Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
22 Ó wá fi odò omi ìyè+ kan hàn mí, tó mọ́ rekete bíi kírísítálì, tó ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà + 2 wá sí àárín ọ̀nà rẹ̀ tó bọ́ sí gbangba. Àwọn igi ìyè tó ń so èso méjìlá (12) sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì odò náà, wọ́n ń so èso lóṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.+
3 Kò ní sí ègún kankan mọ́. Àmọ́ ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ máa wà ní ìlú náà, àwọn ẹrú rẹ̀ á sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un; 4 wọ́n máa rí ojú rẹ̀,+ orúkọ rẹ̀ sì máa wà níwájú orí wọn.+ 5 Bákan náà, ilẹ̀ ò ní ṣú mọ́,+ wọn ò sì nílò ìmọ́lẹ̀ fìtílà tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn, torí pé Jèhófà* Ọlọ́run máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí wọn,+ wọ́n sì máa jọba títí láé àti láéláé.+
6 Ó sọ fún mi pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé,* òótọ́ sì ni;+ kódà, Jèhófà* Ọlọ́run tó mí sí àwọn wòlíì+ ti rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀. 7 Wò ó! mò ń bọ̀ kíákíá.+ Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tó bá ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́.”+
8 Èmi Jòhánù fi ojú ara mi rí àwọn nǹkan yìí, mo sì fi etí ara mi gbọ́ ọ. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí i, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn ní ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tó ń fi àwọn nǹkan yìí hàn mí. 9 Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ wòlíì àti àwọn tó ń pa àwọn ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé yìí mọ́. Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn.”+
10 Ó tún sọ fún mi pé: “Má ṣe gbé èdìdì lé àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí, torí àkókò tí a yàn ti sún mọ́lé. 11 Kí ẹni tó jẹ́ aláìṣòdodo máa ṣe àìṣòdodo, kí ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́gbin má sì jáwọ́ nínú ẹ̀gbin rẹ̀; àmọ́ kí olódodo túbọ̀ máa ṣe òdodo, kí ẹni mímọ́ sì túbọ̀ máa jẹ́ mímọ́.
12 “‘Wò ó! Mò ń bọ̀ kíákíá, èrè tí mo sì ń fúnni wà pẹ̀lú mi, láti san ẹ̀san fún kálukú bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bá ṣe rí.+ 13 Èmi ni Ááfà àti Ómégà,*+ ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin. 14 Aláyọ̀ ni àwọn tó fọ aṣọ wọn,+ kí wọ́n lè ní àṣẹ láti lọ síbi àwọn igi ìyè,+ kí wọ́n sì lè gba ẹnubodè wọnú ìlú náà.+ 15 Ìta ni àwọn ajá* wà àti àwọn tó ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn apààyàn àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo àwọn tó fẹ́ràn irọ́, tí wọ́n sì ń parọ́.’+
16 “‘Èmi Jésù rán áńgẹ́lì mi láti jẹ́rìí àwọn nǹkan yìí fún ọ nítorí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti ọmọ Dáfídì+ àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tó mọ́lẹ̀ rekete.’”+
17 Ẹ̀mí àti ìyàwó+ ń sọ pé, “Máa bọ̀!” kí ẹnikẹ́ni tó ń gbọ́ sọ pé, “Máa bọ̀!” kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀;+ kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́, gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.+
18 “Mò ń jẹ́rìí fún gbogbo ẹni tó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí pé: Tí ẹnikẹ́ni bá fi kún àwọn nǹkan yìí,+ Ọlọ́run máa fi àwọn ìyọnu tó wà nínú àkájọ ìwé yìí kún un fún ẹni náà;+ 19 tí ẹnikẹ́ni bá sì yọ ohunkóhun kúrò nínú àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run máa yọ ìpín rẹ̀ kúrò nínú àwọn igi ìyè+ àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà,+ àwọn nǹkan tí a kọ nípa wọn sínú àkájọ ìwé yìí.
20 “Ẹni tó jẹ́rìí nípa àwọn nǹkan yìí sọ pé, ‘Àní, mò ń bọ̀ kíákíá.’”+
“Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”
21 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa wà pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́.