Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì
A B D E Ẹ F G GB H I J K L M N O Ọ P R S Ṣ T U W Y
A
Ááfà àti Ómégà.
Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú àwọn álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, Ómégà sì ni lẹ́tà tó gbẹ̀yìn. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí pa pọ̀ nínú ìwé Ìfihàn bí orúkọ oyè fún Ọlọ́run. Láwọn ibi tó ti fara hàn yìí, ó túmọ̀ sí “ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn” tàbí “ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.”—Ifi 1:8; 21:6; 22:13.
Ààwẹ̀.
Kí èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ má jẹun fún àwọn àkókò kan. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gba ààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù, nígbà tí wọ́n bá wà nínú wàhálà àti nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn Júù máa ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún láti rántí àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ààwẹ̀ kì í ṣe dandan fún àwọn Kristẹni.—Ẹsr 8:21; Ais 58:6; Lk 18:12.
Àbà.
Abẹ́mìílò.
Ẹni tó gbà pé òun máa ń bá àwọn òkú sọ̀rọ̀.—Le 20:27; Di 18:10-12; 2Ọb 21:6.
Ábíbù.
Oṣù àkọ́kọ́ nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù, òun sì ni oṣù keje nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó túmọ̀ sí “Ṣírí (Ọkà) Tútù.” Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù March sí àárín oṣù April. Ìgbà táwọn Júù dé láti Bábílónì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Nísàn. (Di 16:1)—Wo Àfikún B15.
Ábì.
Orúkọ tí wọ́n ń pe oṣù karùn-ún nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn Bábílónì, òun sì tún ni oṣù kọkànlá nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù July sí àárín oṣù August. Bíbélì kò sọ orúkọ oṣù yìí, ó kàn pè é ní “oṣù karùn-ún.” (Nọ 33:38; Ẹsr 7:9)—Wo Àfikún B15.
Adágún iná.
Ibi ìṣàpẹẹrẹ tó tọ́ka sí ibi “tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.” Bíbélì tún pè é ní “ikú kejì.” Àwọn tí wọ́n máa jù síbẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà àti Èṣù, títí kan ikú àti Isà Òkú (tàbí Hédíìsì). Bí wọ́n á ṣe ju àwọn nǹkan tí iná kò lè jó síbẹ̀, irú bí ẹ̀dá ẹ̀mí àti ikú pẹ̀lú Hédíìsì fi hàn pé iná ìṣàpẹẹrẹ lásán ni, kì í ṣe ibi tí wọ́n á ti máa joró títí láé, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìparun ayérayé.—Ifi 19:20; 20:14, 15; 21:8.
Ádárì.
Orúkọ tí wọ́n ń pe oṣù kejìlá nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn Bábílónì, òun sì tún ni oṣù kẹfà nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù February sí àárín oṣù March. (Ẹst 3:7)—Wo Àfikún B15.
Àgọ́ ìjọsìn.
Àgọ́ kan tó ṣe é gbé kiri tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń lò fún ìjọsìn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. Inú rẹ̀ ni àpótí májẹ̀mú Jèhófà wà, àpótí yìí sì jẹ́ àmì pé Ọlọ́run wà láàárín wọn. Àgọ́ yìí ni wọ́n ti máa ń rúbọ, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ń jọ́sìn. Nígbà míì, wọ́n máa ń pè é ní “àgọ́ ìpàdé.” Igi ni wọ́n fi ṣe àgọ́ náà, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tí a fi àwọn kérúbù ṣiṣẹ́ ọnà sí lára bò ó. Yàrá méjì ló wà nínú rẹ̀, wọ́n ń pe àkọ́kọ́ ní Ibi Mímọ́, ìkejì sì ń jẹ́ Ibi Mímọ́ Jù Lọ. (Joṣ 18:1; Ẹk 25:9)—Wo Àfikún B5.
Àgọ́ ìpàdé.
Àgbàlá.
Àyè fífẹ̀ tó yí àgọ́ ìjọsìn ká, tí wọ́n ta aṣọ sí yí ká. Nígbà tó yá, wọ́n tún lo orúkọ yìí fún àyè fífẹ̀ tó wà láàárín tẹ́ńpìlì àti ògiri tó yí i ká. Inú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn àti àgbàlá inú tó wà ní tẹ́ńpìlì ni pẹpẹ ẹbọ sísun wà. (Wo Àfikún B5, Àfikún B8 àti Àfikún B11.) Bíbélì tún mẹ́nu kan àgbàlá nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ilé àti ààfin.—Ẹk 8:13; 27:9; 1Ọb 7:12; Ẹst 4:11; Mt 26:3.
Àgbèrè.
Àìmọ́.
Ó lè tọ́ka sí kéèyàn dọ̀tí tàbí kéèyàn rú òfin ìwà rere. Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún ohun tí kò bójú mu tàbí ohun tí kò mọ́ bí Òfin Mósè ṣe sọ. (Le 5:2; 13:45; Mt 10:1; Iṣe 10:14; Ef 5:5)—Wo MỌ́ TÓNÍTÓNÍ.
Àjàgà.
Igi tí wọ́n máa ń gbé sí èjìká tí wọ́n sì máa ń gbé ẹrù kọ́ lápá méjèèjì. Òun tún ni igi tí wọ́n máa ń gbé kọ́ ọrùn àwọn ẹranko méjì (tó sábà máa ń jẹ́ màlúù) láti fa kẹ̀kẹ́ tàbí ohun èlò iṣẹ́ ọ̀gbìn. Torí pé àwọn ẹrú sábà máa ń fi àjàgà gbé àwọn ẹrù tó wúwo, Bíbélì fi àjàgà ṣàpẹẹrẹ ìsìnrú tàbí ìfìyàjẹni àti ìnilára. Tí wọ́n bá yọ àjàgà tàbí tí wọ́n ṣẹ́ àjàgà, ó túmọ̀ sí pé wọ́n dáni sílẹ̀ lọ́wọ́ ìsìnrú, ìnilára àti ìrẹ́jẹ.—Le 26:13; Mt 11:29, 30.
Àjàkálẹ̀ àrùn.
Àrùn èyíkéyìí tó máa ń tètè ranni, tó lè yára tàn kálẹ̀ débi tí á fi gbalẹ̀ kan, tó sì máa ń pani. Ọlọ́run sábà máa ń lò ó láti mú ìdájọ́ wá sórí àwọn èèyàn burúkú.—Nọ 14:12; Isk 38:22, 23; Emọ 4:10.
Àjíǹde.
Kí ẹni tó ti kú pa dà wà láàyè. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí àjíǹde, ìyẹn a·naʹsta·sis ń tọ́ka sí “gbé dìde” tàbí “dìde dúró.” Àjíǹde mẹ́sàn-án ni Bíbélì mẹ́nu kàn, títí kan bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe jí Jésù dìde. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Èlíjà, Èlíṣà, Jésù, Pétérù àti Pọ́ọ̀lù jí àwọn èèyàn dìde, síbẹ̀ gbogbo wọn gbà pé agbára Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe. “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” tó máa wáyé lórí ilẹ̀ ayé ṣe pàtàkì kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ. (Iṣe 24:15) Bíbélì tún mẹ́nu kan àjíǹde ti ọ̀run, ó pè é ní “àjíǹde àkọ́kọ́,” èyí sì kan àwọn arákùnrin Jésù tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró.—Flp 3:11; Ifi 20:5, 6; Jo 5:28, 29; 11:25.
Àjọyọ̀ Àtíbàbà.
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn tàbí Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé. Étánímù 15 sí 21 ni wọ́n máa ń ṣe é. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi ṣe ayẹyẹ ìkórè nǹkan ọ̀gbìn tó gbẹ̀yìn nínú ọdún, ó sì máa ń jẹ́ àkókò ayọ̀ àti ìdúpẹ́ fún ìbùkún Jèhófà lórí irè oko wọn. Nígbà àjọyọ̀ náà, inú àtíbàbà ni wọ́n máa ń wà kí wọ́n lè máa rántí bí wọ́n ṣe jáde kúrò ní Íjíbítì. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àjọyọ̀ mẹ́ta tí Ọlọ́run ní kí àwọn ọkùnrin lọ máa ṣe ní Jerúsálẹ́mù.—Le 23:34; Ẹsr 3:4.
Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.
Àjọyọ̀ Ìkórè; Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀.
—Wo PẸ́ŃTÍKỌ́SÌ.
Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́.
Òun ni wọ́n fi ń ṣe ìrántí ọdọọdún bí wọ́n ṣe fọ tẹ́ńpìlì mọ́ lẹ́yìn tí Áńtíókọ́sì Ẹpifánísì sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Àjọyọ̀ náà máa ń bẹ̀rẹ̀ ní Kísíléfì 25, ọjọ́ mẹ́jọ sì ni wọ́n fi ń ṣe é.—Jo 10:22.
Àkájọ ìwé.
Awọ tàbí òrépèté tó gùn, wọ́n máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí apá kan rẹ̀, wọ́n sábà ń ká a mọ́ ara igi kan. Inú àkájọ ìwé ni wọ́n kọ Ìwé Mímọ́ sí, inú rẹ̀ ni wọ́n ṣàdàkọ rẹ̀ sí, òun ló sì dà bí ìwé tí wọ́n sábà máa ń lò nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì.—Jer 36:4, 18, 23; Lk 4:17-20; 2Ti 4:13.
Ákáyà.
Bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó jẹ́ ìpínlẹ̀ ìjọba Róòmù tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Gíríìsì, Kọ́ríńtì sì ni olú ìlú rẹ̀. Agbègbè Peloponnese àti gbogbo ìlú tó wà ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Gíríìsì ló para pọ̀ di ìpínlẹ̀ Ákáyà. (Iṣe 18:12)—Wo Àfikún B13.
Àkọ́bí.
Àkọlé.
Àkọ́so.
Èso tí wọ́n bá kọ́kọ́ kórè nígbà ìkórè tàbí ohun tó bá kọ́kọ́ jáde látinú ohunkóhun. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fún òun ní àkọ́so wọn, yálà ó jẹ́ ti èèyàn, ti ẹranko tàbí ti ohun ọ̀gbìn. Lápapọ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi àkọ́so wọn rúbọ sí Ọlọ́run nígbà Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú àti ní Pẹ́ńtíkọ́sì. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a pe Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró ní “àkọ́so.”—1Kọ 15:23; Nọ 15:21; Owe 3:9; Ifi 14:4.
Akọ̀wé òfin.
Àwọn tó ṣàdàkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Nígbà ayé Jésù, àwùjọ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ Òfin ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. Wọ́n ta ko Jésù.—Ẹsr 7:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; Mk 12:38, 39; 14:1.
Alabásítà.
Àwọn ìṣà lọ́fínńdà kékeré tí wọ́n ń fi òkúta ṣe nígbà àtijọ́. Tòsí ìlú Alabastron tó wà ní Íjíbítì ni wọ́n ti máa ń rí òkúta náà. Àwọn ìṣà yẹn sábà máa ń ní ọrùn tóóró tó ṣeé fi ìdérí dé kí lọ́fínńdà iyebíye inú rẹ̀ má bàa dà nù. Nígbà tó yá, orúkọ yìí gan-an ni wọ́n fi ń pe òkúta náà.—Mk 14:3.
Alábòójútó.
Ọkùnrin tó ní ojúṣe láti máa bójú tó ìjọ, kó sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí alábòójútó ni e·piʹsko·pos, ó ń tọ́ka sí ẹni tó ń ṣọ́ni kó lè dáàbò boni. Ipò kan náà ni ọ̀rọ̀ náà “alábòójútó” àti “alàgbà” (pre·sbyʹte·ros) ń tọ́ka sí nínú ìjọ Kristẹni. Ọ̀rọ̀ náà “alàgbà” ń tọ́ka sí àwọn ànímọ́ tó fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹni tí a yàn sípò, “alábòójútó” sì tọ́ka sí àwọn ojúṣe ẹni tí a yàn sípò náà.—Iṣe 20:28; 1Ti 3:2-7; 1Pe 5:2.
Alàgbà; Àgbààgbà.
Ọkùnrin tó ti dàgbà. Àmọ́ nínú Ìwé Mímọ́, ó tọ́ka sí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ tó sì ní ojúṣe pàtàkì láwùjọ tàbí lórílẹ̀-èdè kan. Ìwé Ìfihàn tún lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run. Wọ́n tún máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pre·sbyʹte·ros sí “alàgbà” tó bá ń tọ́ka sí àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ.—Ẹk 4:29; Owe 31:23; 1Ti 5:17; Ifi 4:4.
Aláìwú.
Alákòóso ìbílẹ̀.
Álámótì.
Ọ̀rọ̀ nípa orin tó túmọ̀ sí “Àwọn Omidan; Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin,” ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ohùn tó ròkè tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin fi ń kọrin. Ó tún lè jẹ́ pé wọ́n máa ń lò ó fún àwọn ohùn orin tí wọ́n fẹ́ kó ròkè lala.—1Kr 15:20; Sm 46:Akl.
Alárinà.
Aláwọ̀ṣe.
Àlùfáà àgbà.
Lábẹ́ Òfin Mósè, òun ni àlùfáà tí ipò rẹ̀ ga jù lọ tó máa ń ṣojú àwọn èèyàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun ló sì ń darí iṣẹ́ àwọn àlùfáà yòókù. Wọ́n tún máa ń pè é ní “olórí àlùfáà.” (2Kr 26:20; Ẹsr 7:5) Òun nìkan ló lè wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ìyẹn yàrá inú lọ́hùn-ún nínú àgọ́ ìjọsìn àti yàrá inú lọ́hùn-ún nínú tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń lò nígbà tó yá. Ọjọ́ Ètùtù nìkan ló máa ń wọ ibẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Bíbélì tún pe Jésù Kristi ní “àlùfáà àgbà.”—Le 16:2, 17; 21:10; Mt 26:3; Heb 4:14.
Àlùfáà.
Ọkùnrin tó máa ń ṣojú fún Ọlọ́run lọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó ń bójú tó, ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run àtàwọn òfin rẹ̀. Àwọn àlùfáà tún máa ń ṣojú fáwọn èèyàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n máa ń rúbọ, wọ́n sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn èèyàn. Kí Jèhófà tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè, àwọn olórí ìdílé ló ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú ìdílé wọn. Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ọkùnrin nínú ìdílé Áárónì tó wá láti ẹ̀yà Léfì ló máa ń jẹ́ àlùfáà. Àwọn ọkùnrin yòókù tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí májẹ̀mú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Ísírẹ́lì tẹ̀mí di orílẹ̀-èdè àwọn àlùfáà, Jésù sì jẹ́ Àlùfáà Àgbà.—Ẹk 28:41; Heb 9:24; Ifi 5:10.
Amágẹ́dọ́nì.
Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà Har Meghid·dohnʹ, èyí tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò.” Ọ̀rọ̀ náà tan mọ́ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” níbi tí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” pé jọ sí láti bá Jèhófà jagun. (Ifi 16:14, 16; 19:11-21)—Wo ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ.
Àmín.
Ó túmọ̀ sí “kó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “dájúdájú.” Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʼa·manʹ, tó túmọ̀ sí “jẹ́ olóòótọ́, ṣeé gbọ́kàn lé.” Àwọn èèyàn máa ń ṣe “Àmín” láti fi hàn pé àwọn fara mọ́ ẹ̀jẹ́, àdúrà tàbí àdéhùn. Àmín tún jẹ́ orúkọ oyè tí Bíbélì lò fún Jésù nínú ìwé Ìfihàn.—Di 27:26; 1Kr 16:36; Ifi 3:14.
Àmì.
Ohun kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ipò kan tàbí ohun àrà kan tó ń tọ́ka sí ohun míì tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Jẹ 9:12, 13; 2Ọb 20:9; Mt 24:3; Ifi 1:1.
Amọ̀kòkò.
Áńgẹ́lì.
Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà mal·ʼakhʹ àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà agʹge·los. “Òjíṣẹ́” ni ọ̀rọ̀ méjèèjì túmọ̀ sí, àmọ́ “áńgẹ́lì” la máa ń lò fún un tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó ń jíṣẹ́. (Jẹ 16:7; 32:3; Jem 2:25; Ifi 22:8) Ẹ̀dá ẹ̀mí tó lágbára làwọn áńgẹ́lì, Ọlọ́run sì ti dá wọn tipẹ́tipẹ́ kó tó dá èèyàn. Bíbélì pè wọ́n ní “ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹni mímọ́,” “àwọn ọmọ Ọlọ́run” àti “àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀.” (Di 33:2; Job 1:6; 38:7) Ọlọ́run ò dá wọn pé kí wọ́n máa bímọ, ó dìídì dá wọn lọ́kọ̀ọ̀kan ni. Wọ́n ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù lọ. (Da 7:10) Bíbélì fi hàn pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ tiẹ̀ àti ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn, púpọ̀ lára wọn kì í sì í fẹ́ sọ orúkọ wọn fún èèyàn. (Jẹ 32:29; Lk 1:26; Ifi 22:8, 9) Ọlọ́run fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí ipò tó yàtọ̀ síra, ó sì yan iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún wọn. Àwọn kan máa ń wà níwájú ìtẹ́ Jèhófà, àwọn míì ń jíṣẹ́ fún un, àwọn kan máa ń gbèjà àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tó wà láyé, àwọn míì máa ń mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ, àwọn kan sì ń ṣètìlẹyìn fún àwọn tó ń wàásù ìhìn rere. (2Ọb 19:35; Sm 34:7; Lk 1:30, 31; Ifi 5:11; 14:6) Lọ́jọ́ iwájú, wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ja ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ifi 19:14, 15.
Àpéjọ.
Àpò awọ.
Àpò tí wọ́n fi awọ odindi ewúrẹ́ tàbí àgùntàn ṣe, wáìnì ni wọ́n máa ń rọ sínú rẹ̀. Inú àpò awọ tuntun ni wọ́n máa ń rọ wáìnì sí, bí wáìnì náà bá ṣe ń pẹ́ sí i, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa kan. Torí náà, afẹ́fẹ́ carbon dioxide tó jáde lára rẹ̀ máa mú kí àpò awọ náà fẹ̀, kó sì máa ràn. Àpò awọ tuntun máa ń ràn, àmọ́ èyí tó jẹ́ ògbólógbòó kì í ràn, ó sì máa bẹ́ tí wọ́n bá rọ wáìnì sínú rẹ̀.—Joṣ 9:4; Mt 9:17.
Àpótí májẹ̀mú.
Àpótí kan tí wọ́n fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe, tí wọ́n sì fi wúrà bò lára, inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn ló máa ń wà, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n gbé e sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́. Ó ní ìdérí tí wọ́n fi wúrà tó nípọn ṣe, ère kérúbù méjì tó kọjú síra sì wà lórí rẹ̀. Olórí ohun tó wà nínú rẹ̀ ni wàláà òkúta méjì tí wọ́n kọ Òfin Mẹ́wàá sí lára. (Di 31:26; 1Ọb 6:19; Heb 9:4)—Wo Àfikún B5 àti B8.
