ORÍ 22
“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”
Pọ́ọ̀lù múra tán láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù
Ó dá lórí Ìṣe 21:1-17
1-4. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sí i níbẹ̀?
INÚ àwọn ará ò dùn bí Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù ṣe ń fi wọ́n sílẹ̀ ní Mílétù. Ó sì dájú pé ó máa dun Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù nígbà tí wọ́n ń fi àwọn alàgbà ìjọ Éfésù sílẹ̀ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà yẹn gan-an! Àwọn míṣọ́nnárì méjèèjì yìí dìde dúró nínú ọkọ̀ ojú omi kan. Gbogbo ohun tí wọ́n máa nílò níbi tí wọ́n ń lọ ló wà nínú ẹrù wọn. Owó táwọn ará fi ṣètìlẹ́yìn fáwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní ní Jùdíà náà wà lọ́wọ́ wọn, ó sì wù wọ́n gan-an láti fi ọrẹ náà jíṣẹ́.
2 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yẹ́ẹ́ lórí omi, ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ gbéra, ó sì kúrò ní èbúté tí ariwo wà. Bí ọkọ̀ ojú omi náà ṣe ń lọ, Pọ́ọ̀lù, Lúùkù àtàwọn ọkùnrin méje míì tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò ń wo ojú àwọn ará tó sìn wọ́n dé èbúté, wọ́n sì rí i pé inú àwọn ará náà ò dùn. (Ìṣe 20:4, 14, 15) Àwọn tó ń rìnrìn àjò náà ń juwọ́ sáwọn ará yìí títí wọn ò fi rí wọn mọ́.
3 Pọ́ọ̀lù ti bá àwọn alàgbà tó wà nílùú Éfésù ṣiṣẹ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Àmọ́ ní báyìí, ó ti ń lọ sí Jerúsálẹ́mù bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí ẹ̀. Ó mọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun níbẹ̀, torí ó ti sọ fáwọn alàgbà náà tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ̀mí ti sọ ọ́ di dandan fún mi, mò ń rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀, kìkì pé ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́rìí fún mi léraléra láti ìlú dé ìlú pé ẹ̀wọ̀n àti ìpọ́njú ń dúró dè mí.” (Ìṣe 20:22, 23) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìyà máa jẹ òun, ó gbà pé “ẹ̀mí ti sọ ọ́ di dandan” fún òun láti lọ sí Jerúsálẹ́mù ó sì múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kú, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù sí i ni pé kó ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
4 Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe la ṣèlérí fún un pé ìfẹ́ rẹ̀ la fẹ́ ṣe àti pé ohun tó bá fẹ́ la máa jẹ́ kó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa. Nínú orí yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ká lè mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀.
Wọ́n Gba “Erékùṣù Sápírọ́sì” Kọjá (Ìṣe 21:1-3)
5. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò gbà lọ sí Tírè?
5 Ọkọ̀ ojú omi tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò wọ̀ “lọ tààrà” sí Kọ́sì torí pé kò sí atẹ́gùn tó lágbára tó dí wọn lọ́wọ́ lọ́jọ́ yẹn. (Ìṣe 21:1) Ó jọ pé ibẹ̀ ni ọkọ̀ náà wà di ọjọ́ kejì, kí wọ́n tó wá gbéra lọ sí Ródésì àti Pátárà. Nígbà tí wọ́n dé Pátárà, tó jẹ́ etíkun kan ní gúúsù Éṣíà Kékeré, wọ́n wọ ọkọ̀ òkun tó gbé wọn lọ sí Tírè ní Foníṣíà. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n gba “erékùṣù Sápírọ́sì” kọjá. (Ìṣe 21:3) Kí nìdí tí Lúùkù tó kọ̀wé Ìṣe fi sọ pé wọ́n gba Sápírọ́sì kọjá?
6. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fún Pọ́ọ̀lù lókun nígbà tó rí erékùṣù Sápírọ́sì? (b) Kí ló dá ẹ lójú bó o ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ?
6 Ó jọ pé Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó wà ní erékùṣù yẹn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹ̀ àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́sàn-án sígbà yẹn, òun, Bánábà àti Jòhánù Máàkù pàdé Élímà oníṣẹ́ oṣó tó ta ko iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe. (Ìṣe 13:4-12) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí erékùṣù yẹn tó sì rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i níbẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó ronú lé fún un lókun kó lè fara da àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí i ní Jerúsálẹ́mù. Àwa náà máa jàǹfààní tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa àti bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà á lè sọ bíi ti Dáfídì pé: “Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.”—Sm. 34:19.
