Jẹ́nẹ́sísì
45 Jósẹ́fù ò lè mú un mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀. Ló bá pariwo pé: “Kí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ mi!” Kò sẹ́nì kankan lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí Jósẹ́fù sọ bí òun ṣe jẹ́ fún àwọn arákùnrin+ rẹ̀.
2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, ohùn rẹ̀ sì lọ sókè débi pé àwọn ará Íjíbítì gbọ́, ilé Fáráò sì gbọ́. 3 Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù. Ṣé bàbá mi ṣì wà láàyè?” Àmọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ ò lè dá a lóhùn rárá, torí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu. 4 Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sún mọ́ mi.” Ni wọ́n bá sún mọ́ ọn.
Ó sọ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tí ẹ tà sí Íjíbítì.+ 5 Àmọ́ ẹ má banú jẹ́, ẹ má sì bínú sí ara yín torí pé ẹ tà mí síbí; torí Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là.+ 6 Ọdún kejì tí ìyàn náà ti mú káàkiri nìyí,+ ó ṣì ku ọdún márùn-ún tí wọn ò ní túlẹ̀, tí wọn ò sì ní kórè. 7 Àmọ́ Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín, kó lè mú kí ẹ ní àṣẹ́kù+ ní ayé,* kó sì gba ẹ̀mí yín là lọ́nà ìyanu. 8 Torí náà, ẹ̀yin kọ́ lẹ rán mi wá síbí, Ọlọ́run tòótọ́ ni, torí kó lè fi mí ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn* fún Fáráò, kó sì fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo ilé rẹ̀ àti olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+
9 “Ẹ tètè pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi, kí ẹ sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jósẹ́fù ọmọ rẹ sọ nìyí: “Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo Íjíbítì.+ Máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Tètè máa bọ̀.+ 10 Kí o máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ kí o lè wà nítòsí mi, ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ, àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti gbogbo ohun tí o ní. 11 Èmi yóò máa fún ọ ní oúnjẹ níbẹ̀, torí ó ṣì ku ọdún márùn-ún tí ìyàn+ á fi mú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ àti ilé rẹ máa di aláìní àti gbogbo ohun tí o ní.”’ 12 Ẹ̀yin àti Bẹ́ńjámínì àbúrò mi ti wá fojú ara yín rí i pé èmi gan-an ni mò ń bá yín sọ̀rọ̀.+ 13 Torí náà, kí ẹ sọ fún bàbá mi nípa gbogbo ògo tí mo ní nílẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ohun tí ẹ rí. Ó yá, ẹ tètè lọ mú bàbá mi wá síbí.”
14 Ó wá dì mọ́* Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, ó sì bú sẹ́kún, Bẹ́ńjámínì náà dì mọ́ ọn lọ́rùn,+ ó sì sunkún. 15 Ó wá fi ẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ń sunkún bó ṣe ń dì mọ́ wọn, lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀.
16 Ìròyìn dé ilé Fáráò pé: “Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ti dé!” Èyí dùn mọ́ Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú. 17 Fáráò wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ di ẹrù lé àwọn ẹran tí ẹ fi ń kẹ́rù, kí ẹ lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, 18 kí ẹ sì mú bàbá yín àti agbo ilé yín wá sọ́dọ̀ mi níbí. Màá fún yín ní àwọn ohun rere ilẹ̀ Íjíbítì, ẹ ó sì jẹ ohun tó dára jù* ní ilẹ̀ yìí.’+ 19 Mo sì pàṣẹ pé kí o sọ fún wọn pé:+ ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ kó àwọn kẹ̀kẹ́+ láti ilẹ̀ Íjíbítì torí àwọn ọmọ yín àti ìyàwó yín, kí ẹ sì fi ọ̀kan lára rẹ̀ gbé bàbá yín wá síbí.+ 20 Ẹ má da ara yín láàmú torí àwọn ohun ìní+ yín, torí ẹ̀yin lẹ ni gbogbo ohun tó dáa jù ní ilẹ̀ Íjíbítì.’”
21 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù fún wọn ní àwọn kẹ̀kẹ́ bí Fáráò ṣe pàṣẹ, ó tún fún wọn ní ohun tí wọ́n á jẹ lójú ọ̀nà. 22 Ó fún kálukú wọn ní aṣọ tuntun, àmọ́ ó fún Bẹ́ńjámínì ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ẹyọ fàdákà àti aṣọ+ tuntun márùn-ún. 23 Àwọn ohun tó fi ránṣẹ́ sí bàbá rẹ̀ nìyí: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ Íjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé ọkà àti búrẹ́dì àti ohun tí bàbá rẹ̀ máa jẹ lẹ́nu ìrìn àjò. 24 Ó wá ní kí àwọn arákùnrin rẹ̀ máa lọ, nígbà tí wọ́n sì ń lọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe bá ara yín jà lójú ọ̀nà.”+
25 Wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì dé ilẹ̀ Kénáánì lọ́dọ̀ Jékọ́bù bàbá wọn. 26 Wọ́n ròyìn fún un pé: “Jósẹ́fù ò tíì kú, ó ti di olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì!”+ Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ kò wọ Jékọ́bù lọ́kàn, torí kò gbà wọ́n gbọ́.+ 27 Nígbà tí wọ́n wá ń sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jósẹ́fù sọ fún wọn, tí Jékọ́bù sì wá rí àwọn kẹ̀kẹ́ tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ pé kí wọ́n fi gbé e, ara Jékọ́bù bàbá wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yá gágá. 28 Ísírẹ́lì sọ pé: “Ó tó! Jósẹ́fù ọmọ mi ò tíì kú! Mo gbọ́dọ̀ lọ rí i kí n tó kú!”+