Ìsíkíẹ́lì
16 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ ohun ìríra tí Jerúsálẹ́mù ń ṣe fún un.+ 3 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún Jerúsálẹ́mù nìyí: “Ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì lo ti wá, ibẹ̀ ni wọ́n sì bí ọ sí. Ọmọ Ámórì+ ni bàbá rẹ, ọmọ Hétì+ sì ni ìyá rẹ. 4 Nígbà ìbí rẹ, ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ, wọn ò gé ìwọ́ rẹ, wọn ò fi omi wẹ̀ ọ́ kí ara rẹ lè mọ́, wọn ò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn ò sì fi aṣọ wé ọ. 5 Kò sẹ́ni tó káàánú rẹ débi tí wọ́n á ṣe ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí fún ọ. Kò sẹ́ni tó yọ́nú sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, pápá gbalasa ni wọ́n jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ* ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.
6 “‘“Nígbà tí mò ń kọjá lọ, mo rí ọ tí ò ń yí kiri nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, bí o sì ṣe wà níbẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ pé, ‘Máa wà láàyè!’ Àní mo sọ fún ọ bí o ṣe wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, ‘Máa wà láàyè!’ 7 Mo mú kí o pọ̀ níye, bí àwọn ewéko tó ń hù ní oko, o dàgbà, o lára, o sì wọ ohun ọ̀ṣọ́ tó dára jù. Àwọn ọmú rẹ yọ dáadáa, irun rẹ sì hù; àmọ́ o ṣì wà ní ìhòòhò.”’
8 “‘Nígbà tí mò ń kọjá lọ tí mo rí ọ, mo rí i pé o ti dàgbà tó ẹni tí wọ́n ń kọnu ìfẹ́ sí. Mo wá fi aṣọ* mi bò ọ́,+ mo fi bo ìhòòhò rẹ, mo búra, mo sì bá ọ dá májẹ̀mú,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘o sì di tèmi. 9 Mo tún fi omi wẹ̀ ọ́, mo ṣan ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára.+ 10 Mo wá fi aṣọ tí wọ́n kó iṣẹ́ sí wọ̀ ẹ́, mo fún ọ ní bàtà awọ* tó dáa, mo fi aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa wé ọ, mo sì wọ aṣọ olówó iyebíye fún ọ. 11 Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́, mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn. 12 Mo tún fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì dé ọ ládé tó rẹwà. 13 Ò ń fi wúrà àti fàdákà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, o wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, aṣọ olówó iyebíye àti aṣọ tí wọ́n kó iṣẹ́ sí. O jẹ ìyẹ̀fun tó kúnná, oyin àti òróró, o ti wá rẹwà gan-an,+ o sì ti yẹ láti di ayaba.’”*
14 “‘Òkìkí rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kàn* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ torí ẹwà rẹ, ẹwà rẹ kò lábùlà torí èmi ni mo dá ọ lọ́lá,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
15 “‘Àmọ́ ẹwà rẹ mú kí o bẹ̀rẹ̀ sí í jọ ara rẹ lójú,+ o sì di aṣẹ́wó torí òkìkí rẹ ti kàn káàkiri.+ Gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ lo bá ṣèṣekúṣe,+ ẹwà rẹ sì di tiwọn. 16 O mú lára àwọn ẹ̀wù rẹ, o sì ṣe àwọn ibi gíga aláràbarà tí o ti ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ Kò yẹ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé, kò tiẹ̀ yẹ kó ṣẹlẹ̀ rárá. 17 O tún mú ohun ọ̀ṣọ́ wúrà àti fàdákà tí mo fún ọ, o fi ṣe àwọn ère ọkùnrin fún ara rẹ, o sì bá wọn ṣèṣekúṣe.+ 18 O fi aṣọ rẹ tí wọ́n kó iṣẹ́ sí bò wọ́n,* o sì fi òróró àti tùràrí mi rúbọ sí wọn.+ 19 Búrẹ́dì tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná, òróró àti oyin ṣe tí mo fún ọ pé kí o jẹ, lo tún fi rúbọ olóòórùn dídùn* sí wọn.+ Ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan nìyẹn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
20 “‘O fi àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin tí o bí fún mi+ rúbọ sí àwọn òrìṣà.+ Ṣé ohun kékeré lo pe iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ò ń ṣe ni? 21 O pa àwọn ọmọ mi, o sì sun wọ́n nínú iná láti fi wọ́n rúbọ.+ 22 Bí o ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn ohun ìríra tí o sì ń ṣèṣekúṣe, o ò rántí ìgbà tí o ṣì kéré tí o sì wà ní ìhòòhò, tí ò ń yí kiri nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ. 23 O gbé, o gbé lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi rẹ,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 24 ‘O mọ òkìtì fún ara rẹ, o sì kọ́ ibi gíga fún ara rẹ ní gbogbo ojúde ìlú. 25 Ibi tó gbàfiyèsí jù ní gbogbo ojú ọ̀nà lo kọ́ àwọn ibi gíga rẹ sí, o sì sọ ẹwà rẹ di ohun ìríra bí o ṣe ń bá gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ ṣèṣekúṣe,*+ o sì wá jingíri sínú iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 26 O bá àwọn ọmọ Íjíbítì ṣèṣekúṣe,+ àwọn aládùúgbò rẹ oníṣekúṣe,* iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ tó bùáyà sì múnú bí mi. 27 Màá wá na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ọ́, màá dín oúnjẹ tí ò ń rí gbà kù,+ màá mú kí àwọn obìnrin tó kórìíra rẹ,+ àwọn ọmọbìnrin Filísínì, ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́* sí ọ, àwọn tí ìwà àìnítìjú rẹ ń rí lára.+
28 “‘Torí kò tẹ́ ọ lọ́rùn, o tún bá àwọn ọmọ Ásíríà ṣèṣekúṣe.+ Síbẹ̀ ìṣekúṣe tí o bá wọn ṣe yẹn kò tẹ́ ọ lọ́rùn. 29 O tún lọ ṣèṣekúṣe ní ilẹ̀ àwọn oníṣòwò* àti lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà,+ síbẹ̀, kò tẹ́ ọ lọ́rùn. 30 Wo bí àárẹ̀* ṣe mú ọkàn rẹ tó,’* ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘nígbà tí o ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, tí ò ń hùwà bí aṣẹ́wó tí kò nítìjú!+ 31 Àmọ́ nígbà tí o mọ òkìtì rẹ sí ibi tó gbàfiyèsí jù ní gbogbo ojú ọ̀nà, tí o sì kọ́ ibi gíga rẹ sí gbogbo ojúde ìlú, ìwọ ò dà bí aṣẹ́wó torí o ò gba owó kankan. 32 Alágbèrè obìnrin tó ń tẹ̀ lé àwọn àjèjì dípò ọkọ rẹ̀ ni ọ́!+ 33 Àwọn èèyàn ló máa ń fún aṣẹ́wó lẹ́bùn+ àmọ́ ìwọ lò ń fún gbogbo àwọn tó ń bá ọ ṣèṣekúṣe lẹ́bùn,+ o tún fún wọn ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè wá bá ọ ṣèṣekúṣe láti ibi gbogbo.+ 34 O yàtọ̀ sí àwọn obìnrin míì tó ń ṣe aṣẹ́wó. Kò sí ẹni tó ń ṣe aṣẹ́wó bíi tìẹ! Ò ń san owó fún àwọn ẹlòmíì, àwọn kò sì sanwó fún ọ. O yàtọ̀ sí wọn pátápátá.’
35 “Torí náà, gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ, ìwọ aṣẹ́wó.+ 36 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé ìṣekúṣe rẹ ti hàn sí gbangba, ìhòòhò rẹ sì ti hàn síta nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣèṣekúṣe, tí o sì ń bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* rẹ+ tó ń ríni lára ṣèṣekúṣe, àwọn tí o tún fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ rúbọ sí,+ 37 torí náà, èmi yóò kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ tí ẹ jọ gbádùn ara yín jọ, gbogbo àwọn tí o fẹ́ràn àti àwọn tí o kórìíra. Màá kó wọn jọ láti ibi gbogbo kí wọ́n lè bá ọ jà, màá sì tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, wọ́n á sì rí ìhòòhò rẹ.+
38 “‘Màá dá ọ lẹ́jọ́ tó tọ́ sí àwọn alágbèrè obìnrin+ àti àwọn obìnrin tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+ màá sì fi ìbínú àti owú ta ẹ̀jẹ̀ rẹ sílẹ̀.+ 39 Màá mú kí o kó sọ́wọ́ wọn, wọ́n á ya àwọn òkìtì rẹ lulẹ̀, wọ́n á sì wó àwọn ibi gíga rẹ;+ wọ́n á bọ́ aṣọ lára rẹ,+ wọ́n á gba ohun ọ̀ṣọ́ rẹ tó rẹwà,+ wọ́n á sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò. 40 Wọn yóò kó èrò jọ láti bá ọ jà,+ wọ́n á sọ ọ́ ní òkúta,+ wọ́n á sì fi idà wọn pa ọ́.+ 41 Wọn yóò dáná sun àwọn ilé rẹ,+ wọ́n á sì dá ọ lẹ́jọ́ níṣojú ọ̀pọ̀ obìnrin; èmi yóò fòpin sí iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ,+ o ò sì ní san owó fún wọn mọ́. 42 Màá bínú sí ọ débi tó máa tẹ́ mi lọ́rùn,+ mi ò wá ní bínú sí ọ mọ́;+ ìbínú mi á rọlẹ̀, ohun tí o ṣe ò sì ní dùn mí mọ́.’
43 “‘Torí pé o ò rántí ìgbà èwe rẹ,+ tí gbogbo ohun tí o ṣe yìí sì múnú bí mi, màá fi ìwà rẹ san ọ́ lẹ́san,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘o ò ní hùwà àìnítìjú, o ò sì ní ṣe ohun tó ń ríni lára mọ́.