‘A Wá Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn, A sì Rí Wọn’ (Ìṣe 21:4-9)
7. Kí làwọn tó ń rìnrìn àjò náà ṣe nígbà tí wọ́n dé Tírè?
7 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn wà láàárín àwọn ará, torí náà ó máa ń wù ú láti wà pẹ̀lú wọn. Nígbà tí wọ́n dé Tírè, Lúùkù kọ̀wé pé, ‘a wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn, a sì rí wọn.’ (Ìṣe 21:4) Àwọn tó ń rìnrìn àjò náà mọ̀ pé àwọn Kristẹni wà ní Tírè, torí náà wọ́n wá wọn rí, ó sì jọ pé wọ́n dúró lọ́dọ̀ wọn. Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tá a máa ń rí bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà ni pé, ibi yòówù ká lọ a máa ráwọn ará wa tó máa gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ ló ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi kárí ayé.
8. Kí lohun tó wà nínú ìwé Ìṣe 21:4 túmọ̀ sí?
8 Nígbà tí Lúùkù ń ṣàlàyé bí nǹkan ṣe lọ ní Tírè láàárín ọjọ́ méje tí wọ́n lò níbẹ̀, ó sọ ohun kan tó kọ́kọ́ dà bíi pé ó rúni lójú. Ó sọ pé: “Nítorí ohun tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn wọ́n, léraléra ni [àwọn ará tó wà ní Tírè] sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó má ṣe fẹsẹ̀ kan Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 21:4) Ṣé Jèhófà ti yí èrò ẹ̀ pa dà ni? Ṣé kò fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lọ sí Jerúsálẹ́mù mọ́ ni? Rárá o. Ẹ̀mí mímọ́ ti fi hàn pé ojú Pọ́ọ̀lù máa rí màbo ní Jerúsálẹ́mù, àmọ́ kò sọ pé kó má lọ síbẹ̀. Ó sì jọ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ káwọn ará tó wà ní Tírè mọ̀ pé òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù máa kojú ìṣòro ní Jerúsálẹ́mù. Torí náà, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù mú kí wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó má lọ sílùú yẹn. Kò burú bí wọ́n ṣe fẹ́ yọ Pọ́ọ̀lù nínú ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Àmọ́ torí pé Pọ́ọ̀lù ti múra tán láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó forí lé Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 21:12.
9, 10. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù rántí nígbà táwọn ará tó wà ní Tírè sọ fún un pé kó má lọ sí Jerúsálẹ́mù? (b) Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ń fẹ́, àmọ́ kí ni Jésù sọ?
9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbọ́ èrò àwọn ará yìí, ó ṣeé ṣe kó rántí ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé òun ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun jìyà tó pọ̀, kí wọ́n sì pa òun. Èyí ló mú kí Pétérù sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jésù pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.” Àmọ́ Jésù sọ pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ lo jẹ́ fún mi, torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.” (Mát. 16:21-23) Jésù ti pinnu láti kú ikú ìrúbọ tí Ọlọ́run fẹ́ kó kú. Ohun tí Pọ́ọ̀lù náà fẹ́ ṣe nìyẹn. Bíi ti àpọ́sítélì Pétérù, àwọn ará tó wà ní Tírè ní èrò tó dáa, àmọ́ wọn ò mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí Pọ́ọ̀lù lọ sí Jerúsálẹ́mù.
10 Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló máa ń fẹ́ ṣàánú ara wọn, kí wọ́n sì ṣe ohun tó máa rọ̀ wọ́n lọ́rùn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan náà ò dáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ ṣe ẹ̀sìn tó máa gbà wọ́n láyè láti máa ṣe ohun tó wù wọ́n, tí kò sì ní máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. Àmọ́, ohun tí Jésù sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi.” (Mát. 16:24) Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àmọ́ kì í ṣe ohun tó rọrùn.
11. Báwo làwọn ará tó wà ní Tírè ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
11 Ó ti tó àkókò báyìí fún Pọ́ọ̀lù, Lúùkù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò láti máa bá ìrìn àjò wọn lọ. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn ará Tírè nígbà tí wọ́n ń dágbére fún wọn wọni lọ́kàn gan-an. Èyí fi hàn pé àwọn ará Tírè nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an àti pé wọ́n fẹ́ kó ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò, wọ́n sì bá wọn dé etíkun. Gbogbo wọn kúnlẹ̀, wọ́n jọ gbàdúrà, wọ́n sì dágbére pé ó dìgbòóṣe. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù, Lúùkù àtàwọn tó ń bá wọn rìnrìn àjò wọ ọkọ̀ ojú omi míì lọ sí Tólẹ́máísì, níbi tí wọ́n ti pàdé àwọn ará, wọ́n sì wà lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan.—Ìṣe 21:5-7.
12, 13. (a) Báwo ni Fílípì ṣe fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (b) Báwo ni Fílípì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn bàbá tó jẹ́ Kristẹni lónìí?
