Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kejì Sáàmù
NÍWỌ̀N bá a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, a mọ̀ pé a máa dojú kọ àdánwò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò àti inúnibíni, tí èyí sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a jólóòótọ́ sí Ọlọ́run?
Ìsọ̀rí kejì nínú ìsọ̀rí márùn-ún tí ìwé Sáàmù pín sí pèsè ìrànlọ́wọ́ yẹn. Sáàmù kejìlélógójì sí ìkejìléláàádọ́rin jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ fara da àdánwò láìjuwọ́ sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ká sì dúró dìgbà tó máa dá wa nídè. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn jẹ́ fún wa! Láìsí àní-àní, àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Kejì Sáàmù “yè, ó sì ń sa agbára” bíi tàwọn ìwé yòókù nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kódà ó ń sa agbára lóde òní pàápàá.—Hébérù 4:12.
JÈHÓFÀ NI “IBI ÌSÁDI ÀTI OKUN” WA
Inú ọmọ Léfì kan tó wà nígbèkùn ò dùn rárá nítorí pé kò lè lọ jọ́sìn ní ibi ìjọsìn Jèhófà. Ó wá ń tu ara rẹ̀ nínú nípa sísọ pé: “Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi, èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi? Dúró de Ọlọ́run.” (Sáàmù 42:5, 11; 43:5) Ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ yìí tó fara hàn níbi púpọ̀ ló so àwọn ìsọ̀rí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà nínú Sáàmù kejìlélógójì àti ìkẹtàlélógójì pọ̀ tó fi di ewì kan ṣoṣo. Sáàmù kẹrìnlélógójì jẹ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí Júdà, orílẹ̀-èdè tó wà nínú ìbànújẹ́, bóyá nítorí àwọn ará Ásíríà tó ń gbógun tì wọ́n nígbà ayé Hesekáyà Ọba.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà Ọba ni Sáàmù karùnlélógójì tó jẹ́ orin nípa ìgbéyàwó ọba kan dá lé lórí. Àwọn sáàmù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó tẹ̀ lé e pe Jèhófà ní “ibi ìsádi àti okun,” “Ọba ńlá lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,” àti “ibi gíga ààbò.” (Sáàmù 46:1; 47:2; 48:3) Ọ̀nà tí Sáàmù kọkàndínláàádọ́ta gbà fi hàn pé kó sí ẹnì kankan tó “lè tún arákùnrin kan pàápàá rà padà” mà dára gan-an o! (Sáàmù 49:7) Àwọn ọmọ Kórà ló kọ Sáàmù mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ àkọ́kọ́ nínú ìsọ̀rí kejì ìwé Sáàmù. Ásáfù ló kọ èyí tó jẹ́ ìkẹsàn-án níbẹ̀, ìyẹn Sáàmù àádọ́ta.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
44:19—Kí ni “ipò àwọn akátá”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ojú ogun kan táwọn tó kú sógun náà ti di oúnjẹ fún àwọn akátá ni onísáàmù náà ń tọ́ka sí.
45:13, 14a—Ta ni “ọmọbìnrin ọba” tí ‘a óò mú tọ ọba wá’? Ọmọbìnrin Jèhófà Ọlọ́run, “Ọba ayérayé” ni. (Ìṣípayá 15:3) Ó dúró fún ìjọ ológo ti àwọn Kristẹni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí Jèhófà sọ dọmọ nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ yàn wọ́n. (Róòmù 8:16) “Ọmọbìnrin” Jèhófà yìí, tá a “múra rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀,” ni a óò mú wá sọ́dọ̀ ọkọ ìyàwó, ìyẹn Mèsáyà Ọba.—Ìṣípayá 21:2.
45:14b, 15—Ta ni “àwọn wúńdíá” dúró fún? Àwọn ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn tòótọ́, tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ìyókù ẹni àmì òróró tí wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Níwọ̀n bí wọ́n ti “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá” láàyè, wọ́n á wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ìgbéyàwó Mèsáyà Ọba bá parí ní ọ̀run. (Ìṣípayá 7:9, 13, 14) Ní àkókò yẹn, wọ́n á kún fún “ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú.”
