Àkọsílẹ̀ Mátíù
19 Nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán, ó kúrò ní Gálílì, ó sì wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà ní òdìkejì Jọ́dánì.+ 2 Èrò rẹpẹtẹ tún tẹ̀ lé e, ó sì wò wọ́n sàn níbẹ̀.
3 Àwọn Farisí wá bá a, wọ́n fẹ́ dán an wò, wọ́n sì bi í pé: “Ṣé ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn?”+ 4 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ò kà á pé ẹni tó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ dá wọn ní akọ àti abo,+ 5 ó sì sọ pé, ‘Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan’?+ 6 Tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”+ 7 Wọ́n sọ fún un pé: “Kí ló wá dé tí Mósè fi sọ pé ká fún un ní ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?”+ 8 Ó sọ fún wọn pé: “Torí pé ọkàn yín le ni Mósè ṣe yọ̀ǹda fún yín láti kọ ìyàwó yín sílẹ̀,+ àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.+ 9 Mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe,* tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.”+
10 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀ rí, ó sàn kéèyàn má tiẹ̀ níyàwó.” 11 Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń wá àyè láti ṣe bẹ́ẹ̀, àfi àwọn tó ní ẹ̀bùn rẹ̀.+ 12 Torí àwọn kan wà tí a bí ní ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà kan wà tí àwọn èèyàn sọ di ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà kan sì wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà nítorí Ìjọba ọ̀run. Kí ẹni tó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”+
13 Wọ́n mú àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, kó sì gbàdúrà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá wọn wí.+ 14 Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé: “Ẹ fi àwọn ọmọdé sílẹ̀, ẹ má sì dá wọn dúró láti wá sọ́dọ̀ mi, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ ti irú wọn.”+ 15 Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.
16 Wò ó! ẹnì kan wá bá a, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 17 Ó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kan ló wà.+ Àmọ́ o, tí o bá fẹ́ jogún ìyè, máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo.”+ 18 Ó bi í pé: “Àwọn àṣẹ wo?” Jésù sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ 19 bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ+ àti pé, kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 20 Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fún un pé: “Mo ti ń ṣe gbogbo nǹkan yìí; kí ló kù tí mi ò tíì ṣe?” 21 Jésù sọ fún un pé: “Tí o bá fẹ́ jẹ́ pípé,* lọ ta àwọn ohun ìní rẹ, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run;+ kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 22 Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà gbọ́ èyí, ó fi ìbànújẹ́ kúrò, torí ohun ìní rẹ̀ pọ̀.+ 23 Jésù wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó máa ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba ọ̀run.+ 24 Mo tún ń sọ fún yín pé, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+
25 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, wọ́n sọ pé: “Ta ló máa wá lè rí ìgbàlà?”+ 26 Jésù bá tẹjú mọ́ wọn, ó sì sọ pé: “Lójú èèyàn, èyí kò ṣeé ṣe, àmọ́ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+
27 Ni Pétérù bá fèsì pé: “Wò ó! A ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀ lé ọ; kí ló máa wá jẹ́ tiwa?”+ 28 Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, nígbà àtúndá, tí Ọmọ èèyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tẹ̀ lé mi máa jókòó sórí ìtẹ́ méjìlá (12), ẹ sì máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+ 29 Gbogbo ẹni tó bá sì ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, bàbá, ìyá, àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi máa gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ó sì máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun.+
30 “Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ máa di ẹni ìkẹyìn, àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́.+