Dáníẹ́lì
5 Ní ti Ọba Bẹliṣásárì,+ ó se àsè ńlá kan fún ẹgbẹ̀rún (1,000) àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, ó sì ń mu wáìnì níwájú wọn.+ 2 Nígbà tí wáìnì ń pa Bẹliṣásárì, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà tí Nebukadinésárì bàbá rẹ̀ kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá,+ kí ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, àwọn wáhàrì* rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ onípò kejì lè fi wọ́n mutí. 3 Wọ́n wá kó àwọn ohun èlò wúrà tí wọ́n kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì ilé Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá, ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, àwọn wáhàrì* rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ onípò kejì sì fi wọ́n mutí. 4 Wọ́n mu wáìnì, wọ́n sì yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi wúrà, fàdákà, bàbà, irin, igi àti òkúta ṣe.
5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ìka ọwọ́ èèyàn fara hàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé síbi tí wọ́n rẹ́ lára ògiri ààfin ọba níwájú ọ̀pá fìtílà, ọba sì ń rí ẹ̀yìn ọwọ́ náà bó ṣe ń kọ̀wé. 6 Ara ọba wá funfun,* èrò ọkàn rẹ̀ sì kó jìnnìjìnnì bá a, ìgbáròkó rẹ̀ mì,+ àwọn orúnkún rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá ara wọn.
7 Ọba ké jáde pé kí wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀.+ Ọba sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ka ọ̀rọ̀ yìí, tó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ̀ ọ́, a máa fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí i lọ́rùn,+ ó sì máa di igbá kẹta nínú ìjọba.”+
8 Gbogbo àwọn amòye ọba wá wọlé, àmọ́ wọn ò lè ka ọ̀rọ̀ náà, wọn ò sì lè sọ ohun tó túmọ̀ sí fún ọba.+ 9 Torí náà, ẹ̀rù ba Ọba Bẹliṣásárì gidigidi, ojú rẹ̀ sì funfun; ọ̀rọ̀ náà sì rú àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì lójú.+
10 Torí ohun tí ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì sọ, ayaba wọnú gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ń jẹ àsè. Ayaba sọ pé: “Kí ẹ̀mí ọba gùn títí láé. Má ṣe jẹ́ kí èrò rẹ kó jìnnìjìnnì bá ọ, má sì jẹ́ kí ojú rẹ funfun. 11 Ọkùnrin kan* wà nínú ìjọba rẹ tó ní ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́. Nígbà ayé bàbá rẹ, ó ní ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n, bí ọgbọ́n àwọn ọlọ́run.+ Ọba Nebukadinésárì, bàbá rẹ fi ṣe olórí àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀;+ ohun tí bàbá rẹ ṣe nìyí, ọba. 12 Torí Dáníẹ́lì, ẹni tí ọba pè ní Bẹtiṣásárì,+ ní ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye láti túmọ̀ àwọn àlá, láti ṣàlàyé àwọn àlọ́, kó sì wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.*+ Jẹ́ kí wọ́n pe Dáníẹ́lì wá, ó sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
13 Wọ́n wá mú Dáníẹ́lì wá síwájú ọba. Ọba bi Dáníẹ́lì pé: “Ṣé ìwọ ni Dáníẹ́lì, tí wọ́n mú nígbèkùn ní Júdà,+ tí bàbá mi ọba mú wá láti Júdà?+ 14 Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run wà nínú rẹ,+ o sì ní ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀.+ 15 Wọ́n mú àwọn amòye àti àwọn pidánpidán wá síwájú mi, kí wọ́n lè ka ọ̀rọ̀ yìí, kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, àmọ́ wọn ò lè sọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.+ 16 Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀,+ o sì lè wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.* Tí o bá lè ka ọ̀rọ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ̀ ọ́, a máa fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí ọ lọ́rùn, o sì máa di igbá kẹta nínú ìjọba.”+
17 Dáníẹ́lì wá dá ọba lóhùn pé: “Di àwọn ẹ̀bùn rẹ mú, kí o sì fi ta àwọn míì lọ́rẹ. Àmọ́ màá ka ọ̀rọ̀ náà fún ọba, màá sì sọ ohun tó túmọ̀ sí fún un. 18 Ní tìrẹ, ọba, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ gbé ìjọba fún Nebukadinésárì bàbá rẹ, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó sì fún un ní ògo àti ọlá ńlá.+ 19 Torí pé Ó jẹ́ kó di ẹni ńlá, gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ń gbọ̀n rìrì níwájú rẹ̀.+ Ó lè pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ tàbí kó dá a sí, ó sì lè gbé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ga tàbí kó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.+ 20 Àmọ́ nígbà tí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, tí ẹ̀mí rẹ̀ sì le, débi tó fi kọjá àyè rẹ̀,+ a rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀ látorí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, a sì gba iyì rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. 21 A lé e kúrò láàárín aráyé, a jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ dà bíi ti ẹranko, ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó. A fún un ní ewéko jẹ bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.+
22 “Àmọ́ ìwọ Bẹliṣásárì ọmọ rẹ̀, o ò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí o tiẹ̀ mọ gbogbo èyí. 23 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lo gbé ara rẹ ga sí Olúwa ọ̀run,+ o sì ní kí wọ́n kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ wá fún ọ.+ Ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ pàtàkì, àwọn wáhàrì rẹ àti àwọn ìyàwó rẹ onípò kejì wá fi wọ́n mu wáìnì, ẹ sì ń yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi fàdákà, wúrà, bàbà, irin, igi àti òkúta ṣe, àwọn ọlọ́run tí kò rí nǹkan kan, tí wọn ò gbọ́ nǹkan kan, tí wọn ò sì mọ nǹkan kan.+ Àmọ́ o ò yin Ọlọ́run tí èémí rẹ+ àti gbogbo ọ̀nà rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀. 24 Torí náà, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ọwọ́ náà ti wá, tó sì kọ ọ̀rọ̀ yìí.+ 25 Ohun tó kọ nìyí: MÉNÈ, MÉNÈ, TÉKÉLÍ àti PÁRÁSÍNÌ.
26 “Ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí nìyí: MÉNÈ, Ọlọ́run ti ka iye ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti fòpin sí i.+
27 “TÉKÉLÌ, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o ò kúnjú ìwọ̀n.
28 “PÉRÉSÌ, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà.”+
29 Bẹliṣásárì wá pàṣẹ, wọ́n sì fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ Dáníẹ́lì, wọ́n fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí i lọ́rùn; wọ́n sì kéde pé ó máa di igbá kẹta nínú ìjọba.+
30 Òru ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n pa Bẹliṣásárì, ọba àwọn ará Kálídíà.+ 31 Dáríúsì + ará Mídíà sì gba ìjọba; ọjọ́ orí rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọdún méjìlélọ́gọ́ta (62).