Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
15 Àwọn ọkùnrin kan wá láti Jùdíà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ará pé: “Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́* gẹ́gẹ́ bí àṣà tí Mósè fi lélẹ̀,+ ẹ ò lè rí ìgbàlà.” 2 Àmọ́ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ti bá wọn jiyàn díẹ̀, tí wọ́n sì jọ ṣe awuyewuye, àwọn ará ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pẹ̀lú àwọn míì lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù+ lórí ọ̀rọ̀* yìí.
3 Lẹ́yìn tí ìjọ ti sin àwọn ọkùnrin yìí síwájú díẹ̀, wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n gba Foníṣíà àti Samáríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe ń yí pa dà, wọ́n sì ń mú inú gbogbo àwọn ará dùn gidigidi. 4 Nígbà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, ìjọ àti àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú àwọn alàgbà gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì ròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn. 5 Ṣùgbọ́n, àwọn kan tó wá látinú ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisí, àmọ́ tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ dìde lórí ìjókòó wọn, wọ́n sì sọ pé: “Ó pọn dandan kí a dádọ̀dọ́ wọn,* kí a sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa pa Òfin Mósè mọ́.”+
6 Torí náà, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà kóra jọ láti gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. 7 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu,* Pétérù dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ mọ̀ dáadáa pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti yàn mí láàárín yín pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere látẹnu mi, kí wọ́n sì gbà gbọ́.+ 8 Ọlọ́run tí ó mọ ọkàn+ sì jẹ́rìí sí i ní ti pé ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́,+ bó ṣe fún àwa náà. 9 Kò sì fi ìyàtọ̀ kankan sáàárín àwa àti àwọn,+ àmọ́ ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ 10 Kí ló wá dé tí ẹ fi ń dán Ọlọ́run wò báyìí, tí ẹ̀ ń gbé àjàgà+ tí àwọn baba ńlá wa tàbí àwa fúnra wa kò lè rù kọ́ ọrùn àwọn ọmọ ẹ̀yìn?+ 11 Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní ìgbàgbọ́ pé ipasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa+ la fi rí ìgbàlà bíi ti àwọn náà.”+
12 Ni gbogbo wọn bá dákẹ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sílẹ̀ bí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ṣe ń ròyìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. 13 Lẹ́yìn tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ wọn, Jémíìsì fèsì pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ gbọ́ mi. 14 Símíónì+ ti ròyìn ní kíkún bí Ọlọ́run ṣe yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.+ 15 Ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì sì bá èyí mu, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: 16 ‘Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, màá pa dà, màá sì tún gbé àgọ́* Dáfídì tó ti wó lulẹ̀ dìde; màá tún àwókù rẹ̀ kọ́, màá sì mú kó rí bíi ti tẹ́lẹ̀, 17 kí àwọn tó ṣẹ́ kù lè máa wá Jèhófà* taratara, àwọn àti àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà* ẹni tó ń ṣe àwọn nǹkan yìí wí,+ 18 àwọn nǹkan tí a ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́.’+ 19 Torí náà, ìpinnu* mi ni pé kí a má dààmú àwọn tó ń yíjú sí Ọlọ́run látinú àwọn orílẹ̀-èdè,+ 20 àmọ́ kí a kọ̀wé sí wọn láti ta kété sí àwọn ohun tí àwọn òrìṣà ti sọ di ẹlẹ́gbin,+ sí ìṣekúṣe,*+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa* àti sí ẹ̀jẹ̀.+ 21 Torí pé láti ìgbà láéláé ni Mósè ti ní àwọn tó ń wàásù nípa rẹ̀ láti ìlú dé ìlú, torí wọ́n ń ka ìwé rẹ̀ sókè nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì.”+
22 Lẹ́yìn náà, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ pinnu láti rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn láàárín wọn lọ sí Áńtíókù, pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà; wọ́n rán Júdásì tí wọ́n ń pè ní Básábà àti Sílà,+ àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ará. 23 Wọ́n kọ̀wé, wọ́n sì fi rán wọn, wọ́n ní:
“Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà, àwa arákùnrin yín, sí àwọn ará ní Áńtíókù,+ Síríà àti Sìlíṣíà tí wọ́n wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè: A kí yín o! 24 Nígbà tí a gbọ́ pé àwọn kan láàárín wa wá sọ́dọ̀ yín, tí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ kó wàhálà bá yín,+ tí wọ́n fẹ́ dojú yín* dé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò fún wọn ní àṣẹ kankan, 25 a ti fìmọ̀ ṣọ̀kan, a sì ti pinnu láti yan àwọn ọkùnrin tí a máa rán sí yín pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ wa, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, 26 àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí* wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi.+ 27 Nítorí náà, à ń rán Júdásì àti Sílà bọ̀, kí àwọn náà lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu jíṣẹ́ + ohun kan náà fún yín. 28 Nítorí ẹ̀mí mímọ́+ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ọn pé ká má ṣe dì kún ẹrù yín, àyàfi àwọn ohun tó pọn dandan yìí: 29 láti máa ta kété sí àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ láti máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀,+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti sí ìṣekúṣe.*+ Tí ẹ bá ń yẹra fún àwọn nǹkan yìí délẹ̀délẹ̀, ẹ ó láásìkí. Kí ara yín ó le o!”*
30 Tóò, nígbà tí wọ́n ní kí àwọn ọkùnrin yìí máa lọ, wọ́n lọ sí Áńtíókù, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n sì fi lẹ́tà náà lé wọn lọ́wọ́. 31 Lẹ́yìn tí wọ́n kà á, ìṣírí tí wọ́n rí gbà mú inú wọn dùn. 32 Júdásì àti Sílà tí àwọn náà jẹ́ wòlíì fi ọ̀pọ̀ àsọyé gba àwọn ará níyànjú, wọ́n sì fún wọn lókun.+ 33 Lẹ́yìn tí wọ́n lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, àwọn ará yọ̀ǹda wọn kí wọ́n máa lọ, wọ́n ní kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn tó rán wọn wá láyọ̀. 34* —— 35 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà dúró sí Áńtíókù, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ Jèhófà,* àwọn àti ọ̀pọ̀ àwọn míì.
36 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ fún Bánábà pé: “Ní báyìí,* jẹ́ ká pa dà lọ bẹ àwọn ará wò ní gbogbo ìlú tí a ti kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà,* ká lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí.”+ 37 Bánábà pinnu láti mú Jòhánù tí wọ́n ń pè ní Máàkù dání.+ 38 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ ọn pé kí wọ́n mú un dání, ó wò ó pé ó fi àwọn sílẹ̀ ní Panfílíà, kò sì bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.+ 39 Ni àwọn méjèèjì bá gbaná jẹ, débi pé wọ́n pínyà; Bánábà+ mú Máàkù dání, ó sì wọkọ̀ òkun lọ sí Sápírọ́sì. 40 Pọ́ọ̀lù mú Sílà, ó sì lọ lẹ́yìn tí àwọn ará gbàdúrà pé kí Jèhófà* fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí i.+ 41 Ó gba Síríà àti Sìlíṣíà kọjá, ó sì ń fún àwọn ìjọ lókun.