ORÍ 2
“Ọlọ́run Fọwọ́ Sí” Àwọn Ẹ̀bùn Wọn
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìtàn nípa ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́
1-3. (a) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ dáhùn? (b) Àwọn nǹkan mẹ́rin pàtàkì wo la máa jíròrò nípa ìjọsìn mímọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
ÉBẸ́LÌ fara balẹ̀ yẹ agbo ẹran rẹ̀ wò. Látìgbà tí wọ́n ti bí wọn ló ti ń bójú tó wọn. Àmọ́ ní báyìí, ó mú àwọn kan lára àwọn ẹran náà, ó dúńbú wọn, ó sì fi ṣe ẹ̀bùn fún Ọlọ́run. Ṣé Jèhófà máa fọwọ́ sí ohun tí èèyàn aláìpé ṣe láti jọ́sìn rẹ̀ yìí?
2 Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé nípa Ébẹ́lì pé: “Ọlọ́run fọwọ́ sí àwọn ẹ̀bùn rẹ̀.” Àmọ́ Jèhófà kò tẹ́wọ́ gba ẹbọ Kéènì. (Ka Hébérù 11:4.) Èyí mú ká béèrè àwọn ìbéèrè kan tó yẹ ká ronú lé. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi tẹ́wọ́ gba ìjọsìn Ébẹ́lì àmọ́ tí kò gba ìjọsìn Kéènì? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Kéènì àti Ébẹ́lì àti àwọn míì tí ìwé Hébérù orí 11 sọ̀rọ̀ nípa wọn? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ohun tó rọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́.
3 Bá a ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ látìgbà ayé Ébẹ́lì sí ìgbà ayé Ìsíkíẹ́lì, kíyè sí nǹkan mẹ́rin pàtàkì tá a ní láti ṣe láìyọ ìkankan sílẹ̀ kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa: Jèhófà ni ẹni tá a gbọ́dọ̀ fún, ohun tó dáa jù lọ la gbọ́dọ̀ ṣe, ọ̀nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí la gbọ́dọ̀ gbà ṣe é àti pé ẹni tó ń ṣe ìjọsìn náà gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́.
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Gba Ìjọsìn Kéènì?
4, 5. Kí ló mú kí Kéènì pinnu pé òun fẹ́ mú ẹ̀bùn wá fún Ọlọ́run?
4 Ka Jẹ́nẹ́sísì 4:2-5. Kéènì mọ̀ pé Jèhófà ni ẹni tí òun fẹ́ fún ní ẹ̀bùn náà. Kéènì ní àkókò tó pọ̀ gan-an, ó sì tún láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí òun àti Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún nígbà tí wọ́n mú ẹ̀bùn wọn wá.a Bí àwọn méjèèjì ṣe ń dàgbà, wọ́n á ti mọ̀ nípa ọgbà Édẹ́nì, wọ́n tiẹ̀ lè ti máa rí ọgbà tó rẹwà yẹn lọ́ọ̀ọ́kán. Ó dájú pé wọ́n á ti rí àwọn kérúbù tó dúró sí ẹnu ọ̀nà ọgbà náà. (Jẹ́n. 3:24) Àwọn òbí wọn á sì ti sọ fún wọn pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo àti pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn báyìí, ìyẹn bí ara wọn ṣe ń kú lọ díẹ̀díẹ̀, kọ́ ni Jèhófà ní lọ́kàn fún àwa èèyàn níbẹ̀rẹ̀. (Jẹ́n. 1:24-28) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ohun tí Kéènì mọ̀ yìí ló mú kó pinnu láti mú ẹ̀bùn wá fún Ọlọ́run.