45:16—Ọ̀nà wo làwọn ọmọkùnrin yóò fi wá wà nípò àwọn baba ńlá ọba náà? Nígbà tá a bí Jésù sórí ilẹ̀ ayé, ó ní àwọn baba ńlá. Àwọn wọ̀nyí yóò wá di ọmọ rẹ̀ nígbà tó bá jí wọn dìde kúrò nínú ikú nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀. Àwọn kan lára àwọn baba ńlá wọ̀nyí yóò wà lára àwọn tá a yàn láti jẹ́ “olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”
50:2—Kí nìdí tá a fi pe Jerúsálẹ́mù ní “ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra”? Èyí kì í ṣe nítorí bí ìlú náà ṣe rí. Kàkà bẹ́ẹ̀ lílò tí Jèhófà lò ó tó sì tún fi ẹwà jíǹkí rẹ̀ nípa fífi ibẹ̀ ṣe ibi tí tẹ́ńpìlì rẹ̀ wà àti olú ìlú àwọn ọba rẹ̀ tí a fi òróró yàn ló mú ká pè é bẹ́ẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
42:1-3. Bí egbin tó wà ní àgbègbè tó gbẹ táútáú ṣe máa ń wá omi lójú méjèèjì, ni ọmọ Léfì náà ṣe ń wá Jèhófà lójú méjèèjì. Inú ọkùnrin náà bà jẹ́ nítorí pé kò rọ́nà jọ́sìn Jèhófà ní tẹ́ńpìlì débi pé ‘omijé rẹ̀ di oúnjẹ fún un ní ọ̀sán àti òru,’ ìyẹn ni pé oúnjẹ ò wù ú jẹ rárá. Ǹjẹ́ kò yẹ ká ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún jíjọ́sìn táwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ń jọ́sìn Jèhófà?
42:4, 5, 11; 43:3-5. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò ráyè bá ìjọ Kristẹni pé jọ fún ìgbà díẹ̀, bóyá nítorí àwọn ìdí kan tó kọjá agbára wa, bá a ṣe ń rántí ayọ̀ tí irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń fún wa tẹ́lẹ̀ rí lè mẹ́sẹ̀ wa dúró. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè kọ́kọ́ mú ká máa ronú pé a dá nìkan wà, àmọ́ yóò tún máa rán wa létí pé Ọlọ́run ni ibi ìsádi wa àti pé a ní láti dúró dìgbà tó máa ṣọ̀nà àbáyọ.
46:1-3. Àjálù èyíkéyìí tó wù kó dé bá wa, a ní láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó dájú pé “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa.”
50:16-19. Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tó sì ń ṣe àwọn ohun búburú kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣojú fún Ọlọ́run.
50:20. Dípò ká máa yára sọ àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn káàkiri, ńṣe ló yẹ ká máa gbójú fò wọ́n.—Kólósè 3:13.
“FI ÌDÁKẸ́JẸ́Ẹ́ DÚRÓ DE ỌLỌ́RUN, ÌWỌ ỌKÀN MI”
Àwọn sáàmù wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá tí Dáfídì gbà lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Sáàmù kejìléláàádọ́ta sí ìkẹtàdínlọ́gọ́ta fi hàn pé Jèhófà yóò pèsè ìdáǹdè fáwọn tó bá kó ẹrù ìnira wọn lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì dúró dè é láti fún wọn ní ìgbàlà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú Sáàmù kejìdínlọ́gọ́ta sí ìkẹrìnlélọ́gọ́ta, Jèhófà ni Dáfídì fi ṣe ibi ìsádi rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó wà nínú wàhálà yẹn. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ní tòótọ́, fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de Ọlọ́run, ìwọ ọkàn mi, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.”—Sáàmù 62:5.
Àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Olùdáǹdè wa yẹ kó sún wa láti máa “kọ orin atunilára sí ògo orúkọ rẹ̀.” (Sáàmù 66:2) A yin Jèhófà nínú Sáàmù karùnlélọ́gọ́ta gẹ́gẹ́ bí olùpèsè tó lawọ́ gan-an, a pè é ní Ọlọ́run tó ń gbani là nínú Sáàmù kẹtàdínláàádọ́rin àti ìkejìdínláàádọ́rin, a tún pè é ní Olùpèsè àsálà nínú Sáàmù àádọ́rin àti ìkọkànléláàádọ́rin.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
51:12—“Ẹ̀mí ìmúratán” ti ta ni Dáfídì sọ pé kó ti òun lẹ́yìn? Èyí kò tọ́ka sí bí Ọlọ́run ṣe múra tán láti ran Dáfídì lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò tọ́ka sí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, àmọ́ ẹ̀mí ti Dáfídì fúnra rẹ̀ ló ń sọ nípa rẹ̀, ìyẹn èrò ọkàn rẹ̀. Ó ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí ṣíṣe ohun tó tọ́ máa wu òun.
53:1—Ọ̀nà wo lẹni tó sọ pé kò sí Ọlọ́run gbà jẹ́ “òpònú”? Jíjẹ́ òpònú tá à ń sọ níbi yìí kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ dìndìnrìn. A lè lóye ọ̀nà tí ẹnì kan gbà jẹ́ òpònú lórí ọ̀ràn ìwà rere tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìwàkiwà tá a sọ nípa wọn nínú Sáàmù 53:1-4.