12 Lúùkù ròyìn pé, lẹ́yìn náà Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò forí lé Kesaríà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n “wọ ilé Fílípì ajíhìnrere.”a (Ìṣe 21:8) Ó dájú pé inú wọn máa dùn bí wọ́n ṣe rí Fílípì. Ní Jerúsálẹ́mù, ní nǹkan bí ogún (20) ọdún sẹ́yìn, àwọn àpọ́sítélì yàn án láti bójú tó bí wọ́n ṣe ń pín oúnjẹ nínú ìjọ Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà yẹn. Ọjọ́ pẹ́ tí Fílípì ti ń fìtara wàásù. Ẹ rántí pé nígbà tí inúnibíni tú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ká, Fílípì lọ sí Samáríà ó sì ń wàásù níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wàásù fún ìwẹ̀fà ará Etiópíà ó sì ṣe ìrìbọmi fún un. (Ìṣe 6:2-6; 8:4-13, 26-38) Ẹ ò rí i pé tọkàntọkàn ni Fílípì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún!
13 Fílípì ń fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nìṣó. Bí Lúùkù ṣe pè é ní “ajíhìnrere” fi hàn pé ó ṣì ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní ìlú Kesaríà níbi tó ń gbé. Bákan náà, Fílípì láwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tó ń sọ tẹ́lẹ̀, èyí tó fi hàn pé wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá wọn.b (Ìṣe 21:9) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Fílípì ti ní láti sapá gan-an kí ìdílé rẹ̀ tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àbẹ́ ò rí i pé ó dáa káwọn bàbá tó jẹ́ Kristẹni tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Fílípì, káwọn náà nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí wọ́n sì máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ajíhìnrere.
14. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù bá lọ sọ́dọ̀ àwọn Kristẹni, àǹfààní wo làwa náà sì ní lónìí?
14 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń lọ láti ibì kan síbòmíì, ó máa ń wá àwọn tó jẹ́ Kristẹni, ó sì máa ń dé sọ́dọ̀ wọn. Ibi yòówù tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò bá dé sí làwọn ará ti máa ń gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Ó sì dájú pé tí wọ́n bá jọ wà pa pọ̀, wọ́n ‘máa ń fún ara wọn ní ìṣírí.’ (Róòmù 1:11, 12) Àwa náà ní irú àǹfààní yìí lónìí. Tá a bá ń gba alábòójútó àyíká àtìyàwó rẹ̀ sínú ilé wa láìka bí ilé wa ṣe mọ sí, ó máa ṣe wá láǹfààní gan-an.—Róòmù 12:13.
“Mo Ti Múra Tán Láti Kú” (Ìṣe 21:10-14)
15, 16. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Ágábù sọ, báwo lọ̀rọ̀ náà sì ṣe rí lára àwọn tó gbọ́ ọ?
15 Láàárín àkókò tí Pọ́ọ̀lù fi wà lọ́dọ̀ Fílípì, Ágábù táwọn ará bọ̀wọ̀ fún náà wá síbẹ̀. Àwọn tó pé jọ sílé Fílípì mọ̀ pé wòlíì ni Ágábù torí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ nígbà kan rí nípa ìyàn ńlá kan tó mú nígbà tí Kíláúdíù ń ṣàkóso. (Ìṣe 11:27, 28) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa rò pé: ‘Kí nìdí tí Ágábù fi wá? Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló tún fẹ́ sọ?’ Wọ́n ń wò ó bó ṣe mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ìyẹn aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ kan tó níbi tí wọ́n lè tọ́jú owó àtàwọn nǹkan míì sí. Ágábù fi àmùrè náà so ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ara rẹ̀. Ó wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn, ó ní: “Ohun tí ẹ̀mí mímọ́ sọ nìyí, ‘Bí àwọn Júù ṣe máa di ọkùnrin tí àmùrè yìí jẹ́ tirẹ̀ nìyí ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n á sì fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.’ ”—Ìṣe 21:11.
16 Àsọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó tún fi hàn pé, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láàárín Pọ́ọ̀lù àtàwọn Júù tó wà níbẹ̀ máa mú kí wọ́n fà á “lé ọwọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.” Ọkàn àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ò balẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Lúùkù sọ pé: “Tóò, nígbà tí a gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwa àti àwọn tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó má lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ni Pọ́ọ̀lù bá fèsì pé: ‘Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ sì fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi? Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé, mo ti múra tán láti kú ní Jerúsálẹ́mù nítorí orúkọ Jésù Olúwa, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn dè mí nìkan ni.’ ”—Ìṣe 21:12, 13.
17, 18. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun dúró lórí ìpinnu òun, kí làwọn ará sì ṣe?