Àpọ́sítélì.
Árámáíkì.
Èdè yìí sún mọ́ èdè Hébérù, álífábẹ́ẹ̀tì kan náà ni wọ́n sì ní. Àwọn ará Arémíà ló ń sọ èdè yìí níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Ásíríà àti ti Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó nílé lóko àti nídìí òwò. Èdè yìí náà ni Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ń lò. (Ẹsr 4:7) Èdè Árámáíkì yìí ni wọ́n fi kọ àwọn apá kan nínú ìwé Ẹ́sírà, Jeremáyà àti Dáníẹ́lì.—Ẹsr 4:8–6:18; 7:12-26; Jer 10:11; Da 2:4b–7:28.
Ará Mídíà; Mídíà.
Àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ Mádáì ọmọ Jáfẹ́tì; wọ́n tẹ̀ dó sí àwọn ilẹ̀ olókè tí orí rẹ̀ tẹ́jú tó wá di orílẹ̀-èdè Mídíà. Àwọn ará Mídíà dara pọ̀ mọ́ àwọn ará Bábílónì láti ṣẹ́gun Ásíríà. Nígbà yẹn, Páṣíà jẹ́ ìpínlẹ̀ kan lábẹ́ ìjọba Mídíà, àmọ́ nígbà tí Kírúsì ṣọ̀tẹ̀, wọ́n da Mídíà pọ̀ mọ́ Páṣíà, òun ló wá di Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà tó ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Tuntun lọ́dún 539 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ará Mídíà wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Da 5:28, 31; Iṣe 2:9)—Wo Àfikún B9.
Árámù; Àwọn ará Arémíà.
Àwọn àtọmọdọ́mọ Árámù tó jẹ́ ọmọ Ṣémù tó ń gbé ní agbègbè Òkè Lẹ́bánónì títí lọ dé Mesopotámíà, wọ́n tún wà ní àwọn Òkè Táúrù ní àríwá títí dé ìkọjá Damásíkù ní gúúsù. Agbègbè tí wọ́n ń pè ní Árámù lédè Hébérù yìí ni wọ́n wá ń pè ní Síríà nígbà tó yá, wọ́n sì ń pe àwọn tó ń gbé ibẹ̀ ní àwọn ará Síríà.—Jẹ 25:20; Di 26:5; Ho 12:12.
Ará Násárẹ́tì.
Orúkọ tí wọ́n ń pe Jésù torí pé ìlú Násárẹ́tì ló ti wá. Ó ṣeé ṣe kó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “èéhù” nínú Àìsáyà 11:1. Nígbà tó yá, wọ́n pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà ní ará Násárẹ́tì.—Mt 2:23; Iṣe 24:5.
Áréópágù.
Òkè gíga kan tó wà ní Áténì lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn ilé tí wọ́n kọ́ sí téńté ìlú Áténì. Orúkọ yẹn náà ni wọ́n máa ń pe ìgbìmọ̀ (kọ́ọ̀tù) tó máa ń pàdé níbẹ̀. Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́ìkì àti Epikúríà mú Pọ́ọ̀lù wá sí Áréópágù kó lè wá ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́.—Iṣe 17:19.
Aríran.
Ẹni tí Ọlọ́run fi àwọn ohun tó fẹ́ ṣe hàn, ẹni tó ń rí ohun táwọn míì ò lè rí, tó sì máa ń lóye ohun táwọn míì ò mọ̀. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n ń lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí “láti rí,” bóyá ká fojú rí i tàbí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Tí àwọn èèyàn bá ní ìṣòro, wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn aríran kí wọ́n lè gba ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n.—1Sa 9:9.
Ásásélì.
Aselgeia.
—Wo ÌWÀ ÀÌNÍTÌJÚ.
Aṣẹ́wó.
Ẹni tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀, ó sì sábà máa ń jẹ́ torí owó. (Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “aṣẹ́wó” ni porʹne, èyí tó dúró fún “láti tà.”) Obìnrin ni wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin tó jẹ́ aṣẹ́wó. Òfin Mósè kò fàyè gba iṣẹ́ aṣẹ́wó, ó sì sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi owó tí wọ́n bá rí nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó ṣètọrẹ nínú ilé Jèhófà, èyí sì yàtọ̀ sí àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n ń fi àwọn aṣẹ́wó pawó nínú tẹ́ńpìlì wọn. (Di 23:17, 18; 1Ọb 14:24) Bíbélì tún máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpẹẹrẹ àwọn èèyàn, àwọn orílẹ̀-èdè tàbí àwọn àjọ tí wọ́n ń bọ̀rìṣà àmọ́ tí wọ́n ń sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Ìfihàn, Bíbélì pe àwọn ẹ̀sìn kan ní “Bábílónì Ńlá,” ó sì fi wé aṣẹ́wó torí pé ó máa ń bá àwọn aláṣẹ ayé da nǹkan pọ̀ kó lè ní agbára àtàwọn nǹkan tara tó pọ̀.—Ifi 17:1-5; 18:3; 1Kr 5:25.
Àṣírí mímọ́.
Àṣìṣe; Ìṣìnà.
Áṣítórétì.
Abo òrìṣà ilẹ̀ Kénáánì tó jẹ́ ọlọ́run ogun àti ìbímọlémọ, òun sì ni ìyàwó Báálì.—1Sa 7:3.
Aṣíwájú.
Aṣòdì sí Kristi.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún gbólóhùn yìí ní ìtumọ̀ méjì. Ó túmọ̀ sí ṣòdì sí tàbí ta ko Kristi. Ó tún lè túmọ̀ sí èké Kristi, ìyẹn ẹni tó fi ara rẹ̀ sípò Kristi. Gbogbo èèyàn, àjọ tàbí àwùjọ tó bá ń parọ́ pé àwọn ń ṣojú fún Kristi tàbí tó ń pe ara wọn ní Mèsáyà tàbí tó ń ta ko Kristi àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ni a lè pè ní aṣòdì sí Kristi.—1Jo 2:2.
Aṣọ ìdábùú.
Aṣọ ìgbàyà.
Aṣọ pélébé tí wọ́n to àwọn òkúta iyebíye sí lára. Àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì máa ń wọ̀ ọ́ sáyà tó bá fẹ́ wọ Ibi Mímọ́. Wọ́n máa ń pè é ní “aṣọ ìgbàyà ìdájọ́” torí pé Úrímù àti Túmímù wà nínú rẹ̀, èyí tí wọ́n máa ń lò láti sọ ìdájọ́ Jèhófà. (Ẹk 28:15-30)—Wo Àfikún B5.
Aṣọ ọ̀fọ̀.
Àsọtẹ́lẹ̀.
Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìran nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe tàbí kó jẹ́ ìkéde rẹ̀. Ọlọ́run lè lò ó láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, láti pàṣẹ, láti kéde ìdájọ́ tàbí láti kéde ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.—Isk 37:9, 10; Da 9:24; Mt 13:14; 2Pe 1:20, 21.
Awòràwọ̀.
Àwọn agbófinró; Àwọn adájọ́ kéékèèké.
Lábẹ́ ìjọba Bábílónì, àwọn agbófinró ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó máa ń wà lágbègbè kọ̀ọ̀kan, wọ́n mọ òfin, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ẹjọ́ ni wọ́n lè dá. Ní àwọn agbègbè tó wà lábẹ́ àkóso Róòmù, àwọn agbófinró ìlú ló máa ń bójú tó ètò ìjọba. Ara iṣẹ́ wọn ni láti rí i pé nǹkan ń lọ dáadáa nílùú, wọ́n ń bójú tó ìnáwó, wọ́n ń dájọ́ àwọn arúfin, wọ́n sì máa ń fàṣẹ sí i pé kí wọ́n lọ fìyà jẹ arúfin.—Da 3:2; Iṣe 16:20.
Àwọn ará Samáríà.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lábẹ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà ní àríwá ni wọ́n kọ́kọ́ ń pè bẹ́ẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn táwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun Samáríà lọ́dún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n kó àwọn àjèjì wá, àwọn náà wá di ará Samáríà. Nígbà ayé Jésù, orúkọ yìí kì í sábà tọ́ka sí ẹ̀yà tàbí ìjọba kan, wọ́n máa ń lò ó fún àwọn tó wà nínú ẹ̀ya ìsìn kan lágbègbè Samáríà àti Ṣékémù àtijọ́. Ohun táwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí gbà gbọ́ yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ẹlẹ́sìn Júù yòókù.—Jo 8:48.
Àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú.
—Wo BÚRẸ́DÌ ÀFIHÀN.
Àwọn onídàájọ́.
Àwọn ọkùnrin tí Jèhófà lò láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, kó tó di pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ní ọba tó jẹ́ èèyàn.—Ond 2:16.
Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Epikúríà.
Àwọn ọmọlẹ́yìn Epicurus ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí (tó gbáyé ní 341 sí 270 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni). Wọ́n gbà pé ohun tí a wáyé wá ṣe ni pé ká jayé orí wa.—Iṣe 17:18.
Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́ìkì.
Àwọn Gíríìkì tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí. Wọ́n gbà pé ọgbọ́n orí àtàwọn nǹkan àbáláyé ló lè mú kéèyàn láyọ̀. Èrò wọn ni pé, ẹni tó bá gbọ́n lóòótọ́ kò ní ka ìrora tàbí ìgbádùn sí bàbàrà.—Iṣe 17:18.
Àwọn ọmọ Áárónì.
Àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì, tó jẹ́ ọmọ ọmọ Léfì. Áárónì ni àlùfáà àgbà àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run yàn lábẹ́ Òfin Mósè. Àwọn ọmọ Áárónì ló máa ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì.—1Kr 23:28.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù.
B
Baálẹ̀.
Báálì.
Òrìṣà ilẹ̀ Kénáánì tí wọ́n gbà pé òun ló ni ojú ọ̀run, tó sì ń fúnni ní òjò àti ọmọ. Wọ́n tún máa ń pe àwọn òrìṣà kéékèèké ní “Báálì.” Lédè Hébérù, orúkọ náà túmọ̀ sí “Oníǹkan; Ọ̀gá.”—1Ọb 18:21; Ro 11:4.
Báàtì.
Gẹ́gẹ́ bí orúkọ tó wà lára àwọn àfọ́kù kan táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ṣe fi hàn, báàtì jẹ́ òṣùwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn nǹkan olómi tí ó tó nǹkan bíi Lítà 22 (ìyẹn gálọ́ọ̀nù 5.81). Ọ̀pọ̀ àwọn òṣùwọ̀n nǹkan gbígbẹ àti nǹkan olómi tí Bíbélì mẹ́nu kàn ló jẹ́ pé báàtì ni wọ́n fi ń díwọ̀n wọn. (1Ọb 7:38; Isk 45:14)—Wo Àfikún B14.
Béélísébúbù.
Búlì.
Orúkọ tí wọ́n ń pe oṣù kẹjọ nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù, òun sì tún ni oṣù kejì nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Orúkọ yìí wá látinú ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “hù; so èso.” Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù October sí àárín oṣù November. (1Ọb 6:38)—Wo Àfikún B15.
Búrẹ́dì àfihàn.
Búrẹ́dì méjìlá tí wọ́n tò ní mẹ́fà-mẹ́fà sórí tábìlì ní Ibi Mímọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì. Òun náà ni wọ́n tún ń pè ní “búrẹ́dì onípele” àti “búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú.” Ọrẹ sí Ọlọ́run ni, wọ́n sì máa ń fi búrẹ́dì tuntun rọ́pò rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Sábáàtì. Àwọn àlùfáà nìkan ló máa ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n bá kó kúrò níbẹ̀. (2Kr 2:4; Mt 12:4; Ẹk 25:30; Le 24:5-9; Heb 9:2)—Wo Àfikún B5.
D
Dágónì.
Òrìṣà àwọn ará Filísínì. Kò sẹ́ni tó mọ ibi tí orúkọ yìí ti wá gan-an, àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ó jọ ọ̀rọ̀ Hébérù náà dagh (ìyẹn ẹja).—Ond 16:23; 1Sa 5:4.
Dáríkì.
Ẹyọ owó góòlù àwọn ará Páṣíà tó wúwo tó gíráàmù 8.4. (1Kr 29:7)—Wo Àfikún B14.
Dekapólì.
Àpapọ̀ àwọn ìlú kan ní Gíríìsì, wọ́n jẹ́ mẹ́wàá níbẹ̀rẹ̀ (orúkọ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà deʹka, tó túmọ̀ sí “mẹ́wàá” àti poʹlis, tó túmọ̀ sí “ìlú”). Orúkọ yìí náà ni wọ́n fi ń pe agbègbè kan ní ìlà oòrùn Òkun Gálílì àti odò Jọ́dánì, ibẹ̀ sì ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìlú yẹn wà. Wọ́n jẹ́ ojúkò àṣà àti òwò àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì. Jésù gba agbègbè yìí kọjá, àmọ́ kò sí ẹ̀rí pé ó wọnú ìkankan lára àwọn ìlú náà. (Mt 4:25; Mk 5:20)—Wo Àfikún A7 àti B10.
Dínárì.
Ẹyọ owó fàdákà àwọn ará Róòmù tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi gíráàmù 3.85, ó sì ní àwòrán Késárì lápá kan. Òun ni iye owó tí lébìrà máa ń gbà fún iṣẹ́ ọjọ́ kan. Òun sì tún ni iye “owó orí” tí àwọn ará Róòmù ń gbà lọ́wọ́ àwọn Júù. (Mt 22:17; Lk 20:24)—Wo Àfikún B14.
Dírákímà.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí ẹyọ owó fàdákà táwọn Gíríìkì máa ń ná nígbà yẹn, ó sì wúwo tó gíráàmù 3.4. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù mẹ́nu ba dírákímà wúrà nígbà ayé àwọn ará Páṣíà, iye kan náà ló sì jẹ́ pẹ̀lú dáríkì. (Ne 7:70; Mt 17:24)—Wo Àfikún B14.
E
Èbíbu.
Èyíkéyìí lára àwọn àrùn tó máa ń mú kí nǹkan hu olú, tó sì máa ń ba irè oko jẹ́. Àwọn kan sọ pé ńṣe ni èbíbu tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ máa ń jẹ́ kí ara ewé àti igi dà bí ìgbà tí ìpẹtà bá yọ lára nǹkan (Puccinia graminis).—1Ọb 8:37.
Èdìdì.
Ohun tí wọ́n fi ń tẹ ọ̀rọ̀ sára nǹkan, ó sábà máa ń jẹ́ sára amọ̀ tàbí ìda. Ó lè jẹ́ àmì tó jẹ́ ká mọ ẹni tó ni nǹkan, àmì àdéhùn tàbí láti fi hàn pé nǹkan kan jẹ́ ojúlówó. Láyé àtijọ́, àwọn nǹkan tó le, irú bí òkúta, eyín erin tàbí igi ni wọ́n fi ń ṣe é, ọ̀rọ̀ tí wọ́n yí sódì ni wọ́n máa ń kọ si í lára. Bíbélì máa ń lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti tọ́ka sí ohun tó jẹ́ ojúlówó, ohun tó jẹ́ àṣírí tàbí tí a fi pa mọ́, ó sì lè jẹ́ àmì ẹni tó ni nǹkan.—Ẹk 28:11; Ne 9:38; Ifi 5:1; 9:4.
Édómù.
Eéfà.
Òṣùwọ̀n nǹkan gbígbẹ. Orúkọ yìí náà ni wọ́n ń pe ohun tí wọ́n fi ń wọn ọkà. Ìwọ̀n kan náà ni pẹ̀lú báàtì tí wọ́n fi ń wọn nǹkan olómi, tó jẹ́ Lítà 22. (Ẹk 16:36; Isk 45:10)—Wo Àfikún B14.
Eéṣú.
Éfódì.
Éfúrémù.
Ègún.
Kéèyàn fi èpè halẹ̀ mọ́ ẹnì kan tàbí kó ṣépè fún onítọ̀hún tàbí ohun kan. Ó yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀rọ̀ òdì tàbí ọ̀rọ̀ ìbínú. Ègún lágbára gan-an torí pé ó sábà máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé nǹkan burúkú máa ṣẹlẹ̀. Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run tàbí ẹnì kan tí Ọlọ́run yàn ló gégùn-ún, ó máa ń jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó lágbára.—Jẹ 12:3; Nọ 22:12; Ga 3:10.
Élúlì.
Orúkọ tí wọ́n ń pe oṣù kẹfà nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn Bábílónì, òun sì tún ni oṣù kejìlá nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù August sí àárín oṣù September. (Ne 6:15)—Wo Àfikún B15.
Éṣíà.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, òun ni orúkọ ìpínlẹ̀ ìjọba Róòmù tó ní nínú ibi tí a wá mọ̀ lónìí sí apá ìwọ̀ oòrùn Tọ́kì àtàwọn erékùṣù kan bíi Sámósì àti Pátímọ́sì. Éfésù ni olú ìlú rẹ̀ nígbà yẹn. (Iṣe 20:16; Ifi 1:4)—Wo Àfikún B13.
Èṣù.
Esùsú.
Orúkọ tí à ń pe onírúurú koríko tó sábà máa ń hù níbi tí omi wà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ewéko tí ọ̀rọ̀ yìí sábà máa ń tọ́ka sí ni Arundo donax. (Job 8:11; Ais 42:3; Mt 27:29; Ifi 11:1)—Wo Ọ̀PÁ ESÙSÚ.
Étánímù.
Orúkọ tí wọ́n ń pe oṣù keje nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù, òun sì tún ni oṣù kìíní nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù September sí àárín oṣù October. Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Tíṣírì. (1Ọb 8:2)—Wo Àfikún B15.
Etiópíà.
Orílẹ̀-èdè àtijọ́ kan tó wà ní gúúsù Íjíbítì. Òun ló wà ní ìkángun apá gúúsù orílẹ̀-èdè Íjíbítì òde òní àti orílẹ̀-èdè Sudan òde òní. Wọ́n tún máa ń pè é ní “Kúṣì” lédè Hébérù.—Ẹst 1:1.