44 “‘Wò ó! Gbogbo ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lówelówe yóò pa òwe yìí fún ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin rẹ̀ rí!”+ 45 Ọmọbìnrin ìyá rẹ ni ọ́, ẹni tó kórìíra ọkọ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Arábìnrin lo sì jẹ́ sí àwọn ọmọ ìyá rẹ lóbìnrin, àwọn tó kórìíra ọkọ àti àwọn ọmọ wọn. Ọmọ Hétì ni ìyá rẹ, ọmọ Ámórì+ sì ni bàbá rẹ.’”
46 “‘Samáríà ni ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin,+ tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin* ń gbé ní àríwá rẹ.*+ Sódómù+ sì ni àbúrò rẹ obìnrin, tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin ń gbé ní gúúsù rẹ.*+ 47 Kì í ṣe pé o rìn ní ọ̀nà wọn, tí o sì bá wọn ṣe àwọn ohun ìríra wọn nìkan ni, àmọ́ láàárín àkókò díẹ̀, ìwà ìbàjẹ́ tí ò ń hù nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ burú ju tiwọn lọ.+ 48 Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Sódómù arábìnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin kò ṣe ohun tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin ti ṣe. 49 Wò ó! Àṣìṣe tí Sódómù arábìnrin rẹ ṣe ni pé: Òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin+ gbéra ga,+ wọ́n ní oúnjẹ rẹpẹtẹ,+ ara tù wọ́n;+ síbẹ̀ wọn ò ran àwọn tí ìyà ń jẹ àti tálákà lọ́wọ́.+ 50 Wọn ò yéé gbéra ga,+ wọ́n sì ń ṣe ohun ìríra níṣojú mi,+ torí náà, mo rí i pé ó yẹ kí n mú wọn kúrò.+
51 “‘Ẹ̀ṣẹ̀ Samáríà+ kò tiẹ̀ tó ìdajì tìrẹ. Ṣe ni ohun ìríra tí ò ń ṣe ń pọ̀ sí i, débi pé gbogbo ohun ìríra tí ò ń ṣe mú kí àwọn arábìnrin rẹ dà bí olódodo.+ 52 Ó yẹ kí ojú tì ọ́ báyìí torí ìwà rẹ ti dá àwọn arábìnrin rẹ láre.* Torí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá ń ríni lára ju tiwọn lọ, òdodo wọn ju tìrẹ lọ. Ní báyìí, kí o tẹ́, kí ojú sì tì ọ́ torí o mú kí àwọn arábìnrin rẹ dà bí olódodo.’
53 “‘Èmi yóò kó àwọn ẹrú wọn jọ, àwọn ẹrú Sódómù àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin àti àwọn ẹrú Samáríà àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin; màá sì kó àwọn ẹrú tìrẹ náà jọ,+ 54 kí o lè tẹ́; kí ojú sì tì ọ́ torí ohun tí o ti ṣe, bí o ṣe mú kí ara tù wọ́n. 55 Àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, yóò pa dà sí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀, Samáríà àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin yóò pa dà sí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin yóò sì pa dà sí bí ẹ ṣe wà tẹ́lẹ̀.+ 56 Ní ọjọ́ tí o gbé ara rẹ ga, o ka Sódómù arábìnrin rẹ sí ẹni tí kò yẹ kí o máa sọ̀rọ̀ rẹ̀, 57 kó tó di pé ìwà burúkú rẹ hàn síta.+ Àwọn ọmọbìnrin Síríà àti àwọn tó wà ní agbègbè wọn wá ń kẹ́gàn rẹ, àwọn ọmọbìnrin Filísínì,+ àwọn tó yí ọ ká sì ń fi ọ́ ṣẹlẹ́yà. 58 O máa jìyà ìwà àìnítìjú rẹ àti àwọn ohun ìríra tí o ṣe,’ ni Jèhófà wí.”
59 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Ní báyìí, ohun tí o ṣe sí mi ni màá fi hùwà sí ọ,+ torí o fojú kéré ìbúra tí o ṣe ní ti pé o da májẹ̀mú mi.+ 60 Àmọ́ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nígbà èwe rẹ, màá sì bá ọ dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé.+ 61 Ìwọ yóò rántí ìwà rẹ, ojú á sì tì ọ́+ nígbà tí o bá gba àwọn arábìnrin rẹ, àwọn ẹ̀gbọ́n àti àwọn àbúrò rẹ, èmi yóò sì fi wọ́n fún ọ bí ọmọbìnrin, àmọ́ kì í ṣe torí májẹ̀mú rẹ.’
62 “‘Èmi yóò fìdí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá múlẹ̀; ìwọ yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà. 63 Nígbà tí mo bá dárí jì ọ́* láìka gbogbo ohun tí o ti ṣe sí,+ wàá rántí, ìtìjú ò sì ní jẹ́ kí o lè la ẹnu rẹ+ torí pé o ti tẹ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”