ORÍ KẸSÀN-ÁN
Máa Bá Àwọn Ẹlòmíràn Lò Lọ́nà Tí Ọlọ́run Fẹ́
1-3. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó wá sọ́kàn ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n bá gbọ́ orúkọ ìlú Tírè ayé ọjọ́un? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Hírámù Ọba gbà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò. (d) Kí ló máa dára ká ronú lé nípa Tírè?
TÓ O bá gbọ́ orúkọ ìlú Tírè ayé ọjọ́un, kí ló máa wá sọ́kàn rẹ? Ohun tó máa wá sọ́kàn ọ̀pọ̀ Kristẹni ni bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe nímùúṣẹ nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá kó àwókù ìlú Tírè tó jẹ́ èbúté, ìyẹn èyí tó wà létí omi, tó wá fi ṣe ọ̀nà lọ sí ìlú Tírè kejì tó jẹ́ erékùṣù, ìyẹn èyí tó wà láàárín omi, tó sì pa á run. (Ìsíkíẹ́lì 26:4, 12; Sekaráyà 9:3, 4) Àmọ́, tó o bá gbọ́ orúkọ ìlú yìí, ṣé ó máa mú kó o ronú nípa bó ṣe yẹ kó o máa bá àwọn ará àtàwọn mìíràn lò àti bí kò ṣe yẹ kó o máa ṣe sí wọn?
2 Kí nìdí tí ìlú Tírè fi pa run? Ìwé wòlíì Ámósì sọ ìdí rẹ̀ fún wa, ó ní: “Ní tìtorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Tírè, . . . ní tìtorí fífi tí wọ́n fi odindi ẹgbẹ́ àwọn ìgbèkùn lé Édómù lọ́wọ́, àti nítorí pé wọn kò rántí májẹ̀mú àwọn arákùnrin. Èmi yóò sì rán iná sí ògiri Tírè dájúdájú.” (Ámósì 1:9, 10) Nígbà láéláé, Hírámù ọba Tírè ṣe Dáfídì lóore ó sì fún Sólómọ́nì ní àwọn ohun èlò láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì. Sólómọ́nì bá Hírámù dá májẹ̀mú ó sì fún un ní ìlú ńlá-ńlá ní Gálílì. Kódà, Hírámù pe Sólómọ́nì ní “arákùnrin mi.” (1 Àwọn Ọba 5:1-18; 9:10-13, 26-28; 2 Sámúẹ́lì 5:11) Àmọ́ nígbà tí Tírè “kò rántí májẹ̀mú àwọn arákùnrin” tó sì ta àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́rú, Jèhófà kíyè sí ọ̀nà tó gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò yìí.
3 Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ àwọn ará Kénáánì tó ń gbé ní Tírè nítorí pé wọ́n fi ìwà ìkà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò? Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tá a rí kọ́ jẹ́ nípa ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lò. Ní àwọn orí kan tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ kọjá nínú ìwé yìí, a rí ohun táwọn wòlíì méjìlá náà sọ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa bá àwọn ẹlòmíràn lò, bí àpẹẹrẹ, ká jẹ́ ẹni tí kì í rẹni jẹ nídìí òwò, ká sì mọ́ níwà. Àmọ́, àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí tún fi àwọn nǹkan mìíràn hàn nípa bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa bá àwọn ẹlòmíràn lò.
MÁ ṢE FI ÌPỌ́NJÚ ẸLÒMÍRÀN ṢE OHUN ÀRÍDUNNÚ
4. Báwo làwọn ọmọ Édómù ṣe jẹ́ “arákùnrin” Ísírẹ́lì, àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe bá “arákùnrin” wọn lò?
