Diutarónómì
28 “Tí o bá ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́ délẹ̀délẹ̀, kí o lè máa rí i pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tó wà láyé+ lọ. 2 Gbogbo ìbùkún yìí máa jẹ́ tìrẹ, ó sì máa bá ọ,+ torí pé ò ń fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ:
3 “Ìbùkún ni fún ọ nínú ìlú, ìbùkún sì ni fún ọ nínú pápá.+
4 “Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ*+ rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ àtàwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ, ọmọ màlúù àti àgùntàn+ rẹ.
5 “Ìbùkún ni fún apẹ̀rẹ̀+ rẹ àti abọ́ tí o fi ń po nǹkan.+
6 “Ìbùkún ni fún ọ tí o bá wọlé, ìbùkún sì ni fún ọ tí o bá jáde.
7 “Jèhófà máa mú kí o ṣẹ́gun+ àwọn ọ̀tá rẹ tí wọ́n dìde sí ọ. Ọ̀nà kan ni wọ́n á gbà yọ sí ọ láti bá ọ jà, àmọ́ ọ̀nà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n á gbà sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ 8 Jèhófà máa pàṣẹ ìbùkún sórí àwọn ilé ìkẹ́rùsí+ rẹ àti gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé, ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tó fẹ́ fún ọ. 9 Jèhófà máa fi ọ́ ṣe èèyàn mímọ́ fún ara rẹ̀,+ bó ṣe búra fún ọ+ gẹ́lẹ́, torí pé ò ń pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, o sì ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. 10 Gbogbo èèyàn tó wà ní ayé á sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni wọ́n fi ń pè ọ́,+ wọ́n á sì máa bẹ̀rù rẹ.+
11 “Jèhófà máa mú kí o ní ọmọ tó pọ̀ rẹpẹtẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ.+ 12 Jèhófà máa ṣí ọ̀run, ilé ìkẹ́rùsí rẹ̀ tó dáa fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àkókò+ rẹ̀, kó sì bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. O máa yá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, àmọ́ kò ní sóhun tó máa mú kí o yá+ nǹkan. 13 Orí ni Jèhófà máa fi ọ́ ṣe, kò ní fi ọ́ ṣe ìrù; òkè+ lo máa wà, o ò ní sí nísàlẹ̀, tí o bá ń ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí pé kí o máa pa mọ́ kí o sì máa tẹ̀ lé. 14 Ẹ ò gbọ́dọ̀ yà kúrò nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ sì sìn wọ́n.+
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
16 “Ègún máa wà lórí rẹ nínú ìlú, ègún sì máa wà lórí rẹ nínú oko.+
17 “Ègún máa wà lórí apẹ̀rẹ̀+ rẹ àti lórí abọ́ tí o fi ń po nǹkan.+
18 “Ègún máa wà lórí àwọn ọmọ*+ rẹ, èso ilẹ̀ rẹ, ọmọ màlúù àti àgùntàn+ rẹ.
19 “Ègún máa wà lórí rẹ tí o bá wọlé, ègún sì máa wà lórí rẹ tí o bá jáde.
20 “Jèhófà máa mú kí ègún bá ọ, kí nǹkan dà rú fún ọ, kí ìyà sì jẹ ọ́ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé títí o fi máa pa run, tí o sì máa yára ṣègbé, torí ìwà búburú tí ò ń hù àti torí pé o pa mí tì.+ 21 Jèhófà máa mú kí àrùn ṣe ọ́ títí ó fi máa pa ọ́ run ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+ 22 Jèhófà máa fi ikọ́ ẹ̀gbẹ kọ lù ọ́, pẹ̀lú akọ ibà,+ ara wíwú, ara gbígbóná, idà,+ ooru tó ń jó nǹkan gbẹ àti èbíbu;+ wọ́n á sì bá ọ títí o fi máa ṣègbé. 23 Ojú ọ̀run tó wà lókè orí rẹ máa di bàbà, ilẹ̀ tó sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ máa di irin.+ 24 Jèhófà máa sọ òjò ilẹ̀ rẹ di nǹkan lẹ́búlẹ́bú àti eruku tí á máa kù sórí rẹ láti ọ̀run títí o fi máa pa run. 25 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá+ rẹ ṣẹ́gun rẹ. Ọ̀nà kan lo máa gbà yọ sí wọn láti bá wọn jà, àmọ́ ọ̀nà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo máa gbà sá kúrò lọ́dọ̀ wọn; o sì máa di ohun àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba+ ayé. 26 Òkú rẹ á di oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àtàwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+
