Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ẹní Bá Ń Ṣàníyàn Ò Nígbàgbọ́ Ni?
“A FÒFIN DE ṢÍṢÀNÍYÀN.” Lábẹ́ àkọlé yìí, pásítọ̀ kan tó gbáyé lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún kọ̀wé pé kì í ṣe pé kéèyàn máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tara burú nìkan ni àmọ́, “ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo gan-an ló jẹ́.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà tí alálàyé kan ń kọ̀wé nípa bíborí ìdààmú àti àníyàn, ó sọ pé: “Ṣíṣàníyàn ń fi hàn pé a ò gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.”
Orí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè, pé, “ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn” làwọn òǹkọ̀wé méjì yìí gbé ọ̀rọ̀ wọn kà. (Mátíù 6:25) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn lóde òní, a lè béèrè pé: Ṣó yẹ kí Kristẹni kan máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi nítorí pé ó ń ṣàníyàn? Béèyàn bá ń ṣàníyàn, ṣé olúwarẹ̀ ò nígbàgbọ́ ni?
Ọlọ́run Lóye Ipò Àìpé Wa
Bíbélì ò fi kọ́ni pé àìnígbàgbọ́ ló ń fa gbogbo àníyàn téèyàn bá ń ṣe. Níwọ̀n bá a ti ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” kò sí bá ò ṣe ní ṣàníyàn, bó ti wù ó kéré mọ́. (2 Tímótì 3:1) Àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ kojú àwọn àníyàn ojoojúmọ́ nítorí àìlera, ọjọ́ ogbó, àìríná àìrílò, gbọ́nmi-si omi-ò-to nínú ìdílé, ìwà ọ̀daràn àtàwọn ìṣòro mìíràn. Kódà, látijọ́, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kojú ọ̀pọ̀ ìbẹ̀rù àti àníyàn.
Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa Lọ́ọ̀tì. Ọlọ́run pàṣẹ fún un pé kó sá lọ síbi àwọn òkè ńlá kó má bàa kú nígbà tí òun bá pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Bí Lọ́ọ̀tì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn nìyẹn o. Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́, jọ̀wọ́, Jèhófà!” Ó ṣáà ń lọ́ tíkọ̀, ló bá tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ṣùgbọ́n èmi-èmi kò lè sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá kí ìyọnu àjálù má bàa sún mọ́ mi kí èmi sì kú.” Kí ló ń ba Lọ́ọ̀tì lẹ́rù níbi àwọn òkè ńlá? Bíbélì kò sọ fún wa. Ohun yòówù tí ì báà jẹ́, ó dájú pé ẹ̀rù tó ba Lọ́ọ̀tì kúrò ní kékeré. Kí ni Ọlọ́run wá ṣe? Ṣé ó tìtorí ẹ̀ bá Lọ́ọ̀tì wí pé kò gbẹ́kẹ̀ lé Òun? Ó tì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà gba ti Lọ́ọ̀tì rò, ó sì jẹ́ kó sá lọ sí ìlú kan nítòsí.—Jẹ́nẹ́sísì 19:18-22.
Àpẹẹrẹ àwọn olùjọsìn tòótọ́ mìíràn táwọn náà ti ṣàníyàn gidigidi rí wà nínú Bíbélì. Ẹ̀rù ba wòlíì Èlíjà ó sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ lẹ́yìn tó ti gbọ́ pé wọ́n fẹ́ pa òun. (1 Àwọn Ọba 19:1-4) Mósè, Hánà, Dáfídì, Hábákúkù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ìgbàgbọ́ wọ́n lágbára, làwọn náà tún ṣàníyàn. (Ẹ́kísódù 4:10; 1 Sámúẹ́lì 1:6; Sáàmù 55:5; Hábákúkù 1:2, 3; 2 Kọ́ríńtì 11:28) Síbẹ̀, Ọlọ́run fi àánú hàn sí wọn, ó ń bá a lọ láti máa lò wọ́n nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé yé òun dáadáa.
“Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Ó Máa Ń Wé Mọ́ Wa Pẹ̀lú Ìrọ̀rùn”
Bí àníyàn bá ti ń ṣe lemọ́lemọ́ jù, ó lè sọ ìgbàgbọ́ wa di aláìlágbára kí ìyẹn sì wá yọrí sí àìnígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe àìnígbàgbọ́ ní “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Hébérù 12:1) Nítorí pé Pọ́ọ̀lù ò yọ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló gbà pé ó ṣeé ṣe fóun náà láti dẹni tí ‘ẹ̀ṣẹ̀ wé mọ́’ bí ìgbàgbọ̀ òun bá ṣàdédé mì.
Bóyá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sekaráyà nìyẹn tí kò fi gba áńgẹ́lì tó sọ fún un pé ìyàwó ẹ̀ á lóyún gbọ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn àpọ́sítélì Jésù ò lè mú ẹnì kan lára dá nítorí “ìgbàgbọ́” wọn “tí ó kéré.” Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ṣì ń bá a nìṣó láti máa tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn wọ̀nyí.—Mátíù 17:18-20; Lúùkù 1:18, 20, 67; Jòhánù 17:26.
Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì tún fún wa lápẹẹrẹ àwọn èèyàn tí wọ́n ṣíwọ́ níní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run tí wọ́n sì jìyà nítorí ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ò yọ̀ǹda fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí nítorí àìnígbàgbọ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n sọ̀rọ̀ tààràtà lòdì sí Ọlọ́run pé: ‘Èé ṣe tó fi mú àwọn gòkè wá láti Íjíbítì láti kú ní aginjù? Nítorí kò sí oúnjẹ, kò sì sí omi.’ Ọlọ́run bínú sí wọn, ló bá rán àwọn ejò olóró láti lọ bù wọ́n ṣán.—Númérì 21:5, 6.
Àwọn ará Násárétì, ìyẹn ìlú Jésù, ò láǹfààní àtirí púpọ̀ sí i lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ì bá ti ṣe lágbègbè wọn nítorí pé wọn kò nígbàgbọ́. Ìyẹn nìkan wá kọ́ o, Jésù tún bá ìran èèyàn burúkú tó wà nígbà yẹn wí kíkankíkan nítorí àìnígbàgbọ́. (Mátíù 13:58; 17:17; Hébérù 3:19) Nítorí náà, ìkìlọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe wẹ́kú pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.”—Hébérù 3:12.
Òótọ́ ni pé nínú àwọn ọ̀ràn tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀, ọkàn-àyà tó bá burú ló máa ń fa àìnígbàgbọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ti Sekaráyà àtàwọn àpọ́sítélì Jésù nínú àwọn àpẹẹrẹ tá a ti mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀ o. Àìlera tó máa ń ṣàdédé wáyé ló fa àìnígbàgbọ́ tiwọn. Irú ìgbésí ayé tí wọ́n gbé látìbẹ̀rẹ̀ dópin fi hàn pé ẹni “mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà” ni wọ́n.—Mátíù 5:8.
Ọlọ́run Mọ Àwọn Ohun Tá A Ṣaláìní
Ìwé Mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àníyàn tó jẹ́ apá kan ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ àìnígbàgbọ́. Ṣíṣàníyàn lójoojúmọ́ tàbí àìnígbàgbọ́ tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí àìlera ẹ̀dá yàtọ̀ pátápátá sí kíkọ̀ jálẹ̀ láti ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run, èyí tó máa ń ti inú ọkàn-àyà burúkú, tó ti sébọ́ wá. Nítorí náà, kó yẹ kí ọkàn àwọn Kristẹni máa dá wọn lẹ́bi nígbà gbogbo ṣáá kìkì nítorí pé wọ́n máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Bí ọ̀ràn tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó gba ìṣọ́ra o, kí àníyàn má bàa bò wá mọ́lẹ̀ búrúbúrú débi tí yóò fi máa darí ìgbésí ayé wa. Nítorí náà, ọgbọ́n wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’” Lẹ́yìn ìyẹn ló wá sọ̀rọ̀ ìtùnú yìí pé: “Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:25-33.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn