Àkọsílẹ̀ Mátíù
25 “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n mú fìtílà wọn,+ tí wọ́n sì jáde lọ pàdé ọkọ ìyàwó.+ 2 Márùn-ún nínú wọ́n jẹ́ òmùgọ̀, márùn-ún sì jẹ́ olóye.*+ 3 Àwọn òmùgọ̀ mú fìtílà wọn, àmọ́ wọn ò gbé òróró dání, 4 ṣùgbọ́n àwọn olóye rọ òróró sínú ìgò* wọn, wọ́n sì gbé fìtílà wọn dání. 5 Nígbà tí ọkọ ìyàwó ò tètè dé, gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn lọ. 6 Ni ariwo bá sọ láàárín òru pé: ‘Ọkọ ìyàwó ti dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’ 7 Gbogbo àwọn wúńdíá náà bá dìde, wọ́n sì tún fìtílà wọn ṣe.+ 8 Àwọn òmùgọ̀ sọ fún àwọn olóye pé, ‘Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú òróró yín, torí pé àwọn fìtílà wa ti fẹ́ kú.’ 9 Àwọn olóye dá wọn lóhùn pé: ‘Ó ṣeé ṣe kó má tó àwa àti ẹ̀yin. Torí náà, ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń tà á, kí ẹ sì ra tiyín.’ 10 Bí wọ́n ṣe ń lọ rà á, ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí wọ́n ti ṣe tán bá a wọlé síbi àsè ìgbéyàwó náà,+ a sì ti ilẹ̀kùn. 11 Lẹ́yìn náà, àwọn wúńdíá yòókù dé, wọ́n ní, ‘Ọ̀gá, Ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!’+ 12 Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Kí n sọ òótọ́ fún yín, mi ò mọ̀ yín rí.’
13 “Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà,+ torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.+
14 “Torí ṣe ló dà bí ọkùnrin kan tó fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó wá pe àwọn ẹrú rẹ̀, tó sì fa àwọn ohun ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́.+ 15 Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì* márùn-ún, ó fún òmíràn ní méjì, òmíràn ní ọ̀kan, ó fún kálukú bí agbára rẹ̀ ṣe mọ, ó sì lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. 16 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún lọ, ó fi ṣòwò, ó sì jèrè márùn-ún sí i. 17 Bákan náà, ẹni tó gba méjì jèrè méjì sí i. 18 Àmọ́ ẹrú tó gba ẹyọ kan ṣoṣo lọ, ó gbẹ́ ilẹ̀, ó sì fi owó* ọ̀gá rẹ̀ pa mọ́.
19 “Lẹ́yìn tó ti pẹ́ gan-an, ọ̀gá àwọn ẹrú yẹn dé, wọ́n sì jọ yanjú ọ̀rọ̀ owó.+ 20 Torí náà, ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún wá, ó sì mú tálẹ́ńtì márùn-ún míì wá, ó ní, ‘Ọ̀gá, tálẹ́ńtì márùn-ún lo fún mi; wò ó, mo ti jèrè tálẹ́ńtì márùn-ún sí i.’+ 21 Ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé: ‘O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ.+ Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.’+ 22 Lẹ́yìn náà, ẹni tó gba tálẹ́ńtì méjì wá, ó sì sọ pé, ‘Ọ̀gá, tálẹ́ńtì méjì lo fún mi; wò ó, mo ti jèrè tálẹ́ńtì méjì sí i.’+ 23 Ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé: ‘O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ. Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.’
24 “Níkẹyìn, ẹrú tó gba tálẹ́ńtì kan wá, ó sì sọ pé: ‘Ọ̀gá, ẹni tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn ni mo mọ̀ ọ́ sí, o máa ń kárúgbìn níbi tí o ò fúnrúgbìn sí, o sì máa ń kó ọkà jọ níbi tí o ò ti fẹ́ ọkà.+ 25 Torí náà, ẹ̀rù bà mí, mo sì lọ fi tálẹ́ńtì rẹ pa mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, gba nǹkan rẹ.’ 26 Ọ̀gá rẹ̀ fún un lésì pé: ‘Ẹrú burúkú tó ń lọ́ra, o mọ̀ àbí, pé mò ń kárúgbìn níbi tí mi ò fúnrúgbìn sí, mo sì ń kó ọkà jọ níbi tí mi ò ti fẹ́ ọkà? 27 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí o ti kó owó* mi lọ sí báǹkì, tí mo bá sì dé, ǹ bá ti gbà á pẹ̀lú èlé.
28 “‘Torí náà, ẹ gba tálẹ́ńtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fún ẹni tó ní tálẹ́ńtì mẹ́wàá.+ 29 Torí gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, ó sì máa ní ọ̀pọ̀ yanturu. Àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 30 Ẹ ju ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun náà sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ lá ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.’
31 “Tí Ọmọ èèyàn+ bá dé nínú ògo rẹ̀, tòun ti gbogbo áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà,+ ó máa jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. 32 A máa kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ síwájú rẹ̀, ó sì máa ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. 33 Ó máa kó àwọn àgùntàn+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àmọ́ ó máa kó àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.+
34 “Ọba máa wá sọ fún àwọn tó wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé: ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún Ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín látìgbà ìpìlẹ̀ ayé. 35 Torí ebi pa mí, ẹ sì fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan mu. Mo jẹ́ àjèjì, ẹ sì gbà mí lálejò;+ 36 mo wà ní ìhòòhò,* ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí.+ Mo ṣàìsàn, ẹ sì tọ́jú mi. Mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ sì wá wò mí.’+ 37 Àwọn olódodo máa wá dá a lóhùn pé: ‘Olúwa, ìgbà wo la rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ tàbí tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tí a sì fún ọ ní nǹkan mu?+ 38 Ìgbà wo la rí ọ ní àjèjì, tí a sì gbà ọ́ lálejò tàbí tí o wà ní ìhòòhò, tí a sì fi aṣọ wọ̀ ọ́? 39 Ìgbà wo la rí ọ tí ò ń ṣàìsàn tàbí tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a sì wá wò ọ́?’ 40 Ọba máa dá wọn lóhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, torí pé ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi tó kéré jù lọ yìí, ẹ ti ṣe é fún mi.’+
41 “Ó máa wá sọ fún àwọn tó wà ní òsì rẹ̀ pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi,+ ẹ̀yin tí a ti gégùn-ún fún, ẹ lọ sínú iná àìnípẹ̀kun+ tí a ṣètò sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+ 42 Nítorí ebi pa mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní nǹkan kan mu. 43 Mo jẹ́ àjèjì, àmọ́ ẹ ò gbà mí lálejò; mo wà ní ìhòòhò, àmọ́ ẹ ò fi aṣọ wọ̀ mí; mo ṣàìsàn, mo sì wà lẹ́wọ̀n, àmọ́ ẹ ò tọ́jú mi.’ 44 Àwọn náà á fi ọ̀rọ̀ yìí dá a lóhùn pé: ‘Olúwa, ìgbà wo la rí ọ tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tàbí tí o jẹ́ àjèjì tàbí tí o wà ní ìhòòhò tàbí tí ò ń ṣàìsàn tàbí tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò sì ṣe ìránṣẹ́ fún ọ?’ 45 Ó máa dá wọn lóhùn pé: ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, torí pé ẹ ò ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tó kéré jù lọ yìí, ẹ ò ṣe é fún mi.’+ 46 Àwọn yìí máa lọ sínú ìparun* àìnípẹ̀kun,+ ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”+