Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
2 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì+ ìjọ ní Éfésù+ pé: Àwọn nǹkan tí ẹni tó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sọ nìyí, ẹni tó ń rìn láàárín ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe:+ 2 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ àti làálàá tí ò ń ṣe àti ìfaradà rẹ, mo mọ̀ pé o ò jẹ́ gba àwọn èèyàn burúkú láyè àti pé o dán àwọn tó pe ara wọn ní àpọ́sítélì wò,+ àmọ́ tí wọn kì í ṣe àpọ́sítélì, o sì rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n. 3 O tún fi hàn pé o ní ìfaradà, o ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra nítorí orúkọ mi,+ àárẹ̀ ò sì mú ọ.+ 4 Síbẹ̀, ohun tí mo rí tí o ṣe tí kò dáa ni pé o ti fi ìfẹ́ tí o ní níbẹ̀rẹ̀ sílẹ̀.
5 “‘Torí náà, rántí ibi tí o ti ṣubú, kí o ronú pìwà dà,+ kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí o ṣe níbẹ̀rẹ̀. Tí o ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá wá sọ́dọ̀ rẹ, màá sì gbé ọ̀pá fìtílà rẹ+ kúrò ní àyè rẹ̀, àfi tí o bá ronú pìwà dà.+ 6 Ohun míì tí o tún ṣe tó dáa ni pé: o kórìíra àwọn ohun tí ẹ̀ya ìsìn Níkóláósì+ ń ṣe, èmi náà sì kórìíra rẹ̀. 7 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ:+ Ẹni tó bá ṣẹ́gun+ ni màá jẹ́ kó jẹ nínú igi ìyè+ tó wà nínú párádísè Ọlọ́run.’
8 “Bákan náà, kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Símínà pé: Àwọn nǹkan tí ‘Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn’+ sọ nìyí, ẹni tó kú tẹ́lẹ̀, tó sì pa dà wà láàyè:+ 9 ‘Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—àmọ́ ọlọ́rọ̀ ni ọ́+—àti ọ̀rọ̀ òdì àwọn tó ń pe ara wọn ní Júù, síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe Júù, àmọ́ sínágọ́gù Sátánì ni wọ́n.+ 10 Má bẹ̀rù àwọn nǹkan tí o máa tó jìyà rẹ̀.+ Wò ó! Èṣù á máa ju àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n láti dán yín wò ní kíkún, ojú sì máa pọ́n yín fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olóòótọ́, kódà títí dójú ikú, màá sì fún ọ ní adé ìyè.+ 11 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ + ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ: Ó dájú pé ikú kejì+ kò ní pa ẹni tó bá ṣẹ́gun.’+
12 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Págámù pé: Àwọn nǹkan tí ẹni tó ní idà olójú méjì, tó mú, tó sì gùn+ sọ nìyí: 13 ‘Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ìyẹn ibi tí ìtẹ́ Sátánì wà; síbẹ̀ ò ń di orúkọ mi mú ṣinṣin,+ o ò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi,+ kódà ní àwọn ọjọ́ Áńtípà, ẹlẹ́rìí mi tòótọ́,+ ẹni tí wọ́n pa+ ní ẹ̀gbẹ́ yín, níbi tí Sátánì ń gbé.
14 “‘Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tí mo rí tí ò ń ṣe tí kò dáa, àwọn kan wà láàárín yín tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Báláámù,+ ẹni tó kọ́ Bálákì+ pé kó fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n jẹ àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà, kí wọ́n sì ṣe ìṣekúṣe.*+ 15 Bákan náà, àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ ẹ̀ya ìsìn Níkóláósì tún wà láàárín yín.+ 16 Torí náà, ronú pìwà dà. Tí o ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá wá sọ́dọ̀ rẹ ní kíákíá, màá sì fi idà gígùn ẹnu mi bá wọn jà.+
17 “‘Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ:+ Màá fún ẹni tó bá ṣẹ́gun+ ní díẹ̀ nínú mánà tí a fi pa mọ́,+ màá sì fún un ní òkúta róbótó funfun kan, orúkọ tuntun kan sì máa wà lára òkúta róbótó náà, èyí tí ẹnì kankan ò mọ̀ àfi ẹni tó gbà á.’
18 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà+ pé: Ohun tí Ọmọ Ọlọ́run sọ nìyí, ẹni tí ojú rẹ̀ dà bí ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bíi bàbà tó dáa gan-an:+ 19 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́, ìgbàgbọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ tí ò ń ṣe báyìí pọ̀ ju èyí tí o ṣe níbẹ̀rẹ̀.
20 “‘Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tí mo rí tí ò ń ṣe tí kò dáa, o fàyè gba Jésíbẹ́lì+ obìnrin yẹn, ẹni tó pe ara rẹ̀ ní wòlíì obìnrin, tó ń kọ́ àwọn ẹrú mi, tó sì ń ṣì wọ́n lọ́nà kí wọ́n lè ṣe ìṣekúṣe,*+ kí wọ́n sì jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà. 21 Mo ní sùúrù fún un kó lè ronú pìwà dà, àmọ́ kò fẹ́ ronú pìwà dà kúrò nínú ìṣekúṣe* rẹ̀. 22 Wò ó! Mo máa tó dá a dùbúlẹ̀ àìsàn, màá sì mú kí ìpọ́njú tó le gan-an bá àwọn tó ń bá a ṣe àgbèrè, àfi tí wọ́n bá ronú pìwà dà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 23 Màá fi àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọ rẹ̀, kí gbogbo ìjọ lè mọ̀ pé èmi ni ẹni tó ń wá èrò inú* àti ọkàn, màá sì san án fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bí iṣẹ́ yín bá ṣe rí.+
24 “‘Àmọ́, mo sọ fún ẹ̀yin yòókù ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ò tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ yìí, ẹ̀yin tí ẹ ò mọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń pè ní “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì”:+ Mi ò tún fi nǹkan míì ni yín lára. 25 Síbẹ̀, kí ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí mo fi máa dé.+ 26 Ẹni tó bá ṣẹ́gun, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ mi títí dé òpin ni màá fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè,+ 27 ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn,+ kó lè fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, bí mo ṣe gbà á lọ́wọ́ Baba mi gẹ́lẹ́. 28 Màá sì fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.+ 29 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’