Ètò àwọn nǹkan; Àwọn ètò àwọn nǹkan.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí ètò àwọn nǹkan ni ai·onʹ, èyí sì ń tọ́ka sí bí nǹkan ṣe rí lásìkò kan tàbí àwọn ohun tó mú kí ìgbà kan yàtọ̀ sáwọn àkókò míì. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí” láti tọ́ka sí bí nǹkan ṣe rí lágbàáyé àti irú ìgbésí ayé táwọn tí kò mọ Ọlọ́run ń gbé. (2Ti 4:10) Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ètò àwọn nǹkan pàtó kan nígbà tó fi Májẹ̀mú Òfin lọ́lẹ̀, àwọn kan sì máa ń pe àkókò náà ní àsìkò àwọn Júù tàbí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ọlọ́run tún lo Jésù Kristi láti bẹ̀rẹ̀ ètò àwọn nǹkan míì tó kan ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní pàtàkì. Ẹbọ ìràpadà Jésù ló sì mú kí èyí ṣeé ṣe. Èyí ló bẹ̀rẹ̀ àsìkò tuntun míì, ìyẹn ìgbà táwọn nǹkan tó wà nínú Májẹ̀mú Òfin bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ. Nígbà tí a bá lo ọ̀rọ̀ náà àwọn ètò àwọn nǹkan, ó ń tọ́ka sí onírúurú ètò àwọn nǹkan tó ti wà tàbí ètò tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí èyí tó ń bọ̀.—Mt 24:3; Mk 4:19; Ro 12:2; 1Kọ 10:11.
Ètùtù.
Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ yìí jẹ mọ́ àwọn ẹbọ tí àwọn èèyàn máa ń rú kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀. Nínú Òfin Mósè, wọ́n máa ń rúbọ pàápàá ní Ọjọ́ Ètùtù, èyí tó máa ń wáyé ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti nítorí ti orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ kí wọ́n lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Àwọn ẹbọ yẹn ń tọ́ka sí ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú, èyí tó kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, tó sì mú káwọn èèyàn láǹfààní láti pa dà bá Jèhófà rẹ́.—Le 5:10; 23:28; Kol 1:20; Heb 9:12.
Ẹ
Ẹbọ ẹ̀bi.
Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Ẹbọ ìdúpẹ́.
Ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí wọ́n máa ń rú láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àwọn ìpèsè rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Wọ́n máa ń jẹ ẹran tí wọ́n fi rúbọ náà pẹ̀lú búrẹ́dì tó ní ìwúkàrà àtèyí tí kò ní ìwúkàrà. Ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹran náà.—2Kr 29:31.
Ẹbọ ìrẹ́pọ̀.
Ẹbọ tí ẹnì kan rú sí Jèhófà kó lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn tó máa jẹ ẹ́ ni: olùjọ́sìn Jèhófà tó fẹ́ rúbọ àti ìdílé rẹ̀, àlùfáà tó máa ṣètò ẹbọ náà àtàwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ náà. Tí wọ́n bá ti ń sun ọ̀rá ẹran náà, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń gba òórùn èéfín rẹ̀ tó ń tuni lára. Wọ́n tún máa fún Jèhófà ní ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, èyí tó dúró fún ẹ̀mí rẹ̀. Á wá dà bíi pé àwọn àlùfáà àti àwọn tó rúbọ náà jọ jókòó tí wọ́n ń bá Jèhófà jẹun, èyí á sì fi hàn pé àlàáfíà wà láàárín wọn.—Le 7:29, 32; Di 27:7.
Ẹbọ.
Ohun téèyàn fún Ọlọ́run láti fi ẹ̀mí ìmoore hàn, láti gbà pé òun jẹ̀bi, kó sì lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Látorí Ébẹ́lì, àwọn èèyàn fínnúfíndọ̀ rú onírúurú ẹbọ, àwọn míì fi ẹran rúbọ, kí májẹ̀mú Òfin Mósè tó wá sọ ọ́ di dandan. Látìgbà tí Jésù ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rú ẹbọ tó pé pérépéré fún wa, a ò nílò láti máa fi ẹran rúbọ mọ́, àmọ́ àwa Kristẹni ṣì ń rú ẹbọ tẹ̀mí sí Ọlọ́run.—Jẹ 4:4; Heb 13:15, 16; 1Jo 4:10.
Ẹbọ sísun.
Ẹ̀jẹ́.
Ẹ̀mí Èṣù.
Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú tí kò ṣeé fojú rí, tí wọ́n sì lágbára ju èèyàn lọ. Jẹ́nẹ́sísì 6:2 pè wọ́n ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́,” Júùdù 6 sì pè wọ́n ní “áńgẹ́lì.” Ọlọ́run ò dá wọn ní ẹ̀dá burúkú; áńgẹ́lì ni wọ́n, àwọn fúnra wọn ló sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọ́run torí wọ́n ṣàìgbọràn sí i nígbà ayé Nóà, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.—Di 32:17; Lk 8:30; Iṣe 16:16; Jem 2:19.
Ẹ̀mí mímọ́.
Ẹ̀mí.
Ọ̀rọ̀ tí a sábà máa ń tú sí “ẹ̀mí” ni ruʹach lédè Hébérù àti pneuʹma lédè Gíríìkì, onírúurú ìtumọ̀ lọ̀rọ̀ yìí ní. Gbogbo ìtúmọ̀ náà ń tọ́ka sí agbára kan tó ń ṣiṣẹ́ àmọ́ tí èèyàn ò lè fojú rí. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì yìí ń tọ́ka sí (1) atẹ́gùn, (2) ohun tó ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà ní ayé wà láàyè, (3) agbára tó ń tinú ọkàn èèyàn wá, tó ń mú kó sọ̀rọ̀ kó sì hùwà lọ́nà kan, (4) àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tó wá látibi tí èèyàn ò lè fojú rí, (5) àwọn ẹni ẹ̀mí àti (6) agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run tàbí ẹ̀mí mímọ́.—Ẹk 35:21; Sm 104:29; Mt 12:43; Lk 11:13.
Ẹni burúkú, náà.
Ẹ̀rí.
Ó sábà máa ń tọ́ka sí àwọn Òfin Mẹ́wàá tí Jèhófà kọ sórí wàláà òkúta méjì tó fún Mósè.—Ẹk 31:18.
Ẹrù ogun.
Ẹ̀ṣọ́ Ọba.
Àwùjọ àwọn ọmọ ogun Róòmù tí wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún olú ọba Róòmù. Nígbà tó yá, àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí lágbára nínú òṣèlú débi pé wọ́n lè ti olú ọba kan lẹ́yìn tàbí kí wọ́n dìtẹ̀ láti lé e kúrò lórí àlééfà.—Flp 1:13.
Ẹ̀tẹ̀; Adẹ́tẹ̀.
Àrùn burúkú tó máa ń ba awọ ara jẹ́. Kì í ṣe àrùn tí a mọ̀ sí ẹ̀tẹ̀ lónìí nìkan ni Bíbélì máa ń pè ní ẹ̀tẹ̀, torí pé kì í ṣe ara èèyàn nìkan ló máa ń wà, ó tún lè wà lára aṣọ àti ilé. Ẹni tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ là ń pè ní adẹ́tẹ̀.—Le 14:54, 55; Lk 5:12.
Ẹ̀ya ìsìn.
Àwùjọ àwọn èèyàn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ kan tàbí ẹnì kan tí wọ́n kà sí aṣáájú, wọ́n sì ní òfin àtàwọn ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ya ìsìn làwọn Farisí àtàwọn Sadusí tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ méjì tó lókìkí nínú Ìsìn Àwọn Júù. Àwọn tí kì í ṣe Kristẹni máa ń pe àwọn Kristẹni ní “ẹ̀ya ìsìn” tàbí “ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárẹ́tì,” bóyá torí wọ́n gbà pé wọ́n yapa kúrò nínú Ìsìn Àwọn Júù. Nígbà tó yá, ẹ̀ya ìsìn náà jẹ yọ nínú ìjọ Kristẹni. Bíbélì mẹ́nu kan “ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì” nínú ìwé Ìfihàn.—Iṣe 5:17; 15:5; 24:5; 28:22; Ifi 2:6; 2Pe 2:1.
F
Fáráò.
Farisí.
Ẹgbẹ́ kan tó gbajúmọ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ìdílé àwọn àlùfáà kọ́ ni wọ́n ti wá, àmọ́ wọ́n máa ń tẹ̀ lé Òfin dórí bíńtín, ọwọ́ kan náà ni wọ́n sì fi ń mú àwọn òfin àtẹnudẹ́nu. (Mt 23:23) Wọ́n máa ń ta ko gbogbo àṣà àwọn Gíríìkì. Torí pé ọ̀mọ̀wé ni wọ́n tó bá kan ọ̀rọ̀ Òfin àti àṣà àwọn Júù, wọ́n máa ń jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí gan-an. (Mt 23:2-6) Àwọn kan lára wọn wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn. Wọ́n máa ń ta ko Jésù gan-an lórí ọ̀rọ̀ Sábáàtì, àwọn àṣà àti kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àtàwọn agbowó orí. Àwọn kan lára wọn di Kristẹni, àpẹẹrẹ kan ni Sọ́ọ̀lù ará Tásù.—Mt 9:11; 12:14; Mk 7:5; Lk 6:2; Iṣe 26:5.
Fátọ́ọ̀mù.
Ìdíwọ̀n gbọọrọ tí wọ́n fi ń mọ bí omi ṣe jìn tó. Ó jẹ́ mítà 1.8 (ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà 6). (Iṣe 27:28)—Wo Àfikún B14.
Filísíà; Àwọn Filísínì.
Fòróró yàn.
Lédè Hébérù, ó túmọ̀ sí “láti fi nǹkan olómi pa.” Wọ́n máa ń da òróró sórí ẹnì kan tàbí ohun kan láti fi hàn pé a ti yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ pàtàkì kan. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, wọ́n tún lo ọ̀rọ̀ náà fún dída ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn tí Ọlọ́run yàn láti lọ sí ọ̀run.—Ẹk 28:41; 1Sa 16:13; 2Kọ 1:21.
G
Gérà.
Òṣùwọ̀n tó wúwo tó gíráàmù 0.57. Ogún gérà ni ṣékélì kan. (Le 27:25)—Wo Àfikún B14.
Gẹ̀hẹ́nà.
Orúkọ Gíríìkì tí wọ́n ń pe Àfonífojì Hínómù, tó wà ní gúúsù sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù àtijọ́. (Jer 7:31) Ó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ pé ibẹ̀ máa di ibi tí wọ́n á máa ju àwọn òkú sí. (Jer 7:32; 19:6) Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ju ẹranko tàbí èèyàn sínú Gẹ̀hẹ́nà kí wọ́n lè jóná láàyè tàbí kí wọ́n lè máa joró. Torí náà, kì í ṣe ibi téèyàn ò lè rí ló ń ṣàpẹẹrẹ, níbi tí ẹ̀mí àwọn èèyàn ti ń joró nínú iná títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi Gẹ̀hẹ́nà ṣàpẹẹrẹ “ikú kejì,” ìyẹn ìparun ayérayé tàbí ìparun yán-án yán-án.—Ifi 20:14; Mt 5:22; 10:28.
Gílíádì.
Gíríìkì.
Èdè tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ń sọ. Wọ́n tún máa ń lò ó fún ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tàbí ẹni tí ìdílé rẹ̀ wá láti ibẹ̀. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí gbòòrò, ó lè tọ́ka sí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Júù tàbí àwọn míì tí wọ́n ń sọ èdè Gíríìkì tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àṣà wọn.—Joẹ 3:6; Jo 12:20.
Gítítì.
Ọ̀rọ̀ nípa orin ni, a ò mọ ìtúmọ̀ rẹ̀, àmọ́ ó jọ pé ó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà gath. Àwọn kan gbà pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orin tó jẹ mọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe wáìnì, torí pé ọ̀rọ̀ náà gath ń tọ́ka sí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.—Sm 81:Akl.
Gb
Gbé ọwọ́ lé.
H
Hébérù.
Ábúrámù (Ábúráhámù) ni wọ́n kọ́kọ́ lo orúkọ yìí fún, ìyẹn sì mú kó yàtọ̀ sáwọn ọmọ Ámórì tí wọ́n jẹ́ aládùúgbò rẹ̀. Nígbà tó yá, orúkọ yìí ni wọ́n fi ń pe àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù tó ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ Jékọ́bù ọmọ ọmọ rẹ̀ àti èdè tí wọ́n ń sọ. Nígbà ayé Jésù, àwọn ọ̀rọ̀ èdè Árámáíkì ti wọnú èdè Hébérù, òun sì ni èdè tí Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń sọ.—Jẹ 14:13; Ẹk 5:3; Iṣe 26:14.
Hédíìsì.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó ní ìtúmọ̀ kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Ṣìọ́ọ̀lù.” A máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “Isà Òkú” (tí a fi lẹ́tà ńlá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀) láti jẹ́ kó dá yàtọ̀ sí ibojì aráyé.—Wo ISÀ ÒKÚ.
Hẹ́mísì.
Òrìṣà àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì, ó jẹ́ ọmọ òrìṣà Súúsì. Ní ìlú Lísírà, wọ́n ṣèèṣì pe Pọ́ọ̀lù ní òrìṣà Hẹ́mísì, torí wọ́n gbà pé Hẹ́mísì jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn òrìṣà yòókù àti pé òun ni òrìṣà tí ọ̀rọ̀ dá ṣáká lẹ́nu rẹ̀.—Iṣe 14:12.
Hẹ́rọ́dù.
Orúkọ ìdílé tó ń jọba lórí àwọn Júù, ìjọba Róòmù ló sì máa ń yàn wọ́n sípò. Hẹ́rọ́dù Ńlá gbajúmọ̀ torí òun ló tún tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù kọ́, òun ló sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ọmọ ọwọ́ kí ó lè pa Jésù. (Mt 2:16; Lk 1:5) Wọ́n yan Hẹ́rọ́dù Ákíláọ́sì àti Hẹ́rọ́dù Áńtípà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hẹ́rọ́dù Ńlá, láti jọba lórí àwọn apá kan lára ilẹ̀ tí bàbá wọn ń ṣàkóso. (Mt 2:22) Áńtípà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́rin tó ń ṣàkóso, wọ́n sábà máa ń pè é ní “ọba,” òun ló wà lórí oyè lásìkò tí Kristi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ títí di àkókò tí ìwé Ìṣe orí 12 mẹ́nu kàn. (Mk 6:14-17; Lk 3:1, 19, 20; 13:31, 32; 23:6-15; Iṣe 4:27; 13:1) Lẹ́yìn ìyẹn, áńgẹ́lì Ọlọ́run pa Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní lẹ́yìn tó ti ṣàkóso fúngbà díẹ̀, òun ni ọmọ ọmọ Hẹ́rọ́dù Ńlá. (Iṣe 12:1-6, 18-23) Ọmọ rẹ̀ Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kejì ló di alákòóso lẹ́yìn rẹ̀, ó sì ṣàkóso títí di ìgbà tí àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí Róòmù.—Iṣe 23:35; 25:13, 22-27; 26:1, 2, 19-32.
Hẹ́rọ́dù, àwọn ọmọ ẹgbẹ́.
Wọ́n tún mọ̀ wọ́n sí àwọn alátìlẹyìn Hẹ́rọ́dù. Wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣètìlẹ́yìn fún orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n fara mọ́ èrò àwọn Hẹ́rọ́dù tó ń ṣàkóso lábẹ́ ìjọba Róòmù. Ó ṣeé ṣe kí lára àwọn Sadusí wà nínú ẹgbẹ́ yìí. Àwọn alátìlẹ́yìn Hẹ́rọ́dù dara pọ̀ mọ́ àwọn Farisí láti ta ko Jésù.—Mk 3:6.
Hígáíónì.
Ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń lò fún dídarí orin. Bí wọ́n ṣe lò ó nínú Sáàmù 9:16, ó lè tọ́ka sí ohùn háàpù tó ń múni ronú jinlẹ̀, tó ń tuni lára tàbí tó lè jẹ́ kéèyàn fara balẹ̀ ṣàṣàrò.
Hínì.
Ìdíwọ̀n nǹkan olómi àti ohun èlò tí wọ́n fi ń wọ̀n ọ́n. Ó dọ́gba pẹ̀lú Lítà 3.67, bí òpìtàn Josephus ṣe sọ, hínì kan dọ́gba pẹ̀lú ìwọ̀n méjì Athenian choe. (Ẹk 29:40)—Wo Àfikún B14.
Hísópù.
Ewéko kan tó máa ń ní ẹ̀ka àti ewé tó rẹwà, tí wọ́n fi ń wọ́n ẹ̀jẹ̀ tàbí omi nígbà ìwẹ̀mọ́. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti ti Hébérù tí wọ́n lò fún un nínú Bíbélì lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi ewéko. “Hísópù” tí Jòhánù 19:29 mẹ́nu bà ṣeé ṣe kó jẹ́ oríṣi kan tó máa ń ga, ó lè ga débi pé ó máa gùn tó láti gbé kànrìnkàn tí wọ́n rì bọnú wáìnì kíkan dé ẹnu Jésù.—Ẹk 12:22; Sm 51:7.
Hómérì.
Ìdíwọ̀n nǹkan gbígbẹ, ó dọ́gba pẹ̀lú òṣùwọ̀n kọ́ọ̀. Tí a bá fi òṣùwọ̀n báàtì wọ̀n ọ́n, ó jẹ́ Lítà 220. (Le 27:16)—Wo Àfikún B14.
Hórébù; Òkè Hórébù.
I
Ìbẹ́mìílò.
Ìgbàgbọ́ tí àwọn kan ní pé tí èèyàn bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ kì í kú àti pé wọ́n lè bá àwọn tó ṣì wà láàyè sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀, pàápàá nípasẹ̀ ẹnì kan (tàbí ohun kan) tó wà lábẹ́ ìdarí wọn. Ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ìbẹ́mìílò” ni phar·ma·kiʹa lédè Gíríìkì, ó túmọ̀ sí “lílo oògùn olóró.” Ohun tó mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀rọ̀ yìí fún bíbá ẹ̀mí lò ni pé, láyé àtijọ́ àwọn oníṣẹ́ oṣó máa ń lo oògùn olóró tí wọ́n bá fẹ́ rán àwọn ẹ̀mí èṣù níṣẹ́.—Ga 5:20; Ifi 21:8.
Ibi gíga.
Ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.
Ibi Mímọ́.
Ibi téèyàn máa kọ́kọ́ kàn nínú àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ sì tóbi, ó yàtọ̀ sí Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó jẹ́ yàrá inú lọ́hùn-ún. Àwọn ohun tó wà ní Ibi Mímọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn ni ọ̀pá fìtílà wúrà, pẹpẹ tùràrí wúrà, tábìlì búrẹ́dì àfihàn àti àwọn nǹkan èlò wúrà. Àwọn ohun tó wà ní Ibi Mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì ni pẹpẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe, ọ̀pá fìtílà mẹ́wàá tí wọ́n fi wúrà ṣe àti tábìlì búrẹ́dì àfihàn mẹ́wàá. (Ẹk 26:33; Heb 9:2)—Wo Àfikún B5 àti B8.
Ibi Mímọ́ Jù Lọ.
Yàrá inú lọ́hùn-ún nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú sí; wọ́n tún máa ń pe ibẹ̀ ní Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́. Nínú Òfin Mósè, ẹnì kan ṣoṣo tó lè wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni àlùfáà àgbà, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ní Ọjọ́ Ètùtù ló sì lè wọ ibẹ̀.—Ẹk 26:33; Le 16:2, 17; 1Ọb 6:16; Heb 9:3.
Ibi mímọ́; Ibi ìjọsìn.
Ó sábà máa ń jẹ́ ibi tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn, ibi tó jẹ́ mímọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń tọ́ka sí àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n tún máa ń lò ó láti tọ́ka sí ọ̀run níbi tí Ọlọ́run ń gbé.—Ẹk 25:8, 9; 2Ọb 10:25; 1Kr 28:10; Ifi 11:19.
Ibojì ìrántí.
Ibi tí wọ́n máa ń sin òkú sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà mne·meiʹon túmọ̀ sí ibojì ìrántí, ó wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe náà “láti rántí,” èyí fi hàn pé a ò gbàgbé ẹni tó ti kú náà.—Jo 5:28, 29.
Ìbòrí ìpẹ̀tù.
Èyí ni ìbòrí àpótí májẹ̀mú, iwájú ìbòrí náà ni àlùfáà àgbà ti máa ń wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù. Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan lédè Hébérù tó túmọ̀ sí “láti bo (ẹ̀ṣẹ̀) mọ́lẹ̀” tàbí “láti nu (ẹ̀ṣẹ̀) kúrò.” Ògidì wúrà ni wọ́n fi ṣe ìbòrí ìpẹ̀tù, kérúbù méjì sì wà lórí rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìkángun kọ̀ọ̀kan. Nígbà míì, wọ́n máa ń pè é ní “ìbòrí náà.” (Ẹk 25:17-22; 1Kr 28:11; Heb 9:5)—Wo Àfikún B5.
Ìbú àtẹ́lẹwọ́.
Ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà díwọ̀n bí nǹkan kan ṣe gùn tó, ó sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ láti orí àtàǹpàkò dé orí ọmọ ìka tó kéré jù téèyàn bá yàka. Tí a bá fi wé ìgbọ̀nwọ́ tí gígùn rẹ̀ jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5), ìbú àtẹ́lẹwọ́ máa jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). (Ẹk 28:16; 1Sa 17:4)—Wo Àfikún B14.
Ìbúra.
Téèyàn bá búra, ṣe ló ń fọwọ́ sọ̀yà pé òótọ́ lòun sọ, ó sì lè jẹ́ pé ṣe lẹni náà ń ṣèlérí pé òun máa ṣe ohun kan tàbí òun ò ní ṣe é. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Ọlọ́run tàbí fún ẹni tó juni lọ. Jèhófà búra fún Ábúráhámù kó lè dá a lójú pé májẹ̀mú tí òun dá pẹ̀lú rẹ̀ máa ṣẹ.—Jẹ 14:22; Heb 6:16, 17.
Ìdádọ̀dọ́.
Ìdá mẹ́wàá (ìpín kan nínú mẹ́wàá).
Ìdá mẹ́wàá ohun téèyàn ní tó sì san tàbí tó fúnni, ó sì sábà máa ń jẹ́ láti fi bójú tó ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn. A máa ń sọ pé ẹni tó mú un wá san “ìdá mẹ́wàá.” (Mal 3:10; Di 26:12; Mt 23:23) Lábẹ́ Òfin Mósè, ọdọọdún ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fún àwọn ọmọ Léfì ní ìdá mẹ́wàá irè oko àti ìdá mẹ́wàá ohun tó lé lórí ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran kí wọ́n lè fi ti àwọn ọmọ Léfì lẹ́yìn. Àwọn ọmọ Léfì náà sì máa ń fún àwọn ọmọ Áárónì tó jẹ́ àlùfáà ní ìdá mẹ́wàá ohun tí wọ́n gbà kí wọ́n lè fi tì wọ́n lẹ́yìn. Àwọn ìdá mẹ́wàá míì wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń san. Ìdá mẹ́wàá ò pọn dandan fáwọn Kristẹni.
Ìdógò; Ìdúró.
Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.
Ìfọkànsin Ọlọ́run.
Igi ìmọ̀ rere àti búburú.
Igi ìyè.
Igi olófì.
Igi tí wọ́n fi ń hun fọ́nrán òwú títí á fi di aṣọ.—Ẹk 39:27.
Ìgbèkùn.
Ó túmọ̀ sí pé kí wọ́n lé ẹnì kan kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ tàbí ní ilé rẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó bá ṣẹ́gun ìlú kan ló máa ń pàṣẹ náà. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí ìgbèkùn túmọ̀ sí “lílọ kúrò.” Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn. Àwọn ará Ásíríà kó ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá lọ sí ìgbèkùn, àwọn ará Bábílónì náà sì kó ẹ̀yà méjì tó wà ní gúúsù lọ sí ìgbèkùn. Àmọ́ nígbà ìjọba Kírúsì ọba ilẹ̀ Páṣíà, wọ́n dá àwọn tó wà nígbèkùn pa dà sí ilẹ̀ wọn.—2Ọb 17:6; 24:16; Ẹsr 6:21.
Ìgbọ̀nwọ́.
Ìwọ̀n kan tí gígùn rẹ̀ tó ìgúnpá sí orí ìka àárín ọwọ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sábà máa ń lo ìgbọ̀nwọ́ tó jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ìyẹn ínǹṣì 17.5), àmọ́ wọ́n tún máa ń lo ìgbọ̀nwọ́ gígùn tó fi ìbú ọwọ́ kan jù ú lọ, tó jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 51.8 (ìyẹn ínǹṣì 20.4). (Jẹ 6:15; Lk 12:25)—Wo Àfikún B14.
Ìhámọ́ra.
Ohun táwọn ọmọ ogun máa ń wọ̀ láti dáàbò bo ara wọn. Irú bí akoto, ẹ̀wù irin, àmùrè, kóbìtà àti apata.—1Sa 31:9; Ef 6:13-17.
Ìhìn rere.
Ìjókòó ìdájọ́.
Ó sábà máa ń jẹ́ pèpéle kan tó wà níta, ó máa ń ní àtẹ̀gùn, orí rẹ̀ ni àwọn aláṣẹ máa ń jókòó sí láti bá àwọn èrò sọ̀rọ̀, ibẹ̀ ni wọ́n á sì ti kéde ìpinnu wọn. Gbólóhùn náà “ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run” àti “ìjókòó ìdájọ́ Kristi” jẹ́ àpẹẹrẹ ètò tí Jèhófà ṣe láti ṣèdájọ́ aráyé.—Ro 14:10; 2Kọ 5:10; Jo 19:13.
Ìjọ.
Ìjọba Ọlọ́run.
Ìkóná.
Ohun èlò tí wọ́n fi wúrà, fàdákà tàbí bàbà ṣe, tí wọ́n máa ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì láti fi sun tùràrí, wọ́n tún ń lò ó láti yọ ẹyin iná nínú pẹpẹ àti láti yọ òwú tó ti jóná kúrò nínú ọ̀pá fìtílà. Wọ́n tún máa ń pè é ní àwo tùràrí.—Ẹk 37:23; 2Kr 26:19; Heb 9:4.
Ìléru.
Ílíríkónì.
Ìpínlẹ̀ kan lábẹ́ ìjọba Róòmù tó wà ní àríwá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Gíríìsì. Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò dé agbègbè yìí nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ Bíbélì ò sọ bóyá ó wàásù ní Ílíríkónì tàbí ó kàn débẹ̀ ni. (Ro 15:19)—Wo Àfikún B13.
Ìlú ààbò.
Ìlú àwọn ọmọ Léfì tí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn lè sá lọ kí agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á. Jèhófà ní kí Mósè yan ìlú mẹ́fà káàkiri Ilẹ̀ Ìlérí tó máa jẹ́ ìlú ààbò, nígbà tó yá, Jóṣúà tẹ̀ lé ìtọ́ni náà. Tí ẹni tó sá wá náà bá dé ẹnubodè ìlú yìí, á ro ẹjọ́ níwájú àwọn àgbààgbà ìlú náà, wọ́n á sì gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Kí àwọn èèyàn má bàa ṣi àǹfààní yìí lò láti máa mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, wọ́n máa dá ẹni tó bá sá wá sí ìlú ààbò pa dà síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó jẹ̀bi tàbí kò jẹ̀bi. Tí wọ́n bá dá a láre, wọ́n máa dá a pa dà sí ìlú ààbò náà, kò sì gbọ́dọ̀ kúrò níbẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ayé rẹ̀ àfi tí àlùfáà àgbà bá kú.—Nọ 35:6, 11-15, 22-29; Joṣ 20:2-8.
Ìlú Dáfídì.
Orúkọ yìí ni wọ́n ń pe ìlú Jébúsì lẹ́yìn tí Dáfídì ṣẹ́gun ìlú náà, tó sì kọ́ ààfin rẹ̀ síbẹ̀. Wọ́n tún máa ń pè é ní Síónì. Òun ni apá gúúsù ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù, òun náà sì ni ibi tó ti pẹ́ jù lọ lára rẹ̀.—2Sa 5:7; 1Kr 11:4, 5.
Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.
Ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí ń gbé jáde ni ohun tó dára tó sì wuni. Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti tọ́ka sí ẹ̀bùn àtọkànwá tàbí ọ̀nà onínúure tẹ́nì kan gbà fúnni lẹ́bùn. Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, ó máa ń tọ́ka sí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run fínnúfíndọ̀ fúnni láìretí àtigba ohunkóhun pa dà. Ó máa ń jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run lawọ́ gan-an, ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ń fi inúure hàn sáwa èèyàn. Wọ́n tún máa ń tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí sí “ojú rere” àti “ẹ̀bùn àtọkànwá.” Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ló máa ń jẹ́ kẹ́nì kan fúnni lẹ́bùn yìí, kì í ṣe pé ẹni tí wọ́n fún náà ṣiṣẹ́ fún un tàbí pé ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i.—2Kọ 6:1; Ef 1:7.
Ìpalẹ̀mọ́.
Ìpaná.
Ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó ṣeé ṣe kó fara jọ ẹ̀mú, wọ́n máa ń lò ó nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì láti pa iná orí fìtílà.—Ẹk 37:23.
Ìparí ètò àwọn nǹkan.
Ó túmọ̀ sí àkókò tó máa ṣáájú òpin ètò àwọn nǹkan tàbí òpin àwọn nǹkan tí Sátánì ń darí. Àkókò yẹn náà ni ìgbà tí Kristi máa wà níhìn-ín. Lábẹ́ ìdarí Jésù, àwọn áńgẹ́lì máa “ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn olódodo,” wọ́n á sì pa wọ́n run. (Mt 13:40-42, 49) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ mọ àkókò pàtó tí “ìparí” yẹn máa wáyé. (Mt 24:3) Kí Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa wà pẹ̀lú wọn títí di àkókò yẹn.—Mt 28:20.
Ìpẹ̀tù.
—Wo ÈTÙTÙ.
Ìpẹ̀yìndà.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún ìp̣ẹ̀yìndà ni a·po·sta·siʹa, èyí tó wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ ní tààràtà sí “láti dúró sọ́tọ̀.” Àmọ́ ọ̀rọ̀ orúkọ tó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí jẹ́ ká rí i pé ó tún lè túmọ̀ sí “yapa kúrò, fi sílẹ̀ tàbí ṣọ̀tẹ̀.” Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà “ìpẹ̀yìndà” fún àwọn tó ya kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́.—Owe 11:9; Iṣe 21:21; 2Tẹ 2:3.
Ìpọ́njú ńlá.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún “ìpọ́njú” túmọ̀ sí ìdààmú tàbí ìyà tí ipò tí kò bára dé ń fà. Jésù sọ nípa “ìpọ́njú ńlá” tí kò sírú rẹ̀ rí tó máa dé bá Jerúsálẹ́mù, ó sì tún sọ nípa ìpọ́njú ńlá míì tó máa dé bá gbogbo aráyé lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Jésù bá ń ‘bọ̀ pẹ̀lú ògo.’ (Mt 24:21, 29-31) Pọ́ọ̀lù sọ pé ìpọ́njú yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó tọ́ tí Ọlọ́run máa gbé láti rẹ́yìn “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa.” Ìfihàn orí 19 fi hàn pé Jésù ló máa ṣáájú àwọn ọmọ ogun ọ̀run láti gbéjà ko “ẹranko náà àti àwọn ọba ayé pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn.” (2Tẹ 1:6-8; Ifi 19:11-21) Bíbélì tún fi hàn pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” máa la ìpọ́njú náà já. (Ifi 7:9, 14)—Wo AMÁGẸ́DỌ́NÌ.
Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·aʹko·nos tí a sábà máa ń túmọ̀ sí “òjíṣẹ́” tàbí “ìránṣẹ́.” “Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́” ni àwọn tó ń ran ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lọ́wọ́ nínú ìjọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ dójú ìlà ohun tí Bíbélì béèrè kí wọ́n tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ yìí.—1Ti 3:8-10, 12.
Ìràpadà.
Ohun tí a san láti gbani sílẹ̀ lóko ẹrú, lọ́wọ́ ìyà, ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ojúṣe kan. Nígbà míì, ohun tí a san lè má jẹ́ owó. (Ais 43:3) Onírúurú nǹkan ló lè gba pé ká san ìràpadà. Bí àpẹẹrẹ, ti Jèhófà ni gbogbo àkọ́bí ọkùnrin tàbí àkọ́bí ẹranko, torí náà ó ní iye owó tí wọ́n gbọ́dọ̀ san láti rà wọ́n pa dà kúrò nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tó yẹ kí wọ́n lò wọ́n fún tàbí tó yẹ kí wọ́n máa ṣe. (Nọ 3:45, 46; 18:15, 16) Tí akọ màlúù tí wọn ò bójú tó tàbí tó burú bá pa ẹnì kan, ẹni tó ni ín máa san ìràpadà kí wọ́n má bàa pa òun fúnra rẹ̀ bí òfin ṣe sọ. (Ẹk 21:29, 30) Àmọ́, kò sí ìràpadà fún ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn. (Nọ 35:31) Ìràpadà tó ṣe pàtàkì jù tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni èyí tí Kristi san, nígbà tó kú ikú ìrúbọ kó lè ra àwọn èèyàn onígbọràn pa dà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Sm 49:7, 8; Mt 20:28; Ef 1:7.
Ìràwọ̀ ojúmọ́.
Ìtumọ̀ kan náà ló ní pẹ̀lú “ìràwọ̀ òwúrọ̀.” Òun ni ìràwọ̀ tó máa ń yọ gbẹ̀yìn lójú ọ̀run lápá ìlà oòrùn kí oòrùn tó yọ, ó máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ilẹ̀ ti fẹ́ mọ́.—Ifi 22:16; 2Pe 1:19.
Ìràwọ̀ òwúrọ̀.
—Wo ÌRÀWỌ̀ OJÚMỌ́.
Ìrékọjá.
Àjọyọ̀ kan tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ábíbù (tí wọ́n pè ní Nísàn nígbà tó yá). Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe é láti ṣàjọyọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn nídè lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé wọ́n á pa ọ̀dọ́ àgùntàn (tàbí ewúrẹ́) kan, wọ́n á yan án, wọ́n á sì jẹ ẹ́ pẹ̀lú ewébẹ̀ kíkorò àti búrẹ́dì aláìwú.—Ẹk 12:27; Jo 6:4; 1Kọ 5:7.
Ìrìbọmi; Batisí.
Ìrònúpìwàdà.
Ìṣákọ́lẹ̀.
Isà Òkú; Sàréè.
Ìṣekúṣe.
Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà por·neiʹa, tí Ìwé Mímọ́ lò fún onírúurú ìbálòpọ̀ tí Ọlọ́run kórìíra. Lára ẹ̀ ni àgbèrè, ṣíṣe aṣẹ́wó, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú ìwé Ìfihàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìsìn èké pé ó jẹ́ aṣẹ́wó, ó sì pè é ní “Bábílónì Ńlá” torí pé ó ń bá àwọn aláṣẹ ayé da nǹkan pọ̀ kó lè ní agbára àtàwọn nǹkan tara tó pọ̀. (Ifi 14:8; 17:2; 18:3; Mt 5:32; Iṣe 15:29; Ga 5:19)—Wo AṢẸ́WÓ.
Iṣẹ́ ìsìn mímọ́.
Iṣẹ́ ìyanu; Iṣẹ́ agbára.
Ísírẹ́lì.
Orúkọ tí Ọlọ́run fún Jékọ́bù. Nígbà tó yá, wọ́n ń fi orúkọ yìí pe gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Wọ́n sábà máa ń pe àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọkùnrin méjìlá tí Jékọ́bù bí ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ilé Ísírẹ́lì tàbí àwọn èèyàn (ọkùnrin) Ísírẹ́lì. Àwọn míì tí wọ́n tún ń pè ní Ísírẹ́lì ni ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà ní àríwá tó yapa kúrò lára àwọn tó wà ní gúúsù. Nígbà tó yá, Bíbélì pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Ga 6:16; Jẹ 32:28; 2Sa 7:23; Ro 9:6.
Ìtọrẹ àánú.
Ẹ̀bùn tí wọ́n fún ẹni tí kò ní lọ́wọ́. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ò mẹ́nu bà á ní tààràtà, àmọ́ Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ àwọn ohun pàtó tí wọ́n á máa ṣe fún àwọn òtòṣì.—Mt 6:2.
Ìwà àìnítìjú.
Ìwé awọ.
Èyí ni awọ tí wọ́n máa ń kọ̀wé sí, wọ́n lè fi awọ àgùntàn, ti ewúrẹ́ tàbí ti ọmọ màlúù ṣe é. Kì í tètè bà jẹ́ bí òrépèté, òun sì ni wọ́n fi ṣe àwọn àkájọ ìwé Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá kan Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni ìwé awọ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé kí Tímótì bá òun mú wá. Awọ ni wọ́n fi ṣe àwọn kan nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú.—2Ti 4:13.
Ìwé Mímọ́.
Ìwẹ̀fà.
Ní tààrà, ó túmọ̀ sí ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá. Wọ́n sábà máa ń fi àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe ìránṣẹ́ ní ààfin tàbí kí wọ́n máa tọ́jú àwọn ayaba àti àwọn wáhàrì ọba. Ọ̀rọ̀ yìí tún máa ń tọ́ka sí ọkùnrin tí wọn ò tẹ̀ lọ́dàá àmọ́ tó jẹ́ ìjòyè tó ń ṣiṣẹ́ láàfin ọba. Ó tún láwọn tí à ń pè ní ‘ìwẹ̀fà nítorí Ìjọba Ọlọ́run,’ ìyẹn ẹni tó fi nǹkan du ara rẹ̀ kó bàa lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.—Mt 19:12; Ẹst 2:15; Iṣe 8:27.