4 O lè rí ẹ̀kọ́ kan kọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìdálẹ́bi tí Ọlọ́run sọ sí Édómù tó jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tó wà nítòsí Ísírẹ́lì. Ìdálẹ́bi ọ̀hún ni pé: “Kò . . . yẹ kí o máa wo ìran náà ní ọjọ́ arákùnrin rẹ, ní ọjọ́ àgbákò ibi rẹ̀; kò sì yẹ kí o máa yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣègbé lọ.” (Ọbadáyà 12) Àwọn ará Tírè lè jẹ́ “arákùnrin” Ísírẹ́lì nítorí òwò tó dà wọ́n pọ̀, àmọ́ kì í ṣe òwò ló mú káwọn ọmọ Édómù jẹ́ “arákùnrin” Ísírẹ́lì, nítorí pé ìbejì ni Ísọ̀ baba ńlá wọn àti Jékọ́bù baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kódà Jèhófà pe àwọn ọmọ Édómù ní “arákùnrin” Ísírẹ́lì. (Diutarónómì 2:1-4) Nítorí náà, ó dájú pé ìkórìíra ló mú káwọn ọmọ Édómù yọ̀ lọ́jọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kàgbákò lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì.—Ìsíkíẹ́lì 25:12-14.
5. Ní irú àwọn ipò wo ló ti ṣeé ṣe ká ṣe bíi tàwọn ọmọ Édómù?
5 Ó hàn gbangba pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí àwọn ọmọ Édómù ṣe sí àwọn Júù arákùnrin wọn. Nítorí náà, a lè bi ara wa pé, ‘Kí ni Ọlọ́run á rí tó bá ṣàyẹ̀wò bí mo ṣe ń bá àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lò?’ Ohun kan tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni ojú tá a fi máa ń wo àwọn ará wa àti bá a ṣe máa ń ṣe sí wọn tí nǹkan ò bá lọ déédéé fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wò ó pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣe nǹkan kan tó dùn ọ́ tàbí pé aáwọ̀ wà láàárín òun àti ìbátan rẹ kan. Tó o bá ní “ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí” arákùnrin tàbí arábìnrin náà, ṣé ńṣe ni wàá fi ìbínú sínú, tí o kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ náà kó o sì gbìyànjú láti yanjú rẹ̀? (Kólósè 3:13; Jóṣúà 22:9-30; Mátíù 5:23, 24) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á nípa lórí bó o ṣe ń ṣe sí onítọ̀hún; o ò ní ṣọ̀yàyá sí i mọ́, o ò ní fẹ́ wà níbi tó bá wà, o sì lè máa sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa rẹ̀. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o ṣe kọjá ìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé onítọ̀hún ṣe àṣemáṣe, kódà tí àṣìṣe náà gba pé káwọn alàgbà ìjọ tọ́ ọ sọ́nà tàbí kí wọ́n bá a wí. (Gálátíà 6:1) Ǹjẹ́ inú rẹ á dùn bíi tàwọn ọmọ Édómù nítorí pé ẹni náà kó sínú ìṣòro? Báwo ni Ọlọ́run á ṣe fẹ́ kó o ṣe tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?
6. Kí ni Míkà 7:18 dábàá pé ká ṣe, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tí Sekaráyà 7:10 mẹ́nu kàn?
6 Jèhófà ní kí Sekaráyà sọ ohun tóun ń fẹ́, pé ká ‘má ṣe pète-pèrò nǹkan búburú sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ọkàn wa.’ (Sekaráyà 7:9, 10; 8:17) A lè fi èyí sílò nígbà tó bá dà bíi pé ará wa kan ti ṣẹ̀ wá tàbí ṣẹ ìbátan wa kan. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó rọrùn láti ‘gbèrò ohun búburú nínú ọkàn wa’ ká sì fi hàn nínú ìṣe wa. Àmọ́, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká fara wé àpẹẹrẹ rere òun. Sì rántí pé Míkà kọ̀wé pé Jèhófà ‘ń dárí ìrélànàkọjá jì, ó sì ń ré ìṣìnà kọjá.’a (Míkà 7:18) Àwọn ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà fi ìyẹn sílò?
7. Kí nìdí tá a fi lè pinnu pé ńṣe la óò gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ṣẹ̀ wá?
7 Ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa tàbí sí ìbátan wa lè dùn wá, àmọ́ ká sòótọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ lohun náà ṣe burú tó ni? Bíbélì sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè, kódà ẹ̀ṣẹ̀ tí ará wa kan bá ṣẹ̀ wá. Síbẹ̀, ohun tó ti dáa jù ni pé kéèyàn gbójú fo ohun tẹ́ni náà ṣe, kéèyàn ‘ré ìṣìnà kọjá.’ Bi ara rẹ pé: ‘Àbí ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìgbà àádọ́rin lé méje tó yẹ kí n dárí jì í? Mi ò ṣe kúkú gbàgbé ohun tó ṣe fún mi?’ (Mátíù 18:15-17, 21, 22) Tó bá sì dà bíi pé nǹkan ńlá lohun tó ṣe fún wa náà nísinsìnyí, ṣé ó ṣì máa jẹ́ nǹkan ńlá ní ẹgbẹ̀rún ọdún sákòókò yìí? Kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan látinú ohun tí Oníwàásù 5:20 sọ nípa òṣìṣẹ́ tó ń gbádùn oúnjẹ àtohun mímu. Ẹsẹ náà ní: “Kì í ṣe ìgbà gbogbo ni yóò máa rántí àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ mú ọwọ́ rẹ̀ dí pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà rẹ̀.” Bí ọkùnrin yẹn ṣe fọkàn rẹ̀ sí ohun tó ń gbádùn lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe kó gbàgbé àwọn ìṣòro tó ní nígbèésí ayé. Ǹjẹ́ àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀? Tá a bá fọkàn wa sí ayọ̀ tá à ń rí nínú ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti gbàgbé àwọn ọ̀ràn tí kò lè wà pẹ́, tí a kò ní rántí nínú ayé tuntun. Dájúdájú, èyí dára ó sì yàtọ̀ sí kéèyàn máa yọ̀ nítorí ìṣòro ẹlòmíràn tàbí kéèyàn máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ṣẹ̀ ẹ́.
MÁA SỌ ÒTÍTỌ́ FÁWỌN ẸLÒMÍRÀN
8. Ìṣòro wo la lè ní tó bá di ọ̀ràn pé ká máa sọ òtítọ́?
8 Àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà tún tẹnu mọ́ bó ṣe wu Ọlọ́run tó pé ká máa fòtítọ́ bá àwọn ẹlòmíràn lò. Òótọ́ ni pé à ń lo ara wa tokuntokun láti sọ “òtítọ́ ìhìn rere” fáwọn èèyàn. (Kólósè 1:5; 2 Kọ́ríńtì 4:2; 1 Tímótì 2:4, 7) Àmọ́ ó lè túbọ̀ ṣòro láti máa ṣòótọ́ nígbà gbogbo bá a ṣe ń bá àwọn ẹbí wa àtàwọn ará wa sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ lórí onírúurú nǹkan. Kí nìdí tó fi lè ṣòro?
9. Ìgbà wo ló lè ṣe wá bíi pé ká má sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́, àmọ́ kí ló yẹ ká bi ara wa?
9 Ǹjẹ́ a rẹ́nì kan nínú wa tí kò sọ̀rọ̀ burúkú rí tàbí kó ṣe nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó tó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n sọ fún un ló tó mọ̀? Nígbà tá a bá sì mọ̀, ó ṣeé ṣe kójú tì wá tàbí ká rí i pé a jẹ̀bi. Ìyẹn lè mú ká sẹ́ pé a ò ṣe nǹkan náà tàbí ká “kó àlàyé palẹ̀” láti yí òótọ́ padà ká lè fi wí àwíjàre fún ohun tá a ṣe tàbí láti fi mú kó dà bíi pé ohun náà ò burú. Tí ìtìjú ọ̀hún bá wá légbá kan, ó lè ṣe wá bíi pé ká má sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́, ká kàn sọ kìkì ohun tó máa jẹ́ ká jàre. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tá a sọ lè jẹ́ òótọ́ dé àyè kan, síbẹ̀ kó jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an kọ́ la sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn lè máà jẹ́ irọ́ funfun báláú, irú èyí tó wọ́pọ̀ nínú ayé lóde òní, àmọ́ ṣé ‘òtítọ́ la bá aládùúgbò wa’ tàbí ará wa sọ yẹn? (Éfésù 4:15, 25; 1 Tímótì 4:1, 2) Tí Kristẹni kan bá ń sọ̀rọ̀ kan, tó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ lọ́hùn-ún pé ńṣe lòun fẹ́ mú kí arákùnrin tàbí arábìnrin òun ní èrò tí kò yẹ, pé ńṣe lòun fẹ́ mú kó gba ohun tí kì í ṣe òótọ́ gbọ́, irú ojú wo lo rò pé Ọlọ́run á fi wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
10. Báwo làwọn wòlíì náà ṣe ṣàpèjúwe nǹkan kan tó wọ́pọ̀ ní Ísírẹ́lì àti Júdà ayé ọjọ́un?
10 Àwọn wòlíì náà rí i pé àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà pàápàá lè má ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ nígbà mìíràn. Hóséà sọ bí ohun táwọn kan ń ṣe nígbà ayé rẹ̀ ṣe rí lára Ọlọ́run, ó ní: “Kí a fi wọ́n ṣe ìjẹ, nítorí pé wọ́n ti ré ìlànà mi kọjá! Èmi fúnra mi sì tẹ̀ síwájú láti tún wọn rà padà, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti pa irọ́ mọ́ èmi gan-an.” Wọ́n ń pa irọ́ funfun báláú mọ́ Jèhófà àti irọ́ tí wọ́n fọgbọ́n gbé kalẹ̀ lọ́nà téèyàn ò fi ní lè bá wọn jiyàn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń ‘gégùn-ún wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tàn,’ bóyá nípa yíyí òtítọ́ po láti fi tan àwọn ẹlòmíràn jẹ. (Hóséà 4:1, 2; 7:1-3, 13; 10:4; 12:1) Samáríà ni Hóséà ti ṣe àkọsílẹ̀ yẹn, ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Àmọ́ ṣé nǹkan sàn ní Júdà? Míkà sọ fún wa pé: “Àwọn ọlọ́rọ̀ rẹ̀ ti kún fún ìwà ipá, àwọn olùgbé rẹ̀ sì ti sọ̀rọ̀ èké, ahọ́n wọ́n sì jẹ́ alágàálámàṣà ní ẹnu wọn.” (Míkà 6:12) Ó yẹ ká mọ bí àwọn wòlíì náà ṣe bẹnu àtẹ́ lu “ṣíṣe ẹ̀tàn” àti bí wọ́n ṣe bẹnu àtẹ́ lu àwọn tí wọ́n ní ‘ahọ́n àgálámàṣà ní ẹnu wọn,’ ìyẹn àwọn tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Nítorí náà, àwa Kristẹni, tó dájú pé a ò ní dìídì parọ́, lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ ó lè ṣeé ṣe pé kí ń ṣe ẹ̀tàn nígbà mìíràn tàbí kí n ní ahọ́n àgálámàṣà? Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí n máa ṣe nínú irú ọ̀rọ̀ yìí?’
11. Kí làwọn wòlíì náà fi hàn nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà lo ahọ́n wa?
11 Ọlọ́run tún lo àwọn wòlíì náà láti fi ìwà rere tó ń fẹ́ ká máa hù hàn kedere. Sekaráyà 8:16 sọ pé: “Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹ ó ṣe: Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì. Ẹ fi òtítọ́ àti ìdájọ́ àlàáfíà ṣe ìdájọ́ yín ní ẹnubodè yín.” Nígbà ayé Sekaráyà, gbangba ìta ní ẹnubodè làwọn àgbà ọkùnrin ti máa ń bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ẹjọ́. (Rúùtù 4:1; Nehemáyà 8:1) Àmọ́, Sekaráyà ò sọ pé ibi ọ̀rọ̀ ẹjọ́ nìkan lèèyàn ti ní láti máa sọ òtítọ́. Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó kan ọ̀pọ̀ èèyàn, àmọ́ ẹsẹ Bíbélì yẹn tún rọ̀ wá pé: “Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” Ìyẹn kan abẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ wa nígbà tá a bá ń bá ọkọ tàbí aya wa tàbí àwọn ẹbí wa sọ̀rọ̀. Ó tún kan ọ̀rọ̀ tá a máa ń bá àwọn ará wa sọ lójoojúmọ́, yálà lójúkojú, lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn. Ó yẹ kó dá wọn lójú hán-únhán-ún pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tá à ń sọ fún wọn. Ó yẹ káwọn òbí tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọ wọn létí pé ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí wọ́n má máa parọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe ń dàgbà, wọ́n á mọ̀ pé Ọlọ́run ò fẹ́ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, pé òótọ́ ló fẹ́ kí wọ́n máa sọ.—Sefanáyà 3:13.
12. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ náà?
12 Àgbàlagbà tàbí ọmọdé tó bá ń rọ̀ mọ́ òtítọ́ nígbà gbogbo máa fara mọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú Sekaráyà, pé: “Nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.” (Sekaráyà 8:19) Wo bí Málákì ṣe ṣàpèjúwe àpẹẹrẹ tí Jèhófà rí pé Ọmọ Òun yóò fi lélẹ̀. Ó ní: “Àní òfin òtítọ́ sì wà ní ẹnu rẹ̀, a kò sì rí àìṣòdodo kankan ní ètè rẹ̀. Ó bá mi rìn ní àlàáfíà àti ní ìdúróṣánṣán.” (Málákì 2:6) Ǹjẹ́ Jèhófà á retí pé ká ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn? Rántí o, pé a ní odindi Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara rẹ̀ sì ni ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà àti gbogbo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú wọn.
YẸRA FÚN ÌWÀ IPÁ NÍNÚ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN
13. Àléébù mìíràn wo ni Míkà 6:12 fi hàn?
13 Míkà 6:12 sọ fún wa pé ọ̀nà kan táwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ọjọ́un gbà bá àwọn ẹlòmíràn lò tí kò dára ni pé, ‘wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, ahọ́n wọn sì jẹ́ alágàálámàṣà ní ẹnu wọn.’ Àmọ́, ẹsẹ Bíbélì yẹn tún fi àléébù mìíràn hàn. Ó sọ pé ‘àwọn ọlọ́rọ̀ ti kún fún ìwà ipá.’ Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú ìyẹn?
14, 15. Ìwà ipá wo ni àkọsílẹ̀ fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń hù?
14 Ṣe àgbéyẹ̀wò bí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè kan tó wà nítòsí orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe rí. Orílẹ̀-èdè tó wà ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè wọn ni Ásíríà, tí Nínéfè jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Náhúmù kọ̀wé nípa Nínéfè pé: “Ègbé ni fún ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀. Gbogbo rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn àti fún ìjanilólè. Ẹran ọdẹ kì í kúrò!” (Náhúmù 3:1) Àwọn ará Nínéfè jẹ́ òǹrorò lójú ogun wọ́n sì máa ń hùwà ìkà sáwọn tí wọ́n bá mú lóǹdè nígbà ogun. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń bó awọ ara àwọn tí wọ́n mú lóǹdè tàbí kí wọ́n sun wọ́n lóòyẹ̀, wọ́n máa ń fọ́ ojú àwọn mìíràn tàbí kí wọ́n gé imú wọn, etí wọn, tàbí ìka wọn. Ìwé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, Gods, Graves, and Scholars, sọ pé: “Ohun tí aráyé ń rántí jù nípa Nínéfè ni báwọn ará ibẹ̀ ṣe máa ń pààyàn, bí wọ́n ṣe máa ń kóni lẹ́rù lọ, bí wọ́n ṣe máa ń tẹ àwọn mìíràn lórí ba àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn tí agbára wọn kéré ṣúkaṣùka; ogun àti onírúurú ìwà ipá ni wọ́n sì máa ń lò.” Ẹnì kan wà tí gbogbo ìwà ipá tí wọ́n ń hù yẹn ṣojú rẹ̀ (ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n hù ú sóun náà). Onítọ̀hún ni Jónà. Lẹ́yìn tí ọba Nínéfè gbọ́ ìkéde Jónà, ó sọ fáwọn ará ìlú rẹ̀ pé: “Kí wọ́n . . . fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bo ara wọn, ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀; kí wọ́n sì fi tokun-tokun ké pe Ọlọ́run, kí wọ́n sì padà, olúkúlùkù kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀ àti kúrò nínú ìwà ipá tí ó wà ní ọwọ́ wọn.”—Jónà 3:6-8.b
15 Ásíríà nìkan kọ́ ni wọ́n ti ń hùwà ipá tó burú jáì. Édómù tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn Júdà pẹ̀lú á jìyà. Kí nìdí? Ìwé wòlíì Jóẹ́lì sọ pé: “Ní ti Édómù, aginjù ahoro ni yóò dà, nítorí ìwà ipá sí àwọn ọmọ Júdà, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.” (Jóẹ́lì 3:19) Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Édómù fi ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn kí wọ́n sì dẹ́kun ìwà ipá? Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ọdún lẹ́yìn náà, Ọbadáyà kọ̀wé pé: “Àyà àwọn alágbára ńlá rẹ yóò sì já, ìwọ Témánì [ìyẹn orúkọ ìlú kan ní Édómù], . . . Nítorí ìwà ipá sí Jékọ́bù arákùnrin rẹ, . . . a ó ké ọ kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Ọbadáyà 9, 10) Àmọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run ńkọ́?
