Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
21 Lẹ́yìn tí a já ara wa gbà lọ́wọ́ wọn, tí a sì wọkọ̀ òkun, a lọ tààrà, a sì dé Kọ́sì, ní ọjọ́ kejì a lọ sí Ródésì, láti ibẹ̀ a lọ sí Pátárà. 2 Nígbà tí a rí ọkọ̀ òkun kan tó ń sọdá lọ sí Foníṣíà, a wọ̀ ọ́, ó sì gbéra. 3 Bí a ṣe ń wo erékùṣù Sápírọ́sì lọ́ọ̀ọ́kán, a fi í sílẹ̀ sẹ́yìn ní apá òsì,* ọkọ̀ wa forí lé Síríà, a sì gúnlẹ̀ sí Tírè, níbi tí ọkọ̀ náà ti máa já ẹrù rẹ̀. 4 A wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn, a rí wọn, a sì lo ọjọ́ méje níbẹ̀. Àmọ́ nítorí ohun tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn wọ́n, léraléra ni wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó má ṣe fẹsẹ̀ kan Jerúsálẹ́mù.+ 5 Torí náà, nígbà tí àkókò tí a fẹ́ lò níbẹ̀ pé, a kúrò níbẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa, àmọ́ gbogbo wọn, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, sìn wá títí a fi jáde nínú ìlú náà. A kúnlẹ̀ ní etíkun, a gbàdúrà, 6 a sì dágbére fún ara wa. A lọ wọkọ̀ òkun, àwọn náà sì pa dà sílé wọn.
7 Lẹ́yìn náà, ọkọ̀ òkun wa kúrò ní Tírè, a sì dé Tólémáísì, a kí àwọn ará, a sì lo ọjọ́ kan lọ́dọ̀ wọn. 8 Lọ́jọ́ kejì, a gbéra, a sì dé Kesaríà, a wọ ilé Fílípì ajíhìnrere, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin méje + náà, a sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Ọkùnrin yìí ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí kò tíì lọ́kọ,* tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.+ 10 Àmọ́ lẹ́yìn tí a lo ọjọ́ mélòó kan níbẹ̀, wòlíì kan tó ń jẹ́ Ágábù+ wá láti Jùdíà. 11 Ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó sì de ẹsẹ̀ àti ọwọ́ ara rẹ̀, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ̀mí mímọ́ sọ nìyí, ‘Bí àwọn Júù ṣe máa di ọkùnrin tí àmùrè yìí jẹ́ tirẹ̀ nìyí ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n á sì fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.’”+ 12 Tóò, nígbà tí a gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwa àti àwọn tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó má lọ sí Jerúsálẹ́mù. 13 Ni Pọ́ọ̀lù bá fèsì pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ sì fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi?* Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé, mo ti múra tán láti kú ní Jerúsálẹ́mù nítorí orúkọ Jésù Olúwa,+ kì í ṣe pé kí wọ́n kàn dè mí nìkan ni.” 14 Nígbà tí a ò lè yí i lérò pa dà, a fi í sílẹ̀,* a sọ pé: “Kí ìfẹ́ Jèhófà* ṣẹ.”
15 Lẹ́yìn ìgbà yẹn, a múra ìrìn àjò, a sì bọ́ sọ́nà, ó di Jerúsálẹ́mù. 16 Lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti Kesaríà náà bá wa lọ, wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ Mínásónì ará Sápírọ́sì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn, ilé rẹ̀ ni wọ́n fẹ́ fi wá sí. 17 Nígbà tí a dé Jerúsálẹ́mù, àwọn ará gbà wá tayọ̀tayọ̀. 18 Àmọ́ lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé wa lọ sọ́dọ̀ Jémíìsì,+ gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. 19 Ó kí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó ṣe.