Ìwo.
Ìwo pẹpẹ.
Iwọ.
Nínú Bíbélì, onírúurú igi tó korò gan-an, tí òórùn rẹ̀ sì kan. Bíbélì lo iwọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti ṣàlàyé àbájáde búburú tó máa ń gbẹ̀yìn ìṣekúṣe, ìsìnrú, ìwà ìrẹ́jẹ àti ìpẹ̀yìndà. Nínú Ìfihàn 8:11, “iwọ” ṣàpẹẹrẹ májèlé kan tó korò, tí wọ́n tún ń pè ní absinthe.—Di 29:18; Owe 5:4; Jer 9:15; Emọ 5:7.
Ìwúkàrà.
Èròjà kan tí wọ́n máa ń fi sínú ìyẹ̀fun tí wọ́n pò láti mú kó wú tàbí tí wọ́n ń fi sí nǹkan olómi kó lè kan; pàápàá èyí tí wọ́n bù pa mọ́ lára ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò pọ̀ tó sì ti wú. Bíbélì sábà máa ń lò ó láti ṣàpẹẹrẹ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ohun tó ti bà jẹ́, ó sì tún máa ń lò ó láti ṣàpẹẹrẹ bí nǹkan ṣe ń gbèrú lọ́nà téèyàn ò lè tètè kíyè sí.—Ẹk 12:20; Mt 13:33; Ga 5:9.
Ìyàngbò.
Ìyàsímímọ́, àmì mímọ́.
Ìyọnu.
Iyùn.
Ohun ọ̀ṣọ́ kan tó le lọ́wọ́. Egungun àwọn ẹran kéékèèké inú omi tó ti kú ló máa ń di iyùn. Inú òkun ni wọ́n ti máa ń rí i, ó sì máa ń ní oríṣiríṣi àwọ̀ bí àwọ̀ pupa, funfun àti dúdú. Iyùn pọ̀ gan-an nínú Òkun Pupa. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, iyùn pupa níye lórí gan-an, wọ́n sì máa ń fi ṣe ìlẹ̀kẹ̀ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì.—Owe 8:11.
J
Jédútúnì.
Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere, ó fara hàn nínú àkọlé Sáàmù 39, 62 àti 77. Ó jọ pé ńṣe ni wọ́n lo àkọlé yìí láti fún àwọn tó máa kọ orin inú sáàmù náà ní ìtọ́ni, bóyá ṣe ló ń sọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà kọ ọ́ tàbí irú ohun ìkọrin tí wọ́n máa lò. Ọmọ Léfì kan wà tó jẹ́ akọrin, Jédútúnì lorúkọ rẹ̀, torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ ni àwọn èèyàn mọ̀ pé ó máa ń kọrin lọ́nà yìí tàbí tó máa ń lo ohun ìkọrin yìí.
Jèhófà.
Jékọ́bù.
Ọmọ Ísákì àti Rèbékà. Nígbà tó yá, Ọlọ́run yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ísírẹ́lì, ó sì di baba ńlá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì (tàbí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n wá ń pè ní àwọn Júù). Ó bí ọmọkùnrin méjìlá, àwọn ọmọ yìí àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn ló wá di ẹ̀yà méjìlá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Wọ́n sì máa ń pe orílẹ̀-èdè náà tàbí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Jékọ́bù.—Jẹ 32:28; Mt 22:32.
Júbílì.
Àádọ́ta (50) ọdún síra ni wọ́n máa ń ṣe é, látìgbà tí Ísírẹ́lì ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Wọn ò ní dáko rárá lọ́dún yẹn, wọ́n á sì dá àwọn Hébérù tó jẹ́ ẹrú sílẹ̀ lómìnira. Wọ́n á dá gbogbo ilẹ̀ àjogúnbá tí wọ́n rà pa dà fún ẹni tó ni ín. Lọ́rọ̀ kan, ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń ṣe àjọyọ̀ ní ọdún Júbílì, ó jẹ́ ọdún òmìnira, tí orílẹ̀-èdè náà máa pa dà sí bó ṣe rí nígbà tí Ọlọ́run dá a sílẹ̀.—Le 25:10.
Júdà.
Ọmọ kẹrin tí Líà ìyàwó Jékọ́bù bí fún un. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jékọ́bù kú, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé alákòóso ńlá kan tí ìjọba rẹ̀ kò ní lópin máa wá láti ìlà ìdílé Júdà. Ìlà ìdílé yìí sì ni Jésù ti wá. Júdà tún ń tọ́ka sí ẹ̀yà kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n wá ń pe ìjọba ẹ̀yà méjì tó wà ní gúúsù ní Júdà. Ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjì tó para pọ̀ di ìjọba gúúsù ni Júdà àti Bẹ́ńjámínì, àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì sì wà lára wọn. Júdà ló wà ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè náà, ibẹ̀ sì ni ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì wà.—Jẹ 29:35; 49:10; 1Ọb 4:20; Heb 7:14.
Júù.
Orúkọ tí wọ́n ń pe ẹni tó wá láti ẹ̀yà Júdà lẹ́yìn tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ṣubú. (2Ọb 16:6) Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tó pa dà dé láti ìgbèkùn Bábílónì ní orúkọ yìí. (Ẹsr 4:12) Nígbà tó yá, kárí ayé ni wọ́n ti ń pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Júù, kí wọ́n lè fìyàtọ̀ sáàárín àwọn àtàwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ Kèfèrí. (Ẹst 3:6) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà àpèjúwe láti mú káwọn èèyàn rí i pé orílẹ̀-èdè téèyàn ti wá kọ́ ló ṣe pàtàkì nínú ìjọ Kristẹni.—Ro 2:28, 29; Ga 3:28.
K
Káàbù.
Òṣùwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn nǹkan gbígbẹ. Ó jẹ́ Lítà 1.22, orí òṣùwọ̀n báàtì ni wọ́n gbé e kà. (2Ọb 6:25)—Wo Àfikún B14.
Kàkàkí.
Ohun èlò kan tí wọ́n ń fọn, irin ni wọ́n fi ń ṣe é. Wọ́n máa ń fi kọrin tàbí kí wọ́n fi ṣe ìkéde. Nínú Nọ́ńbà 10:2, Jèhófà sọ fún Mósè pé kó fi fàdákà ṣe kàkàkí méjì tí wọ́n á máa lò fún onírúurú ìkéde. Wọ́n máa ń fi pe àwọn èèyàn náà jọ, wọ́n fi ń kéde pé káwọn èèyàn ṣí kúrò ní ibùdó tàbí kí wọ́n fi kéde ogun. Ó ṣeé ṣe káwọn kàkàkí yìí rí gbọọrọ, kó sì yàtọ̀ sáwọn “ìwo” ẹran tó rí kọdọrọ tí wọ́n máa ń fọn. Àwọn kàkàkí míì tí Bíbélì ò sọ bó ṣe rí tún wà lára àwọn ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. Ìró kàkàkí sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ìkéde ìdájọ́ Jèhófà tàbí àwọn ohun pàtàkì míì tí Jèhófà fẹ́ ṣe.—2Kr 29:26; Ẹsr 3:10; 1Kọ 15:52; Ifi 8:7–11:15.
Kálídíà; Àwọn ará Kálídíà.
Ní ìbẹ̀rẹ̀, ó tọ́ka sí ilẹ̀ àtàwọn èèyàn tó wà ní agbègbè tí odò Tígírísì àti Yúfírétì ti wọnú òkun; nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀rọ̀ náà fún ilẹ̀ Babilóníà àti àwọn èèyàn ibẹ̀. Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ará Kálídíà” láti tọ́ka sí àwọn tó kàwé láwùjọ, tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa sáyẹ́ǹsì, ìtàn, èdè, ojú ọ̀run àti ìràwọ̀, àmọ́ tí wọ́n jẹ́ awòràwọ̀ àti pidánpidán.—Ẹsr 5:12; Da 4:7; Iṣe 7:4.
Kànnàkànnà.
Okùn tí wọ́n fi awọ ṣe, ó sì lè jẹ́ fọ́nrán iṣan ẹranko, koríko tàbí irun tí a hun pọ̀ mọ́ra. Ó máa ń fẹ̀ ní àárín, ibẹ̀ sì ni wọ́n máa ń fi ohun tí wọ́n bá fẹ́ jù sí, ó sábà máa ń jẹ́ òkúta. Wọ́n máa so apá kan kànnàkànnà náà mọ́ ọwọ́ tàbí ọrùn ọwọ́, wọ́n á sì di apá kejì mú. Tí wọ́n bá ti fi kànnàkànnà náà, wọ́n á sọ apá tí wọ́n dì mú sílẹ̀, kí òkúta náà lè fò jáde. Láyé àtijọ́, àwọn orílẹ̀-èdè máa ń ní àwọn tó ń lo kànnàkànnà nínú ẹgbẹ́ ológun wọn.—Ond 20:16; 1Sa 17:50.
Kaṣíà.
Kèké.
Òkúta tàbí igi kéékèèké tí wọ́n máa ń lò tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu. Wọ́n máa ń kó o sínú etí aṣọ tàbí kí wọ́n kó o sínú ohun kan, wọ́n á sì mì í. Èyí tó bá já bọ́ tàbí tí wọ́n fà yọ ni wọ́n máa lò. Wọ́n sábà máa ń gbàdúrà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe é. Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “kèké” ní tààràtà, wọ́n tún máa ń lò ó lọ́nà àpèjúwe, ó sì máa ń túmọ̀ sí “ìpín.”—Joṣ 14:2; Sm 16:5; Owe 16:33; Mt 27:35.
Kémóṣì.
Olú òrìṣà àwọn ọmọ Móábù.—1Ọb 11:33.
Kénáánì.
Kérúbù.
Àwọn áńgẹ́lì tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n sì wà nípò gíga. Wọ́n yàtọ̀ sí àwọn séráfù.—Jẹ 3:24; Ẹk 25:20; Ais 37:16; Heb 9:5.
Késárì.
Kẹ̀kẹ́ ẹṣin.
Kísíléfì.
Orúkọ tí wọ́n ń pe oṣù kẹsàn-án nínú kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn Bábílónì, òun sì tún ni oṣù kẹta nínú kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù November sí àárín oṣù December. (Ne 1:1; Sek 7:1)—Wo Àfikún B15.
Kọ́ọ̀.
Òṣùwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn nǹkan gbígbẹ àti nǹkan olómi. Ó jẹ́ Lítà 220 (ìyẹn gálọ́ọ̀nù 58.1), tí a bá gbé e lé ìdíwọ̀n òṣùwọ̀n báàtì. (1Ọb 5:11)—Wo Àfikún B14.
Kristẹni.
Orúkọ tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi.—Iṣe 11:26; 26:28.
Kristi.
L
Láwàní.
Aṣọ tí wọ́n fi ń wé orí tàbí èyí tí wọ́n máa ń dé sórí. Àlùfáà àgbà máa ń wé láwàní tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe, wọ́n sì máa ń fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù de irin wúrà pẹlẹbẹ mọ́ iwájú rẹ̀. Àwọn ọba máa ń dé láwàní sábẹ́ adé wọn. Jóòbù lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tó ń fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ wé láwàní.—Ẹk 28:36, 37; Job 29:14; Isk 21:26.
Léfíátánì.
Ẹran kan tí wọ́n gbà pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹran inú omi. Ohun tí Jóòbù 3:8 àti 41:1 sọ nípa rẹ̀ fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀nì tàbí oríṣi ẹran omi kan tó tóbi gan-an tó sì lágbára. Bí Sáàmù 104:26 ṣe sọ, ó jọ pé oríṣi ẹja àbùùbùtán kan ni. Láwọn ibòmíì, ńṣe ni wọ́n lò ó lọ́nà àpèjúwe, a ò lè sọ irú ẹran tó jẹ́ ní pàtó.—Sm 74:14; Ais 27:1.
Léfì; Ọmọ Léfì.
Ọmọ kẹta tí Líà bí fún Jékọ́bù. Wọ́n tún ń fi orúkọ yìí pe ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì. Àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí Léfì bí ni wọ́n pilẹ̀ apá pàtàkì mẹ́ta tí àwọn ọmọ Léfì pín sí. Nígbà míì, ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọmọ Léfì” máa ń tọ́ka sí ẹ̀yà náà lápapọ̀, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n kì í ka ìdílé Áárónì tó ń ṣiṣẹ́ àlùfáà mọ́ wọn. Wọn ò pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Léfì ní Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ wọ́n fún wọn ní ìlú méjìdínláàádọ́ta (48) ní ààlà àwọn ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ẹ̀yà tó kù.—Di 10:8; 1Kr 6:1; Heb 7:11.
Lẹ́pítónì.
Ẹyọ owó bàbà tàbí idẹ tó kéré jù lọ táwọn Júù ń ná lásìkò tí wọ́n ń kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Nínú àwọn Bíbélì kan, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “owó idẹ.” (Mk 12:42; Lk 21:2; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé)—Wo Àfikún B14.
Lọ́ọ̀gì.
Òṣùwọ̀n tó kéré jù tí wọ́n fi ń wọn nǹkan olómi tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Nínú ìwé Támọ́dì Àwọn Júù, wọ́n sọ pé ó jẹ́ ìdá kan nínú méjìlá òṣùwọ̀n hínì, torí náà, a lè sọ pé lọ́ọ̀gì kan máa gba nǹkan bí ìlàta Lítà, (Lítà 0.31). (Le 14:10)—Wo Àfikún B14.
M
Máhálátì.
Ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ orin, ó wà nínú àkọlé Sáàmù 53 àti 88. Ó ṣeé ṣe kó tan mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣe kan lédè Hébérù tó túmọ̀ sí “ṣàárẹ̀” tàbí “ṣàìsàn,” torí náà ohùn arò tàbí ti ìbànújẹ́ ni wọ́n máa fi kọ ọ́, èyí á sì bá ọ̀rọ̀ inú sáàmù méjèèjì tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí mu.
Máìlì.
Bí ibì kan ṣe jìnnà tó. Ìgbà kan ṣoṣo ni wọ́n lò ó nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ní Mátíù 5:41, ó sì ṣeé ṣe kó tọ́ka sí máìlì àwọn ará Róòmù tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ mítà (mítà 1,479.5) tàbí ẹsẹ̀ bàtà 4,854. Ibi mẹ́ta míì tí wọ́n ti lo “máìlì” nínú Bíbélì ni Lúùkù 24:13, Jòhánù 6:19 àti Jòhánù 11:18, àmọ́ láwọn ibẹ̀ yẹn, ó ń tọ́ka sí máìlì tí wọ́n yí pa dà látinú ìwọ̀n sítédíọ̀mù àtijọ́ tó wà nínú àwọn ìwé yẹn níbẹ̀rẹ̀.—Wo Àfikún B14.
Májẹ̀mú.
Àdéhùn láàárín Ọlọ́run àti èèyàn tàbí láàárín ẹni méjì láti ṣe ohun kan tàbí láti má ṣe ohun kan. Nígbà míì, ó lè jẹ́ àdéhùn (ìyẹn ìlérí) tí ẹnì kan ṣoṣo ṣe pé òun máa ṣe ohun kan. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ ẹni méjì ló ṣe àdéhùn pé àwọn máa ṣe ohun kan. Yàtọ̀ sí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá èèyàn dá, Bíbélì tún mẹ́nu kan májẹ̀mú láàárín èèyàn, ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè tàbí àwùjọ. Lára àwọn májẹ̀mú tó lágbára tí Bíbélì mẹ́nu kàn ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú Ábúráhámù, Dáfídì, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì (ìyẹn Májẹ̀mú Òfin) àti èyí tó dá pẹ̀lú Ísírẹ́lì Ọlọ́run (ìyẹn májẹ̀mú tuntun).—Jẹ 9:11; 15:18; 21:27; Ẹk 24:7; 2Kr 21:7.
Makedóníà.
Agbègbè kan tó wà ní àríwá ilẹ̀ Gíríìsì, ó lókìkí nígbà ìjọba Alẹkisáńdà Ńlá, kò sì sí lábẹ́ ìjọba kankan títí dìgbà táwọn ará Róòmù ṣẹ́gun rẹ̀. Makedóníà jẹ́ ìpínlẹ̀ kan lábẹ́ ìjọba Róòmù nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ Yúróòpù. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù lọ sí agbègbè yìí. (Iṣe 16:9)—Wo Àfikún B13.
Málíkámù.
Mánà.
Oúnjẹ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ ní gbogbo ogójì (40) ọdún tí wọ́n lò ní aginjù. Jèhófà ló pèsè oúnjẹ yìí. Àràárọ̀ ló máa ń wà lórí ilẹ̀ àyàfi ní ọjọ́ Sábáàtì, ó máa ń sẹ̀ bí ìrì lọ́nà ìyanu. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́kọ́ rí i, wọ́n sọ pé, “Kí nìyí?” tàbí “man huʼ?” lédè Hébérù. (Ẹk 16:13-15, 35) Láwọn ẹsẹ Bíbélì míì, wọ́n pè é ní “ọkà ọ̀run” (Sm 78:24), “oúnjẹ láti ọ̀run” (Sm 105:40) àti “oúnjẹ àwọn alágbára” (Sm 78:25). Jésù tún lo mánà láti fi ṣe àpèjúwe.—Jo 6:49, 50.
Másíkílì.
Ọ̀rọ̀ Hébérù tó wà ní àkọlé sáàmù mẹ́tàlá (13), ìtúmọ̀ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “ewì tó ń múni ronú jinlẹ̀.” Àwọn kan ronú pé ọ̀rọ̀ kan tó jọ ọ́ ni wọ́n túmọ̀ sí, ‘fi ọgbọ́n inú sìn,’ ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó túmọ̀ sí nìyẹn.—2Kr 30:22; Sm 32:Akl.
Méródákì.
Olórí òrìṣà tí wọ́n ń bọ ní ìlú Bábílónì. Lẹ́yìn tí Hammurabi tó jẹ́ ọba àti aṣòfin Bábílónì sọ ìlú Bábílónì di olú ìlú ilẹ̀ Babilóníà, òrìṣà Méródákì (tàbí Mádọ́kì) wá di òrìṣà táwọn èèyàn túbọ̀ kà sí pàtàkì, bó ṣe di pé ó borí gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ ṣáájú rẹ̀ nìyẹn, tó sì di olórí òrìṣà táwọn ará Bábílónì ń bọ. Nígbà tó yá, wọ́n fi orúkọ oyè náà “Belu” (“Oníǹkan”) rọ́pò orúkọ Méródákì (tàbí Mádọ́kì), Bélì ni wọ́n sì sábà máa ń pe Méródákì.—Jer 50:2.