5 Nǹkan míì wo ló ṣeé ṣe kó mú kí Kéènì pinnu láti rúbọ sí Ọlọ́run? Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “ọmọ” kan máa wà, tó máa fọ́ orí “ejò náà,” ìyẹn ejò tó tan Éfà, tó mú kó ṣe ìpinnu tó burú jáì yẹn. (Jẹ́n. 3:4-6, 14, 15) Torí pé Kéènì ni àkọ́bí, ó ṣeé ṣe kó ti máa ronú pé òun ni “ọmọ” tí a ṣèlérí náà. (Jẹ́n. 4:1) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ṣì ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀; kódà lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó ṣe kedere pé Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ áńgẹ́lì. (Jẹ́n. 3:8-10) Jèhófà sì tún bá Kéènì sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó rúbọ. (Jẹ́n. 4:6) Ó dájú pé Kéènì mọ̀ pé Jèhófà ni ìjọsìn tọ́ sí.
6, 7. Ṣé ohun tí Kéènì fi rúbọ àbí ọ̀nà tó gbà rúbọ ni kò dáa tó? Ṣàlàyé.
6 Kí wá nìdí tí Jèhófà ò fi tẹ́wọ́ gba ẹbọ Kéènì rárá? Àbí ẹ̀bùn tó mú wá kò dáa tó ni? Bíbélì kò sọ. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé Kéènì mú “àwọn èso kan wá.” Nínú Òfin tí Jèhófà fún Mósè nígbà tó yá, ó sọ níbẹ̀ pé òun tẹ́wọ́ gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀. (Nọ́ń. 15:8, 9) Bákan náà, ronú nípa bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn. Irè oko nìkan làwọn èèyàn máa ń jẹ nígbà yẹn. (Jẹ́n. 1:29) Kéènì sì ti jìyà gan-an kó tó lè mú ẹbọ yẹn wá torí pé Ọlọ́run ti gégùn-ún fún ilẹ̀ tó wà lẹ́yìn ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 3:17-19) Oúnjẹ tó ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn fún kó lè fi gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ ró ló fi rúbọ! Síbẹ̀, Jèhófà ò tẹ́wọ́ gba ẹbọ Kéènì.
7 Àbí bó ṣe mú ẹbọ yẹn wá ni kò dáa ni? Bóyá ọ̀nà tó gbà mú un wá ni kò ní ìtẹ́wọ́gbà. Kò dájú pé ìyẹn ló fà á. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà tí Jèhófà kò tẹ́wọ́ gba ẹbọ Kéènì, kò sọ pé bó ṣe mú ẹbọ náà wá kò dáa. Kódà, Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí Kéènì tàbí Ébẹ́lì gbà rú ẹbọ wọn. Kí ló wá burú nínú ohun tó wáyé yẹn?
8, 9. (a) Kí nìdí tí inú Jèhófà ò fi dùn sí Kéènì àti ẹbọ rẹ̀? (b) Kí lo kíyè sí nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa Kéènì àti Ébẹ́lì?
8 Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sí àwọn Hébérù jẹ́ ká rí i pé Kéènì kò ní èrò tó tọ́ nípa ohun tó fi rúbọ. Kò nígbàgbọ́. (Héb. 11:4; 1 Jòh. 3:11, 12) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà kò fi ṣojúure sí Kéènì fúnra ẹ̀ àti ohun tó mú wá. (Jẹ́n. 4:5-8) Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, torí náà ó gbìyànjú láti fi sùúrù tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà. Àmọ́ ṣe ni Kéènì kọ etí dídi sí ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Kéènì jẹ́ kí iṣẹ́ ẹran ara aláìpé gbilẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀, ìyẹn ‘ìkórìíra, wàhálà àti owú.’ (Gál. 5:19, 20) Tí Kéènì bá tiẹ̀ ṣe àwọn nǹkan míì tó dáa nínú ìjọsìn rẹ̀, kò lè lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ torí ọkàn burúkú tó ní. Àpẹẹrẹ Kéènì kọ́ wa pé ìjọsìn mímọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé ká kàn máa ṣojú ayé bíi pé à ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.
9 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì sọ fún wa nípa Kéènì. A kà nípa bí Jèhófà ṣe bá Kéènì sọ̀rọ̀ àti bó ṣe fèsì, a tún rí orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ àti díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n ṣe. (Jẹ́n. 4:17-24) Ní ti Ébẹ́lì, a ò rí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ó bímọ, kò sì sí àkọsílẹ̀ ohunkóhun tí Ébẹ́lì sọ nínú Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn ohun tí Ébẹ́lì ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ títí di báyìí. Lọ́nà wo?
Ébẹ́lì Fi Àpẹẹrẹ Ìjọsìn Mímọ́ Lélẹ̀
10. Àpẹẹrẹ wo ni Ébẹ́lì fi lélẹ̀ nípa ìjọsìn mímọ́?
10 Nígbà tí Ébẹ́lì rúbọ sí Jèhófà, ó mọ̀ pé Jèhófà nìkan ni ẹni tó yẹ kí òun fún ní ẹ̀bùn yẹn. Ohun tó dáa jù lọ ló fi ṣe ẹ̀bùn tó mú wá. Ó mú “lára àwọn àkọ́bí ẹran rẹ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò rí i kà bóyá orí pẹpẹ ló ti fi rúbọ àbí kò fi rúbọ lórí pẹpẹ, ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ọ̀nà tó gbà fi rúbọ. Ohun tó ta yọ jù lọ nípa ẹ̀bùn tí Ébẹ́lì mú wa ni pé Ébẹ́lì ní èrò tó tọ́. Àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọdún sẹ́yìn yẹn ṣì ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ títí dòní. Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí Ébẹ́lì ní fún ìlànà òdodo Jèhófà ló mú kó rú ẹbọ yẹn. Báwo la ṣe mọ̀?
11. Kí nìdí tí Jésù fi pe Ébẹ́lì ní olódodo?
11 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wo ohun tí Jésù sọ nípa Ébẹ́lì torí ó mọ̀ ọ́n dáadáa. Jésù wà ní ọ̀run nígbà tí Ébẹ́lì gbé ayé. Jésù nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí ọmọ Ádámù yìí. (Òwe 8:22, 30, 31; Jòh. 8:58; Kól. 1:15, 16) Torí náà, nígbà tí Jésù pe Ébẹ́lì ní olódodo, ohun tó fojú ara ẹ̀ rí ló ń sọ. (Mát. 23:35) Ẹni tó bá gbà pé Jèhófà ló yẹ kó fi ìlànà lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ la lè pè ní olódodo. Àmọ́, kì í wulẹ̀ ṣe pé kí ẹni náà gbà nìkan, ó tún gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà rẹ̀ pé òun fara mọ́ àwọn ìlànà yẹn. (Fi wé Lúùkù 1:5, 6.) Ó máa ń gba àkókò ká tó lè mọ ẹnì kan sí olódodo. Torí náà, kí Ébẹ́lì tó mú ẹ̀bùn wá fún Ọlọ́run, ó ti ní láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó fi hàn pé ó máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Ìyẹn kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá. Torí kò dájú pé Kéènì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, ìwà ìkà ti kún ọkàn Kéènì. (1 Jòh. 3:12) Ìyá Ébẹ́lì kò tẹ̀ lé òfin tó ṣe tààràtà tí Ọlọ́run fún wọn, bàbá rẹ̀ sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó fẹ́ máa pinnu ohun tó dára àti èyí tó burú fúnra rẹ̀. (Jẹ́n. 2:16, 17; 3:6) Ẹ ò rí i pé ó gba ìgboyà gan-an kí Ébẹ́lì tó lè ṣe ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ará ilé rẹ̀!
12. Ohun pàtàkì wo ló mú kí Ébẹ́lì yàtọ̀ sí Kéènì?
12 Yàtọ̀ síyẹn, wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa bí òdodo àti ìgbàgbọ́ ṣe tan mọ́ra. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ mú kí Ébẹ́lì rú ẹbọ tó níye lórí ju ti Kéènì lọ sí Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ náà sì mú kó rí ẹ̀rí pé ó jẹ́ olódodo.” (Héb. 11:4) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé ìgbàgbọ́ àtọkànwá tí Ébẹ́lì ní fún Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀, jálẹ̀ ayé rẹ̀, ló mú kó sún mọ́ Ọlọ́run, ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sí ti Kéènì.
13. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Ébẹ́lì ṣe?