27 “Jèhófà máa fi eéwo ilẹ̀ Íjíbítì kọ lù yín, pẹ̀lú jẹ̀díjẹ̀dí, ifo àti àwúfọ́, èyí tí kò ní ṣeé wò sàn. 28 Jèhófà máa mú kí o ya wèrè, kí o fọ́jú,+ kí nǹkan sì dà rú fún ọ.* 29 Wàá máa táràrà kiri ní ọ̀sán gangan, bí afọ́jú ṣe máa ń táràrà torí ó wà lókùnkùn,+ o ò sì ní ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe; wọ́n á máa lù ọ́ ní jìbìtì, wọ́n á sì máa jà ọ́ lólè léraléra, kò ní sẹ́ni tó máa gbà ọ́ sílẹ̀.+ 30 O máa fẹ́ obìnrin sọ́nà, àmọ́ ọkùnrin míì á fipá bá a lò pọ̀. O máa kọ́ ilé, àmọ́ o ò ní gbé ibẹ̀.+ O máa gbin àjàrà, àmọ́ o ò ní rí i lò.+ 31 Wọ́n á pa akọ màlúù rẹ níṣojú rẹ, àmọ́ o ò ní fi ẹnu kàn án rárá. Wọ́n á jí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ níṣojú rẹ, àmọ́ kò ní pa dà sọ́dọ̀ rẹ. Wọ́n á kó àwọn àgùntàn rẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ, àmọ́ ẹnì kankan ò ní gbà ọ́ sílẹ̀. 32 Wọ́n á fún àwọn èèyàn míì+ ní àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin rẹ níṣojú rẹ, àárò wọn á máa sọ ẹ́ nígbà gbogbo, àmọ́ o ò ní rí nǹkan kan ṣe sí i. 33 Àwọn èèyàn tí o kò mọ̀+ ló máa jẹ èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Wọ́n á máa lù ọ́ ní jìbìtì, wọ́n á sì máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ nígbà gbogbo. 34 Ohun tí ojú rẹ bá rí máa dà ọ́ lórí rú.
35 “Jèhófà máa fi eéwo tó ń roni lára, tí kò sì ṣeé wò sàn kọ lù ọ́ ní orúnkún àti ẹsẹ̀ rẹ, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ. 36 Jèhófà máa lé ìwọ àti ọba tí o bá fi jẹ lórí ara rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀,+ o sì máa sin àwọn ọlọ́run míì níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta+ ṣe. 37 O máa di ohun tó ń dẹ́rù bani, ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo àwọn tí Jèhófà bá lé ọ lọ bá.+
38 “Irúgbìn púpọ̀ lo máa kó lọ sí oko, àmọ́ díẹ̀+ lo máa rí kó jọ, torí pé eéṣú máa jẹ ẹ́ run. 39 O máa gbin àjàrà, o sì máa roko rẹ̀, àmọ́ o ò ní rí wáìnì mu, o ò sì ní rí nǹkan kan+ kó jọ, torí kòkòrò mùkúlú ló máa jẹ ẹ́. 40 Igi ólífì máa wà ní gbogbo ilẹ̀ rẹ, àmọ́ o ò ní rí òróró fi para, torí pé àwọn ólífì rẹ máa rẹ̀ dà nù. 41 O máa bí ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àmọ́ wọn ò ní jẹ́ tìẹ mọ́, torí wọ́n máa kó wọn lẹ́rú.+ 42 Ọ̀wọ́ àwọn kòkòrò* máa bo gbogbo igi àtàwọn èso ilẹ̀ rẹ. 43 Ọwọ́ àjèjì tó wà láàárín rẹ á máa ròkè ju tìẹ lọ ṣáá, àmọ́ ṣe ni ìwọ á máa rẹlẹ̀ sí i. 44 Ó máa yá ọ ní nǹkan, àmọ́ ìwọ ò ní yá a+ ní ohunkóhun. Òun ló máa di orí, ìwọ á sì di ìrù.+
45 “Ó dájú pé gbogbo ègún+ yìí máa wá sórí rẹ, ó máa tẹ̀ lé ọ, ó sì máa bá ọ, títí o fi máa pa run,+ torí pé o ò tẹ̀ lé àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó pa láṣẹ+ fún ọ, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀. 46 Kò ní kúrò lórí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, ó máa jẹ́ àmì àti ìkìlọ̀+ tó máa wà títí láé, 47 torí o ò fi ìdùnnú àti ayọ̀ tó wá látọkàn sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ nígbà tí o ní ohun gbogbo ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 48 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ dìde sí ọ, o sì máa sìn+ wọ́n tòun ti ebi+ àti òùngbẹ, láìsí aṣọ gidi lọ́rùn rẹ àti láìní ohunkóhun. Ó máa fi àjàgà irin sí ọ lọ́rùn títí ó fi máa pa ọ́ run.