Mèsáyà.
Míkítámù.
Mílíkómù.
Mímọ́; Ìjẹ́mímọ́.
Lájorí ànímọ́ kan tí Jèhófà ní; ó jẹ́ ìwà mímọ́ àti ohun mímọ́ lọ́nà pípé. (Ẹk 28:36; 1Sa 2:2; Owe 9:10; Ais 6:3) Tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ yìí fún èèyàn (Ẹk 19:6; 2Ọb 4:9), ẹranko (Nọ 18:17), nǹkan (Ẹk 28:38; 30:25; Le 27:14), ibì kan (Ẹk 3:5; Ais 27:13), àkókò kan (Ẹk 16:23; Le 25:12) tàbí iṣẹ́ kan (Ẹk 36:4), ní èdè Hébérù, ó túmọ̀ sí ìyàsọ́tọ̀, ìyàsọ́tọ̀ pátápátá tàbí ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run; ìyẹn ni yíya ohun kan sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́” ń tọ́ka sí ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ yìí tún máa ń tọ́ka sí kí ìwà èèyàn jẹ́ mímọ́.—Mk 6:20; 2Kọ 7:1; 1Pe 1:15, 16.
Mínà.
Òun náà ni wọ́n pè ní mánẹ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ó jẹ́ ìwọ̀n bí nǹkan ṣe wúwo tó àti iye owó. Ẹ̀rí látọ̀dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn fi hàn pé mínà kan jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì, ṣékélì kan sì wúwo tó gíráàmù 11.4, mínà tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ wúwo tó gíráàmù ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́rin (570). Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọba náà ní ìwọ̀n mínà tiwọn bó ṣe rí pẹ̀lú ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, mínà kan jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) dírákímà. Ó wúwo tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogójì (340) gíráàmù. Ọgọ́ta (60) mínà ló wà nínú tálẹ́ńtì kan. (Ẹsr 2:69; Lk 19:13)—Wo Àfikún B14.
Mólékì.
Òrìṣà àwọn ọmọ Ámónì; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òun náà ni wọ́n ń pè ní Málíkámù, Mílíkómù àti Mólókù. Ó lè jẹ́ orúkọ oyè dípò orúkọ òrìṣà kan pàtó. Òfin Mósè sọ pé ńṣe ni kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tó bá fi ọmọ rẹ̀ rúbọ sí òrìṣà Mólékì.—Le 20:2; Jer 32:35; Iṣe 7:43.
Mólókù.
—Wo MÓLÉKÌ.
Mọ́ tónítóní.
Muti-lábénì.
Ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n lò nínú àkọlé Sáàmù 9. Ó sábà máa ń túmọ̀ sí “nípa ikú ọmọkùnrin.” Àwọn kan sọ pé ó jẹ́ orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń bẹ̀rẹ̀ orin táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, òun ni wọ́n máa ń lò tí wọ́n bá ń kọ sáàmù yìí lórin.
N
Náádì.
Òróró olóòórùn dídùn tó pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tó sì wọ́n gan-an. Ewéko sípíkénádì (Nardostachys jatamansi) ni wọ́n fi ń ṣe é. Torí pé ó wọ́n gan-an, wọ́n sábà máa ń pò ó mọ́ àwọn òróró míì tí kò dáa tó o, wọ́n sì máa ń ṣe gbàrọgùdù rẹ̀ nígbà míì. Ó gbàfiyèsí pé “ojúlówó náádì” ni Máàkù àti Jòhánù sọ pé wọ́n lò fún Jésù.—Mk 14:3; Jo 12:3.
Násírì.
Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Yàn,” “Ẹni Tí A Yà Sí Mímọ́,” “Ẹni Tí A Yà Sọ́tọ̀.” Oríṣi Násírì méjì ló wà: àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn àtàwọn tí Ọlọ́run yàn. Ọkùnrin tàbí obìnrin kan lè jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà pé òun máa jẹ́ Násírì fáwọn àkókò kan. Òfin mẹ́ta pàtàkì kan wà tí àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn láti jẹ́ Násírì gbọ́dọ̀ pa mọ́: wọn ò gbọ́dọ̀ mu ọtí tàbí jẹ ohunkóhun tí wọ́n bá fi àjàrà ṣe, wọn ò gbọ́dọ̀ gé irun wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú. Àwọn tí Ọlọ́run bá yàn láti jẹ́ Násírì máa wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn, Jèhófà sì sọ àwọn ìlànà tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé.—Nọ 6:2-7; Ond 13:5.
Néfílímù.
Àwọn ọmọkùnrin oníjàgídíjàgan tí àwọn ọmọbìnrin èèyàn bí fáwọn áńgẹ́lì tó fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ayé ṣáájú Ìkún Omi.—Jẹ 6:4.
Néhílótì.
Ọ̀rọ̀ kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ kò ṣe kedere, ó fara hàn nínú àkọlé Sáàmù 5. Àwọn kan gbà pé ohun ìkọrin kan tí wọ́n ń fọn ni, wọ́n ní ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tí wọ́n ń pè ní cha·lilʹ (fèrè). Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orin.
Nétínímù.
Àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ ẹrú tàbí ìránṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí túmọ̀ sí “Àwọn Tí A Fi Fúnni,” tó túmọ̀ sí pé a fi wọ́n fúnni láti máa siṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára àwọn Nétínímù yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbéónì tí Jóṣúà sọ di “aṣẹ́gi àti àwọn tí á máa pọnmi fún àpéjọ náà àti pẹpẹ Jèhófà.”—Joṣ 9:23, 27; 1Kr 9:2; Ẹsr 8:17.
Nísàn.
Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, orúkọ yìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe oṣù Ábíbù tó jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù. Oṣù yìí sì ni oṣù keje lórí kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ní àárín oṣù March, ó sì máa ń parí ní àárín oṣù April. (Ne 2:1)—Wo Àfikún B15.
O
Òdodo.
Òfin Mósè.
Òfin.
Ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà.
Wọ́n máa ń lò ó nínú àgọ́ ìjọsìn àti ní tẹ́ńpìlì. Wúrà tàbí bàbà ni wọ́n fi ṣe é. Ó ṣeé ṣe kó rí bíi sísọ́ọ̀sì tí wọ́n fi ń gé òwú fìtílà.—2Ọb 25:14.
Oje igi tùràrí.
Oje tó ti gbẹ láti ara àwọn oríṣi igi kan tó ń jẹ́ Boswellia. Tí wọ́n bá ń sun oje yìí, ó máa ń ní òórùn dídùn tó ń ta sánsán. Ó wà lára àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe tùràrí tí wọ́n ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì. Wọ́n tún máa ń fi sí ọrẹ ọkà, wọ́n sì máa ń fi sórí ipele kọ̀ọ̀kan búrẹ́dì àfihàn tó wà nínú Ibi Mímọ́.—Ẹk 30:34-36; Le 2:1; 24:7; Mt 2:11.
Òjíá.
Oje igi tó ń ta sánsán tí wọ́n máa ń rí lára onírúurú igi ẹlẹ́gùn-ún tàbí àwọn igi kéékèèké tí wọ́n ń pè ní Commiphora. Òjíá wà lára èròjà tí wọ́n fi ń ṣe òróró àfiyanni mímọ́. Wọ́n máa ń fi sára aṣọ tàbí ibùsùn láti mú kó máa ta sánsán, wọ́n sì tún máa ń fi sínú òróró tí wọ́n fi ń wọ́ra tàbí ìpara. Wọ́n tún máa ń fi sára òkú kí wọ́n tó sin ín.—Ẹk 30:23; Owe 7:17; Jo 19:39.
Òkè Lẹ́bánónì.
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òkè gígùn méjì tó wà nílẹ̀ Lẹ́bánónì. Òkè Lẹ́bánónì àkọ́kọ́ wà ní ìwọ̀ oòrùn, òkè Lẹ́bánónì kejì (ìyẹn, Anti-Lebanon) sì wà ní ìlà oòrùn. Àfonífojì tó wà láàárín àwọn òkè méjèèjì yìí gùn gan-an, ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé etíkun Mẹditaréníà ni òkè Lẹ́bánónì ti jáde, ó sì ga tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (1,800) sí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún kan (2,100) mítà, (ìyẹn, 6,000 sí 7,000 ẹsẹ̀ bàtà). Láyé àtijọ́, àwọn igi kédárì ńláńlá pọ̀ gan-an nílẹ̀ Lẹ́bánónì, igi yìí sì ṣeyebíye gan-an lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí. (Di 1:7; Sm 29:6; 92:12)—Wo Àfikún B7.
Òkìtì.
Òkúta igun ilé.
Òkúta tó máa ń wà ní igun ilé, níbi tí ògiri méjì ti pàdé, ó kó ipa pàtàkì nínú síso ògiri méjèèjì pọ̀. Olórí òkúta igun ilé ni òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé. Òkúta yìí máa ń lágbára gan-an, òun ni wọ́n sì máa ń fi kọ́ àwọn ilé ìjọba àtàwọn odi ìlú. A máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpẹẹrẹ bí a ṣe pilẹ̀ ayé, a sì pe Jésù ní “òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé” ìjọ Kristẹni, tí a fi wé ilé tẹ̀mí.—Ef 2:20; Job 38:6.
Olórí àlùfáà.
Orúkọ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ míì tí wọ́n lò fún “àlùfáà àgbà” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà “àlùfáà àgbà” dúró fún àwọn aṣáájú láàárín àwọn àlùfáà, títí kan àwọn àlùfáà àgbà tí wọ́n ti mú kúrò nípò àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ olórí nínú ìpín mẹ́rìnlélógún (24) àwọn àlùfáà tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì.—2Kr 26:20; Ẹsr 7:5; Mt 2:4; Mk 8:31.
Olórí Aṣojú.
Olú Áńgẹ́lì.
Olùdarí.
Bí wọ́n ṣe lò ó nínú Sáàmù, ó jọ pé ọ̀rọ̀ yìí lédè Hébérù ń tọ́ka sí ẹnì kan tó máa ń ṣètò orin, tó sì máa ń darí bí wọ́n ṣe máa kọ ọ́, ó máa ń kọ́ àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin ní orin, wọ́n á sì jọ fi dánra wò, kódà òun ló máa ń múpò iwájú tí wọ́n bá fẹ́ kọrin nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì pe ẹni yìí ní “olórí akọrin” tàbí “olùdarí orin.”—Sm 4:Akl; 5:Akl.
Olùṣọ́.
Ẹni tó máa ń ṣọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́ ewu tàbí tó ń ṣọ́ àwọn nǹkan ìní. Alẹ́ ni olùṣọ́ sábà máa ń ṣiṣẹ́, ó sì máa ń ké gbàjarè tó bá rí ewu. Lọ́pọ̀ ìgbà, orí ògiri ìlú àti ilé ìṣọ́ làwọn olùṣọ́ máa ń wà kí wọ́n lè rí àwọn tó ń bọ̀ látọ̀ọ́kán kí wọ́n tó sún mọ́ ẹnubodè. Ẹ̀ṣọ́ ni wọ́n sábà máa ń pe ọmọ ogun tó ń ṣe olùṣọ́. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn wòlíì máa ń ṣe olùṣọ́ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kí wọ́n lè kìlọ̀ ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.—2Ọb 9:20; Isk 3:17.
Ómérì.
Òṣùwọ̀n nǹkan gbígbẹ tó lè gba ohun tí ó tó Lítà 2.2, kúọ̀tì méjì ló wà nínú ómérì kan. Ómérì kan jẹ́ ìdá mẹ́wàá eéfà kan. (Ẹk 16:16, 18)—Wo Àfikún B14.
Òmìnira; Ẹni tí a sọ di òmìnira.
Nígbà ìjọba Róòmù, ẹni “òmìnira” ni ẹni tó jẹ́ ọmọ ìlú, tó sì ní gbogbo ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú. “Ẹni tí a sọ di òmìnira” ni ẹni tó jẹ́ ẹrú tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí kì í ṣe ẹrú mọ́. Nígbà ìjọba Róòmù, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ní gbogbo ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú, àmọ́ kò ní lè wà ní ipò kankan nínú ìṣèlú. Ẹrú tí ọ̀gá rẹ̀ bá dá sílẹ̀ máa ní òmìnira, àmọ́ tí ìjọba ò bá tíì fọwọ́ sí i, onítọ̀hún ò ní ní gbogbo ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú.—1Kọ 7:22.
Ónísì.
Òkúta tó níye lórí dé ìwọ̀n àyè kan, ó jẹ́ oríṣi òkúta ágétì tó le tàbí òkúta kásídónì tí wọ́n dìpọ̀. Òkúta yìí ní àwọ̀ funfun, àmọ́ torí ó ń bì, ó tún máa ń mú àwọ̀ míì jáde, bí àwọ̀ dúdú, àwọ̀ tó pọ́n rẹ́súrẹ́sú, àwọ̀ pupa, àwọ̀ eérú àti àwọ̀ ewé. Wọ́n máa ń fi òkúta yìí sára aṣọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí àlùfáà àgbà máa ń wọ̀.—Ẹk 28:9, 12; 1Kr 29:2; Job 28:16.
Òpó igi.
Òpó tó wà lóòró tí wọ́n máa ń de àwọn ọ̀daràn mọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń pa àwọn ọ̀daràn lórí òpó igi, àwọn kan sì máa ń gbé àwọn òkú kọ́ sórí ẹ̀ kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn míì tàbí kí wọ́n lè fi wọ́n ṣẹ̀sín. Òǹrorò làwọn èèyàn mọ àwọn ará Ásíríà sí torí pé wọ́n máa ń gbé àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú kọ́ sórí òpó igi tó ní ẹnu ṣóńṣó, wọ́n máa ń ki igi ṣóńṣó náà bọ ikùn wọn, ó sì máa ń wọlé lọ dé àyà wọn. Àmọ́ nínú òfin àwọn Júù, tí wọ́n bá mú ẹni tó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì irú bíi sísọ̀rọ̀ òdì tàbí ìbọ̀rìṣà, wọ́n á kọ́kọ́ sọ ọ́ ní òkúta pa tàbí kí wọ́n pa á lọ́nà míì, lẹ́yìn náà ni wọ́n á gbé òkú rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn míì. (Di 21:22, 23; 2Sa 21:6, 9) Nígbà míì, àwọn ará Róòmù máa ń so àwọn ọ̀daràn mọ́ òpó igi, ó sì lè gbà tó ọjọ́ mélòó kan kí ìrora, òùngbẹ, ebi àti oòrùn tó pa onítọ̀hún. Láwọn ìgbà míì, wọ́n máa ń fi ìṣó kan ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ẹni náà mọ́ òpó igi, ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà pa Jésù. (Lk 24:20; Jo 19:14-16; 20:25; Iṣe 2:23, 36)—Wo ÒPÓ IGI ORÓ.
Òpó igi oró.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí òpó igi oró ni stau·rosʹ, tó túmọ̀ sí igi tàbí òpó tó wà lóòró, irú èyí tí wọ́n kan Jésù mọ́. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà túmọ̀ sí àgbélébùú, irú èyí táwọn abọ̀rìṣà máa ń lò nínú ìjọsìn wọn lọ́pọ̀ ọdún kí Jésù tó wá sáyé. “Òpó igi oró” ló gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà yọ dáadáa torí pé Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà stau·rosʹ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìdálóró, ìyà àti ìfiniṣẹ̀sín táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa kojú. (Mt 16:24; Heb 12:2)—Wo ÒPÓ IGI.
Òpó òrìṣà.
Ọ̀rọ̀ Hébérù náà (ʼashe·rahʹ) túmọ̀ sí (1) òpó òrìṣà tó ń ṣàpẹẹrẹ Áṣérà, abo òrìṣà ìbímọlémọ ti àwọn ará Kénáánì tàbí (2) ère abo òrìṣà Áṣérà fúnra rẹ̀. Òpó náà máa ń wà lóòró, ó lè jẹ́ igi látòkè délẹ̀ tàbí kí apá kan rẹ̀ jẹ́ igi. Ó lè jẹ́ àwọn òpó tí wọn kò gbẹ́ tàbí kó jẹ́ igi.—Di 16:21; Ond 6:26; 1Ọb 15:13.
Òrépèté.
Koríko kan tó máa ń hù lórí omi, ó jọ esùsú, wọ́n sì máa ń fi ṣe àwọn nǹkan bí apẹ̀rẹ̀, ohun ìkó-nǹkan-sí àti ọkọ̀ ojú omi. Wọ́n tún máa ń fi ṣe ohun tí wọ́n lè kọ nǹkan sí bíi bébà, òun ni wọ́n fi ṣe ọ̀pọ̀ àkájọ ìwé.—Ẹk 2:3.
Orin arò.
Orin Ìgòkè.
Àkọlé tó wà lórí Sáàmù 120 sí 134. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ìtumọ̀ làwọn èèyàn ti fún ọ̀rọ̀ yìí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fìdùnnú kọ àwọn sáàmù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) yìí nígbà tí wọ́n bá ń ‘gòkè’ lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àwọn àjọyọ̀ pàtàkì mẹ́ta tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Orí òkè ni Jerúsálẹ́mù wà ní ilẹ̀ Júdà.
Òrìṣà; Ìbọ̀rìṣà.
Òrìṣà jẹ́ ère tàbí àwòrán ohun gidi kan tàbí ohun téèyàn fọkàn rò, táwọn èèyàn máa ń lò nínú ìjọsìn. Ìbọ̀rìṣà ni kéèyàn máa bọ̀wọ̀ fún òrìṣà, kéèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó máa sìn ín tàbí kó máa fògo fún un.—Sm 115:4; Iṣe 17:16; 1Kọ 10:14.
Òrùka èdìdì.
Oṣó.
Àwọn tó ń lo agbára tí wọ́n gbà pé àwọn ẹ̀mí burúkú máa ń fúnni.—2Kr 33:6.
Òṣùpá tuntun.
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
Búrẹ́dì tí kò ní ìwúkàrà àti wáìnì tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ ara àti ẹ̀jẹ̀ Kristi; òun náà ni ìrántí ikú Jésù. A máa ń pè é ní “Ìrántí Ikú Kristi,” torí pé Ìwé Mímọ́ dìídì pàṣẹ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ṣe é.—1Kọ 11:20, 23-26.
Òwe.
Òwú tó wà lóròó.
Òwú tó máa ń wà lóròó tí wọ́n bá ń hun aṣọ. Àwọn òwú míì wà tí wọ́n máa ń hun mọ́ ọn ní ìbú.—Ond 16:13.
Òwú tó wà ní ìbú.
Òwú tó máa ń wà ní ìbú tí wọ́n bá ń hun aṣọ. Àwọn òwú míì wà tí wọ́n máa ń hun mọ́ ọn lóròó. Tí wọ́n bá hun aṣọ, bí wọ́n ṣe ń gbé òwú tó wà ní ìbú lé èyí tó wà lóròó ni wọ́n á máa gbé èyí tó wà lóròó lé èyí tó wà ní ìbú.—Le 13:59.
Ọ
Ọbabìnrin Ọ̀run.
Orúkọ oyè abo ọlọ́run táwọn ọmọ Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń bọ nígbà ayé Jeremáyà. Àwọn kan gbà pé òun náà ni abo ọlọ́run àwọn ará Bábílónì tí wọ́n ń pè ní Íṣítà (Ásítátè). Orúkọ míì tí wọ́n mọ̀ ọ́n sí ni Inanna, èyí tó túmọ̀ sí “Ọbabìnrin Ọ̀run.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún gbà pé òun ni abo òrìṣà ìbímọlémọ. Wọ́n tiẹ̀ pe Ásítátè ní “Ìyálóde Ọ̀run” nínú ìkọ̀wé àwọn ará Íjíbítì kan.—Jer 44:19.
Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Sólómọ́nì.
Nínú tẹ́ńpìlì tó wà nígbà ayé Jésù, ojú ọ̀nà kan tó ní ìbòrí lápá ìlà oòrùn àgbàlá ìta. Ọ̀pọ̀ gbà pé ó jẹ́ apá tó ṣẹ́ kù lára tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Jésù rìn níbẹ̀ ní “ìgbà òtútù,” àwọn Kristẹni ìgbàanì náà sì pàdé níbẹ̀ fún ìjọsìn. (Jo 10:22, 23; Iṣe 5:12)—Wo Àfikún B11.
Ọ̀fọ̀.
Kí èèyàn fi bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ hàn nígbà tí ẹnì kan bá kú tàbí tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà wọn láti ṣọ̀fọ̀ fún àkókò kan. Yàtọ̀ sí pé àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń sunkún gan-an, wọ́n tún máa ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n á da eérú sórí, wọ́n á fa aṣọ wọn ya, wọ́n á sì máa fọwọ́ lu àyà wọn. Nígbà míì, wọ́n máa ń pe àwọn tó ń fi ẹkún sísun ṣiṣẹ́ ṣe wá síbi ìsìnkú.—Jẹ 23:2; Ẹst 4:3; Ifi 21:4.
Ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.
Ọjọ́ Ètùtù.
Ọjọ́ mímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n tún máa ń pè é ní Yom Kippur (látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà yohm hak·kip·pu·rimʹ, “ọjọ́ ìbo nǹkan mọ́lẹ̀ tàbí ìpẹ̀tù”), ọjọ́ kẹwàá oṣù Étánímù ni wọ́n máa ń ṣe é. Jálẹ̀ ọdún, ọjọ́ yìí nìkan ni àlùfáà àgbà máa ń wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn. Ibẹ̀ ló ti máa ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹran rúbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó bá ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Léfì àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn yòókù. Ó jẹ́ àkókò àpéjọ mímọ́ àti ààwẹ̀, ó sì tún jẹ́ sábáàtì, tí wọn kì í ṣe iṣẹ́ kankan.—Le 23:27, 28.
Ọjọ́ Ìdájọ́.
Ó jẹ́ ọjọ́ kan tàbí àkókò kan pàtó, tí Ọlọ́run máa pe àwùjọ àwọn èèyàn, àwọn orílẹ̀-èdè tàbí gbogbo èèyàn lápapọ̀ láti wá jẹ́jọ́. Ó lè jẹ́ ìgbà yẹn ni Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn tó gba ìdájọ́ ikú, ìdájọ́ náà sì lè fún àwọn kan láǹfààní láti rí ìgbàlà, kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tọ́ka sí “Ọjọ́ Ìdájọ́” kan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ìdájọ́ náà máa kan gbogbo àwọn tó wà láàyè àtàwọn tó ti kú.—Mt 12:36.
Ọjọ́ ìkẹyìn.
Ọ̀rọ̀ yìí àtàwọn gbólóhùn bí “àkókò òpin” wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó sì ń tọ́ka sí ìgbà tí àwọn ohun mánigbàgbé ti fẹ́ dópin. (Isk 38:16; Da 10:14; Iṣe 2:17) Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá dá lé ló máa pinnu bí àkókò náà ṣe máa gùn tó, ó lè jẹ́ ọdún díẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ ọdún. Bíbélì sábà máa ń lo gbólóhùn náà “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí láti tọ́ka sí ìgbà tí Jésù máa wà níhìn-ín tí a ò ní lè fojú rí i.—2Ti 3:1; Jem 5:3; 2Pe 3:3.
Ọkàn.
Ọ̀rọ̀ tí a tú sí ọkàn ni neʹphesh lédè Hébérù àti psy·kheʹ lédè Gíríìkì. Nígbà tí a wo bí wọ́n ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí nínú Bíbélì, ó ṣe kedere pé ohun tó ń tọ́ka sí ni (1) èèyàn, (2) ẹranko tàbí (3) ẹ̀mí èèyàn tàbí ti ẹranko. (Jẹ 1:20; 2:7; Nọ 31:28; 1Pe 3:20; tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) Bíbélì jẹ́ ká rí i pé tí a bá lo àwọn ọ̀rọ̀ náà neʹphesh àti psy·kheʹ fún àwọn ohun alààyè tó wà láyé, ó máa ń tọ́ka sí ohun gidi, tó ṣeé dì mú, tó ṣeé fojú rí, tó sì lè kú. Èyí yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa ń lò ó nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn. Nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí, àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì yìí ká ló pinnu bí a ṣe tú u. Lára àwọn ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ rẹ̀ sí ni “ẹ̀mí,” “ohun alààyè,” “ẹni,” “gbogbo ara,” tàbí ká kàn lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ (bí àpẹẹrẹ, a lo “èmi” dípò “ọkàn mi”). Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa rí “ọkàn” nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé. Nígbà tí a bá lo “ọkàn” nínú ẹsẹ Bíbélì kan tàbí nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, àlàyé tí a ṣe lókè máa jẹ́ ká lóye ohun tó túmọ̀ sí. Tí Bíbélì bá ní ká fi gbogbo ọkàn ṣe nǹkan, ó túmọ̀ sí pé ká fi taratara ṣe é, ká ṣe é tọkàntọkàn, ká sì fi gbogbo ẹ̀mí wa ṣe é. (Di 6:5; Mt 22:37) Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì kan, ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì yìí lè tọ́ka sí ohun tó wuni tàbí tó wà lọ́kàn ẹni. Ó tún lè tọ́ka sí ẹni tó ti kú tàbí òkú.—Nọ 6:6; Owe 23:2; Ais 56:11; Hag 2:13.
Ọlọ.
Òkúta ribiti kan tí wọ́n gbé sórí òkúta míì, tí wọ́n fi ń lọ nǹkan oníhóró di lẹ́búlẹ́bú. Igi kan máa ń wà láàárín òkúta tó wà nísàlẹ̀ tó máa wọnú òkúta tó wà lókè, tí kò ní jẹ́ kó yí dà nù. Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ ilé ló máa ń ní ọlọ ọlọ́wọ́ táwọn obìnrin ń lò. Torí pé ọlọ ọlọ́wọ́ ni wọ́n fi ń lọ ọkà tí wọ́n fi ń ṣe oúnjẹ gbogbo ìdílé lójoojúmọ́, Òfin Mósè sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ gba ọlọ tàbí ọmọ ọlọ ẹlòmíì torí kó lè san gbèsè tó jẹ. Àwọn ẹranko ló máa ń yí ọlọ ńlá tó jọ irú èyí.—Di 24:6; Mk 9:42.
Ọlọ́run tòótọ́, náà.
Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fi hàn pé “Ọlọ́run” tó yàtọ̀ là ń tọ́ka sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí a bá sọ pé Ọlọ́run tòótọ́ náà, ó máa ń gbé ìtumọ̀ èdè Hébérù náà jáde tó jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́, ó sì yàtọ̀ sáwọn ọlọ́run èké. Bí a ṣe lo “Ọlọ́run tòótọ́ náà” jẹ́ kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà ṣe kedere láwọn ibi tí a ti lò ó.—Jẹ 5:22, 24; 46:3; Di 4:39.
Ọmọ Dáfídì.
Ọmọ èèyàn.
Nǹkan bí ọgọ́rin (80) ìgbà lọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Jésù Kristi ló ń tọ́ka sí, ó sì ń jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù di èèyàn nígbà tí wọ́n bí i sáyé, kì í ṣe pé ó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. Ọ̀rọ̀ yìí tún fi hàn pé Jésù máa mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì 7:13, 14 ṣẹ. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí fún Ìsíkíẹ́lì àti Dáníẹ́lì kí ìyàtọ̀ lè wà láàárín Ọlọ́run tó rán wọn níṣẹ́ àti àwọn agbẹnusọ rẹ̀ tó jẹ́ èèyàn.—Isk 3:17; Da 8:17; Mt 19:28; 20:28.
Ọ̀nà, náà.
Ìwé Mímọ́ máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti tọ́ka sí ìgbésẹ̀ tàbí ìwà kan tó lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. Wọ́n pe àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Jésù ní àwọn tó ń tẹ̀ lé “Ọ̀nà Náà,” torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Iṣe 19:9.
Ọ̀pá àṣẹ.
Ọ̀pá esùsú tí wọ́n fi ń wọn nǹkan.
Ọ̀pá esùsú tí wọ́n fi ń wọn nǹkan gùn tó ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Mítà 2.67 (ẹsẹ̀ bàtà 8.75) ni tí wọ́n bá fi ìgbọ̀nwọ́ tó wọ́pọ̀ wọ̀n ọ́n, àmọ́ tí wọ́n bá fi ìgbọ̀nwọ́ gígùn wọ̀n ọ́n, á jẹ́ mítà 3.11 (ẹsẹ̀ bàtà 10.2). (Isk 40:3, 5; Ifi 11:1)—Wo Àfikún B14.
Ọ̀pá kẹ́sẹ́.
Ọ̀pá gígùn tó ní irin ṣóńṣó lẹ́nu tí darandaran máa ń rọra fi gún ẹran ọ̀sìn. Wọ́n máa ń fi wé ọ̀rọ̀ tí ọlọ́gbọ́n èèyàn sọ láti mú kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ gba ìmọ̀ràn. Tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan “ń tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́,” ńṣe ló dà bí ohun tí akọ màlúù kan tó ya alágídí ń ṣe nígbà tó bá ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ gbá ọ̀pá kẹ́sẹ́, tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe.—Iṣe 26:14; Ond 3:31.
Ọpọ́n.
Ọrẹ ẹ̀jẹ́.
Ọrẹ fífì.
Ọrẹ kan tí àlùfáà ti máa ń fi ọwọ́ rẹ̀ sábẹ́ ọwọ́ ẹni tó gbé ohun tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ náà dání, kó sì máa fì í síwá-sẹ́yìn; tàbí kí àlùfáà náà fúnra rẹ̀ máa fi ọrẹ náà. Fífi ọrẹ náà ń ṣàpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe ń fún Jèhófà láwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ náà.—Le 7:30.
Ọrẹ ohun mímu.
Ọwọ̀n; Òpó.
Ohun tó wà lóòró, tí wọ́n fi gbé nǹkan ró tàbí ohun tó jọ ọ́. Wọ́n máa ń ṣe é nígbà míì láti fi rántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. Wọ́n lo òpó láti fi gbé tẹ́ńpìlì àtàwọn ilé ọba tí Sólómọ́nì kọ́ dúró. Àwọn abọ̀rìṣà máa ń lo ọwọ̀n òrìṣà nínú ìsìn èké, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà sì máa ń kọ́ àṣà wọn nígbà míì. (Ond 16:29; 1Ọb 7:21; 14:23)—Wo ỌPỌ́N.
Ọwọ̀n òrìṣà.
Ọwọ̀n tí wọ́n gbé nàró, tí wọ́n sábà máa ń fi òkúta ṣe. Ó ní ìrísí ẹ̀yà ìbímọ akọ, èyí tó dúró fún Báálì tàbí àwọn òrìṣà míì.—Ẹk 23:24.
P
Panṣágà.
—Wo ÀGBÈRÈ.
Párádísè.
Ọgbà kan tó lẹ́wà gan-an, tó sì tura. Àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ni ọgbà Édẹ́nì tí Jèhófà ṣe fún tọkọtaya àkọ́kọ́. Nígbà tí Jésù ń bá ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí òpó igi oró, Jésù sọ pé ayé máa di Párádísè. Nínú 2 Kọ́ríńtì 12:4, ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí Párádísè tí à ń retí lọ́jọ́ iwájú, ó sì tọ́ka sí Párádísè ti ọ̀run nínú Ìfihàn 2:7.—Sol 4:13; Lk 23:43.
Páṣíà; Àwọn ará Páṣíà.
Ó ń tọ́ka sí ilẹ̀ tàbí àwọn èèyàn tí wọ́n sábà máa ń mẹ́nu kàn pẹ̀lú àwọn ará Mídíà, ẹ̀rí sì wà pé wọ́n tan mọ́ra. Níbẹ̀rẹ̀, gúúsù ìwọ̀ oòrùn agbègbè kan tó tẹ́jú nílẹ̀ Iran nìkan làwọn ará Páṣíà wà. Nígbà ìṣàkóso Kírúsì Ńlá (tí àwọn òpìtàn kan láyé àtijọ́ sọ pé ará Páṣíà ni bàbá rẹ̀, tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Mídíà), ọwọ́ àwọn ará Páṣíà mókè ju tàwọn ará Mídíà lọ, síbẹ̀ wọ́n jọ ń ṣàkóso. Kírúsì ṣẹ́gun Ìjọba Bábílónì lọ́dún 539 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì jẹ́ káwọn Júù tí wọ́n mú lẹ́rú pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Agbègbè tí Ìjọba Páṣíà ń ṣàkóso bẹ̀rẹ̀ láti odò Íńdọ́sì lápá ìlà oòrùn títí dé òkun Aegean lápá ìwọ̀ oòrùn. Ìjọba Páṣíà ló ń ṣàkóso àwọn Júù títí dìgbà tí Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun àwọn ará Páṣíà lọ́dún 331 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Dáníẹ́lì rí ìran kan nípa Ìjọba Páṣíà, ó sì tún fara hàn nínú ìwé Ẹ́sírà, Nehemáyà àti Ẹ́sítà. (Ẹsr 1:1; Da 5:28; 8:20)—Wo Àfikún B9.
Pèéṣẹ́.
Kí ẹnì kan kó irè oko tí àwọn tó ń kórè fi sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ fi sílẹ̀ tàbí kí wọ́n gbàgbé. Òfin Mósè sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe kó irè oko tó wà ní eteetí oko wọn, kí wọ́n má sì kó gbogbo àwọn èso ólífì tàbí àjàrà wọn. Àwọn tálákà, àwọn tí ìyà ń jẹ, àwọn àjèjì, àwọn ọmọ aláìníbaba àti àwọn opó ni Ọlọ́run fún lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pèéṣẹ́ ohun tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn ìkórè.—Rut 2:7.
Pẹ́ńtíkọ́sì.
Ìkejì nínú àwọn àjọyọ̀ pàtàkì mẹ́ta tí gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ Júù gbọ́dọ̀ wá ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Pẹ́ńtíkọ́sì túmọ̀ sí “Àádọ́ta (Ọjọ́).” Àjọyọ̀ Ìkórè tàbí Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pè ní Pẹ́ńtíkọ́sì. Àádọ́ta ọjọ́ lẹ́yìn Nísàn 16 ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ yìí.—Ẹk 23:16; 34:22; Iṣe 2:1.
Pẹpẹ.
Pèpéle tàbí ohun kan tó ga tí wọ́n fi iyẹ̀pẹ̀ tàbí òkúta mọ, ó sì tún lè jẹ́ pé igi tí wọ́n fi irin bò ni wọ́n fi ṣe é. Wọ́n máa ń rúbọ tàbí kí wọ́n sun tùràrí lórí rẹ̀ nígbà ìjọsìn. “Pẹpẹ wúrà” kékeré kan wà nínú yàrá àkọ́kọ́ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì, tí wọ́n máa ń sun tùràrí lórí rẹ̀. Igi tí wọ́n fi wúrà bò ni wọ́n fi ṣe é. Àmọ́ ní ìta àgọ́ ìjọsìn náà, “pẹpẹ bàbà” kan tó tóbi wà níbẹ̀ tí wọ́n máa ń rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀. (Ẹk 27:1; 39:38, 39; Jẹ 8:20; 1Ọb 6:20; 2Kr 4:1; Lk 1:11)—Wo Àfikún B5 àti B8.
Píìmù.
Ohun ìdíwọ̀n kan, ó tún jẹ́ iye táwọn ará Filísínì ń gbà fún pípọ́n onírúurú irinṣẹ́. Kọ́ńsónáǹtì èdè Hébérù tó dúró fún “píìmù” wà lára àwọn òkúta ìdíwọ̀n kan táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde ní Ísírẹ́lì; wọ́n sábà máa ń wúwo tó nǹkan bíi gíráàmù mẹ́jọ (7.8 g), èyí sì jẹ́ nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta ṣékélì kan.—1Sa 13:20, 21.
Pípakà; Ibi ìpakà.
Yíyọ ìyàngbò tàbí èèpo kúrò lára ọkà. Ibi ìpakà ni ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe iṣẹ́ yìí. Wọ́n máa ń fi ọ̀pá lu ọkà tí wọ́n fẹ́ pa, tó bá sì jẹ́ pé ọkà náà pọ̀, wọ́n máa ń lo àwọn irinṣẹ́ bí ohun èlò ìpakà táwọn ẹranko máa ń fà. Wọ́n máa ń yí àwọn ohun èlò yìí lórí ọkà tí wọ́n tẹ́ síbi ìpakà. Ibi ìpakà máa ń rí bìrìkìtì, ó sì máa ń tẹ́jú, ó máa ń ga, ó sì máa ń jẹ́ ibi tí atẹ́gùn ti máa ń fẹ́ dáadáa.—Le 26:5; Ais 41:15; Mt 3:12.
Pómégíránétì.
Èso tó rí bí ápù, ó ní ohun tó dà bí adé ní orí rẹ̀. Èpo ara rẹ̀ le, èso kéékèèké tó lómi nínú ló sì kún inú rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan èso kéékèèké náà ní kóró pupa kékeré kan nínú. Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bíi Pómégíránétì wà létí aṣọ àwọ̀lékè búlúù tí kò lápá tí àlùfáà àgbà máa ń wọ̀. Ó sì tún wà lára ọpọ́n tó wà lórí òpó Jákínì àti Bóásì níwájú tẹ́ńpìlì.—Ẹk 28:34; Nọ 13:23; 1Ọb 7:18.
