Àìsáyà
48 Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +
Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+
Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+
2 Torí wọ́n ń fi ìlú mímọ́+ pe ara wọn,
Wọ́n sì ń wá ìtìlẹyìn Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+
Tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
3 “Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti sọ àwọn ohun àtijọ́* fún ọ.
Wọ́n ti ẹnu mi jáde,
Mo sì jẹ́ kó di mímọ̀.+
Mo gbé ìgbésẹ̀ lójijì, wọ́n sì ṣẹlẹ̀.+
4 Torí mo mọ bí o ṣe lágídí tó,
Pé irin ni iṣan ọrùn rẹ àti pé bàbà ni iwájú orí rẹ,+
5 Mo sọ fún ọ tipẹ́tipẹ́.
Kó tó ṣẹlẹ̀, mo mú kí o gbọ́ ọ,
Kí o má bàa sọ pé, ‘Òrìṣà mi ló ṣe èyí,
Ère gbígbẹ́ mi àti ère onírin* mi ló pa á láṣẹ.’
6 Ẹ ti gbọ́, ẹ sì ti rí gbogbo èyí.
Ṣé ẹ ò ní kéde rẹ̀ ni?+
Láti ìsinsìnyí lọ, màá kéde àwọn ohun tuntun fún ọ,+
Àwọn àṣírí tí mo pa mọ́, tí o kò mọ̀.
7 A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá wọn ni, kì í ṣe látìgbà àtijọ́,
Àwọn ohun tí o ò gbọ́ rí kó tó di òní,
Kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.’
9 Àmọ́ nítorí orúkọ mi, mi ò ní bínú mọ́;+
Nítorí ìyìn mi, màá kó ara mi níjàánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ,
Mi ò sì ní pa ọ́ run.+
10 Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, àmọ́ kì í ṣe bíi ti fàdákà.+
Mo ti dán ọ wò* nínú iná ìléru ti ìyà, tí a fi ń yọ́ nǹkan.+
Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì.*
12 Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè,
Ẹnì kan náà ni mí.+ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́; èmi náà ni ẹni ìkẹyìn.+
Tí mo bá pè wọ́n, wọ́n jọ máa dìde.
14 Gbogbo yín, ẹ kóra jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀.
Ta ni nínú wọn ló kéde àwọn nǹkan yìí?
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+
15 Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pè é.+
Mo ti mú un wá, ọ̀nà rẹ̀ sì máa yọrí sí rere.+
16 Ẹ sún mọ́ mi, kí ẹ sì gbọ́ èyí.
Láti ìbẹ̀rẹ̀, mi ò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀.+
Látìgbà tó ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.”
Ní báyìí, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti rán mi àti* ẹ̀mí rẹ̀.
17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,
Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,*+
Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+
18 Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni!+
A ò ní pa orúkọ wọn rẹ́ tàbí ká pa á run kúrò níwájú mi láé.”
Ẹ fi igbe ayọ̀ polongo rẹ̀! Ẹ kéde rẹ̀!+
Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ dé àwọn ìkángun ayé.+
Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ rà.+
21 Òùngbẹ ò gbẹ wọ́n nígbà tó mú wọn gba àwọn ibi tó ti pa run.+
Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta fún wọn;
Ó la àpáta, ó sì mú kí omi rọ́ jáde.”+