Wọ́n ‘Ṣe Bẹ́ẹ̀ Gẹ́lẹ́’
“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọrun túmọ̀ sí, pé kí a pa awọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 JOHANNU 5:3.
1. Kí ni a lè sọ ní ti bí ìfẹ́ Ọlọrun ti tó?
“ỌLỌRUN JẸ́ ÌFẸ́.” Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ ń ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún bí ìfẹ́ náà ti jinlẹ̀ tó. “Ìfẹ́ naa jẹ́ lọ́nà yii, kì í ṣe pé awa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun, bíkòṣe pé oun nífẹ̀ẹ́ wa ó sì rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Bí a ti ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà ṣíṣeyebíye ti Jesu, a ‘ń dúró nínú ìfẹ́ Ọlọrun.’ (1 Johannu 4:8-10‚ 16) Nípa báyìí, a lè gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún nípa tẹ̀mí nísinsìnyí àti nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.—Johannu 17:3; 1 Johannu 2:15‚ 17.
2. Bawo ni ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọrun ṣe ṣàǹfààní fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
2 Àkọsílẹ̀ Bibeli kún fún àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọrun, tí a sì ti bù kún wọn jìngbìnnì nítorí rẹ̀. Èyí ní àwọn ẹlẹ́rìí ṣáájú ìgbà Kristian nínú, aposteli Paulu kọ̀wé nípa àwọn kan nínú wọn pé: “Gbogbo awọn wọnyi kú ninu ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìmúṣẹ awọn ìlérí naa gbà, ṣugbọn wọ́n rí wọn lókèèrè réré wọ́n sì fi inúdídùn tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé awọn jẹ́ àjèjì ati olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ naa.” (Heberu 11:13) Lẹ́yìn náà, àwọn Kristian olùfọkànsìn, ìránṣẹ́ Ọlọrun, jàǹfààní láti inú “inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ati òtítọ́ [tí ó] wá wà nípasẹ̀ Jesu Kristi.” (Johannu 1:17) Jálẹ̀ nǹkan bíi 6,000 ọdún ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, Jehofa ti san èrè fún àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ tí wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ, èyí tí “kì í . . . ṣe ẹrù-ìnira” ní tòótọ́.—1 Johannu 5:2‚ 3.
Ní Àwọn Ọjọ́ Noa
3. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Noa gbà ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’?
3 Àkọsílẹ̀ Bibeli sọ pé: “Nipa ìgbàgbọ́ ni Noa, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nipa awọn ohun tí a kò tí ì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn ó sì kan ọkọ̀ áàkì kan fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀; ati nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yii ó dá ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo naa tí ó wà ní ìbámu pẹlu ìgbàgbọ́.” Gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo,” Noa ṣègbọràn ní kíkún sí Ọlọrun, nípa kíkìlọ̀ fún ayé oníwà ipá tí ó ṣáájú Ìkún Omi nípa ìdájọ́ àtọ̀runwá tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. (Heberu 11:7; 2 Peteru 2:5) Ní kíkọ́ áàkì náà, ó fìṣọ́ra tẹ̀ lé ìlànà àtọ̀runwá tí a pèsè. Nígbà náà ni ó kó àwọn ẹranko àti àwọn oúnjẹ tí a ti dárúkọ pàtó, wọlé. “Bẹ́ẹ̀ ni Noa . . . ṣe; gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ọlọrun pàṣẹ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe.”—Genesisi 6:22.
4, 5. (a) Báwo ni ipa búburú ṣe nípa lórí aráyé títí di òní? (b) Èé ṣe tí a fi ní láti ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’ ní ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá?
4 Noa àti ìdílé rẹ̀ ní láti kojú ipa búburú tí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn ní. Àwọn ọmọ Ọlọrun wọ̀nyí gbé àwọ̀ ènìyàn wọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn obìnrin gbé pọ̀, wọ́n sì ń bí àwọn àdàmọ̀dì ènìyàn tí ń bú mọ́ aráyé. “Ayé sì bà jẹ́ níwájú Ọlọrun, ayé sì kún fún ìwà agbára.” Jehofa fi Àkúnya pa ìran búburú náà run. (Genesisi 6:4‚ 11-17; 7:1) Láti ọjọ́ Noa wá, a kò gba àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí èṣù láyè láti yí padà di ẹ̀dá ènìyàn mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ‘gbogbo ayé ń bá a lọ láti máa wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa,’ Satani Èṣù. (1 Johannu 5:19; Ìṣípayá 12:9) Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, Jesu fi ìran ọlọ̀tẹ̀ ọjọ́ Noa wé ìran aráyé tí wọ́n ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ìgbà tí àmì “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í hàn kedere ní 1914.—Matteu 24:3, 34, 37-39; Luku 17:26‚ 27.
5 Lónìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, Satani ń gbìyànjú láti run aráyé àti pílánẹ́ẹ̀tì wa. (Ìṣípayá 11:15-18) Nítorí náà, ó jẹ́ kánjúkánjú láti kọbi ara sí àṣẹ onímìísí náà pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ̀ kí ẹ̀yin baà lè dúró gbọn-in-gbọn-in lòdì sí awọn ọgbọ́n àrékérekè Èṣù.” (Efesu 6:11, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Nípa báyìí, kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti fífi í sílò nínú ìgbésí ayé wa ń fún wa lókun. Síwájú sí i, a ní ètò àjọ Jehofa tí ń bójú tó wa, pẹ̀lú “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” tí a fi òróró yàn, àti àwọn alàgbà rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, láti fi sùúrù darí wa sọ́nà tí ó yẹ kí á gbà. A ní láti ṣàṣeparí iṣẹ́ wíwàásù kárí àgbáyé. (Matteu 24:14‚ 45-47) Gẹ́gẹ́ bíi Noa, ẹni tí ó fìṣọ́ra ṣègbọràn sí ìtọ́ni àtọ̀runwá, ǹjẹ́ kí a máa ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’
Mose—Ọlọ́kàn Tútù Jù Lọ Nínú Ènìyàn
6, 7. (a) Yíyàn tí ó lérè wo ni Mose ṣe? (b) Àwòkọ́ṣe onígboyà wo ni Mose fi lélẹ̀ fún wa?
6 Gbé ọkùnrin ìgbàgbọ́ mìíràn yẹ̀ wò—Mose. Òun ì bá ti gbádùn ìgbésí ayé onígbọ̀jẹ̀gẹ́ nínú fàájì ilẹ̀ Egipti. Ṣùgbọ́n ó yàn “pé kí a ṣẹ́ oun níṣẹ̀ẹ́ pẹlu awọn ènìyàn Ọlọrun dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí Jehofa rán níṣẹ́, “ó fi tọkàntara wo sísan èrè-ẹ̀san naa [ó sì] ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni naa tí a kò lè rí.”—Heberu 11:23-28.
7 A kà nínú Numeri 12:3 pé: “Ọkùnrin náà Mose, ó ṣe ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn lọ tí ń bẹ lórí ilẹ̀.” Ní ìyàtọ̀ gédégbé, Farao ti Egipti hùwà bí onígbèéraga jù lọ nínú gbogbo ènìyàn. Nígbà tí Jehofa pàṣẹ fún Mose àti Aaroni láti polongo ìdájọ́ rẹ̀ lórí Farao, báwo ni wọ́n ṣe dáhùn padà? A sọ fún wa pé: “Mose àti Aaroni . . . ṣe bẹ́ẹ̀; bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe.” (Eksodu 7:4-7) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ onígboyà tí èyí jẹ́ fún àwa tí ń polongo ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọrun lónìí!
8. Báwo ni a ṣe retí pé kí àwọn ọmọ Israeli ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́,’ báwo sì ni ayọ̀ tí ó yọrí sí yóò ṣe ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà?
8 Àwọn ọmọ Israeli ha fi ìdúró ṣinṣin ṣètìlẹyìn fún Mose bí? Lẹ́yìn tí Jehofa ti mú ìyọnu mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá, wá sórí Egipti, ó fún Israeli ní ìsọfúnni lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lórí ṣíṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. “Àwọn ènìyàn sì tẹrí ba wọ́n sì sìn. Àwọn ọmọ Israeli sì lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti fi àṣẹ fún Mose àti Aaroni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe.” (Eksodu 12:27‚ 28) Ní òru ọjọ́ mánigbàgbé náà, Nisan 14, 1513 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, áńgẹ́lì Ọlọrun pa gbogbo àkọ́bí àwọn ará Egipti, ṣùgbọ́n ó ré ilé àwọn ọmọ Israeli kọjá. Èé ṣe tí a fi dá àkọ́bí Israeli sí? Nítorí pé, wọ́n ti rí ààbò lábẹ́ ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá, tí wọ́n fi wọ́n òpó ilẹ̀kùn wọn. Wọ́n ṣe gẹ́lẹ́ bí Jehofa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni. Àní, “bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe.” (Eksodu 12:50‚ 51) Ní Òkun Pupa, Jehofa tún ṣe iṣẹ́ ìyanu síwájú sí i láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ onígbọràn là, nígbà tí ó pa Farao àti ẹgbẹ́ ogun alágbára rẹ̀ run. Ẹ wo bí àwọn ọmọ Israeli ti láyọ̀ tó! Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ tó ṣègbọràn sí àṣẹ Jehofa yóò láyọ̀ láti jẹ́ ẹlẹ́rìí ìṣẹ́gun rẹ̀ ní Armageddoni.—Eksodu 15:1‚ 2; Ìṣípayá 15:3‚ 4.
9. Àwọn àǹfààní òde òní wo ni ṣíṣe tí àwọn ọmọ Israeli ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’ ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àgọ́ àjọ?
9 Nígbà tí Jehofa pàṣẹ fún Israeli láti kó ọrẹ jọ, kí wọ́n sì kọ́ àgọ́ àjọ ní aginjù, àwọn ènìyàn náà ṣètìlẹyìn tinútinú. Nígbà náà, títí dórí bínńtín pàápàá, Mose àti àwọn olùyọ̀ọ̀da ara ẹni, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, tẹ̀ lé ìlànà ìkọ́lé tí Jehofa pèsè. “Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ ti àgọ́ àjọ náà parí: àwọn ọmọ Israeli sì ṣe gẹ́gẹ́ bíi gbogbo èyí tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe.” Bákan náà, nígbà ìfilọ́lẹ̀ ipò àlùfáà, “bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe: gẹ́gẹ́ bí èyí tí OLUWA pa láṣẹ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe.” (Eksodu 39:32; 40:16) Ní òde òní, a ní àǹfààní láti fi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wíwàásù àti ètò mímú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìjọba náà gbòòrò sí i. Nípa báyìí, ẹ̀tọ́ wa ni láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní ṣíṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’
Joṣua—Onígboyà àti Alágbára Gidigidi
10, 11. (a) Kí ni ó múra Joṣua sílẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí? (b) Báwo ni a ṣe lè fún wa lókun láti kojú àwọn àdánwò òde òní?
10 Nígbà tí Mose fún Joṣua níṣẹ́ẹ dídarí Israeli lọ sí ilẹ̀ ìlérí, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, kìkì àwọn ìwé márùn-ún Mose, psalmu kan tàbí méjì, àti ìwé Jobu nìkan ni Ọ̀rọ̀ onímìísí Jehofa tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Mose ti pàṣẹ fún Joṣua láti pe àwọn ènìyàn náà jọ, nígbà tí wọ́n bá dé Ilẹ̀ Ìlérí, kí ó sì “ka òfin yìí níwájú gbogbo Israeli ní etí wọn.” (Deuteronomi 31:10-12) Ní àfikún sí i, Jehofa fúnra rẹ̀ pàṣẹ fún Joṣua pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọdọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ óò máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè kíyè sí àtiṣe gẹ́gẹ́ bíi gbogbo èyí tí a kọ sínú rẹ̀: nítorí nígbà náà ni ìwọ óò ṣe ọ̀nà rẹ ní rere, nígbà náà ni yóò sì dára fún ọ.”—Joṣua 1:8.
11 Kíka “ìwé” Jehofa lójoojúmọ́ múra Joṣua sílẹ̀ láti bójú tó àwọn àdánwò tí ń bẹ níwájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí kíka Ọ̀rọ̀ Jehofa, Bibeli, lójoojúmọ́, ṣe ń fún àwọn Ẹlẹ́rìí Rẹ̀ òde òní lókun láti kojú àwọn àdánwò “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” líle koko wọ̀nyí. (2 Timoteu 3:1) Bí ayé oníwà ipá ti yí wa ká yìí, ẹ jẹ́ kí a fi ìṣílétí tí Ọlọrun fún Joṣua sílò pé: “Ṣe gírí, kí o sì mú àyà le; má ṣe bẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́: nítorí pé OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ́ bá ń lọ.” (Joṣua 1:9) Lẹ́yìn ṣíṣẹ́gun Kenaani, a bù kún àwọn ẹ̀yà Israeli jìngbìnnì nígbà tí wọ́n ń tẹ̀ dó sí ilẹ̀ ogún ìní wọn. “Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israeli ṣe.” (Joṣua 14:5) Èrè tí ó fara jọ èyí ń dúró de gbogbo àwa tí ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lónìí, tí a sì ń fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa, tí a ń fìgbọràn ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’
Àwọn Ọba—Olùṣòtítọ́ àti Aláìgbọràn
12. (a) Àṣẹ wo ni a fún àwọn ọba ní Israeli? (b) Kí ni ìkùnà àwọn ọba láti ṣègbọràn yọrí sí?