13 Àpẹẹrẹ Ébẹ́lì jẹ́ ká rí i pé ọkàn tó ní èrò tó tọ́ nìkan la lè fi ṣe ìjọsìn mímọ́, ìyẹn ọkàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà dáadáa, tó sì fara mọ́ àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Bákan náà, a tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ìjọsìn mímọ́ kọjá ìjọsìn téèyàn ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ó kan gbogbo ìgbésí ayé wa, ìyẹn gbogbo ohun tá à ń ṣe.
Àwọn Baba Ńlá Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tó Fi Lélẹ̀
14. Kí nìdí tí Jèhófà fi tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn tí Nóà, Ábúráhámù àti Jékọ́bù mú wá?
14 Ébẹ́lì ni èèyàn aláìpé tó kọ́kọ́ ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Jèhófà, àmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọ́ ló mọ sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ẹlòmíì tí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, àwọn bíi Nóà, Ábúráhámù àti Jékọ́bù. (Ka Hébérù 11:7, 8, 17-21.) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí rúbọ sí Jèhófà nígbà kan tàbí òmíràn nígbèésí ayé wọn, Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn ò ṣe ìjọsìn ojú ayé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn tún ṣe gbogbo nǹkan pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ wọn.
15, 16. Ọ̀nà wo ni Nóà gbà ṣe nǹkan mẹ́rin pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́?
15 Ọdún mẹ́rìndínláàádóje (126) lẹ́yìn tí Ádámù kú ni wọ́n bí Nóà; síbẹ̀ inú ayé tí ìjọsìn èké ti gbòde kan ló dàgbà sí.b (Jẹ́n. 6:11) Nínú gbogbo ìdílé tó wà láyé kété kí Ìkún Omi tó wáyé, Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló sin Jèhófà bó ṣe tọ́. (2 Pét. 2:5) Lẹ́yìn tí Nóà la Ìkún Omi já, ìmọrírì tó ní mú kó mọ pẹpẹ, ó sì rúbọ sí Jèhófà, pẹpẹ yẹn ni Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní tààràtà. Ohun tí Nóà ṣe tọkàntọkàn yìí kọ́ ìdílé rẹ̀ àti gbogbo ìran èèyàn tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tó ṣe kedere, ìyẹn ni pé Jèhófà nìkan ni ẹni tó yẹ ká fún ní ìjọsìn. Nínú gbogbo ẹran tó wà níkàáwọ́ Nóà tó lè fi rúbọ, “ó mú lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti lára gbogbo ẹ̀dá tó ń fò tó sì mọ́.” (Jẹ́n. 8:20) Ohun tó dáa jù lọ ló fi rúbọ, torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ló pè wọ́n ní ẹran tó mọ́.—Jẹ́n. 7:2.
16 Orí pẹpẹ tí Nóà fúnra rẹ̀ kọ́ ló ti rú àwọn ẹbọ sísun yìí. Ṣé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tí Nóà gbà jọ́sìn rẹ̀ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí òórùn dídùn ẹbọ náà, ó sì súre fún Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀. (Jẹ́n. 8:21; 9:1) Àmọ́ ní pàtàkì, ohun tó mú kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹbọ náà ni èrò tó tọ́ tí Nóà ní, tó sì mú kó rú ẹbọ náà. Nóà tún fi hàn nípasẹ̀ ẹbọ tó rú yìí pé òun ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà àti ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣe nǹkan. Bíbélì sọ pé Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” torí pé ìgbà gbogbo ló máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà, tó sì máa ń tẹ̀ lé ìlànà Rẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí Nóà wá di ẹni tá a mọ̀ sí olódodo títí dòní olónìí.—Jẹ́n. 6:9; Ìsík. 14:14; Héb. 11:7.
17, 18. Ọ̀nà wo ni Ábúráhámù gbà ṣe nǹkan mẹ́rin pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́?
17 Àwọn ẹlẹ́sìn èké ló yí Ábúráhámù ká. Tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ fún ọlọ́run òṣùpá tí wọ́n ń pè ní Nánà ló tóbi jù ní ìlú Úrì tí Ábúráhámù ń gbé.c Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí bàbá Ábúráhámù pàápàá jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. (Jóṣ. 24:2) Síbẹ̀, Ábúráhámù pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀dọ̀ Ṣémù baba ńlá rẹ̀, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Nóà, ló ti kọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́. Àádọ́jọ (150) ọdún ni wọ́n fi jọ gbé láyé.