16. Kí ni Ámósì àti Hábákúkù jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wọn?
16 Ámósì jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní Samáríà tí í ṣe olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, ó ní: ‘Ẹ wo ọ̀pọ̀ rúgúdù tí ó wà ní àárín rẹ̀ àti jìbìtì lílù ní inú rẹ̀. Wọn kò mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn tí ń to ìwà ipá àti ìfiṣèjẹ jọ pa mọ́ sínú ilé gogoro ibùgbé wọn.’ (Ámósì 3:9, 10) O lè rò pé ọ̀rọ̀ ò ní rí bẹ́ẹ̀ ní Júdà tí tẹ́ńpìlì Jèhófà wà. Àmọ́ Hábákúkù tó ń gbé ní Júdà bi Ọlọ́run pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là? Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi?”—Hábákúkù 1:2, 3; 2:12.
17. Kí ló ṣeé ṣe kó fa ìwà ipá táwọn èèyàn Ọlọ́run ń hù?
17 Ṣé kì í ṣe pé ohun tó mú kí ìwà ipá wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ni jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ kí èèràn ìwà ipá àwọn orílẹ̀-èdè bí Ásíríà àti Édómù ran àwọn? Sólómọ́nì ti kìlọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Òwe 3:31; 24:1) Lẹ́yìn náà, Jeremáyà sojú abẹ níkòó pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ẹ má ṣe kọ́ ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè rárá.’”—Jeremáyà 10:2; Diutarónómì 18:9.
18, 19. (a) Ká sọ pé Hábákúkù ṣì wà láyé, báwo ni oríṣiríṣi ìwà ipá tó wà lónìí á ṣe rí lójú rẹ̀? (b) Ojú wo lo fi ń wo ìwà ipá tó ń wáyé lákòókò wa yìí?
18 Ká sọ pé Hábákúkù ṣì wà láyé, ǹjẹ́ ìwà ipá táwọn èèyàn ń hù lákòókò wa yìí ò ní kó o nírìíra? Àtikékeré ni ìwà ipá ti máa ń wọ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́wù. Eré bèbí orí tẹlifíṣọ̀n táwọn ọmọdé máa ń gbádùn gan-an ń fi ìwà ipá hàn, bíi kí ẹnì kan fọ́ ẹnì kejì mọ́lẹ̀, tàbí kó kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́, tàbí kó tiẹ̀ gbìyànjú àtipa á. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ọ̀pọ̀ wọn á dẹni tó yíjú sí eré orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n á ti máa yìnbọn, tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù tàbí tí wọ́n á ti máa pa alátakò wọn kí wọ́n lè mọ ẹni tó borí. Àwọn kan lè sọ pé, “eré lásán ni.” Àmọ́, ńṣe ni eré oníwà ipá orí kọ̀ǹpútà tàbí fídíò máa ń jẹ́ kí ìwà ipá kó sí àwọn tó ń ṣe é lórí, ó máa ń yí ìṣesí àti ìwà wọn padà. Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ènìyàn tí ń hu ìwà ipá yóò sún ọmọnìkejì rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú, yóò mú kí ó rin ọ̀nà tí kò dára”!—Òwe 16:29.