58:3-5—Ọ̀nà wo làwọn ẹni ibi fi dà bí ejò? Àwọn irọ́ tí wọ́n máa ń pa mọ́ àwọn ẹlòmíràn dà bí oró ejò. Wọ́n á bá orúkọ onítọ̀hún jẹ́ bí oró ejò ṣe máa ń ba ara èèyàn jẹ́. “Bíi ṣèbé tí ń di etí rẹ̀” làwọn ẹni ibi ṣe máa ń kọ etí dídi sí ìtọ́ni tàbí ìbáwí.
58:7—Báwo làwọn ẹni ibi ṣe ń “yọ́ bí ẹni pé sínú omi tí ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ”? Dáfídì ti lè máa ronú nípa àwọn omi tó wà láwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá kan ní Ilẹ̀ Ìlérí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀yamùúmùú òjò kan lè mú káwọn omi náà pọ̀ sí i, àmọ́ kíá ni irú àwọn omi bẹ́ẹ̀ máa ń ṣàn lọ tá ò sì ni rí wọn mọ́. Dáfídì gbàdúrà pé káwọn ẹni ibi tètè pòórá.
68:13—Kí ni “ìyẹ́ apá àdàbà tí a fi fàdákà bò . . . àti ìyẹ́ rẹ̀ àfifò tí ó ní wúrà aláwọ̀ ewéko àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò” túmọ̀ sí? Àwọn àdàbà kan tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ búlúù tó dà pọ̀ mọ́ àwọ̀ eérú máa ń ní oríṣiríṣi àwọ̀ tó máa ń tàn yanran lára díẹ̀ nínú àwọn ìyẹ́ wọn. Àwọn ìyẹ́ wọn á wá máa dán gbinrin nínú oòrùn tó ń tàn bíi wúrà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Dáfídì ń fi àwọn jagunjagun ọmọ Ísírẹ́lì tó ń bọ̀ látojú ogun wé irú àwọn àdàbà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n lágbára láti fò, tí àwọ̀ wọn sì jojú ní gbèsè. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ, àpèjúwe rẹ̀ yìí tún lè túmọ̀ sí iṣẹ́ ọ̀nà kan tàbí àmì ẹ̀yẹ kan tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun. Ohun yòówù kó jẹ́, ńṣe ni Dáfídì ń sọ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn.
68:18—Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? Àwọn wọ̀nyí làwọn ọkùnrin tó wà lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lákòókò tí wọ́n jagun tí wọ́n fi gba Ilẹ̀ Ìlérí. Wọ́n wá yan irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn.—Ẹ́sírà 8:20.
68:30—Kí ni ẹ̀bẹ̀ tí Dáfídì bẹ Ọlọ́run pé kó “bá ẹranko ẹhànnà tí ń bẹ nínú àwọn esùsú wí lọ́nà mímúná” túmọ̀ sí? Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Dáfídì pe àwọn tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Jèhófà ní ẹranko ẹhànnà, ó wá ń bẹ Ọlọ́run pé kó bá wọn wí, tàbí kó má ṣe jẹ́ kí wọ́n lágbára láti pa ẹnikẹ́ni lára.
69:23—Kí ni ‘mímú kí ìgbáròkó ọ̀tá yẹ̀’ túmọ̀ sí? Àwọn iṣu ẹran tó wà ní ìgbáròkó ṣe pàtàkì gan-an téèyàn bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ agbára, bíi kéèyàn fẹ́ gbé nǹkan sókè tàbí kó fẹ́ gbé ẹrù tó wúwo. Ìgbáròkó yíyẹ̀ túmọ̀ sí kéèyàn máà lágbára. Dáfídì wá gbàdúrà pé káwọn ọ̀tá òun dẹni tí kò lágbára mọ́.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
51:1-4, 17. Pé a dá ẹ̀ṣẹ̀ kan kò túmọ̀ sí pé àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run ti bà jẹ́ nìyẹn. Tá a bá ronú pìwà dà, a lè ní ìdánilójú pé á ṣàánú wa.
51:5, 7-10. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí jì wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. A tún lè gbàdúrà pé kó wẹ̀ wá mọ́, kó sọ wá dọ̀tun, kó sì ràn wá lọ́wọ́ láti mú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lọ́kàn wa, kó tún fún wa ní ẹ̀mí tó máa jẹ́ ká fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
51:18. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo orílẹ̀-èdè náà síyọnu. Ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìfẹ́ rere rẹ̀ hàn sí Síónì. Nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá, ó sábà máa ń kó àbààwọ́n bá orúkọ Jèhófà àti ìjọ. A ní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó bá wa ṣàtúnṣe ohun tá a ti bà jẹ́.
52:8. A lè dà bíi “igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run,” ìyẹn ni pé a lè sún mọ́ Jèhófà ká sì máa so èso tó dáa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nípa ṣíṣègbọràn sí i àti nípa fífi gbogbo ọkàn tẹ́wọ́ gba ìbáwí.—Hébérù 12:5, 6.