49 “Jèhófà máa gbé orílẹ̀-èdè kan tó wà lọ́nà jíjìn+ dìde sí ọ, láti ìkángun ayé; ó máa kì ọ́ mọ́lẹ̀ bí ẹyẹ idì+ ṣe ń ṣe, orílẹ̀-èdè tí o ò ní gbọ́+ èdè rẹ̀, 50 orílẹ̀-èdè tí ojú rẹ̀ le gan-an, tí kò ní wo ojú arúgbó, tí kò sì ní ṣojúure sí àwọn ọmọdé.+ 51 Wọ́n á jẹ àwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ títí wọ́n fi máa pa ọ́ run. Wọn ò ní ṣẹ́ ọkà kankan kù fún ọ àti wáìnì tàbí òróró tuntun, ọmọ màlúù tàbí àgùntàn, títí wọ́n fi máa pa ọ́ run.+ 52 Wọ́n máa dó tì ọ́, wọ́n máa sé ọ mọ́ inú gbogbo ìlú* rẹ, jákèjádò ilẹ̀ rẹ títí àwọn ògiri rẹ tó ga, tí o fi ṣe odi tí o gbẹ́kẹ̀ lé fi máa wó lulẹ̀. Àní ó dájú pé wọ́n máa dó tì ọ́ nínú gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ.+ 53 O sì máa wá jẹ àwọn ọmọ* rẹ, ẹran ara àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ, torí bí nǹkan ṣe máa le tó nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti torí wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá ọ.
54 “Ọkùnrin tí kò lágbaja rárá, tó sì lójú àánú láàárín rẹ kò tiẹ̀ ní ṣàánú arákùnrin rẹ̀ tàbí ìyàwó rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ́ kù, 55 kò sì ní fún wọn ní ìkankan lára ẹran ara àwọn ọmọ rẹ̀ tó máa jẹ, torí kò ní nǹkan kan mọ́ nítorí bí àwọn ọ̀tá ṣe dó tì ọ́ àti bí wàhálà tí wọ́n kó bá àwọn ìlú+ rẹ ṣe pọ̀ tó. 56 Obìnrin tí kò lágbaja tó sì lójú àánú láàárín rẹ, tí kò tiẹ̀ ní ronú rárá láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ kanlẹ̀ torí pé kò lágbaja+ kò ní ṣàánú ọkọ rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀, 57 àní kò ní ṣàánú àwọn ohun tó jáde láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lẹ́yìn tó bímọ àtàwọn ọmọ tó bí. Ó máa jẹ wọ́n níkọ̀kọ̀ torí bí nǹkan ṣe máa le nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá àwọn ìlú rẹ.
58 “Tí o ò bá rí i pé o tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin tí wọ́n kọ sínú ìwé+ yìí, tí o ò sì bẹ̀rù orúkọ+ ológo, tó ń bani lẹ́rù yìí tí Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ ní, 59 Jèhófà máa mú kí àwọn àrùn tó le gan-an ṣe ìwọ àti ọmọ rẹ, àwọn ìyọnu+ tó lágbára gan-an tí kò sì ní lọ bọ̀rọ̀, pẹ̀lú àwọn àìsàn tó le gan-an tí kò sì ní lọ bọ̀rọ̀. 60 Ó máa mú gbogbo àìsàn Íjíbítì tí ò ń bẹ̀rù pa dà wá sórí rẹ, ó sì dájú pé wọn ò ní fi ọ́ sílẹ̀. 61 Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún máa mú gbogbo àìsàn tàbí àrùn tí wọn ò kọ sínú ìwé Òfin yìí wá sórí rẹ títí o fi máa pa run. 62 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ti pọ̀ rẹpẹtẹ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ ìwọ̀nba ló máa ṣẹ́ kù+ lára rẹ, torí pé o ò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
63 “Bí inú Jèhófà ṣe dùn nígbà kan láti mú kí nǹkan máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni inú Jèhófà ṣe máa dùn láti pa yín run kó sì pa yín rẹ́; ẹ sì máa pa run kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.
64 “Jèhófà máa tú ọ ká sáàárín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti ìkángun kan ayé dé ìkángun kejì ayé,+ o sì máa ní láti sin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀.+ 65 Ọkàn rẹ ò ní balẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ yẹn, àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ ò sì ní rí ibi ìsinmi. Dípò ìyẹn, Jèhófà máa mú kí o kó ọkàn sókè,+ ojú rẹ á di bàìbàì, ìrẹ̀wẹ̀sì*+ á sì bá ọ níbẹ̀. 66 Ẹ̀mí rẹ máa wà nínú ewu ńlá, ẹ̀rù á máa bà ọ́ tọ̀sántòru, kò sì ní dá ọ lójú pé wàá rí ìgbàlà. 67 Ní àárọ̀, wàá sọ pé, ‘Ì bá dáa ká ní alẹ́ la wà!’ tó bá sì di alẹ́, wàá sọ pé, ‘Ì bá dáa ká ní àárọ̀ la wà!’ nítorí ìpayà tó máa bá ọkàn rẹ àti nítorí ohun tí ojú rẹ máa rí. 68 Ó dájú pé Jèhófà máa fi ọkọ̀ ojú omi gbé ọ pa dà wá sí Íjíbítì, ní ọ̀nà tí mo sọ fún ọ pé, ‘O ò ní rí i mọ́ láé,’ ẹ sì máa fẹ́ ta ara yín níbẹ̀ fún àwọn ọ̀tá yín pé kí wọ́n fi yín ṣe ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, àmọ́ kò ní sẹ́ni tó máa rà yín.”