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó di dandan kí Hábákúkù máa rí èkìdá ìdààmú ‘tí ìwà ipá sì wà ní iwájú rẹ̀,’ èyí bà á nínú jẹ́. Wàyí o, o lè bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ó máa dùn mọ́ Hábákúkù tó bá jókòó tì mí tó sì ń wo àwọn nǹkan tí mo máa ń wò nínú tẹlifíṣọ̀n déédéé?’ Tún bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ Hábákúkù á ya àkókò sọ́tọ̀ láti máa fi wo ìwà ipá tí wọ́n ń pè ní eré ìdárayá, tó jẹ́ pé ńṣe làwọn tó ń ṣe é máa ń dì káká dì kuku kí wọ́n má bàa fara pa, bíi tàwọn tó máa ń ja àjàkú akátá láyé ọjọ́un?’ Nínú àwọn eré ìdárayá mìíràn, ohun tó máa ń múnú àwọn òǹwòran kan dùn ni báwọn oníjà ṣe máa ń wà á kò lágbo ìjà, tàbí báwọn ẹgbẹ́ òǹwòran tórí wọn kanrin ṣe jọ máa ń ná an tán bí owó. Láwọn ibì kan, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wo àwọn eré fídíò oníwà ipá àtàwọn fídíò tó dá lórí ogun tàbí onírúurú ìjà téèyàn lè jà láìlo ohun ìjà. Wọ́n lè sọ pé kò burú, pé ìtàn láwọn fi sọ tàbí pé ńṣe làwọn fi ṣe àfihàn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè náà, àmọ́ ṣé ìyẹn lè sọ ìwà ipá tó wà níbẹ̀ di ohun tó dára?—Òwe 4:17.
20. Irú ìwà ipá wo ni Málákì sọ ojú tí Jèhófà fi ń wò ó?
20 Málákì tún sọ ohun mìíràn tó jọ ìyẹn nígbà tó sọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àdàkàdekè táwọn Júù kan ń ṣe sí ìyàwó wọn. Ó ní: “‘Òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,’ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; ‘àti ẹni tí ó ti fi ìwà ipá bo ẹ̀wù rẹ̀ mọ́lẹ̀.’” (Málákì 2:16) Bákan náà kọ́ làwọn èèyàn ṣe lóye ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí, “ti fi ìwà ipá bo ẹ̀wù rẹ̀ mọ́lẹ̀.” Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí ẹ̀jẹ̀ tá sáṣọ ẹnì kan nígbà tó ń lu ẹlòmíràn. Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tó hàn gbangba pé Málákì ń sọ ni pé kò dára rárá kéèyàn máa lu aya rẹ̀ tàbí ọkọ rẹ̀. Dájúdájú, Málákì fi hàn pé ìwà ipá abẹ́ ilé wà, ó sì fi hàn pé Ọlọ́run ò fẹ́ bẹ́ẹ̀.
21. Àwọn ipò wo ni Kristẹni ti gbọ́dọ̀ yẹra fún ìwà ipá?
21 Tí Kristẹni kan bá ń hùwà ipá lábẹ́ òrùlé rẹ̀, yálà ńṣe ló ń lu àwọn ẹlòmíràn tàbí ó ń bú wọn, ìyẹn ò yàtọ̀ sí kéèyàn máa hùwà ipá ní gbangba ìta; kò séyìí tí Ọlọ́run ò rí nínú méjèèjì. (Oníwàásù 5:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ipá tí ọkọ ń hù sí aya ni Málákì mẹ́nu kàn, kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó sọ pé kì í ṣe ìwàkiwà tí ọkùnrin bá hùwà ipá sáwọn ọmọ rẹ̀ tàbí sí àwọn òbí rẹ̀ tó ti dàgbà. Kò sì sí àwíjàre kankan tí aya bá hùwà ipá sí ọkọ rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ tàbí àwọn òbí rẹ̀. Òótọ́ ni pé, bó ṣe jẹ́ pé aláìpé làwọn tó wà nínú ìdílé, ó ṣeé ṣe kí èdèkòyédè máa wáyé, èyí tó lè fa ìbínú nígbà mìíràn. Síbẹ̀, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.”—Éfésù 4:26; 6:4; Sáàmù 4:4; Kólósè 3:19.
22. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ṣeé ṣe ká má di oníwà ipá, kódà bí ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ ń hùwà ipá láyìíká wa?
