Sí Àwọn Hébérù
12 Nígbà náà, torí pé a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó pọ̀ gan-an yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa náà ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù àti ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń wé mọ́ wa tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn,+ ká sì máa fi ìfaradà sá eré ìje tó wà níwájú wa,+ 2 bí a ṣe ń tẹjú mọ́ Jésù, Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.+ Torí ayọ̀ tó wà níwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró,* kò ka ìtìjú sí, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.+ 3 Ní tòótọ́, ẹ fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó fara da irú ọ̀rọ̀ kòbákùngbé bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tí wọ́n ń ṣàkóbá fún ara wọn, kó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ má sì sọ̀rètí nù.*+
4 Bí ẹ ṣe ń bá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jà, ẹ ò tíì ta kò ó débi pé kí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ rárá. 5 Ẹ sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pátápátá, tó fi bá yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé: “Ọmọ mi, má fojú kéré ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà,* má sì sọ̀rètí nù nígbà tó bá tọ́ ọ sọ́nà; 6 torí àwọn tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí, àní, gbogbo ẹni tó gbà bí ọmọ ló máa ń nà lẹ́gba.”*+
7 Ẹ nílò ìfaradà bí ẹ ṣe ń gba ìbáwí.* Ọlọ́run mú yín bí ọmọ.+ Torí ọmọ wo ni bàbá kì í bá wí?+ 8 Àmọ́ tí gbogbo yín ò bá tíì pín nínú ìbáwí yìí, a jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ. 9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+ 10 Torí ìgbà díẹ̀ ni wọ́n fi ń bá wa wí, bó ṣe dáa lójú wọn, àmọ́ torí ire wa ni òun ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ká lè pín nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.+ 11 Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tó jẹ́ ohun ayọ̀ báyìí, àmọ́ ó máa ń dunni;* síbẹ̀, tó bá yá, ó máa ń so èso àlàáfíà ti òdodo fún àwọn tí a ti fi dá lẹ́kọ̀ọ́.
12 Torí náà, ẹ fún àwọn ọwọ́ tó rọ jọwọrọ àti àwọn orúnkún tí kò lágbára lókun,+ 13 kí ẹ sì máa ṣe ọ̀nà tó tọ́ fún ẹsẹ̀ yín,+ kí ohun tó rọ má bàa yẹ̀ kúrò ní oríkèé, àmọ́ ká lè wò ó sàn. 14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn+ àti ìsọdimímọ́,*+ tó jẹ́ pé láìsí i, èèyàn kankan ò lè rí Olúwa. 15 Ẹ kíyè sára gidigidi ká má bàa rí ẹnikẹ́ni tí kò ní gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí gbòǹgbò kankan tó ní májèlé má bàa rú yọ láti dá wàhálà sílẹ̀, kó sì sọ ọ̀pọ̀ di aláìmọ́;+ 16 kí ẹ sì máa kíyè sára, kó má bàa sí ẹnì kankan láàárín yín tó jẹ́ oníṣekúṣe* tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọyì àwọn ohun mímọ́, bí Ísọ̀, tó fi àwọn ẹ̀tọ́ àkọ́bí tó ní tọrẹ nítorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.+ 17 Torí ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn náà, nígbà tó fẹ́ gba ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́; torí bó tiẹ̀ sunkún bó ṣe gbìyànjú gan-an láti mú kí èrò yí pa dà,*+ pàbó ló já sí.*
18 Torí kì í ṣe ohun tó ṣeé fọwọ́ bà,+ tí a sì dáná sí,+ lẹ sún mọ́, kì í ṣe ìkùukùu* tó ṣú dùdù àti òkùnkùn biribiri àti ìjì,+ 19 àti ìró kàkàkí+ àti ohùn tó ń sọ̀rọ̀,+ èyí tó jẹ́ pé nígbà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ọ, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé ká má ṣe bá àwọn sọ̀rọ̀ mọ́.+ 20 Torí wọn ò lè mú àṣẹ náà mọ́ra pé: “Tí ẹranko pàápàá bá fara kan òkè náà, ẹ gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta.”+ 21 Bákan náà, ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù débi pé Mósè sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà mí, jìnnìjìnnì sì bò mí.”+ 22 Àmọ́ ẹ ti sún mọ́ Òkè Síónì+ àti ìlú Ọlọ́run alààyè, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run+ àti ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn áńgẹ́lì 23 tí wọ́n kóra jọ+ àti ìjọ àwọn àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ọ̀run àti Ọlọ́run Onídàájọ́ gbogbo ẹ̀dá+ àti ìgbésí ayé àwọn olódodo nípa ti ẹ̀mí,+ àwọn tí a ti sọ di pípé+ 24 àti Jésù alárinà+ májẹ̀mú tuntun + àti ẹ̀jẹ̀ tí a wọ́n, tó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa ju ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì lọ.+
25 Ẹ rí i pé ẹ ò di etí yín sí* ẹni tó ń sọ̀rọ̀.* Torí tí àwọn tó kọ̀ láti fetí sí ẹni tó ń kéde ìkìlọ̀ Ọlọ́run ní ayé kò bá yè bọ́, báwo wá ni àwa ṣe lè yè bọ́ tí a bá yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run!+ 26 Nígbà yẹn, ohùn rẹ̀ mi ayé jìgìjìgì,+ àmọ́ ní báyìí, ó ti ṣèlérí pé: “Lẹ́ẹ̀kan sí i, kì í ṣe ayé nìkan ni màá mì jìgìjìgì, màá mi ọ̀run pẹ̀lú.”+ 27 Ọ̀rọ̀ náà “lẹ́ẹ̀kan sí i” tọ́ka sí i pé a máa mú àwọn ohun tí a mì kúrò, àwọn ohun tí a ti ṣe, kí àwọn ohun tí a ò mì lè dúró. 28 Torí náà, bí a ṣe rí i pé a máa tẹ́wọ́ gba Ìjọba kan tí kò ṣeé mì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀. 29 Torí Ọlọ́run wa jẹ́ iná tó ń jóni run.+