Àkọsílẹ̀ Jòhánù
14 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín.+ Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run;+ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú èmi náà. 2 Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùgbé* ló wà. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹ bá ti sọ fún yín, torí pé mò ń lọ kí n lè pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.+ 3 Bákan náà, tí mo bá lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, màá tún pa dà wá, màá sì gbà yín sílé sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ̀yin náà lè wà ní ibi tí mo wà.+ 4 Ẹ mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.”
5 Tọ́másì+ sọ fún un pé: “Olúwa, a ò mọ ibi tó ò ń lọ. Báwo la ṣe fẹ́ mọ ọ̀nà ibẹ̀?”
6 Jésù sọ fún un pé: “Èmi ni ọ̀nà+ àti òtítọ́ + àti ìyè.+ Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.+ 7 Ká ní ẹ mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá mọ Baba mi náà; láti ìsinsìnyí lọ, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”+
8 Fílípì sọ fún un pé: “Olúwa, fi Baba hàn wá, ìyẹn sì máa tó wa.”
9 Jésù sọ fún un pé: “Fílípì, pẹ̀lú bó ṣe pẹ́ tó tí mo ti wà pẹ̀lú yín, ṣé o ò tíì mọ̀ mí ni? Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.+ Kí ló dé tí o wá sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá’? 10 Ṣé o ò gbà pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba àti pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ni?+ Kì í ṣe èrò ara mi+ ni àwọn nǹkan tí mò ń sọ fún yín, àmọ́ Baba tó ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba, Baba sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi; tàbí kẹ̀, kí ẹ gbà gbọ́ nítorí àwọn iṣẹ́ náà fúnra wọn.+ 12 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi náà máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; ó sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ,+ torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba.+ 13 Bákan náà, ohunkóhun tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, màá ṣe é, ká lè tipasẹ̀ Ọmọ+ yin Baba lógo. 14 Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, màá ṣe é.
15 “Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+ 16 Màá béèrè lọ́wọ́ Baba, ó sì máa fún yín ní olùrànlọ́wọ́* míì tó máa wà pẹ̀lú yín títí láé,+ 17 ẹ̀mí òtítọ́,+ tí ayé ò lè gbà, torí pé kò rí i, kò sì mọ̀ ọ́n.+ Ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, torí ó wà pẹ̀lú yín, ó sì wà nínú yín. 18 Mi ò ní fi yín sílẹ̀ ní ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀.* Mò ń bọ̀ lọ́dọ̀ yín.+ 19 Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé ò ní rí mi mọ́, àmọ́ ẹ máa rí mi,+ torí pé mo wà láàyè, ẹ sì máa wà láàyè. 20 Ọjọ́ yẹn lẹ máa mọ̀ pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba mi àti pé ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín.+ 21 Ẹnikẹ́ni tó bá ní àwọn àṣẹ mi, tó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi. Lọ́wọ́ kejì, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi náà máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, màá sì fi ara mi hàn án kedere.”
22 Júdásì,+ tí kì í ṣe Ìsìkáríọ́tù, sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi jẹ́ pé àwa lo fẹ́ fi ara rẹ hàn kedere sí, tí kì í ṣe ayé?”
23 Jésù dá a lóhùn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, ó máa pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,+ Baba mi sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a máa wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì máa fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé* wa.+ 24 Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ mi kì í pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti Baba tó rán mi.+
25 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín. 26 Àmọ́ olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, tí Baba máa rán ní orúkọ mi, máa kọ́ yín ní gbogbo nǹkan, ó sì máa rán yín létí gbogbo ohun tí mo sọ fún yín.+ 27 Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín; mo fún yín ní àlàáfíà mi.+ Mi ò fún yín lọ́nà tí ayé gbà ń fúnni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú. 28 Ẹ gbọ́ tí mo sọ fún yín pé, ‘Mò ń lọ, mo sì ń pa dà bọ̀ sọ́dọ̀ yín.’ Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, inú yín máa dùn pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, torí pé Baba tóbi jù mí lọ.+ 29 Torí náà, mo ti sọ fún yín báyìí kó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbà gbọ́ tó bá ṣẹlẹ̀.+ 30 Mi ò ní bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀ mọ́, torí alákòóso ayé+ ń bọ̀, kò sì ní agbára kankan lórí mi.*+ 31 Àmọ́ torí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.+ Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká kúrò níbí.