17 Fojú inú wo bí ibẹ̀ ṣe máa rí lọ́jọ́ náà. Lúùkù àtàwọn ará tó kù bẹ Pọ́ọ̀lù pé kó má lọ. Kódà àwọn kan ń sunkún. Ohun táwọn ará ṣe yìí wọ Pọ́ọ̀lù lọ́kàn gan-an, ó wá rọra sọ fún wọn pé, ńṣe lẹ “fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.” Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ará tó wà ní Tírè ti ṣe ohun kan náà, àmọ́ Pọ́ọ̀lù dúró lórí ìpinnu ẹ̀, ohun kan náà ló sì ṣe báyìí. Ó wá ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kóun lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ẹ ò rí i pé Pọ́ọ̀lù ti mọ́kàn! Bí Jésù ṣe jẹ́ onígboyà títí dójú ikú, bẹ́ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù náà pinnu pé òun máa ṣe, torí náà ó múra tán láti lọ sí Jerúsálẹ́mù. (Héb. 12:2) Kì í ṣe pé ó wu Pọ́ọ̀lù kó kú o, àmọ́ tíkú bá dé, àǹfààní ló máa kà á sí pé òun kú nítorí pé òun jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi Jésù.
18 Kí làwọn ará wá ṣe? Ńṣe ni wọ́n fara mọ́ ìpinnu Pọ́ọ̀lù. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí a ò lè yí i lérò pa dà, a fi í sílẹ̀, a sọ pé: ‘Kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.’ ” (Ìṣe 21:14) Àwọn tó gbìyànjú láti yí Pọ́ọ̀lù lérò pa dà pé kó má lọ sí Jerúsálẹ́mù ò sọ pé Pọ́ọ̀lù gbọ́dọ̀ ṣe ohun táwọn sọ. Wọ́n fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, wọ́n gbà pé kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù nìyẹn níbi tó ti máa kú. Ká sọ pé àwọn tó fẹ́ràn Pọ́ọ̀lù ò gbìyànjú láti yí i lérò pa dà ni, ì bá túbọ̀ rọrùn fún un láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.
19. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù?
19 Ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ni pé: A ò gbọ́dọ̀ yí àwọn èèyàn lérò pa dà pé kí wọ́n má ṣe ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tó máa gba pé kí wọ́n yááfì àwọn nǹkan. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ló lè la ikú lọ bí èyí tí Pọ́ọ̀lù ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kì í rọrùn fáwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n yọ̀ǹda àwọn ọmọ wọn láti lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láwọn ibi tó jìnnà, síbẹ̀ wọ́n máa ń pinnu pé àwọn ò ní kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Arábìnrin Phyllis, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè England sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó bí fẹ́ lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi rárá, inú mi ò sì dùn torí mi ò mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀ máa jìn tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́ mo gbà pé ọmọ àmúyangàn lọmọ mi. Àìmọye ìgbà ni mo gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Òun fúnra ẹ̀ ló ṣèpinnu yẹn, torí náà, mi ò gbìyànjú láti yí i lérò pa dà. Ó ṣe tán, èmi náà ni mo kọ́ ọ pé kó fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Ó ti lé ní ọgbọ̀n (30) ọdún báyìí tó ti ń sìn nílẹ̀ òkèèrè, mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ torí pé ó ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.” Ẹ ò rí i pé ó dáa gan-an tá a bá ń fún àwọn ará wa tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú níṣìírí!
“Àwọn Ará Gbà Wá Tayọ̀tayọ̀” (Ìṣe 21:15-17)
20, 21. Kí ló fi hàn pé Pọ́ọ̀lù máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn ará, kí ló sì mú kó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀?
20 Nígbà tí wọ́n ṣe tán Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀, àwọn arákùnrin tó wà ní Kesaríà sì tẹ̀ lé e. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù àti pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni wọ́n. Bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n bá dé ìlú kan wọ́n máa ń wá àwọn ará tó wà níbẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n dé Tírè, wọ́n rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì dúró sọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ méje. Bákan náà ní Tólẹ́máísì, wọ́n yà kí àwọn arábìnrin àtàwọn arákùnrin, wọ́n sì lo ọjọ́ kan lọ́dọ̀ wọn. Ní Kesaríà, wọ́n tún lo bí ọjọ́ mélòó kan ní ilé Fílípì. Lẹ́yìn náà, àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wá láti Kesaríà sin Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò dé Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Mínásónì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ dọmọ ẹ̀yìn gbà wọ́n lálejò. Kódà, Lúùkù ròyìn pé, “àwọn ará gbà wá tayọ̀tayọ̀.”—Ìṣe 21:17.
21 Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fún un níṣìírí, bó sì ṣe máa ń rí fáwa náà lónìí nìyẹn. Ó dájú pé ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù rí gbà fún un lókun láti fara da inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn tínú ń bí, tí wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
a Wo àpótí náà, “Kesaríà—Olú Ìlú Jùdíà Tí Ìjọba Róòmù Ń Ṣàkóso.”
b Wo àpótí náà, “Ṣé Àwọn Obìnrin Lè Máa Kọ́ni Nínú Ìjọ?”