12 Àwọn ọba ní Israeli ńkọ́? Jehofa gbé ohun àbéèrèfún yìí síwájú wọn pé: “Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí òun kí ó sì kọ ìwé òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀, láti inú èyí tí ń bẹ níwájú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi: Yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun óò sì máa kà nínú rẹ̀ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo: kí ó lè máa kọ́ àtibẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, láti máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí mọ́ àti ìlànà wọ̀nyí, láti máa ṣe wọ́n.” (Deuteronomi 17:18‚ 19) Àwọn ọba Israeli ha ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn bí? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n kùnà gidigidi, débi pé wọ́n jìyà ègún tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Deuteronomi 28:15-68. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a tú Israeli ká “láti òpin ilẹ̀ dé òpin ilẹ̀.”
13. Gẹ́gẹ́ bíi Dafidi, báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nípa fífi ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Jehofa hàn?
13 Ṣùgbọ́n, Dafidi—olùṣòtítọ́, ọba ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní Israeli—fi ìfọkànsìn tí ó ga lọ́lá fún Jehofa hàn. Ó fi ẹ̀rí hàn pé òun ni ‘ọmọ kìnnìún ẹ̀ya Judah,’ tí ń ṣàpẹẹrẹ Kristi Jesu, tí ó jẹ́ ajagunṣẹ́gun ‘kìnnìún ẹ̀ya Judah, gbòǹgbò Dafidi.’ (Genesisi 49:8‚ 9; Ìṣípayá 5:5) Níbo ni agbára Dafidi wà? Ó ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ alákọsílẹ̀ Jehofa, ó sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Nínú Orin Dafidi 19, “orin atunilára Dafidi,” a kà pé: “Òfin Oluwa pé.” Lẹ́yìn títọ́ka sí ìránnilétí, àwọn ìlànà, àṣẹ àti ìdájọ́ Jehofa, Dafidi tẹ̀ síwájú ní sísọ pé: “Wọ́n ju wúrà dáradára púpọ̀; wọ́n sì dùn ju oyin lọ, àti ríro afárá oyin. Pẹ̀lúpẹ̀lú, nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ létí; àti ní pípamọ́ wọn èrè púpọ̀ ń bẹ.” (Orin Dafidi 19:7-11) Bí kíka Ọ̀rọ̀ Jehofa àti ṣíṣàṣàrò lé e lórí lójoojúmọ́ bá ní èrè ní 3,000 ọdún sẹ́yìn, mélòómélòó ni lónìí!—Orin Dafidi 1:1-3; 13:6; 119:72, 97, 111.
14. Ní ọ̀nà wo ni ipa ọ̀nà tí Solomoni tọ̀ ṣe fi hàn pé a nílò ju kìkì ìmọ̀ lọ?
14 Síbẹ̀, kò tó láti wulẹ̀ ní ìmọ̀. Ó tún ṣe pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun láti ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ náà, láti lò ó ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ àtọ̀runwá—àní, láti ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’ A lè fi Solomoni, ọmọ Dafidi, tí Jehofa yàn “láti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba Oluwa lórí Israeli” ṣàpèjúwe èyí. Solomoni gba iṣẹ́ àyànfúnni láti kọ́ tẹ́ḿpìlì, ní lílo ìlànà ilé kíkọ́ tí Dafidi gbà “nípa ìmísí.” (1 Kronika 28:5‚ 11-13, NW) Báwo ni Solomoni ṣe lè ṣàṣeparí iṣẹ́ bàtàkùnbatakun yìí? Ní ìdáhùn sí àdúrà rẹ̀, Jehofa fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Pẹ̀lú èyí, àti nípa dídìrọ̀ mọ́ ìlànà náà tí a pèsè látọ̀runwá, ó ṣeé ṣé fún Solomoni láti kọ́ ilé ńlá náà, tí ó wá kún fún ògo Jehofa. (2 Kronika 7:2‚ 3) Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn náà, Solomoni kùnà. Ní ọ̀nà wo? Òfin Jehofa ti sọ nípa ọba ní Israeli pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe kó obìnrin jọ fún ara rẹ̀, kí àyà rẹ̀ kí ó má baà yí padà.” (Deuteronomi 17:17) Síbẹ̀, Solomoni “ní ọ̀ọ́dẹ́gbẹ̀rin obìnrin, àwọn ọmọ ọba, àti ọ̀ọ́dúnrún àlè, àwọn aya rẹ̀ sì . . . yí i ní ọkàn padà sí ọlọrun mìíràn.” Ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ ayé rẹ̀, Solomoni yí padà kúrò nínú ṣíṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’—1 Awọn Ọba 11:3‚ 4; Nehemiah 13:26.
15. Báwo ni Josiah ṣe ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’?
15 Àwọn ọba onígbọràn díẹ̀ wà ní Judah, èyí tí ó kẹ́yìn nínú wọn ni Josiah. Ní ọdún 648 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìbọ̀rìṣà rẹ́ nílẹ̀, ó sì ń tún tẹ́ḿpìlì Jehofa ṣe. Níbẹ̀ ni olórí àlùfáà ti rí “ìwé òfin Oluwa tí a ti ọwọ́ Mose kọ.” Kí ni Josiah ṣe nípa èyí? “Ọba sì gòkè lọ sínú ilé Oluwa, àti gbogbo ọkùnrin Juda, àti àwọn tí ń gbé Jerusalemu, àti àwọn àlùfáà, àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ènìyàn àti ẹni ńlá àti ẹni kékeré: ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé májẹ̀mú náà tí a rí nínú ilé Oluwa ní etí wọn. Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀, ó sì dá májẹ̀mú níwájú Oluwa láti máa fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn rìn tọ Oluwa lẹ́yìn, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀, àti àṣẹ rẹ̀, láti ṣe ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà tí a kọ sínú ìwé yìí.” (2 Kronika 34:14‚ 30‚ 31) Àní, Josiah ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’ Nítorí ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ tí ó tẹ̀ lé, a dá ìmúṣẹ ìdájọ́ Jehofa lórí Judah aláìgbàgbọ́ dúró de ọjọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọ́n ya pòkíì.
Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
16, 17. (a) Báwo ni a ṣe gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jesu? (b) Àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun mìíràn wo ni wọ́n pèsè àpẹẹrẹ fún wa?
16 Nínú gbogbo ènìyàn tí ó tí ì gbé ayé rí, Jesu Kristi Oluwa ni àpẹẹrẹ tí ó dára jù lọ ti ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dà bí oúnjẹ fún un. (Johannu 4:34) Ó sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ọmọkùnrin kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bíkòṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe. Nitori ohun yòówù tí Ẹni yẹn ń ṣe, nǹkan wọnyi ni Ọmọkùnrin ń ṣe pẹlu ní irú-ọ̀nà kan naa.” (Johannu 5:19‚ 30; 7:28; 8:28, 42) Jesu ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́,’ ní pípolongo pé: “Emi ti sọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀run, kì í ṣe lati ṣe ìfẹ́-inú mi, bíkòṣe ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi.” (Johannu 6:38) A ké sí àwa tí a jẹ́ Ẹlẹ́rìí olùṣèyàsímímọ́ fún Jehofa láti ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’ nípa títẹ̀ lé ipasẹ̀ Jesu.—Luku 9:23; 14:27; 1 Peteru 2:21.
17 Ní gbogbo ìgbà ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun wà ní oókan àyà Jesu. Ó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dunjú, ó sì tipa báyìí gbara dì láti fúnni ní ìdáhùn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. (Matteu 4:1-11; 12:24-31) Nípa fífi ọkàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé, àwa pẹ̀lú lè di ẹni tí ó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Timoteu 3:16‚ 17) Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa ti ìgbàanì àti ti àwọn ìgbà tí ó tẹ̀ lé e, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ti Ọ̀gá wa, Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ pé: “Nitori kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi lati ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.” (Johannu 14:31) Ǹjẹ́ kí àwa pẹ̀lú fi ìfẹ́ wa fún Ọlọrun hàn nípa títẹ̀ síwájú láti ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.’—Marku 12:29-31.
18. Kí ni ó ní láti sún wa láti “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa,” kí sì ni a óò jíròrò tẹ̀ lé e?
18 Bí a ti ń ṣàṣàrò lórí ipa ọ̀nà onígbọràn ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ìgbà Bibeli, a kò ha ń fún wa níṣìírí láti ṣe iṣẹ́ ìsìn àfòtítọ́ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti Satani bí? (Romu 15:4-6) Ní ti gidi, a ní láti sún wa láti “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa” lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò ti jíròrò.—Jakọbu 1:22.
O Ha Rántí Bí?
◻ Kí ló yẹ kí “ìfẹ́ Ọlọrun” túmọ̀ sí fún wa?
◻ Kí ni a rí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Noa, Mose, àti Joṣua?
◻ Dé ìwọ̀n àyè wo ni àwọn ọba ní Israeli ṣègbọràn sí “ọ̀rọ̀” Ọlọrun?
◻ Báwo ni Jesu ṣe jẹ́ Àwòkọ́ṣe wa nínú ṣíṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Noa, Mose, àti Joṣua ‘ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’