20 Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Arákùnrin, wo bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́ tó wà láàárín àwọn Júù ṣe pọ̀ tó, gbogbo wọn ló sì ní ìtara fún Òfin.+ 21 Àmọ́ wọ́n ti gbọ́ àhesọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo Júù tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n kẹ̀yìn sí Mósè, tí ò ń sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe dádọ̀dọ́* àwọn ọmọ wọn tàbí tẹ̀ lé àwọn àṣà wọn.+ 22 Kí wá ni ṣíṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ó dájú pé wọ́n á gbọ́ pé o ti dé. 23 Torí náà, ṣe ohun tí a bá sọ fún ọ: Ọkùnrin mẹ́rin wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. 24 Mú àwọn ọkùnrin yìí dání, kí o wẹ ara rẹ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin, kí o sì bójú tó ìnáwó wọn, kí wọ́n lè fá orí wọn. Nígbà náà, gbogbo èèyàn á mọ̀ pé kò sí òótọ́ kankan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n ń gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ pé ò ń rìn létòlétò àti pé ìwọ náà ń pa Òfin mọ́.+ 25 Ní ti àwọn onígbàgbọ́ tó wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè, a ti kọ ìpinnu wa ránṣẹ́ sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà,+ kí wọ́n yẹra fún ẹ̀jẹ̀,+ fún ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti ìṣekúṣe.”*+
26 Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà dání ní ọjọ́ kejì, ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin,+ ó wọ tẹ́ńpìlì lọ láti sọ ìgbà tí àwọn ọjọ́ ìwẹ̀mọ́ náà máa parí, kí àlùfáà lè rú ẹbọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.
27 Nígbà tó kù díẹ̀ kí ọjọ́ méje náà pé, àwọn Júù tó wá láti Éṣíà rí i nínú tẹ́ńpìlì, ni wọ́n bá ru gbogbo èrò lọ́kàn sókè, wọ́n sì gbá a mú, 28 wọ́n ń kígbe pé: “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbà wá o! Ọkùnrin tó ń kọ́ gbogbo èèyàn níbi gbogbo láti kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn wa àti sí Òfin àti sí ibí yìí ti dé síbí o. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún mú àwọn Gíríìkì wá sínú tẹ́ńpìlì, ó sì ti sọ ibi mímọ́ yìí di ẹlẹ́gbin.”+ 29 Nítorí wọ́n ti rí Tírófímù+ ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìlú náà tẹ́lẹ̀, wọ́n sì rò pé Pọ́ọ̀lù mú un wọ inú tẹ́ńpìlì. 30 Gbogbo ìlú náà dà rú, àwọn èèyàn rọ́ wá, wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù mú, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn tẹ́ńpìlì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn. 31 Bí wọ́n ṣe fẹ́ pa á, ọ̀gágun àwùjọ ọmọ ogun gbọ́ pé gbogbo Jerúsálẹ́mù ti dà rú; 32 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọ̀gá ọmọ ogun lẹ́yìn, wọ́n sì sáré lọ bá wọn. Nígbà tí wọ́n tajú kán rí ọ̀gágun náà àti àwọn ọmọ ogun, wọ́n ṣíwọ́ lílu Pọ́ọ̀lù.
33 Ọ̀gágun wá sún mọ́ wọn, ó mú un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é;+ lẹ́yìn náà, ó wádìí ẹni tó jẹ́ àti ohun tó ṣe. 34 Àmọ́, bí àwọn kan láàárín èrò náà ṣe ń pariwo ohun kan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn míì ń pariwo ohun míì. Torí náà, ó ní kí wọ́n mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun, torí ariwo wọn kò jẹ́ kó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. 35 Àmọ́ nígbà tó dé orí àtẹ̀gùn, àwọn ọmọ ogun ní láti gbé e nítorí ìwà ipá àwọn èrò náà, 36 torí ṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé wọn, tí wọ́n ń kígbe pé: “Ẹ pa á dà nù!”
37 Bí wọ́n ṣe fẹ́ mú Pọ́ọ̀lù wọ ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó béèrè lọ́wọ́ ọ̀gágun náà pé: “Ṣé mo lè sọ nǹkan kan fún ọ?” Ó fèsì pé: “Ṣé o lè sọ èdè Gíríìkì? 38 Ìwọ kọ́ ni ará Íjíbítì tó dáná ọ̀tẹ̀ sí ìjọba ní ìjelòó, tó sì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró jáde lọ sí aginjù?” 39 Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ní tòótọ́, Júù ni mí,+ láti Tásù+ ní Sìlíṣíà, ọmọ ìlú kan tó gbajúmọ̀.* Torí náà, mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀.” 40 Lẹ́yìn tó gbà á láyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn náà, ó ju ọwọ́ sí àwọn èèyàn náà. Nígbà tí kẹ́kẹ́ pa, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù,+ ó ní: