Àwọn Ọba Kejì
18 Ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Hẹsikáyà+ ọmọ Áhásì+ ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábì* ọmọ Sekaráyà.+ 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 4 Òun ló mú àwọn ibi gíga kúrò,+ tó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, tó sì gé òpó òrìṣà*+ lulẹ̀. Ó tún fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe;+ torí pé títí di àkókò yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń mú ẹbọ rú èéfín sí i, tí wọ́n sì ń pè é ní òrìṣà ejò bàbà.* 5 Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì; kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọba Júdà tó wà ṣáájú rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jẹ lẹ́yìn rẹ̀. 6 Kò fi Jèhófà sílẹ̀.+ Kò yà kúrò lẹ́yìn rẹ̀; ó ń pa àwọn àṣẹ tí Jèhófà fún Mósè mọ́. 7 Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó ń hùwà ọgbọ́n níbikíbi tó bá lọ. Ó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà, ó sì kọ̀ láti sìn ín.+ 8 Ó tún ṣẹ́gun àwọn Filísínì+ títí dé Gásà àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀, láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi.*
9 Ní ọdún kẹrin Ọba Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún keje Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Ṣálímánésà ọba Ásíríà wá gbéjà ko Samáríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dó tì í.+ 10 Wọ́n gbà á+ ní òpin ọdún mẹ́ta; ní ọdún kẹfà Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì, wọ́n gba Samáríà. 11 Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Ásíríà kó Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn+ ní Ásíríà, ó sì ní kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+ 12 Ohun tó fa èyí ni pé wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn, wọ́n ń da májẹ̀mú rẹ̀, ìyẹn gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ.+ Wọn ò fetí sílẹ̀, wọn ò sì ṣègbọràn.
13 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 14 Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà. 15 Torí náà, Hẹsikáyà fi gbogbo fàdákà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ lélẹ̀. 16 Lákòókò yẹn, Hẹsikáyà yọ* àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì+ Jèhófà kúrò àti àwọn òpó ilẹ̀kùn tí Hẹsikáyà ọba Júdà fúnra rẹ̀ fi wúrà bò,+ ó sì kó wọn fún ọba Ásíríà.
17 Ọba Ásíríà wá rán àwọn mẹ́ta tí orúkọ oyè wọn ń jẹ́ Tátánì* àti Rábúsárísì* àti Rábúṣákè* pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà, èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 18 Nígbà tí wọ́n pe ọba pé kó jáde, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí jáde wá bá wọn.
19 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 20 Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 21 Wò ó! Ṣé Íjíbítì+ tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e. 22 Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’+ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ tó wà ní Jerúsálẹ́mù yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 23 Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n.+ 24 Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 25 Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ibí yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’”
26 Ni Élíákímù ọmọ Hilikáyà àti Ṣẹ́bínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 27 Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”
28 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 29 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi.+ 30 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 31 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 32 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà, ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin. Kí ẹ lè máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má sì kú. Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, nítorí ṣe ló ń ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ 33 Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà? 34 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti ti Áápádì wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù,+ Hénà àti ti Ífà wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 35 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ náà ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+
36 Àmọ́ àwọn èèyàn náà dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 37 Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.