Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
16 Mo gbọ́ tí ohùn kan dún ketekete látinú ibi mímọ́ náà,+ ó sọ fún àwọn áńgẹ́lì méje náà pé: “Ẹ lọ da abọ́ méje tí ìbínú Ọlọ́run wà nínú rẹ̀ sórí ayé.”+
2 Àkọ́kọ́ lọ, ó sì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí ayé.+ Egbò tó ń dunni wọra tó sì lè pani+ kọ lu àwọn èèyàn tó ní àmì ẹranko náà,+ tí wọ́n sì ń jọ́sìn ère rẹ̀.+
3 Ìkejì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú òkun.+ Ó sì di ẹ̀jẹ̀+ bí ẹ̀jẹ̀ ẹni tó ti kú, gbogbo ohun alààyè* kú, àní àwọn ohun tó wà nínú òkun.+
4 Ìkẹta da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú àwọn odò àti àwọn ìsun* omi.+ Wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.+ 5 Mo gbọ́ tí áńgẹ́lì tó wà lórí àwọn omi sọ pé: “Ìwọ, Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ Ẹni ìdúróṣinṣin,+ jẹ́ olódodo, torí o ti ṣe àwọn ìdájọ́ yìí,+ 6 torí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn wòlíì sílẹ̀,+ o sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu;+ ó tọ́ sí wọn.”+ 7 Mo sì gbọ́ tí pẹpẹ náà sọ pé: “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àní òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́* rẹ.”+
8 Ìkẹrin da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí oòrùn,+ a sì gbà kí oòrùn fi iná jó àwọn èèyàn gbẹ. 9 Ooru tó gbóná janjan náà sì jó àwọn èèyàn náà gbẹ, àmọ́ wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tó ní àṣẹ lórí àwọn ìyọnu yìí, wọn ò ronú pìwà dà, wọn ò sì yìn ín lógo.
10 Ìkarùn-ún da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà. Ni ìjọba rẹ̀ bá ṣókùnkùn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gé ahọ́n wọn jẹ torí ìrora wọn, 11 àmọ́ wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti egbò wọn, wọn ò sì ronú pìwà dà nínú àwọn iṣẹ́ wọn.
12 Ìkẹfà da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú odò ńlá Yúfírétì,+ omi rẹ̀ sì gbẹ+ láti palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọba+ láti ibi tí oòrùn ti ń yọ.*
13 Mo sì rí i tí àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́ mẹ́ta tó ní ìmísí,* èyí tó rí bí àkèré jáde láti ẹnu dírágónì+ náà àti láti ẹnu ẹranko náà àti láti ẹnu wòlíì èké náà. 14 Ní tòótọ́, wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí, wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì,+ wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti kó wọn jọ sí ogun+ ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.+
15 “Wò ó! Mò ń bọ̀ bí olè.+ Aláyọ̀ ni ẹni tó wà lójúfò,+ tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,* kó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn èèyàn sì wo ìtìjú rẹ̀.”+
16 Wọ́n sì kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì*+ lédè Hébérù.
17 Ìkeje sì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú afẹ́fẹ́. Lẹ́yìn náà, ohùn kan dún ketekete látinú ibi mímọ́+ níbi ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Ó ti rí bẹ́ẹ̀!” 18 Mànàmáná kọ yẹ̀rì, a gbọ́ ohùn, ààrá sán, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára sì ṣẹlẹ̀, irú rẹ̀ kò tíì ṣẹlẹ̀ látìgbà téèyàn ti wà ní ayé,+ ìmìtìtì náà lágbára gan-an ó sì lọ jìnnà. 19 Ìlú ńlá náà+ pín sí mẹ́ta, àwọn ìlú àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú; a sì rántí Bábílónì Ńlá+ níwájú Ọlọ́run, ká lè fún un ní ife wáìnì tí ìbínú Ọlọ́run ń ru nínú rẹ̀.+ 20 Bákan náà, gbogbo erékùṣù sá lọ, a ò sì rí àwọn òkè.+ 21 Lẹ́yìn náà àwọn òkúta yìnyín ńlá já bọ́ lu àwọn èèyàn láti ọ̀run,+ òkúta kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó tálẹ́ńtì* kan, àwọn èèyàn náà sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí ìyọnu yìnyín náà+ àti pé ìyọnu náà pọ̀ lọ́nà tó kàmàmà.