Porneia.
—Wo ÌṢEKÚṢE.
Púrímù.
Àjọyọ̀ ọdọọdún tí wọ́n máa ń ṣe ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù Ádárì. Wọ́n máa ń fi àjọyọ̀ yìí rántí bí Jèhófà ṣe dá àwọn Júù nídè láyé ìgbà Ayaba Ẹ́sítà. Ọ̀rọ̀ náà pu·rimʹ túmọ̀ sí “kèké,” àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ Hébérù. Torí pé Hámánì ṣẹ́ Púrì (kèké) láti mọ ọjọ́ tó máa rẹ́yìn àwọn Júù ni wọ́n ṣe ń pe àjọyọ̀ náà ní Àjọyọ̀ Púrímù tàbí Àjọyọ̀ Kèké.—Ẹst 3:7; 9:26.
R
Ráhábù.
S
Sáàmù.
Orin ìyìn sí Ọlọ́run. Àwọn olùjọsìn Jèhófà máa ń kọ orin yìí nígbà ìjọsìn, títí kan ìgbà tí wọ́n bá ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tó wà ní Jerúsálẹ́mù.—Lk 20:42; Iṣe 13:33; Jem 5:13.
Sábáàtì.
Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “láti sinmi” tàbí “láti dáwọ́ dúró.” Ó jẹ́ ọjọ́ keje nínú ọ̀sẹ̀ àwọn Júù (bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ Friday sí ìrọ̀lẹ́ Saturday). Wọ́n tún máa ń pe àwọn ọjọ́ àjọyọ̀ míì láàárín ọdún ní sábáàtì, bákan náà ni ọdún keje àti ọdún àádọ́ta. Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì, àwọn àlùfáà nìkan ló lè ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn. Ní àwọn ọdún Sábáàtì, wọn ò gbọ́dọ̀ gbin nǹkan kan, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fipá gba ohunkóhun tí ọmọ Ísírẹ́lì ẹgbẹ́ wọn bá jẹ wọ́n. Ó rọrùn láti pa Sábáàtì mọ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè, ṣùgbọ́n díẹ̀díẹ̀ làwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi òfin tiwọn kún un débi pé nígbà ayé Jésù, ó nira fáwọn èèyàn láti pa á mọ́.—Ẹk 20:8; Le 25:4; Lk 13:14-16; Kol 2:16.
Sadusí.
Ẹgbẹ́ kan tó lókìkí nínú Ìsìn Àwọn Júù. Àwọn ọlọ́rọ̀ tó gbajúmọ̀ àtàwọn àlùfáà ló wà nínú ẹgbẹ́ yìí, wọ́n sì láṣẹ gan-an lórí ohun tó ń lọ nínú tẹ́ńpìlì. Wọn ò fara mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ míì táwọn Farisí ń gbé lárugẹ. Wọn ò gbà pé àjíǹde máa wà, wọn ò sì gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà. Wọ́n tún ta ko Jésù.—Mt 16:1; Iṣe 23:8.
Sàhẹ́ndìrìn.
Ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà ayé Jésù, àwọn mọ́kànléláàádọ́rin (71) ló wà nínú ìgbìmọ̀ yìí. Lára wọn ni àlùfáà àgbà àtàwọn míì tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ àlùfáà àgbà, àwọn ẹbí àlùfáà àgbà, àwọn àgbààgbà, àwọn olórí ẹ̀yà, àwọn olórí ìdílé àtàwọn akọ̀wé òfin.—Mk 15:1; Iṣe 5:34; 23:1, 6.
Samáríà.
Olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì fún nǹkan bí igba (200) ọdún, orúkọ yìí náà sì ni wọ́n ń pe àwọn ibi tí wọ́n ń jọba lé lórí. Orí òkè kan tí wọ́n ń pè ní Samáríà ni wọ́n kọ́ ìlú náà sí. Nígbà ayé Jésù, Samáríà lorúkọ agbègbè tó wà láàárín Gálílì ní àríwá àti Jùdíà ní gúúsù. Jésù kì í sábà wàásù lágbègbè yẹn, àmọ́ nígbà míì ó máa ń gba ibẹ̀ kọjá ó sì máa ń bá àwọn tó ń gbé ibẹ̀ sọ̀rọ̀. Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ kejì Ìjọba náà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà táwọn ará Samáríà gba ẹ̀mí mímọ́. (1Ọb 16:24; Jo 4:7; Iṣe 8:14)—Wo Àfikún B10.
Sátánì.
Sélà.
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò láti fi darí orin tàbí ewì nínú ìwé Sáàmù àti Hábákúkù. Ó lè túmọ̀ sí pé kí ẹni tó ń kọrin dánu dúró díẹ̀ tàbí kí wọ́n dáwọ́ ohùn orin dúró díẹ̀, kéèyàn lè ṣàṣàrò tàbí kí kókó tí orin náà gbé jáde lè wọni lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n lò nínú Bíbélì Septuagint ni di·aʹpsal·ma, tó túmọ̀ sí “ìdánudúró nínú orin.”—Sm 3:4; Hab 3:3.
Séráfù.
Síà.
Òṣùwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn nǹkan gbígbẹ. Tí a bá fi wé òṣùwọ̀n báàtì tí wọ́n fi ń wọn nǹkan olómi, á gba nǹkan tó lé díẹ̀ ní Lítà méje (Lítà 7.33, ìyẹn kúọ̀tì 6.66). (2Ọb 7:1)—Wo Àfikún B14.
Sífánì.
Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, orúkọ yìí ni wọ́n ń pe oṣù kẹta lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù, òun sì ni oṣù kẹsàn-án lórí kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ láti àárín oṣù May, ó sì máa ń parí ní àárín oṣù June. (Ẹst 8:9)—Wo Àfikún B15.
Sífì.
Orúkọ tí oṣù kejì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù, òun sì ni oṣù kẹjọ lórí kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ní àárín oṣù April, ó sì máa ń parí ní àárín oṣù May. Wọ́n pè é ní Ííyà nínú ìwé Támọ́dì Àwọn Júù àti nínú àwọn ìwé míì tí wọ́n kọ lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì. (1Ọb 6:37)—Wo Àfikún B15.
Sínágọ́gù.
Ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “kíkóra jọ; àpéjọ,” àmọ́ nínú ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ó máa ń tọ́ka sí ilé tàbí ibi táwọn Júù kóra jọ sí láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n gba ìtọ́ni, kí wọ́n gbọ́ ìwàásù, kí wọ́n sì gbàdúrà. Nígbà ayé Jésù, ìlú kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì máa ń ní Sínágọ́gù kan, àwọn ìlú tó bá tóbi sì máa ń ní ju Sínágọ́gù kan lọ.—Lk 4:16; Iṣe 13:14, 15.
Síónì; Òkè Síónì.
Ìlú olódi Jébúsì táwọn ará Jébúsì kọ́ sí orí òkè tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn tí Dáfídì ṣẹ́gun wọn, ó kọ́ ààfin rẹ̀ síbẹ̀, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní “Ìlú Dáfídì.” (2Sa 5:7, 9) Síónì di òkè mímọ́ fún Jèhófà nígbà tí Dáfídì gbé Àpótí Májẹ̀mú lọ síbẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n ń pe gbogbo agbègbè tẹ́ńpìlì tó wà lórí Òkè Moráyà ní Síónì, wọ́n sì máa ń pe gbogbo ìlú Jerúsálẹ́mù ní Síónì nígbà míì. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lọ́pọ̀ ìgbà.—Sm 2:6; 1Pe 2:6; Ifi 14:1.
Sípẹ́ẹ̀tì.
Oríṣi ọkà kan tí kò dáa tó àlìkámà (Triticum spelta), èèpo tàbí ìyàngbò rẹ̀ kì í tètè ṣí kúrò.—Ẹk 9:32.
Síríà; Àwọn Ará Síríà.
Sítísì.
Ibi méjì tó fẹ̀ gan-an ní etíkun Líbíà ní Àríwá Áfíríkà. Àwọn awakọ̀ okùn ayé àtijọ́ kì í fẹ́ gba ibẹ̀ torí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn àti pé iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ sábà máa ń wọ́ kiri torí ìgbì òkun náà. (Iṣe 27:17)—Wo Àfikún B13.
Súúsì.
Òrìṣà táwọn Gíríìkì gbà pé ó jẹ́ olórí àwọn òrìṣà tó kù. Ní Lísírà, àwọn kan rò pé Bánábà ni Súúsì. Ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí nítòsí Lísírà sọ̀rọ̀ nípa “àwọn àlùfáà Súúsì” àti “Súúsì ọlọ́run oòrùn.” Wọ́n kọ ọ̀rọ̀ náà “Àwọn Ọmọ Súúsì,” ìyẹn àwọn ìbejì náà Kásítọ̀ àti Pólúsì sára ère orí ọkọ̀ ojú omi tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ láti erékùṣù Málítà.—Iṣe 14:12; 28:11.
Ṣ
Ṣébátì.
Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, orúkọ yìí ni wọ́n ń pe oṣù kọkànlá lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù, òun sì ni oṣù karùn-ún lórí kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ní àárín oṣù January, ó sì máa ń parí ní àárín oṣù February. (Sek 1:7)—Wo Àfikún B15.
Ṣékélì.
Òṣùwọ̀n táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe wúwo tó, wọ́n sì fi ń díwọ̀n owó. Ìwúwo rẹ̀ fi díẹ̀ lé ní gíráàmù mọ́kànlá (gíráàmù 11.4). Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà “ṣékélì ibi mímọ́” tẹnu mọ́ bó ṣe yẹ kí òṣùwọ̀n náà péye tó tàbí kó ṣe déédéé pẹ̀lú òṣùwọ̀n tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn. Ó ṣeé ṣe kí òṣùwọ̀n ṣékélì míì tún wà tí wọ́n ń lò ní ààfin (tó yàtọ̀ sí ti gbogbogbòò) tàbí kó jẹ́ òṣùwọ̀n tó péye tó wà ní ààfin.—Ẹk 30:13.
Ṣẹ́mínítì.
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò nínú orin, ó túmọ̀ sí “ìkẹjọ,” tó ṣeé ṣe kó tọ́ka sí ohùn orin tó rọra ń dún. Tó bá jẹ́ àwọn ohun èlò ìkọrin la lò ó fún, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí èyí tó máa ń gbé ohùn kíkẹ̀ jáde. Nínú orin, ó ṣeé ṣe kó tọ́ka sí àwọn ohun èlò ìkọrin tó rọra ń dún lábẹ́lẹ̀, tó sì ń bá orin tí wọ́n ń kọ mu.—1Kr 15:21; Sm 6:Akl; 12:Akl.
Ṣìọ́ọ̀lù.
Ṣíṣú opó.
T
Tálẹ́ńtì.
Èyí tó tóbi jù nínú òṣùwọ̀n táwọn Hébérù fi ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe wúwo tó, wọ́n sì fi ń díwọ̀n owó. Ìwúwo rẹ̀ jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Tálẹ́ńtì àwọn Gíríìkì kéré síyẹn, ó wúwo tó nǹkan bíi kìlógíráàmù 20.4. (1Kr 22:14; Mt 18:24)—Wo Àfikún B14.
Támúsì.
(1) Orúkọ òrìṣà táwọn obìnrin Hébérù tó di apẹ̀yìndà ní Jerúsálẹ́mù ń tìtorí rẹ̀ sunkún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọba ni Támúsì, àwọn èèyàn sì sọ ọ́ di òrìṣà lẹ́yìn tó kú. Nínú ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Súmà, wọ́n pe Támúsì ní Dúmúsì, wọ́n sì gbà pé òun ni olólùfẹ́ Inanna tó jẹ́ abo òrìṣà ìbímọlémọ (táwọn ará Bábílónì ń pè ní Íṣítà). (Isk 8:14) (2) Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, orúkọ yìí ni wọ́n ń pe oṣù kẹrin lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù. Oṣù yìí sì ni oṣù kẹwàá lórí kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ní àárín oṣù June, ó sì máa ń parí ní àárín oṣù July.—Wo Àfikún B15.
Táṣíṣì, àwọn ọkọ̀ òkun.
Tátárọ́sì.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, Tátárọ́sì ni ipò ẹ̀tẹ́ tí a fi àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn nígbà ayé Nóà sí. Ipò náà sì dà bí ìgbà téèyàn wà lẹ́wọ̀n. Nínú 2 Pétérù 2:4, ọ̀rọ̀ ìṣe náà tar·ta·roʹo (ìyẹn “láti jù sínú Tátárọ́sì”) kò túmọ̀ sí pé “àwọn áńgẹ́lì tó ṣẹ̀” náà wà nínú Tátárọ́sì táwọn abọ̀rìṣà máa ń sọ nínú ìtàn àròsọ (ìyẹn ẹ̀wọ̀n abẹ́lẹ̀ àti ibi òkùnkùn tí wọ́n gbà pé àwọn ọlọ́run kéékèèké wà). Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run lé wọn kúrò ní ipò tí wọ́n wà ní ọ̀run, ó gba àwọn àǹfààní tí wọ́n ní, òye àwọn ohun tó hàn kedere pé Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe sì ṣókùnkùn sí wọn pátápátá. Àtubọ̀tán wọn náà ò dáa torí pé Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ìparun ayérayé ló máa gbẹ̀yìn àwọn àti Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí wọn. Torí náà, Tátárọ́sì ń tọ́ka sí ipò ẹ̀tẹ́ tó rẹlẹ̀ jù lọ táwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn wà. Ó sì yàtọ̀ sí “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” tí Ìfihàn 20:1-3 mẹ́nu kàn.
Tébétì.
Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, orúkọ yìí ni wọ́n ń pe oṣù kẹwàá lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù. Oṣù yìí sì ni oṣù kẹrin lórí kàlẹ́ńdà gbogbo ayé. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ní àárín oṣù December, ó sì máa ń parí ní àárín oṣù January. Bíbélì sábà máa ń pè é ní “oṣù kẹwàá.” (Ẹst 2:16)—Wo Àfikún B15.
Tẹ́ńpìlì.
Ilé tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, òun ló rọ́pò àgọ́ ìjọsìn tí wọ́n máa ń gbé kiri, Jerúsálẹ́mù sì ni wọ́n kọ́ ọ sí. Sólómọ́nì ló kọ́ tẹ́ńpìlì àkọ́kọ́, àwọn ará Bábílónì ló sì pa tẹ́ńpìlì náà run. Serubábélì ló kọ́ tẹ́ńpìlì kejì lẹ́yìn tí wọ́n pa dà dé láti ìgbèkùn Bábílónì, Hẹ́rọ́dù Ńlá sì tún un kọ́ nígbà tó yá. Lọ́pọ̀ ìgbà, “ilé Jèhófà” ni Ìwé Mímọ́ sábà máa ń pe tẹ́ńpìlì. (Ẹsr 1:3; 6:14, 15; 1Kr 29:1; 2Kr 2:4; Mt 24:1)—Wo Àfikún B8 àti Àfikún B11.
Tẹ́ráfímù.
Òrìṣà ìdílé, wọ́n sì máa ń lò ó nígbà míì láti woṣẹ́. (Isk 21:21) Àwọn kan máa ń tóbi tó èèyàn, wọ́n tún máa ń rí bí èèyàn, àwọn míì sì máa ń kéré. (Jẹ 31:34; 1Sa 19:13, 16) Ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí ní Mesopotámíà fi hàn pé ẹni tó bá ní ère tẹ́ráfímù lọ́wọ́ ló máa gba ogún ìdílé. (Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí ẹ̀ ni Réṣẹ́lì fi mú tẹ́ráfímù bàbá rẹ̀.) Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń lo tẹ́ráfímù fún ìbọ̀rìṣà lásìkò àwọn onídàájọ́ àti lásìkò àwọn ọba, wọ́n wà lára àwọn nǹkan tí Ọba Jòsáyà tó jẹ́ olóòótọ́ pa run.—Ond 17:5; 2Ọb 23:24; Ho 3:4.
Tíṣírì.
—Wo ÉTÁNÍMÙ àti Àfikún B15.
Tùràrí.
Oje igi tí wọ́n pò mọ́ òróró básámù tó máa ń rọra jó tí wọ́n bá finá sí i, tí á sì máa ta sánsán. Èròjà mẹ́rin ni wọ́n fi ṣe àkànṣe tùràrí tí wọ́n máa ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn àti ní tẹ́ńpìlì. Wọ́n máa ń sun tùràrí yìí láàárọ̀ àti lálẹ́ lórí pẹpẹ tùràrí tó wà ní Ibi Mímọ́, àmọ́ ní Ọjọ́ Ètùtù, wọ́n máa ń sun ún nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ó ṣàpẹẹrẹ àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ní ìtẹ́wọ́gbà. Ọlọ́run ò sọ pé káwọn Kristẹni máa sun tùràrí.—Ẹk 30:34, 35; Le 16:13; Ifi 5:8.
U
Úrímù àti Túmímù.
Ohun kan tí àlùfáà àgbà máa ń lò láti wádìí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó kan gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Bí wọ́n ṣe ń lò ó jọ bí wọ́n ṣe ń lo kèké. Inú aṣọ ìgbàyà àlùfáà àgbà ni Úrímù àti Túmímù máa ń wà tó bá ti wọnú àgọ́ ìjọsìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run ni wọn ò lo Úrímù àti Túmímù mọ́.—Ẹk 28:30; Ne 7:65.
W
Wáhàrì.
Wíwàníhìn-ín.
Ní àwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó tọ́ka sí àkókò tí Jésù Kristi fi wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí ọba, èyí tó bẹ̀rẹ̀ látìgbà tó di Mèsáyà Ọba ní ọ̀run títí wọ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí. Ìgbà tí Kristi máa wà níhìn-ín kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé ó máa dé tó sì máa tètè pa dà; kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ sáà àkókò kan.—Mt 24:3.
Wòlíì.
Woṣẹ́woṣẹ́.
Y
Yúfírétì.
Odò tó gùn jù lọ tó sì ṣe pàtàkì jù ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Éṣíà, ó wà lára odò méjì tó tóbi jù lọ ní Mesopotámíà. Inú Jẹ́nẹ́sísì 2:14 ni Bíbélì ti kọ́kọ́ mẹ́nu kàn án pé ó jẹ́ ọ̀kan lára odò mẹ́rin tó wà ní Édẹ́nì. Wọ́n sábà máa ń pè é ní “Odò.” (Jẹ 31:21) Òun ni ààlà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní apá àríwá. (Jẹ 15:18; Ifi 16:12)—Wo Àfikún B2.