18 Ábúráhámù pẹ́ láyé gan-an, ó sì rú ọ̀pọ̀ ẹbọ sí Jèhófà jálẹ̀ ayé rẹ̀. Àmọ́ Jèhófà, ẹnì kan ṣoṣo tó yẹ ká fún ní ìjọsìn ló máa ń rúbọ sí nígbà gbogbo. (Jẹ́n. 12:8; 13:18; 15:8-10) Ṣé Ábúráhámù múra tán láti fún Jèhófà ní ẹbọ tó dáa jù lọ? Ìdáhùn ìbéèrè yìí túbọ̀ dá wa lójú gan-an nígbà tí Ábúráhámù fi hàn pé òun ṣe tán láti fi Ísákì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ. Nígbà yẹn, Jèhófà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bó ṣe fẹ́ kí Ábúráhámù rú ẹbọ náà. (Jẹ́n. 22:1, 2) Ábúráhámù sì ṣe tán láti tẹ̀ lé ìtọ́ni yẹn láìkù síbì kan. Jèhófà ló dá Ábúráhámù dúró tí kò fi pa ọmọ rẹ̀. (Jẹ́n. 22:9-12) Jèhófà sì tẹ́wọ́ gba àwọn ohun tí Ábúráhámù ṣe láti jọ́sìn rẹ̀ torí pé èrò tó tọ́ ló máa ń mú kó rúbọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì kà á sí òdodo fún un.”—Róòmù 4:3.
19, 20. Ọ̀nà wo ni Jékọ́bù gbà ṣe nǹkan mẹ́rin pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́?
19 Ilẹ̀ Kénáánì ni Jékọ́bù ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún Ábúráhámù àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Jẹ́n. 17:1, 8) Àwọn èèyàn ibẹ̀ máa ń ṣèṣekúṣe tó burú jáì nínú ìjọsìn wọn, débi tí Jèhófà fi sọ nípa wọn pé ṣe ni ilẹ̀ yẹn máa “pọ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ jáde.” (Léf. 18:24, 25) Nígbà tí Jékọ́bù pé ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77), ó kúrò ní ìlú Kénáánì, ó gbéyàwó, ó sì pa dà síbẹ̀ nígbà tó yá pẹ̀lú agbo ilé ńlá. (Jẹ́n. 28:1, 2; 33:18) Àmọ́, ìjọsìn èké ti nípa lórí àwọn kan nínú ìdílé rẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí Jèhófà ní kí Jékọ́bù lọ sí Bẹ́tẹ́lì, kó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, Jékọ́bù ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ó kọ́kọ́ sọ fún ìdílé rẹ̀ pé: “Ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì tó wà láàárín yín kúrò, kí ẹ wẹ ara yín mọ́.” Lẹ́yìn náà, ó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún un láìkù síbì kan.—Jẹ́n. 35:1-7.
20 Jékọ́bù mọ pẹpẹ mélòó kan sí Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ Jèhófà ni ẹni tó máa ń jọ́sìn nígbà gbogbo. (Jẹ́n. 35:14; 46:1) Bí àwọn ẹbọ tí Jékọ́bù rú ṣe dáa gan-an, ọ̀nà tó gbà ń sin Ọlọ́run àti èrò tó ní ló mú kí Bíbélì pè é ní “aláìlẹ́bi,” ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí àwọn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. (Jẹ́n. 25:27) Bí Jékọ́bù ṣe lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn tó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Jẹ́n. 35:9-12.
