù, Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ la kọ̀ sílẹ̀ yẹn.—Sáàmù 2:11, 12.
24. Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá méjì wo là ń retí, nípa bẹ́ẹ̀ kí ló yẹ ka máa sọ?
24 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ka pohùn pọ̀ ká sọ ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Sáàmù 146 sí 150 pé: “Ẹ yin Jáà!” Ǹjẹ́ kí orin Halelúyà náà máa dún bí ààrá bá a ṣe ń fojú sọ́nà pé kí Jèhófà ṣẹ́gun Bábílónì tó jẹ́ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé! Ǹjẹ́ kí ayọ̀ wa máa pọ̀ gidigidi sí i bí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti ń sún mọ́lé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
b Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
c Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
d Tún wo Ìṣípayá 1:3; 14:13; 16:15.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 273]
“Ẹ̀písù sí Sódómù àti Gòmórà”
Àkòrí gàdàgbà tó wà lókè yìí wà nínú ìwé ìròyìn Daily Telegraph ti ìlú London tó jáde ní November 12, 1987. Lábẹ́ àkòrí yìí, ìwé ìròyìn náà sọ nípa àbá kan tó wà níwájú Ìgbìmọ̀ Gbogbo Gbòò Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti gbé yẹ̀ wò nínú ìpàdé wọn. Àbá náà ni pé kí wọ́n máa lé àwọn “Kristẹni” tó jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Akọ̀ròyìn Godfrey Barker sọ pé: “Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ìlú Canterbury fi ìbànújẹ́ sọ èrò rẹ̀ lánàá pé: ‘A lè bi ara wa pé, ká tiẹ̀ sọ pé Pọ́ọ̀lù Mímọ́ fẹ́ kọ ẹ̀písù kan sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, irú lẹ́tà wo ló máa jẹ́?’” Ọ̀gbẹ́ni Barker tó kọ̀ròyìn yìí fúnra rẹ̀ dáhùn pé: “Ẹ̀písù sí Sódómù àti Gòmórà ni yóò jẹ́,” ó wá fi kún un pé: “Dókítà Runcie [tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà] wòye pé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀písù náà á dà bí èyí tó wà ní Róòmù, Orí 1.”
Akọ̀ròyìn náà ṣàyọlò àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà ní Róòmù 1:26-32, tó kà pé: “Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó wà lọ́kàn wọn fún ìwà èérí. . . . Àwọn ọkùnrin ń ṣe àwọn ìṣe aláìnítìjú pẹ̀lú àwọn ọkùnrin . . . bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ òfin Ọlọ́run pé àwọn tí ń ṣe irúfẹ́ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹ fún ikú, síbẹ̀ kì í ṣe kìkì pé wọ́n ń ṣe wọn nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n fọwọ́ sí àwọn tí wọ́n sọ wọ́n dàṣà.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn tó wà lórí àga ìjókòó tó ń fetí sílẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù Mímọ́ wulẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àmọ́ àwọn tó wà lórí àga ìwàásù ni Dókítà Runcie ní lọ́kàn.”
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni bíṣọ́ọ̀bù àgbà náà ní lọ́kàn? Àwọn àkọlé gàdàgbà gàdàgbà inú ìwé ìròyìn Daily Mail ti London tó jáde ní October 22, 1987 kéde pé: “‘Tá a bá mú ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lò pọ̀ mẹ́ta, ọ̀kan nínú wọn máa jẹ́ àlùfáà’ . . . Tí wọ́n bá fi ṣe ohun tí wọ́n ń sọ pé kí wọ́n lé àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì, ‘àfi kí Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yáa kógbá sílé.’” Ìròyìn náà ṣàyọlò ọ̀rọ̀ “ẹni ọ̀wọ̀” akọ̀wé àgbà Ẹgbẹ́ Àwọn Kristẹni Obìnrin Tí Ń Bá Obìnrin Lò Pọ̀ àti Ọkùnrin Tí Ń Bá Ọkùnrin Lò Pọ̀, pé: “Bá a bá gba àbá yìí wọlé yóò run Ṣọ́ọ̀ṣì kanlẹ̀, Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ìlú Canterbury sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Tá a bá fojú bù ú, a gbà pé á tó ọgbọ̀n sí ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lò pọ̀. Àwọn sì ló jẹ́ alákitiyan jù lọ nínú àwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì.” Kò sí àní-àní pé ìdí kan tó mú kí iye àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì máa dín kù ni pé àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lò pọ̀ tí iye wọn ń pọ̀ sí i ló ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà, èyí sì ń rí àwọn kan lára nínú àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì.
