Àìsáyà
Kí wọ́n sún mọ́ tòsí; kí wọ́n wá sọ̀rọ̀.+
Ẹ jẹ́ ká kóra jọ fún ìdájọ́.
2 Ta ló ti gbé ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+
Tó pè é nínú òdodo wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀,*
Láti fa àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,
Kó sì mú kó tẹ àwọn ọba lórí ba?+
Ta ló ń sọ wọ́n di eruku níwájú idà rẹ̀,
Bí àgékù pòròpórò tí atẹ́gùn ń gbé kiri níwájú ọfà rẹ̀?
3 Ó ń lé wọn, ohunkóhun ò sì dí i lọ́wọ́
Lójú ọ̀nà tí kò fẹsẹ̀ tẹ̀ rí.
4 Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni,
Tó ń pe àwọn ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?
5 Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
Àwọn ìkángun ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wárìrì.
Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì bọ́ síwájú.
6 Kálukú ń ran ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́,
Wọ́n ń sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ẹ jẹ́ alágbára.”
7 Torí náà, oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin+ lókun;
Ẹni tó ń fi òòlù irin* lu nǹkan di pẹlẹbẹ
Ń fún ẹni tó ń fi òòlù lu nǹkan lórí irin lókun.
Ó ń sọ nípa ohun tí wọ́n jó pọ̀ pé: “Ó dáa.”
Wọ́n wá fi ìṣó kàn án, kó má bàa ṣubú.
8 “Àmọ́ ìwọ Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ mi,+
Ìwọ Jékọ́bù, ẹni tí mo yàn,+
9 Ìwọ tí mo mú láti àwọn ìkángun ayé,+
Ìwọ tí mo pè láti àwọn apá ibi tó jìnnà jù níbẹ̀.
10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+
Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+
Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+
Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’
11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+
Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+
12 O máa wá àwọn tó ń bá ọ jà, àmọ́ o ò ní rí wọn;
Àwọn tó ń bá ọ jagun máa dà bí ohun tí kò sí, bí ohun tí kò sí rárá.+
13 Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,
Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+
14 Má bẹ̀rù, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú,*+
Ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì, màá ràn yín lọ́wọ́,” ni Jèhófà, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí.
15 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ohun tí wọ́n fi ń pakà,+
Ohun tuntun tó ní eyín olójú méjì tí wọ́n fi ń pakà.
O máa tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, o máa fọ́ wọn túútúú,
O sì máa ṣe àwọn òkè kéékèèké bí ìyàngbò.*
16 O máa fẹ́ wọn bí ọkà,
Atẹ́gùn sì máa gbé wọn lọ;
Ìjì máa tú wọn ká.
17 “Àwọn aláìní àti àwọn tálákà ń wá omi, àmọ́ kò sí rárá.
Òùngbẹ ti mú kí ahọ́n wọn gbẹ.+
Èmi Jèhófà máa dá wọn lóhùn.+
Èmi Ọlọ́run Ísírẹ́lì ò ní fi wọ́n sílẹ̀.+
Màá gbin igi júnípà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú,
Pẹ̀lú igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì,+
20 Kí gbogbo èèyàn lè rí i, kí wọ́n sì mọ̀,
Kí wọ́n fiyè sí i, kó sì yé wọn,
Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí,
Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ló sì dá a.”+
21 “Ẹ ro ẹjọ́ yín,” ni Jèhófà wí.
“Ẹ gbèjà ara yín,” ni Ọba Jékọ́bù wí.
22 “Ẹ mú ẹ̀rí wá, kí ẹ sì sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún wa.
Tàbí kí ẹ kéde àwọn ohun tó ń bọ̀ fún wa.+
Àní, ẹ ṣe nǹkan kan, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú,
Kó lè yà wá lẹ́nu tí a bá rí i.+
Ohun ìríra ni ẹnikẹ́ni tó bá yàn yín.+
Lóòótọ́, kò sí ẹni tó sọ ọ́!
Kò sí ẹni tó kéde rẹ̀!
Kò sí ẹni tó gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ!”+
27 Èmi ni mo kọ́kọ́ sọ fún Síónì pé: “Wò ó! Àwọn nìyí!”+
Màá sì rán ẹni tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù.+
28 Àmọ́ mò ń wò, kò sì sí ẹnì kankan;
Kò sí ìkankan nínú wọn tó ń gbani nímọ̀ràn.
Mo sì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n fèsì.
29 Wò ó! Gbogbo wọn jẹ́ ẹ̀tàn.*
Iṣẹ́ wọn kò já mọ́ nǹkan kan.
Afẹ́fẹ́ lásán àti ohun tí kò sí rárá ni àwọn ère onírin* wọn.+