21. Kí la rí kọ́ nípa ìjọsìn mímọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn baba ńlá ìgbà àtijọ́?
21 Kí la rí kọ́ nípa ìjọsìn mímọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn baba ńlá ìgbà àtijọ́? Bíi tiwọn, àwọn tó lè dí wa lọ́wọ́ ká má bàa fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà ló yí wa ká, wọ́n tiẹ̀ lè jẹ́ mọ̀lẹ́bí wa pàápàá. Ká tó lè jára wa gbà, ó gba pé ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà lágbára gan-an, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ ló dáa jù lọ. Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, tá à ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. (Mát. 22:37-40; 1 Kọ́r. 10:31) Ẹ ò rí i pé ó dáa gan-an bá a ṣe mọ̀ pé tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jọ́sìn Jèhófà, tá a ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fẹ́, tá a sì ní èrò tó tọ́, ó máa kà wá sí olódodo!—Ka Jémíìsì 2:18-24.
Orílẹ̀-Èdè Tí A Yà Sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Mímọ́
22-24. Báwo ni Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tó yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn, irú ohun tí wọ́n máa fi rúbọ àti ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà jọ́sìn?
22 Jèhófà fún àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù ní Òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tó fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Tí wọ́n bá gbọ́ ti Jèhófà, wọ́n á di ‘ohun ìní rẹ̀ pàtàkì’ àti “orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kís. 19:5, 6) Wo bí Òfin yẹn ṣe tẹnu mọ́ nǹkan mẹ́rin pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́.
23 Jèhófà jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ẹni tó yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn. Jèhófà sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.” (Ẹ́kís. 20:3-5) Tí wọ́n bá fẹ́ rúbọ sí i, àwọn ohun tó dáa jù lọ ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi rúbọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, tí kò ní àbùkù kankan. (Léf. 1:3; Diu. 15:21; fi wé Málákì 1:6-8.) Àwọn ọmọ Léfì jàǹfààní nínú àwọn ọrẹ táwọn èèyàn ń fún Jèhófà, àmọ́ àwọn náà gbọ́dọ̀ fún Jèhófà ní ọrẹ tiwọn. Inú “ohun tó dáa jù nínú gbogbo ẹ̀bùn” tí àwọn èèyàn fún wọn ni wọ́n á ti fún Jèhófà lẹ́bùn. (Nọ́ń. 18:29) Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn ìtọ́ni pàtó nípa ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà jọ́sìn, ó sọ ohun tí wọ́n á fi rúbọ, ibi tí wọ́n á ti rúbọ àti bí wọ́n á ṣe rú ẹbọ náà. Lápapọ̀, ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) òfin tí Ọlọ́run fún wọn, àwọn òfin yìí ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe, ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹ rí i pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín gẹ́lẹ́ lẹ̀ ń ṣe. Ẹ ò gbọ́dọ̀ yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.”—Diu. 5:32.
24 Ṣé ibi tó bá wu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti lè rúbọ? Rárá o. Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ibẹ̀ sì wá di ibi tí wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn mímọ́. (Ẹ́kís. 40:1-3, 29, 34) Nígbà yẹn, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ kí Ọlọ́run gba ọrẹ tí wọ́n mú wá, àfi kí wọ́n mú un wá sí àgọ́ ìjọsìn.d—Diu. 12:17, 18.
25. Kí ló ṣe pàtàkì jù tí ẹnì kan bá fẹ́ rúbọ? Ṣàlàyé.
25 Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni èrò tó tọ́ tó mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan mú ọrẹ wá! Ìfẹ́ àtọkànwá tó ní sí Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ sún un láti rúbọ. (Ka Diutarónómì 6:4-6.) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá kàn ń jọ́sìn Jèhófà torí ó ní kí wọ́n máa sin òun, Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba àwọn ẹbọ wọn. (Àìsá. 1:10-13) Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Àìsáyà fi yé wọn pé wọn ò lè fi ìjọsìn tí kò dénú tan òun jẹ, ó ní: “Àwọn èèyàn yìí . . . ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi.”—Àìsá. 29:13.
Ìjọsìn Nínú Tẹ́ńpìlì
26. Níbẹ̀rẹ̀, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ìjọsìn mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́?
