Sáàmù
Ti Dáfídì.
א [Áléfì]
ב [Bétì]
ג [Gímélì]
6 Yóò mú kí òdodo rẹ yọ bí ọjọ́,
Àti ìwà títọ́ rẹ bí oòrùn ọ̀sán gangan.
ד [Dálétì]
Má banú jẹ́ nítorí ẹni
Tó gbèrò ibi, tó sì mú un ṣẹ.+
ה [Híì]
Wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀,
Wọn ò ní sí níbẹ̀.+
ז [Sáyìn]
12 Ẹni burúkú ń dìtẹ̀ olódodo;+
Ó ń wa eyín pọ̀ sí i.
13 Àmọ́ Jèhófà yóò fi í rẹ́rìn-ín,
Nítorí Ó mọ̀ pé ọjọ́ rẹ̀ máa dé.+
ח [Hétì]
14 Àwọn ẹni burúkú fa idà wọn yọ, wọ́n sì tẹ* ọrun wọn
Láti mú àwọn tí à ń ni lára àti àwọn aláìní balẹ̀,
Láti pa àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́.
15 Àmọ́ idà àwọn fúnra wọn yóò gún ọkàn wọn;+
A ó sì ṣẹ́ ọrun wọn.
ט [Tétì]
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní
Sàn ju ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn ẹni burúkú ní.+
17 A ó ṣẹ́ apá àwọn ẹni burúkú,
Àmọ́ Jèhófà yóò ti àwọn olódodo lẹ́yìn.
י [Yódì]
19 Ní àkókò àjálù, ojú kò ní tì wọ́n;
Ní àkókò ìyàn, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ.
כ [Káfì]
20 Àmọ́ àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé;+
Àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò pòórá bí ibi ìjẹko tó léwé dáadáa;
Wọ́n á pòórá bí èéfín.
ל [Lámédì]
22 Àwọn tí Ọlọ́run bù kún yóò jogún ayé,
Àmọ́ àwọn tí Ọlọ́run gégùn-ún fún yóò pa rẹ́.+
מ [Mémì]
נ [Núnì]
26 Ó máa ń yáni ní nǹkan látọkàn wá,+
Ìbùkún sì ń dúró de àwọn ọmọ rẹ̀.
ס [Sámékì]
27 Yẹra fún ohun búburú, máa ṣe rere,+
Wàá sì máa gbé ayé títí láé.
ע [Áyìn]
פ [Péè]
צ [Sádì]
32 Ẹni burúkú ń ṣọ́ olódodo,
Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
ק [Kófì]
34 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀,
Yóò gbé ọ ga láti jogún ayé.
Nígbà tí a bá pa àwọn ẹni burúkú rẹ́,+ wàá rí i.+
ר [Réṣì]
35 Mo ti rí ìkà ẹ̀dá tó jẹ́ olubi
Tó ń tẹ́ rẹrẹ bí igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ilẹ̀ tó dàgbà sí.+
ש [Ṣínì]
37 Máa fiyè sí aláìlẹ́bi,*
Kí o sì máa wo adúróṣinṣin,+
Nítorí àlàáfíà ń dúró de ẹni yẹn ní ọjọ́ ọ̀la.+
38 Àmọ́ a ó pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rẹ́,
Ìparun ló sì ń dúró de àwọn ẹni burúkú ní ọjọ́ ọ̀la.+
ת [Tọ́ọ̀]
40 Jèhófà á ràn wọ́n lọ́wọ́, á sì gbà wọ́n sílẹ̀.+
Á gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú, á sì gbà wọ́n là,
Nítorí òun ni wọ́n fi ṣe ibi ààbò.+