55:4, 5, 12-14, 16-18. Ọ̀tẹ̀ tí Ábúsálómù ọmọ Dáfídì fúnra rẹ̀ dì mọ́ ọn àti dídà tí Áhítófẹ́lì tó máa ń gbà á nímọ̀ràn dà á kó ìbànújẹ́ ọkàn tó burú jáì bá Dáfídì. Àmọ́, ìyẹn ò dín ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà kù. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbànújẹ́ èyíkéyìí dín ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Ọlọ́run kù.
55:22. Báwo la ṣe ń ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà? À ń ṣe èyí (1) nípa sísọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún un nínú àdúrà, (2) nípa gbígbára lé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà àti láti tì wá lẹ́yìn, àti (3) nípa ṣíṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà.—Òwe 3:5, 6; 11:14; 15:22; Fílípì 4:6, 7.
56:8. Kì í ṣe pé Jèhófà mọ ìṣòro wa nìkan, àmọ́ ó tún mọ báwọn ìṣòro náà ṣe ń bà wá lọ́kàn jẹ́ tó.
62:11. Kò síbi tí Ọlọ́run ti ń gba agbára. Òun gan-an ni orísun agbára. ‘Tirẹ̀ ni okun.’
63:3. ‘Inú rere onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run sàn ju ìyè,’ nítorí pé láìsí i, òtúbáńtẹ́ ni ìgbésí ayé èèyàn. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́.
63:6. Òru jẹ́ àkókò tí ibi gbogbo máa ń dákẹ́ rọ́rọ́ tí kò sì ní sí ohunkóhun tó ń gba àfiyèsí èèyàn, àkókò yìí jẹ́ àkókò tó dára jù lọ láti ṣe àṣàrò.
64:2-4. Òfófó lè ba orúkọ rere ẹnì kan jẹ́. A ò gbọ́dọ̀ máa fetí sí irú òfófó bẹ́ẹ̀ tàbí ká máa tàn án kálẹ̀.
69:4. Tá a bá fẹ́ kí àlàáfíà wà, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ láti ṣe nígbà mìíràn ni pé ká “dá” nǹkan “padà,” ìyẹn ni pé ká tọrọ àforíjì, bí kò tilẹ̀ dá wa lójú pé àwa la jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.
70:1-5. Jèhófà máa ń tẹ́tí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa pé kó ràn wá lọ́wọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:17; Jákọ́bù 1:13; 2 Pétérù 2:9) Ọlọ́run lè fàyè gba àdánwò kan láti máa bá a lọ, síbẹ̀ yóò fún wa ní ọgbọ́n tá a máa fi kojú ìṣòro náà àti okun tá a máa fi fara dà á. Kò ní jẹ́ kí a dán wa wò ju ibi tí agbára wa mọ lọ.—1 Kọ́ríńtì 10:13; Hébérù 10:36; Jákọ́bù 1:5-8.
71:5, 17. Dáfídì ní ìgboyà àti okun nítorí pé ó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, kódà kó tó di pé ó dojú kọ Gòláyátì, òmìrán ará Filísínì yẹn. (1 Sámúẹ́lì 17:34-37) Á dára káwọn ọ̀dọ́ máa gbára lé Jèhófà nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.
“Kí Ògo Rẹ̀ sì Kún Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”
Orin tó kẹ́yìn nínú ìsọ̀rí kejì ìwé sáàmù, ìyẹn Sáàmù kejìléláàádọ́rin, dá lórí ìṣàkóso Sólómọ́nì, tó fi bí ipò nǹkan ṣe máa rí lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà hàn. Àwọn ìbùkún tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀ mà kọyọyọ o, ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà yóò wà, ìninilára àti ìwà ipá yóò kásẹ̀ nílẹ̀, ọ̀pọ̀ yanturu ọkà yóò sì wà lórí ilẹ̀ ayé! Ṣé a máa wà lára àwọn tó máa gbádùn àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn ìbùkún mìíràn tí Ìjọba náà máa mú wá? A lè wà lára wọn tá a bá ṣe bíi ti onísáàmù náà, tá a fára balẹ̀ dúró de Jèhófà, tá a sì fi í ṣe ààbò àti okun wa.
“Àwọn àdúrà Dáfídì . . . wá sí òpin” pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ẹni tí ó jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu. Ìbùkún sì ni fún orúkọ rẹ̀ ológo fún àkókò tí ó lọ kánrin, kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Àmín àti Àmín.” (Sáàmù 72:18-20) Ẹ jẹ́ káwa náà máa fi gbogbo ọkàn wa bù kún Jèhófà ká sì máa yin orúkọ rẹ̀ ológo.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí “ọmọbìnrin ọba” dúró fún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
A pe Jerúsálẹ́mù ní “ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra.”
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tá a fi pè é bẹ́ẹ̀?