26 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí, Ọba Sólómọ́nì kọ́ ibi ìjọsìn kan táwọn èèyàn á ti máa ṣe ìjọsìn mímọ́, ibẹ̀ sì lọ́lá ju àgọ́ ìjọsìn lọ. (1 Ọba 7:51; 2 Kíró. 3:1, 6, 7) Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, Jèhófà nìkan ni ẹni tí wọ́n ń rúbọ sí nínú tẹ́ńpìlì yìí. Sólómọ́nì àtàwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran rúbọ, àwọn ẹran tó dáa jù ni wọ́n lò, ọ̀nà tí Ọlọ́run là kalẹ̀ nínú Òfin ni wọ́n sì gbà ṣe é. (1 Ọba 8:63) Àmọ́, kì í ṣe iye tí wọ́n ná sórí tẹ́ńpìlì náà tàbí iye ẹran tí wọ́n fi rúbọ ló ń mú kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Èrò tó tọ́ tí àwọn tó ń rúbọ ní ló ṣe pàtàkì. Sólómọ́nì tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì. Ó ní: “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín sin Jèhófà Ọlọ́run wa láti máa rìn nínú àwọn ìlànà rẹ̀ àti láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ bíi ti òní yìí.”—1 Ọba 8:57-61.
27. Kí ni àwọn ọba Ísírẹ́lì àtàwọn tó wà lábẹ́ àkóso wọn ṣe, kí sì ni Jèhófà ṣe fún wọn?
27 Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Ọba Sólómọ́nì fún wọn. Wọn ò ṣe ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn nǹkan pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́. Àwọn ọba Ísírẹ́lì àtàwọn tó wà lábẹ́ àkóso wọn jẹ́ kí ọkàn wọn dìdàkudà, wọn ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà mọ́, wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Léraléra ni Jèhófà fìfẹ́ rán àwọn wòlíì pé kí wọ́n tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìwà tí wọ́n bá hù. (Jer. 7:13-15, 23-26) Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn wòlíì yẹn ni ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Ìsíkíẹ́lì. Ìgbà tí nǹkan ò rọrùn fún àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ ló gbé ayé.
Ìsíkíẹ́lì Rí Bí Ìjọsìn Mímọ́ Ṣe Dìdàkudà
28, 29. Kí la mọ̀ nípa Ìsíkíẹ́lì? (Wo àpótí náà, “Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ayé Ìsíkíẹ́lì.”)
28 Ìsíkíẹ́lì mọ ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ lámọ̀dunjú. Àlùfáà ni bàbá rẹ̀, iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì á sì ti yí kàn án dáadáa. (Ìsík. 1:3) Ó jọ pé ìgbésí ayé Ìsíkíẹ́lì dùn nígbà tó wà ní kékeré. Ó dájú pé bàbá rẹ̀ á ti kọ́ ọ nípa Jèhófà àti Òfin rẹ̀. Kódà, àsìkò tí wọ́n bí Ìsíkíẹ́lì ni wọ́n rí “ìwé Òfin” nínú tẹ́ńpìlì.e Ohun tí ọba rere tó ń ṣàkóso nígbà yẹn, ìyẹn Ọba Jòsáyà, gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó mú kó túbọ̀ gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ.—2 Ọba 22:8-13.
29 Ìsíkíẹ́lì ṣe bíi tàwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó wà ṣáájú rẹ̀, ó ṣe ohun mẹ́rin téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́. Bá a ṣe rí i nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, tọkàntọkàn ló fi sin Jèhófà, ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ọ̀nà tí Jèhófà bá sì ní kó gbà ṣe nǹkan ló máa ń gbà ṣe é. Ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Ìsíkíẹ́lì ní ló mú kó ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Àmọ́ ọ̀rọ̀ èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tí wọ́n jọ gbé ayé nígbà yẹn ò rí bẹ́ẹ̀. Àtìgbà tí Ìsíkíẹ́lì ti wà ní kékeré ló ti ń gbọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà, ọdún 647 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì, ó sì fìtara kéde ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ fáwọn èèyàn.
30. (a) Kí la rí nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì kọ? (b) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀, òye wo ló sì yẹ ká ní nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì? (Wo àpótí náà, “Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì.”)
30 Àwọn ohun tí Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì pé kó kọ sílẹ̀ jẹ́ ká rí bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe kẹ̀yìn sí ìjọsìn rẹ̀ tó. (Ka Ìsíkíẹ́lì 8:6.) Nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn Júdà wí, Ìsíkíẹ́lì wà lára àwọn tí wọ́n mú lọ sígbèkùn ní Bábílónì. (2 Ọba 24:11-17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà lára àwọn tí wọ́n mú, wọn ò fìyà jẹ ẹ́. Jèhófà ní iṣẹ́ tó fẹ́ kó ṣe láàárín àwọn èèyàn Rẹ̀ tó wà nígbèkùn. Ìran tó kàmàmà àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì kọ sílẹ̀ jẹ́ ká rí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ohun tó wà nínú àwọn àkọsílẹ̀ náà jùyẹn lọ, ó tún jẹ́ ká rí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
31. Kí ni ìwé yìí máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?
31 Nínú àwọn apá tí ìwé yìí pín sí, á máa sọ díẹ̀ nípa ọ̀run níbi tí Jèhófà gúnwà sí. A tún máa rí bí wọ́n ṣe sọ ìjọsìn mímọ́ di ẹlẹ́gbin, bí Jèhófà ṣe mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò àti bó ṣe gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. A sì máa rí bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí nígbà tí gbogbo aráyé á máa sin Jèhófà. Nínú orí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò ìran àkọ́kọ́ tí Ìsíkíẹ́lì kọ sílẹ̀. Ìran náà jẹ́ ká lè fojú inú rí àwòrán tó ṣe kedere nípa Jèhófà àti apá ti ọ̀run nínú ètò rẹ̀, ó sì tún gbìn ín sí wa lọ́kàn pé kò sí ẹlòmíì tí ìjọsìn mímọ́ tọ́ sí, àfi òun nìkan.
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò pẹ́ sígbà tí Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà kúrò ní Édẹ́nì ni wọ́n lóyún Ébẹ́lì. (Jẹ́n. 4:1, 2) Jẹ́nẹ́sísì 4:25 sọ pé Ọlọrun yan Sẹ́ẹ̀tì “rọ́pò Ébẹ́lì.” Ẹni àádóje (130) ọdún ni Ádámù nígbà tó bí Sẹ́ẹ̀tì, lẹ́yìn tí Kéènì pa Ébẹ́lì nípakúpa. (Jẹ́n. 5:3) Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì jẹ́ ẹni nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) ọdún nígbà tí Kéènì pa á.
b Jẹ́nẹ́sísì 4:26 sọ pé nígbà ayé Énọ́ṣì tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ádámù, “àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.” Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ń lo orúkọ náà lọ́nà tí kò tọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fi orúkọ Jèhófà pe àwọn òrìṣà wọn.
c Òrìṣà akọ tí wọ́n ń pè ní Nánà, ni wọ́n tún ń pè ní Sínì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ìlú Úrì ní àwọn òrìṣà tí wọ́n ń jọ́sìn, òun ni wọ́n dìídì kọ́ àwọn tẹ́ńpìlì àtàwọn pẹpẹ tó wà nílùú náà fún.
d Lẹ́yìn tí wọ́n gbé Àpótí mímọ́ kúrò nínú àgọ́ ìjọsìn, ó jọ pé Jèhófà gbà kí wọ́n rúbọ láwọn ibòmíì yàtọ̀ sí àgọ́ ìjọsìn.—1 Sám. 4:3, 11; 7:7-9; 10:8; 11:14, 15; 16:4, 5; 1 Kíró. 21:26-30.
e Ó jọ pé ọmọ ọgbọ̀n (30) ọdún ni Ìsíkíẹ́lì nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tẹ́lẹ̀ lọ́dún 613 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan bí ọdún 643 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bí i. (Ìsík. 1:1) Ọdún 659 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jòsáyà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, nǹkan bí ọdún kejìdínlógún (18) tàbí ọdún 642 sí 641 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tí Jòsáyà ti wà lórí oyè sì ni wọ́n rí ìwé Òfin, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tí wọ́n kọ́kọ́ fọwọ́ kọ.