22 Àwọn kan lè máa wí àwíjàre fún ìwà ipá tí wọ́n ń hù, wọ́n lè sọ pé, ‘Torí pé wọ́n ń hùwà ipá nínú ìdílé tí wọ́n ti tọ́ mi dàgbà lèmi náà ṣe ń hùwà ipá,’ tàbí kí wọ́n sọ pé ‘Nílùú tiwa, àwọn èèyàn máa ń tètè bínú, wọ́n sì máa ń fara ya.’ Ṣùgbọ́n nígbà tí Míkà bẹnu àtẹ́ lu ‘àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n kún fún ìwà ipá,’ kò sọ pé wọn ò lè jàjàbọ́ lọ́wọ́ ìwà ipá nítorí pé ibi tí wọ́n ti ń hùwà ipá ni wọ́n dàgbà sí. (Míkà 6:12) Nígbà ayé Nóà, ilẹ̀ ayé “kún fún ìwà ipá,” ipò yẹn náà sì làwọn ọmọ rẹ̀ ti dàgbà. Àmọ́ ṣé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ipá bíi tàwọn èèyàn tó kù? Rárá o! ‘Nóà rí ojú rere Jèhófà,’ àwọn ọmọ rẹ̀ náà ṣe bíi tiẹ̀, wọ́n sì la Ìkún-omi já.—Jẹ́nẹ́sísì 6:8, 11-13; Sáàmù 11:5.
23, 24. (a) Kí ló ràn wá lọ́wọ́ tí a kì í fi í ṣe ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí oníwà ipá? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń bá àwọn ẹlòmíràn lò bó ṣe fẹ́?
23 Jákèjádò ayé, ẹni àlàáfíà làwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí, wọn kò mọ̀ wá sí oníwà ipá. A kì í rú òfin tí Késárì ṣe nípa ìwà ipá. (Róòmù 13:1-4) A ti sapá láti ‘fi idà wa rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,’ a sì máa ń làkàkà láti wá bí àlàáfíà yóò ṣe jọba. (Aísáyà 2:4) À ń gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, èyí tó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìwà ipá. (Éfésù 4:22-26) A sì máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere àwọn alàgbà, tó jẹ́ pé wọn kì í ṣe “aluni” nínú ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí nínú ìṣe.—1 Tímótì 3:3; Títù 1:7.
24 Dájúdájú, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀. Hóséà sọ pé: “Ta ni ó gbọ́n, kí ó lè lóye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó lóye, kí ó lè mọ̀ wọ́n? Nítorí àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán, àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn.”—Hóséà 14:9.
a Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ̀rọ̀ nípa gbólóhùn náà, “ré ìṣìnà kọjá” tó jẹ́ àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ nínú èdè Hébérù. Ó ní wọ́n “mú un látinú ìṣesí arìnrìn-àjò kan tó kàn ń kọjá lára àwọn nǹkan kan láìwò wọ́n nítorí pé kò fẹ́ kíyè sí wọn. Kì í ṣe pé ohun tí ìyẹn ń sọ ni pé Ọlọ́run kì í kíyè sí ẹ̀ṣẹ̀ o, ohun tó fi hàn ni pé, nígbà mìíràn, Ọlọ́run kì í sàmì sí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú èrò àtifìyà jẹ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà; pé ṣe ló máa ń dárí jini dípò kó fìyà jẹni.”
b Ìlú Kálà (ìyẹn Nímírúdù) tí Aṣunásípà tún kọ́ jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà márùndínlógójì sí àríwá ìlà oòrùn Nínéfè. Àwọn àwòrán ara ògiri tí wọ́n rí ní Kálà wà ní Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ohun tá a rí kà nípa àwọn àwòrán ara ògiri náà ni pé: “Aṣunásípà sọ gbogbo ìwà òǹrorò àti ìwà ìkà tó burú jáì tó fi máa ń gbógun lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ní àwọn ìlú tí wọ́n bá sàga tì, wọ́n máa ń so àwọn tí wọ́n bá mú lóǹdè rọ̀ sórí òpó igi tàbí kí wọ́n kàn wọ́n mọ́ òpó igi . . . ; wọ́n máa ń bó awọ ara àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin lóòyẹ̀.”—Archaeology of the Bible.