11 Òṣùwọ̀n èké jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,
Àmọ́ ìwọ̀n tí ó pé máa ń mú inú rẹ̀ dùn.+
2 Tí ìkọjá àyè bá dé, àbùkù á tẹ̀ lé e,+
Àmọ́ ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.+
3 Ìwà títọ́ àwọn adúróṣinṣin ló ń tọ́ wọn sọ́nà,+
Àmọ́ ẹ̀tàn àwọn oníbékebèke ni yóò pa wọ́n run.+
4 Ọrọ̀ kò ní ṣeni láǹfààní ní ọjọ́ ìbínú ńlá,+
Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+
5 Òdodo aláìlẹ́bi ń mú kí ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́,
Àmọ́ ẹni burúkú á ṣubú nítorí ìwà burúkú rẹ̀.+
6 Òdodo àwọn adúróṣinṣin ni yóò gbà wọ́n,+
Àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn oníbékebèke ni yóò dẹkùn mú wọn.+
7 Nígbà tí ẹni burúkú bá kú, ìrètí rẹ̀ á ṣègbé;
Ohun tó sì ń retí pé òun á fi agbára òun ṣe yóò ṣègbé pẹ̀lú.+
8 A gba olódodo lọ́wọ́ wàhálà,
Ẹni burúkú sì bọ́ síbẹ̀ dípò rẹ̀.+
9 Ẹnu ni apẹ̀yìndà fi ń fa ìparun bá ọmọnìkejì rẹ̀,
Àmọ́ ìmọ̀ ló ń gba àwọn olódodo sílẹ̀.+
10 Ìwà rere àwọn olódodo ń mú kí ìlú yọ̀,
Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá ṣègbé, igbe ìdùnnú á ta.+
11 Nítorí ìbùkún àwọn adúróṣinṣin, ìlú á ní ìgbéga,+
Àmọ́ ẹnu àwọn ẹni burúkú á wó o lulẹ̀.+
12 Ẹni tí kò ní làákàyè ń kórìíra ọmọnìkejì rẹ̀,
Àmọ́ ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń dákẹ́.+
13 Abanijẹ́ ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kiri,+
Àmọ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń pa àṣírí mọ́.
14 Nígbà tí kò bá sí ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n, àwọn èèyàn á ṣubú,
Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.+
15 Ẹni tó bá ṣe onídùúró fún àjèjì yóò rí láburú,+
Àmọ́ ẹni tó bá yẹra fún bíbọ ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́ yóò rí ààbò.
16 Obìnrin onínúure ń gba ògo,+
Àmọ́ àwọn ìkà èèyàn ń gbẹ́sẹ̀ lé ọrọ̀.
17 Ẹni tó ń ṣoore ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní,+
Àmọ́ ìkà èèyàn ń fa wàhálà bá ara rẹ̀.+
18 Ẹni burúkú ń jẹ èrè asán,+
Àmọ́ ẹni tó ń gbin òdodo ń jẹ èrè gidi.+
19 Ẹni tó dúró gbọn-in lórí òdodo máa rí ìyè,+
Àmọ́ ẹni tó ń lépa ohun búburú á rí ikú he.
20 Àwọn tí ọkàn wọn burú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+
Àmọ́ àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́ ń mú inú rẹ̀ dùn.+
21 Jẹ́ kó dá ọ lójú pé: Ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,+
Àmọ́ àwọn ọmọ olódodo yóò yè bọ́.
22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀
Ni obìnrin tó rẹwà àmọ́ tí kì í lo làákàyè.
23 Ìfẹ́ ọkàn àwọn olódodo ń yọrí sí ire,+
Àmọ́ ohun tí àwọn ẹni burúkú ń retí máa ń yọrí sí ìbínú ńlá.
24 Ẹnì kan wà tó ń fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ń ní sí i;+
Ẹnì kan sì wà tó ń fawọ́ ohun tó yẹ kó fúnni sẹ́yìn, àmọ́ ó di aláìní.+
25 Ẹni tó bá lawọ́ máa láásìkí,+
Ẹni tó bá sì ń mára tu àwọn míì, ara máa tu òun náà.+
26 Àwọn èèyàn á gégùn-ún fún ẹni tó bá kó oúnjẹ pa mọ́,
Àmọ́ wọ́n á súre fún ẹni tó bá ń tà á.
27 Ẹni tó ń wá bó ṣe máa ṣe rere lójú méjèèjì ń wá ojú rere,+
Àmọ́ ẹni tó bá ń wá ibi, ó dájú pé ibi ló máa wá sórí rẹ̀.+
28 Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀ máa ṣubú,+
Àmọ́ olódodo máa rú yọ bí ewé tútù.+
29 Ẹni tó bá ń fa wàhálà bá agbo ilé rẹ̀ á jogún òfo,+
Òmùgọ̀ èèyàn ló sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ ọlọ́gbọ́n.
30 Èso olódodo jẹ́ igi ìyè,+
Ẹni tó bá sì ń jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.+
31 Tó bá jẹ́ pé ẹ̀san wà fún olódodo lóòótọ́,
Mélòómélòó ni ti ẹni burúkú àti ẹlẹ́ṣẹ̀!+