Kí wá ni ìpinnu ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé gbogbo àwọn àlùfáà tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà, ìyẹn irínwó ó dín méjìlá [388] lára wọn (tàbí àlùfáà márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95] nínú ọgọ́rùn-ún), ló fara mọ́ ọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àbá yẹn le tó bẹ́ẹ̀. Ìwé ìròyìn The Economist tó jáde ní November 14, 1987 sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó ní: “Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lòdì sí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, àmọ́ kò lòdì sí i pátápátá. Lọ́sẹ̀ yìí, ìgbìmọ̀ gbogbo gbòò ṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn ìgbìmọ̀ aṣòfin Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ nípa sísọ pé ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bíi ti àgbèrè àti panṣágà. Ó ní ó kàn jẹ́ pé ‘kò dára tó ìbálòpọ̀ bíbójúmu tó máa ń wáyé láàárín tọkọtaya ni, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí fífi ara ẹni fúnni pátápátá.’” Nígbà tí ìwé ìròyìn The Economist ń fi hàn pé èrò Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ìlú Canterbury yàtọ̀ sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ láìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀ nínú Róòmù 1:26, 27, ó ṣe àyọlò ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó wá kọ gbólóhùn kan sísàlẹ̀ rẹ̀ pé, “Pọ́ọ̀lù Mímọ́ mọ ohun tó rò tó fi kọ ohun tó kọ.”
Jésù Kristi pẹ̀lú mọ ohun tóun rò, ó sì sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere. Ó sọ pé yóò “ṣeé fara dà fún ilẹ̀ Sódómù ní Ọjọ́ Ìdájọ́” jù fún àwọn onísìn tí wọn kò tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ òun. (Mátíù 11:23, 24) Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, ó lo àkànlò èdè tá à ń pè ní àbùmọ́ tàbí àsọrégèé láti fi hàn pé ohun tí àwọn aṣáájú ìsìn ti wọ́n kọ Ọmọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ṣe tilẹ̀ burú ju ohun tí àwọn ará Sódómù pàápàá ṣe lọ. Júúdà 7 sì sọ pé àwọn ará Sódómù wọ̀nyẹn bọ́ sábẹ́ “ìyà ìdájọ́ iná àìnípẹ̀kun,” tó túmọ̀ sí ìparun ayérayé. (Mátíù 25:41, 46) Ẹ ò wá rí i pé ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn tí wọ́n pera wọn ní aṣáájú Kristẹni á le gan-an! Afọ́jú ni wọ́n, wọ́n sì ń da agbo wọn tó jẹ́ afọ́jú kúrò lójú ọ̀nà ìwà rere ti Ìjọba Ọlọ́run lọ sí ọ̀nà ìwà ìbàjẹ́ ayé tó gbọ̀jẹ̀gẹ́ yìí. (Mátíù 15:14) Ohùn tó dún láti ọ̀run náà fi àìjáfara kéde nípa Bábílónì Ńlá tí í ṣe ìsìn èké pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:2, 4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 275]
Halelúyà mẹ́rin tí ń dún lọ rére lọ́run ń yin Jáà pé ó ti ṣẹ́gun Bábílónì Ńlá pátápátá