Ẹ́sírà
1 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé:
2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà. 3 Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́, òun ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ilé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù.* 4 Àjèjì èyíkéyìí ní ilẹ̀ yìí,+ níbikíbi tó bá wà, kí àwọn aládùúgbò rẹ̀* ràn án lọ́wọ́, kí wọ́n fún un ní fàdákà àti wúrà, àwọn ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọ́run tòótọ́+ tó wà ní Jerúsálẹ́mù.’”
5 Nígbà náà, àwọn olórí agbo ilé Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn gbogbo ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ ta ẹ̀mí rẹ̀ jí, múra láti lọ tún ilé Jèhófà kọ́, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù. 6 Gbogbo àwọn tó wà láyìíká wọn tì wọ́n lẹ́yìn,* wọ́n fún wọn ní àwọn nǹkan èlò fàdákà àti ti wúrà, àwọn ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣeyebíye, yàtọ̀ sí gbogbo ọrẹ àtinúwá.
7 Ọba Kírúsì tún kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà jáde, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù, tó sì kó sínú ilé ọlọ́run rẹ̀.+ 8 Kírúsì ọba Páṣíà kó wọn jáde lábẹ́ àbójútó Mítírédátì, ẹni tó ń tọ́jú ìṣúra, ó sì ka iye wọn fún Ṣẹṣibásà*+ ìjòyè Júdà.
9 Iye wọn nìyí: ọgbọ̀n (30) ohun èlò tó rí bí apẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ohun èlò tó rí bí apẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ohun èlò mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) míì,* 10 ọgbọ̀n (30) abọ́ kékeré tí wọ́n fi wúrà ṣe, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́wàá (410) abọ́ kékeré tí wọ́n fi fàdákà ṣe àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) nǹkan èlò míì. 11 Gbogbo àwọn nǹkan èlò wúrà àti ti fàdákà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (5,400). Gbogbo nǹkan yìí ni Ṣẹṣibásà kó wá nígbà tí wọ́n kó àwọn tó wà nígbèkùn+ kúrò ní Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù.