Ìwé Kìíní Pétérù
2 Nítorí náà, ẹ jáwọ́ nínú gbogbo ìwà burúkú,+ ẹ̀tàn, àgàbàgebè àti owú, ẹ má sì sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni láìdáa. 2 Bíi ti ìkókó,+ ẹ jẹ́ kí wàrà tí kò lábùlà* tó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà máa wù yín gan-an, kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀,+ 3 tí ẹ bá ti tọ́ ọ wò* pé onínúure ni Olúwa.
4 Bí ẹ ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tó jẹ́ òkúta ààyè tí àwọn èèyàn kọ̀ sílẹ̀,+ àmọ́ tó jẹ́ àyànfẹ́, tó sì ṣeyebíye lójú Ọlọ́run,+ 5 bí àwọn òkúta ààyè, à ń fi ẹ̀yin pẹ̀lú kọ́ ilé tẹ̀mí+ kí ẹ lè di ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́, kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ ẹ̀mí+ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jésù Kristi.+ 6 Torí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Wò ó! Màá fi òkúta àyànfẹ́ kan lélẹ̀ ní Síónì, òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé tó ṣeyebíye, kò sì sí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ tí a máa já kulẹ̀.”*+
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ló ṣe iyebíye fún, torí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; àmọ́ fún àwọn tí kò gbà gbọ́, “òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀,+ òun ló wá di olórí òkúta igun ilé”*+ 8 àti “òkúta ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta agbéniṣubú.”+ Wọ́n ń kọsẹ̀ torí wọn ò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà. Ìdí tí a fi yàn wọ́n nìyí. 9 Àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́,+ àwùjọ àwọn èèyàn tó jẹ́ ohun ìní pàtàkì,+ kí ẹ lè kéde káàkiri àwọn ọlá ńlá”*+ Ẹni tó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.+ 10 Torí ẹ kì í ṣe àwùjọ èèyàn nígbà kan, àmọ́ ní báyìí ẹ ti di àwùjọ èèyàn Ọlọ́run;+ a kò ṣàánú yín nígbà kan, àmọ́ ní báyìí, a ti ṣàánú yín.+
11 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, mò ń gbà yín níyànjú, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀*+ pé kí ẹ máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara+ tó ń bá yín* jà.+ 12 Ẹ jẹ́ oníwà rere láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ kó lè jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ̀sùn ìwà ibi kàn yín, wọ́n á lè fojú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín,+ kí wọ́n sì torí ẹ̀ yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ àbẹ̀wò rẹ̀.
13 Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí èèyàn dá sílẹ̀,*+ ì báà jẹ́ ọba+ torí pé ó jẹ́ aláṣẹ 14 tàbí àwọn gómìnà tó rán níṣẹ́ pé kí wọ́n fìyà jẹ àwọn aṣebi, kí wọ́n sì yin àwọn tó ń ṣe rere.+ 15 Torí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ fi ìwà rere yín pa àwọn aláìnírònú tó ń fi àìmọ̀kan sọ̀rọ̀ lẹ́nu mọ́.*+ 16 Ẹ wà lómìnira,+ kí ẹ má sì fi òmìnira yín bojú* láti máa hùwà burúkú,+ àmọ́ kí ẹ lò ó bí ẹrú Ọlọ́run.+ 17 Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn,+ ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará,*+ ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run,+ ẹ bọlá fún ọba.+
18 Kí àwọn ìránṣẹ́ máa tẹrí ba fún àwọn ọ̀gá wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù tó yẹ,+ kì í ṣe fún àwọn tó jẹ́ ẹni rere, tó sì ń gba tẹni rò nìkan, àmọ́ fún àwọn tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn pẹ̀lú. 19 Torí ó dáa tí ẹnì kan bá fara da ìnira,* tó sì jìyà tí kò tọ́ sí i nítorí kó lè ní ẹ̀rí ọkàn rere lójú Ọlọ́run.+ 20 Àbí àǹfààní wo ló wà níbẹ̀ tí wọ́n bá lù yín torí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ tí ẹ sì fara dà á?+ Àmọ́ tí ẹ bá fara da ìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere, èyí dáa lójú Ọlọ́run.+
21 Kódà, ọ̀nà yìí la pè yín sí, torí Kristi pàápàá jìyà torí yín,+ ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.+ 22 Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan,+ kò sì sí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.+ 23 Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù sí i,*+ kò sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn* pa dà.+ Nígbà tó ń jìyà,+ kò bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀, àmọ́ ó fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́ Ẹni tó ń dájọ́+ òdodo. 24 Ó fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa+ lórí òpó igi,*+ ká lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀,* ká sì wà láàyè sí òdodo. Ẹ “sì rí ìwòsàn nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀.”+ 25 Torí ẹ dà bí àwọn àgùntàn tó sọnù,+ àmọ́ ẹ ti wá pa dà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ àti alábòójútó ọkàn* yín.